Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Máa Yin Jèhófà “ní Àárín Ìjọ”

Máa Yin Jèhófà “ní Àárín Ìjọ”

Máa Yin Jèhófà “ní Àárín Ìjọ”

ÀWỌN ìpàdé Kristẹni jẹ́ ètò tí Jèhófà ti ṣe láti máa fún àwọn èèyàn rẹ̀ lókun nípa tẹ̀mí. À ń fi ìmọrírì hàn fún ìpèsè tó ń wá látọ̀dọ̀ Jèhófà nípa lílọ sípàdé déédéé. Kò tán síbẹ̀ o, èyí á tún mú ká “ru [àwọn ará wa] sókè sí ìfẹ́ àti sí àwọn iṣẹ́ àtàtà, èyí tó jẹ́ ọ̀nà pàtàkì láti fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ ara wa.” (Hébérù 10:24; Jòhánù 13:35) Nígbà náà, báwo la ṣe lè ru àwọn ará wa sókè, tàbí fún wọn níṣìírí láwọn ìpàdé?

Sọ̀rọ̀ Nínú Ìjọ

Dáfídì Ọba kọ̀wé nípa ara rẹ̀ pé: “Ṣe ni èmi yóò máa polongo orúkọ rẹ fún àwọn arákùnrin mi; èmi yóò máa yìn ọ́ ní àárín ìjọ. Láti ọ̀dọ̀ rẹ ni ìyìn mi yóò wà ní ìjọ ńlá.” “Ṣe ni èmi yóò máa gbé ọ lárugẹ nínú ìjọ ńlá; èmi yóò máa yìn ọ́ láàárín àwọn ènìyàn tí ó pọ̀ níye.” “Mo ti sọ ìhìn rere òdodo nínú ìjọ ńlá. Wò ó! Èmi kò ṣèdíwọ́ fún ètè mi.”—Sáàmù 22:22, 25; 35:18; 40:9.

Nígbà ayé àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù, táwọn Kristẹni bá kóra jọ láti jọ́sìn, àwọn náà máa ń sọ̀rọ̀ nípa ìgbàgbọ́ tí wọ́n ní nínú Jèhófà wọ́n sì máa ń sọ̀rọ̀ nípa ògo rẹ̀. Ọ̀nà yìí ni wọ́n gbà ń fún ara wọn níṣìírí tí wọ́n sì ń ru ara wọn sókè sí ìfẹ́ àti sáwọn iṣẹ́ àtàtà. Lọ́jọ́ tiwa, tí í ṣe ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún lẹ́yìn àkókò Dáfídì àti Pọ́ọ̀lù, lóòótọ́ ni a “ti rí i pé ọjọ́ [Jèhófà] ń sún mọ́lé” ju ti ìgbàkigbà rí lọ. (Hébérù 10:24, 25) Ètò àjọ Sátánì ń sún kẹrẹkẹrẹ lọ sí ìparun, bẹ́ẹ̀ náà ni ìṣòro túbọ̀ ń pọ̀ sí i. A “nílò ìfaradà” nísinsìnyí ju ti ìgbàkigbà rí lọ. (Hébérù 10:36) Tá a bá mú àwọn arákùnrin wa kúrò, ta ló tún tóótun láti fún wa níṣìírí tó máa jẹ́ ká ní ìfaradà?

Ètò tó wà nígbà àtijọ́ tún wà lóde òní pẹ̀lú, ìyẹn àǹfààní táwọn ará ní láti sọ ohun tí wọ́n gbà gbọ́ “ní àárín ìjọ.” Àǹfààní kan tí gbogbo èèyàn ní ni dídáhùn ìbéèrè tá a bá béèrè lọ́wọ́ àwùjọ láwọn ìpàdé ìjọ. Má ṣe fojú kéré àǹfààní tó wà nínú ìpèsè yìí. Bí àpẹẹrẹ, àwọn ìdáhùn tó ń fi bá a ṣe lè borí ìṣòro hàn tàbí bá a ṣe lè yẹra fún wọn lè fún àwọn ará wa lókun láti túbọ̀ máa tẹ̀ lé àwọn ìlànà inú Bíbélì. Àwọn ìdáhùn tó ṣàlàyé àwọn ẹsẹ Bíbélì tá a tọ́ka sí àmọ́ tí a kò fa ọ̀rọ̀ inú wọn yọ tàbí èyí tó dá lórí àwọn ìwádìí téèyàn fúnra rẹ̀ ṣe lè fún àwọn mìíràn níṣìírí láti túbọ̀ mú ọ̀nà tí wọ́n gbà ń kẹ́kọ̀ọ́ sunwọ̀n sí i.

Tá a bá fi sọ́kàn pé àwa àtàwọn ẹlòmíràn ló máa jàǹfààní nínú ìdáhùn wa nípàdé, èyí á mú kí gbogbo àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà borí ìtìjú. Ó ṣe pàtàkì gan-an káwọn alàgbà àtàwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ máa dáhùn nípàdé, nítorí pé àwọn ló ń mú ipò iwájú nínú kíkópa nínú ìpàdé àti wíwá sípàdé. Nígbà náà, báwo lẹnì kan ṣe lè ṣàtúnṣe tó bá rí i pé òun ò tíì ṣe dáadáa tó nínú ojúṣe òun gẹ́gẹ́ Kristẹni, ìyẹn dídáhùn nípàdé?

Àwọn Ìmọ̀ràn Tó Lè Mú Ká Túbọ̀ Máa Kópa Nínú Ìpàdé

Rántí pé dídáhùn nípàdé jẹ́ apá kan ìjọsìn wa sí Jèhófà. Arábìnrin kan tó jẹ́ Kristẹni ní ilẹ̀ Jámánì ṣàlàyé ojú tó fi ń wo àwọn ìdáhùn rẹ̀ nípàdé. Ó sọ pé: “Ó jẹ́ ọ̀nà tí mo gbà ń dójú ti Sátánì, ẹni tí kò fẹ́ káwọn èèyàn sọ̀rọ̀ nípa ohun tí wọ́n gbà gbọ́.” Arákùnrin kan tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣèrìbọmi, tí wọ́n jọ wà nínú ìjọ kan náà sọ pé: “Tó bá kan ọ̀ràn dídáhùn nípàdé, mo máa ń gbàdúrà nípa rẹ̀ gan-an ni.”

Múra sílẹ̀ dáadáa. Tí o ò bá ka àwọn ibi tá a fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ wá láti ilé, o ò ní lè dáhùn bó ṣe yẹ, àwọn ìdáhùn rẹ ò sì ní fi bẹ́ẹ̀ gbéṣẹ́. Àwọn àbá lórí bó ṣe yẹ ká máa dáhùn láwọn ìpàdé ìjọ wà nínú ìwé Jàǹfààní Nínú Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run, ojú ìwé 70. a

Ní in lọ́kàn láti dáhùn ó kéré tán lẹ́ẹ̀kan ní ìpàdé kọ̀ọ̀kan. Èyí túmọ̀ sí pé wàá múra ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìdáhùn sílẹ̀, nítorí pé bí iye ìgbà tó o bá nawọ́ bá ṣe pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ ni ó ṣe máa ṣeé ṣe tó fún ẹni to ń darí ìpàdé láti pè ọ́. O tiẹ̀ lè pè é ṣáájú ìpàdé kó o sì sọ àwọn ìbéèrè tó o ti múra láti dáhùn fún un. Èyí máa ń ṣèrànlọ́wọ́ gan-an àgàgà tó o bá jẹ́ ẹni tuntun. Ẹ̀rù lè máa bà ọ́ láti nawọ́ sókè “ní ìjọ ńlá,” àmọ́ tó o bá ní i lọ́kàn pé ìpínrọ̀ tó o múra sílẹ̀ rèé, àti pé ẹni tó ń darí ìpàdé á retí pé kó o nawọ́, èyí á fún ọ níṣìírí láti dáhùn.

Dáhùn níbẹ̀rẹ̀. Fífi òní dónìí fi ọ̀la dọ́la kò ní yanjú ìṣòro kan tó le koko. Dídáhùn nígbà tí ìpàdé bá ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ lè ṣèrànwọ́. Yóò yà ọ́ lẹ́nu láti rí i pé ó rọrùn gan-an láti dáhùn lẹ́ẹ̀kejì tàbí lẹ́ẹ̀kẹta tó o bá ti lè borí ohun tó mú kó ṣòro fún ọ láti dáhùn nígbà àkọ́kọ́.

Jókòó síbi tó yẹ. Ó máa ń rọrùn fáwọn mìíràn láti dáhùn tí wọ́n bá jókòó sí apá iwájú nínú Gbọ̀ngàn Ìjọba. Kò fi bẹ́ẹ̀ sí ohun tó lè pín ọkàn wọn níyà níbẹ̀, ẹni tó sì ń darí ìpàdé á tún lè tètè rí ọwọ́ tí wọ́n nà sókè. Tó o bá jókòó sápá iwájú, má gbàgbé láti sọ̀rọ̀ sókè dáadáa kí gbogbo èèyàn lè gbọ́, pàápàá tí ìjọ rẹ kò bá ní makirofóònù.

Fetí sílẹ̀ dáadáa. Èyí kò ní mú kó o máa ṣe àtúnsọ ohun tí ẹlòmíràn ti sọ. Bákan náà, ìdáhùn àwọn ẹlòmíràn lè rán ọ létí ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan tàbí kókó kan tó lè túbọ̀ tànmọ́lẹ̀ sórí ohun tẹ́nì kan ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ tán. Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, ìrírí ṣókí lè mú kí kókó tá a ń jíròrò túbọ̀ ṣe kedere. Irú àwọn ìdáhùn bẹ́ẹ̀ máa ń ṣèrànwọ́ gan-an.

Kọ́ bí wàá ṣe máa dáhùn ní ọ̀rọ̀ ara rẹ. Kíka ìdáhùn jáde látinú ibi tá a ń kẹ́kọ̀ọ́ lè fi hàn pé o ti rí ìdáhùn tó yẹ, èyí sì lè jẹ́ ọ̀nà tó dáa láti bẹ̀rẹ̀ sí dáhùn. Àmọ́ dídáhùn ní ọ̀rọ̀ ara rẹ á fi hàn pé o lóye kókó tá a ń jíròrò. Kò pọn dandan láti ka àwọn ọ̀rọ̀ inú ìtẹ̀jáde wa gẹ́gẹ́ bá a ṣe kọ wọ́n sílẹ̀. Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà kì í kàn án ṣàtúnsọ ohun tó wà nínú ìwé wa.

Má yà kúrò lórí kókó tẹ́ ẹ ń jíròrò. Àwọn ìdáhùn tí kò bá kókó tá a ń jíròrò mu tàbí tó lè ṣini lọ́nà kò yẹ. Èyí túmọ̀ sí pé àwọn ìdáhùn rẹ gbọ́dọ̀ bá kókó tẹ́ ẹ ń jíròrò mu. Èyí á jẹ́ kí kókó tẹ́ ẹ ń jíròrò lọ́wọ́ túbọ̀ jẹ́ èyí tó ń gbéni ró nípa tẹ̀mí.

Ní in lọ́kàn láti fúnni níṣìírí. Nígbà tó jẹ́ pé olórí ìdí tá a fi ń dáhùn nípàdé ni pé ká lè fún àwọn ẹlòmíràn níṣìírí, a gbọ́dọ̀ yẹra fún àwọn ọ̀rọ̀ tó máa kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá wọn. Kò tán síbẹ̀ o, má ṣe sọ gbogbo ohun tó wà nínú ìpínrọ̀ tẹ́ ẹ ń jíròrò débí pé kò ku ohunkóhun tí ẹlòmíràn lè rí sọ nínú ìpínrọ̀ náà mọ́. Ńṣe ni ìdáhùn gígùn tàbí èyí tó ní kókó ọ̀rọ̀ púpọ̀ nínú máa ń da ojú ọ̀rọ̀ rú. Ìdáhùn tó ṣe ṣókí tí ọ̀rọ̀ inú rẹ̀ kò pọ̀ máa ń gbéṣẹ́ gan-an ni, ó sì máa ń fún àwọn ẹni tuntun níṣìírí láti sọ àwọn ìdáhùn ṣókí tí wọ́n ti múra sílẹ̀.

Iṣẹ́ Àwọn Tó Ń Darí Ìpàdé

Tó bá di ti fífúnni níṣìírí, àwọn to ń darí ìpàdé ní iṣẹ́ tó pọ̀ láti ṣe. Wọ́n á fẹ́ gbọ́ ìdáhùn ẹnì kọ̀ọ̀kan lágbọ̀ọ́yé nípa fífetí sílẹ̀ dáadáa kí wọ́n sì máa fiyè sí ohun tó ń sọ dípò ṣíṣe nǹkan mìíràn. Kò mà ní bójú mu rárá o, kí wọ́n má fetí sílẹ̀ dáadáa sí ìdáhùn ẹni náà kó wá di pé wọ́n á bẹ̀rẹ̀ sí ṣe àsọtúnsọ ọ̀rọ̀ tẹ́ni náà ti sọ tàbí kí wọ́n tún béèrè ìbéèrè tẹ́nì kan ti dáhùn tẹ́lẹ̀!

Ohun mìíràn tí kì í fúnni níṣìírí ni pé kí ẹni tó ń darí ìpàdé máa ṣe àsọtúnsọ ìdáhùn tí ẹnì kan ti sọ bí ẹni pé ìdáhùn tí ẹni náà sọ kò tọ̀nà. Àmọ́ ó máa ń fúnni níṣìírí gan-an tí àwọn ìdáhùn bá mú ká túbọ̀ jíròrò àwọn kókó pàtàkì sí i. Àwọn ìbéèrè bíi ‘Báwo la ṣe lè fi kókó yìí sílò nínú ìjọ wa?’ tàbí ‘Ẹsẹ Ìwé Mímọ́ wo nínú ìpínrọ̀ tá a kà yìí ló ti ìdáhùn tá a ti gbọ́ lẹ́yìn?’ jẹ́ irú àwọn ìbéèrè tó ń mú káwọn èèyàn dáhùn lọ́nà tó yẹ.

Ó ṣe pàtàkì gan-an láti gbóríyìn fún àwọn ẹni tuntun tàbí àwọn tó jẹ́ onítìjú nígbà tí wọ́n bá dáhùn nípàdé. A lè gbóríyìn fún wọn lẹ́nì kọ̀ọ̀kan lẹ́yìn ìpàdé kó máa bàa di pé a tún ń dójú tì wọ́n, èyí á sì tún jẹ́ kí olùdarí láǹfààní láti fún wọn láwọn àbá tó bá yẹ.

Ìjíròrò ọlọ́rẹ̀ẹ́sọ́rẹ̀ẹ́ pàápàá máa ń súni tẹ́nì kan bá wà tó jẹ́ pé òun ló fẹ́ máa sọ̀rọ̀ ṣáá. Àwọn tó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀ kò ní fẹ́ fèsì sọ́rọ̀ náà. Tí wọ́n bá tiẹ̀ fetí sílẹ̀ gan-an, ọkàn wọn kì í sí nínú ohun tí ẹni náà ń sọ. Ohun kan náà lè ṣẹlẹ̀ bí ẹni tó ń darí ìpàdé bá ń sọ̀rọ̀ jù. Àmọ́ o, ẹni tó ń darí ìpàdé lè béèrè àwọn àfikún ìbéèrè káwọn èèyàn lè túbọ̀ dáhùn kí wọ́n sì lè túbọ̀ ronú lórí kókó tí wọ́n ń gbé yẹ̀ wò. Irú àwọn ìbéèrè bẹ́ẹ̀ kì í ṣohun téèyàn ń lò ní gbogbo ìgbà ṣáá o.

Kò pọn dandan kó jẹ́ pé ẹni tó kọ́kọ́ nawọ́ ni ẹni tó ń darí ìpàdé máa pè. Èyí lè kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá àwọn tó nílò láti ronú lórí ohun tí wọ́n fẹ́ sọ. Níní sùúrù díẹ̀ á jẹ́ kí ẹni tí kò tíì dáhùn tẹ́lẹ̀ láǹfààní láti ṣe bẹ́ẹ̀. Ẹni tó ń darí ìpàdé á tún lo òye nípa pé kò ní máa pe àwọn ọmọdé láti dáhùn àwọn ìbéèrè tó jẹ mọ́ àwọn ọ̀rọ̀ tó kọjá òye wọn.

Bí ìdáhùn ẹnì kan kò bá tọ̀nà ńkọ́? Ẹni tó ń darí ìpàdé kò gbọ́dọ̀ dójú ti ẹni tó sọ ìdáhùn tí kò tọ̀nà náà. Bí àwọn ìdáhùn kan ò bá tiẹ̀ tọ̀nà, òótọ́ díẹ̀ sábà máa ń wà níbẹ̀. Ẹni tó ń darí ìpàdé lè tún ìdáhùn náà ṣe láì kó ìtìjú bá ẹni tó sọ ọ́ nípa fífi ọgbọ́n tún ìdáhùn náà tò, tàbí kó tún béèrè ìbéèrè díẹ̀ sí i.

Tí ẹni tó ń darí ìpàdé bá fẹ́ káwọn èèyàn túbọ̀ dáhùn, ó gbọ́dọ̀ yẹra fáwọn ìbéèrè tí kò ṣe pàtó, irú bíi, ‘Ǹjẹ́ ẹlòmíràn ní ohun kan láti sọ?’ Èèyàn lè ní èrò rere lọ́kàn tó bá béèrè àwọn ìbéèrè bíi ‘Ta ni kò tí ì dáhùn o? Tí ó ò bá dáhùn nísinsìnyí, ó parí nìyẹn o!’ àmọ́ irú àwọn ìbéèrè bẹ́ẹ̀ kò lè fún èèyàn níṣìírí láti sọ èrò rẹ̀ jáde. Olùdarí kò gbọ́dọ̀ mú káwọn ará bẹ̀rẹ̀ sí lérò pé nǹkan burúkú gbáà làwọn ṣe báwọn ò bá tètè dáhùn nípàdé. Dípò ìyẹn, ńṣe ni ká fún wọn níṣìírí pé kí wọ́n ṣàjọpín ìmọ̀ wọn pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn nítorí pé èyí jẹ́ ọ̀nà kan téèyàn gbà ń fi ìfẹ́ hàn. Ní àfikún sí i, bí ẹni tó ń darí ìpàdé bá ti pe ẹnì kan pé kó dáhùn ìbéèrè, kò gbọ́dọ̀ tún sọ pé, “Lẹ́yìn rẹ̀, a óò gbọ́ ìdáhùn Arákùnrin lágbájá, lẹ́yìn náà ni Arábìnrin tàmẹ̀dù á wá fún wa ní ìdáhùn tirẹ̀.” Olùdarí gbọ́dọ̀ kọ́kọ́ gbọ́ ìdáhùn ẹni àkọ́kọ́, ìgbà náà ni yóò mọ̀ bóyá ó pọn dandan kí ẹlòmíràn tún dáhùn.

Dídáhùn Nípàdé Jẹ́ Àǹfààní

Lílọ sáwọn ìpàdé Kristẹni ṣe pàtàkì fún ire wa nípa tẹ̀mí. Dídáhùn níbẹ̀ jẹ́ àǹfààní. Bá a bá ṣe lọ́wọ́ tó nínú ọ̀nà aláìlẹ́gbẹ́ yìí tá a gbà ń yin Jèhófà “ní àárín ìjọ,” bẹ́ẹ̀ náà ni a ṣe ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Dáfídì tó, tá a sì ń fi ìmọ̀ràn Pọ́ọ̀lù sílò. Kíkópa nínú àwọn ìpàdé fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ àwọn arákùnrin wa àti pé a jẹ́ apá kan ìjọ ńlá Jèhófà. Ibo là bá tún máa lọ bí kò ṣe àwọn ìpàdé Kristẹni ‘bí a ti rí i pé ọjọ́ náà ń sún mọ́lé’?—Hébérù 10:25.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la tẹ̀ ẹ́ jáde.

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 20]

Fífetísílẹ̀ àti dídáhùn àwọn ìbéèrè ṣe pàtàkì láwọn ìpàdé Kristẹni

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 21]

Ó yẹ kí ẹni tó ń darí ìpàdé máa gbọ́ ìdáhùn ẹnì kọ̀ọ̀kan lágbọ̀ọ́yé