Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Bó O Ṣe Lè Mú Kí Ìdè Ìgbéyàwó Rẹ Lágbára Sí I

Bó O Ṣe Lè Mú Kí Ìdè Ìgbéyàwó Rẹ Lágbára Sí I

Bó O Ṣe Lè Mú Kí Ìdè Ìgbéyàwó Rẹ Lágbára Sí I

FOJÚ inú wo ilé kan tó ń fẹ́ àtúnṣe nítorí pé a ti pa á tì. Ọ̀dà ara rẹ̀ ti bẹ̀rẹ̀ sí ṣí, òrùlé rẹ̀ ti ń jò, igbó sì ti kún dí ilé náà. Òjò ti pa á, oòrùn náà ti pa á, àwọn èèyàn kò sì bójú tó ilé náà mọ́. Ṣé ká wá wo ilé náà dànù ni? Èyí lè má pọn dandan. Bí ìpìlẹ̀ rẹ̀ bá ṣì dúró dáadáa, tí ilé náà kò sì tíì di hẹ́gẹhẹ̀gẹ, a jẹ́ pé a ṣì lè tún un ṣe.

Ṣé ipò tí ilé tá a fi ṣàpèjúwe yìí wà jọ ipò tí ìgbéyàwó rẹ wà? Láti àwọn ọdún wọ̀nyí wá, ó ṣeé ṣe kí àwọn ìṣòro tó dà bí ìjì ti nípa lórí ìgbéyàwó rẹ. Ẹ lè ti pa ara yín tì dé ìwọ̀n àyè kan. Ọ̀ràn yín lè dà bíi ti Sandy. Lẹ́yìn ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún tó ti wà nílé ọkọ, ó sọ pé: “A kò bá ara wa mu rárá, a kàn fẹ́ ara wa ni. Kò sì yẹ kó rí bẹ́ẹ̀.”

Kódà bí ìgbéyàwó rẹ bá ti rí bí èyí tá a ń sọ yìí, má ṣe kù gìrì sọ pé kí ẹ tú u ká. Ìgbéyàwó rẹ ṣì lè ní àtúnṣe. Àtúnṣe yìí sinmi lórí irú ọwọ́ tí ẹ̀yin méjèèjì bá fi mú àdéhùn ìgbéyàwó yín. Bí ẹ̀yin méjèèjì bá fi ọwọ́ gidi mú àdéhùn ìgbéyàwó yín, èyí kò ní jẹ́ kó túká lákòókò ìṣòro. Báwo ni Bíbélì ṣe lè ràn ọ́ lọ́wọ́ láti fi ọwọ́ gidi mú àdéhùn ìgbéyàwó rẹ?

Àdéhùn Ìgbéyàwó Ń Mú Iṣẹ́ Lọ́wọ́

Ẹ̀jẹ́ ìgbéyàwó túmọ̀ sí kéèyàn fi gbogbo ọkàn dúró lórí àdéhùn tó ṣe. Nígbà mìíràn, ẹnì kan lè pinnu láti dúró lórí àdéhùn tó ṣe nípa ohun kan, irú bí àdéhùn nípa iṣẹ́ ajé. Bí àpẹẹrẹ, bí kọ́lékọ́lé kan bá kọwọ́ bọ ìwé àdéhùn láti kọ́ ilé kan, ó di dandan kó mú àdéhùn náà ṣẹ. Ìyẹn ni pé kó kọ́ ilé náà ní àkọ́yanjú. Ó lè máà mọ ẹni tó ni ilé náà sójú, àmọ́ ó di dandan pé kó mú àdéhùn náà ṣẹ.

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀ràn ìgbéyàwó kò dà bí iṣẹ́ ìkọ́lé tá a mẹ́nu kàn lókè yìí, àdéhùn inú rẹ̀ mú iṣẹ́ lọ́wọ́. Ó ṣeé ṣe kí ìwọ àti ọkọ tàbí aya rẹ ti jẹ́jẹ̀ẹ́ níwájú Ọlọ́run àti èèyàn pé èkùrọ́ ni alábàákú ẹ̀wà, pé ẹ kò ní fi ara yín sílẹ̀ láé. Jésù sọ pé: “Ẹni tí ó dá [ọkùnrin àti obìnrin] láti ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ṣe wọ́n ní akọ àti abo, ó sì wí pé, ‘Nítorí ìdí yìí ọkùnrin yóò fi baba rẹ̀ àti ìyá rẹ̀ sílẹ̀, yóò sì fà mọ́ aya rẹ̀.’” Jésù tún fi kún un pé: “Ohun tí Ọlọ́run ti so pọ̀, kí ènìyàn kankan má ṣe yà á sọ́tọ̀.” (Mátíù 19:4-6) Bí ìṣòro bá dé, ìwọ àti ọkọ tàbí aya rẹ gbọ́dọ̀ dúró gbọn-in lórí àdéhùn tẹ́ ẹ jọ ṣe. a Ìyàwó kan sọ pé: “Ìgbà tá a jáwọ́ nínú sísọ pé àfi tá a bá kọ ara wa sílẹ̀ la tó bẹ̀rẹ̀ sí rí ojútùú sáwọn ìṣòro wa.”

Bó ti wù kó rí, ohun tó wà nínú àdéhùn ìgbéyàwó ju kéèyàn kàn gbà pé ojúṣe òun ló jẹ́. Ohun mìíràn wo ló tún wà níbẹ̀?

Ìfọwọ́sowọ́pọ̀ Ń Fún Àdéhùn Ìgbéyàwó Lókun

Àdéhùn ìgbéyàwó kò túmọ̀ sí pé èdèkòyédè kò ní wáyé láàárín tọkọtaya. Bí èdèkòyédè bá ṣẹlẹ̀, ohun tó yẹ kó wà lọ́kàn ọkọ àti aya ni bí wọ́n ṣe máa yanjú rẹ̀ ní kíákíá. Kì í ṣe nítorí ẹ̀jẹ́ tí wọ́n jẹ́ nìkan o, àmọ́ nítorí ìfẹ́ àtọkànwá tí wọ́n ní sí ara wọn. Jésù sọ̀rọ̀ nípa àwọn tọkọtaya, ó ní: “Wọn kì í ṣe méjì mọ́, bí kò ṣe ara kan.”

Kí ni jíjẹ́ tí ìwọ àti ọkọ tàbí aya rẹ jẹ́ “ara kan” túmọ̀ sí? Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé “ó yẹ kí àwọn ọkọ máa nífẹ̀ẹ́ àwọn aya wọn gẹ́gẹ́ bí ara àwọn fúnra wọn.” (Éfésù 5:28, 29) Lọ́nà kan, ó túmọ̀ sí pé kí ire ọkọ tàbí aya rẹ máa jẹ ọ́ lọ́kàn bíi tìrẹ fúnra rẹ. Àwọn lọ́kọláya gbọ́dọ̀ yí bí wọ́n ṣe ń ronú padà. Dípò sísọ pé kiní yìí jẹ́ “tèmi,” kí wọ́n máa sọ pé kiní yìí jẹ́ “tiwa.” Dípò “èmi” kí wọ́n máa sọ pé “àwa.” Olùgbani-nímọ̀ràn kan sọ pé: “Àwọn tọkọtaya náà gbọ́dọ̀ ṣíwọ́ ríronú bí àpọ́n, kí wọ́n máa ronú bí ẹni tó ti ṣègbéyàwó.”

Ǹjẹ́ ìwọ àti ọkọ tàbí aya rẹ máa ń ronú bí ẹni tó ti “ṣègbéyàwó”? Ó ṣeé ṣe kẹ́ ẹ jọ máa gbé pọ̀ fún ọ̀pọ̀ ọdún, síbẹ̀ kẹ́ ẹ máà jẹ́ “ara kan” tí ẹ kì í bá ronú bí ẹni tó ti ṣègbéyàwó. Ó lè ṣẹlẹ̀ bẹ́ẹ̀ o, àmọ́ ìwé Giving Time a Chance sọ pé: “Ìgbéyàwó túmọ̀ sí ṣíṣe nǹkan pa pọ̀, bí èèyàn méjì bá sì ṣe ń ṣe nǹkan pa pọ̀ tó, ni ìgbésí ayé wọn á ṣe lójú tó.”

Àwọn lọ́kọláya kan tí àárín wọn kò gún ṣì ń gbé pọ̀ nítorí tàwọn ọmọ wọn tàbí nítorí àtirí owó gbọ́ bùkátà. Àwọn mìíràn ń rún ọ̀ràn náà mọ́ra nítorí pé wọn kò nífẹ̀ẹ́ sí ìkọ̀sílẹ̀ rárá tàbí nítorí ohun táwọn èèyàn á sọ tí wọ́n bá kọ ara wọn sílẹ̀. Lóòótọ́, ohun tó dára ni pé kí ìgbéyàwó wà pẹ́ títí, àmọ́ ohun tó yẹ kó wà lọ́kàn yín ni pé kí ìfẹ́ jọba nínú ìgbéyàwó yín. Kì í ṣe pé kẹ́ ẹ sáà ti wà pa pọ̀.

Àìmọtara-Ẹni-Nìkan Ń Fún Àdéhùn Ìgbéyàwó Lókun

Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ pé ní “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn,” àwọn èèyàn á jẹ́ “olùfẹ́ ara wọn.” (2 Tímótì 3:1, 2) Gẹ́gẹ́ bí àsọtẹ́lẹ̀ yẹn ṣe sọ, ohun tó wọ́pọ̀ lónìí ni pé ńṣe làwọn èèyàn ń sọ ara wọn di òrìṣà àkúnlẹ̀bọ. Nínú ọ̀pọ̀ ìgbéyàwó, òmùgọ̀ ni wọ́n ń pe ẹni tó bá ń fi gbogbo ara ṣe fún ẹnì kejì rẹ̀ láìretí pé kí onítọ̀hún san án padà. Àmọ́ ẹ̀mí bù-fún-mi-n-bù-fún-ọ ló máa ń jọba nínú ìgbéyàwó aláyọ̀. Báwo ni ìwọ náà ṣe lè ní irú ẹ̀mí yìí?

Dípò tí wàá fi máa bi ara rẹ pé, ‘Àǹfààní wo ni mo ń rí nínú ìgbéyàwó yìí pàápàá?’ kúkú máa bi ara rẹ pé, ‘Kí lèmi fúnra mi ń ṣe láti fún ìgbéyàwó mi lókun?’ Bíbélì sọ pé kí àwọn Kristẹni ‘má ṣe máa mójú tó ire ti ara wọn nìkan, ṣùgbọ́n ire ti àwọn ẹlòmíràn pẹ̀lú.’ (Fílípì 2:4) Bó o ṣe ń ṣàṣàrò lórí ìlànà Bíbélì yìí, ronú lórí àwọn nǹkan tó o ṣe lọ́sẹ̀ tó kọjá. Ìgbà mélòó lo dìídì ṣe ohun kan tó dára fún àǹfààní ọkọ tàbí aya rẹ? Nígbà tí ọkọ tàbí aya rẹ fẹ́ bá ọ sọ̀rọ̀, ǹjẹ́ o tẹ́tí sílẹ̀—ká tiẹ̀ ní kò wù ọ́ láti gbọ́ ọ̀rọ̀ kankan lákòókò náà? Àwọn nǹkan wo lo ṣe tó dùn mọ́ ọkọ tàbí aya rẹ nínú ju bó ṣe dùn mọ́ ìwọ fúnra rẹ nínú lọ?

Bó o ṣe ń ronú lórí àwọn ìbéèrè wọ̀nyí, má ṣe rò pé kò sẹ́ni tó rí iṣẹ́ rere tó o ń ṣe tàbí pé iṣẹ́ náà kò lérè. Ìwé kan tá a ṣèwádìí nínú rẹ̀ sọ pé “Nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbéyàwó, ìwà rere tẹ́nì kan bá hù máa ń mú kí ẹnì kejì náà hùwà rere. Nítorí náà, tó o bá fẹ́ kí ọkọ tàbí aya rẹ hùwà rere, ìwọ náà gbọ́dọ̀ kọ́kọ́ hùwà rere.” Fífi gbogbo ara ṣe fún ẹnì kejì máa ń fún ìgbéyàwó lókun nítorí ó ń fi hàn pé o mọyì ìgbéyàwó rẹ o ò sì fẹ́ kó tú ká.

Ní In Lọ́kàn Pé Ìgbéyàwó Rẹ Gbọ́dọ̀ Wà Pẹ́ Títí

Jèhófà Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ sí kéèyàn jẹ́ adúróṣinṣin. Kódà, Bíbélì sọ pé: “Ìwọ [Jèhófà] yóò hùwà lọ́nà ìdúróṣinṣin sí ẹni ìdúróṣinṣin.” (2 Sámúẹ́lì 22:26) Jíjẹ́ adúróṣinṣin sí Ọlọ́run kan pé kéèyàn jẹ́ adúróṣinṣin sí ètò ìgbéyàwó tó dá sílẹ̀.—Jẹ́nẹ́sísì 2:24.

Bí ìwọ àti ọkọ tàbí aya rẹ bá dúró ṣinṣin ti ara yín, èrò pé ẹ̀ ń kọ ara yín sílẹ̀ kò tiẹ̀ ní wá sọ́kàn yín rárá. Nígbà tẹ́ ẹ bá ń ronú nípa ọjọ́ iwájú, ẹ̀ ẹ́ rí i pé ẹ̀yin méjèèjì lẹ ṣì jọ máa wà pa pọ̀ láìsí ìpínyà. Ẹ kò ní kábàámọ̀ láé pé ẹ fẹ́ ara yín, èyí á sì jẹ́ kẹ́ ẹ mọ̀ pé mìmì kan ò lè mi ìgbéyàwó yín. Ìyàwó kan sọ pé: “Kódà nígbà tí inú bá ń bí mi gan-an sí [ọkọ mi], tí inú mi sì ń ru ṣùù-ṣùù nípa èdèkòyédè tá a ní, ẹ̀rù kì í bà mí rárá pé bóyá ìgbéyàwó wa lè tú ká. Ohun tó ń ká mi lára ni bá a ṣe máa padà sí bá a ṣe ń ṣe tẹ́lẹ̀. Mo mọ̀ pé a máa yanjú èdèkòyédè tá a ní, àmọ́ ọ̀nà tá a máa gbé e gbà ni kò tíì yé mi.”

Níní in lọ́kàn pé ìgbéyàwó gbọ́dọ̀ wà pẹ́ títí jẹ́ apá pàtàkì nínú àdéhùn tá a bá ọkọ tàbí aya ẹni ṣe. Àmọ́, ó dunni pé ìyẹn ṣọ̀wọ́n nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbéyàwó. Tí èdèkòyédè bá ṣẹlẹ̀ láàárín tọkọtaya, ọ̀kan lára wọn lè sọ pé, “Mo máa fi ẹ́ sílẹ̀ ni!” tàbí “Mo máa lọ wá ẹlòmíràn tó mọyì mi!” Lóòótọ́, ọ̀pọ̀ ìgbà ló jẹ́ pé irú ọ̀rọ̀ yìí kì í dénú ẹni tó sọ ọ́. Síbẹ̀, Bíbélì sọ pé ahọ́n lè “kún fún panipani májèlé.” (Jákọ́bù 3:8) Tí ẹnì kan bá ń halẹ̀ lọ́nà yìí, ohun tó ń sọ ni pé: ‘Mi ò ka ìgbéyàwó yìí sóhun tó máa wà pẹ́ títí. Mo lè bá tèmi lọ nígbàkugbà tó bá wù mí.’ Irú àwọn èrò báyìí lè fọ́ ìgbéyàwó túútúú.

Tó o bá fi í sọ́kàn pé ìgbéyàwó rẹ máa wà pẹ́ títí, wàá fẹ́ wà pẹ̀lú ọkọ tàbí aya rẹ ní ọjọ́ dídùn àti ọjọ́ kíkorò. Èyí tún ní àǹfààní kan tó ń ṣe. Ó máa mú kó túbọ̀ rọrùn fún ìwọ àti ọkọ tàbí aya rẹ láti máa fara da ìkùdíẹ̀-káàtó tẹ́yin méjèèjì ní àti àṣìṣe ara yín, kí ẹ sì máa dárí ji ara yín ní fàlàlà. (Kólósè 3:13) Ìwé kan sọ pé: “Nínú ìgbéyàwó aláyọ̀, tọkọtaya lè ṣàṣìṣe, síbẹ̀ ìyẹn ò sọ pé kí ìgbéyàwó wọn tú ká.”

Lọ́jọ́ ìgbéyàwó rẹ, o jẹ́ ẹ̀jẹ̀. Ẹ̀jẹ́ yìí kì í ṣe fún ètò ìgbéyàwó bí kò ṣe fún ẹnì kan—ìyẹn ọkọ tàbí aya rẹ. Ẹ̀jẹ́ tó o jẹ́ yìí gbọ́dọ̀ máa nípa lórí ọ̀nà tó o gbà ń ronú báyìí àti bó o ṣe ń hùwà gẹ́gẹ́ bí ẹni tó ti ṣègbéyàwó. Ǹjẹ́ o gbà pé kì í ṣe tìtorí pé o ka ètò ìgbéyàwó sí mímọ́ nìkan lo ṣe dúró ti ọkọ tàbí aya rẹ, àmọ́ o tún ṣe bẹ́ẹ̀ nítorí pé o nífẹ̀ẹ́ ẹni tó o bá ṣègbéyàwó?

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Bí ọ̀ràn bá dójú ẹ̀ nígbà mìíràn, ó lè di dandan kí ọkọ àti aya pínyà. (1 Kọ́ríńtì 7:10, 11; wo ìwé Àṣírí Ayọ̀ Ìdílé, ojú ìwé 160 sí 161, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la tẹ̀ ẹ́ jáde.) Láfikún sí i, Bíbélì fàyè gba ìkọ̀sílẹ̀ bí ọ̀kan lára wọn bá ṣàgbèrè (ìyẹn bí ọ̀kan lára wọn bá lọ ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú ẹlòmíràn).—Mátíù 19:9.

[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 5]

Ohun Tó O Lè Ṣe Nísinsìnyí

Ọwọ́ wo ni ìwọ àti ọkọ tàbí aya rẹ fi ń mú àdéhùn ìgbéyàwó tẹ́ ẹ jọ ṣe? Ó ṣeé ṣe kó o ti rí ibi tẹ́ ẹ ti nílò àtúnṣe. Tó o bá fẹ́ kí ìgbéyàwó rẹ túbọ̀ lókun, ṣe àwọn ohun tó wà nísàlẹ̀ wọ̀nyí:

● Ṣàyẹ̀wò ara rẹ. Bi ara rẹ léèrè pé: ‘Ṣé lóòótọ́ ni mò ń ronú bí ẹni tó ti ṣègbéyàwó, àbí mo ṣì ń ronú bí àpọ́n?’ Béèrè lọ́wọ́ ọkọ tàbí aya rẹ bóyá lóòótọ́ lò ń ronú bí ẹni tó ti ṣègbéyàwó.

● Ka àpilẹ̀kọ yìí pẹ̀lú ọkọ tàbí aya rẹ. Lẹ́yìn náà, kẹ́ ẹ wá jìjọ fẹ̀sọ̀ jíròrò àwọn ọ̀nà tẹ́ ẹ lè gbà mú kí ìgbéyàwó yín túbọ̀ lágbára sí i.

● Kí ìwọ àti ọkọ tàbí aya rẹ máa ṣe àwọn nǹkan tó máa mú kí ìgbéyàwó yín túbọ̀ lágbára sí i. Bí àpẹẹrẹ: Ẹ jìjọ wo àwọn fọ́tò tẹ́ ẹ yà nígbà ìgbéyàwó yín àtèyí tẹ́ ẹ yà nígbà àwọn ayẹyẹ mánigbàgbé mìíràn. Ẹ jọ máa ṣe àwọn ohun tẹ́ ẹ máa ń ṣe nígbà tẹ́ ẹ ṣì ń fẹ́ra yín sọ́nà tàbí nígbà tẹ́ ẹ ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣègbéyàwó. Ẹ jùmọ̀ ka àwọn àpilẹ̀kọ tó jẹ mọ́ ọ̀ràn ìgbéyàwó, èyí tá a gbé karí Bíbélì nínú Ilé Ìṣọ́ àti Jí.

[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 6]

Lára Ohun Tó Ń Mú Kí Ìgbéyàwó Kẹ́sẹ Járí Nìwọ̀nyí . . .

Ojúṣe “Ohun tí o jẹ́jẹ̀ẹ́, san án. Ó sàn kí o má ṣe jẹ́jẹ̀ẹ́ ju pé kí o jẹ́jẹ̀ẹ́, kí o má sì san án.”—Oníwàásù 5:4, 5.

Ìfọwọ́sowọ́pọ̀ “Ẹni méjì sàn ju ẹnì kan . . . Nítorí, bí ọ̀kan nínú wọn bá ṣubú, èkejì lè gbé alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀ dìde.”—Oníwàásù 4:9, 10.

Ẹ̀mí Bù-Fún-Mi-N-Bù-Fún-Ọ “Ayọ̀ púpọ̀ wà nínú fífúnni ju èyí tí ó wà nínú rírígbà lọ.”—Ìṣe 20:35.

Níní In Lọ́kàn Pé Ìgbéyàwó Gbọ́dọ̀ Wà Pẹ́ Títí “Ìfẹ́ a máa . . . fara da ohun gbogbo.”—1 Kọ́ríńtì 13:4, 7.

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]

Tí ọkọ tàbí aya rẹ bá fẹ́ bá ọ sọ̀rọ̀, ǹjẹ́ o máa ń tẹ́tí sílẹ̀?