Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Kí ni gbólóhùn náà ní “ìyè nínú ara rẹ̀” túmọ̀ sí?

Bíbélì sọ pé Jésù Kristi ní “ìyè nínú ara rẹ̀,” ó sì tún sọ pé àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ní ‘ìyè nínú ara wọn.’ (Jòhánù 5:26; 6:53) Àmọ́ ṣá, ìtumọ̀ ẹsẹ Ìwé Mímọ́ méjèèjì yìí yàtọ̀ síra o.

Jésù sọ pé: “Gan-an gẹ́gẹ́ bí Baba ti ní ìyè nínú ara rẹ̀, bẹ́ẹ̀ náà ni ó ti yọ̀ǹda fún Ọmọ láti ní ìyè nínú ara rẹ̀.” Kó tó di pé Jésù sọ gbólóhùn tó gbàfiyèsí yìí, ó sọ pé: “Lóòótọ́-lóòótọ́ ni mo wí fún yin, Ẹni tí ó bá gbọ́ ọ̀rọ̀ mi, tí ó sì gba ẹni tí ó rán mi gbọ́, ní ìyè àìnípẹ̀kun . . . Wákàtí náà ń bọ̀, ìsinsìnyí sì ni, nígbà tí àwọn òkú yóò gbọ́ ohùn Ọmọ Ọlọ́run, àwọn tí wọ́n sì kọbi ara sí i yóò yè.” Níhìn-ín, Jésù ń sọ̀rọ̀ nípa agbára tó ju agbára lọ tí Baba rẹ̀ gbé lé e lọ́wọ́—ìyẹn agbára tó ń mú kí àwọn ẹ̀dá èèyàn lè jèrè ojú rere lọ́dọ̀ Ọlọ́run. Kò tán síbẹ̀ o, Jésù lágbára láti jí àwọn tó ti kú dìde kó sì fún wọn ní ìyè. Agbára tá a fún Jésù láti ṣe àwọn nǹkan wọ̀nyí ni gbólóhùn náà pé ó ní “ìyè nínú ara rẹ̀” túmọ̀ sí. Ọ̀nà mìíràn tá a tún lè gbà túmọ̀ gbólóhùn yìí ni pé, gẹ́gẹ́ bíi ti Baba, Ọmọ pẹ̀lú ní ‘ẹ̀bùn ìyè nínú ara rẹ̀.’ (Jòhánù 5:24-26) Àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ wá ń kọ́?

Ní nǹkan bí ọdún kan lẹ́yìn náà, Jésù sọ fáwọn tó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé: “Lóòótọ́-lóòótọ́ ni mo wí fún yín, láìjẹ́ pé ẹ jẹ ẹran ara Ọmọ ènìyàn, kí ẹ sì mu ẹ̀jẹ̀ rẹ̀, ẹ kò ní ìyè kankan nínú ara yín. Ẹni tí ó bá ń fi ẹran ara mi ṣe oúnjẹ jẹ, tí ó sì ń mu ẹ̀jẹ̀ mi ní ìyè àìnípẹ̀kun, èmi yóò sì jí i dìde ní ọjọ́ ìkẹyìn.” (Jòhánù 6:53, 54) Jésù fi hàn níbí yìí pé níní ‘ìyè nínú ara wọn’ àti níní “ìyè àìnípẹ̀kun” túmọ̀ sí ohun kan náà. Nínú ọ̀nà tá a gbà ń kọ gírámà èdè Gíríìkì, àwọn ọ̀rọ̀ tá a kọ lọ́nà kan náà tá a gbà kọ gbólóhùn náà ní “ìyè . . . nínú ara yín” wà láwọn ibòmíràn nínú Ìwé Mímọ́ lédè Gíríìkì. Àpẹẹrẹ méjì rèé: “Ẹ ní iyọ̀ nínú ara yín” àti “wọ́n sì ń gba èrè iṣẹ́ kíkún nínú ara wọn.” (Máàkù 9:50; Róòmù 1:27) Gbólóhùn méjèèjì yìí kò túmọ̀ sí pé àwọn tá a ń sọ̀rọ̀ wọn ní agbára láti fún àwọn ẹlòmíràn ní iyọ̀ tàbí láti san èrè iṣẹ́ ọwọ́ àwọn ẹlòmíràn fún wọn. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó túmọ̀ sí pé kí nǹkan pé pérépéré, kó kún rẹ́rẹ́. Nítorí náà, gbólóhùn náà “ìyè . . . nínú ara yín” tó wà nínú Jòhánù 6:53, túmọ̀ sí níní ìwàláàyè tó kún rẹ́rẹ́.

Lákòókò tí Jésù sọ pé àwọn ọmọ ẹ̀yìn òun ní ìyè nínú ara wọn, ó mẹ́nu ba ẹran ara àti ẹ̀jẹ̀ òun fúnra rẹ̀. Nígbà tó tún yá tí Jésù ń fi Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa lọ́lẹ̀, ó tún sọ̀rọ̀ nípa ẹran ara àti ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ ó sì sọ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ tó máa wọnú májẹ̀mú tuntun náà pé kí wọ́n jẹ nínú àwọn ohun ìṣàpẹẹrẹ náà tá a fi búrẹ́dì aláìwú àti wáìnì ṣe. Ǹjẹ́ èyí wá túmọ̀ sí pé kìkì àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró, tí wọ́n wà nínú májẹ̀mú tuntun náà pẹ̀lú Jèhófà Ọlọ́run, ló ní irú ìwàláàyè kíkún rẹ́rẹ́ bẹ́ẹ̀? Rárá o. Àkókò tí Jésù sọ gbólóhùn méjèèjì fi ọdún kan gbáko jìnnà síra. Àwọn èèyàn tó gbọ́ ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ tí àkọsílẹ̀ rẹ̀ wà nínú Jòhánù 6:53, 54, kò mọ ohunkóhun nípa fífi ohun ìṣàpẹẹrẹ tó dúró fún ẹran ara àti ẹ̀jẹ̀ Kristi ṣe ayẹyẹ ìrántí ọlọ́dọọdún.

Gẹ́gẹ́ bí ìwé Jòhánù orí kẹfà ṣe sọ, Jésù kọ́kọ́ fi ẹran ara rẹ̀ wé mánà, ó sọ pé: “Àwọn baba ńlá yín jẹ mánà ní aginjù, síbẹ̀ wọ́n kú. Èyí ni oúnjẹ tí ó sọ kalẹ̀ wá láti ọ̀run, kí ẹnikẹ́ni lè jẹ nínú rẹ̀, kí ó má sì kú. Èmi ni oúnjẹ ààyè tí ó sọ kalẹ̀ wá láti ọ̀run; bí ẹnikẹ́ni bá jẹ nínú oúnjẹ yìí, yóò wà láàyè títí láé.” Ẹran ara Jésù àti ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ níye lórí ju mánà lọ. Kí nìdí? Ìdí ni pé ẹran ara rẹ̀ tá a fúnni jẹ́ nítorí “ìyè ayé,” èyí tó mú kí ìyè àìnípẹ̀kun ṣeé ṣe. a Nítorí náà, gbólóhùn náà “ìyè . . . nínú ara yín,” tó wà nínú Jòhánù 6:53 ń sọ̀rọ̀ nípa gbogbo àwọn tó máa rí ìyè àìnípẹ̀kun—lókè ọ̀run tàbí lórí ilẹ̀ ayé.—Jòhánù 6:53, 48-51.

Ìgbà wo wá ni àwọn ọmọ ẹ̀yìn Kristi máa gba ìyè nínú ara wọn, tàbí tí wọ́n á ní ìwàláàyè tó kún rẹ́rẹ́? Ní ti àwọn ẹni àmì òróró tó máa jogún Ìjọba náà, èyí máa ṣẹlẹ̀ nígbà tá a bá jí wọn dìde sí ìwàláàyè lókè ọ̀run gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá ẹ̀mí tí kò lè kú. (1 Kọ́ríńtì 15:52, 53; 1 Jòhánù 3:2) Àwọn “àgùntàn mìíràn” Jésù máa ní ìwàláàyè tó kún rẹ́rẹ́ nígbà tó bá parí Ìṣàkóso Ẹlẹ́gbẹ̀rúndún rẹ̀. Tó bá fi máa dìgbà yẹn, àá ti dán wọn wò, àá sì ti rí i pé olóòótọ́ èèyàn ni wọ́n. Àá sì wá pè wọ́n ní olódodo pé wọ́n tóótun láti wà láàyè títí láé lórí ilẹ̀ ayé tó ti di Párádísè.—Jòhánù 10:16; Ìṣípayá 20:5, 7-10.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Nínú aginjù, gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì àti “àwùjọ onírúurú ènìyàn púpọ̀ jaburata” ló nílò mánà láti rí nǹkan jẹ kí wọ́n má bàa kú. (Ẹ́kísódù 12:37, 38; 16:13-18) Lọ́nà kan náà, láti wà láàyè títí láé, gbogbo Kristẹni, yálà wọ́n jẹ́ ẹni àmì òróró tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́, gbọ́dọ̀ jẹ mánà náà tó ti ọ̀run wá nípa lílo ìgbàgbọ́ nínú agbára tí ẹran ara àti ẹ̀jẹ̀ Jésù tá a fi rúbọ ní fún ìgbàlà ẹ̀dá èèyàn.Wo Ilé Ìṣọ́ February 1, 1988, ojú ìwé 30 àti 31.

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 31]

Gbogbo àwọn Kristẹni tòótọ́ lè ní ‘ìyè nínú ara wọn’