Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Jèhófà Máa Ń Bójú Tó Wa

Jèhófà Máa Ń Bójú Tó Wa

Ìtàn Ìgbésí Ayé

Jèhófà Máa Ń Bójú Tó Wa

GẸ́GẸ́ BÍ ENELESI MZANGA ṢE SỌ Ọ́

Ọdún 1972 lọ̀rọ̀ yí ṣẹlẹ̀. Àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin mẹ́wàá tí wọ́n wà nínú Ẹgbẹ́ Ọ̀dọ́ ní Màláwì já wọ inú ilé wa, wọ́n rá mi mú, wọ́n sì wọ́ mi tuuru lọ sí oko ìrèké kan tó wà nítòsí. Ibẹ̀ ni wọ́n ti lù mí títí mo fi dákú tí wọ́n sì fi mí sílẹ̀ nítorí wọ́n rò pé mo ti kú.

Ọ̀pọ̀ Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Màláwì ló fojú winá irú ìyà bí èyí. Kí nìdí táwọn èèyàn fi ṣenúnibíni sí wọn? Kí ló ràn wọ́n lọ́wọ́ láti fara dà á? Ẹ jẹ́ kí n sọ ìtàn ìdílé mi fún yín.

INÚ ìdílé kan tí kò fọ̀rọ̀ ìsìn ṣeré ni wọ́n ti bí mi ní December 31, 1921. Pásítọ̀ ni bàbá mi nínú Ìjọ Central African Presbyterian. Ìlú Nkhoma ni wọ́n ti tọ́ mi dàgbà, ìyẹn ìlú kékeré kan tó wà nítòsí Lilongwe, tó jẹ́ olú ìlú Màláwì. Mo relé ọkọ ní ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún, Emmas Mzanga sì ni ọkọ mi.

Lọ́jọ́ kan, ọ̀rẹ́ bàbá mi kan tóun náà jẹ́ pásítọ̀ wá kí wa. Ó ti rí i pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń gbé nítòsí ilé wa, ó sì kìlọ̀ fún wa pé ká yẹra fún wọn. Ó sọ fún wa pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní ẹ̀mí èṣù, tá a ò bá sì ṣọ́ra, àwa náà á máa bá ẹ̀mí èṣù lò. Ìkìlọ̀ yẹn dẹ́rù bá wá gan-an débi pé a kó lọ sí abúlé mìíràn, níbi tí Emmas ti bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe iṣẹ́ nílé ìtajà kan. Àmọ́ kò pẹ́ tá a rí i pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tún wà nítòsí ilé wa tuntun yìí!

Kò pẹ́ rárá tí ìfẹ́ jíjinlẹ̀ tí Emmas ní sí Bíbélì fi mú kó bá Ẹlẹ́rìí kan fọ̀rọ̀ jomitoro ọ̀rọ̀. Lẹ́yìn tí Emmas rí àwọn ìdáhùn tó tẹ́ ẹ lọ́rùn sí ọ̀pọ̀ ìbéèrè tó ní, ó gbà pé kí Ẹlẹ́rìí náà máa kọ́ òun ní ẹ̀kọ́ Bíbélì. Wọ́n kọ́kọ́ ńṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì náà nílé ìtajà tó ti ń ṣiṣẹ́, àmọ́ nígbà tó yá wọ́n wá ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ náà nílé wa lẹ́ẹ̀kan lọ́sẹ̀. Gbogbo ìgbà táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà bá ti wá ni mo máa ń sá kúrò nílé, nítorí pé ẹ̀rù wọn ń bà mí. Síbẹ̀, Emmas ń bá ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì náà lọ. Ó ṣe ìrìbọmi ní April 1951, ìyẹn nǹkan bí oṣù mẹ́fà lẹ́yìn tó bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ náà. Àmọ́ kò jẹ́ kí n mọ̀ nípa èyí rárá, nítorí ó ń bẹ̀rù pé tí mò bá gbọ́ nípa rẹ̀ pẹ́nrẹ́n, ìgbéyàwó wa tú ká nìyẹn.

Àwọn Ọ̀sẹ̀ Líle Koko

Àmọ́, ọjọ́ kan ni ọ̀rẹ́ mi Ellen Kadzalero wá sọ fún mi pé ọkọ mi ti ṣe batisí gẹ́gẹ́ bí Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Inú bí mi gan-an! Àtọjọ́ yẹn ni mi o ti bá a sọ̀rọ̀ mọ́, tí mi ò sì ṣe oúnjẹ fún un. Mi ò pọnmi fún un mọ́, mi ò sì tún bá a gbé omi ìwẹ̀ rẹ̀ kaná mọ́—bẹ́ẹ̀ sì rèé, ojúṣe ìyàwó ilé gan-an lèyí jẹ́ gẹ́gẹ́ bí àṣà ìbílẹ̀ wa.

Lẹ́yìn tí Emmas fara da èyí fún ọ̀sẹ̀ mẹ́ta gbáko, ó pè mí jókòó, ó wá ṣàlàyé ìdí tóun fi pinnu láti di Ẹlẹ́rìí. Ó ka ẹsẹ Ìwé Mímọ́ bíi mélòó kan, ó sì ṣàlàyé wọn, ìwé 1 Kọ́ríńtì 9:16 wà lára ibi tó kà. Ohun tó sọ yìí wọ̀ mí lára gan-an, mo sì rí i pé ó yẹ kí èmi náà bẹ̀rẹ̀ sí wàásù ìhìn rere náà. Mo wá pinnu láti bẹ̀rẹ̀ sí kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́dọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Inú ọkọ mi ọ̀wọ́n dùn gan-an nígbà tí mo se oúnjẹ aládùn fún un nírọ̀lẹ́ ọjọ́ yẹn.

Sísọ Òtítọ́ Náà Fún Tẹbí Tọ̀rẹ́

Nígbà táwọn òbí wa gbọ́ pé a ti ń dara pọ̀ mọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ńṣe ni wọ́n tutọ́ sókè tí wọ́n fojú gbà á. Àwọn ẹbí mi kọ̀wé sí wa pé a ò gbọ́dọ̀ dé ọ̀dọ̀ àwọn mọ́. Ohun tí wọ́n ṣe yìí bà wá nínú jẹ́, àmọ́ a gbẹ́kẹ̀ lé ìlérí tí Jésù ṣe pé a óò ní ọ̀pọ̀ arákùnrin àti arábìnrin àti bàbá àti ìyá nípa tẹ̀mí.—Mátíù 19:29.

Mo jára mọ́ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tí mò ń ṣe, mo sì ṣèrìbọmi ní August 1951, ìyẹn oṣù mẹ́ta ààbọ̀ péré lẹ́yìn tí ọkọ mi ṣèrìbọmi. Mo rí i pé ó di dandan fún mi láti sọ òtítọ́ náà fún Ellen ọ̀rẹ́ mi. Inú mi dùn gan-an pé ó gbà pé kí n máa kọ́ òun lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ellen ṣe ìrìbọmi ní May 1952, ó sì di arábìnrin mi nípa tẹ̀mí, èyí tó wá jẹ́ kí ìdè ọ̀rẹ́ wa túbọ̀ lágbára sí i. Ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ ṣì ni wá di òní olónìí.

Ní ọdún 1954, wọ́n yan Emmas láti máa bẹ àwọn ìjọ wò gẹ́gẹ́ bí alábòójútó àyíká. A ti bí ọmọ mẹ́fà lákòókò yẹn. Nígbà yẹn lọ́hùn-ún, ńṣe ni alábòójútó arìnrìn-àjò tó bá ti láwọn ọmọ máa ń bẹ ìjọ wò ní ọ̀sẹ̀ kan táá sì dúró sọ́dọ̀ ìyàwó àtàwọn ọmọ rẹ̀ ní ọ̀sẹ̀ tó tẹ̀ lé e. Àmọ́, nígbà tí Emmas bá fẹ́ rin ìrìn àjò, ó máa ń rí i dájú pé mo darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ìdílé wa. A máa ń gbìyànjú láti rí i pé ìkẹ́kọ̀ọ́ tá à ń bá àwọn ọmọ wá ṣe dùn yùngbà. A tún máa ń fi ìdánilójú sọ̀rọ̀ nípa ìfẹ́ tá a ní fún Jèhófà àti fún òtítọ́ tó wà nínú Ọ̀rọ̀ rẹ̀, ìdílé wa lápapọ̀ sì máa ń kópa nínú iṣẹ́ ìwàásù. Ìtòlẹ́sẹẹsẹ ìdálẹ́kọ̀ọ́ tẹ̀mí yìí fún ìgbàgbọ́ àwọn ọmọ wa lókun, ó sì mú kí wọ́n gbára dì de inúnibíni tá a dojú kọ.

Inúnibíni Nítorí Ẹ̀sìn Bẹ̀rẹ̀

Ọdún 1964 ni Màláwì gba òmìnira. Nígbà táwọn aláṣẹ rí i pé a ò dá sí tọ̀túntòsì nínú ọ̀ràn ìṣèlú, wọ́n fẹ́ fagbára mú wa ra káàdì ẹgbẹ́ òṣèlú. a Nítorí pé èmi àti Emmas kọ̀ láti ṣe bẹ́ẹ̀, àwọn ọmọ tó wà nínú Ẹgbẹ́ Ọ̀dọ́ wá ba oko àgbàdo wa jẹ́—bẹ́ẹ̀ ibì kan ṣoṣo tá a ti máa rí oúnjẹ jẹ lọ́dún tó tẹ̀ lé e nìyẹn. Bí àwọn ọmọ Ẹgbẹ́ Ọ̀dọ́ yìí ṣe ń gé àgbàdo wa lulẹ̀ ni wọ́n ń kọrin pé: “Gbogbo ẹni tó bá kọ̀ tí ò ra káàdì Kamuzu, [ìyẹn Ààrẹ Banda], ikán ni yóò jẹ oko àgbàdo wọn, wọ́n á sì ki ìka àbámọ̀ bọnu.” Síbẹ̀, pẹ̀lú gbogbo oúnjẹ wa tí wọ́n fi ṣòfò yìí, a ò bọ́hùn. A rọ́wọ́ Jèhófà lára wa. Ó fún wa lókun tìfẹ́tìfẹ́.—Fílípì 4:12, 13.

Ní alẹ́ ọjọ́ kan ní ìparí oṣù August 1964, èmi àtàwọn ọmọ nìkan la wà nínú ilé. A ti sùn, àmọ́ orin kan tí wọ́n ń kọ láti ọ̀nà jíjìn ló jí mi. Àṣé àwọn Gulewamkulu ni, ìyẹn ẹgbẹ́ awo kan táwọn èèyàn bẹ̀rù gidigidi. Ẹgbẹ́ yìí máa ń jó ijó ìbílẹ̀, wọ́n máa ń yọ àwọn èèyàn lẹ́nu, wọ́n á sì máa díbọ́n pé ẹ̀mí àwọn baba ńlá tó ti kú làwọn. Àwọn Ẹgbẹ́ Ọ̀dọ́ ló rán Gulewamkulu láti wá hàn wá léèmọ̀. Ojú ẹsẹ̀ ni mo jí àwọn ọmọ, káwọn olubi yìí sì tó dé ilé wa, a ti sá wọ inú igbó lọ.

Àti ibi tá a sá pa mọ́ sí la ti rí iná tó ń jó lala. Àwọn Gulewamkulu ti fi iná sílé wa tá a fi koríko ṣe òrùlé rẹ̀. Ilé náà jó kanlẹ̀ tòun ti gbogbo ohun ìní wa tó wà nínú rẹ̀. Bí àwọn olubi náà ṣe ń kúrò níbi ilé wa tó ti jó di eérú náà la gbọ́ tí wọ́n sọ pé, “A ti dáná fún Ẹlẹ́rìí yẹn láti fi gbọn òtútù nù.” A dúpẹ́ a tún ọpẹ́ dá lọ́wọ́ Jèhófà pé ẹ̀mí wa ò lọ sí i! Lóòótọ́, wọ́n ba gbogbo ohun ìní wa jẹ́, àmọ́ wọn ò ba ìpinnu tá a ṣe láti gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà dípò ènìyàn jẹ́.—Sáàmù 118:8.

A gbọ́ pé ẹgbẹ́ Gulewamkulu ṣe irú ohun búburú yìí fún ìdílé márùn-ún mìíràn tí wọ́n jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà lágbègbè yẹn. Inú wa mà dùn o, nígbà táwọn arákùnrin tó wà níjọ kan nítòsí wá ràn wá lọ́wọ́! Wọ́n tún ilé wa kọ́, wọ́n sì fún wa ní oúnjẹ fún ọ̀sẹ̀ bíi mélòó kan.

Inúnibíni Tún Le Sí I

Ní September 1967, wọ́n polongo pé kí wọ́n fàṣẹ ọba mú gbogbo Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà lórílẹ̀-èdè náà. Ńṣe ni àwọn ọ̀dọ́kùnrin kan tí wọn ò lójú àánú, tí wọ́n sì burú bí nǹkan míì—ìyẹn àwọn tó wà nínú Ẹgbẹ́ Ọ̀dọ́ àti Aṣíwájú Ọ̀dọ́ nílẹ̀ Màláwì—kó àdá lọ́wọ́ tí wọ́n sì ń wá àwa Ẹlẹ́rìí kiri láti ilé kan sí òmíràn. Nígbà tí wọ́n bá rí wa, wọ́n á sọ pé àwọn fẹ́ ta káàdì ẹgbẹ́ òṣèlú fún wa.

Nígbà tí wọ́n dé ilé wa, wọ́n béèrè bóyá a ní káàdì ẹgbẹ́ òṣèlú. Mo sọ pé: “Rárá, mi ò tíì rà á. Mi ò sì ní rà á nísinsìnyí, kódà mi ò ní rà á lọ́jọ́ iwájú pàápàá.” Bí wọ́n ṣe gbé èmi àti ọkọ mi nìyẹn, ó di àgọ́ ọlọ́pàá tó wà ládùúgbò wa, wọn ò tiẹ̀ jẹ́ ká mú ohunkóhun. Nígbà táwọn ọmọ wa kéékèèké tilé ìwé dé, wọn ò rí wa, ẹ̀rù sì bẹ̀rẹ̀ sí bà wọn. Àmọ́, kò pẹ́ lẹ́yìn náà ni Daniel, ọmọkùnrin wa àgbà dé, tó béèrè ohun tó ṣẹlẹ̀ lọ́wọ́ àwọn aládùúgbò. Ojú ẹsẹ̀ ló kó àwọn àbúrò rẹ̀ wá sí àgọ́ ọlọ́pàá. Báwọn ọlọ́pàá ṣe bẹ̀rẹ̀ sí kó wa sínú ọkọ tó máa kó wa lọ sí Lilongwe làwọn ọmọ wá dé. Wọ́n sì tẹ̀ lé wa lọ.

Ìlú Lilongwe ni wọ́n ti wá ṣe ìgbẹ́jọ́ kan tí kò lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ ní orílé iṣẹ́ àwọn ọlọ́pàá tó wà níbẹ̀. Àwọn ọlọ́pàá ibẹ̀ béèrè lọ́wọ́ wa pé, “Ṣé ẹ̀sìn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lẹ fẹ́ máa ṣe lọ?” A dáhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni!” bó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ̀wọ̀n ọdún méje gbáko la máa fi gbára nítorí ìdáhùn wa yìí. Ẹ̀wọ̀n ọdún mẹ́rìnlá sì ni fáwọn tó mú “ipò iwájú” nínú ètò àjọ wa.

Lẹ́yìn tá a lo òru ọjọ́ kan mọ́jú níbẹ̀ láìsinmi tá a ò sì jẹ oúnjẹ kankan, àwọn ọlọ́pàá náà kó wa lọ sí Ọgbà Ẹ̀wọ̀n Maula. Ọgbà ẹ̀wọ̀n náà kún gan-an débi pé a ò ríbi sùn sí nílẹ̀ẹ́lẹ̀! Korobá kan ṣoṣo ló wà nílé ìyàgbẹ́ tí wọ́n ṣe fún ilé ẹ̀wọ̀n kọ̀ọ̀kan táwọn èrò kún inú rẹ̀ bámúbámú. Oúnjẹ tí wọ́n ń fún wa kò ju kékeré, wọ́n ò sì se oúnjẹ náà dáadáa. Lẹ́yìn ọ̀sẹ̀ méjì, àwọn aláṣẹ ọgbà ẹ̀wọ̀n náà rí i pé èèyàn àlàáfíà ni wá, wọ́n sì gbà wá láyè láti lo ibi eré ìdárayá ọgbà ẹ̀wọ̀n náà. Pẹ̀lú bí ọ̀pọ̀ lára wa ṣe wà níbì kan náà yẹn, a láǹfààní àtigba ara wa níyànjú lójoojúmọ́, a sì ń jẹ́rìí àtàtà fáwọn ẹlẹ́wọ̀n mìíràn. Ìyàlẹ́nu ńlá ló jẹ́ fún wa pé wọ́n dá wa sílẹ̀ lẹ́yìn tá a lo nǹkan bí oṣù mẹ́ta péré lára àkókò tí wọ́n sọ pé a máa lò lọ́gbà ẹ̀wọ̀n náà, nítorí pé àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn fúngun mọ́ ìjọba Màláwì.

Àwọn ọlọ́pàá náà sọ pé ká padà sílé wa, àmọ́ wọ́n tún sọ fún wa pé wọ́n ti fòfin de àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà nílẹ̀ Màláwì. Nǹkan bí ọdún mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n ni wọ́n fi fòfin de iṣẹ́ wa—láti October 20, 1967, sí August 12, 1993. Àwọn ọdún wọ̀nyẹn le koko bí ojú ẹja, síbẹ̀, pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Jèhófà, ó ṣeé ṣe fún wa láti wà láìdásí-tọ̀túntòsì.

Wọ́n Ń Dọdẹ Wa Kiri Bí Ẹran

Òfin kan tí ìjọba ṣe ní October 1972 tún tanná ran inúnibíni líle koko mìíràn. Òfin náà sọ pé kí wọ́n lé gbogbo Ẹlẹ́rìí Jèhófà kúrò níbi tí wọ́n ti ń ṣiṣẹ́, kí wọ́n sì lé gbogbo Ẹlẹ́rìí tó wà lábúlé kúrò nílé wọn. Bí wọ́n ṣe bẹ̀rẹ̀ sí dọdẹ àwa Ẹlẹ́rìí kiri bí ẹran nìyẹn.

Àkókò yẹn ni ọ̀dọ́ Kristẹni arákùnrin kan wá sílé wa tó wá sọ ìròyìn pàjáwìrì fún Emmas pé, ‘Àwọn Ẹgbẹ́ Ọ̀dọ́ ń gbìmọ̀ láti wá bẹ́ ọ lórí o, wọ́n ní àwọn á fi orí rẹ kọ́ igi, àwọn á sì gbé e lọ sọ́dọ̀ baálẹ̀ àdúgbò.’ Kíá ni Emmas sá kúrò nílé, àmọ́ ó kọ́kọ́ ṣètò bá a ṣe máa wá bá òun láìjáfara. Ojú ẹsẹ̀ ni mo sọ pé káwọn ọmọ sá kúrò nílé. Bí mo ṣe fẹ́ kúrò nílé báyìí ni mẹ́wàá lára àwọn Ẹgbẹ́ Ọ̀dọ́ náà dé, tí wọ́n ń wá Emmas. Wọ́n já wọnú ilé wa, àmọ́ wọ́n rí i pé Emmas ò sí níbẹ̀ mọ́. Pẹ̀lú ìbínú làwọn ọkùnrin náà fi wọ́ mi tuuru lọ sí oko ìrèké kan tó wà nítòsí, níbi tí wọ́n ti ń ta mí nípàá, tí wọ́n sì fi igi ìrèké lù mí lálùbolẹ̀. Ìgbà tí mo dákú tí wọ́n rò pé mo ti kú ni wọ́n tó fi mí sílẹ̀. Nígbà tí mo wá ta jí, ńṣe ni mo wọ́ lọ sílé wa.

Lóru ọjọ́ yẹn, nínú òkùnkùn biribiri ni Emmas ti fẹ̀mí ara rẹ̀ wewu láti wá wò mí nílé. Nígbà tí Emmas rí i pé wọ́n ti lù mí nílùkulù, òun àti ọ̀rẹ́ rẹ̀ kan tó ní ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ rọra gbé mi sínú ọkọ̀ náà. Bá a ṣe forí lé ilé arákùnrin kan ní Lilongwe nìyẹn, ibẹ̀ ni mo sì wà títí ara mi fi yá tí Emmas sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣètò bá a ṣe máa sá kúrò lórílẹ̀-èdè wa.

Àwọn Olùwá-Ibi-Ìsádi Tí Wọn Kò Rí Ibi Sá Sí

Dinesi, ọmọ wa obìnrin àti ọkọ rẹ̀ ní ọkọ̀ akẹ́rù kékeré kan. Wọ́n gba awakọ̀ kan tó ti fìgbà kan wà nínú Ẹgbẹ́ Aṣíwájú Ọ̀dọ́ ní Màláwì, àmọ́ tí ohun tó ṣẹlẹ̀ sí wa ń jẹ́ kó káàánú wa báyìí. Ó ní òun á ran àwa àtàwọn Ẹlẹ́rìí mìíràn lọ́wọ́. Fún àwọn ìrọ̀lẹ́ bíi mélòó kan ni awakọ̀ yìí fi ń kó àwa Ẹlẹ́rìí láti àwọn ibi tá a ti ṣètò pé a ó sá pa mọ́ sí. Ó wá wọ aṣọ Ẹgbẹ́ Ọ̀dọ́ Màláwì rẹ̀, ó sì wa ọkọ̀ kọjá ní gbogbo ibi táwọn ọlọ́pàá wà láìsí ẹni tó dá a dúró. Ó fi ẹ̀mí ara rẹ̀ wewu láti ran ọgọ́rọ̀ọ̀rún àwa Ẹlẹ́rìí lọ́wọ́ láti gba ẹnubodè kọjá lọ sí Zambia.

Lẹ́yìn oṣù bíi mélòó kan, àwọn aláṣẹ ilẹ̀ Zambia tún dá wa padà sí Màláwì; síbẹ̀, a ò lè padà sí abúlé tiwa. Gbogbo ohun ìní wa tá a fi sílẹ̀ làwọn olè ti jí kó. Kódà wọ́n ti ká páànù tá a fi ṣe òrùlé ilé wa lọ. Nígbà tí kò sí ibòmíràn tá a lè lọ, a forí lé Mòsáńbíìkì, a sì gbé àgọ́ àwọn olùwá-ibi-ìsádi tó wà ní Mlangeni fún ọdún méjì àtààbọ̀. Àmọ́, ní June 1975, ìjọba tuntun tó wà lórí àlééfà ní Mòsáńbíìkì ti àgọ́ náà pa, wọ́n sì sọ pé a gbọ́dọ̀ padà sí Màláwì, bẹ́ẹ̀ ohun tí wọ́n ń fojú àwọn èèyàn Jèhófà rí níbẹ̀ ò tíì yí padà. Kò sí ọgbọ́n mìíràn tá a lè dá ju pé ká tún sá lọ sí Zambia lẹ́ẹ̀kejì. A wá lọ sí àgọ́ àwọn olùwá-ibi-ìsádi tó wà ní Chigumukire.

Oṣù méjì lẹ́yìn ìyẹn ni wọ́n kó ọ̀pọ̀ bọ́ọ̀sì àtàwọn ọkọ̀ ológun jọ sójú pópó, tí ọgọ́rọ̀ọ̀rún àwọn sójà ilẹ̀ Zambia tí wọ́n dìhámọ́ra ogun sì ya wọ àgọ́ náà. Wọ́n sọ fún wa pé wọ́n ti kọ́ àwọn ilé rèǹtèrente fún wa àti pé àwọn ti kó àwọn ọkọ̀ tó máa gbé wa lọ síbẹ̀ wá. A mọ̀ pé irọ́ gbuu lèyí. Àwọn sójà náà wá bẹ̀rẹ̀ sí sọ́gọ àwọn èèyàn sínú ọkọ̀ ẹlẹ́rù àtàwọn bọ́ọ̀sì náà, wọ́n sì kó jìnnìjìnnì bá gbogbo wa. Àwọn sójà yìí tún yìnbọn sókè pà-à-rà-pà, ìbẹ̀rùbojo sì mú kí ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin fọ́n ká.

Inú rìgbòrìyẹ̀ yìí ni Emmas ti ṣèèṣì ṣubú táwọn èèyàn sì ń gba orí rẹ̀ kọjá, àmọ́ arákùnrin kan fà á dìde. A rò pé ìbẹ̀rẹ̀ ìpọ́njú ńlá lèyí. Gbogbo àwa tá a jẹ́ olùwá-ibi-ìsádi wá forí lé ọ̀nà Màláwì. A ò tíì kúrò ní Zambia nígbà tá a dé ibi odò kan, bí gbogbo wa ṣe di ara wa lọ́wọ́ mú lórí ìlà kan nìyẹn, ìyẹn sì mú kó ṣeé ṣe fún gbogbo wa láti sọdá láìfarapa. Àmọ́, nígbà tá a dé òdì kejì odò náà, àwọn sójà Zambia rá wa mú wọ́n sì fagbára dá wa padà sí Màláwì.

Nígbà tá a tún padà dé Màláwì, a ò mọ ibi tá a ó forí lé. A gbọ́ pé wọ́n ti kìlọ̀ fáwọn èèyàn níbi ìpàdé ìṣèlú àti nínú ìwé ìròyìn pé bí wọ́n bá ti rí “ojú tuntun” kí wọ́n ké gbàjarè, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni wọ́n sì ní lọ́kàn. Ìyẹn ló wá mú ká pinnu láti sá lọ sí olú ìlú wa, níbi táwọn èèyàn ò tí ní tètè dá wa mọ̀ bíi ti abúlé. A wá háyà ilé kékeré kan níbẹ̀, Emmas sì tún padà sórí ìbẹ̀wò bòókẹ́lẹ́ tó ń ṣe sáwọn ìjọ gẹ́gẹ́ bí alábòójútó arìnrìn-àjò.

Àwọn Ìpàdé Ìjọ Ràn Wá Lọ́wọ́

Kí ló ràn wá lọ́wọ́ láti dúró bí olóòótọ́? Àwọn ìpàdé ìjọ ni! Nígbà tá a wà ní àgọ́ àwọn olùwá-ibi-ìsádi ní Mòsáńbíìkì àti Zambia, ńṣe là ń lọ sáwọn ìpàdé fàlàlà ní àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba kékeré tá a fi koríko ṣe òrùlé wọn. Kíkó ara wa jọ láti ṣe àwọn ìpàdé ní Màláwì léwu gan-an kò sì rọrùn rárá—síbẹ̀ a rí i pé ohun tó yẹ ní ṣíṣe ni. Káwọn èèyàn má bàa rí wa, òru ọ̀gànjọ́ la máa ń ṣe àwọn ìpàdé wa níbi táwọn èèyàn ò lè tètè dé. A kì í pàtẹ́wọ́ káwọn èèyàn má bàá mọ̀ pé a wà níbẹ̀, ńṣe la máa ń fọwọ́ rawọ́ láti fi hàn pé a mọrírì àsọyé táwọn ará bá sọ.

Òru ọ̀gànjọ́ là ń ṣe ìrìbọmi. Irú àkókò yẹn ni Abiyudi ọmọ wa ọkùnrin ṣe ìrìbọmi. Lẹ́yìn àsọyé ìrìbọmi náà, inú òkùnkùn yẹn ni wọ́n ti kó òun àtàwọn yòókù tó fẹ́ ṣe ìrìbọmi lọ sí àkùrọ̀ kan níbi tí wọ́n gbẹ́ kòtò kan tí kò jìn sí kí omi lè sun jáde. Ibẹ̀ ni wọ́n sì ti ṣe ìrìbọmi fún wọn.

Ilé Wa Kékeré Di Ibi Ààbò

Láàárín àwọn ọdún tó kẹ́yìn àkókò ìfòfindè náà, a bẹ̀rẹ̀ sí lo ilé wa tó wà ní Lilongwe gẹ́gẹ́ bí ilé ààbò. Àwọn ará ń kó àwọn lẹ́tà àtàwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tó ń wá láti ẹ̀ka ilé iṣẹ́ ti Zambia wá sílé wa ní bòókẹ́lẹ́. Àwọn arákùnrin tó ń fi kẹ̀kẹ́ kó lẹ́tà kiri á wá kó ẹrù tí wọ́n kó ránṣẹ́ láti Zambia, wọ́n á sì pín àwọn lẹ́tà àtàwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ náà káàkiri orílẹ̀-èdè Màláwì. Ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ tí wọ́n ń pín kiri náà kò jù kékeré nítorí pé bébà tí wọ́n fi ń tẹ Bíbélì ni wọ́n fi tẹ̀ wọ́n. Èyí jẹ́ kí wọ́n lè kó ìlọ́po méjì ohun tí wọ́n ì bá kó ká ní bébà ìwé ìròyìn la fi tẹ̀ wọ́n. Àwọn tó ń kó lẹ́tà náà tún máa ń pín àwọn ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ kéékèèké kiri, ìyẹn èyí tó ní kìkì àwọn àpilẹ̀kọ́ tá a ń kà nípàdé nínú. Ó rọrùn láti fi ìwé ìròyìn kékeré yìí sínú àpò àyà nítorí pé abala ìwé kan ṣoṣo ni.

Pẹ̀lú ìnira làwọn akólẹ́tà wọ̀nyí fi máa ń wa kẹ̀kẹ́ kiri inú igbó, wọ́n sì máa ń fi ẹ̀mí ara wọn wewu. Ìgbà mìíràn wà tí wọ́n máa ń rìn lóru, tí wọ́n á di àwọn ìwé tá a ti fòfin dè náà gègèrè sórí kẹ̀kẹ́ wọn. Láìfi báwọn ọlọ́pàá ṣe pọ̀ sójú ọ̀nà àti àwọn ewu mìíràn pè, wọ́n máa ń rin ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ kìlómítà lójò lẹ́ẹ̀rùn láti pín oúnjẹ tẹ̀mí fún àwọn ará. Àwọn ẹni iyì ẹni ẹ̀yẹ tó ń pín ìwé kiri yìí mà nígboyà gan-an o!

Jèhófà Ń Bójú Tó Àwọn Opó

Ibi tí Emmas ti ń sọ àsọyé lọ́wọ́ nígbà tó lọ bẹ ìjọ kan wò ní December 1992, ni àrùn rọpárọsẹ̀ ti kọ lù ú. Nígbà tó yá kò wá lè sọ̀rọ̀ mọ́. Nígbà tó tún ṣe díẹ̀ lẹ́yìn ìyẹn, àìsàn náà tún kọ lù ú lẹ́ẹ̀kejì, apá kan ara rẹ̀ sì rọ kanlẹ̀. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àìsàn yìí yọ ọ́ lẹ́nu gan-an, síbẹ̀ ìtìlẹ́yìn onífẹ̀ẹ́ tá à ń rí gbà látinú ìjọ wa kò jẹ́ kí ìbànújẹ́ dorí mi kodò. Ó ṣeé ṣe fún mi láti tọ́jú ọkọ mi ọ̀wọ́n nílé títí tó fi kú lẹ́ni ọdún mẹ́rìndínlọ́gọ́rin ní November 1994. Ọdún mẹ́tàdínlọ́gọ́ta la fi jọ wà pa pọ̀, wọ́n sì ti mú òfin tí wọ́n fi de iṣẹ́ wa kúrò kí Emmas tó kú. Àmọ́ mo ṣì ń ṣèdárò ikú ọkọ mi tòótọ́.

Nígbà tí mo di opó, ọkọ ọmọ mi bẹ̀rẹ̀ sí gbọ́ bùkátà aya rẹ̀, àwọn ọmọ rẹ̀ márààrún àti tèmi náà. Ó mà ṣe o, lẹ́yìn àìsàn ráńpẹ́, òun náà kú ní August 2000. Ibo ni kí ọmọ mi ti wá rí oúnjẹ tá a ó máa jẹ àti ilé tí a ó máa gbé báyìí? Lẹ́ẹ̀kan sí i, mo tún rí i pé Jèhófà ń bójú tó wa, lóòótọ́ ló sì jẹ́ “baba àwọn ọmọdékùnrin aláìníbaba àti onídàájọ́ fún àwọn opó.” (Sáàmù 68:5) Jèhófà pèsè ilé rèǹtèrente tuntun kan fún wa nípasẹ̀ àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ orí ilẹ̀ ayé. Báwo nìyẹn ṣe ṣẹlẹ̀? Nígbà táwọn arákùnrin àti arábìnrin tó wà nínú ìjọ wa rí ipò tá a wà, wọ́n kọ́ ilé kan fún wa láàárín ọ̀sẹ̀ márùn-ún péré! Àwọn arákùnrin tó jẹ́ mọlémọlé láwọn ìjọ mìíràn wá ṣèrànwọ́ pẹ̀lú. Ìfẹ́ àti inú rere táwọn Ẹlẹ́rìí wọ̀nyí fi hàn wú wa lórí gan-an nítorí pé ilé tí wọ́n kọ́ fún wa dára ju èyí tí ọ̀pọ̀ lára wọn ń gbé. Ìfẹ́ táwọn ará ìjọ fi hàn yìí jẹ́ ẹ̀rí àtàtà fún àwọn aládùúgbò wa. Bí mo bá ti fẹ́ sun ní alaalẹ́, ńṣe ló ń dá bíi pé inú Párádísè ni mo wà! Lóòótọ́, bíríkì ni wọ́n fi kọ́ ilé wa tuntun rèǹtèrente yìí, àmọ́ gẹ́gẹ́ bí ohun tí ọ̀pọ̀ èèyàn ń sọ, ìfẹ́ ni a fi kọ́ ọ ní ti gidi.—Gálátíà 6:10.

Jèhófà Ṣì Ń Bójú Tó Wa

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ìgbà mìíràn wà tí ìbànújẹ́ dorí mi kodò, síbẹ̀ Jèhófà kò fi mí sílẹ̀. Méje nínú àwọn ọmọ mẹ́sàn-án tí mo bí ṣì wà láàyè, ìdílé mi ti di mẹ́tàlélọ́gọ́fà báyìí. Inú mi sì dùn gan-an pé èyí tó pọ̀ jù lọ lára wọn ló ń fi ìṣòtítọ́ sin Jèhófà!

Lónìí, tí mo ti di ẹni ọdún méjìlélọ́gọ́rin, inú mi ń dùn gan-an bí mo ṣe ń rí ohun tí ẹ̀mí Ọlọ́run ti gbé ṣe ní Màláwì. Láàárín ọdún mẹ́rin péré sẹ́yìn, mo ti rí i bí iye Gbọ̀ngàn Ìjọba ti lọ sókè látorí ẹyọ kan sí ẹgbẹ̀ta. A tún ti ní ẹ̀ka ilé iṣẹ́ tuntun ní Lilongwe báyìí, a sì ń gbádùn oúnjẹ tẹ̀mí tó dọ́ṣọ̀. Mo rí i pé mo ti gbádùn ìmúṣẹ ìlérí tí Ọlọ́run ṣe, èyí tó wà nínú ìwé Aísáyà 54:17, níbi tó ti mú un dá wa lójú pé: “Ohun ìjà yòówù tí a bá ṣe sí ọ kì yóò ṣe àṣeyọrí sí rere.” Lẹ́yìn tí mo ti sin Jèhófà fún àádọ́ta ọdún, mo ti rí i dájú pé àdánwò èyíkéyìí tó lè bá wa, Jèhófà máa ń bójú tó wa.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Láti rí ìsọfúnni síwájú sí i lórí ìtàn àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Màláwì, wo ìwé 1999 Yearbook of Jehovah’s Witnesses, ojú ìwé 149 sí 223, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la tẹ ìwé yìí jáde.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]

Emmas, ọkọ mi ṣe ìrìbọmi ní April 1951

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]

Àwọn akólẹ́tà tí wọ́n jẹ́ onígboyà

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 28]

Ilé tá a fi ìfẹ́ kọ́