Jíjíròrò Ohun Tẹ̀mí Ń gbéni Ró
Jíjíròrò Ohun Tẹ̀mí Ń gbéni Ró
“Kí àsọjáde jíjẹrà má ti ẹnu yín jáde, bí kò ṣe àsọjáde yòówù tí ó dára fún gbígbéniró bí àìní bá ṣe wà, kí ó lè fi ohun tí ó ṣeni lóore fún àwọn olùgbọ́.”—ÉFÉSÙ 4:29.
1, 2. (a) Báwo ni ọ̀rọ̀ sísọ ṣe ṣeyebíye tó? (b) Báwo ni ó ṣe yẹ kí ọ̀rọ̀ ẹnu àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà rí?
“ÀDÌTÚ gbáà ni ọ̀rọ̀ sísọ jẹ́, ẹ̀bùn Ọlọ́run ni, iṣẹ́ ìyanu sì ni.” Ohun tí Ludwig Koehler tó jẹ́ atúmọ̀ èdè kọ nìyẹn. Ó ṣeé ṣe ká má fi bẹ́ẹ̀ mọyì àgbàyanu ẹ̀bùn ọ̀rọ̀ sísọ tí Ọlọ́run fúnni yìí. (Jákọ́bù 1:17) Àmọ́ àdánù ńlá ló máa ń jẹ́ nígbà tí àrùn ẹ̀gbà bá kọ lu èèyàn ẹni, tí kò sì lè sọ̀rọ̀ lọ́nà tó já gaara mọ́. Joan tí àrùn ẹ̀gbà kọ lu ọkọ rẹ̀ lẹ́nu àìpẹ́ yìí sọ pé: “A jọ máa ń sọ̀rọ̀ gan-an tẹ́lẹ̀, ìyẹn sì jẹ́ ká mọwọ́ ara wa dáadáa. Ó mà dùn mí o, pé a ò lè jọ sọ̀rọ̀ mọ́!”
2 Ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ lè mú kí okùn ọ̀rẹ́ túbọ̀ lágbára sí i, ó lè yanjú àìgbọ́ra ẹni yé, ó lè mú kí ẹni tí ìbànújẹ́ dorí ẹ̀ kodò túra ká, ó lè fún ìgbàgbọ́ lókun, ó sì lè mú kí ìgbésí ayé ládùn kó lóyin, àmọ́ àwọn nǹkan wọ̀nyí kì í ṣàdédé wáyé. Sólómọ́nì ọlọ́gbọ́n Ọba nì, sọ pé: “Ẹnì kan wà tí ń sọ̀rọ̀ láìronú bí ẹni pé pẹ̀lú àwọn ìgúnni idà, ṣùgbọ́n ahọ́n ọlọ́gbọ́n jẹ́ ìmúniláradá.” (Òwe 12:18) Gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ Jèhófà, a fẹ́ kí ìjíròrò wa jẹ́ èyí tó ń tuni lára tó sì ń gbéni ró, dípò tíì bá fi jẹ́ èyí tó ń bani nínú jẹ́ tó sì ń bini ṣubú. A tún fẹ́ kí ọ̀rọ̀ ẹnu wa jẹ́ èyí tó ń fi ìyìn fún Jèhófà, yálà lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù tàbí nínú ìfọ̀rọ̀wérọ̀ wa. Onísáàmù náà kọ ọ́ lórin pé: “Ọlọ́run ni a óò máa mú ìyìn wá fún láti òwúrọ̀ ṣúlẹ̀, orúkọ rẹ sì ni a óò máa gbé lárugẹ fún àkókò tí ó lọ kánrin.”—Sáàmù 44:8.
3, 4. (a) Ìṣòro wo ni gbogbo wá ní nípa ọ̀rọ̀ ẹnu wa? (b) Kí nìdí tí ọ̀rọ̀ tó ń ti ẹnu wa jáde fi ṣe pàtàkì?
3 Jákọ́bù ọmọ ẹ̀yìn kìlọ̀ pé, “ahọ́n, kò sí ẹnì kan nínú aráyé tí ó lè rọ̀ ọ́ lójú.” Ó rán wa létí pé: “Gbogbo wa ni a máa ń kọsẹ̀ lọ́pọ̀ ìgbà. Bí ẹnì kan kò bá kọsẹ̀ nínú ọ̀rọ̀, ẹni yìí jẹ́ ènìyàn pípé, tí ó lè kó gbogbo ara rẹ̀ pẹ̀lú níjàánu.” (Jákọ́bù 3:2, 8) Kò sí ẹni pípé lára wa. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé a fẹ́ lo ẹ̀bùn ọ̀rọ̀ sísọ wa lọ́nà rere, síbẹ̀ gbogbo ìgbà kọ́ ló máa ń gbé àwọn ẹlòmíràn ró tàbí kó fi ìyìn fún Ẹlẹ́dàá wa. Nítorí náà, a gbọ́dọ̀ ṣọ́ra nípa irú ọ̀rọ̀ tó ń ti ẹnu wa jáde. Jésù sọ pé: “Gbogbo àsọjáde aláìlérè tí àwọn ènìyàn ń sọ, ni wọn yóò jíhìn nípa rẹ̀ ní Ọjọ́ Ìdájọ́; nítorí nípa àwọn ọ̀rọ̀ rẹ ni a ó polongo rẹ ní olódodo, nípa àwọn ọ̀rọ̀ rẹ sì ni a óò dá ọ lẹ́bi.” (Mátíù 12:36, 37) Bẹ́ẹ̀ ni o, a máa jíhìn ọ̀rọ̀ tó ti ẹnu wa jáde fún Ọlọ́run.
4 Ọ̀kan lára ọ̀nà tó dára jù lọ ni pé ká sọ ọ́ dàṣà láti máa jíròrò àwọn ohun tó dá lórí nǹkan tẹ̀mí. Àpilẹ̀kọ yìí yóò ṣàlàyé ọ̀nà tá a lè gbà ṣe ìyẹn, yóò jẹ́ ká mọ àwọn ọ̀rọ̀ tá a lè máa jíròrò àtàwọn àǹfààní tá a lè rí nínú ọ̀rọ̀ tó ń gbéni ró.
Ṣíṣe Àyẹ̀wò Ohun Tó Wà Lọ́kàn Wa
5. Báwo ni ọkàn wa ṣe ń kó ipa pàtàkì nínú àwọn ìjíròrò tó ń gbéni ró?
5 Tá a bá fẹ́ kó mọ́ wa lára láti máa jíròrò àwọn ohun tó ń gbéni ró, ó yẹ ká kọ́kọ́ mọ̀ pé ohun tó wà nínú ọkàn ni ẹnu ń sọ jáde. Jésù sọ pé: “Lára ọ̀pọ̀ yanturu tí ń bẹ nínú ọkàn-àyà ni ẹnu ń sọ.” (Mátíù 12:34) Lẹ́nu kan, ohun tá a kà sí pàtàkì la máa ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀. Ó yẹ ká bi ara wa pé: ‘Kí ni ìjíròrò mi ń fi hàn pé ó wà lọ́kàn mi? Nígbà tí mo bá wà lọ́dọ̀ àwọn ẹbí àtàwọn tá a jọ jẹ́ onígbàgbọ́, ṣé ọ̀rọ̀ tó ń ti ẹnu mi jáde máa ń dá lórí ohun tẹ̀mí tàbí ńṣe ló máa ń dá lórí eré ìdárayá, aṣọ, sinimá, oúnjẹ, àwọn ohun tí mo ṣẹ̀ṣẹ̀ rà, tàbí àwọn nǹkan pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́ mìíràn?’ Àwa fúnra wa pàápàá lè má mọ̀ pé ìgbésí ayé wa àtàwọn ìrònú wa ti di èyí tá a gbé karí àwọn ohun tí kò ṣe pàtàkì. Fífi àwọn ohun pàtàkì tó yẹ kó wà nípò kìíní sí àyè wọn á jẹ́ kí ìjíròrò wa túbọ̀ mọ́yán lórí, ìgbésí ayé wa á sì lárinrin.—Fílípì 1:10.
6. Ipa wo ni àṣàrò ṣíṣe ń kó nínú àwọn ìjíròrò wa?
6 Ṣíṣe àṣàrò lórí ohun kan pàtó jẹ́ ọ̀nà mìíràn láti mú kí ọ̀rọ̀ tó ń ti ẹnu wa jáde jẹ́ èyí tó múná dóko. Tá a bá dìídì sapá láti ronú lórí àwọn ohun tẹ̀mí, a ó rí i pé ọ̀rọ̀ tó dá lórí ohun tẹ̀mí ni yóò máa ti ẹnu wa jáde. Dáfídì Ọba rí i pé òótọ́ lọ̀rọ̀ yìí. Ó kọ ọ́ lórin pé: “Kí àwọn àsọjáde ẹnu mi àti àṣàrò ọkàn-àyà mi dùn mọ́ ọ, ìwọ Jèhófà.” (Sáàmù 19:14) Ásáfù tóun náà jẹ́ onísáàmú sọ pé: “Dájúdájú, èmi yóò máa ṣe àṣàrò lórí gbogbo ìgbòkègbodò rẹ [Ọlọ́run], ṣe ni èmi yóò sì máa dàníyàn nípa ìbálò rẹ.” (Sáàmù 77:12) Bí ọkàn ẹnì kan bá ń ṣàṣàrò lórí kìkì òtítọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ní gbogbo ìgbà, àwọn ọ̀rọ̀ ìyìn ni yóò máa ti inú irú ọkàn ẹni bẹ́ẹ̀ jáde ní mẹ́sàn-án mẹ́wàá. Jeremáyà ò lè ṣe kó má sọ̀rọ̀ nípa ohun tí Jèhófà ti kọ́ ọ. (Jeremáyà 20:9) Àwa náà lè ṣe bẹ́ẹ̀, bá a bá ń ṣàṣàrò lórí àwọn nǹkan tẹ̀mí ní gbogbo ìgbà.—1 Tímótì 4:15.
7, 8. Àwọn kókó ọ̀rọ̀ wo ló dára fún ìjíròrò tó ń gbéni ró?
7 Tá a bá ní ìtòlẹ́sẹẹsẹ tó jíire fún àwọn nǹkan tẹ̀mí, ìyẹn á jẹ́ ká máa rí ọ̀pọ̀ ohun tó ń gbéni ró sọ. (Fílípì 3:16) Àwọn àpéjọ àyíká, àpéjọ àgbègbè, ìpàdé ìjọ, àwọn ìtẹ̀jáde tuntun, àwọn ẹ̀kọ́ ojoojúmọ àtàwọn àlàyé tá à ń ṣe lórí wọn, gbogbo wọn ló ń jẹ́ ká rí àwọn ohun tẹ̀mí tá a lè jíròrò. (Mátíù 13:52) Àwọn ìrírí tá a tún ń ní lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ Kristẹni máa ń gbéni ró gan-an nípa tẹ̀mí!
8 Onírúurú igi, àwọn ẹranko, ẹyẹ, àti ẹja tí Sólómọ́nì Ọbá rí ní Ísírẹ́lì mórí rẹ̀ wú gan-an. (1 Àwọn Ọba 4:33) Ó fẹ́ràn láti máa sọ̀rọ̀ nípa àwọn ohun tí Ọlọ́run dá. Àwa náà lè ṣe bẹ́ẹ̀. Àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà máa ń gbádùn sísọ̀rọ̀ nípa onírúurú nǹkan, àmọ́ àwọn ìjíròrò tó dá lórí ohun tẹ̀mí máa ń fi adùn sí ìjíròrò àwọn èèyàn tó nífẹ̀ẹ́ sí nǹkan tẹ̀mí.—1 Kọ́ríńtì 2:13.
“Ẹ Máa Báa Lọ Ní Gbígba Nǹkan Wọ̀nyí Rò”
9. Ìmọ̀ràn wo ni Pọ́ọ̀lù fún àwọn ará Fílípì?
9 Ohun yòówù kí kókó ọ̀rọ̀ náà jẹ́, àwọn ìjíròrò wa yóò máa gbé àwọn ẹlòmíràn ró bí wọ́n bá wà níbàámu pẹ̀lú ìmọ̀ràn tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fún ìjọ tó wà ní Fílípì. Ó kọ̀wé pé: “Ohun yòówù tí ó jẹ́ òótọ́, ohun yòówù tí ó jẹ́ ti ìdàníyàn ṣíṣe pàtàkì, ohun yòówù tí ó jẹ́ òdodo, ohun yòówù tí ó jẹ́ mímọ́ níwà, ohun yòówù tí ó dára ní fífẹ́, ohun yòówù tí a ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ dáadáa, ìwà funfun yòówù tí ó bá wà, ohun yòówù tí ó bá sì wà tí ó yẹ fún ìyìn, ẹ máa bá a lọ ní gbígba nǹkan wọ̀nyí rò.” (Fílípì 4:8) Àwọn ohun tí Pọ́ọ̀lù mẹ́nu kàn ṣe pàtàkì débi tó fi sọ pé “ẹ máa bá a lọ ní gbígba nǹkan wọ̀nyí rò.” Àwọn nǹkan wọ̀nyí ló yẹ kó kún inú ọkàn wa. Nítorí náà, ẹ jẹ́ ká wo bí ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn kókó mẹ́jọ tí Pọ́ọ̀lù mẹ́nu bà ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ láti máa jíròrò ohun tó ń gbéni ró.
10. Báwo làwọn ìjíròrò wa ṣe lè ní ohun tó jẹ́ òtítọ́ nínú?
10 Tá a bá sọ pé ohun kan jẹ́ òótọ́, kì í wulẹ̀ ṣe pé ìsọfúnni náà jẹ́ òótọ́ pọnbele nìkan là ń sọ. Ó túmọ̀ sí ohun kan tó dúró sán-ún tó sì ṣeé gbẹ́kẹ̀ lé, irú bí òtítọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Nítorí náà, nígbà tá a bá ń bá àwọn ẹlòmíràn sọ̀rọ̀ nípa òtítọ́ Bíbélì tó wú wa lórí, tà a sì ń jíròrò àwọn àsọyé tó ru wá sókè, tàbí àwọn ìmọ̀ràn Ìwé Mímọ́ tó ràn wá lọ́wọ́, àwọn ohun tó jẹ́ òtítọ́ la ń gbé yẹ̀ wò yẹn. Bákan náà, a kì í fàyè gba àwọn “ohun tí a fi èké pè ní ‘ìmọ̀.’” tó dà bí ohun tó jẹ́ òtítọ́. (1 Tímótì 6:20) A kì í sì í gbéborùn tàbí ká máa sọ àwọn ìrírí tá a ò lè fìdí wọn múlẹ̀.
11. Kí ni àwọn ohun ìdàníyàn ṣiṣe pàtàkì tá a lè sọ̀rọ̀ lé lórí nínú ìjíròrò wa?
11 Àwọn ohun tó jẹ́ ìdàníyàn ṣíṣe pàtàkì ni àwọn ọ̀rọ̀ tó ń buyì kúnni tó sì ṣe pàtàkì, kì í ṣe àwọn ọ̀rọ̀ yẹ̀bùyẹ́bù tàbí àwọn ọ̀rọ̀ tí kò ní láárí. Lára wọn ni ọ̀rọ̀ nípa iṣẹ́ òjíṣẹ́ Kristẹni wa, àwọn àkókò líle koko tí à ń gbé, àti ìdí tó fi yẹ ká máa hùwà rere. Nígbà tá a bá ń jíròrò àwọn ọ̀rọ̀ pàtàkì bí èyí, ìyẹn á jẹ́ ká túbọ̀ wà lójúfò nípa tẹ̀mí, a ó pa ìwà títọ́ wa mọ́, a ó sì máa bá a lọ láti wàásù ìhìn rere náà. Ní tòótọ́, àwọn ìrírí alárinrin nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa àtàwọn ohun tó ń ṣẹlẹ̀ kárí ayé tó ń rán wa létí pé àwọn ọjọ́ ìkẹyìn la wà yìí ń jẹ́ ká ní ọ̀rọ̀ púpọ̀ láti sọ nínú ìjíròrò tó ń gbéni ró.—Ìṣe 14:27; 2 Tímótì 3:1-5.
12. Àwọn ọ̀rọ̀ wo ló yẹ ká yẹra fún nítorí ìmọ̀ràn tí Pọ́ọ̀lù fúnni pé ká máa gba àwọn ohun tó jẹ́ òdodo àti ohun tó mọ́ níwà rò?
12 Ọ̀rọ̀ náà òdodo túmọ̀ sí ṣíṣe ohun tí ó tọ́ lójú Ọlọ́run—ìyẹn ni ṣíṣe ohun tó bá àwọn ìlànà rẹ̀ mu. Mímọ́ níwà túmọ̀ sí pé èrò àti ìwà èèyàn mọ́. Ọ̀rọ̀ ìbanilórúkọjẹ́, ọ̀rọ̀ rírùn tàbí àwọn ọ̀rọ̀ ìṣekúṣe kò gbọ́dọ̀ wáyé nínú ìjíròrò wa. (Éfésù 5:3; Kólósè 3:8) Nígbà tí ọ̀rọ̀ bá ti ń lọ sórí irú ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ níbi iṣẹ́ tàbí nílé ìwé, ńṣe làwọn Kristẹn máa ń fi ọgbọ́n kúrò níbẹ̀.
13. Fúnni lápẹẹrẹ àwọn ìjíròrò tó dá lórí àwọn ohun tó yẹ ní fífẹ́ àtàwọn ohun tá a ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ dáadáa.
13 Nígbà tí Pọ́ọ̀lù sọ pé ká máa ronú lórí ohun tó yẹ ní fífẹ́, ohun tó ń sọ ni àwọn ọ̀rọ̀ tó ń tuni lára, tó ṣe ìtẹ́wọ́gbà tàbí tó fi ìfẹ́ hàn, dípò àwọn ohun tó ń fa ìkórìíra, ìkannú, tàbí gbọ́nmisi-omi-ò-to. Àwọn ohun tí a ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ dáadáa ń tọ́ka sí ìsọfúnni tó wúni lórí tàbí ìròyìn rere. Lára irú ìròyìn rere bẹ́ẹ̀ ni ìtàn ìgbésí ayé àwọn arákùnrin àti arábìnrin tí wọ́n jẹ́ olóòótọ́, èyí tá a máa ń rí nínú ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí! ní gbogbo ìgbà. Lẹ́yìn tó o bá ka àwọn àpilẹ̀kọ tó ń gbéni ró wọ̀nyí tán, o ò ṣe sọ bí ohun tó o kà níbẹ̀ ṣe rí lára rẹ fún àwọn ẹlòmíràn? Ẹ sì wo bó ṣe ń fúnni níṣìírí tó láti gbọ́ nípa àwọn ohun tẹ̀mí táwọn ẹlòmíràn ti gbé ṣe! Irú ìfọ̀rọ̀wérọ̀ bẹ́ẹ̀ yóò mú ìfẹ́ àti ìṣọ̀kan dàgbà nínú ìjọ.
14. (a) Kí la gbọ́dọ̀ ṣe tá a bá fẹ́ jẹ́ oníwà funfun? (b) Báwo làwọn ọ̀rọ̀ ẹnu wa ṣe lè ní àwọn ohun tó yẹ fún ìyìn nínú?
14 Pọ́ọ̀lù sọ̀rọ̀ nípa “ìwà funfun yòówù tí ó bá wà.” Ìwà funfun ń tọ́ka sí ohun rere tó jẹ mọ́ ìwà ọmọlúàbí. A gbọ́dọ̀ rí i dájú pé àwọn ìlànà Ìwé Mímọ́ ló ń darí àwọn ọ̀rọ̀ tó ń ti ẹnu wa jáde, pé wọn ò sì yà kúrò lórí ohun tó jẹ́ òdodo, èyí tó mọ́ níwà, àti ìwà funfun. Ohun tí ó yẹ fún ìyìn túmọ̀ sí “èyí tá a lè gbóríyìn fún.” Tó o bá gbọ́ àsọyé kan tó gbámúṣé tàbí tó o kíyè sí ẹnì kan nínú ìjọ tí ìṣòtítọ́ rẹ̀ jẹ́ àwòfiṣàpẹẹrẹ, sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀—sọ fún onítọ̀hún fúnra rẹ̀ kó o sì tún sọ fún àwọn ẹlòmíràn pẹ̀lú. Gbogbo ìgbà ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù máa ń gbóríyìn fún àwọn ànímọ́ rere táwọn olùjọsìn ẹlẹ́gbẹ́ rẹ̀ ní. (Róòmù 16:12; Fílípì 2:19-22; Fílémónì 4-7) Tá a bá sì tún wò ó, a ó rí i pé àwọn ohun tí Ẹlẹ́dàá wa dá yẹ fún ìyìn lóòótọ́. Lára àwọn nǹkan wọ̀nyí ni a ti lè rí ọ̀pọ̀ yanturu àwọn ohun tá a lè sọ nínú ìjíròrò tó ń gbéni ró.—Òwe 6:6-8; 20:12; 26:2.
Máa Jíròrò Àwọn Ohun Tó Ń Gbéni Ró
15. Àṣẹ Ìwé Mímọ́ wo ni ó sọ pé ó pọn dandan fún àwọn òbí láti máa bá àwọn ọmọ wọn jíròrò ohun tó nítumọ̀?
15 Ìwé Diutarónómì 6:6, 7 sọ pé: “Kí ọ̀rọ̀ wọ̀nyí tí mo ń pa láṣẹ fún ọ lónìí sì wà ní ọkàn-àyà rẹ; kí ìwọ sì fi ìtẹnumọ́ gbìn wọ́n sínú ọmọ rẹ, kí o sì máa sọ̀rọ̀ nípa wọn nígbà tí o bá jókòó nínú ilé rẹ àti nígbà tí o bá ń rìn ní ojú ọ̀nà àti nígbà tí o bá dùbúlẹ̀ àti nígbà tí o bá dìde.” Ní kedere, àṣẹ yìí fi hàn pé àwọn òbí gbọ́dọ̀ máa bá àwọn ọmọ wọn jíròrò ohun tó nítumọ̀, tó sì dá lórí nǹkan tẹ̀mí.
16, 17. Ẹ̀kọ́ wo làwọn Kristẹni tó jẹ́ òbí lè rí kọ́ látinú àpẹẹrẹ Jèhófà àti ti Ábúráhámù?
16 A lè fojú inú wo ìjíròrò gígùn tó ti ní láti wáyé láàárín Jésù àti Baba rẹ̀ ọ̀run nígbà tí wọ́n ń jíròrò nípa iṣẹ́ tó ń bọ̀ wá ṣe láyé. Jésù sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Baba fúnra rẹ̀ tí ó rán mi ti fún mi ní àṣẹ kan ní ti ohun tí èmi yóò wí àti ohun tí èmi yóò sọ.” (Jòhánù 12:49; Diutarónómì 18:18) Ábúráhámù baba ńlá ti ní láti lo ọ̀pọ̀ wákàtí láti bá Ísákì ọmọ rẹ̀ sọ̀rọ̀ nípa bí Jèhófà ṣe bù kún àwọn àtàwọn baba ńlá wọn. Ó dájú pé irú ìjíròrò bẹ́ẹ̀ ló ran Jésù àti Ísákì lọ́wọ́ láti gbà láìjanpata pé ìfẹ́ Ọlọ́run ni ṣíṣe.—Jẹ́nẹ́sísì 22:7-9; Mátíù 26:39.
17 Àwọn ọmọ tiwa náà nílò ìjíròrò tí ń gbéni ró. Bó ti wù kí ọwọ́ àwọn òbí dí tó, wọ́n gbọ́dọ̀ wá àyè láti bá àwọn ọmọ wọn sọ̀rọ̀. Tó bá ṣeé ṣe, ẹ ò ṣe ṣètò láti jẹun pọ̀ gẹ́gẹ́ bí ìdílé ó kéré tán lẹ́ẹ̀kan lójúmọ́? Láàárín àti lẹ́yìn irú àkókò oúnjẹ bẹ́ẹ̀, àǹfààní á wà fún àwọn ìjíròrò tó ń gbéni ró, tó ṣeyebíye, tá á sì wúlò gan-an fún ìlera tẹ̀mí ìdílé yín.
18. Sọ ìrírí kan tó fi àǹfààní tó wà nínú ìjíròrò tó gbámúṣé láàárín àwọn òbí àtàwọn ọmọ hàn.
18 Alejandro, aṣáájú ọ̀nà kan tó ti lé lẹ́ni ogún ọdún báyìí rántí pé òun máa ń ṣiyè méjì nígbà tóun wà lọ́mọ ọdún mẹ́rìnlá. Ó sọ pé: “Nítorí ipa tí àwọn ọmọ tá a jọ ń lọ sílé ìwé àtàwọn olùkọ́ ní lórí mi, kò wá dá mi lójú pé Ọlọ́run wà, kò sì tún dá mi lójú pé Bíbélì jẹ́ òtítọ́. Àwọn òbí mi fi sùúrù bá mi fọ̀rọ̀ wérọ̀ fún ọ̀pọ̀ wákàtí. Kì í ṣe pé ìjíròrò yìí ràn mí lọ́wọ́ láti borí iyèméjì tí mò ń ṣe lákòókò líle koko yìí nìkan, àmọ́ ó tún ràn mí lọ́wọ́ láti ṣe àwọn ìpinnu tó tọ́ nínú ìgbésí ayé mi.” Lónìí ńkọ́? Alejandro ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ, ó ní: “Mi ò tíì bẹ̀rẹ̀ sí dágbé. Àmọ́ ọwọ́ wa tó máa ń dí kò jẹ́ kí èmi àti baba mi ráyè fi bẹ́ẹ̀ bára wa sọ̀rọ̀. Nítorí ìdí èyí, àwa méjèèjì máa ń jẹun pọ̀ níbi iṣẹ́ rẹ̀ lẹ́ẹ̀kan lọ́sẹ̀. Mo máa ń gbádùn àwọn ìfọ̀rọ̀wérọ̀ náà gan-an.”
19. Kí nìdí tó fi yẹ kí gbogbo wa máa jíròrò àwọn ohun tẹ̀mí?
19 Ǹjẹ́ àwa náà kì í mọyì àǹfààní tá a ní láti gbádùn àwọn ìjíròrò tẹ̀mí tó lérè pẹ̀lú àwọn tá a jọ jẹ́ onígbàgbọ́? A máa ń ní irú àǹfààní yìí ní àwọn ìpàdé, nígbà tá a bá wà lóde ẹ̀rí, níbi àpèjẹ àti nígbà tá a bá ń rìnrìn àjò. Ńṣe ló ń ṣe Pọ́ọ̀lù bíi pé kó ti dé ọ̀dọ̀ àwọn Kristẹni ní Róòmù kó sì bá wọn sọ̀rọ̀. Ó kọ̀wé sí wọn pé: “Aáyun ń yun mí láti rí yín, kí n lè fi ẹ̀bùn ẹ̀mí díẹ̀ fún yín, kí a lè fìdí yín múlẹ̀ gbọn-in; tàbí, kí a kúkú wí pé, kí pàṣípààrọ̀ ìṣírí lè wà láàárín yín, láti ọ̀dọ̀ ẹnì kọ̀ọ̀kan nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ ẹnì kejì, tiyín àti tèmi.” (Róòmù 1:11, 12) Johannes, tó jẹ́ Kristẹni alàgbà sọ pé: “Bíbá àwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ wa jíròrò ohun tẹ̀mí máa ń fúnni ní ohun pàtàkì tá a nílò. Wọ́n máa ń mú kí ara ẹni yá gágá, wọ́n sì máa ń dín pákáǹleke ojoojúmọ́ kù. Mo sábà máa ń sọ pé káwọn àgbàlagbà sọ nípa ìgbésí ayé wọn fún mi àti ohun tó ràn wọ́n lọ́wọ́ láti dúró bí olóòótọ́. Láti àwọn ọdún wọ̀nyí wá, mo ti bá ọ̀pọ̀ lára wọn sọ̀rọ̀, mo sì ti rí ọgbọ́n kọ́ lára ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn, wọ́n ti là mí lóye, èyí sì ti mú kí ìgbésí ayé mi sunwọ̀n sí i.”
20. Kí la lè ṣe tá a bá bá onítìjú èèyàn pàdé?
20 Kí lo máa ṣe bí ẹnì kan kò bá fẹ́ gbọ́ ìjíròrò tẹ̀mí tó o dẹ́nu lé? Má ṣe jẹ́ kí ìyẹn kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá ọ. O lè wá àkókò mìíràn láti bá a sọ̀rọ̀. Sólómọ́nì sọ pé: “Bí àwọn èso ápù ti wúrà nínú àwọn ohun gbígbẹ́ tí a fi fàdákà ṣe ni ọ̀rọ̀ tí a sọ ní àkókò tí ó tọ́.” (Òwe 25:11) Fòye bá àwọn tó jẹ́ onítìjú lò. “Ìmọ̀ràn ní ọkàn-àyà ènìyàn dà bí omi jíjìn, ṣùgbọ́n ènìyàn tí ó ní ìfòyemọ̀ ni yoo fà á jáde.” a (Òwe 20:5) Ju gbogbo rẹ̀ lọ, má ṣe jẹ́ kí ìwà àwọn ẹlòmíràn mú kó sú ọ láti sọ̀rọ̀ nípa àwọn ohun tó o gbọ́ tó sì wọ̀ ọ́ lọ́kàn.
Jíjíròrò Àwọn Ohun Tẹ̀mí Ń Mérè Wa
21, 22. Àwọn àǹfààní wo la máa ń rí nínú jíjíròrò àwọn nǹkan tẹ̀mí?
21 Ìmọ̀ràn Pọ́ọ̀lù ni pé: “Kí àsọjáde jíjẹrà má ti ẹnu yín jáde, bí kò ṣe àsọjáde yòówù tí ó dára fún gbígbéniró bí àìní bá ṣe wà, kí ó lè fi ohun tí ó ṣeni lóore fún àwọn olùgbọ́.” (Éfésù 4:29; ) Ó lè gba ìsapá gan-an láti mú kí ìjíròrò dá lórí àwọn ohun tó ń gbéni ró, àmọ́ èrè ibẹ̀ pọ̀ jọjọ. Ìjíròrò tó dá lórí ohun tẹ̀mí ń mú kó ṣeé ṣe fún wa láti sọ ohun tá a gbà gbọ́ fáwọn ẹlòmíràn ká sì gbé ẹgbẹ́ ará wa ró. Róòmù 10:10
22 Nítorí náà, ẹ jẹ́ ká lo ẹ̀bùn ọ̀rọ̀ sísọ wa láti gbé àwọn ẹlòmíràn ró àti láti fi ìyìn fún Ọlọ́run. Irú ìjíròrò bẹ́ẹ̀ á mú kí ọkàn wa balẹ̀ á sì fún àwọn ẹlòmíràn níṣìírí pẹ̀lú. Ju gbogbo rẹ̀ lọ, wọ́n á mú ọkàn Jèhófà yọ̀, nítorí pé ó ń tẹ́tí sí àwọn ìjíròrò wa, inú rẹ̀ sì máa ń dùn nígbà tá a bá lo ahọ́n wa lọ́nà tí ó tọ́. (Sáàmù 139:4; Òwe 27:11) Nígbà tí àwọn ìjíròrò wa bá ń dá lórí àwọn nǹkan tẹ̀mí, a lè ní ẹ̀rí ìdánilójú pé Jèhófà kò ní gbàgbé wa. Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa àwọn tó ń sin Jèhófà ní àkókò wa yìí pé: “Ní àkókò yẹn, àwọn tí ó bẹ̀rù Jèhófà bá ara wọn sọ̀rọ̀ lẹ́nì kìíní-kejì, olúkúlùkù pẹ̀lú alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀, Jèhófà sì ń fiyè sí i, ó sì ń fetí sílẹ̀. Ìwé ìrántí kan ni a sì bẹ̀rẹ̀ sí kọ sílẹ̀ níwájú rẹ̀ fún àwọn tí ó bẹ̀rù Jèhófà àti fún àwọn tí ń ronú lórí orúkọ rẹ̀.” (Málákì 3:16; 4:5) Ẹ ò rí i pé ó ṣe pàtàkì gan-an kí ìjíròrò wa jẹ́ èyí tó ń gbéni ró nípa tẹ̀mí!
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Àwọn kànga kan ní Ísírẹ́lì jìn gan-an. Àwọn awalẹ̀pìtàn ti rí ìkùdu omi kan tó jìn tó mítà mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n ní Gíbéónì. Ó ní àwọn àtẹ̀gùn nínú, èyí tó mú kó ṣeé ṣe fáwọn èèyàn láti sọ̀ kalẹ̀ lọ fa omi jáde nínú rẹ̀.
Báwo Lo Ṣe Máa Dáhùn?
• Irú èèyàn wo ni àwọn ohun tá a ń jíròrò fi hàn pé a jẹ́?
• Kí làwọn ohun tó ń gbéni ró tá a lè sọ̀rọ̀ lé lórí?
• Ipa pàtàkì wo ni ìjíròrò ń kó nínú ìdílé àti nínú ìjọ Kristẹni?
• Àǹfààní wo ló wà nínú ìjíròrò tó ń gbéni ró?
[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 12]
Àwọn ìjíròrò tó ń gbéni ró dá lórí . . .
“ohun yòówù tí ó jẹ́ òótọ́”
“ohun yòówù tí ó jẹ́ ìdàníyàn ṣíṣe pàtàkì”
“ohun yòówù tí ó bá sì wà tí ó yẹ fún ìyìn”
“ohun yòówù tí a ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ dáadáa”
[Àwọn Credit Line]
Àwòrán ẹ̀yìn fídíò, Stalin: Fọ́tò ológun ilẹ̀ Amẹ́ríkà; Ẹ̀yin ìwé Creator, Eagle Nebula: J. Hester and P. Scowen (AZ State Univ.), NASA
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 13]
Àwọn àkókò oúnjẹ jẹ́ àkókò tó dára gan-an láti jíròrò àwọn nǹkan tẹ̀mí