Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ǹjẹ́ Ò Ń Wá Jèhófà Tọkàntọkàn?

Ǹjẹ́ Ò Ń Wá Jèhófà Tọkàntọkàn?

Ǹjẹ́ Ò Ń Wá Jèhófà Tọkàntọkàn?

ỌKÙNRIN kan tó jẹ́ Kristẹni fẹ́ sọ ìhìn rere tó wà nínú Bíbélì fún àwọn tí wọ́n jọ máa ń wọ ọkọ̀ ojú irin lọ síbi iṣẹ́. (Máàkù 13:10) Àmọ́ ìbẹ̀rù kì í jẹ́ kó lè ṣe bẹ́ẹ̀. Ṣé kò wá wàásù nínú ọkọ̀ ọ̀hún ni? Rárá o, ó gbàdúrà àtọkànwá lórí ọ̀ràn náà ó sì ṣiṣẹ́ lórí ọ̀nà tó yẹ kéèyàn máa gbà bẹ̀rẹ̀ ìjùmọ̀sọ̀rọ̀. Jèhófà Ọlọ́run dáhùn àdúrà ọ̀gbẹ́ni yìí ó sì fún un lókun láti wàásù.

Irú fífi gbogbo ọkàn ṣe nǹkan bẹ́ẹ̀ ṣe pàtàkì gan-an nígbà tá a bá ń wá Jèhófà àti ojú rere rẹ̀. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Ẹni tí ó bá ń tọ Ọlọ́run wá gbọ́dọ̀ gbà gbọ́ pé ó ń bẹ àti pé òun ni olùsẹ̀san fún àwọn tí ń fi taratara wá a.” (Hébérù 11:6) Kìkì wíwá Jèhófà nìkan kò tó. Lápá kan, ọ̀rọ̀ ìṣe Gíríìkì náà tá a tú sí “fi taratara wá” túmọ̀ sí ìsapá tá a fi gbogbo ara àti ọkàn ṣe. Èyí kan gbogbo èrò inú, ọkàn àti okun ẹni. Tá a bá ń wá Jèhófà tọkàntọkàn, a ò ní máa jókòó gẹlẹtẹ, a ò ní ṣe ìmẹ́lẹ́ tàbí ṣe ọ̀lẹ. Dípò ìyẹn, ńṣe là á máa fi taratara wá a.—Ìṣe 15:17.

Àwọn Tó Wá Jèhófà Tọkàntọkàn

Àpẹẹrẹ àwọn tó ti sapá gidigidi láti wá Jèhófà pọ̀ gan-an nínú Ìwé Mímọ́. Ọ̀kan lára wọn ni Jákọ́bù, tó wọ̀yá ìjà pẹ̀lú áńgẹ́lì Ọlọ́run títí ilẹ̀ fi mọ́. Ìdí rèé tá a fi sọ Jákọ́bù ní Ísírẹ́lì (Ẹni tó bá Ọlọ́run wọ̀jà) nítorí pé ó wọ̀jà pẹ̀lú Ọlọ́run, tàbí pé ó “lo ara rẹ̀.” Áńgẹ́lì náà bù kún un nítorí ìsapá tó fi gbogbo ọkàn ṣe.—Jẹ́nẹ́sísì 32:24-30.

Obìnrin ará Gálílì kan tún wà tá ò dárúkọ rẹ̀, tí àrùn ìṣàn ẹ̀jẹ̀ hàn léèmọ̀ fún odindi ọdún méjìlá, èyí sì ti fa “ọ̀pọ̀ ìrora” fún un. Kò gbọ́dọ̀ fara kan ẹlòmíràn nítorí ipò tó wà yìí. Síbẹ̀, ó ṣọkàn gírí láti lọ bá Jésù. Ó ń sọ pé: “Bí mo bá fọwọ́ kan ẹ̀wù àwọ̀lékè rẹ̀ lásán, ara mi yóò dá.” Fojú inú wo bí obìnrin yìí ṣe ń la àárín ‘ogunlọ́gọ̀ èrò tí wọ́n tẹ̀ lé [Jésù] kọjá, tí wọ́n sì ń há a gádígádí.’ Bó ṣe fọwọ́ kan ẹ̀wù àwọ̀lékè Jésù báyìí, ó rí i pé “ìsun ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ gbẹ fáú”—àìsàn tó ti ń bá a jà láti ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn ti lọ! Jìnnìjìnnì bò ó nígbà tí Jésù béèrè pé, “Ta ní fọwọ́ kan ẹ̀wù àwọ̀lékè mi?” Àmọ́ Jésù sọ fún un tìfẹ́tìfẹ́ pé: “Ọmọbìnrin, ìgbàgbọ́ rẹ ti mú ọ lára dá. Máa lọ ní àlàáfíà, kí o sì ní ìlera kúrò lọ́wọ́ àìsàn burúkú tí ń ṣe ọ́.” Ó rí ìbùkún gbà nítorí ìsapá rẹ̀.—Máàkù 5:24-34; Léfítíkù 15:25-27.

Lákòókò mìíràn, obìnrin kan tó jẹ́ ará Fòníṣíà bẹ Jésù títí pé kó dákun wo ọmọbìnrin òun sàn. Jésù dá a lóhùn pé kò dára kéèyàn gbé oúnjẹ ọmọ fún àwọn ajá kéékèèké jẹ. Ohun tó ní lọ́kàn ni pé òun kò lè fi àwọn Júù sílẹ̀ kóun wá máa gbọ́ tàwọn tí kì í ṣe ọmọ Ísírẹ́lì. Àkàwé náà yé obìnrin yìí, àmọ́ ńṣe ló bẹ̀rẹ̀ sí bẹ̀bẹ̀, ó ní: “Bẹ́ẹ̀ ni, Olúwa; ṣùgbọ́n àwọn ajá kéékèèké ní ti gidi máa ń jẹ nínú èérún tí ń jábọ́ láti orí tábìlì àwọn ọ̀gá wọn.” Ìgbàgbọ́ tó lágbára àti òótọ́ inú tí obìnrin yìí ní mú kí Jésù sọ pé: “Ìwọ obìnrin yìí, títóbi ni ìgbàgbọ́ rẹ; kí ó ṣẹlẹ̀ sí ọ gẹ́gẹ́ bí o ti fẹ́.”—Mátíù 15:22-28.

Kí ni ì bá ti ṣẹlẹ̀ sáwọn èèyàn wọ̀nyí ká ní wọn ò tẹpẹlẹ mọ́ ìsapá wọn ni? Ǹjẹ́ wọn ì bá rí ìbùkún gbà ká ní wọ́n ti juwọ́ sílẹ̀ nígbà tí wọ́n bá ìṣòro tàbí àtakò pàdé níbẹ̀rẹ̀? Rárá o! Àwọn àpẹẹrẹ wọ̀nyí jẹ́ ká lóye kókó tí Jésù fi kọ́ni dáadáa, ìyẹn ni pé kò sóhun tó burú nínú ‘títẹpẹlẹ mọ́ nǹkan láìṣojo,’ pé ó tiẹ̀ ṣe pàtàkì pàápàá téèyàn bá ń wá Jèhófà.—Lúùkù 11:5-13.

Ní Ìbámu Pẹ̀lú Ìfẹ́ Rẹ̀

Nínú àwọn àpẹẹrẹ tá a mẹ́nu bà lókè nípa àwọn tá a fi iṣẹ́ ìyanu wò sàn, ǹjẹ́ fífi gbogbo ọkàn sapá ni olórí ohun tó jẹ́ ká mú wọn lára dá? Rárá o, ńṣe ni ohun tí wọ́n béèrè fún wà níbàámu pẹ̀lú ìfẹ́ Ọlọ́run. A fún Jésù lágbára láti ṣiṣẹ́ ìyanu kó bà a lè fi ẹ̀rí tó dájú hàn pé òun ni Ọmọ Ọlọ́run, ìyẹn Mèsáyà náà tá a ṣèlérí. (Jòhánù 6:14; 9:33; Ìṣe 2:22) Síwájú sí i, àwọn iṣẹ́ ìyanu tí Jésù ṣe jẹ́ ìtọ́wò àwọn ìbùkún yàbùgà-yabuga tí Jèhófà máa fún ẹ̀dá èèyàn nígbà Ìṣàkóso Ẹgbẹ̀rúndún Kristi.—Ìṣípayá 21:4; 22:2.

Kì í ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run mọ́ pé káwọn tó ń ṣe ìsìn tòótọ́ ní agbára àtiṣe iṣẹ́ ìyanu, irú bí agbára láti múni lára dá àti láti máa fi èdè fọ̀. (1 Kọ́ríńtì 13:8, 13) Lára ohun tó fẹ́ ká ṣe lákòókò tiwa ni pé ká polongo ìhìn rere Ìjọba náà kárí gbogbo ayé kí ‘gbogbo onírúurú èèyàn bàa lè wá sí ìmọ̀ pípéye nípa òtítọ́.’ (1 Tímótì 2:4; Mátíù 24:14; 28:19, 20) Àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run lè fọkàn balẹ̀ pé ó máa dáhùn àdúrà wọn bí wọ́n bá sapá láti ṣe àwọn ohun tó bá ìfẹ́ rẹ̀ mú.

Àwọn kan lè máa ṣe kàyéfì pé: ‘Kí la wá ń ṣe làálàá fún nígbà tó jẹ́ pé ohun tí Ọlọ́run bá fẹ́ ló máa ṣẹ?’ Òótọ́ ni pé Jèhófà máa mú ète rẹ̀ ṣẹ láìka ìsapá yòówù kí ẹ̀dá èèyàn ṣe sí, àmọ́ ó fẹ́ káwọn èèyàn lọ́wọ́ nínú mímú ìfẹ́ rẹ̀ ṣẹ. A lè fi Jèhófà wé ọkùnrin kan tó ń kọ́ ilé. Kọ́lékọ́lé náà ní àwòrán bí ilé ọ̀hún ṣe máa rí tó bá kọ́ ọ tán, àmọ́ ohun tí wọ́n fi ń kọ́lé lágbègbè rẹ̀ ló máa fi kọ́ ilé náà. Lọ́nà kan náà, Jèhófà ní iṣẹ́ kan tó fẹ́ ṣe láṣeyanjú lónìí, ó sì tẹ́ ẹ lọ́rùn láti lo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, ìyẹn àwọn ti wọ́n fínnúfíndọ̀ yọ̀ǹda ara wọn.—Sáàmù 110:3; 1 Kọ́ríńtì 9:16, 17.

Gbé àpẹẹrẹ ọ̀dọ́mọkùnrin kan tó ń jẹ́ Toshio yẹ̀ wò. Nígbà tó wọ ilé ẹ̀kọ́ gíga, ó fẹ́ wàásù dé ibi tí àyè bá gbà á dé nílé ẹ̀kọ́ náà èyí tó kà sí ìpínlẹ̀ rẹ̀. Bíbélì rẹ̀ kì í yà á lẹ́sẹ̀ kan ó sì sapá gan-an láti jẹ́ Kristẹni àwòfiṣàpẹẹrẹ. Nígbà tí ọdún kìíní fẹ́rẹ̀ẹ́ parí, ó láǹfààní láti sọ̀rọ̀ níwájú àwọn ọmọ kíláàsì rẹ̀. Toshio gbàdúrà sí Jèhófà pé kó ran òun lọ́wọ́, inú rẹ̀ sì dùn nígbà tó rí bí gbogbo ọmọ kíláàsì ṣe pa lọ́lọ́ tí wọ́n sì ń fetí sí ọ̀rọ̀ tó ń bá wọn sọ èyí tó pe àkọlé rẹ̀ ní “Ìdí Tí Mo Fi Fi Iṣẹ́ Aṣáájú Ọ̀nà Ṣe Iṣẹ́ Ìgbésí Ayé Mi.” Ó ṣàlàyé pé òun fẹ́ di òjíṣẹ́ alákòókò kíkún ti àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ọ̀kan lára àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà gbà pé kó máa kọ́ òun lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ó sì tẹ̀ síwájú débi pé ó ṣèrìbọmi. A bù kún ìsapá tí Toshio ṣe níbàámu pẹ̀lú àdúrà rẹ̀.

Báwo Lo Ṣe Ń Fi Gbogbo Ọkàn Ṣe Nǹkan Tó?

Ọ̀pọ̀ ọ̀nà lo lè gbà fi hàn pé ò ń wá Jèhófà àtàwọn ìbùkún rẹ̀ tọkàntọkàn. Lákọ̀ọ́kọ́, àwọn ohun pàtàkì kan wà tó o gbọ́dọ̀ ṣe, bíi mímúra sílẹ̀ dáadáa fún àwọn ìpàdé Kristẹni. Tó o ba ń múra àwọn ìdáhùn rẹ sílẹ̀ dáadáa fún ìpàdé, tó o ń sọ àwọn àsọyé tó nítumọ̀ tó o sì ń ṣe àwọn àṣefihàn tó gbéṣẹ́, ńṣe lò ń fi hàn pé ò ń wá Jèhófà tọkàntọkàn. O tún lè fi hàn pé gbogbo ọkàn lo fi ń wá Jèhófà nípa mímú kí iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ túbọ̀ sunwọ̀n sí i. Ṣíṣe bí ọ̀rẹ́ nígbà tó o bá ń bá onílé sọ̀rọ̀ ńkọ́, kó o sì máa bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ lọ́nà tó gbéṣẹ́ tó sì bá ìpínlẹ̀ rẹ mu? (Kólósè 3:23) Tí ọkùnrin tó jẹ́ Kristẹni bá yọ̀ǹda ara rẹ̀ pátápátá, yóò lè tẹ́wọ́ gba ẹrù iṣẹ́ nínú ìjọ, irú bí sísìn gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ tàbí alàgbà. (1 Tímótì 3:1, 2, 12, 13) Nípa yíyọ̀ǹda ara rẹ, ìwọ náà lè nípìn-ín nínú ayọ̀ tó wà nínú fífúnni. Wàá lè yọ̀ǹda ara rẹ láti lọ́wọ́ nínú kíkọ́ ẹ̀ka iléeṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tàbí kó o lọ sìn níbẹ̀. Tó o bá jẹ́ àpọ́n tó tóótun, o lè lọ sí Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́, èyí tó máa ń sọ àwọn ọkùnrin tí wọ́n jẹ́ ẹni tẹ̀mí di olùṣọ́ àgùntàn rere. Tó o bá ti ṣègbéyàwó, iṣẹ́ míṣọ́nnárì lè jẹ́ ọ̀nà kan tó o lè gbà fi hàn pé tọkàntọkàn lo fi fẹ́ túbọ̀ sin Jèhófà sí i. Ó lè ṣeé ṣe fún ọ láti ṣí lọ sí ibi tá a ti nílò àwọn oníwàásù Ìjọba náà gan-an. —1 Kọ́ríńtì 16:9.

Ohun tó ṣe pàtàkì jù lọ ni irú ẹ̀mí tó o fi ń ṣe iṣẹ́ ìsìn rẹ. Ẹrù iṣẹ́ èyíkéyìí tá a bá yàn fún ọ, ṣe é tokuntokun, tọkàntọkàn àti pẹ̀lú ‘òtítọ́ ọkàn.’ (Ìṣe 2:46; Róòmù 12:8) Ka iṣẹ́ èyíkéyìí tá a bá yàn fún ọ sí àǹfààní kan láti fi hàn pé o fẹ́ fi ìyìn fún Jèhófà tọkàntọkàn. Máa gbàdúrà sí Jèhófà nígbà gbogbo pé kó ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o sì máa ṣe ohun tí agbára rẹ bá ká. Nípa bẹ́ẹ̀, èrè ńlá ló máa jẹ́ tìrẹ.

Èrè Tó Wà Nínú Fífi Gbogbo Ọkàn Ṣe Nǹkan

Ǹjẹ́ o rántí Kristẹni tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ níbẹ̀rẹ̀, tó gbàdúrà láti borí ẹ̀rù tó máa ń bà á nígbà tó bá fẹ́ wàásù fáwọn tí wọ́n jọ máa ń wọkọ̀ ojú irin lọ síbi iṣẹ́? Jèhófà bù kún un fún ohun rere tó wà lọ́kàn rẹ̀ yìí. Arákùnrin náà gbìyànjú láti máa bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò pẹ̀lú àwọn èèyàn lọ́nà tó rọrùn, ó sì ń múra àwọn kókó ọ̀rọ̀ lóríṣiríṣi sílẹ̀ láti fi bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò. Ó bẹ̀rẹ̀ sí lo Bíbélì lọ́nà tó gbéṣẹ́ láti wàásù fún ọkùnrin kan tó ń kọminú nípa àjọṣe ẹ̀dá èèyàn tó ti dojú rú. Bó ṣe ń bá ọ̀gbẹ́ni yìí sọ̀rọ̀ nínú ọkọ̀ ojú irin fún ọ̀pọ̀ ìgbà mú kó bẹ̀rẹ̀ sí i bá a ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Jèhófà bù kún un lóòótọ́ nítorí ìsapá tó fi gbogbo ọkàn ṣe!

O lè ṣe irú àṣeyọrí bẹ́ẹ̀ tó ò bá ń bá a lọ láti máa wá Jèhófà tọkàntọkàn. Tó o bá rọra ń fara dà á tó o sì ń fi gbogbo ọkàn rẹ sí ìgbòkègbodò Ìjọba Ọlọ́run tó o ń ṣe, Jèhófà yóò lò ọ́ lọ́nà tó bá ète rẹ̀ mu á sì rọ̀jò ìbùkún sórí rẹ.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]

Kí ni ì bá ti ṣẹlẹ̀ sí obìnrin yìí ká ní kò tẹra mọ́ ìsapá rẹ̀?

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 27]

Ǹjẹ́ o ń tẹra mọ́ bíbẹ Jèhófà pé kó bù kún ọ?

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 28]

Báwo lo ṣe lè fi hàn pé ò ń wá Jèhófà tọkàntọkàn?