Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Gbẹ́kẹ̀ Lé Jèhófà Pátápátá Lákòókò Ìpọ́njú

Gbẹ́kẹ̀ Lé Jèhófà Pátápátá Lákòókò Ìpọ́njú

Gbẹ́kẹ̀ Lé Jèhófà Pátápátá Lákòókò Ìpọ́njú

“Ọlọ́run jẹ́ ibi ìsádi àti okun fún wa, ìrànlọ́wọ́ tí a lè rí tìrọ̀rùn-tìrọ̀rùn nígbà wàhálà.”—SÁÀMÙ 46:1.

1, 2. (a) Àpẹẹrẹ wo ló fi hàn pé fífẹnu lásán sọ pé a gbẹ́kẹ̀ lé Ọlọ́run kò tó? (b) Èé ṣe tá a fi ní láti ṣe ju wíwulẹ̀ sọ pé a gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà lọ?

 Ó RỌRÙN kéèyàn sọ pé òun gbẹ́kẹ̀ lé Ọlọ́run. Àmọ́ sísọ bẹ́ẹ̀ kò dà bíi ṣíṣe é. Bí àpẹẹrẹ, ó ti pẹ́ tí wọ́n ti ń kọ gbólóhùn náà “Ọlọ́run La Gbẹ́kẹ̀ Lé” sára owó bébà àti owó ẹyọ ti orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà. a Lọ́dún 1956, Ilé Ìgbìmọ̀ Aṣòfin ilẹ̀ Amẹ́ríkà ṣe òfin kan tí wọ́n fi sọ gbólóhùn yìí di ọ̀rọ̀ àkọmọ̀nà orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà. Àmọ́ ìyàlẹ́nu gbáà ló jẹ́ pé ọ̀pọ̀ èèyàn lórílẹ̀-èdè yẹn àti kárí ayé, ló gbẹ́kẹ̀ lé owó àti ọrọ̀ ju Ọlọ́run lọ.—Lúùkù 12:16-21.

2 Gẹ́gẹ́ bí Kristẹni tòótọ́, gbígbẹ́kẹ̀lé Jèhófà kọjá wíwulẹ̀ máa fẹnu lásán sọ ọ́ lọ. Bí “ìgbàgbọ́ láìsí àwọn iṣẹ́ ṣe jẹ́ òkú,” bẹ́ẹ̀ náà ló ṣe jẹ́ asán tá a bá kàn sọ pé a gbẹ́kẹ̀ lé Ọlọ́run àmọ́ tá ò hùwà níbàámu pẹ̀lú ohun tá a sọ. (Jákọ́bù 2:26) Nínú àpilẹ̀kọ tó ṣáájú, a kẹ́kọ̀ọ́ pé a ń fi hàn pé a gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà nípa gbígbàdúrà sí i, nípa jíjẹ́ kí Ọ̀rọ̀ rẹ̀ darí wa àti nípa wíwá ìtọ́sọ́nà nínú ètò àjọ rẹ̀. Wàyí o, ẹ jẹ́ ká ṣàyẹ̀wò bá a ṣe le ṣe àwọn nǹkan mẹ́ta wọ̀nyí nígbà tí ìpọ́njú bá dé.

Bí Iṣẹ́ Bá Bọ́ Lọ́wọ́ Ẹni Tàbí Pé Owó Táṣẹ́rẹ́ Ló Ń Wọlé

3. Àwọn ìṣòro nípa ọ̀ràn ìnáwó wo làwọn ìránṣẹ́ Jèhófà ń dojú kọ ní “àwọn àkókò lílekoko” tá a wà yìí, báwo la sì ṣe mọ̀ pé Ọlọ́run á ràn wá lọ́wọ́?

3 Ní “àwọn àkókò lílekoko” tá a wà yìí, àwọn ìṣòro tó ń kojú àwọn èèyàn ní ti ọ̀ràn ìnáwó ló ń kojú àwa náà tá a jẹ́ Kristẹni. (2 Tímótì 3:1) Iṣẹ́ lè bọ́ lọ́wọ́ wa láìròtẹ́lẹ̀. Tàbí kó máà sí ohun mìíràn tá a lè ṣe ju pé ká máa ṣiṣẹ́ fún ọ̀pọ̀ wákàtí kó sì jẹ́ pé owó táṣẹ́rẹ́ ni a óò máa gbà. Nírú àwọn ipò báwọ̀nyí, ó lè ṣòro fúnni gan-an láti ‘pèsè fún àwọn ará ilé ẹni.’ (1 Tímótì 5:8) Ǹjẹ́ Ọlọ́run tí í ṣe Ẹni Gíga Jù Lọ náà yóò ràn wá lọ́wọ́ nírú àwọn àkókò báwọ̀nyí? Ó dájú pé ó máa ṣe bẹ́ẹ̀! Lóòótọ́, kì í ṣe pé Jèhófà kò ní jẹ́ ká rí ìnira èyíkéyìí nínú ètò àwọn nǹkan yìí. Àmọ́ tá a bá gbẹ́kẹ̀ lé e, àwọn ọ̀rọ̀ inú Sáàmù 46:1 á ṣẹ sí wa lára pé: “Ọlọ́run jẹ́ ibi ìsádi àti okun fún wa, ìrànlọ́wọ́ tí a lè rí tìrọ̀rùn-tìrọ̀rùn nígbà wàhálà.” Nígbà náà, báwo la ṣe lè fi hàn pé a gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà pátápátá lákòókò tá a bá níṣòro tó jẹ mọ́ ọ̀ràn ìnáwó?

4. Kí la lè gbàdúrà fún tá a bá níṣòro tó jẹ mọ́ ọ̀ràn ìnáwó, báwo ni Jèhófà sì ṣe ń dáhùn irú àdúrà bẹ́ẹ̀?

4 Ọ̀nà kan tá a lè gbà fi hàn pé a gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà ni pé ká máa gbàdúrà sí i. Àmọ́ kí la lè gbàdúrà pé kí ó ṣe fún wa? Tóò, tá a bá níṣòro tó jẹ mọ́ ọ̀ràn ìnáwó, a lè nílò ọgbọ́n tó gbéṣẹ́ lákòókò yẹn ju ti ìgbàkigbà rí lọ. Nítorí náà, gbàdúrà sí Ọlọ́run pé kó fún ọ ní ọgbọ́n náà! Ọ̀rọ̀ Jèhófà mú un dá wa lójú pé: “Bí ẹnikẹ́ni nínú yín bá ṣaláìní ọgbọ́n, kí ó máa bá a nìṣó ní bíbéèrè lọ́wọ́ Ọlọ́run, nítorí òun a máa fi fún gbogbo ènìyàn pẹ̀lú ìwà ọ̀làwọ́ àti láìsí gíganni; a ó sì fi í fún un.” (Jákọ́bù 1:5) Bẹ́ẹ̀ ni o, bẹ Jèhófà pé kó fún ọ ní ọgbọ́n ìyẹn agbára láti lo ìmọ̀, òye àti ọgbọ́n inú lọ́nà tó dára kó o lè ṣe àwọn ìpinnu tó tọ́ kó o sì yan àwọn ohun tó yẹ. Baba wa onífẹ̀ẹ́ tí ń bẹ lọ́run ti mú un dá wa lójú pé òun á gbọ́ irú àdúrà bẹ́ẹ̀. Gbogbo ìgbà ló ṣe tán láti mú ọ̀nà àwọn tó fi gbogbo ọkàn wọn gbẹ́kẹ̀ lé e tọ́.—Sáàmù 65:2; Òwe 3:5, 6.

5, 6. (a) Kí nìdí tá a fi lè wonú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fún ìrànlọ́wọ́ láti kojú ìṣòro àtijẹ àtimu? (b) Kí la lè ṣe láti dín àníyàn kù nígbà tí iṣẹ́ bá bọ́ lọ́wọ́ wa?

5 Wíwá ìtọ́sọ́nà lọ sínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tún jẹ́ ọ̀nà mìíràn tá a lè gbà fi hàn pé a gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà. Àwọn ìránnilétí rẹ̀ tó wà nínú Bíbélì jẹ́ “aṣeégbẹ́kẹ̀lé gan-an.” (Sáàmù 93:5) Òótọ́ ni pé ó ti lé ní ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀wá (1,900) ọdún sẹ́yìn tí wọ́n kọ ìwé yìí, síbẹ̀ ìwé tí Ọlọ́run mí sí yìí ní àwọn ìmọ̀ràn tó ṣe é gbíyè lé nínú ó sì ní òye tó jinlẹ̀ tó lè ràn wá lọ́wọ́ láti kojú ìṣòro àtijẹ àtimu. Gbé àpẹẹrẹ bíi mélòó kan yẹ̀ wò nípa ọgbọ́n tó wà nínú Bíbélì.

6 Sólómọ́nì ọlọgbọ́n Ọba sọ láyé ọjọ́un pé: “Dídùn ni oorun ẹni tí ń ṣiṣẹ́ sìn, ì báà jẹ́ oúnjẹ díẹ̀ tàbí púpọ̀ ni ó jẹ; ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ tí ó jẹ́ ti ọlọ́rọ̀ kì í jẹ́ kí ó sùn.” (Oníwàásù 5:12) Ó máa ń gba àkókò àti owó láti tún àwọn nǹkan ìní wa ṣe, láti mú kí wọ́n wà ní mímọ́ tónítóní, láti bójú tó wọn ká sì dáàbò bò wọ́n. Nítorí náà, tí iṣẹ́ bá bọ́ lọ́wọ́ wa, a lè lo àkókò náà láti ṣàyẹ̀wò àwọn ohun ìní wa àti bá a ṣe ń gbé ìgbésí ayé wa, ká mọ àwọn ohun tá a nílò ní ti gidi àtàwọn ohun tí kò pọn dandan. Ó lè jẹ́ ohun tó bọ́gbọ́n mu ni pé ká ṣe àwọn àyípadà kan láti lè dín àníyàn kù. Bí àpẹẹrẹ, ṣé a lè dín bá a ṣe ń náwó kù, bóyá ká kó lọ sí ilé tí owó rẹ̀ kó tó ti èyí tá a ń gbé tẹ́lẹ̀ tàbí ká wá nǹkan ṣe sáwọn dúkìá tí kò pọn dandan?—Mátíù 6:22.

7, 8. (a) Báwo ni Jésù ṣe fi hàn pé òun mọ̀ pé ẹ̀dá aláìpé máa ń ṣe àníyàn àṣejù nípa àwọn nǹkan tara? (Tún wo àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé.) (b) Ìmọ̀ràn ọlọ́gbọ́n wo ni Jésù fúnni nípa bá a ṣe lè yẹra fún àníyàn tí kò yẹ?

7 Nínú Ìwàásù tí Jésù ṣe lórí Òkè, ó fúnni nímọ̀ràn pé: “Ẹ dẹ́kun ṣíṣàníyàn nípa ọkàn yín, ní ti ohun tí ẹ ó jẹ tàbí ohun tí ẹ ó mu, tàbí nípa ara yín, ní ti ohun tí ẹ ó wọ̀.” b (Mátíù 6:25) Jésù mọ̀ pé ohun tó sábàá máa ń jẹ àwọn ẹ̀dá aláìpé lọ́kàn ni bí wọ́n ṣe máa rí àwọn ohun kòṣeémáàní. Nígbà náà, báwo la ṣe lè “dẹ́kun ṣíṣàníyàn” nípa àwọn nǹkan wọ̀nyí? Jésù sọ pé “Ẹ máa bá a nìṣó . . . ní wíwá ìjọba náà . . . lákọ̀ọ́kọ́.” Ìṣòro èyíkéyìí tó wù ká kojú, a gbọ́dọ̀ máa bá a lọ ní fífi ìjọsìn Jèhófà sí ipò kìíní nínú ìgbésí ayé wa. Tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, gbogbo ohun tá a nílò lójoojúmọ́ ni Baba wa ọ̀run á “fi kún un” fún wa. Lọ́nà kan ṣáá, ó máa pèsè ohun tá a nílò fún wa.—Mátíù 6:33.

8 Jésù tún fúnni nímọ̀ràn síwájú sí i pé: “Ẹ má ṣàníyàn láé nípa ọ̀la, nítorí ọ̀la yóò ní àwọn àníyàn tirẹ̀.” (Mátíù 6:34) Kò bọ́gbọ́n mu kéèyàn máa ṣe àníyàn àṣejù nípa ohun tó ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú. Ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ kan sọ pé: “Ohun tá a máa ń bẹ̀rù nípa ọjọ́ iwájú kì í sábàá ṣẹlẹ̀.” Fífi ìmọ̀ràn Bíbélì sílò èyí tó sọ pé kìkì àwọn ohun tó ṣe pàtàkì jù lọ ni ká máa dáwọ́ lé àti lílo ọjọ́ kọ̀ọ̀kan bó bá ṣe gbà lè mú ká yẹra fún àníyàn tí kò yẹ.—1 Pétérù 5:6, 7.

9. Bí ìṣòro tó jẹ mọ́ ọ̀ràn ìnáwó bá dé, àwọn ìrànlọ́wọ́ wo la lè rí nínú àwọn ìtẹ̀jáde “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” náà?

9 Bí ìṣòro tó jẹ mọ́ ọ̀ràn ìnáwó bá dìde, a tún lè fi hàn pé a gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà nípa wíwá ìrànlọ́wọ́ lọ sínú àwọn ìtẹ̀jáde “ẹrú olóòótọ́ àti olóye.” (Mátíù 24:45) Látìgbàdégbà ni ìwé ìròyìn Jí! máa ń ní àwọn àpilẹ̀kọ kan tó dá lórí àwọn ìmọ̀ràn àti àbá lórí bí a ṣe lè kojú ìṣòro tó jẹ mọ́ ọ̀ràn ìnáwó. Àpilẹ̀kọ náà “Àìníṣẹ́lọ́wọ́—Ki Ni Awọn Ojútùú Rẹ̀?” tó wà nínú ìtẹ̀jáde January 8, 1992, sọ ìlànà mẹ́jọ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tó ti ran àwọn tí iṣẹ́ bọ́ lọ́wọ́ wọn lọ́wọ́ láti rọ́gbọ́n dá sọ́ràn àtijẹ àtimú tí wọn kò sì jẹ́ kí ìbànújẹ́ dorí wọn kodò. c Àmọ́ ṣá o, a gbọ́dọ̀ lo àwọn ìlànà wọ̀nyí lọ́nà tó yẹ ká bàa lè ní èrò tó tọ́ nípa ìjẹ́pàtàkì owó. Èyí la jíròrò nínú àpilẹ̀kọ náà “Ohun kan tí ó Ṣe Pataki Ju Owó Lọ,” tó wà nínú ìtẹ̀jáde tá a sọ lókè yìí.—Oníwàásù 7:12.

Bí Àìsàn Bá Ń Pọ́n Ọ Lójú

10. Báwo ni àpẹẹrẹ Dáfídì Ọba ṣe fi hàn pé ó bọ́gbọ́n mu láti gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà nígbà tí àìsàn líle bá kọlu ni?

10 Ǹjẹ́ ó bọ́gbọ́n mu kéèyàn gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà nígbà tí àìsàn lílé bá kọ luni? Ó yẹ bẹ́ẹ̀ o! Jèhófà máa ń káàánú àwọn tí àìsàn ń ṣe lára àwọn èèyàn rẹ̀. Síwájú sí i, ó múra tán láti ràn wọ́n lọ́wọ́. Àpẹẹrẹ kan ni ti Dáfídì Ọba. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ìgbà tó wà nínú àìsàn líle ló kọ̀wé nípa bí Ọlọ́run ṣe ń bójú tó adúróṣinṣin tó ń ṣàìsàn. Ó sọ pé: “Jèhófà tìkára rẹ̀ yóò gbé e ró lórí àga ìnàyìn ti àmódi; gbogbo ibùsùn rẹ̀ ni ìwọ yóò yí padà dájúdájú nígbà àìsàn rẹ̀.” (Sáàmù 41:1, 3, 7, 8) Dáfídì gbẹ́kẹ̀ lé Ọlọ́run gan-an, nígbà tó sì ṣe ara ọba yìí yá. Báwo làwa náà ṣe lè gbẹ́kẹ̀ lé Ọlọ́run nígbà tí àìsàn bá kọlù wá?

11. Kí la lè béèrè lọ́wọ́ Baba wa ọ̀run bí àìsàn bá gbé wa dè?

11 Bí àìsàn bá gbé wa dè, ọ̀nà kan tá a lè gbà fi hàn pé a gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà ni pé ká gbàdúrà ẹ̀bẹ̀ sí i pé kó ràn wá lọ́wọ́ ká lè fara dà á. A lè bẹ̀ ẹ́ pé kó ràn wá lọ́wọ́ láti lo “ọgbọ́n tí ó gbéṣẹ́” ká lè ní ìlera dé ibi tó bá ṣeé ṣe. (Òwe 3:21) A tún lè sọ fún un pé kó fún wa ní ẹ̀mí sùúrù àti ìfaradà láti lè mú àìsàn náà mọ́ra. Ju gbogbo rẹ̀ lọ, àá bẹ Jèhófà pé kó mú ẹsẹ̀ wa dúró, kó fún wa ní okun ká bàa lè jẹ́ olóòótọ́ sí i ká má sì jẹ́ kí ohunkóhun tó wù kó ṣẹlẹ̀ jin ìgbàgbọ́ wa lẹ́sẹ̀. (Fílípì 4:13) Jíjẹ́ olóòótọ́ sí Ọlọ́run tiẹ̀ ṣe pàtàkì ju pípa ìwàláàyè wa mọ́ nísinsìnyí pàápàá. Tá a bá pa ìwà títọ́ wa mọ́, Atóbilọ́lá Olùsẹ̀san náà á fún wa ní ìwàláàyè àti ìlera tó jí pépé títí láé.—Hébérù 11:6.

12. Àwọn ìlànà Ìwé Mímọ́ wo ló lè mú ká ṣe ìpinnu tó mọ́gbọ́n dáni nígbà tó bá kan ọ̀ràn gbígba ìtọ́jú?

12 Ìgbẹ́kẹ̀lé wa nínú Jèhófà á tún mú ká wá ìtọ́sọ́nà tó gbéṣẹ́ lọ sínú Bíbélì tí í ṣe Ọ̀rọ̀ rẹ̀. Àwọn ìlànà tó wà nínú Ìwé Mímọ́ lè ràn wá lọ́wọ́ láti ṣe àwọn ìpinnu tó tọ́ lórí ọ̀ràn ìtọ́jú tá a máa gbà tá a bá ń ṣàìsàn. Bí àpẹẹrẹ, níwọ̀n bá a ti mọ̀ pé Bíbélì ka “bíbá ẹ̀mí lò” léèwọ̀, a óò yẹra fún gbígba ìtọ́jú tàbí àwọn ètò ìṣègùn tó ní ìbẹ́mìílò nínú. (Gálátíà 5:19-21; Diutarónómì 18:10-12) Àpẹẹrẹ mìíràn rèé nípa ọgbọ́n tó ṣeé gbíyè lé tó wà nínú Bíbélì, ó sọ pé: “Ẹnikẹ́ni tí ó jẹ́ aláìní ìrírí ń ní ìgbàgbọ́ nínú gbogbo ọ̀rọ̀, ṣùgbọ́n afọgbọ́nhùwà máa ń ronú nípa àwọn ìṣísẹ̀ ara rẹ̀.” (Òwe 14:15) Nítorí náà, tá a bá ń ronú nípa irú ìtọ́jú tá a máa gbà, ohun tó dára jù lọ ni pé ká wá àwọn ìsọfúnni tó jẹ́ ojúlówó dípò ká máa “ní ìgbàgbọ́ nínú gbogbo ọ̀rọ̀.” Irú “ìyèkooro èrò inú” bẹ́ẹ̀ lè jẹ́ ká ṣàyẹ̀wò àwọn ìtọ́jú tó wà lárọ̀ọ́wọ́tó ká sì ṣe ìpinnu tó mọ́gbọ́n dání.—Títù 2:12.

13, 14. (a) Àwọn àpilẹ̀kọ wo ni a ti kọ sínú ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí! nípa ọ̀ràn ìlera? (Wo àpótí tó wà lójú ìwé 17.) (b) Ìmọ̀ràn wo ló wà nínú Jí! February 8, 2001 nípa bá a ṣe lè kojú àìsàn líle?

13 A tún lè fi hàn pé a gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà nípa ṣíṣàyẹ̀wò àwọn ìtẹ̀jáde ẹrú olóòótọ́ náà. Ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí! ti gbé àwọn àpilẹ̀kọ tó kún fún ẹ̀kọ́ jáde lórí onírúurú àìlera àtàwọn àrùn lóríṣiríṣi. d Nígbà mìíràn, àwọn ìwé ìròyìn ti sọ̀rọ̀ nípa ìrírí àwọn èèyàn kan tí wọ́n ti kojú onírúurú àìlera àti àìsàn. Bákan náà, àwọn àpilẹ̀kọ kan wà tí wọ́n sọ̀rọ̀ nípa àwọn àbá tá a gbé karí Ìwé Mímọ́ àtàwọn ìmọ̀ràn tó gbéṣẹ́ lórí béèyàn ṣe lè fara da àwọn àìsàn líle koko.

14 Bí àpẹẹrẹ, ìtẹ̀jáde Jí! ti February 8, 2001, ní ọ̀wọ́ àwọn àpilẹ̀kọ kan nínú èyí tó dá lórí béèyàn ṣe lè kojú àìsàn tí ń ṣeni. Àwọn àpilẹ̀kọ náà sọ àwọn ìlànà Bíbélì tó lè ranni lọ́wọ́ fún wa. Wọ́n tún ni àwọn ìsọfúnni tó ṣeé gbára lé tí a gbọ́ látẹnu àwọn kan tí àìsàn tí ń sọni di aláàbọ̀ ara ti ń bá jà látọjọ́ pípẹ́. Àpilẹ̀kọ náà “Báwo Lo Ṣe Lè Fara Da Àmódi Tí Ń Ṣe Ọ́?” fúnni láwọn ìmọ̀ràn wọ̀nyí: Mọ gbogbo ohun tó o bá lè mọ̀ nípa àìsàn tó ń ṣe ọ́. (Òwe 24:5) Gbé àwọn góńgó tó bọ́gbọ́n mu tí ọwọ́ sì lè tẹ̀ kalẹ̀, èyí kan níní i lọ́kàn láti ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́, àmọ́ rántí pé ọwọ́ rẹ lè má tẹ irú góńgó kan náà bíi tàwọn ẹlòmíràn o. (Ìṣe 20:35; Gálátíà 6:4) Má ṣe ya ara rẹ láṣo. (Òwe 18:1) Jẹ́ kínú àwọn èèyàn dùn nígbà tí wọ́n bá wá kí ọ. (Òwe 17:22) Ju gbogbo rẹ̀ lọ, ní àjọṣe tó ṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Jèhófà àti pẹ̀lú àwọn ará inú ìjọ. (Náhúmù 1:7; Róòmù 1:11, 12) Ǹjẹ́ inú wa kò dùn sí ìlànà tó ṣeé gbíyè lé tí Jèhófà ń pèsè nípasẹ̀ ètò àjọ rẹ̀?

Bí Ìwà Kan Tó Kù Díẹ̀ Káàtó Kò Bá Ṣe É Fi Sílẹ̀ Bọ̀rọ̀

15. Báwo ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣe borí ìjàkadì to bá ara aláìpé jà, ìdánilójú wo la sì lè ní?

15 Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Nínú ẹran ara mi, kò sí ohun rere tí ń gbé ibẹ̀.” (Róòmù 7:18) Ìrírí Pọ́ọ̀lù fúnra rẹ̀ jẹ́ kó mọ̀ pé ó ṣòro gan-an láti borí àwọn ìwà tó kù díẹ̀ káàtó àtàwọn ohun tí ara àìpé máa ń fẹ́. Síbẹ̀, ó dá Pọ́ọ̀lù lójú pé òun lè borí. (1 Kọ́ríńtì 9:26, 27) Báwo ló ṣe fẹ́ ṣe é? Nípa gbígbẹ́kẹ̀lé Jèhófà pátápátá. Ìdí nìyẹn tí Pọ́ọ̀lù fi sọ pé: “Èmi abòṣì ènìyàn! Ta ni yóò gbà mí lọ́wọ́ ara tí ń kú ikú yìí? Ọpẹ́ ni fún Ọlọ́run nípasẹ̀ Jésù Kristi Olúwa wa!” (Róòmù 7:24, 25) Àwa náà ńkọ́? Àwa náà gbọ́dọ̀ jìjàkadì láti borí àwọn kùdìẹ̀-kudiẹ ti ara. Bá a ṣe ń sapá láti borí irú àwọn kùdìẹ̀-kudiẹ wọ̀nyí, ó rọrùn gan-an láti juwọ́ sílẹ̀, ká máa sọ pé a ò lè borí wọn láé. Àmọ́ Jèhófà á ràn wá lọ́wọ́ tá a bá gbọ́kàn lé E bí i ti Pọ́ọ̀lù, tá ò gbọ́kàn lé kìkì agbára tiwa fúnra wa.

16. Kí la gbọ́dọ̀ gbàdúrà fún bí ìwà àìpé ẹ̀dá kan kò bá ṣeé fi sílẹ̀ bọ̀rọ̀, kí la sì gbọ́dọ̀ ṣe tá a bá tún hu ìwà tá a ti fi sílẹ̀ tẹ́lẹ̀?

16 Bí ìwà kan tó kù díẹ̀ káàtó kò bá ṣeé fi sílẹ̀ bọ̀rọ̀, a lè fi hàn pé a gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà nípa gbígbàdúrà sí I. A ní láti béèrè, kódà ká bẹ̀bẹ̀ pé kí Jèhófà fi ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ ràn wá lọ́wọ́. (Lúùkù 11:9-13) A lè dìídì béèrè pé kó fún wa ní ìkóra-ẹni-níjàánu, tí í ṣe ọ̀kan lára èso ẹ̀mí ti Ọlọ́run. (Gálátíà 5:22, 23) Kí la lè ṣe tó bá ṣẹlẹ̀ pé a tún padà hu ìwà kan tó kù díẹ̀ káàtó tá a ti fi sílẹ̀ tẹ́lẹ̀? A ò gbọ́dọ̀ jẹ́ kó sú wa láé. Ká má ṣe ṣíwọ́ gbígbàdúrà tìrẹ̀lẹ̀tìrẹ̀lẹ̀ sí Ọlọ́run wa aláàánú, ká bẹ̀ ẹ́ pé kó dárí jì wá kó sì ràn wá lọ́wọ́. Jèhófà kò jẹ́ kọ ẹni tó ní “ìròbìnújẹ́” nítorí ẹ̀rí ọkàn rẹ̀ tó ń dá a lẹ́bi sílẹ̀ láé. (Sáàmù 51:17) Tá a bá gbàdúrà sí Jèhófà tọkàntọkàn, tá a ronú pìwà dà, ó máa ràn wá lọ́wọ́ láti borí àdánwò.—Fílípì 4:6, 7.

17. (a) Kí nìdí tó fi dára ká ronú lórí irú ojú tí Jèhófà fi ń wo àìlera tá a fẹ́ borí? (b) Àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ wo la lè há sórí tá a bá fẹ́ borí títètè bínú? tá a bá fẹ́ ṣàkóso ahọ́n wa? tá a bá fẹ́ borí nínífẹ̀ẹ́ sí àwọn eré ìnàjú tí kò bójú mu?

17 A tún lè fi hàn pé a gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà tá a bá ń wá ìrànlọ́wọ́ lọ sínú Ọ̀rọ̀ rẹ̀. A lè lo atọ́ka Bíbélì tàbí Watch Tower Publications Index, ká fi wá ìdáhùn sáwọn ìbéèrè bí, ‘Irú ojú wo ni Jèhófà fi ń wo ìwà tó kù díẹ̀ káàtó tí mò ń bá jìjàkadì yìí?’ Ríronú nípa irú ojú tí Jèhófà fi ń wo ọ̀ràn náà yóò fún wa lókun láti túbọ̀ fẹ́ ṣe ohun tó wù ú. Nítorí náà, bí nǹkan ṣe ń rí lára rẹ̀ ló ṣe ń rí lára àwa náà, ká bẹ̀rẹ̀ sí kórìíra ohun tó kórìíra. (Sáàmù 97:10) Ohun tó ran àwọn kan lọ́wọ́ ni pé wọ́n há àwọn ẹsẹ Bíbélì kan sórí èyí tó sọ̀rọ̀ nípa ìwà tí wọ́n fẹ́ borí. Ṣé a ń sapá láti borí inú tó tètè máa ń bí wa ni? Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, a lè há àwọn ẹsẹ Bíbélì kan sórí, irú bí Òwe 14:17 àti Éfésù 4:31. Ṣé ó ṣòro láti ṣàkóso ahọ́n wa ni? A lè há àwọn ẹsẹ Bíbélì bí Òwe 12:18 àti Éfésù 4:29 sórí. Ṣé eré ìnàjú tí kò bójú mu ló máa ń wù wá? A lè sapá láti máa rántí àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ bíi Éfésù 5:3 àti Kólósè 3:5.

18. Èé ṣe tá ò fi gbọ́dọ̀ tijú láti lọ sọ́dọ̀ àwọn alàgbà fún ìrànlọ́wọ́ láti borí ìwà tó kù díẹ̀ káàtó tá a ń hù?

18 Wíwá ìrànlọ́wọ́ lọ sọ́dọ̀ àwọn alàgbà tí ẹ̀mí mímọ́ yàn sípò nínú ìjọ tún jẹ́ ọ̀nà mìíràn tá a lè gbà fi hàn pé a gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà. (Ìṣe 20:28) Ó ṣe tán àwọn “ẹ̀bùn tí ó jẹ́ ènìyàn” wọ̀nyí jẹ́ ètò tí Jèhófà ṣe nípasẹ̀ Kristi láti dáàbò bo àwọn àgùntàn rẹ̀ àti láti máa bójú tó wọn. (Éfésù 4:7, 8, 11-14) Lóòótọ́, ó lè ṣòro fún wa láti lọ bá ẹnì kan pé kó ràn wá lọ́wọ́ nígbà tá a bá ń jìjàkadì láti borí ìwà kan tó kù díẹ̀ káàtó. Ojú lè máa tì wá, ká máa bẹ̀rù pé àwọn alàgbà náà lè máa fojú yẹpẹrẹ wò wá. Àmọ́, ó dájú pé ńṣe làwọn arákùnrin tó dàgbà nípa tẹ̀mí yìí á yìn wá fún wíwá tá a wá bá wọn pé kí wọ́n ràn wá lọ́wọ́. Síwájú sí i, àwọn alàgbà ń sapá láti lo ànímọ́ Jèhófà ní ọ̀nà tí wọ́n gbà ń bá agbo lò. Ìmọ̀ràn àti ìtọ́ni wọn tó ń tuni nínú tó sì gbéṣẹ́, tó wá látinú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lè jẹ́ gbogbo ohun tá a nílò láti borí ìwà tó kù díẹ̀ káàtó tá a ń hù.—Jákọ́bù 5:14-16.

19. (a) Ọ̀nà wo ni Sátánì gbà ń lo àwọn ohun asán inú ìgbésí ayé ti ètò nǹkan ìsinsìnyí? (b) Kí ni níní ìgbẹ́kẹ̀lé túmọ̀ sí, kí ló sì yẹ kó jẹ́ ìpinnu wa?

19 Má ṣe gbàgbé pé Sátánì mọ̀ pé àkókò díẹ̀ ló kù fún òun. (Ìṣípayá 12:12) Ó fẹ́ fi àwọn ohun asán inú ìgbésí ayé kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá wa kó sì mú ká juwọ́ sílẹ̀. Ẹ jẹ́ kí á ní ìgbọ́kànlé kíkún nínú ohun tó wà ní Róòmù 8:35-39, èyí tó sọ pé: “Ta ni yóò yà wá kúrò nínú ìfẹ́ Kristi? Ṣé ìpọ́njú ni tàbí wàhálà tàbí inúnibíni tàbí ebi tàbí ìhòòhò tàbí ewu tàbí idà? . . . Kàkà bẹ́ẹ̀, nínú gbogbo nǹkan wọ̀nyí, àwa ń di ajagunmólú pátápátá nípasẹ̀ ẹni tí ó nífẹ̀ẹ́ wa. Nítorí mo gbà gbọ́ dájú pé kì í ṣe ikú tàbí ìyè tàbí àwọn áńgẹ́lì tàbí àwọn ìjọba tàbí àwọn ohun tí ó wà níhìn-ín nísinsìnyí tàbí àwọn ohun tí ń bọ̀ tàbí àwọn agbára tàbí ibi gíga tàbí ibi jíjìn tàbí ìṣẹ̀dá èyíkéyìí mìíràn ni yóò lè yà wá kúrò nínú ìfẹ́ Ọlọ́run tí ó wà nínú Kristi Jésù Olúwa wa.” Ẹ ò rí i pé ọ̀rọ̀ ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Jèhófà gan-an lèyí jẹ́! Àmọ́ irú ìgbẹ́kẹ̀lé yìí ju ọ̀ràn bí nǹkan ṣe rí lára ẹni lásán lọ. Dípò bẹ́ẹ̀, ó kan ìpinnu tá a fara balẹ̀ ṣe nínú ìgbésí ayé wa ojoojúmọ́. Nítorí náà, ẹ jẹ́ ká fi ṣe ìpinnu wa pé a máa gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà pátápátá lákòókò ìpọ́njú.

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Nínú lẹ́tà kan tí Salmon P. Chase, tó jẹ́ Akọ̀wé Ètò Ìnáwó kọ ránṣẹ́ sí ilé iṣẹ́ tí wọ́n ti ń tẹ owó ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ní November 20, 1861, ó sọ pé: “Kò sí orílẹ̀-èdè tó lè lágbára láìjẹ́ pé Ọlọ́run tì í lẹ́yìn, kò sì sí orílẹ̀-èdè tó lè láàbò láìjẹ́ pé Ọlọ́run dáàbò bò ó. Ó yẹ ká fi hàn nínú owó ẹyọ orílẹ̀-èdè wa pé àwọn èèyàn wa gbẹ́kẹ̀ lé Ọlọ́run.” Látàrí èyí, ara owó ẹyọ àwọn ará Amẹ́ríkà la ti kọ́kọ́ rí ọ̀rọ̀ àkọmọ̀nà náà “Ọlọ́run La Gbẹ́kẹ̀ Lé” lọ́dún 1864.

b Wọ́n sọ pé àníyàn tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ níhìn-ín jẹ́ “ìbẹ̀rù tó ń kó jìnnìjìnnì báni, tí kì í jẹ́ kéèyàn láyọ̀ nígbèésí ayé.” Irú àwọn ìtumọ̀ bí “Ẹ má máa ṣe àníyàn,” tàbí “Ẹ maṣe ṣe aniyan,” fi hàn pé a ò tiẹ̀ gbọ́dọ̀ ṣàníyàn rárá. Ìwé kan tá a ṣèwádìí nínú rẹ̀ sọ pé: “Ọ̀rọ̀ ìṣe Gíríìkì náà fi ohun tó ń lọ lọ́wọ́lọ́wọ́ hàn, tó túmọ̀ sí pé ká dá ohun tá a ń ṣe lọ́wọ́ dúró.”

c Àwọn kókó mẹ́jọ ọ̀hún rèé: (1) Má ṣe wárìrì; (2) ronú lọ́nà tí ó gbéṣẹ́; (3) ronú nípa àwọn iṣẹ́ mìíràn tó o lè ṣe; (4) ṣe bó o ti mọ; (5) ṣọ́ra fún rírajà àwìn; (6) jẹ́ kí ìdílé wà ní ìṣọ̀kan; (7) má ṣe fi ara rẹ wọ́lẹ̀; àti (8) ní àkọsílẹ̀ ètò ìnáwó.

d Kì í ṣe pé àwọn ìwé ìròyìn tá a gbé karí Bíbélì yìí ń sọ irú ìtọ́jú kan pàtó tó yẹ kó o gbà, nítorí olúkálukú ló lẹ́tọ̀ọ́ láti yan ohun tó wù ú. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ni àwọn àpilẹ̀kọ tó jíròrò àwọn àìsàn tàbí àìlera pàtó kan ń fúnni ní ìsọfúnni lọ́ọ́lọ́ọ́ nípa àwọn àìsàn náà.

Ǹjẹ́ O Rántí?

• Àwọn ọ̀nà wo la lè gbà fi hàn pé a gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà nígbà tá a bá níṣòro tó jẹ mọ́ ọ̀ràn ìnáwó?

• Báwo la ṣe lè fi hàn pé a gbẹ́kẹ̀ lé Ọlọ́run nígbà tí àìsàn bá kó ìdààmú bá wa?

• Báwo la ṣe lè fi hàn pé lóòótọ́ la gbára lé Jèhófà nígbà tí ìwà kan tó kù díẹ̀ káàtó kò bá ṣeé fi sílẹ̀ bọ̀rọ̀?

[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 17]

Ǹjẹ́ O Rántí Àwọn Àpilẹ̀kọ Wọ̀nyí?

Nígbà tí àìsàn bá ń pọ́n wa lójú, ó máa ń ṣèrànwọ́ gan-an láti ka ìrírí àwọn ẹlòmíràn tí wọ́n ti kojú àìlera, àrùn tàbí àbùkù ara. Díẹ̀ lára àwọn àpilẹ̀kọ tó ti jáde nínú ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí! ló wà nísàlẹ̀ yìí.

“Kíkojúkápá Awọn Àìlera Mi” tó dá lórí béèyàn ṣe lè borí àwọn èrò tí kò tọ́ àti béèyàn ò ṣe ní jẹ́ kí ìbànújẹ́ dorí òun kodò.—Ilé Ìṣọ́, May 1, 1990.

“Ẹ̀rọ Àfimí Kò Tilẹ Lè Dá A Duro Wiwaasu.”—Jí!, January 22, 1993.

“Ọta Ìbọn Kan Yí Ìgbésí Ayé Mi Padà,” ó sọ ìrírí ẹni tó ní àrùn ẹ̀gbà.—Jí!, October 22, 1995.

“Ẹ Kò Mọ Ohun Tí Ìwàláàyè Yín Yóò Jẹ́ Lọ́la,” tó sọ̀rọ̀ nípa béèyàn ṣe lè kojú àrùn tí kì í jẹ́ kí ìṣesí èèyàn bára dé.—Ilé Ìṣọ́, December 1, 2000.

“Bí Loida Ṣe Di Ẹni Tó Ń Sọ̀rọ̀,” tó sọ nípa béèyàn ṣe lè kojú àrùn tí kì í jẹ́ kí ọpọlọ lè darí ìséraró àti ìsọ̀rọ̀ ẹni.—Jí!, September 8, 2000.

“Nígbà Tí Àrùn Burúkú Kan Bá Kọ Lù Ọ́.”—Jí!, February 8, 2001.

“Bí Mo Tilẹ̀ Dití tí Mo Tún Fọ́jú, Mo Rí Ààbò.”—Jí!, June 8, 2001.

“A Gbé Mi Ṣánlẹ̀, Ṣùgbọ́n A Kò Pa Mí Run.”—Ilé Ìṣọ́, November 1, 1995.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]

Nígbà tí iṣẹ́ bá bọ́ lọ́wọ́ wa, ó lè jẹ́ ohun tó yẹ ni pé ká ṣàyẹ̀wò bá a ṣe ń gbé ìgbésí ayé wa

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]

Ìrírí Loida jẹ́ ká rí bi gbígbẹ́kẹ̀lé Jèhófà ṣe ń jẹ́ kéèyàn ní ìforítì. (wo àpótí ojú ìwé 17)

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]

Kò yẹ ká jẹ́ kí ojú tì wá láti sọ pé káwọn èèyàn ràn wá lọ́wọ́ láti borí ìwà kan tó kù díẹ̀ káàtó