“Àwọn Èèyàn Méjì Wá Kan Ilẹ̀kùn Ilé Wa”
“Àwọn Èèyàn Méjì Wá Kan Ilẹ̀kùn Ilé Wa”
“ỌDÚN méjì sẹ́yìn ni ìbànújẹ́ dorí wa kodò nítorí ikú ọmọbìnrin wa kékeré.” Ohun tó bẹ̀rẹ̀ lẹ́tà kan tí wọ́n kọ sínú ìwé ìròyìn Le Progrès, tí wọ́n tẹ̀ jáde ní Saint-Étienne nílẹ̀ Faransé nìyẹn.
“Ọmọ oṣù mẹ́ta ni Mélissa nígbà tí àrùn búburú tí wọ́n ń pè ní trisomy 18 kọ lù ú. Irú ọ̀ràn ìbànújẹ́ bẹ́ẹ̀ kì í kúrò lọ́kàn ẹni, ìyẹn sì burú gan-an. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé inú ẹ̀sìn Kátólíìkì ni wọ́n ti tọ́ wa dàgbà, èrò tó ń wá sí wa lọ́kàn ṣáá ni pé ‘Ọlọ́run, tó bá jẹ́ pé lóòótọ́ lo wà, kí nìdí tó o fi jẹ́ kírú nǹkan bẹ́ẹ̀ ṣẹlẹ̀?’” Ó hàn gbangba pé inú ìbànújẹ́ kíkorò ni ìyá tó kọ lẹ́tà yìí wà, gbogbo nǹkan sì ti sú u. Ohun tó tún kọ sínú lẹ́tà náà ni pé:
“Kété lẹ́yìn ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ni àwọn èèyàn méjì wá kan ilẹ̀kùn ilé wa. Kíá ni mo mọ̀ pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni wọ́n. Ńṣe ni mo fẹ́ fọgbọ́n lé wọn dà nù, àmọ́ mo wá rí ìwé pẹlẹbẹ kan tí wọ́n ń fi lọni. Ọ̀rọ̀ nípa ìdí tí Ọlọ́run fi fàyè gba ìjìyà ló wà níbẹ̀. Mo ní kí wọ́n wọlé pẹ̀lú èrò pé màá bá wọn jiyàn dọ́ba. Mo ronú pé tó bá jẹ́ ní ti ọ̀ràn ìṣòro ni, ìdílé mi ti ní ìṣòro kọjá wẹ́rẹwẹ̀rẹ, ọ̀rọ̀ kòbákùngbé tá a si ti gbọ́ ti tó gẹ́ẹ́, ìyẹn àwọn ọ̀rọ̀ bí ‘Ọlọ́run ló fún wa, Ọlọ́run ló sì gbà á.’ Àwọn Ẹlẹ́rìí náà lo ohun tó lé ní wákàtí kan lọ́dọ̀ mi. Tàánútàánú ni wọ́n fi tẹ́tí bẹ̀lẹ̀jẹ́ sí gbogbo ọ̀rọ̀ tí mo sọ, nígbà tí wọ́n sì ń lọ, mo rí i pé ara mi yá gan-an ju ti tẹ́lẹ̀ lọ débi pé mo ní kí wọ́n tún padà wá lọ́jọ́ mìíràn. Ọdún méjì sẹ́yìn nìyẹn o. Mi ò tíì di Ẹlẹ́rìí Jèhófà o, àmọ́ mo ti bẹ̀rẹ̀ sí kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́dọ̀ wọn, mo sì máa ń lọ sáwọn ìpàdé wọn ni gbogbo ìgbà tó bá ṣeé ṣe fún mi láti lọ.”