Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìjọsìn Tòótọ́ So Ìdílé Kan Pọ̀

Ìjọsìn Tòótọ́ So Ìdílé Kan Pọ̀

Ìjọsìn Tòótọ́ So Ìdílé Kan Pọ̀

ỌMỌ ọdún mẹ́tàlá ni Maria nígbà tóun àti àbúrò rẹ̀ obìnrin tó ń jẹ́ Lucy gbọ́ nípa Jèhófà látọ̀dọ̀ mọ̀lẹ́bí wọn kan. Ó tún ṣàlàyé fún wọn nípa ìrètí Párádísè orí ilẹ̀ ayé. Ohun tí wọ́n gbọ́ wù wọ́n gan-an wọ́n sì tẹ̀ lé e lọ sí Gbọ̀ngàn Ìjọba tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ń ṣèpàdé. Àwọn ìtọ́ni tó ṣe tààrà tí Maria gbọ́ níbẹ̀ wú u lórí gan-an ni. Ó yàtọ̀ pátápátá sí ṣọ́ọ̀ṣì tó máa ń lọ, tó jẹ́ pé kìkì orin ni wọ́n máa ń kọ! Kò pẹ́ táwọn ọmọ yìí fi bẹ̀rẹ̀ sí kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́dọ̀ ẹnì kan tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà.

Ẹ̀gbọ́n wọn ọkùnrin tó ń jẹ́ Hugo fẹ́ràn ìmọ̀ ọgbọ́n orí àti ẹ̀kọ́ ẹfolúṣọ̀n gan-an. Ó ní òun ò gbà pé Ọlọ́run wà. Àmọ́ nígbà tó wà lẹ́nu iṣẹ́ ológun, ó ka ìwé Life—How Did It Get Here? By Evolution or by Creation?  a Ó rí ìdáhùn sáwọn ìbéèrè tó jẹ́ pé kò sí ìsìn mìíràn tó lè dáhùn wọn. Nígbà tó parí iṣẹ́ ológun tó ń ṣe, ó bẹ̀rẹ̀ sí fún ìgbàgbọ́ tó ti ní nínú Ọlọ́run lókun nípa kíkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ó sì ǹ bá àwọn àbúrò rẹ̀ obìnrin lọ sí ìpàdé. Maria àti Lucy ṣèrìbọmi lọ́dún 1992, ìyẹn ọdún méjì lẹ́yìn tí wọ́n kọ́kọ́ gbọ́ òtítọ́ náà, ẹ̀gbọ́n wọn ọkùnrin sì ṣèrìbọmi ní ọdún méjì lẹ́yìn náà.

Ní gbogbo àkókò yìí, àwọn òbí wọn tí wọ́n jẹ́ ẹlẹ́sìn Kátólíìkì kò fi bẹ́ẹ̀ nífẹ̀ẹ́ sí òtítọ́ Bíbélì. Wọ́n ní àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń múnú bíni, bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n nífẹ̀ẹ́ sí ìwà ọmọlúàbí táwọn ọ̀dọ́ Ẹlẹ́rìí táwọn ọmọ wọn máa ń mú wálé ń hù àti bí ìmúra wọn ṣe wà níwọ̀ntúnwọ̀nsì. Bákan náà, táwọn ọmọ bá ń sọ àwọn nǹkan tí wọ́n kọ́ nípàdé nígbà tí wọ́n bá ń jẹun, èyí máa ń mú káwọn òbí náà fẹ́ mọ̀ sí i nípa ohun tí wọ́n ń sọ.

Àmọ́ ṣá, àti ìyá àti bàbá ló ṣì wà nínú ẹgbẹ́ òkùnkùn. Òkú ọ̀mùtí ni bàbá ó sì máa ń lu màmá. Ìdílé náà pàápàá ti fẹ́ tú ká. Bàbá tiẹ̀ lọ fi ẹ̀wọ̀n ọ̀sẹ̀ méjì gbára nítorí ìwàkiwà tó hù nígbà tó mutí yó. Nígbà tó wà lẹ́wọ̀n, ó bẹ̀rẹ̀ sí ka Bíbélì. Bó ṣe ń kà á, ó kíyè sí àwọn ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ nípa àmì ọjọ́ ìkẹyìn. Èyí mú kí onírúurú ìbéèrè bẹ̀rẹ̀ sí gbé bàbá àti màmá lọ́kàn, àwọn méjèèjì wá lọ sí Gbọ̀ngàn Ìjọba wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Nígbà tí wọ́n kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́, wọ́n kó gbogbo ìwé ẹgbẹ́ òkùnkùn tí wọ́n ní dànù, orúkọ Jèhófà tí wọ́n sì ń pè kò jẹ́ káwọn ẹ̀mí èṣù lè dà wọ́n láàmú mọ́. Ìyípadà ńláǹlà bẹ̀rẹ̀ sí hàn nínú ìwà wọn.

Ṣé ẹ rí i, béèyàn gẹṣin nínú Maria àti Lucy kò lè kọsẹ̀ lọ́jọ́ tí wọ́n ń wo bí Hugo ṣe ń ṣèrìbọmi fún bàbá àti màmá wọn ní àpéjọ àgbègbè kan tí wọ́n ṣe ní Bolivia lọ́dún 1999! Ọdún mẹ́sàn-án ti kọjá báyìí tí Maria àti Lucy kọ́kọ́ gbọ́ nípa Jèhófà àtàwọn ìlérí rẹ̀. Àwọn méjèèjì àti Hugo ń ṣe iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún báyìí. Inú wọn dùn gan-an pé ìjọsìn tòótọ́ ti so ìdílé wọn pọ̀!

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la tẹ̀ ẹ́ jáde.