Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Fífarawé Ọlọ́run Òtítọ́

Fífarawé Ọlọ́run Òtítọ́

Fífarawé Ọlọ́run Òtítọ́

“Ẹ di aláfarawé Ọlọ́run, gẹ́gẹ́ bí àwọn ọmọ tí í ṣe olùfẹ́ ọ̀wọ́n.”—ÉFÉSÙ 5:1.

1. Kí làwọn kan gbà gbọ́ nípa òtítọ́, kí sì nìdí tí ọ̀nà tí wọ́n gbà ń ronú fi kù díẹ̀ káàtó?

 “KÍ NI òtítọ́?” (Jòhánù 18:38) Bí ẹní pẹ̀gàn ni Pọ́ńtíù Pílátù fi béèrè ìbéèrè yìí ní ohun tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ẹgbàá ọdún sẹ́yìn, ó sì fi hàn pé òtítọ́ jẹ́ ohun kan tí ọwọ́ ò lè tètè tẹ̀. Ọ̀pọ̀ èèyàn lónìí ló máa gbà pé bẹ́ẹ̀ lọ̀ràn rí. Àwọn èèyàn ti ń pa òtítọ́ dà sí nǹkan mìíràn. O lè ti gbọ́ táwọn èèyàn ń sọ pé olúkúlùkù ló máa pinnu ohun tó jẹ́ òtítọ́, tàbí pé ojúlówó òtítọ́ kò sí tàbí pé òtítọ́ kò dúró sójú kan. Irú èrò yìí kù díẹ̀ káàtó. Olórí ìdí táwọn èèyàn fi ń ṣèwádìí lóríṣiríṣi tí wọ́n sì ń kẹ́kọ̀ọ́ ni láti mọ òkodoro òtítọ́ nípa ilẹ̀ ayé tá à ń gbé. Òtítọ́ kì í ṣe ọ̀ràn ohun tó bá wuni. Bí àpẹẹrẹ, bóyá ọkàn èèyàn máa ń kú tàbí pé kì í kú. Bóyá Sátánì wà tàbí pé kò sí. Bóyá ó ní ìdí téèyàn fi wà láàyè tàbí pé kò ní ìdí. Nínú ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ọ̀ràn yìí, ìdáhùn kan ló lè jẹ́ òótọ́. Ọ̀kan á jẹ́ òótọ́ èkejì á sì jẹ́ èké; ìdáhùn méjèèjì ò lè jẹ́ òótọ́ láéláé.

2. Àwọn ọ̀nà wo ni Jèhófà gbà jẹ́ Ọlọ́run òtítọ́, àwọn ìbéèrè wo la sì máa gbé yẹ̀ wò?

2 Nínú àpilẹ̀kọ tó ṣáájú, a sọ níbẹ̀ pé Jèhófà ni Ọlọ́run òtítọ́. Ó mọ ohun tó jẹ́ òtítọ́ nípa ohun gbogbo. Òtítọ́ ni Jèhófà máa ń sọ nígbà gbogbo, èyí ló mú kó yàtọ̀ pátápátá sí elénìní rẹ̀ Sátánì Èṣù, tó jẹ́ ẹlẹ́tàn. Àní Jèhófà tún ń jẹ́ káwọn èèyàn mọ òtítọ́. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù rọ àwọn Kristẹni bíi tirẹ̀ pé: “Ẹ di aláfarawé Ọlọ́run, gẹ́gẹ́ bí àwọn ọmọ tí í ṣe olùfẹ́ ọ̀wọ́n.” (Éfésù 5:1) Gẹ́gẹ́ bí Ẹlẹ́rìí fún Jèhófà, báwo la ṣe lè ṣàfarawé rẹ̀ ní sísọ òtítọ́ ká sì tún máa gbé ìgbésí ayé wa níbàámu pẹ̀lú òtítọ́? Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì láti ṣe bẹ́ẹ̀? Báwo ló sì ṣe dá wa lójú pé Jèhófà ní inú dídùn sáwọn tí wọ́n ń tẹ̀ lé ipa ọ̀nà òtítọ́? Ẹ jẹ́ ká wò ó.

3, 4. Báwo ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù àti Pétérù ṣe ṣàpèjúwe ohun tó máa ṣẹlẹ̀ ní “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn”?

3 Sànmánì tí èké pọ̀ lọ rẹpẹtẹ nínú ẹ̀sìn la wà yìí. Gẹ́gẹ́ bí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣe sọ tẹ́lẹ̀ lábẹ́ ìmísí látọ̀run, ọ̀pọ̀ èèyàn ló dà bí ẹni tó ń fọkàn sin Ọlọ́run ní “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” wọ̀nyí ṣùgbọ́n tí wọ́n já sí èké ní ti agbára rẹ̀. Àwọn kan kì í fẹ́ gbọ́ òótọ́ rárá, wọ́n “ti dìbàjẹ́ pátápátá nínú èrò inú wọn.” Síwájú sí i, ‘àwọn ènìyàn burúkú àti àwọn afàwọ̀rajà ń tẹ̀ síwájú láti inú búburú sínú búburú jù, wọ́n ń ṣini lọ́nà, a sì ń ṣi àwọn pẹ̀lú lọ́nà.’ Bó tiẹ̀ jẹ́ pé irú àwọn èèyàn yìí ò fìgbà kan dẹ́kun ẹ̀kọ́ kíkọ́, síbẹ̀ wọn ò lè ní “ìmọ̀ pípéye nípa òtítọ́” láé.—2 Tímótì 3:1, 5, 7, 8, 13.

4 A tún mí sí àpọ́sítélì Pétérù náà láti ṣe àkọsílẹ̀ nípa àwọn ọjọ́ ìkẹyìn. Ohun tó sọ tẹ́lẹ̀ gẹ́lẹ́ ló ń ṣẹlẹ̀, àwọn èèyàn ń kọ òtítọ́ sílẹ̀ kódà wọ́n tún ń yọ ṣùtì ètè sí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run àtàwọn tó ń polongo òtítọ́ tá a kọ sínú rẹ̀. “Ní ìbámu pẹ̀lú ìdàníyàn wọn,” àwọn tó ń yọ ṣùtì ètè yìí kò kà á kún rárá pé ìkún omi la fi pa ayé rẹ́ lọ́jọ́ Nóà, pé èyí sì jẹ́ àpẹẹrẹ ìparun tó ń bọ̀ lọ́jọ́ iwájú. Èrò wọn tí wọ́n fi ń tan ara wọn jẹ ló máa kó wọn sí yọ́ọ́yọ́ọ́ nígbà tí àkókò tí Ọlọ́run fẹ́ pa àwọn èèyànkéèyàn run bá dé.—2 Pétérù 3:3-7.

Àwọn Ìránṣẹ́ Jèhófà Mọ Òtítọ́

5. Gẹ́gẹ́ bí wòlíì Dáníẹ́lì ṣe sọ, kí ló máa ṣẹlẹ̀ ní “àkókò òpin,” báwo sì ni àsọtẹ́lẹ̀ yìí ṣe nímùúṣẹ?

5 Nígbà tí wòlíì Dáníẹ́lì ń sọ̀rọ̀ nípa “àkókò òpin,” ó sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa báwọn èèyàn Ọlọ́run ṣe máa yàtọ̀ pátápátá ní tiwọn—àwọn ló máa mú òtítọ́ nípa ẹ̀sìn padà bọ̀ sípò. Ó kọ̀wé pé: “Ọ̀pọ̀ yóò máa lọ káàkiri, ìmọ̀ tòótọ́ yóò sì di púpọ̀ yanturu.” (Dáníẹ́lì 12:4) Ẹlẹ́tàn ńlá náà kò rí àwọn èèyàn Jèhófà tàn jẹ bẹ́ẹ̀ ni kò ríbi fi júújúú bò wọ́n lójú. Wọ́n ti yẹ Bíbélì wò dáadáa, wọ́n sì ti rí ìmọ̀ tòótọ́. Ní ọ̀rúndún kìíní, Jésù la àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ lóye. Ó “ṣí èrò inú wọn payá lẹ́kùn-ún-rẹ́rẹ́ láti mòye ìtumọ̀ Ìwé Mímọ́.” (Lúùkù 24:45) Jèhófà ti ṣe bákan náà ní àkókò wa. Nípasẹ̀ Ọ̀rọ̀ rẹ̀, ẹ̀mí rẹ̀, àti ètò àjọ rẹ̀, ó ti jẹ́ kí ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn kárí ayé lóye nǹkan tóun fúnra rẹ̀ mọ̀—ìyẹn òtítọ́.

6. Àwọn òtítọ́ inú Bíbélì wo làwọn èèyàn Ọlọ́run lóye rẹ̀ lóde òní?

6 Nítorí pé a jẹ́ èèyàn Ọlọ́run, ọ̀pọ̀ nǹkan tí ì bá ṣókùnkùn sí wa la ti lóye. A mọ ìdáhùn sáwọn ìbéèrè táwọn ọlọ́gbọ́n ayé ti ń bá yí láti ọ̀pọ̀ ẹgbẹ̀rúndún sẹ́yìn. Bí àpẹẹrẹ, a mọ ohun tó fa ìjìyà, a mọ ìdí táwọn èèyàn fi ń kú àti ìdí tí ẹ̀dá èèyàn fúnra rẹ̀ ò fi lè mú àlàáfíà kárí ayé àti ìṣọ̀kan wá. A tún ti jẹ́ ká lóye ohun tó ń bọ̀ lọ́jọ́ iwájú—ìyẹn Ìjọba Ọlọ́run, ilẹ̀ ayé tó máa di Párádísè àti ìwàláàyè tí ò lópin nígbà tá a bá ti dé ìjẹ́pípé. A ti mọ Jèhófà, Ẹni Gíga Jù Lọ. A ti kẹ́kọ̀ọ́ nípa àwọn ànímọ́ rẹ̀ tó wuni, bẹ́ẹ̀ la tún kẹ́kọ̀ọ́ ohun tá a gbọ́dọ̀ ṣe ká lè rí ìbùkún rẹ̀ gbà. Òtítọ́ tá a ti mọ̀ ló ń mú ká dá ohunkóhun tó bá jẹ́ ẹ̀tàn mọ̀. Fífi òtítọ́ sílò kì í jẹ́ ká máa sáré lé ohun asán kiri, ó ń mú ká gbé ìgbésí ayé tó nítumọ̀, ó sì ń jẹ́ ká ní ìrètí àgbàyanu fún ọjọ́ iwájú.

7. Àwọn èèyàn wo ló lè rí òtítọ́ inú Bíbélì, irú àwọn wo ni ò sì lè rí i?

7 Ṣé o lóye òtítọ́ inú Bíbélì? Tó o bá lóye rẹ̀ a jẹ́ pé ìbùkún ńláǹlà lo ti rí gbà yẹn o. Nígbà tí òǹkọ̀wé kan bá kọ̀wé, ó máa ṣe é lọ́nà tó fi máa wu oríṣi àwùjọ kan ní pàtó. Àwọn ìwé kan wà tá a kọ nítorí àwọn ọ̀mọ̀wé gidi, a sì kọ àwọn kan fún àwọn ọmọdé, àwọn mìíràn ni a sì kọ fún àwọn èèyàn tó ń ṣe irú iṣẹ́ kan pàtó. Òótọ́ ló jẹ́ pé gbogbo èèyàn ló láǹfààní àtika Bíbélì, àmọ́ àwùjọ àwọn èèyàn kan ní pàtó ló lè lóye rẹ̀ kí wọ́n sì gbádùn rẹ̀. Jèhófà ṣètò rẹ̀ fáwọn tí kì í gbéra ga, àwọn onírẹ̀lẹ̀ ayé. Irú àwọn èèyàn yìí ló lè lóye ohun tó wà nínú Bíbélì láìfi bí wọ́n ṣe kàwé tó, àṣà wọn, ipò wọn tàbí ẹ̀yà wọn pè. (1 Tímótì 2:3, 4) Ní ọwọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, òye òtítọ́ inú Bíbélì kì í ṣe fáwọn tí kò lẹ́mìí tó dára láìka bí ọpọlọ wọn ṣe pé tó tàbí bí wọ́n ṣe mọ̀wé tó sí. Àwọn agbéraga, àtàwọn tó ń fọ́nnu kò lè rí òtítọ́ ṣíṣeyebíye tó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. (Mátíù 13:11-15; Lúùkù 10:21; Ìṣe 13:48) Ọlọ́run nìkan ṣoṣo ló lè ṣe irú ìwé bẹ́ẹ̀.

Olóòótọ́ Làwọn Ìránṣẹ́ Jèhófà

8. Kí nìdí tí Jésù fúnra rẹ̀ fi jẹ́ òtítọ́?

8 Bí Jèhófà ṣe jẹ́ olóòótọ́ làwọn Ẹlẹ́rìí rẹ̀ náà ṣe jẹ́ olóòótọ́. Jésù Kristi tó jẹ́ ẹni tó tayọ lọ́lá jù lọ láàárín àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fìdí òtítọ́ náà múlẹ̀ nípa àwọn ohun tó fi kọ́ni àti ọ̀nà tó gbà gbé ìgbésí ayé rẹ̀ àti bó ṣe kú. Ó fi ọwọ́ pàtàkì mú òtítọ́ ọ̀rọ̀ Jèhófà àtàwọn ìlérí rẹ̀. Ìdí rèé tí Jésù fúnra rẹ̀ fi jẹ́ òtítọ́, gẹ́gẹ́ bóun alára ṣe sọ.—Jòhánù 14:6; Ìṣípayá 3:14; 19:10.

9. Kí ni Ìwé Mímọ́ sọ nípa sísọ òtítọ́?

9 Jésù “kún fún inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí àti òtítọ́,” bẹ́ẹ̀ sì ni “kò sí ẹ̀tàn kankan ní ẹnu rẹ̀.” (Jòhánù 1:14; Aísáyà 53:9) Àpẹẹrẹ tí Jésù fi lélẹ̀ làwọn Kristẹni tòótọ́ ń tẹ̀ lé ní ti jíjẹ́ olóòótọ́ sáwọn ẹlòmíràn. Pọ́ọ̀lù gba àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ nímọ̀ràn pé: “Kí olúkúlùkù yín máa bá aládùúgbò rẹ̀ sọ òtítọ́, nítorí ẹ̀yà ara tí ó jẹ́ ti ara wa lẹ́nì kìíní-kejì ni wá.” (Éfésù 4:25) Wòlíì Sekaráyà ti kọ̀wé ṣáájú pé: “Ẹ bá ara yín sọ òtítọ́ lẹ́nì kìíní-kejì.” (Sekaráyà 8:16) Olóòótọ́ làwọn Kristẹni nítorí pé wọ́n fẹ́ mú inú Ọlọ́run dùn. Olóòótọ́ ni Jèhófà ó sì mọ jàǹbá tó lè tinú èké ṣíṣe jáde. Ìdí rèé tó fi fẹ́ káwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ máa sọ òtítọ́.

10. Kí nìdí táwọn èèyàn fi máa ń parọ́, àbájáde búburú wo ló sì máa ń ní?

10 Fún ọ̀pọ̀ èèyàn irọ́ pípa jẹ́ ọ̀nà ẹ̀bùrú tọ́wọ́ wọn lè gbà tẹ àwọn àǹfààní kan. Àwọn èèyàn máa ń parọ́ kí wọ́n má bàa jìyà àìṣedéédéé wọn, kí wọ́n lè ráwọn àǹfààní kan tàbí káwọn ẹlòmíràn lè gbóṣùbà káre fún wọn. Àmọ́ irọ́ pípa jẹ́ àṣà tí kò yẹ ọmọlúwàbí. Àní sẹ́, òpùrọ́ ò lè rí ojú rere Ọlọ́run. (Ìṣípayá 21:8, 27; 22:15) Táwọn èèyàn bá mọ̀ wá pé a kì í purọ́, wọ́n á gba ohun tá a bá sọ gbọ́; wọ́n á sì fọkàn tán wa. Àmọ́ ṣá, bí àṣírí bá tú pé a parọ́ kódà lẹ́ẹ̀kan péré, àwọn èèyàn ò ní lè gba ohunkóhun yòówù ká sọ lọ́jọ́ iwájú gbọ́ mọ́. Òwe ilẹ̀ Áfíríkà kan sọ pé: “Irọ́ kan ṣoṣo ló ń ba ẹgbẹ̀rún òótọ́ jẹ́.” Òwe mìíràn tún sọ pé “Kò sẹ́ni tó máa gba òpùrọ́ gbọ́, kódà nígbà tó bá ń sọ òótọ́.”

11. Báwo ni ìṣòtítọ́ ṣe ré kọjá kéèyàn kàn máa sọ òótọ́ lẹ́nu?

11 Ìṣòtítọ́ ré kọjá kéèyàn kàn máa sọ òótọ́ lẹ́nu. Ó jẹ́ ọ̀nà téèyàn gbà ń gbé ìgbésí ayé rẹ̀. Òun ló ń sọ irú èèyàn tá a jẹ́. Kì í ṣe ọ̀rọ̀ ẹnu nìkan la fi ń kọ́ àwọn èèyàn ní òtítọ́ náà àmọ́ a tún ń kọ́ wọn nípasẹ̀ ìṣe wa pẹ̀lú. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù béèrè pé: “Ǹjẹ́ ìwọ, ẹni tí ń kọ́ ẹlòmíràn, kò kọ́ ara rẹ? Ìwọ, ẹni tí ń wàásù pé ‘Má jalè,’ ìwọ ha ń jalè bí? Ìwọ, ẹni tí ń sọ pé ‘Má ṣe panṣágà,’ ìwọ ha ń ṣe panṣágà bí?” (Róòmù 2:21, 22) Tá a bá fẹ́ kọ́ àwọn ẹlòmíràn ní òtítọ́, a ní láti jẹ́ olùṣòtítọ́ nínú ohun gbogbo tá a bá ń ṣe. Mímọ̀ táwọn èèyàn bá mọ̀ wá pé olóòótọ́ ni wá yóò túbọ̀ mú káwọn èèyàn tẹ́wọ́ gba ohun tá à ń kọ́ wọn.

12, 13. Kí ni èwe kan kọ nípa ìṣòtítọ́, kí ló sì mú kó máa tẹ̀ lé ìlànà gíga ti ìwà rere?

12 Àwọn èwe tó wà láàárín àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà mọ̀ pé ó ṣe pàtàkì láti jẹ́ olóòótọ́. Nínú àròkọ kan tí Jenny kọ nílé ìwé nígbà tó ṣì wà ní ọmọ ọdún mẹ́tàlá, ó kọ ọ́ pé: “Ìṣòtítọ́ jẹ́ ohun kan tí mo fọwọ́ pàtàkì mú. Àmọ́ ó bani nínú jẹ́ pé gbogbo èèyàn kọ́ ló ń ṣòtítọ́ lóde òní. Mo ti bá ara mi dá májẹ̀mú pé mi ò ní ṣèké láyé mi. Mi ò sì ní yéé sọ òtítọ́ kódà ká tiẹ̀ ní ṣíṣe bẹ́ẹ̀ ò ní mú àǹfààní ojú ẹsẹ̀ wá fún mi tàbí fún àwọn ọ̀rẹ́ mi. Màá rí i dájú pé àwọn tó ń sọ òtítọ́ tí wọ́n ṣì ṣe é fọkàn tán ni mo yàn lọ́rẹ̀ẹ́.”

13 Nígbà tí olùkọ́ Jenny ń sọ̀rọ̀ nípa àròkọ yìí, ó sọ pé: “Pẹ̀lú bó o ṣe kéré lọ́jọ́ orí tó, o ti mọ̀ nípa ìlànà ìwà rere àti ìwà ọmọlúwàbí gan-an. Mo mọ̀ pé wà á ṣe ohun tó o sọ yìí nítorí pé ọmọ tó ní irú ìwà rere bẹ́ẹ̀ ni ẹ́.” Kí ló mú kí irú ọmọdébìnrin kékeré yìí fọwọ́ dan-in dan-in mú ọ̀ràn ìwà rere? Nígbà tí Jenny fẹ́ bẹ̀rẹ̀ àròkọ rẹ̀, ó sọ pé ẹ̀sìn òun “ló gbé àwọn ìlànà kalẹ̀ fún ìgbésí ayé [òun].” Ọdún méje ti kọjá báyìí tí Jenny ti kọ àròkọ náà. Gẹ́gẹ́ bí ohun tí olùkọ́ rẹ̀ sọ, Jenny ò yéé tẹ̀ lé ìlànà ìwà rere gẹ́gẹ́ bí Ẹlẹ́rìí Jèhófà.

Àwọn Ìránṣẹ́ Jèhófà Ń Ṣí Òtítọ́ Payá

14. Kí nìdí tó fi jẹ́ àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run gan-an la fún lẹ́rù iṣẹ́ láti rọ̀ mọ́ òtítọ́?

14 Òótọ́ ni pé àwọn mìíràn tí wọn kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà lè máa sọ òtítọ́ kí wọ́n má sì ṣàbòsí. Àmọ́ gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ Ọlọ́run, àwa gan-an la ní ẹrù iṣẹ́ láti rọ̀ mọ́ òtítọ́. A ti fi òtítọ́ inú Bíbélì síkàáwọ́ wa—ìyẹn òtítọ́ tó lè fúnni ní ìyè àìnípẹ̀kun. Nítorí náà, ẹrù iṣẹ́ wa ni láti jẹ́ káwọn ẹlòmíràn ní ìmọ̀ náà. Jésù sọ pé: “Olúkúlùkù ẹni tí a bá fi púpọ̀ fún, púpọ̀ ni a ó fi dandan béèrè lọ́wọ́ rẹ̀.” (Lúùkù 12:48) Dájúdájú, ‘púpọ̀ ni à ń fi dandan béèrè’ lọ́wọ́ àwọn tá a ti fi ìmọ̀ Ọlọ́run bù kún.

15. Kí ló ń fún ọ láyọ̀ bó o ṣe ń kọ́ àwọn èèyàn ní òtítọ́ Bíbélì?

15 Kíkọ́ àwọn ẹlòmíràn ní òtítọ́ Bíbélì máa ń fúnni láyọ̀. Bíi tàwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù ọ̀rúndún kìíní, à ń polongo ìhìn rere, ìyẹn ìrètí amọ́kànyọ̀ fún àwọn tí ‘a bó láwọ, ti a sì fọ́n ká bí àwọn àgùntàn tí kò ní olùṣọ́ àgùntàn,’ àti àwọn tí “ẹ̀kọ́ ẹ̀mí èṣù” ti fọ́ lójú tí wọn ò sì mọ ohun tó yẹ ní ṣíṣe. (Mátíù 9:36; 1 Tímótì 4:1) Àpọ́sítélì Jòhánù kọ̀wé pé: “Èmi kò ní ìdí kankan tí ó tóbi ju nǹkan wọ̀nyí lọ fún ṣíṣọpẹ́, pé kí n máa gbọ́ pé àwọn ọmọ mi ń bá a lọ ní rírìn nínú òtítọ́.” (3 Jòhánù 4) Ìṣòtítọ́ àwọn “ọmọ” Jòhánù —bóyá àwọn tó kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́—fún un láyọ̀ púpọ̀. Ayọ̀ tiwa náà máa ń kún nígbà tá a bá rí i táwọn èèyàn ń fi ìmọrírì hàn fún Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.

16, 17. (a) Èé ṣe tí gbogbo èèyàn ò fi lè tẹ́wọ́ gba òtítọ́? (b) Ayọ̀ wo ló lè jẹ́ tìrẹ bó o ṣe ń polongo òtítọ́ Bíbélì?

16 Lóòótọ́, kì í ṣe gbogbo èèyàn ló máa tẹ́wọ́ gba òtítọ́ náà. Jésù sọ òtítọ́ nípa Ọlọ́run, kódà lákòókò táwọn èèyàn ń bẹnu àtẹ́ lu irú nǹkan bẹ́ẹ̀. Ó sọ fáwọn Júù alátakò pé: “Èé ṣe tí ẹ kò gbà mí gbọ́? Ẹni tí ó bá ti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá ń fetí sí àwọn àsọjáde Ọlọ́run. Ìdí nìyí tí ẹ kò fi fetí sílẹ̀, nítorí pé ẹ kò ti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá.”—Jòhánù 8:46, 47.

17 Gẹ́gẹ́ bíi Jésù, a ò yéé sọ òtítọ́ ṣíṣeyebíye nípa Jèhófà fáwọn ẹlòmíràn. A ò retí pé kí gbogbo èèyàn gba ohun tá a bá sọ fún wọn, nítorí pé kì í ṣe gbogbo èèyàn ló gba ọ̀rọ̀ Jésù. Síbẹ̀síbẹ̀, à ń láyọ̀ fún mímọ̀ tá a mọ̀ pé ohun tó tọ́ là ń ṣe. Nítorí inú rere onífẹ̀ẹ́ Jèhófà, ó fẹ́ kí ẹ̀dá èèyàn mọ òtítọ́. Àwọn Kristẹni ti di atànmọ́lẹ̀ nínú ayé tó ṣókùnkùn yìí nítorí pé àwọn ló ní òtítọ́. Tá a bá jẹ́ kí ìmọ́lẹ̀ òtítọ́ tàn nípa ọ̀rọ̀ àti ìṣe wa, àá lè ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ láti fi ògo fún Baba wa ọ̀run. (Mátíù 5:14, 16) À ń jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ ní gbangba pé a ò tẹ́wọ́ gba ayédèrú òtítọ́ tí í ṣe ti Sátánì, pé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tó jẹ́ mímọ́ tí ò sì lábùlà la rọ̀ mọ́. Òtítọ́ tá a mọ̀ tá a sì ń sọ fáwọn èèyàn lè fún àwọn tó bá tẹ́wọ́ gbà á lómìnira tòótọ́.—Jòhánù 8:32.

Máa Lépa Ọ̀nà Òtítọ́

18. Kí nìdí tí Jésù fi fojú rere hàn sí Nàtáníẹ́lì, báwo ló sì ṣe ṣe é?

18 Jésù fẹ́ràn òtítọ́ ó sì ń sọ ọ́. Nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé, ó fojú rere hàn sáwọn olóòótọ́. Jésù sọ nípa Nàtáníẹ́lì pé: “Wò ó, ọmọ Ísírẹ́lì kan dájúdájú, nínú ẹni tí ẹ̀tàn kankan kò sí.” (Jòhánù 1:47) Nígbà tó sì ṣe, a yan Nàtáníẹ́lì tó jọ pé òun náà la tún ń pè ní Bátólómíù láti di ọ̀kan lára àwọn àpọ́sítélì méjìlá. (Mátíù 10:2-4) Ẹ ò rí i pé ọlá lèyí jẹ́!

19-21. Báwo la ṣe bù kún ọkùnrin kan tó jẹ́ afọ́jú tẹ́lẹ̀ nítorí pé ó fi ìgboyà sọ òtítọ́?

19 Odidi orí kan nínú ìwé Jòhánù inú Bíbélì ló sọ nípa ọ̀gbẹ́ni mìíràn tó tún jẹ́ olóòótọ́ tí Jésù sì bù kún. A ò mọ orúkọ rẹ̀. Àmọ́ ohun tá a mọ̀ ni pé alágbe lọkùnrin náà afọ́jú sì ni látìgbà tí wọ́n ti bí i. Ìyàlẹ́nu ló jẹ́ fáwọn èèyàn nígbà tí Jésù la ojú rẹ̀. Ìròyìn iṣẹ́ ìyanu yìí ta sétí àwọn Farisí kan, tí wọ́n kórìíra òtítọ́, tí wọ́n sì ti gbìmọ̀ pọ̀ láàárín ara wọn pé lílé làwọn máa lé ẹnikẹ́ni tó bá gba Jésù gbọ́ kúrò nínú sínágọ́gù. Àwọn òbí ọ̀gbẹ́ni afọ́jú tẹ́lẹ̀ náà mọ ohun táwọn aráabí yìí ń gbèrò, ẹ̀rù sì ń bà wọ́n, ni wọ́n bá parọ́ fáwọn Farisí náà pé àwọn ò mọ bí ọmọ wọn ṣe dẹni tó ń ríran àwọn ò mọ ẹni tó ṣe iṣẹ́ ìyanu náà.—Jòhánù 9:1-23.

20 Ni wọ́n bá tún pe ọkùnrin tá a mú lára dá yìí wá síwájú àwọn Farisí. Ó fi àìṣojo sọ òtítọ́ fún wọn, kò tiẹ̀ bẹ̀rù ohunkóhun tó lè tìdí ẹ̀ yọ. Ó ṣàlàyé bá a ṣe mú òun lára dá àti pé Jésù ló mú òun lára dá. Ó ya ọkùnrin tá a mú lára dá náà lẹ́nu pé àwọn èèyàn jàǹkànjàǹkàn tí wọ́n jẹ́ ọ̀mọ̀wé yìí kò mọ̀ pé ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni Jésù ti wa, ó sọ fún wọn tìgboyàtìgboyà pé: “Bí kì í bá ṣe ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni ọkùnrin yìí ti wá, kò ní lè ṣe nǹkan kan rárá.” Kẹ́kẹ́ pa mọ́ àwọn Farisí náà lẹ́nu, wọ́n sì fẹ̀sùn kan ọ̀gbẹ́ni náà pé aláfojúdi ni, ni wọ́n bá tì í síta.—Jòhánù 9:24-34.

21 Nígbà tí Jésù gbọ́ ohun tó ṣẹlẹ̀, ó fi ìfẹ́ wá ọkùnrin yìí ní àwárí. Nígbà tó sì rí i, ó fún ìgbàgbọ́ ọ̀gbẹ́ni tó jẹ́ afọ́jú tẹ́lẹ̀ náà lókun sí i. Jésù fi ara rẹ̀ hàn ní gbangba pé òun ni Mèsáyà náà. Ẹ ò rí ìbùkún yàbùgà yabuga tí ọ̀gbẹ́ni náà rí gbà nítorí pé ó sọ òtítọ́! Dájúdájú, Ọlọ́run máa ń fi ojú rere hàn sáwọn tó bá ń sọ òtítọ́.—Jòhánù 9:35-37.

22. Èé ṣe tá a fi gbọ́dọ̀ máa tẹ̀ lé ipa ọ̀nà òtítọ́?

22 Sísọ òtítọ́ jẹ́ ohun kan tá a gbọ́dọ̀ fọwọ́ pàtàkì mú. Èyí ṣe kókó tẹ́nì kan bá fẹ́ ní àjọṣe tó jíire pẹ̀lú àwọn èèyàn àti pẹ̀lú Ọlọ́run. Téèyàn bá fẹ́ jẹ́ olóòótọ́, ó ní láti jẹ́ ẹni tí kì í fọ̀rọ̀ sábẹ́ ahọ́n sọ, ẹni bí ẹni, tó ṣe é sún mọ́, tó ṣe é fọkàn tán, èyí sì máa ń múni jèrè ojú rere Jèhófà. (Sáàmù 15:1, 2) Aláìṣòótọ́ ni ẹni tó jẹ́ ẹlẹ́tàn, tí kò ṣe é fọkàn tán, òpùrọ́, èyí sì ń múni pàdánù ojú rere Jèhófà. (Òwe 6:16-19) Nítorí náà, fi ṣe ìpinnu rẹ láti máa sọ òótọ́. Àní, tá a ba fẹ́ fara wé Ọlọ́run òtítọ́, a gbọ́dọ̀ mọ òtítọ́, a gbọ́dọ̀ máa sọ òtítọ́, ká sì máa fi òtítọ́ ṣèwà hù.

Báwo Ni Wàá Ṣe Dáhùn?

• Èé ṣe tó fi yẹ ká máa ṣọpẹ́ pé a mọ òtítọ́?

• Báwo la ṣe lè fara wé Jèhófà nípa jíjẹ́ olóòótọ́?

• Àwọn àǹfààní wo ló wà nínú fífi òtítọ́ Bíbélì kọ́ àwọn ẹlòmíràn?

• Èé ṣe tó fi ṣe pàtàkì láti rọ̀ mọ́ ipa ọ̀nà òtítọ́?

[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]

A ti fi òtítọ́ inú Bíbélì síkàáwọ́ àwọn Kristẹni, wọ́n sì ń fi ìtara sọ ọ́ fún àwọn ẹlòmíràn

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]

Ọkùnrin afọ́jú tí Jésù wò sàn rí ìbùkún yàbùgà-yabuga gbà nítorí pé ó sọ òtítọ́