Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Ká Máa Gbàdúrà Láìdabọ̀?
Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Ká Máa Gbàdúrà Láìdabọ̀?
“Ẹ máa gbàdúrà láìdabọ̀. Ní ìsopọ̀ pẹ̀lú ohun gbogbo, ẹ máa dúpẹ́.”—1 Tẹsalóníkà 5:17, 18.
1, 2. Báwo ni Dáníẹ́lì ṣe fi hàn pé òun mọyì àǹfààní àdúrà gbígbà, ipa wo sì ni èyí ní lórí àjọṣe rẹ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run?
ÀṢÀ wòlíì Dáníẹ́lì ni pé kó máa gbàdúrà sí Ọlọ́run lẹ́ẹ̀mẹ́ta lójúmọ́. Iwájú fèrèsé tó wà ní òrùlé rẹ̀ ló máa ń kúnlẹ̀ sí nígbà tó bá fẹ́ gbàdúrà, ìlú Jerúsálẹ́mù sì ni fèrèsé náà kọjú sí. (1 Àwọn Ọba 8:46-49; Dáníẹ́lì 6:10) Kódà nígbà tí òfin ọba sọ pé ẹnikẹ́ni kò gbọ́dọ̀ gbàdúrà sí ẹlòmíràn bí kò ṣe sí Dáríúsì ọba Mídíánì nìkan, Dáníẹ́lì kò mikàn rárá. Ńṣe ni ọkùnrin tí kì í fi ọ̀ràn àdúrà ṣeré yìí máa ń rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí Jèhófà nígbà gbogbo, yálà èyí fi ẹ̀mí rẹ̀ sínú ewu tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́.
2 Irú èèyàn wo ni Jèhófà ka Dáníẹ́lì sí? Nígbà tí áńgẹ́lì Gébúrẹ́lì wá dáhùn àdúrà kan tí Dáníẹ́lì gbà, ó pè é ní “ẹnì kan tí ó fani lọ́kàn mọ́ra gidigidi” tàbí “ayanfẹ gidigidi.” (Dáníẹ́lì 9:20-23; Bibeli Mimọ) Nínú àsọtẹ́lẹ̀ Ìsíkíẹ́lì, Jèhófà pe Dáníẹ́lì ní olódodo. (Ìsíkíẹ́lì 14:14, 20) Nígbà tí Dáníẹ́lì wà láyé, àwọn àdúrà rẹ̀ mú kó ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Ọlọ́rùn, àní Dáríúsì pàápàá mọ̀ bẹ́ẹ̀.—Dáníẹ́lì 6:16.
3. Gẹ́gẹ́ bí ohun tí míṣọ́nnárì kan sọ, báwo ni àdúrà ṣe ń ràn wá lọ́wọ́ láti pa ìwà títọ́ mọ́?
3 Gbígbàdúrà déédéé lè ran àwa náà lọ́wọ́ láti kojú àwọn ìṣòro líle koko. Bí àpẹẹrẹ, gbé ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Harold King yẹ̀ wò, ìyẹn míṣọ́nnárì kan ní orílẹ̀-èdè Ṣáínà tí wọ́n fi sẹ́wọ̀n ọdún márùn-ún nínú àhámọ́ ẹlẹ́nìkan ṣoṣo. Nígbà tí Arákùnrin King ń sọ ìrírí ara rẹ̀, ó ní: “Wọ́n lè mú mi kúrò lọ́dọ̀ àwọn èèyàn ẹlẹgbẹ́ mi o, àmọ́ wọn ò lè mú mi kúrò lọ́dọ̀ Ọlọ́run. . . . Ìgbà mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni mo máa ń kúnlẹ̀ tí màá sì gbàdúrà sókè nínú ibi tí wọ́n há mi mọ́, kò sì sẹ́ni tó máa kọjá tí kò ní rí mi. Èyí mú mi rántí Dáníẹ́lì tí Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀. . . . Nírú àkókò yẹn, mo máa ń mọ̀ ọ́n lára pé ẹ̀mí Ọlọ́run ń darí èrò ọkàn mi sí ohun tó ṣàǹfààní jù lọ, ó sì máa ń fi mí lọ́kàn balẹ̀ pẹ̀lú. Ẹ ò rí i pé okun tẹ̀mí àti ìtùnú tí àdúrà fún mi kò kéré!”
4. Àwọn ìbéèrè wo tó jẹ mọ́ ọ̀ràn àdúrà ni a óò gbé yẹ̀ wò nínú àpilẹ̀kọ yìí?
4 Bíbélì sọ pé: “Ẹ máa gbàdúrà láìdabọ̀. Ní ìsopọ̀ pẹ̀lú ohun gbogbo, ẹ máa dúpẹ́.” (1 Tẹsalóníkà 5:17, 18) Gẹ́gẹ́ bí ohun tó wà nínú ìmọ̀ràn yìí, ẹ jẹ́ ká gbé àwọn ìbéèrè tó tẹ̀ lé e wọ̀nyí yẹ̀ wò: Kí nìdí tó fi yẹ ká fiyè sí àwọn àdúrà wa gidigidi? Kí nìdí tó fi yẹ ká máa gbàdúrà sí Jèhófà nígbà gbogbo? Kí la lè ṣe tó bá ń ṣe wá bí ẹni pé a ò yẹ lẹ́ni tó ń gbàdúrà sí Ọlọ́run nítorí àwọn àṣìṣe wa?
Bá Ọlọ́run Dọ́rẹ̀ẹ́ Nípasẹ̀ Àdúrà
5. Ìbádọ́rẹ̀ẹ́ àrà ọ̀tọ̀ wo ni àdúrà ń ràn wá lọ́wọ́ láti ní?
5 Ṣé wàá fẹ́ kí Jèhófà kà ọ́ sí ọ̀rẹ́ òun? Ó pe Ábúráhámù baba ńlá ní ọ̀rẹ́ òun. (Aísáyà 41:8; Jákọ́bù 2:23) Irú àjọṣe yẹn ni Jèhófà fẹ́ ká ní pẹ̀lú òun. Ó dìídì pè wá pé ká sún mọ́ òun. (Jákọ́bù 4:8) Ǹjẹ́ kò yẹ kí ìpè yẹn mú wa ronú jinlẹ̀ lórí àǹfààní àrà ọ̀tọ̀ tí àdúrà jẹ́? Ẹ wo bó ti ṣòro tó láti rí àwọn lọ́gàálọ́gàá nídìí iṣẹ́ ìjọba bá sọ̀rọ̀, ká máà wá ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ ti bíbá wọn ṣọ̀rẹ́! Bẹ́ẹ̀ sì rèé, Ẹlẹ́dàá ọ̀run òun ayé ń rọ̀ wá pé ká máa gbàdúrà sí òun fàlàlà nígbàkigbà tó bá wù wá. (Sáàmù 37:5) Àdúrà tá a ń gbà láìdabọ̀ yóò jẹ́ ká di ọ̀rẹ́ Jèhófà tímọ́tímọ́.
6. Kí ni àpẹẹrẹ Jésù kọ́ wa nípa bó ti ṣe pàtàkì tó láti “máa gbàdúrà nígbà gbogbo”?
6 Àmọ́ ó rọrùn gan-an láti fọwọ́ yẹpẹrẹ mú àdúrà! Kòókòó jàn-ánjàn-án ojoojúmọ́ lè gba gbogbo àfiyèsí wa débi pé a ò ní sapá láti bá Ọlọ́run sọ̀rọ̀ mọ́. Jésù rọ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ láti “máa gbàdúrà nígbà gbogbo,” òun fúnra rẹ̀ sì ṣe bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú. (Mátíù 26:41) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ńṣe ni ọwọ́ rẹ̀ máa ń dí láti òwúrọ̀ ṣúlẹ̀, síbẹ̀ ó máa ń wá àyè láti bá Baba rẹ̀ ọ̀run sọ̀rọ̀. Nígbà mìíràn, Jésù á dìde láti gbàdúrà “ní kùtùkùtù òwúrọ̀, nígbà tí ilẹ̀ kò tíì mọ́.” (Máàkù 1:35) Ìgbà kan wà tó lọ sí ibi dídákẹ́ rọ́rọ́ lọ́wọ́ àṣálẹ́ kí ó lè bá Jèhófà sọ̀rọ̀. (Mátíù 14:23) Gbogbo ìgbà ni Jésù máa ń wá àyè láti gbàdúrà, ó sì yẹ kí àwa náà ṣe bẹ́ẹ̀.—1 Pétérù 2:21.
7. Àwọn ipò wo ló yẹ kó máa mú wa bá Baba wa ọ̀run sọ̀rọ̀ lójoojúmọ́?
7 Ọ̀pọ̀ ìgbà làwọn àkókò tá a lè gbàdúrà láwa nìkan máa ń wáyé lójoojúmọ́ bá a ṣe ń kojú àwọn ìṣòro, tá à ń bá àwọn àdánwò pàdé, tá a sì ń ṣe àwọn ìpinnu. (Éfésù 6:18) Nígbà tá a bá wá ìtọ́sọ́nà Ọlọ́run ní gbogbo apá ìgbésí ayé wa, okùn ọ̀rẹ́ àwa pẹ̀lú rẹ̀ yóò túbọ̀ nípọn sí i. Bí ọ̀rẹ́ méjì bá para pọ̀ kojú ìṣòro kan, ǹjẹ́ ìdè ọ̀rẹ́ wọn ò ní túbọ̀ lágbára sí i? (Òwe 17:17) Bákan náà ni ìdè ọ̀rẹ́ àárín àwa àti Jèhófà yóò túbọ̀ lágbára sí i, tá a bá gbára lé e tó sì ràn wá lọ́wọ́.—2 Kíróníkà 14:11.
8. Ẹ̀kọ́ wo la rí kọ́ nípa bí àdúrà tá a ń dá nìkan gbà ṣe lè gùn tó látinú àpẹẹrẹ Nehemáyà, Jésù àti Hánà?
8 A mà dúpẹ́ o, pé Jèhófà ò sọ bí àdúrà wa ṣe gbọ́dọ̀ gùn tó tàbí iye ìgbà tá a gbọ́dọ̀ gbàdúrà sí òun! Nehemáyà yára gbàdúrà ìdákẹ́jẹ́ẹ́ kó tó béèrè ohun tó fẹ́ kí ọba Páṣíà ṣe fún òun. (Nehemáyà 2:4, 5) Jésù náà gbàdúrà ṣókí nígbà tó ń bẹ Jèhófà pé kó fún òun lágbára láti jí Lásárù dìde. (Jòhánù 11:41, 42) Àmọ́ Hánà ní tirẹ̀ “gbàdúrà lọ títí níwájú Jèhófà” nígbà tó ń sọ ẹ̀dùn ọkàn rẹ̀ fún un. (1 Sámúẹ́lì 1:12, 15, 16) Àdúrà tá a ń dá nìkan gbà lè kúrú, ó sì lè gùn, ó sinmi lórí ohun tá a nílò àti bí ipò nǹkan ṣe rí.
9. Kí nìdí tó fi yẹ kí ìyìn àti ọpẹ́ wà nínú àdúrà tá a ń gbà nítorí gbogbo ohun tí Jèhófà ń ṣe fún wa?
9 Ọ̀pọ̀ àdúrà táwọn èèyàn gbà nínú Bíbélì ló fi ìmọrírì àtọkànwá hàn fún ipò gíga jù lọ tí Jèhófà wà àti àwọn iṣẹ́ àgbàyanu rẹ̀. (Ẹ́kísódù 15:1-19; 1 Kíróníkà 16:7-36; Sáàmù 145) Nínú ìran kan tá a fi han àpọ́sítélì Jòhánù, ó rí àwọn àgbà mẹ́rìnlélógún—ìyẹn gbogbo àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró bí wọ́n ṣe wà ní ipò wọn ní òkè ọ̀run—tí wọ́n ń yin Jèhófà pé: “Jèhófà, àní Ọlọ́run wa, ìwọ ni ó yẹ láti gba ògo àti ọlá àti agbára, nítorí pé ìwọ ni ó dá ohun gbogbo, àti nítorí ìfẹ́ rẹ ni wọ́n ṣe wà, tí a sì dá wọn.” (Ìṣípayá 4:10, 11) Ìdí wà fún àwa náà láti máa yin Ẹlẹ́dàá nígbà gbogbo. Inú àwọn òbí máa ń dùn gan-an nígbà tọ́mọ wọn bá fi gbogbo ọkàn dúpẹ́ ohun tí wọ́n ṣe fún un! Fífi ẹ̀mí ìmoore ronú lórí oore tí Jèhófà ti ṣe fún wa àti dídúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀ tọkàntọkàn fún àwọn nǹkan wọ̀nyí jẹ́ ọ̀nà tó dára láti mú kí àwọn àdúrà wa sunwọ̀n sí i.
Èé Ṣe Tó Fi Yẹ Ká “Máa Gbàdúrà Láìdabọ̀”?
10. Ọ̀nà wo ni àdúrà gbà ń fún ìgbàgbọ́ wa lókun?
10 Gbígbàdúrà déédéé ń fún ìgbàgbọ́ wa lókun. Lẹ́yìn tí Jésù ṣàlàyé ìdí tó fi yẹ ká “máa gbàdúrà nígbà gbogbo àti láti má ṣe juwọ́ sílẹ̀,” ó wá béèrè pé: “Nígbà tí Ọmọ ènìyàn bá dé, yóò ha bá ìgbàgbọ́ ní ilẹ̀ ayé ní ti gidi bí?” (Lúùkù 18:1-8) Àdúrà àtọkànwá tó nítumọ̀ ń gbé ìgbàgbọ́ ró. Nígbà tí Ábúráhámù baba ńlá ń darúgbó, tí kò sì ní ọmọ kankan, ó bá Ọlọ́run sọ̀rọ̀ nípa ọ̀ràn náà. Nígbà tí Jèhófà ń dá a lóhùn, ó ní kí ó kọ́kọ́ wo ojú ọ̀run kó sì ka àwọn ìràwọ̀ ibẹ̀, ìyẹn tó bá lè kà wọ́n. Ọlọ́run wá mú un dá Ábúráhámù lójú pé: “Bẹ́ẹ̀ ni irú-ọmọ rẹ yóò dà.” Kí ni àbájáde rẹ̀? Ábúráhámù “ní ìgbàgbọ́ nínú Jèhófà; òun sì bẹ̀rẹ̀ sí kà á sí òdodo fún un.” (Jẹ́nẹ́sísì 15:5, 6) Tá a bá sọ gbogbo ohun tó wà lọ́kàn wa fún Jèhófà nínú àdúrà, tá a tẹ́wọ́ gba àwọn ìlérí rẹ̀ tó wà nínú Bíbélì, tá a sì ṣègbọràn sí i, òun yóò fún ìgbàgbọ́ wa lókun.
11. Báwo ni àdúrà ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ láti fàyà rán àwọn ìṣòro?
11 Àdúrà tún lè ràn wá lọ́wọ́ láti yanjú àwọn ìṣòro. Ṣé ẹrù ìgbésí ayé ń ta wá lórí ni, tí ipò nǹkan sì le koko fún wa? Bíbélì sọ fún wa pé: “Ju ẹrù ìnira rẹ sọ́dọ̀ Jèhófà fúnra rẹ̀, òun fúnra rẹ̀ yóò sì gbé ọ ró. Kì yóò jẹ́ kí olódodo ta gbọ̀n-ọ́n gbọ̀n-ọ́n láé.” (Sáàmù 55:22) Nígbà tá a bá fẹ́ ṣe àwọn ìpinnu tí kò rọrùn, a lè fara wé àpẹẹrẹ Jésù. Gbogbo òru ló fi gbàdúrà lóun nìkan kó tó yan àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ méjìlá. (Lúùkù 6:12-16) Ní alẹ́ tí Jésù lò kẹ́yìn kó tó kú, ó gbàdúrà kíkankíkan débi pé “òógùn rẹ̀ sì wá dà bí ẹ̀kán ẹ̀jẹ̀ tí ń jábọ́ sí ilẹ̀.” (Lúùkù 22:44) Kí ni àbájáde rẹ̀? “A sì gbọ́ ọ pẹ̀lú ojú rere nítorí ìbẹ̀rù rẹ̀ fún Ọlọ́run.” (Hébérù 5:7) Àdúrà tá a gbà tọkàntọkàn láìdabọ̀ yóò ràn wá lọ́wọ́ láti fara da àwọn ipò líle koko àtàwọn àdánwò.
12. Báwo ni ọ̀ràn àdúrà ṣe jẹ́ ká mọ̀ pé Jèhófà dìídì nífẹ̀ẹ́ sí wa?
12 Ìdí mìíràn tó fi yẹ ká sún mọ́ Jèhófà nípasẹ̀ àdúrà ni pé, òun náà yóò sún mọ́ wa. (Jákọ́bù 4:8) Nígbà tá a bá sọ gbogbo ohun tó wà lọ́kàn wa fún Jèhófà, ǹjẹ́ a kì í rí i pé ó ń pèsè àwọn ohun tá a nílò, ó sì ń bójú tó wa? Ọlọ́run tún máa ń fi ìfẹ́ rẹ̀ hàn sí wa lẹ́nì kọ̀ọ̀kan. Jèhófà fúnra rẹ̀ ló ń gbọ́ àdúrà táwọn ìrànṣẹ́ rẹ̀ lẹ́nì kọ̀ọ̀kan ń gbà sí i gẹ́gẹ́ bí Baba wọn ọ̀run, kò gbé iṣẹ́ náà lé ẹlòmíràn lọ́wọ́. (Sáàmù 66:19, 20; Lúùkù 11:2) Ó sì tún rọ̀ wá pé ká ‘kó gbogbo àníyàn wa wá bá òun nítorí ó bìkítà fún wa.’—1 Pétérù 5:6, 7.
13, 14. Kí nìdí tó fi yẹ ká máa gbàdúrà láìdabọ̀?
13 Àdúrà lè jẹ́ kí ìtara wa nínú iṣẹ́ ìwàásù túbọ̀ pọ̀ sí i, ó sì lè fún wa lókun nígbà táwọn èèyàn bá ń dágunlá tàbí tí wọ́n ń ṣàtakò tó wá ń ṣe wá bíi pé ká jáwọ́ nínú iṣẹ́ tá à ń ṣe. (Ìṣe 4:23-31) Àdúrà tún lè dáàbò bò wá lọ́wọ́ “àwọn ètekéte Èṣù.” (Éfésù 6:11, 17, 18) Nígbà tá a bá ń tiraka láti borí àwọn ìṣòro ojoojúmọ́, a lè máa bẹ Ọlọ́run ní gbogbo ìgbà pé kó fún wa lókun. Nínú àdúrà àwòkọ́ṣe tí Jésù gbà, ó bẹ̀bẹ̀ pé kí Jèhófà “dá wa nídè kúrò lọ́wọ́ ẹni burúkú náà,” Sátánì Èṣù.—Mátíù 6:13.
14 Tá a bá ń bá a lọ láti máa gbàdúrà pé kí Jèhófà ràn wá lọ́wọ́ láti kápá èrò tó máa ń wá síni lọ́kàn láti dẹ́ṣẹ̀, a ó rí ìrànlọ́wọ́ rẹ̀ gbà. Bíbélì mú un dá wa lójú pé: “Ọlọ́run jẹ́ olùṣòtítọ́, kì yóò sì jẹ́ kí a dẹ yín wò ré kọjá ohun tí ẹ lè mú mọ́ra, ṣùgbọ́n pa pọ̀ pẹ̀lú ìdẹwò náà, òun yóò tún ṣe ọ̀nà àbájáde kí ẹ lè fara dà á.” (1 Kọ́ríńtì 10:13) Ọ̀pọ̀ ìgbà ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù alára rí ìrànlọ́wọ́ afúnnilókun gbà látọ̀dọ̀ Jèhófà. Ó sọ pé: “Mo ní okun fún ohun gbogbo nípasẹ̀ agbára ìtóye ẹni tí ń fi agbára fún mi.”—Fílípì 4:13; 2 Kọ́ríńtì 11:23-29.
Má Ṣe Dẹ́kun Gbígbàdúrà Bó O Tilẹ̀ Ní Àwọn Kùdìẹ̀-Kudiẹ Kan
15. Kí ló lè ṣẹlẹ̀ tá a bá ń hùwà tó lòdì sí ìlànà Ọlọ́run?
15 Bí a bá fẹ́ kí àdúrà wa máa gbà, a ò gbọ́dọ̀ pa ìmọ̀ràn tó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tì. Àpọ́sítélì Jòhánù kọ̀wé pé: “Ohun yòówù tí a bá sì béèrè ni a ń rí gbà láti ọ̀dọ̀ rẹ̀, nítorí a ń pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́, a sì ń ṣe àwọn ohun tí ó dára lójú rẹ̀.” (1 Jòhánù 3:22) Àmọ́ kí ló lè ṣẹlẹ̀ nígbà tá a bá ń hùwà tó lòdì sí ìlànà Ọlọ́run? Ádámù àti Éfà fi ara wọn pa mọ́ lẹ́yìn tí wọ́n dẹ́ṣẹ̀ nínú ọgbà Édẹ́nì. Ó lè ṣe àwa náà bíi pé ká fi ara wa pa mọ́ “kúrò ní ojú Jèhófà” ká sì ṣíwọ́ gbígbàdúrà. (Jẹ́nẹ́sísì 3:8) Klaus tó jẹ́ alábòójútó arìnrìn-àjò tó ti pẹ́ lẹ́nu iṣẹ́, sọ pé: “Mo ti kíyè sí i pé àṣìṣe àkọ́kọ́ táwọn tó sú lọ kúrò lọ́dọ̀ Jèhófà àti ètò àjọ rẹ̀ máa ń ṣe ni pé wọn kì í gbàdúrà mọ́.” (Hébérù 2:1) Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí José Ángel nìyẹn. Ó sọ pé: “Fún nǹkan bí ọdún mẹ́jọ, agbára káká ni mo fi máa ń gbàdúrà sí Jèhófà. Ó máa ń ṣe mí bíi pé mi ò yẹ lẹ́ni tí ń bá a sọ̀rọ̀, bó tilẹ̀ jẹ́ pé mo ṣì kà á sí Baba mi ọ̀run.”
16, 17. Sọ àwọn àpẹẹrẹ tó fi hàn pé gbígbàdúrà déédéé lè ràn wá lọ́wọ́ láti borí àìlera tẹ̀mí.
16 Àwọn kan lára wa lè máa rò pé àwọn ò yẹ lẹ́ni tó ń gbàdúrà nítorí àìlera tẹ̀mí tàbí nítorí pé wọ́n ti hu ìwà àìtọ́ kan. Àmọ́ ìgbà yẹn gan-an ló yẹ ká jàǹfààní látinú àdúrà gbígbà. Jónà sá kúrò nídìí iṣẹ́ tá a yàn fún un. Àmọ́ ‘láti inú wàhálà ni Jónà ti ké pe Jèhófà, Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí dá a lóhùn. Láti inú ikùn Ṣìọ́ọ̀lù ni Jónà ti kígbe fún ìrànlọ́wọ́. Jèhófà sì gbọ́ ohùn rẹ̀.’ (Jónà 2:2) Jónà gbàdúrà, Jèhófà dáhùn àdúrà rẹ̀, àìsàn tẹ̀mí tó ń ṣe Jónà sì fò lọ.
17 José Ángel náà fi gbogbo ọkàn rẹ̀ gbàdúrà fún ìrànlọ́wọ́. Ó sọ pé: “Mo sọ gbogbo ohun tó wà lọ́kàn mi fún Ọlọ́run mo sì bẹ̀ ẹ́ pé kó dárí jì mí. Ó sì ràn mí lọ́wọ́ lóòótọ́. Bí kì í bá ṣe àdúrà ni, mi ò rò pé mo lè padà sínú òtítọ́. Ojoojúmọ́ ni mo wá ń gbàdúrà báyìí, mi ò kì í fi àkókò tí mò ń gbàdúrà ṣeré rárá.” Ó yẹ ká máa sọ gbogbo àṣìṣe wa pátá fún Ọlọ́run ká sì máa fi ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ bẹ̀ ẹ́ pé kó dárí jì wá. Nígbà tí Dáfídì Ọba jẹ́wọ́ àwọn àṣìṣe rẹ̀, Jèhófà dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ jì í. (Sáàmù 32:3-5) Jèhófà fẹ́ ràn wá lọ́wọ́ ni kì í ṣe pé ó fẹ́ ta wá nù. (1 Jòhánù 3:19, 20) Àdúrà àwọn àgbà ọkùnrin nínú ìjọ tún lè ràn wá lọ́wọ́ nípa tẹ̀mí, nítorí pé àdúrà wọn ‘ní agbára púpọ̀.’—Jákọ́bù 5:13-16.
18. Ìgbẹ́kẹ̀lé wo ni àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run ní bó ti wù kí wọ́n ṣako lọ tó?
18 Ǹjẹ́ a rí baba tó lè lé ọmọ rẹ̀ dà nù nígbà tó bá wá bẹ̀ ẹ́ pé kó ran òun lọ́wọ́ kó sì gba òun nímọ̀ràn nítorí àṣìṣe tí òun ṣe? Àkàwé ọmọ onínàákúnàá fi hàn pé bó ti wù kí a ṣako lọ tó, inú Baba wa ọ̀rùn máa ń dùn nígbà tá a bá padà sọ́dọ̀ rẹ̀. (Lúùkù 15:21, 22, 32) Jèhófà rọ gbogbo àwọn tó ṣi ẹsẹ̀ gbé pé kí wọ́n ké pe òun, “nítorí tí òun yóò dárí jì lọ́nà títóbi.” (Aísáyà 55:6, 7) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Dáfídì dá ẹ̀ṣẹ̀ wíwúwo tó pọ̀, ó ké pe Jèhófà, ó sọ pé: “Fi etí sí àdúrà mi, Ọlọ́run; má sì fi ara rẹ pa mọ́ fún ìbéèrè mi fún ojú rere.” Ó tún sọ pé: “Alẹ́ àti òwúrọ̀ àti ìgbà ọ̀sán gangan, èmi kò lè ṣàìfi ìdàníyàn hàn, kí n sì máa kédàárò, [Jèhófà] sì ń gbọ́ ohùn mi.” (Sáàmù 55:1, 17) Ẹ wo bí ìyẹn ti fini lọ́kàn balẹ̀ tó!
19. Kí nìdí tí kò fi yẹ ká máa rò pé àwọn àdúrà tí a kò rí ìdáhùn wọn jẹ́ ẹ̀rí pé Ọlọ́run ò gbọ́ àwọn àdúrà náà?
19 Bó bá ṣẹlẹ̀ pé a ò rí ìdáhùn sí àdúrà wa ní kíákíá ńkọ́? A gbọ́dọ̀ rí i pé àwọn ohun tá a ń béèrè bá ìfẹ́ Jèhófà mu, ká sì gba àdúrà náà ní orúkọ Jésù. (Jòhánù 16:23; 1 Jòhánù 5:14) Jákọ́bù ọmọ ẹ̀yìn mẹ́nu kan àwọn Kristẹni kan tí àdúrà wọn ò gbà nítorí pé wọ́n “ń béèrè fún ète tí kò tọ́.” (Jákọ́bù 4:3) Ní ìdàkejì, kò yẹ ká máa yára rò pé àwọn àdúrà tí a kò rí ìdáhùn sí jẹ́ ẹ̀rí pé Ọlọ́run ò gbọ́ àwọn àdúrà náà. Nígbà mìíràn, Jèhófà lè jẹ́ kí àwọn òlùjọ́sìn rẹ̀ tòótọ́ gbàdúrà nípa ọ̀ràn kan fún àkókò tó gùn kó tó dá wọn lóhùn. Jésù sọ pé: “Ẹ máa bá a nìṣó ní bíbéèrè, a ó sì fi í fún yín.” (Mátíù 7:7) Nítorí ìdí èyí, a ní láti “ní ìforítì nínú àdúrà.”— Róòmù 12:12.
Máa Gbàdúrà Déédéé
20, 21. (a) Kí nìdí tá a fi ní láti máa gbàdúrà láìdabọ̀ láwọn “ọjọ́ ìkẹyìn” yìí? (b) Kí ni a óò rí gbà nígbà tá a bá ń sún mọ́ ìtẹ́ inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Jèhófà lójoojúmọ́?
20 Ńṣe ni pákáǹleke àtàwọn ìṣòro ń peléke sí i ní “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn,” tí “àwọn àkókò lílekoko tí ó nira láti bá lò” yìí jẹ́ àmì rẹ̀. (2 Tímótì 3:1) Àwọn àdánwò sì lè tètè gbà wá lọ́kàn. Àmọ́ àwọn àdúrà tá à ń gbà láìdabọ̀ yóò ràn wá lọ́wọ́ láti pọkàn pọ̀ sórí àwọn nǹkan tẹ̀mí láìfi àwọn ìṣòro, àdánwò àti ìrẹ̀wẹ̀sì pè. Àwọn àdúrà tá a ń gbà sí Jèhófà lójoojúmọ́ lè fún wa ní ìtìlẹ́yìn tá a nílò.
21 Ọwọ́ Jèhófà tó jẹ́ “Olùgbọ́ àdúrà,” kò fìgbà kan dí láti gbọ́ àdúrà wa. (Sáàmù 65:2) Kí àwa náà má ṣe jẹ́ kí ọwọ́ wa dí láé láti bá a sọ̀rọ̀. Bíbá Ọlọ́run dọ́rẹ̀ẹ́ ni ohun ṣíṣeyebíye jù lọ tá a ní. Ẹ má ṣe jẹ́ ká fọwọ́ yẹpẹrẹ mú un láé. “Nítorí náà, ẹ jẹ́ kí a sún mọ́ ìtẹ́ inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí pẹ̀lú òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ, kí a lè rí àánú gbà, kí a sì rí inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí fún ìrànlọ́wọ́ ní àkókò tí ó tọ́.”—Hébérù 4:16.
Báwo Lo Ṣe Máa Dáhùn?
• Ẹ̀kọ́ wo la ti kọ́ lára wòlíì Dáníẹ́lì nípa bí àdúrà ti ṣe pàtàkì tó?
• Báwo la ṣe lè jẹ́ kí okùn ọ̀rẹ́ àárín àwa àti Jèhófà túbọ̀ lágbára sí i?
• Kí nìdí tó fi yẹ ká máa gbàdúrà láìdabọ̀?
• Kí nìdí tá a ò fi gbọ́dọ̀ jẹ́ kí èrò pé a ò yẹ lẹ́ni tó ń gbàdúrà dí wa lọ́wọ́ láti gbàdúrà sí Jèhófà?
[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]
Nehemáyà gba àdúrà ṣókí ní ìdákẹ́jẹ́ẹ́ kó tó bá ọba sọ̀rọ̀
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]
Hánà “gbàdúrà lọ títí níwájú Jèhófà”
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]
Jésù fi gbogbo òru gbàdúrà kó tó yan àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ méjìlá
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 20]
Àwọn àǹfààní láti gbàdúrà máa ń yọjú láti òwúrọ̀ ṣúlẹ̀