Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Láwọn àgbègbè púpọ̀ kárí ayé, fífúnni lẹ́bùn nígbà ayẹyẹ ìgbéyàwó jẹ́ àṣà àdáyébá. Àwọn ìlànà Ìwé Mímọ́ wo ló yẹ ká gbé yẹ̀ wò tá a bá ń fúnni nírú ẹ̀bùn bẹ́ẹ̀ tàbí tá a bá ń gbà á?

Bíbélì kò lòdì sí fífúnni lẹ́bùn tó bá sáà ti jẹ́ pé ẹ̀mí tó dáa lèèyàn fi ṣe é tó sì tún jẹ́ lásìkò tó yẹ. Tó bá kan ọ̀ràn fífúnni lẹ́bùn, ńṣe ni Bíbélì gba gbogbo àwọn Kristẹni tòótọ́ níyànjú láti fara wé Jèhófà, nítorí pé Olùpèsè tó lawọ́ ni. (Jákọ́bù 1:17) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù rọ àwọn Kristẹni ẹlẹ́gbẹ́ rẹ̀ pé: “Ẹ má gbàgbé rere ṣíṣe àti ṣíṣe àjọpín àwọn nǹkan pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn, nítorí irú àwọn ẹbọ bẹ́ẹ̀ ni inú Ọlọ́run dùn sí jọjọ.” Nítorí náà, a rọ àwọn Kristẹni pé kí wọ́n jẹ́ ọ̀làwọ́.—Hébérù 13:16; Lúùkù 6:38.

Ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà àtàwọn orílẹ̀-èdè kan, àṣà táwọn kan tó fẹ́ ṣègbéyàwó ń tẹ̀ lé ni pé wọ́n á to àwọn ẹ̀bùn tí wọ́n fẹ́ sínú ìwé kan, wọ́n á wá pín ìwé náà fáwọn èèyàn. Àkọsílẹ̀ ẹ̀bùn ìgbéyàwó ni wọ́n ń pe ìwé yìí ní ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì. Bí wọ́n ṣe máa ń ṣe é ni pé àwọn tó fẹ́ ṣe ìgbéyàwó á lọ sí ilé ìtajà kan wọ́n á sì wo àwọn nǹkan tó wà lórí igbá. Lára ohun tí wọ́n rí nílé ìtajà yìí ni wọ́n á ti kọ àwọn nǹkan tí wọ́n fẹ́ sínú ìwé kan pé káwọn èèyàn rà fún wọn gẹ́gẹ́ bí ẹ̀bùn lọ́jọ́ ìgbéyàwó wọn. Láti lè mọ ibi tí wọ́n á ti ra àwọn ẹ̀bùn wọ̀nyí, wọ́n á kọ orúkọ ilé ìtajà náà sínú ìwé ìkésíni tí wọ́n á fi ránṣẹ́ sáwọn ẹbí àtàwọn ọ̀rẹ́. Ǹjẹ́ àṣà yìí tọ̀nà? Tá a bá kọ́kọ́ wo àṣà yìí, àá rí i pé ó máa jẹ́ kó rọrùn fún ẹni tó bá fẹ́ fún àwọn tó fẹ́ ṣègbéyàwó lẹ́bùn láti tètè mọ ibi tóun ti lè rí ẹ̀bùn náà rà láìfi àkókò ṣòfò. Bákan náà ni kò ní sí pé ẹni tí wọ́n fún lẹ́bùn náà tún ń dá àwọn ẹ̀bùn kan tí kò fẹ́ padà síbi tí wọ́n ti rà wọ́n.

Bóyá àwọn tó fẹ́ ṣègbéyàwó yóò tẹ̀ lé irú àṣà yìí tàbí wọn ò ní tẹ̀ lé e jẹ́ ohun tí olúkálukú yóò yàn fúnra rẹ̀. Àmọ́ ṣá, àwọn Kristẹni ní láti ṣọ́ra gan-an kí wọ́n sì yẹra fún ṣíṣe ohun tó lòdì sáwọn ìlànà Bíbélì. Bí àpẹẹrẹ, tó bá ṣẹlẹ̀ pé kìkì àwọn ẹ̀bùn olówó gọbọi làwọn tó fẹ́ ṣègbéyàwó kọ sílẹ̀ pé káwọn èèyàn rà fún àwọn ń kọ́? Tọ́ràn bá rí bẹ́ẹ̀, ó ṣeé ṣe káwọn tí kò rí já jẹ máà ní owó tó pọ̀ tó láti ra ẹ̀bùn kankan, tàbí kí wọ́n kúkú sọ pé dípò káwọn lọ kó ìtìjú bá ara àwọn nítorí ẹ̀bùn olówó pọ́ọ́kú táwọn á mú lọ, àwọn ò kúkú ní débi ìgbéyàwó náà. Obìnrin kan tó jẹ́ Kristẹni kọ̀wé pé: “Fífúnni lẹ́bùn ìgbéyàwó ti wá di ẹrù ìnira báyìí o. Mo máa ń gbìyànjú láti fún àwọn èèyàn lẹ́bùn, àmọ́ lẹ́nu ọjọ́ mẹ́ta yìí gbogbo ìdùnnú tí mo máa ń ní tẹ́lẹ̀ ti pòórá.” Ìbànújẹ́ gan-an ló máa jẹ́ tí ayẹyẹ ìgbéyàwó bá lọ di èyí tó ń kó ìrẹ̀wẹ̀sì báni!

Ká sọ̀rọ̀ síbi tọ́rọ̀ wà, kò bọ́gbọ́n mú káwọn tó fẹ́ fúnni lẹ́bùn máa ronú pé táwọn bá fẹ́ kí ẹ̀bùn àwọn jọjú, àwọn gbọ́dọ̀ rà á ní ilé ìtajà kan pàtó, tàbí pé iye owó rẹ̀ gbọ́dọ̀ pọ̀ tó iye kan pàtó. Ó ṣe tán Jésù Kristi sọ pé ohun tó ṣe pàtàkì lójú Ọlọ́run ni irú ẹ̀mí tí ẹni tó fẹ́ fúnni lẹ́bùn náà ní, kì í ṣe bí ẹ̀bùn náà ti níye lórí tó. (Lúùkù 21:1-4) Bákan náà, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé nípa ìtọrẹ àánú fún àwọn aláìní. Ó sọ pé: “Kí olúkúlùkù ṣe gan-an gẹ́gẹ́ bí ó ti pinnu nínú ọkàn-àyà rẹ̀, kì í ṣe pẹ̀lú ìlọ́tìkọ̀ tàbí lábẹ́ àfipáṣe, nítorí Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ olùfúnni ọlọ́yàyà.”—2 Kọ́ríńtì 9:7.

Gẹ́gẹ́ bó ti wà nínú Bíbélì, kò sóhun tó burú nínú káwọn èèyàn mọ̀ pé lágbájá báyìí ló mú ẹ̀bùn yìí wá, bóyá nípa kéèyàn kọ ìwé pélébé kan sínú ẹ̀bùn náà. Àmọ́ ṣá, láwọn ibì kan, àṣà wọn ni pé níbi tí wọ́n bá ti ń ṣe ayẹyẹ, wọ́n máa ń dárúkọ ẹni tó mú ẹ̀bùn wá kí gbogbo àwọn tó wà níbẹ̀ lè mọ̀. Irú àṣà yìí lè fa ìṣòro. Àwọn tó mú ẹ̀bùn wá lè máà fẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ kó má bàa di pé wọ́n ń pe àfiyèsí tí kò yẹ sí ara wọn. Ńṣe ni irú àwọn tí kò fẹ́ ká dárúkọ wọn yìí ń tẹ̀ lé ìlànà tó wà nínú Mátíù 6:3, níbi tí Jésù ti sọ pé: “Ṣùgbọ́n ìwọ, nígbà tí o bá ń fi àwọn ẹ̀bùn àánú fúnni, má ṣe jẹ́ kí ọwọ́ òsì rẹ mọ ohun tí ọwọ́ ọ̀tún rẹ ń ṣe.” Àwọn mìíràn gbà pé ọ̀ràn fífúnni lẹ́bùn jẹ́ ọ̀ràn ara ẹni tó gbọ́dọ̀ wà láàárín ẹni tó fúnni lẹ́bùn náà àti ẹni tá a fún. Kò tán síbẹ̀ o, dídárúkọ ẹni tó mú ẹ̀bùn wá fún àwọn tó wà níbi ayẹyẹ kan lè mú káwọn èèyàn bẹ̀rẹ̀ sí fi ẹ̀bùn wéra, èyí sì lè ‘ru ìdíje sókè.’ (Gálátíà 5:26) Àwọn Kristẹni kò ní fẹ́ kó ìtìjú bá ẹnikẹ́ni nípa pípe orúkọ àwọn tó mú ẹ̀bùn wá láàárín gbogbo èrò.—1 Pétérù 3:8.

Dájúdájú, tá a bá hùwà lọ́nà tó bá àwọn ìlànà inú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run mu, orísun ayọ̀ ni fífúnni ní ẹ̀bùn yóò máa jẹ́ lọ́jọ́kọ́jọ́.—Ìṣe 20:35.