“Òfin Ọlọ́gbọ́n”—Jẹ́ Orísun Ìyè
“Òfin Ọlọ́gbọ́n”—Jẹ́ Orísun Ìyè
ÀPỌ́SÍTÉLÌ Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Ìjìnlẹ̀ àwọn ọrọ̀ àti ọgbọ́n àti ìmọ̀ Ọlọ́run mà pọ̀ o! Àwọn ìdájọ́ rẹ̀ ti jẹ́ àwámáridìí tó, àwọn ọ̀nà rẹ̀ sì ré kọjá àwákàn!” (Róòmù 11:33) Jóòbù baba ńlá olóòótọ́ nì náà sọ pé: “[Jèhófà Ọlọ́run] jẹ́ ọlọ́gbọ́n ní ọkàn-àyà.” (Jóòbù 9:4) Dájúdájú, kò sẹ́ni tó gbọ́n tó Ẹlẹ́dàá ọ̀run òun ayé. Kí la lè sọ nípa òfin irú Ẹlẹ́dàá bẹ́ẹ̀ tàbí nípa Ọ̀rọ̀ rẹ̀ tó wà lákọsílẹ̀?
Onísáàmù náà kọ ọ́ lórin pé: “Òfin Jèhófà pé, ó ń mú ọkàn padà wá. Ìránnilétí Jèhófà ṣeé gbẹ́kẹ̀ lé, ó ń sọ aláìní ìrírí di ọlọ́gbọ́n. Àwọn àṣẹ ìtọ́ni láti ọ̀dọ̀ Jèhófà dúró ṣánṣán, wọ́n ń mú ọkàn-àyà yọ̀; àṣẹ Jèhófà mọ́, ó ń mú kí ojú mọ́lẹ̀.” (Sáàmù 19:7, 8) Ẹ ò rí i pé Sólómọ́nì Ọba Ísírẹ́lì ìgbàanì ti ní láti mọ̀ pé òótọ́ pọ́ńbélé lọ̀rọ̀ yìí! Ó sọ pé: “Òfin ọlọ́gbọ́n jẹ́ orísun ìyè, láti yí ènìyàn padà kúrò nínú àwọn ìdẹkùn ikú.” (Òwe 13:14) Ní ẹsẹ mẹ́tàlá àkọ́kọ́ nínú orí kẹtàlá ìwé Òwe, Sólómọ́nì fi hàn bí ìmọ̀ràn inú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ láti mú kí ìgbésí ayé wa sunwọ̀n sí i, ká sì yẹra fún ewu.
Máa Gba Ẹ̀kọ́
Òwe 13:1 sọ pé: “Ọmọ a jẹ́ ọlọ́gbọ́n níbi tí ìbáwí baba bá wà, ṣùgbọ́n olùyọṣùtì ni èyí tí kò gbọ́ ìbáwí mímúná.” Ìbáwí látọ̀dọ̀ baba kan lè rọ̀ tàbí kí ó le. Ó lè kọ́kọ́ dà bí ẹ̀kọ́, téèyàn ò bá wá gbà á, ó lè wá yọrí sí ìjìyà níkẹyìn. Ọmọ tó bá tẹ́wọ́ gba ìbáwí baba rẹ̀ ni ọlọ́gbọ́n.
Bíbélì sọ pé: “Ẹni tí Jèhófà nífẹ̀ẹ́ ni ó máa ń bá wí; ní ti tòótọ́, ó máa ń na olúkúlùkù ẹni tí ó gbà gẹ́gẹ́ bí ọmọ lọ́rẹ́.” (Hébérù 12:6) Ọ̀kan lára ọ̀nà tí Baba wa ọ̀run gbà ń bá wa wí jẹ́ nípasẹ̀ Bíbélì tí í ṣe Ọ̀rọ̀ rẹ̀. Nígbà tá a bá ka Bíbélì tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀, tá a sì fi ohun tá a kọ́ níbẹ̀ sílò, Ọ̀rọ̀ rẹ̀ ń bá wa wí nìyẹn. Ire wa lèyí máa ń já sí, nítorí pé gbogbo ohun tí Jèhófà bá sọ ló máa ń ṣe wá láǹfààní.—Aísáyà 48:17.
Ìbáwí tún lè wá gẹ́gẹ́ bí ìtọ́sọ́nà látọ̀dọ̀ onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wa tó ń wá ire wa nípa tẹ̀mí. Ìmọ̀ràn èyíkéyìí tó wúlò tó sì wà níbàámu pẹ̀lú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni a gbà pé kò wá látọ̀dọ̀ ènìyàn. Àtọ̀dọ̀ Ọlọ́run tó jẹ́ Orísun òtítọ́ ló ti ń wá. Ọlọ́gbọ́n la jẹ́ tá a bá gbà á gẹ́gẹ́ bí èyí tó wá látọ̀dọ̀ Jèhófà. Nígbà tá a bá ṣe ìyẹn, tá a sì jẹ́ kó darí èrò wa, tá a jẹ́ kó túbọ̀ mú ká lóye Ìwé Mímọ́ sí i, tó sì mú àwọn ọ̀nà wa tọ́, a ń jàǹfààní nínú ìbáwí náà nìyẹn. Bí àwọn ìmọ̀ràn tá a ń rí gbà láwọn ìpàdé Kristẹni àti látinú àwọn ìtẹ̀jáde tá a gbé karí Bíbélì ṣe rí gan-an nìyẹn. Fífi àwọn ọ̀rọ̀ tó wà lákọsílẹ̀ wọ̀nyí àtàwọn èyí tá a ń gbọ́ sílò jẹ́ ọ̀nà tó dára jù lọ láti bá ara ẹni wí.
Àmọ́, olùyọṣùtì kì í gba ìbáwí. Ìwé kan tá a ṣèwádìí nínú rẹ̀ sọ pé: “Kò gba ẹ̀kọ́ nítorí ó
rò pé òun gbọ́n tán.” Kò tiẹ̀ kọbi ara sí ìbáwí mímúná pàápàá, ìyẹn ìbáwí tó le koko. Àmọ́, ǹjẹ́ ó lè sọ pé ìbáwí tí Baba òun fún òun kò tọ̀nà? Jèhófà kò ṣàì tọ̀nà rí, kò sì ní ṣàì tọ̀nà láé. Nípa kíkọ ìbáwí, ńṣe ni olùyọṣùtì náà wulẹ̀ ń sọ ara rẹ̀ di ẹni yẹ̀yẹ́. Pẹ̀lú àṣàyàn ọ̀rọ̀ díẹ̀ yìí, ẹ wo ọ̀nà rèǹtèrente tí Sólómọ́nì gbà fi hàn pé ó ṣe pàtàkì láti gba ẹ̀kọ́!Máa Ṣọ́ Ahọ́n Rẹ!
Láti fi hàn pé ó ṣe pàtàkì láti jẹ́ kí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run máa darí ohun tó ń ti ẹnu wa jáde, ọba Ísírẹ́lì yìí fi ẹnu wé igi tó ń so èso. Ó sọ pé: “Ènìyàn yóò jẹ ohun tí ó dára láti inú èso ẹnu rẹ̀, ṣùgbọ́n ọkàn àwọn tí ń ṣe àdàkàdekè jẹ́ ìwà ipá.” (Òwe 13:2) Àwọn ọ̀rọ̀ tá a máa ń sọ ni èso ẹnu. Èèyàn á sì jèrè ohun tó bá fi ẹnu ara rẹ̀ sọ. Ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ kan sọ pé: “Bí ọ̀rọ̀ ẹnì kan bá tuni lára, tó sì sọ ọ́ di ọ̀rẹ́ àwọn aládùúgbò rẹ̀, onítọ̀hún yóò jẹ ohun tó dára, ìgbésí ayé rẹ̀ á dùn, ọkàn rẹ̀ á sì balẹ̀.” Àmọ́ ọ̀ràn ti aládàkàdekè ò rí bẹ́ẹ̀ rárá. Ó fẹ́ hu ìwà ipá kó sì ṣe àwọn ẹlòmíràn léṣe. Ìwà ìkà ló máa ń gbìn, á sì ká ìwà ìkà. Ìdẹkùn ikú wà ní ẹnu ọ̀nà rẹ̀.
Sólómọ́nì ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ pé:“Ẹni tí ń ṣọ́ ẹnu rẹ̀ ń pa ọkàn ara rẹ̀ mọ́. Ẹni tí ń ṣí ètè rẹ̀ sílẹ̀ gbayawu—ìparun yóò jẹ́ tirẹ̀.” (Òwe 13:3) Sísọ̀rọ̀ òmùgọ̀ jáde láìronú lè ba orúkọ rere èèyàn jẹ́, ó lè múnú bíni, ó lè ba àárín ọ̀rẹ́ jẹ́, ó tiẹ̀ lè fa ìjà pàápàá. Kéèyàn lanu sọ̀rọ̀ láìronú tún lè fa ìbínú Ọlọ́run, nítorí olúkúlùkù ni yóò jíhìn ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ̀ níwájú Ọlọ́run. (Mátíù 12:36, 37) Láìsí àní-àní, ṣíṣàkóso ẹnu wa yóò gbà wá lọ́wọ́ ìparun. Àmọ́, báwo la ṣe fẹ́ kọ́ bí a ó ṣe máa ṣàkóso ẹnu wa?
Ọ̀nà kan tá a lè gbà ṣe èyí ni pé ká má máa sọ̀rọ̀ jù. Bíbélì sọ pé: “Nínú ọ̀pọ̀ yanturu ọ̀rọ̀ kì í ṣàìsí ìrélànàkọjá.” (Òwe 10:19) Ọ̀nà mìíràn ni pé kéèyàn máa ronú kó tó sọ̀rọ̀. Òǹkọ̀wé tí a mí sí náà polongo pé: “Ẹnì kan wà tí ń sọ̀rọ̀ láìronú bí ẹni pé pẹ̀lú àwọn ìgúnni idà.” (Òwe 12:18) Téèyàn ò bá ronú kó tó sọ̀rọ̀, ohun tó ń sọ lè pa òun àtàwọn olùgbọ́ rẹ̀ lára. Abájọ tí Bíbélì fi fún wa ní ìmọ̀ràn gbígbéṣẹ́ yìí pé: “Ọkàn-àyà olódodo máa ń ṣe àṣàrò láti lè dáhùn.”—Òwe 15:28.
Jẹ́ Aláápọn
Sólómọ́nì sọ pé: “Ọ̀lẹ ń fọkàn fẹ́, ṣùgbọ́n ọkàn rẹ̀ kò ní nǹkan kan. Bí ó ti wù kí ó rí, àní ọkàn àwọn ẹni aláápọn ni a óò mú sanra.” (Òwe 13:4) Ìwé kan tá a ṣèwádìí nínú rẹ̀ sọ pé: “Kókó [inú òwe yìí] ni pé asán lórí asán ni kí ohun rere máa wuni, kí onítọ̀hún má sì tẹpá mọ́ṣẹ́. Ńṣe ni ohun rere máa ń wu ọ̀lẹ ṣáá . . . , kò sì fẹ́ ṣiṣẹ́.” Àmọ́ àwọn tó jẹ́ aláápọn máa ń rí ohun tó wu ọkàn wọn tàbí ohun tí wọ́n fẹ́—ìyẹn ni pé a ń mú ọkàn wọn sanra.
Kí la lè sọ nípa tàwọn tí kò fẹ́ ya ara wọn sí mímọ́ fún Jèhófà nítorí ká má bàa gbé ẹrù iṣẹ́ lé wọn lọ́wọ́? Ó lè máa wù wọ́n láti gbé nínú ayé tuntun Ọlọ́run, àmọ́ ǹjẹ́ wọ́n múra tán láti ṣe ohun tó máa mú wọn débẹ̀? Ohun táwọn tó “jáde wá láti inú ìpọ́njú ńlá” ṣe ni pé wọ́n lo ìgbàgbọ́ nínú ẹbọ ìràpadà Jésù, wọ́n ya ara wọn sí mímọ́ fún Jèhófà, wọ́n sì fi ẹ̀rí ìyàsímímọ́ wọn hàn nípa ṣíṣe ìrìbọmi.—Ìṣípayá 7:14, 15.
Tún ṣàgbéyẹ̀wò ohun téèyàn gbọ́dọ̀ ṣe láti tóótun fún ipò alábòójútó nínú ìjọ. Ohun tó dára gan-an ni kéèyàn fẹ́ kóun tóótun fún iṣẹ́ 1 Tímótì 3:1) Àmọ́ kó wulẹ̀ máa wuni láti dé ipò yìí nìkan kò tó. Títóótun fún ipò kan ń béèrè pé kéèyàn ní àwọn ànímọ́ kan kó sì lágbára láti ṣe iṣẹ́ náà. Ìyẹn sì gba ìsapá tá a fi gbogbo ara ṣe.
àtàtà yìí, Ìwé Mímọ́ sì fúnni níṣìírí láti ṣe bẹ́ẹ̀. (Òdodo Ń Dáàbò Boni
Olódodo máa ń ní àwọn ànímọ́ tí Ọlọ́run fẹ́, ó sì máa ń sọ òtítọ́. Ó mọ̀ pé irọ́ pípa lòdì sí òfin Jèhófà. (Òwe 6:16-19; Kólósè 3:9) Nígbà tí Sólómọ́nì ń sọ̀rọ̀ nípa ọ̀ràn yìí, ó ní: “Àwọn olódodo kórìíra ọ̀rọ̀ èké, ṣùgbọ́n àwọn ẹni burúkú ń hùwà lọ́nà tí ń tini lójú, wọ́n sì ń fa ìtìjú bá ara wọn.” (Òwe 13:5) Yàtọ̀ sí pé olódodo kì í parọ́; ó tún kórìíra rẹ̀ bí ìgbẹ́ pẹ̀lú. Ó mọ̀ pé bó ti wù kí irọ́ dà bí ohun tí kò lè pani lára, ó máa ń bá àjọṣe ẹ̀dá jẹ́ ni. Jù bẹ́ẹ̀ lọ, ìgbọ́kànlé táwọn èèyàn ní nínú ẹni tó sọ ara rẹ̀ di òpùrọ́ yóò pòórá. Ẹni ibi máa ń hùwà ìtìjú, yálà nípa píparọ́ tàbí láwọn ọ̀nà mìíràn, yóò sì tipa bẹ́ẹ̀ kó ìtìjú bá ara rẹ̀.
Láti fi hàn pé ṣíṣe ohun tí ó tọ́ lójú Ọlọ́run ń ṣeni láǹfààní, ọba ọlọ́gbọ́n náà sọ pé: “Òdodo ń fi ìṣọ́ ṣọ́ ẹni tí ó jẹ́ aláìlè-panilára ní ọ̀nà rẹ̀, ṣùgbọ́n ìwà burúkú ni ohun tí ń dojú ẹlẹ́ṣẹ̀ dé.” (Òwe 13:6) Gẹ́gẹ́ bí ibi ìsádi, òdodo máa ń dáàbò boni, àmọ́ ńṣe ni ìwà ibi máa ń pani run.
Má Ṣe Díbọ́n
Láti fi hàn pé òun mọ bí ẹ̀dá èèyàn ṣe ń hùwà, ọba Ísírẹ́lì yìí sọ pé: “Ẹnì kan wà tí ń díbọ́n pé òun jẹ́ ọlọ́rọ̀, síbẹ̀síbẹ̀ kò ní nǹkan kan rárá; ẹnì kan wà tí ń díbọ́n pé òun jẹ́ aláìnílọ́wọ́, síbẹ̀síbẹ̀ ó ní ọ̀pọ̀ ohun tí ó níye lórí.” (Òwe 13:7) Ẹnì kan lè máà jẹ́ ohun táwọn èèyàn rò pé ó jẹ́. Àwọn tálákà kan lè máa ṣe bí olówó—bóyá nípa ṣíṣe àṣehàn, káwọn èèyàn lè máa rò pé wọ́n rí já jẹ, tàbí nítorí káwọn èèyàn lè máa wárí fún wọn. Ọlọ́rọ̀ lè máa díbọ́n pé òtòṣì lòun káwọn èèyàn má bàa mọ̀ pé ó lówó.
Kò sí èyí tó dára nínú kéèyàn máa ṣe àṣehàn tàbí kó máa fi ohun tó jẹ́ pa mọ́. Tí a kò bá fi bẹ́ẹ̀ rí já jẹ, kíkó owó lórí àwọn nǹkan ńláńlá káwọn èèyàn lè máa kà wá sí olówó lè sọ àwa àti ìdílé wa di ẹni tí kò ní àwọn ohun kòṣeémánìí ìgbésí ayé. Téèyàn bá sì ń díbọ́n pé òtòṣì lòun nígbà tó jẹ́ olówó, ìyẹn lè sọ onítọ̀hún di ahun, ó sì lè jẹ́ kó pàdánù iyì àti ayọ̀ tí ìwà ọ̀làwọ́ máa ń mú wá. (Ìṣe 20:35) Sísọ bá a ṣe jẹ́ gan-an máa ń jẹ́ kí ìgbésí ayé èèyàn dára.
Ṣe Bó O Ti Mọ
Sólómọ́nì sọ pé: “Ìràpadà ọkàn ènìyàn ni ọrọ̀ rẹ̀, ṣùgbọ́n ẹni tí ó jẹ́ aláìnílọ́wọ́ kò gbọ́ ìbáwí mímúná.” (Òwe 13:8) Ẹ̀kọ́ wo la rí kọ́ nínú ọ̀rọ̀ ọlọ́gbọ́n yìí?
Àǹfààní wà nínú jíjẹ́ ọlọ́rọ̀, àmọ́ kì í ṣe gbogbo ìgbà ni ọrọ̀ máa ń fúnni láyọ̀. Nínú ayé eléwu tá a ń gbé yìí, ọ̀pọ̀ ìgbà ni wọ́n máa ń jí àwọn olówó àtàwọn ìdílé wọn gbé, tí wọ́n á sì ní kí wọ́n wá san iye kan kí wọ́n tó dá wọn sílẹ̀. Nígbà mìíràn, ńṣe ni olówó máa san iye kan láti ra ẹ̀mí ara rẹ̀ tàbí ti ẹnì kan nínú ìdílé rẹ̀ padà. Àmọ́ lọ́pọ̀ ìgbà, pípa làwọn ajínigbé máa ń pa àwọn tí wọ́n bá jí gbé. Àwọn olówó ló sì máa ń bára wọn nínú irú ewu yẹn.
Irú ìdààmú bẹ́ẹ̀ kò sí fáwọn tí kò rí já jẹ. Wọ́n lè máà ní àwọn ohun amáyédẹrùn àti ọrọ̀ àlùmọ́ọ́nì bíi tàwọn ọlọ́rọ̀ o, àmọ́ àwọn ajínigbé kì í fi bẹ́ẹ̀ lépa wọn. Ọ̀kan lára àǹfààní kéèyàn ṣe bó ti mọ nìyí, ká má sì máa lo gbogbo àkókò àti agbára wa lórí lílépa ọrọ̀.—2 Tímótì 2:4.
Máa Yọ̀ Nínú “Ìmọ́lẹ̀”
Sólómọ́nì ń bá a lọ láti fi hàn pé ṣíṣe àwọn nǹkan lọ́nà Jèhófà ló lè ṣe wá láǹfààní jù lọ. Ó sọ pé: “Àní ìmọ́lẹ̀ àwọn olódodo yóò yọ̀; ṣùgbọ́n fìtílà àwọn ẹni burúkú—a óò fẹ́ ẹ pa.”—Òwe 13:9.
Fìtílà dúró fún ohun tá a gbára lé láti tan ìmọ́lẹ̀ sí ipa ọ̀nà wa nínú ìgbésí ayé. ‘Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run jẹ́ fìtílà fún ẹsẹ olódodo, àti ìmọ́lẹ̀ sí òpópónà rẹ̀.’ (Sáàmù 119:105) Ó ní arabarìbì ìmọ̀ àti ọgbọ́n Ẹlẹ́dàá wa nínú. Bí òye tá a ní nípa ìfẹ́ àti ohun tí Ọlọ́run fẹ́ ṣe bá ṣe túbọ̀ ń pọ̀ sí i bẹ́ẹ̀ náà ni ìmọ́lẹ̀ tẹ̀mí tó ń tọ́ wa sọ́nà yóò túbọ̀ máa mọ́lẹ̀ sí i. Èyí sì máa ń fúnni láyọ̀ tó pọ̀! Èé ṣe tá a ó fi wá jẹ́ kí ọgbọ́n ayé tàbí ohun “tí a fi èké pè ní ‘ìmọ̀’” gba àfiyèsí wa?—1 Tímótì 6:20; 1 Kọ́ríńtì 1:20; Kólósè 2:8.
Ní ti ẹni ibi, bó ti wù kó jọ pé fìtílà rẹ̀ mọ́lẹ̀ tó tàbí bó ti wù kó dà bíi pé nǹkan ṣẹnuure fún un tó, fìtílà rẹ̀ máa kú pii. Inú òkùnkùn biribiri ló ti máa bá ara rẹ̀ níbi tó ti máa fẹsẹ̀ kọ. Ìyẹn nìkan kọ́ o, “kì yóò sí ọjọ́ ọ̀la” fún un pẹ̀lú.—Òwe 24:20.
Àmọ́ ṣá o, kí la lè ṣe tá a bá ń ṣiyèméjì lórí ohun tó yẹ ká ṣe lórí ọ̀ràn kan? Tí kò bá dá wa lójú bóyá a lẹ́tọ̀ọ́ láti ṣe ohunkóhun lórí ọ̀ràn náà ńkọ́? Òwe 13:10 kìlọ̀ fún wa pé: “Nípasẹ̀ ìkùgbù, kìkì ìjàkadì ni ẹnì kan ń dá sílẹ̀.” Téèyàn bá kù gìrì ṣe ohun tí kò mọ̀ tàbí tí kò lẹ́tọ̀ọ́ láti ṣe, ìkùgbù tí í ṣe ìkọjá àyè ẹni nìyẹn, ó sì lè fa ìṣòro láàárín àwa àtàwọn ẹlòmíràn. Ǹjẹ́ kò ní dára kí á lọ bá àwọn ẹlòmíràn tó ní ìmọ̀ àti òye tó jinlẹ̀ lórí ọ̀ràn náà? Ọlọ́gbọ́n ọba náà sọ pé: “Ọgbọ́n wà pẹ̀lú àwọn tí ń fikùn lukùn.”
Ṣọ́ra fún Ìrètí Tí Kò Ṣeé Gbára Lé
Owó wúlò gan-an. Níní owó tí ó pọ̀ tó láti ná sàn ju kéèyàn jẹ́ akúùṣẹ́ lọ. (Oníwàásù 7:11, 12) Àmọ́ àǹfààní téèyàn rò pé òun á rí nínú owó bìrìbìrì lè jẹ́ ẹ̀tàn. Sólómọ́nì kìlọ̀ fúnni pé: “Àwọn ohun oníyelórí tí ó ti inú asán wá a máa kéré sí i níye, ṣùgbọ́n ẹni tí ń fi ọwọ́ kó jọ ni ẹni tí yóò máa pọ̀ sí i.”—Òwe 13:11.
Bí àpẹẹrẹ, ronú lórí bí tẹ́tẹ́ títa ṣe máa ń tanni jẹ. Ẹni tó ń ta tẹ́tẹ́ lè ná gbogbo owó tó fi òógùn ojú rẹ̀ kó jọ lérò pé òun á jẹ owó gọbọi. Owó tíì bá fi gbọ́ bùkátà ìdílé rẹ̀ ló sì máa ń ná lọ́pọ̀ ìgbà! Tí ẹni tó ń ta tẹ́tẹ́ náà bá wá jẹ ńkọ́? Kò lè mọyì owó náà nítorí pé kò làágùn kó tó rí i. Àti pé ó lè má mọ bí òun ṣe máa ná owó òjijì yìí. Ǹjẹ́ ọrọ̀ tó ní yìí kò ní lọ lójijì bó ṣe wá lójijì? Ní òdìkejì ẹ̀wẹ̀, ọrọ̀ téèyàn kó jọ ní ení tere èjì tere nípa ṣíṣe iṣẹ́ àṣekára—máa ń pọ̀ sí i, èèyàn á sì lò ó lọ́nà tó ṣàǹfààní.
Sólómọ́nì sọ pé: “Ìfojúsọ́nà tí a sún síwájú ń mú ọkàn-àyà ṣàìsàn, ṣùgbọ́n igi ìyè ni ohun tí a fọkàn fẹ́ nígbà tí ó bá dé ní ti tòótọ́.” (Òwe 13:12) Ìjákulẹ̀ gbáà ló máa ń jẹ́ téèyàn ò bá rí ohun tó ń retí, ìyẹn sì máa ń mú ọkàn ṣàìsàn. Ojoojúmọ́ lèyí máa ń ṣẹlẹ̀. Àmọ́ kò ní rí bẹ́ẹ̀ táwọn ohun tá a ń retí bá jẹ́ èyí tá a gbé karí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. A lè ní ìgbẹ́kẹ̀lé kíkún pé wọ́n yóò ní ìmúṣẹ. Tó bá tiẹ̀ dà bí èyí tó pẹ́ pàápàá, kò ní fa ìjákulẹ̀.
Bí àpẹẹrẹ, a mọ̀ pé ayé tuntun Ọlọ́run ti sún mọ́lé. (2 Pétérù 3:13) Tayọ̀tayọ̀ lara wa fi wà lọ́nà láti rí ìmúṣẹ àwọn ìlérí Ọlọ́run. Ní àkókò tá a fi ń dúró yìí, ǹjẹ́ kò ní dára ká jẹ́ kí ọwọ́ wa dí “nínú iṣẹ́ Olúwa,” ká máa gba àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wa níyànjú, kí àjọṣe àárín àwa àti Jèhófà sì lágbára sí i? Dípò kí ‘ọkàn wa máa ṣàárẹ̀,’ ayọ̀ ló máa kún inú ọkàn wa. (1 Kọ́ríńtì 15:58; Hébérù 10:24, 25; Jákọ́bù 4:8) Tí ọwọ́ wa bá tẹ ohun tá a ń retí látọjọ́ pípẹ́, igi ìyè ló máa jẹ́—tó ń fúnni lókun tó sì ń tuni lára.
Òfin Ọlọ́run Jẹ́ Orísun Ìyè
Nígbà tí ìwé Òwe 13:13 ń sọ ìdí tó fi yẹ ká máa ṣègbọràn sí Ọlọ́run, ó ní: “Ẹni tí ó tẹ́ńbẹ́lú ọ̀rọ̀ náà, ohun ìdógò ajigbèsè ni a ó fi ipá gbà lọ́wọ́ rẹ̀; ṣùgbọ́n ẹni tí ó bẹ̀rù àṣẹ ni ẹni tí a ó san lẹ́san.” Bí ẹni tó jẹ gbèsè bá kùnà láti san owó tó jẹ, yóò pàdánù ohun tó fi dúró. Bẹ́ẹ̀ làwa náà ṣe máa pàdánù tá a bá kùnà láti pa àwọn àṣẹ Ọlọ́run mọ́. Irú àdánù wo nìyẹn?
“Òfin ọlọ́gbọ́n jẹ́ orísun ìyè, láti yí ènìyàn padà kúrò nínú àwọn ìdẹkùn ikú.” (Òwe 13:14) Tí a kò bá pa òfin Jèhófà, Ọlọ́run tó jẹ́ ọlọ́gbọ́n gbogbo mọ́, a ò ní rí ìtọ́sọ́nà tó lè ràn wá lọ́wọ́ láti gbé ìgbésí ayé tó dára tá á sì jẹ́ kí ẹ̀mí wa gùn. Àdánù ńlá mà nìyẹn o! Nítorí náà, ohun tó bọ́gbọ́n mu jù lọ fún wa láti ṣe ni pé ká máa kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ká sì máa ṣe àṣàrò lórí rẹ̀, ká jẹ́ kó máa darí èrò, ọ̀rọ̀, àti ìṣe wa.—2 Kọ́ríńtì 10:5; Kólósè 1:10.
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]
Fífi àwọn ìmọ̀ràn inú Ìwé Mímọ́ sílò jẹ́ ọ̀nà tó dára jù lọ láti bá ara ẹni wí
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24, 25]
“Ọkàn-àyà olódodo máa ń ṣe àṣàrò láti lè dáhùn”
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24, 25]
Jíjẹ́ kí ọwọ́ wa dí “nínú iṣẹ́ Olúwa” ń fún wa láyọ̀