Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ṣé ‘Ìsìn Tòótọ́’ Kan Ṣoṣo Ló Wà?

Ṣé ‘Ìsìn Tòótọ́’ Kan Ṣoṣo Ló Wà?

Ṣé ‘Ìsìn Tòótọ́’ Kan Ṣoṣo Ló Wà?

“BÓ ṢE jẹ́ pé Kristi kan ṣoṣo ló wà, bẹ́ẹ̀ náà ni ìjọ Kristi kò pé méjì, Ìyàwó kan ṣoṣo ni Kristi sì ní, ìyẹn: ‘Ìjọ Kátólíìkì tó ń tẹ̀ lé ipasẹ̀ àwọn àpọ́sítélì.’”—Dominus Iesus.

Bí kádínà ìjọ Kátólíìkì náà Joseph Ratzinger ṣe sọ nípa ohun tí ìjọ rẹ̀ fi ń kọ́ni nìyẹn pé ìsìn tòótọ́ kan ṣoṣo ló wà. Ó sọ pé ìsìn tòótọ́ yìí ni “Ìjọ kan ṣoṣo ti Kristi, ìyẹn Ìjọ Kátólíìkì.”

“Wọn Kì Í Ṣe Ìsìn Tòótọ́”

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Póòpù John Paul Kejì sọ pé ìwé Dominus Iesus kò ní “ọ̀rọ̀ ìgbéraga nínú, bẹ́ẹ̀ sì ni kò tàbùkù àwọn ẹ̀sìn mìíràn,” síbẹ̀ àwọn aṣáájú ẹ̀sìn Pùròtẹ́sítáǹtì kò fara mọ́ ohun tí ìwé náà sọ. Bí àpẹẹrẹ, ní June 2001, níbi Àpérò Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso Gíga Jù Lọ ti Ìjọ Presbyterian ní Belfast, lórílẹ̀-èdè Northern Ireland, òjíṣẹ́ kan sọ pé ìwé yìí jẹ́ iṣẹ́ ọwọ́ “ẹ̀ya kan tó lágbára gan-an nínú Ìjọ Kátólíìkì . . . àmọ́ tí ẹ̀rù wá ń bà nítorí òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ tí wọ́n fi lọ́lẹ̀ níbi àpérò Kejì ti Vatican.”

Robin Eames, tó jẹ́ Bíṣọ́ọ̀bù Ṣọ́ọ̀ṣì Ireland, sọ pé ó máa “dun òun gan-an tí ìwé náà bá máa jẹ́ káwọn èèyàn padà sórí èrò tí wọ́n ní tẹ́lẹ̀ ṣáájú Àpérò Kejì ti Vatican.” Nígbà tí Eames ń sọ̀rọ̀ nípa ohun tí wọ́n sọ níbi àpérò Vatican pé ìsìn èyíkéyìí tí kò bá ti fara mọ́ ìlànà Kátólíìkì “kì í ṣe Ìsìn tòótọ́,” ó sọ pé: “Lójú tèmi o, ọ̀rọ̀ àbùkù gbáà nìyẹn.”

Kí ló fà á tí wọ́n fi kọ ìwé Dominus Iesus? Ó dà bí ẹni pé inú àwọn Aṣáájú ẹ̀sìn Kátólíìkì kò dùn sí ohun táwọn kan pè ní ẹ̀kọ́ ẹ̀sìn-gbogbo-lọ̀nà. Gẹ́gẹ́ bí ìwé ìròyìn The Irish Times, ṣe sọ, “ẹ̀kọ́ gbogbo-ẹ̀sìn-ló-dára tó gbòde kan báyìí—èyí táwọn èèyàn ń sọ pé ẹ̀sìn kan kò sàn ju òmíràn lọ . . . ń bí Kádínà Ratzinger nínú gan-an.” Ó dà bí ẹni pé ẹ̀kọ́ yìí ló mú kó sọ pé ẹ̀sìn tòótọ́ kan ṣoṣo ló wà.

Ǹjẹ́ Irú Ẹ̀sìn Tó O Ń Ṣe Já Mọ́ Ohunkóhun?

Lójú àwọn kan, “ẹ̀kọ́ ẹ̀sìn-gbogbo-lọ́nà” tàbí “ẹ̀kọ́ gbogbo-ẹ̀sìn-ló-dára” mọ́gbọ́n dání ó sì wúni lórí ju èrò náà pé ẹ̀sìn tòótọ́ kan ṣoṣo ló wà. Lójú wọn, ohun tó wù mí kò wù ọ́ ló yẹ kí ọ̀ràn ẹ̀sìn jẹ́. Ohun tí wọ́n sọ nígbẹ̀yìngbẹ́yín ni pé ‘irú ẹ̀sìn yòówù kéèyàn máa ṣe kò já mọ́ ohunkóhun.’

Èyí lè dà bí èrò tí gbogbo gbòò tẹ́wọ́ gbà—bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀kan lára àwọn àbùkù tó ní ni pé ńṣe ló ń mú kí ìsìn pín yẹ́lẹyẹ̀lẹ, tí onírúurú ẹ̀sìn sì ń yọjú. Ọ̀pọ̀ èèyàn ló sì ti sọ pé ńṣe ni ọ̀ràn ẹ̀sìn tó ti wá di ‘irú wá ògìrì wá yìí wulẹ̀ jẹ́ ọ̀nà láti mú kí olúkúlùkù lo òmìnira tó ní.’ Àmọ́ gẹ́gẹ́ bí òǹkọ̀wé Steve Bruce ṣe sọ, ohun kan ṣoṣo tó ń tìdí “gbígba gbogbo ẹ̀sìn láyè” jáde kò ju “àìka ẹ̀sìn sí” lọ.—A House Divided: Protestantism, Schism, and Secularization.

Èrò wo ló wá tọ̀nà nígbà náà? Ṣé ìsìn tòótọ́ kan ṣoṣo ló wà? Ṣé Ìjọ Kátólíìkì sì ni ìsìn tòótọ́ kan ṣoṣo náà? Ǹjẹ́ Ọlọ́run tẹ́wọ́ gba àwọn ìsìn mìíràn? Níwọ̀n bí àwọn ìbéèrè wọ̀nyí ti kan àjọṣe wa pẹ̀lú Ẹlẹ́dàá, ó dájú pé ó ṣe pàtàkì láti mọ èrò rẹ̀ nípa ọ̀rọ̀ náà. Báwo la ó ṣe ṣe èyí? Nípa wíwo inú Bíbélì ni, Ọ̀rọ̀ tí Ọlọ́run mí sí. (Ìṣe 17:11; 2 Tímótì 3:16, 17) Ẹ jẹ́ ká gbé ohun tó sọ nípa ọ̀rọ̀ ìsìn tòótọ́ kan ṣoṣo yẹ̀ wò.

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 2]

ÀWÒRÁN Ẹ̀YÌN ÌWÉ: Mark Gibson/⁠Index Stock Photography