Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Jèhófà, Ọlọ́run Òtítọ́

Jèhófà, Ọlọ́run Òtítọ́

Jèhófà, Ọlọ́run Òtítọ́

“Ìwọ ti tún mi rà padà, Jèhófà Ọlọ́run òtítọ́.”—SÁÀMÙ 31:5.

1. Báwo ni ipò àwọn nǹkan ṣe rí lórí ilẹ̀ ayé àti lájùlé ọ̀run nígbà tí kò sóhun tó ń jẹ́ àìṣòótọ́?

 ÌGBÀ kan wà tí kò sí ohunkóhun tó ń jẹ́ àìṣòótọ́. Àwọn ẹ̀dá ẹ̀mí tí Ọlọ́run dá ní pípé ló wà lájùlé ọ̀run nígbà yẹn, tí wọ́n ń jọ́sìn Ẹlẹ́dàá wọn tí í ṣe “Ọlọ́run òtítọ́.” (Sáàmù 31:5) Ìwà màkàrúrù àti ẹ̀tàn kò sí. Òótọ́ pọ́ńbélé ni Jèhófà máa ń sọ fáwọn ọmọ rẹ̀ tí wọ́n jẹ́ ẹ̀dá ẹ̀mí. Níní tó nífẹ̀ẹ́ wọn tí ire wọn sì jẹ ẹ́ lọ́kàn ló mú kó máa ṣe bẹ́ẹ̀. Bákan náà sì lọ̀ràn ṣe rí lórí ilẹ̀ ayé. Jèhófà dá ọkùnrin àti obìnrin àkọ́kọ́, ó sì ń gba ẹnu ẹni tó yàn bá wọn sọ̀rọ̀ lọ́nà tó ṣe kedere, tí kò ní fífi igbá kan bọ̀kan nínú, tó sì tún jẹ́ òótọ́. Kò sí ni, ohun alárinrin gbáà lèyí ní láti jẹ́ nígbà náà lọ́hùn-ún!

2. Tá ló dá àìṣòótọ́ sílẹ̀, kí sì nìdí?

2 Àmọ́ nígbà tó yá, ọmọ Ọlọ́run kan tó jẹ́ ẹ̀dá ẹ̀mí ṣàyà gbàǹgbà ó sọ pé òun fẹ́ bá Ọlọ́run dọ́gba, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣòdì sí Jèhófà. Ẹ̀dá ẹ̀mí yìí tá a wá mọ̀ sí Sátánì Èṣù, fẹ́ káwọn èèyàn máa jọ́sìn òun. Kí ọwọ́ rẹ̀ lè tẹ ohun tó ń fẹ́, ó dá ìwà àìṣòótọ́ sílẹ̀ kó lè rọ́nà láti máa darí àwọn èèyàn. Ohun tó ṣe yìí ló mú kó di “òpùrọ́ . . . àti baba irọ́.”—Jòhánù 8:44.

3. Kí ni Ádámù àti Éfà ṣe nígbà tí Sátánì parọ́ fun wọn, kí ló sì tẹ̀yìn rẹ̀ yọ?

3 Sátánì gba ẹnu ejò kan sọ fún obìnrin àkọ́kọ́ náà, ìyẹn Éfà, pé kò ní kú tó bá ṣàìgbọràn sí òfin Ọlọ́run tó sì jẹ èso tí Ọlọ́run kà léèwọ̀ náà. Irọ́ ńlá lèyí. Ó tún sọ fún un pé tó bá jẹ ẹ́ ó máa dà bí Ọlọ́run, á sì mọ rere àti búburú. Irọ́ funfun báláú tún lèyí náà. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ẹnikẹ́ni ò tíì parọ́ fún Éfà rí, ó yẹ kó mọ̀ pé ohun tí ejò náà sọ fóun yàtọ̀ sóhun tí Ọlọ́run sọ fún Ádámù ọkọ rẹ̀. Síbẹ̀, ó gba Sátánì gbọ́ dípò Jèhófà. Bó ṣe tàn án jẹ pátápátá nìyẹn, ló bá mú èso náà ó sì jẹ ẹ́. Nígbà tó yá, Ádámù náà tún jẹ nínú èso yìí. (Jẹ́nẹ́sísì 3:1-6) Ọ̀ràn Ádámù dà bíi ti Éfà, a ò tíì parọ́ fóun náà rí, síbẹ̀ a kò tàn án jẹ. (1 Tímótì 2:14) Ìwà tó hù fi hàn pé ó ti kọ Ẹlẹ́dàá rẹ̀ sílẹ̀. Ọ̀ràn yìí kò bímọọre fún ẹ̀dá èèyàn o. Àìgbọràn Ádámù yìí ló fa àìsàn àti ikú—ìwà ìbàjẹ́ àti wàhálà tí ò ṣe é fẹnu sọ—wá sórí gbogbo àtọmọdọ́mọ rẹ̀.—Róòmù 5:12.

4. (a) Irọ́ wo ni Sátánì pa nínú ọgbà Édẹ́nì? (b) Kí la gbọ́dọ̀ ṣe tá ò bá fẹ́ kí Sátánì tàn wá jẹ?

4 Irọ́ náà tún tàn kálẹ̀. Ó yẹ ká fi sọ́kàn pé irọ́ tí Sátánì pa nínú ọgbà Édẹ́nì yìí jẹ́ àtakò sí jíjẹ́ tí Jèhófà jẹ́ olóòótọ́. Sátánì sọ pé ẹlẹ́tàn ni Ọlọ́run pé ńṣe ló ń fi àwọn ohun rere du tọkọtaya àkọ́kọ́ náà. Àmọ́ bẹ́ẹ̀ kọ́ lọ̀ràn rí. Ádámù àti Éfà kò rí èrè kankan nínú àìgbọràn tí wọ́n ṣe yìí. Ńṣe ni wọ́n kú, gẹ́gẹ́ bí Jèhófà ti sọ ṣáájú. Síbẹ̀, Sátánì ò jáwọ́ nínú ọ̀rọ̀ ìbàjẹ́ tó ń sọ sí Jèhófà yìí, tó fi jẹ́ pé ní ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún lẹ́yìn náà, a mí sí àpọ́sítélì Jòhánù láti kọ̀wé pé Sátánì “ń ṣi gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé pátá lọ́nà.” (Ìṣípayá 12:9) Tá ò bá fẹ́ kí Sátánì Èṣù tàn wá jẹ, a gbọ́dọ̀ ní ìgbọ́kànlé kíkún nínú jíjẹ́ tí Jèhófà jẹ́ olóòótọ́ àti jíjẹ́ tí Ọ̀rọ̀ rẹ̀ pẹ̀lú jẹ́ òtítọ́. Báwo lo ṣe lè ní ìgbọ́kànlé nínú Jèhófà kó o sì mú kí ìgbọ́kànlé náà lágbára sí i, kó o tún dáàbò bo ara rẹ lọ́wọ́ ẹ̀tàn àti irọ́ tí Elénìní rẹ̀ ń ṣagbátẹrù rẹ̀?

Jèhófà Mọ Òtítọ́

5, 6. (a) Irú ìmọ̀ wo ni Jèhófà ní? (b) Báwo ni ìmọ̀ ẹ̀dá èèyàn ṣe rí sí ti Jèhófà?

5 Léraléra ni Bíbélì sọ pé Jèhófà ni ẹni náà tó “dá ohun gbogbo.” (Éfésù 3:9) Òun ni “Ẹni tí ó ṣe ọ̀run àti ilẹ̀ ayé àti òkun àti ohun gbogbo tí ń bẹ nínú wọn.” (Ìṣe 4:24) Nígbà tó sì jẹ́ pé Jèhófà ni Ẹlẹ́dàá, ó mọ òtítọ́ nípa ohun gbogbo. Àpèjúwe kan rèé: Gbé àpẹẹrẹ ọkùnrin kan tó fúnra rẹ̀ yàwòrán irú ilé tó fẹ́ kọ́ yẹ̀ wò. Ó fúnra rẹ̀ kọ́ ilé náà ó sì kàn án. Ó máa mọ ilé náà tinú tòde ju ẹnikẹ́ni mìíràn lọ tí kò bá a ṣiṣẹ́ ilé náà. Àwọn èèyàn máa ń mọ tìfun-tẹ̀dọ̀ nǹkan tí wọ́n fúnra wọn ṣe. Lọ́nà kan náà, Ẹlẹ́dàá mọ tinú-tòde àwọn ohun tó dá.

6 Wòlíì Aísáyà sọ bí ìmọ̀ Jèhófà ṣe jinlẹ̀ tó. A kà á pé: “Ta ni ó ti díwọ̀n omi nínú ìtẹkòtò ọwọ́ rẹ̀ lásán, tí ó sì ti fi ìbú àtẹ́lẹwọ́ lásán wọn ọ̀run pàápàá, tí ó sì ti kó ekuru ilẹ̀ ayé jọ sínú òṣùwọ̀n, tàbí tí ó fi atọ́ka-ìwọ̀n wọn àwọn òkè ńláńlá, tí ó sì wọn àwọn òkè kéékèèké nínú òṣùwọ̀n? Ta ni ó ti wọn ẹ̀mí Jèhófà, ta sì ni, gẹ́gẹ́ bí ọkùnrin tí ń gbà á nímọ̀ràn, tí ó lè mú kí ó mọ ohunkóhun? Ta ni òun bá fikùn lukùn, tí ẹnì kan fi lè mú kí ó lóye, tàbí kẹ̀, ta ni ó ń kọ́ ọ ní ipa ọ̀nà ìdájọ́ òdodo, tàbí tí ó ń kọ́ ọ ní ìmọ̀, tàbí tí ó ń mú kí ó mọ àní ọ̀nà òye gidi?” (Aísáyà 40:12-14) Dájúdájú, “Ọlọ́run ìmọ̀” ni Jèhófà ó sì tún jẹ́ “ẹni pípé nínú ìmọ̀.” (1 Sámúẹ́lì 2:3; Jóòbù 36:4; 37:16) Ìmọ̀ wa ò ju bíńtín lọ tá a bá fi wé tirẹ̀! Pẹ̀lú ìmọ̀ ńláǹlà tí ẹ̀dá èèyàn ti kó jọ, òye tá a ní nípa àwọn ìṣẹ̀dá tó ṣe é fojú rí ò tiẹ̀ dé “bèbè àwọn ọ̀nà [Ọlọ́run].” Ńṣe ló dà bí “àhegbọ́” lásán tá a bá fi wé “ààrá agbára ńlá.”—Jóòbù 26:14.

7. Kí ni Dáfídì mọ̀ nípa ìmọ̀ Jèhófà, kí ló sì yẹ kí èyí mú kí àwa náà mọ̀ nípa rẹ̀?

7 Nígbà tó jẹ́ pé Jèhófà ló ṣẹ̀dá wa, ó bọ́gbọ́n mu láti ronú pé ó mọ̀ wá dáadáa. Dáfídì Ọba mọ èyí. Ó kọ̀wé pé: “Jèhófà, ìwọ ti yẹ̀ mí wò látòkè délẹ̀, ìwọ sì mọ̀ mí. Ìwọ alára ti wá mọ jíjókòó mi àti dídìde mi. Ìwọ ti gbé ìrònú mi yẹ̀ wò láti ibi jíjìnnàréré. Ìrìn àjò mi àti ìnàtàntàn mi lórí ìdùbúlẹ̀ ni ìwọ ti díwọ̀n, ìwọ sì ti wá mọ gbogbo ọ̀nà mi dunjú. Nítorí tí kò sí ọ̀rọ̀ kan ní ahọ́n mi, ṣùgbọ́n, wò ó! Jèhófà, ìwọ ti mọ gbogbo rẹ̀ tẹ́lẹ̀.” (Sáàmù 139:1-4) Dájúdájú, Dáfídì mọ̀ pé ẹ̀dá èèyàn ní òmìnira láti yan ohun tó bá wù wọ́n—Ọlọ́run ti fún wa ní òmìnira láti ṣègbọràn sí òun tàbí láti ṣàìgbọràn sí òun. (Diutarónómì 30:19, 20; Jóṣúà 24:15) Síbẹ̀, Jèhófà mọ̀ wá dáadáa ju bá a ṣe mọ ara wa lọ. Ohun tó máa ṣe wá láǹfààní ló fẹ́ fún wa, ó sì lágbára láti darí àwọn ọ̀nà wa. (Jeremáyà 10:23) Ká sòótọ́, kò sí olùkọ́ bẹ́ẹ̀, kò sí ọ̀mọ̀ràn bẹ́ẹ̀, kò sì sí olùgbani-nímọ̀ràn bẹ́ẹ̀ tó tóótun láti fi òtítọ́ kọ́ wa kó sì mú ká gbọ́n ká sì máa yọ̀.

Olóòótọ́ Ni Jèhófà

8. Báwo la ṣe mọ̀ pé olóòótọ́ ni Jèhófà?

8 Ọ̀tọ̀ ni pé kéèyàn mọ òtítọ́, ọ̀tọ̀ sì tún ni pé kéèyàn máa sọ òtítọ́ nígbà gbogbo, kéèyàn jẹ́ olóòótọ́. Bí àpẹẹrẹ, Èṣù yàn láti má ṣe “dúró ṣinṣin nínú òtítọ́.” (Jòhánù 8:44) Àmọ́ Jèhófà ní tiẹ̀ “pọ̀ yanturu ní . . . òtítọ́.” (Ẹ́kísódù 34:6) Gbogbo ìgbà ni Ìwé Mímọ́ ń jẹ́rìí sí i pé olóòótọ́ ni Jèhófà. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé “kò ṣeé ṣe fún Ọlọ́run láti purọ́,” àti pé Ọlọ́run “kò lè purọ́.” (Hébérù 6:18; Títù 1:2) Sísọ òtítọ́ jẹ́ ọ̀kan lára ànímọ́ pàtàkì tí Ọlọ́run ní. Atóófaratì ni Jèhófà a sì lè gbẹ́kẹ̀ lé e nítorí pé olóòótọ́ ni; kò jẹ́ tan àwọn tó bá jẹ́ adúróṣinṣin jẹ láé.

9. Báwo ni orúkọ Jèhófà ṣe tan mọ́ òtítọ́?

9 Orúkọ Jèhófà gan-an jẹ́rìí sí i pé olóòótọ́ ni. Orúkọ Ọlọ́run túmọ̀ sí “Alèwílèṣe.” Èyí fi hàn pé Jèhófà jẹ́ Ẹni tó máa ń mú àwọn ìlérí rẹ̀ ṣẹ. Kò tún sí ẹlòmíràn tó lè ṣe bẹ́ẹ̀. Nítorí pé Jèhófà ni Ẹni Gíga Jù Lọ, kò sí ohun tó lè dí i lọ́wọ́ pé kó máà mú àwọn ète rẹ̀ ṣẹ. Kì í ṣe pé Jèhófà jẹ́ olóòótọ́ nìkan ni, àmọ́ òun nìkan ló tún ní agbára àti ọgbọ́n láti rí i pé gbogbo nǹkan tó sọ pátá ló ṣẹ.

10. (a) Báwo ni Jóṣúà ṣe rí i pé olóòótọ́ ni Jèhófà? (b) Àwọn ìlérí Jèhófà wo lo ti ní ìmúṣẹ?

10 Jóṣúà jẹ́ ọ̀kan lára ọ̀pọ̀ èèyàn tó fojú rí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ àràmàǹdà tó jẹ́rìí sí i pé olóòótọ́ ni Jèhófà. Jóṣúà wà ní Íjíbítì nígbà tí Jèhófà da ìyọnu mẹ́wàá sórí orílẹ̀-èdè náà, tó sì ti sàsọtẹ́lẹ̀ ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn. Ọ̀kan lára àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tó nímùúṣẹ níṣojú Jóṣúà ni ìlérí tí Jèhófà ṣe pé òun á dá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nídè kúrò ní Íjíbítì òun á sì mú wọn wọ Ilẹ̀ Ìlérí, tóun á sì tipa bẹ́ẹ̀ borí ọmọ ogun àwọn ará Kénáánì alágbára tó ń gbógun tì wọ́n. Nígbà tí Jóṣúà ń sún mọ́ ọjọ́ ikú rẹ̀, ó sọ fáwọn àgbààgbà ọkùnrin ní orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì pé: “Ẹ̀yin sì mọ̀ dáadáa ní gbogbo ọkàn-àyà yín àti ní gbogbo ọkàn yín pé kò sí ọ̀rọ̀ kan tí ó kùnà nínú gbogbo ọ̀rọ̀ rere tí Jèhófà Ọlọ́run yín sọ fún yín. Gbogbo wọn ti ṣẹ fún yín. Kò sí ọ̀rọ̀ kan lára wọn tí ó kùnà.” (Jóṣúà 23:14) Bó tiẹ̀ jẹ́ pé oò tíì rí irú iṣẹ́ ìyanu tí Jóṣúà rí, ǹjẹ́ o ti rí i lọ́jọ́ ayé rẹ pé òótọ́ làwọn ìlérí tí Ọlọ́run ṣe?

Jèhófà Ń Ṣí Òtítọ́ Payá

11. Kí ló fi hàn pé òótọ́ ni Jèhófà máa ń sọ fun ẹ̀dá èèyàn?

11 Fojú inú wo bó ṣe máa rí ká ní òbí kan wà tó ní ìmọ̀ gan-an àmọ́ tí kì í fi bẹ́ẹ̀ bá àwọn ọmọ rẹ̀ sọ̀rọ̀. Ǹjẹ́ oò dúpẹ́ pé Jèhófà ní tiẹ̀ kò rí bẹ́ẹ̀? Tìfẹ́tìfẹ́ ni Jèhófà máa ń bá ẹ̀dá èèyàn sọ̀rọ̀ ó sì máa ń ṣe bẹ́ẹ̀ fàlàlà. Ìwé Mímọ́ pè é ní ‘Olùkọ́ni Atóbilọ́lá.’ (Aísáyà 30:20) Inú rere onífẹ̀ẹ́ rẹ̀ sún un débi pé ó ń bá àwọn tí ò tiẹ̀ fẹ́ tẹ́tí sí i pàápàá sọ̀rọ̀. Bí àpẹẹrẹ, Jèhófà sọ pé kí Ìsíkíẹ́lì lọ wàásù fáwọn èèyàn kan tó mọ̀ pé wọn ò ní fẹ́ gbọ́. Jèhófà sọ pé: “Ọmọ ènìyàn, lọ, wọ àárín ilé Ísírẹ́lì, sì fi ọ̀rọ̀ mi bá wọn sọ̀rọ̀.” Ó wá kìlọ̀ fún un pé: “Wọn kì yóò fẹ́ láti fetí sí ọ, nítorí wọn kò fẹ́ láti fetí sí mi; nítorí pé gbogbo ilé Ísírẹ́lì jẹ́ kìígbọ́-kìígbà àti ọlọ́kàn-líle.” Iṣẹ́ ńlá gbáà nìyẹn jẹ́, àmọ́ Ìsíkíẹ́lì ṣe é tinútinú, ṣíṣe tó sì ṣe é yìí fi hàn pé aláàánú ni Jèhófà. Tí ìwọ náà bá ń wàásù níbi tó le koko tó o sì gbẹ́kẹ̀ lé Ọlọ́run, ọkàn rẹ á balẹ̀ pé ó máa fún ẹ lókun gẹ́gẹ́ bó ṣe fún Ìsíkíẹ́lì wòlíì rẹ̀ lókun.—Ìsíkíẹ́lì 3:4, 7-9.

12, 13. Àwọn ọ̀nà wo ni Ọlọ́run ti gbà bá ẹ̀dá èèyàn sọ̀rọ̀?

12 Ohun tí Jèhófà fẹ́ ni pé “kí a gba gbogbo onírúurú ènìyàn là, kí wọ́n sì wá sí ìmọ̀ pípéye nípa òtítọ́.” (1 Tímótì 2:4) Ó ti gba ẹnu àwọn wòlíì, àwọn áńgẹ́lì, tó fi dórí Jésù Kristi Ọmọ rẹ̀ ọ̀wọ́n pàápàá sọ̀rọ̀. (Hébérù 1:1, 2; 2:2) Jésù sọ fún Pílátù pé: “Nítorí èyí ni a ṣe bí mi, nítorí èyí sì ni mo ṣe wá sí ayé, kí n lè jẹ́rìí sí òtítọ́. Olúkúlùkù ẹni tí ó bá wà ní ìhà ọ̀dọ̀ òtítọ́ ń fetí sí ohùn mi.” Pílátù ní àǹfààní aláìlẹ́gbẹ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ nípa àwọn ètò tí Jèhófà ti ṣe fún ìgbàlà látẹnu Ọmọ Ọlọ́run fúnra rẹ̀. Àmọ́ ṣá, Pílátù ò mọrírì òtítọ́, kò sì fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ lọ́dọ̀ Jésù. Dípò ìyẹn, ńṣe ló béèrè ìbéèrè tí ò dénú rẹ̀ pé: “Kí ni òtítọ́?” (Jòhánù 18:37, 38) Ó mà ṣe o! Síbẹ̀, ọ̀pọ̀ èèyàn ló fetí sí òtítọ́ tí Jésù kéde rẹ̀. Ó sọ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Aláyọ̀ ni ojú yín nítorí pé wọ́n rí, àti etí yín nítorí pé wọ́n gbọ́.”—Mátíù 13:16.

13 Jèhófà ti lo Bíbélì láti pa òtítọ́ náà mọ́, ó sì ti mú kó wà lárọ̀ọ́wọ́tó àwọn èèyàn níbi gbogbo. Bíbélì ń jẹ́ ká mọ báwọn nǹkan ṣe rí gan-an. Ó sọ àwọn ànímọ́ Ọlọ́run, àwọn ète rẹ̀, àwọn àṣẹ rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ló tún sọ bí ipò àwọn nǹkan ṣe rí gan-an láàárín ẹ̀dá èèyàn. Nígbà tí Jésù ń gbàdúrà sí Jèhófà, ó sọ pé: “Òtítọ́ ni ọ̀rọ̀ rẹ.” (Jòhánù 17:17) Fún ìdí yìí, ìwé tí ò lẹ́gbẹ́ ni Bíbélì jẹ́. Òun ni ìwé kan ṣoṣo tá a kọ lábẹ́ ìmísí Ọlọ́run tó mọ ohun gbogbo. (2 Tímótì 3:16) Ẹ̀bùn iyebíye ló jẹ́ fún ẹ̀dá èèyàn, àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run sì kà á sí ohun tó ṣeyebíye. Ohun tó dáa ni pé ká máa kà á lójoojúmọ́.

Di Òtítọ́ Mú Ṣinṣin

14. Kí ni díẹ̀ lára àwọn nǹkan tí Jèhófà sọ pé òun á ṣe, kí sì nìdí tó fi yẹ ká gbà á gbọ́?

14 A gbọ́dọ̀ fọwọ́ pàtàkì mú àwọn ohun tí Jèhófà ń sọ fún wa nínú Ọ̀rọ̀ rẹ̀. Irú ẹni tó lóun jẹ́ náà ló kúkú jẹ́, gbogbo ohun tó sì sọ pé òun á ṣe ló máa ṣe. Kò sí ìdí kankan tí ò fi yẹ ká gbẹ́kẹ̀ lé Ọlọ́run. A lè gba ohun tí Jèhófà sọ gbọ́ pé òun á mú “ẹ̀san wá sórí àwọn tí kò mọ Ọlọ́run àti àwọn tí kò ṣègbọràn sí ìhìn rere nípa Jésù Olúwa wa.” (2 Tẹsalóníkà 1:8) Ó tún yẹ ká gba Jèhófà gbọ́ nígbà tó sọ pé òun nífẹ̀ẹ́ àwọn tó ń lépa òdodo, pé òun á fún àwọn tó bá lo ìgbàgbọ́ ní ìyè àìnípẹ̀kun, pé òun á mú ìrora, ẹkún àti ikú pàápàá kúrò. Jèhófà jẹ́ ká mọ̀ pé ìlérí tóun ṣe yìí ṣeé gbíyè lé nípa àwọn ìtọ́ni tó fún àpọ́sítélì Jòhánù pé: “Kọ̀wé rẹ̀, nítorí pé ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ṣeé gbíyè lé, wọ́n sì jẹ́ òótọ́.”—Ìṣípayá 21:4, 5; Òwe 15:9; Jòhánù 3:36.

15. Kí ni díẹ̀ lára àwọn irọ́ tí Sátánì ń tàn kálẹ̀?

15 Òdìkejì pátápátá gbáà ni Sátánì jẹ́ sí Jèhófà. Dípò kó máa tọ́ àwọn èèyàn sọ́nà, ńṣe ló ń tàn wọ́n jẹ. Irọ́ ló sì máa ń tàn kálẹ̀ kí ọwọ́ rẹ̀ bàa lè tẹ ohun tó fẹ́, ìyẹn láti mú àwọn èèyàn kúrò nínú ìjọsìn tòótọ́. Bí àpẹẹrẹ, Sátánì fẹ́ ká gbà gbọ́ pé Ọlọ́run ò fẹ́ sún mọ́ wa rárá àti pé gbogbo ìjìyà tó wà láyé ò kàn án rárá. Àmọ́, Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé Jèhófà bìkítà gan-an fáwọn ìṣẹ̀dá rẹ̀ àti pé ìwà ibi àti ìjìyà tó ń ṣẹlẹ̀ kò dùn mọ́ ọn nínú. (Ìṣe 17:24-30) Sátánì tún fẹ́ káwọn èèyàn gbà gbọ́ pé lílépa ohun tẹ̀mí jẹ́ fífi àkókò ṣòfò. Àmọ́ ọ̀ràn ò rí bẹ́ẹ̀, Ìwé Mímọ́ fi dá wa lójú pé “Ọlọ́run kì í ṣe aláìṣòdodo tí yóò fi gbàgbé iṣẹ́ yín àti ìfẹ́ tí ẹ fi hàn fún orúkọ rẹ̀.” Bákan náà ló tún sọ ní kedere pé “òun ni olùsẹ̀san fún àwọn tí ń fi taratara wá a.”—Hébérù 6:10; 11:6.

16. Kí nìdí táwọn Kristẹni fi gbọ́dọ̀ wà lójúfò kí wọ́n sì di òtítọ́ mú gírígírí?

16 Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé nípa Sátánì pé: “Ọlọ́run ètò àwọn nǹkan yìí ti fọ́ èrò inú àwọn aláìgbàgbọ́ lójú, kí ìmọ́lẹ̀ ìhìn rere ológo nípa Kristi, ẹni tí ó jẹ́ àwòrán Ọlọ́run, má bàa mọ́lẹ̀ wọlé.” (2 Kọ́ríńtì 4:4) Ọ̀rọ̀ àwọn kan ò yàtọ̀ sí ti Éfà, Sátánì Èṣù ti tàn wọ́n jẹ ráúráú. Ipasẹ̀ Ádámù làwọn mìíràn ń tẹ̀ lé, ẹni tí ẹnikẹ́ni ò tàn jẹ, tó jẹ́ pé òun fúnra rẹ̀ ló dìídì yàn láti ṣàìgbọràn. (Júúdà 5, 11) Nítorí náà, ó pọn dandan pé káwọn Kristẹni wà lójúfò kí wọ́n sì di òtítọ́ mú gírígírí.

Jèhófà Ń Béèrè “Ìgbàgbọ́ Láìsí Àgàbàgebè” Lọ́wọ́ Wa

17. Kí la gbọ́dọ̀ ṣe ká bàa lè rí ojú rere Jèhófà?

17 Nítorí pé Jèhófà jẹ́ olóòótọ́ ní gbogbo ọ̀nà rẹ̀, ó ń fẹ́ kí gbogbo àwọn tó ń jọ́sìn òun pẹ̀lú jẹ́ olóòótọ́. Onísáàmù náà kọ̀wé pé: “Jèhófà, ta ni yóò jẹ́ àlejò nínú àgọ́ rẹ? Ta ni yóò máa gbé ní òkè ńlá mímọ́ rẹ? Ẹni tí ń rìn láìlálèébù, tí ó sì ń fi òdodo ṣe ìwà hù tí ó sì ń sọ òtítọ́ nínú ọkàn-àyà rẹ̀.” (Sáàmù 15:1, 2) Ní ti àwọn Júù tí wọ́n kọ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyẹn lórin, tí wọ́n bá ti gbọ́ òkè ńlá mímọ́ Jèhófà báyìí Òkè Síónì ló máa ń wá sí wọn lọ́kàn, níbi tí Dáfídì Ọba kọ́ àgọ́ kan sí tó sì gbé àpótí májẹ̀mú sínú àgọ́ náà. (2 Sámúẹ́lì 6:12, 17) Òkè ńlá yìí àti àgọ́ náà ń múni rántí ibi tí Jèhófà ń gbé lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ. Àwọn èèyàn lè lọ sọ́dọ̀ Ọlọ́run níbẹ̀ láti bẹ̀bẹ̀ fun ojú rere rẹ̀.

18. (a) Kí lèèyàn gbọ́dọ̀ ṣe láti bá Ọlọ́run ṣọ̀rẹ́? (b) Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ tó kàn?

18 Ẹnikẹ́ni tó bá fẹ́ bá Jèhófà ṣọ̀rẹ́ gbọ́dọ̀ máa sọ òtítọ́ “nínú ọkàn rẹ̀,” kì í kàn án ṣe lórí ahọ́n lásán. Àwọn tó jẹ́ ọ̀rẹ́ Ọlọ́run lóòótọ́ gbọ́dọ̀ jẹ́ aláìlábòsí wọ́n sì gbọ́dọ̀ fi hàn pé àwọn ní “ìgbàgbọ́ láìsí àgàbàgebè,” nítorí pé látinú ọkàn ni ìṣòtítọ́ ti ń wá. (1 Tímótì 1:5; Mátíù 12:34, 35) Ọ̀rẹ́ Ọlọ́run kì í ṣe oníbékebèke kì í sì í hùwà ẹ̀tàn, nítorí “ẹni ẹ̀tàn ni Jèhófà ń ṣe họ́ọ̀ sí.” (Sáàmù 5:6) Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kárí ayé ń sapá gan-an láti jẹ́ olóòótọ́ ní ṣíṣàfarawé Ọlọ́run wọn. Àpilẹ̀kọ tó kàn máa jíròrò kókó yìí.

Báwo Lo Ṣe Máa Dáhùn?

• Kí nìdí tí Jèhófà fi mọ òtítọ́ nípa ohun gbogbo?

• Kí ló fi hàn pé olóòótọ́ ni Jèhófà?

• Báwo ni Jèhófà ṣe fi òtítọ́ hàn wá?

• Kí là ń béèrè lọ́wọ́ wa nípa òtítọ́?

[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]

Ọlọ́run òtítọ́ mọ tinú-tòde àwọn ohun tó dá

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 12, 13]

Àwọn ìlérí Jèhófà máa nímùúṣẹ