Onínúure Ni
Onínúure Ni
ARÁKÙNRIN MILTON G. HENSCHEL, tó ti jẹ́ ọ̀kan lára Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà látọjọ́ pípẹ́, dágbére fáyé lọ́jọ́ Sátidé, March 22, 2003. Ẹni ọdún méjìlélọ́gọ́rin ni.
Ìgbà tí Milton Henschel wà lọ́dọ̀ọ́ ló ti di ọ̀kan lára àwọn òṣìṣẹ́ ní orílé iṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ó sì sìn tọkàntọkàn fún ohun tó lé ní ọgọ́ta ọdún. Kíá làwọn èèyàn mọ̀ ọ́n nítorí orí rẹ̀ pé, ó sì nífẹ̀ẹ́ iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba náà. Lọ́dún 1939, ó di akọ̀wé N. H. Knorr, tó jẹ́ alábòójútó ibi ìtẹ̀wé ti àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Brooklyn nígbà yẹn. Nígbà tí Arákùnrin Knorr bẹ̀rẹ̀ sí mú ipò iwájú láàárín àwa Ẹlẹ́rìí kárí ayé lọ́dún 1942, Arákùnrin Henschel ló fi ṣe igbákejì rẹ̀. Arákùnrin Henschel fẹ́ Lucille Bennett lọ́dún 1956. Lọ́jọ́ ayọ̀ àtọjọ́ ìṣòro, ńṣe làwọn méjèèjì jọ wà pa pọ̀.
Arákùnrin Henschel àti Arákùnrin Knorr jọ ń ṣiṣẹ́ ní ìfẹ̀gbẹ́kẹ̀gbẹ́ ni títí dìgbà tí Arákùnrin Knorr dolóògbé lọ́dún 1977. Ọ̀pọ̀ ìgbà ni Arákùnrin Knorr àti Arákùnrin Henschel ti jọ ṣe ìbẹ̀wò sáwọn orílẹ̀-èdè tí iye wọ́n lé ní àádọ́jọ, wọ́n ń bẹ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà wò káàkiri ayé wọ́n sì ń fún wọn níṣìírí àgàgà àwọn míṣọ́nnárì àtàwọn tó ń ṣiṣẹ́ láwọn ọ́fíìsì ẹ̀ka. Àwọn ìrìn àjò yìí máa ń tánni lókun nígbà mìíràn, kódà ó léwu pàápàá. Nígbà tí wọ́n ṣèbẹ̀wò sí àpéjọ àgbègbè kan ní Liberia lọ́dún 1963, wọ́n fojú Arákùnrin Henschel rí màbo nítorí inúnibíni tí wọ́n ṣe sí i pé kò bá wọn lọ́wọ́ nínú ayẹyẹ tó ń fi ìfẹ́ orílẹ̀-èdè ẹni hàn. a Èyí kò kó Arákùnrin Henschel láyà jẹ o, ó tún padà sí Liberia ní oṣù díẹ̀ lẹ́yìn náà láti lọ rí ààrẹ orílẹ̀-èdè náà kó sì bá a sọ̀rọ̀ láti jẹ́ káwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà níbẹ̀ lè ní òmìnira tó pọ̀ sí i láti máa jọ́sìn.
Ní ti kéèyàn bójú tó àwọn ìpèníjà tó le koko, a ń rántí Arákùnrin Henschel fún bó ṣe jẹ́ ẹni tí kì í dábàá ohun tí apá ò lè ká, tí kì í sọ pé ohunkóhun tóun bá ti sọ labẹ gé, tó sì máa ń fòye báni lò. Àwọn tí wọ́n jọ ń ṣiṣẹ́ mọrírì bó ṣe mọ ètò ṣe, tí kì í ṣe ju ara rẹ̀ lọ tó sì tún máa ń pani lẹ́rìn-ín. Ó máa ń rántí nǹkan lọ́nà tó kàmàmà, ó máa ń múnú àwọn míṣọ́nnárì dùn kárí ayé pẹ̀lú bó ṣe mọ orúkọ wọn sórí, ó máa ń gbìyànjú láti sọ gbólóhùn kan tàbí méjì lédè ibi táwọn míṣọ́nnárì náà wà àti bó ṣe máa ń fi ọ̀rọ̀ dárà tá a sì sọ ọ́ lọ́nà tó ń pani lẹ́rìn-ín.
Míkà 6:8 sọ fún wa pé Jèhófà Ọlọ́run fẹ́ ká “nífẹ̀ẹ́ inú rere.” A ò jẹ́ gbàgbé Milton Henschel fún àpẹẹrẹ tó fi lélẹ̀ nípa èyí. Pẹ̀lú bó ṣe ní ẹrù iṣẹ́ tó pọ̀, ó ṣì jẹ́ ẹni tó ṣeé sún mọ́, tó tutù níwà, ó sì jẹ́ onínúure. Ó sábàá máa ń sọ pé, “Tó o bá ń ṣiyèméjì, rántí pé ohun tó tọ́ ló yẹ kó o ṣe.” À ń ṣèdárò ikú arákùnrin olùfẹ́ ọ̀wọ́n yìí, àmọ́ inú wa dùn pé ó ṣe olóòótọ́ títí dópin, èrè rẹ̀ sì dájú ìyẹn “adé ìyè.”—Ìṣípayá 2:10.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Wo 1977 Yearbook of Jehovah’s Witnesses, ojú ìwé 171 sí 177.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 31]
M. G. Henschel àti N. H. Knorr
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 31]
Òun àti Lucille ìyàwó rẹ̀