Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Martin Luther—Ogún Tó Fi Sílẹ̀

Martin Luther—Ogún Tó Fi Sílẹ̀

Martin Luther—Ogún Tó Fi Sílẹ̀

ÌWÉ ìròyìn Time sọ pé: “Kò sí ẹlòmíràn nínú ìtàn tá a tíì kọ ìwé tó pọ̀ nípa rẹ̀ tó [Martin Luther], àyàfi Jésù Kristi tó jẹ́ ọ̀gá rẹ̀.” Àwọn ọ̀rọ̀ àti ìṣe Luther ló mú kí wọ́n dá Ẹgbẹ́ Alátùn-únṣe Ìsìn sílẹ̀—ìyẹn ẹgbẹ́ ìsìn tí wọ́n pè ní “ìyípadà tá ò rírú rẹ̀ rí nínú ìtàn ẹ̀dá èèyàn.” Ó tipa bẹ́ẹ̀ yí ọ̀nà tí wọ́n gbà ń ṣe ìsìn padà nílẹ̀ Yúróòpù ó sì fòpin sí àkókò ojú dúdú ní ilẹ̀ yẹn. Luther náà ló tún fi ìpìlẹ̀ bí wọ́n ṣe ń kọ èdè Jámánì lọ́nà tó bójú mu lélẹ̀. Bíbélì tó túmọ̀ ló ṣì gbayì jù lọ ní èdè Jámánì títí dòní olónìí.

Irú èèyàn wo ni Martin Luther? Báwo ló ṣe wá di ẹni tá ò lè kóyán rẹ̀ kéré nínú ọ̀ràn ilẹ̀ Yúróòpù?

Luther Di Ọ̀mọ̀wé Akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀

Wọ́n bí Martin Luther nílùú Eisleben, ní ilẹ̀ Jámánì ní November 1483. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ibi tí wọ́n ti ń wa bàbà ni Bàbá rẹ̀ ti ń ṣiṣẹ́, ó gbìyànjú láti wá owó tó pọ̀ tó kí Martin lè kàwé dáadáa. Lọ́dún 1501, Martin wọ Yunifásítì Erfurt. Ibi ìkówèésí Yunifásítì yìí ló ti kọ́kọ́ ka Bíbélì. Ó sọ pé: “Mo gbádùn ìwé náà gan-an ni, mo sì lérò pé èmi náà á tó ẹni tó ń ní ìwé yìí lọ́jọ́ kan.”

Nígbà tí Luther pé ọmọ ọdún méjìlélógún, ó wọ ilé ìwé àwọn ajẹ́jẹ̀ẹ́ ìnìkàngbé ti Augustine nílùú Erfurt. Nígbà tó yá, ó wọ Yunifásítì Wittenberg, ibẹ̀ ló sì ti di ọ̀mọ̀wé nínú ẹ̀kọ́ ìsìn. Luther máa ń rò pé òun kò yẹ lẹ́ni tí Ọlọ́run ń ṣe ojú rere sí, ìbànújẹ́ sì máa ń dorí rẹ̀ kodò nítorí ẹ̀rí ọkàn tó máa ń dà á láàmú. Àmọ́ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, àdúrà àti àṣàrò ṣíṣe ràn án lọ́wọ́ láti túbọ̀ lóye ojú tí Ọlọ́run fi ń wo àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀. Luther mọ̀ pé ojú rere Ọlọ́run kì í ṣe ohun téèyàn ń kà sí ẹ̀tọ́ òun. Kàkà bẹ́ẹ̀, àwọn onígbàgbọ́ máa ń rí i gbà nípasẹ̀ inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí.—Róòmù 1:16; 3:23, 24, 28.

Báwo ni Luther ṣe mọ̀ pé òye tuntun tóun ní tọ̀nà? Kurt Aland tó jẹ́ ọ̀jọ̀gbọ́n nínú ìtàn ṣọ́ọ̀ṣì ìjímìjí àti ìwádìí nípa Májẹ̀mú Tuntun, kọ̀wé pé: “Ó ṣàṣàrò lórí Bíbélì látòkèdélẹ̀ láti mọ̀ bóyá ìmọ̀ rẹ̀ tuntun yìí jẹ́ ojúlówó tá a bá fi wéra pẹ̀lú àwọn ohun mìíràn tí Bíbélì sọ, ó sì rí i pé Bíbélì kín ìgbàgbọ́ òun lẹ́yìn.” Ẹ̀kọ́ pé ìgbàgbọ́ ló ń fúnni ní ìgbàlà pé kì í ṣe iṣẹ́, jẹ́ òpómúléró nínú àwọn ẹ̀kọ́ Luther.

Inú Rẹ̀ Kò Dùn Sí Owó Ìdáríjì Ẹ̀ṣẹ̀

Òye tí Luther ní nípa ojú tí Ọlọ́run fi ń wo àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ mú un forí gbárí pẹ̀lú Ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì. Ìgbàgbọ́ tí wọ́n ní nígbà yẹn ni pé tí ẹlẹ́ṣẹ̀ kan bá kú, ó ní láti jìyà ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ fún àkókò kan pàtó. Àmọ́ ṣá, wọ́n sọ pé àkókò yìí lè dín kù tí onítọ̀hún bá ti san iye owó kan láti fi gba ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ lọ́dọ̀ póòpù. Johann Tetzel tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn tó ń bá Bíṣọ́ọ̀bù Àgbà Albert ti Mainz gba owó ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀, sọ iṣẹ́ yìí di okòwò tó ń mówó wọlé gan-an, ó sì ń gba owó ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ lọ́wọ́ àwọn gbáàtúù. Ọ̀pọ̀ èèyàn ló ka owó ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ sí àsansílẹ̀ owó ìdáríjì fún ẹ̀ṣẹ̀ tí wọ́n máa dá lọ́jọ́ iwájú.

Owó ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ tí wọ́n ń gbà yìí kò tẹ́ Luther lọ́rùn rárá. Ó mọ̀ pé èèyàn kò lè fi owó bẹ Ọlọ́run. Nígbà ìrúwé ọdún 1517, ó kọ ìwé márùndínlọ́gọ́rùn-ún tó lókìkí gan-an, tó fi fẹ̀sùn kan ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì lórí bí wọ́n ṣe ń náwó nínàákúnàá, tí ẹ̀kọ́ ìsìn wọn ò bójú mu, tí wọ́n sì ń ṣe ẹ̀sìn bí kò ṣe yẹ. Nítorí pé ńṣe ni Luther fẹ́ tún nǹkan ṣe, tí kì í sì í ṣe pé ó fẹ́ ṣọ̀tẹ̀, ó fi àwọn ẹ̀dà ìwé náà ránṣẹ́ sí Bíṣọ́ọ̀bù Àgbà Albert ti Mainz àtàwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ bíi mélòó kan mìíràn. Ọ̀pọ̀ àwọn òpìtàn ló ń sọ pé ọdún 1517 tàbí láàárín àkókò náà ni Àtúnṣe Ìsìn bẹ̀rẹ̀.

Kì í ṣe Luther nìkan ló ń kédàárò nípa ìwà àìtọ́ tó ń lọ nínú ìsìn. Ní ọgọ́rùn-ún ọdún ṣáájú àkókò yìí, ọ̀gbẹ́ni alátùn-únṣe ìsìn kan, ará Czech, tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Jan Hus, ti bu ẹnu àtẹ́ lu gbígba owó ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀. Kódà, ṣáájú ìgbà tí Hus sọ̀rọ̀ yẹn, John Wycliffe ti ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì ti sọ pé àwọn àṣà kan tó ń lọ nínú ẹ̀sìn Kátólíìkì kò bá Ìwé Mímọ́ mu. Àwọn kan tí wọ́n jọ gbáyé pẹ̀lú Luther, àwọn bíi Erasmus ti Rotterdam àti Tyndale ti ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì gbìyànjú láti ṣàtúnṣe ìsìn. Àmọ́ a dúpẹ́ lọ́wọ́ Johannes Gutenberg tó ṣe ẹ̀rọ ìtẹ̀wé ní ilẹ̀ Jámánì, òun ló jẹ́ ká gbọ́ ọ̀rọ̀ tí Luther sọ nílé lóko ju tàwọn alátùn-únṣe ìsìn ẹlẹ́gbẹ́ rẹ̀ lọ.

Ẹ̀rọ ìtẹ̀wé Gutenberg tó wà nílùú Mainz bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ lọ́dún 1455. Nígbà tó fi máa di ìparí ọ̀rúndún náà, ẹ̀rọ ìtẹ̀wé ti wà láwọn ọgọ́ta ìlú ní ilẹ̀ Jámánì àti ní orílẹ̀-èdè méjìlá mìíràn ní ilẹ̀ Yúróòpù. Ìgbà àkọ́kọ́ rèé tó máa ṣeé ṣe fún àwọn èèyàn láti tètè gbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ tí wọ́n fẹ́ mọ̀ nípa rẹ̀. Ó ṣeé ṣe kí Luther má mọ̀ o, àmọ́ àwọn kan tẹ ìwé márùndínlọ́gọ́rùn-ún tó kọ, wọ́n sì pín wọn káàkiri. Ọ̀ràn ṣíṣe àtúnṣe ìsìn ti wá kúrò ní ọ̀rọ̀ abẹ́lé báyìí. Ó ti wá di àríyànjiyàn tó délé dóko, báyìí sì ni Martin Luther ṣe di ẹni tó lókìkí jù lọ nílẹ̀ Jámánì.

“Oòrùn àti Òṣùpá” Fárígá

Fún ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún ni ilẹ̀ Yúróòpù ti wà lọ́wọ́ àwọn alágbára méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, ìyẹn Ilẹ̀ Ọba Róòmù Mímọ́ àti Ìjọ Kátólíìkì. Hanns Lilje tó jẹ́ ààrẹ Ẹ̀sìn Luther Lágbàáyé nígbà kan rí ṣàlàyé pé: “Ńṣe ni olú ọba àti póòpù jọ ń ṣe nǹkan pa pọ̀ bí oòrùn àti òṣùpá.” Àmọ́ ṣá, ohun tí kò dá àwọn èèyàn lójú ni pé wọn kò mọ ẹni tó jẹ́ oòrùn wọn kò sì mọ ẹni tó jẹ́ òṣùpá. Nígbà tó fi máa di ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀rúndún kẹrìndínlógún, àwọn agbára méjèèjì yìí ti gungi ré kọjá ewé. Ìyípadà ti fẹ́rẹ̀ẹ́ dé.

Póòpù Leo Kẹwàá tutọ́ sókè ó fojú gbà á nítorí ìwé márùndínlọ́gọ́rùn-ún tí Luther kọ, ó sì halẹ̀ pé òun máa yọ ọ́ lẹ́gbẹ́ àyàfi tó bá kó ọ̀rọ̀ rẹ̀ jẹ. Inú bí Luther gan-an débi pé gbangba ìta ló ti dáná sun ìwé ìhàlẹ̀ tí póòpù kọ. Ẹ̀yìn ìyẹn ló tún kọ àwọn ìwé mìíràn tó fi gba àwọn èèyàn níyànjú láti ṣàtúnṣe sóhun tó ń lọ nínú ṣọ́ọ̀ṣì, àní bí póòpù ò bá tiẹ̀ fọwọ́ sí i pàápàá. Lọ́dún 1521, Póòpù Leo Kẹwàá yọ Luther lẹ́gbẹ́. Nígbà tí Luther fárígá pé wọ́n dẹ́bi fún òun lọ́nà àìtọ́, Olú Ọba Charles Karùn-ún sọ pé kí alátùn-únṣe ìsìn yìí wá fara hàn níwájú ìgbìmọ̀ àwọn lọ́balọ́ba nílùú Worms. Tijó tìlù làwọn èrò fi wọ́ tẹ̀ lé Luther nígbà ìrìn àjò ọlọ́jọ́ mẹ́ẹ̀ẹ́dógún tó rìn láti ìlú Wittenberg lọ sí ìlú Worms ní April 1521. Tọmọdé tàgbà ló tẹ́wọ́ gba àwọn ẹ̀kọ́ rẹ̀, gbogbo èèyàn ló sì fẹ́ rí i.

Nílùú Worms, Luther dúró níwájú olú ọba, àwọn ọmọ aládé àtàwọn póòpù jàǹkàn-jàǹkàn. Jan Hus ti fara hàn níwájú irú ìgbìmọ̀ yìí nílùú Constance ní 1415, ńṣe ni wọ́n sì dì í mọ́ òpó igi tí wọ́n dáná sun ún. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé iwájú àwọn èèyàn jàǹkàn-jàǹkàn nínú ṣọ́ọ̀ṣì àtàwọn olú ọba ni Luther wà, ó kọ̀ láti kó ọ̀rọ̀ rẹ̀ jẹ. Ó ní àyàfi bí àwọn alátakò òun bá lè fi hàn látinú Bíbélì pé nǹkan tóun ṣe kò tọ̀nà. Àmọ́ kò sẹ́ni tó mọ Ìwé Mímọ́ tó o nínú gbogbo wọn. Àkọsílẹ̀ kan tí wọ́n pè ní Àbájáde Ìgbẹ́jọ́ Nílùú Worms, sọ ibi tí wọ́n forí ọ̀rọ̀ náà tì sí. Ó sọ pé wọ́n pe Luther ní arúfin wọ́n sì fòfin de àwọn ìwé rẹ̀. Ní báyìí tí póòpù ti yọ ọ́ lẹ́gbẹ́ tí olú ọba sì ti kà á sí arúfin, ikú rọ̀ dẹ̀dẹ̀ sórí ẹ̀.

Ohun kan tí ẹni kẹ́ni kò retí àmọ́ tó wúni lórí gan-an wá ṣẹlẹ̀. Nígbà tí Luther ń padà sílùú Wittenberg, àwọn ajínigbé gbé e lọ. Àmọ́ Frederick ti Saxony ló ní kí wọ́n lọ jí i gbé láti fi dáàbò bo ẹ̀mí rẹ̀. Èyí ló mú kí Luther bọ́ lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá rẹ̀. Wọ́n gbé Luther lọ sí ilé ńlá kan tó wà ní àdádó nílùú Wartburg. Ibẹ̀ ló ti wá hu irùngbọ̀n yẹ̀ù-yẹ̀ù táwọn èèyàn ò da mọ̀ mọ́, tó wá di bọ̀rọ̀kìnní tí wọ́n mọ̀ sí Junker Jörg.

Àwọn Èèyàn Ń Ra Bíbélì September Wìtìwìtì

Odidi oṣù mẹ́wàá tó tẹ̀ lé e ni Luther fi wà ní ilé ńlá kan tó wà nílùú Wartburg, kí olú ọba àti póòpù má bàa rí i. Ìwé Welterbe Wartburg ṣàlàyé pé: “Àkókò tó fi wà ní Wartburg wà lára àkókò tó dára jù lọ tó fi ṣe nǹkan tó ní láárí jù lọ nínú ìgbésí ayé rẹ̀.” Ibẹ̀ ló ti parí títúmọ̀ Ìwé Mímọ́ Lédè Gíríìkì látọwọ́ Erasmus sí èdè Jámánì, èyí sì jẹ́ ọ̀kan lára àwọn iṣẹ́ bàǹtàbanta tó ṣe. Wọ́n tẹ̀ ẹ́ jáde ní September ọdún 1522, wọn ò sì kọ ọ́ sí i pé Luther ló túmọ̀ rẹ̀. Wọ́n pe Bíbélì yìí ní Bíbélì September. Guilder kan àtààbọ̀ ni iye owó tí wọ́n ń ta Bíbélì yìí, ìyẹn sì jẹ́ owó iṣẹ́ tí ọmọ ọ̀dọ̀ kan máa gbà ní odindi ọdún kan. Pẹ̀lú bó ṣe wọ́n tó yẹn, ńṣe làwọn èèyàn ń rà á wìtìwìtì. Láàárín ọdún kan, wọ́n ti ṣe àtúntẹ̀ rẹ̀ lẹ́ẹ̀mejì wọ́n sì tẹ ẹgbàáta [6,000] ẹ̀dà jáde. Láàárín ọdún méjìlá tó tẹ̀ lé e, ó lé ní ìgbà mọ́kàndínláàádọ́rin tí wọ́n fi ṣe àtúntẹ̀ rẹ̀.

Lọ́dún 1525, Martin Luther fẹ́ Katharina von Bora, ìyẹn obìnrin tó jẹ́ ajẹ́jẹ̀ẹ́ ìnìkàngbé tẹ́lẹ̀. Aya tó mọṣẹ́ rẹ̀ níṣẹ́ ni Katharina, ó sì máa ń fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú ọkọ rẹ̀ tó jẹ́ ọ̀làwọ́. Yàtọ̀ sí ìyàwó Luther àtàwọn ọmọ rẹ̀ mẹ́fà, ó tún gba àwọn ọ̀rẹ́, àwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ àtàwọn olùwá-ibi-ìsádi sínú ilé rẹ̀. Nígbà tí Luther ń darúgbó lọ, ó di olùgbaninímọ̀ràn táwọn èèyàn ń wárí fún débi pé ńṣe làwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ tí wọ́n bá a lálejò máa ń mú gègé àti bébà dání láti kọ àwọn ọ̀rọ̀ tó bá ń sọ sílẹ̀. Wọ́n kó àwọn ọ̀rọ̀ rẹ̀ yìí pa pọ̀ wọ́n sì fi wọ́n ṣe ìwé kan tí wọ́n pe orúkọ rẹ̀ ní Luthers Tischreden, (Àwọn Ọ̀rọ̀ Ẹnu Luther). Ìgbà kan wà tó jẹ́ pé kò síwèé mìíràn tó gbajúmọ̀ ju ìwé yìí lọ lédè Jámánì àyàfi Bíbélì.

Atúmọ̀ Èdè Tó Lẹ́bùn Tó Sì Kọ̀wé Rẹpẹtẹ

Nígbà tó fi máa di ọdún 1534, Luther ti fẹ́rẹ̀ẹ́ parí títúmọ̀ Ìwé Mímọ́ lédè Hébérù. Ó ní ẹ̀bùn béèyàn ṣe ń lo ọ̀nà ìgbàkọ̀wé, ìró ọ̀rọ̀ àti àkànlò èdè lọ́nà tó gún régé. Èyí ló jẹ́ kí Bíbélì tó túmọ̀ lè yé gbogbo èèyàn. Nígbà tí Luther ń sọ̀rọ̀ nípa ọ̀nà tó gbà ń ṣètumọ̀, ó ní: “A gbọ́dọ̀ bá àwọn ìyá fọ̀rọ̀ jomitoro ọ̀rọ̀ nínú ilé, ká bá àwọn ọmọ fọ̀rọ̀ wérọ̀ lójú pópó, ká bá àwọn gbáàtúù fèrò wérò lọ́jà, ká wo ọ̀nà tí wọ́n gbà ń sọ̀rọ̀ ká sì fi èyí ṣe ìtumọ̀ ìwé fún wọn.” Bíbélì Luther ló fi ìpìlẹ̀ bí wọ́n ṣe ń kọ̀wé lédè Jámánì lélẹ̀, ọ̀nà ìkọ̀wé yìí ló sì wá di èyí táwọn èèyàn ń lò káàkiri orílẹ̀-èdè náà.

Bí Luther ṣe lẹ́bùn ṣíṣe ìtumọ̀ náà ló tún lẹ́bùn ìwé kíkọ. Wọ́n sọ pé ọ̀sẹ̀ méjìméjì ló máa ń kọ ìwé lórí ọ̀ràn kan tó fakíki, ó sì ṣe èyí ní gbogbo àkókò tó fi ṣiṣẹ́ ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀. Díẹ̀ lára àwọn ìwé náà ní àríyànjiyàn nínú nítorí pé òun fúnra rẹ̀ tó ṣe àwọn ìwé wọ̀nyí lè jiyàn dọ́ba. Ọ̀rọ̀ inú àwọn ìwé tó kọ láàárọ̀ ọjọ́ ayé rẹ̀ mú bí idà, kàkà kó sì rọlẹ̀ bó ṣe ń dàgbà, kan-kan-kan ló tún ń le sí i. Àwọn àròkọ tó kọ lọ́jọ́ alẹ́ rẹ̀ tún le kú. Gẹ́gẹ́ bí ìwé Lexikon für Theologie und Kirche ṣe sọ, àwọn ìwé tí Luther kọ fi hàn pé “ó máa ń bínú sódì” pé “kò lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀” àti pé “ó máa ń fẹ́ ṣe ohun tó bá dáwọ́ lé láṣeyanjú.”

Nígbà tí Ogun Mẹ̀kúnnù bẹ́ sílẹ̀ lágbègbè kan, táwọn ará àgbègbè náà sì para wọn nípakúpa, wọ́n ní kí Luther wá sọ ohun tó rí sí rògbòdìyàn náà. Ǹjẹ́ ó tọ́ kí àwọn mẹ̀kúnnù yìí bá àwọn olórí wọn ṣe awuyewuye? Luther kò tìtorí pé káwọn èèyàn lè gba tòun kó wá sọ ohun tó máa múnú àwọn mẹ̀kúnnù náà dùn. Ó gbà gbọ́ pé àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run gbọ́dọ̀ ṣègbọràn sáwọn aláṣẹ. (Róòmù 13:1) Ńṣe ni Luther sọ ojú abẹ níkòó, ó ní wọ́n gbọ́dọ̀ paná ọ̀tẹ̀ náà. Ó sọ pé: “Kí ẹni tó bá lè gúnni lọ́bẹ máa gún un, kí ẹni tó bá lè ṣáni ládàá máa ṣá a, kí ẹni tó bá sì lè pààyàn pa á.” Hanns Lilje sọ pé ohun tí Luther sọ yìí mú kó di “ẹni ẹ̀tẹ́ láàárín àwọn èèyàn náà.” Kò tán síbẹ̀ o, àwọn ìwé tí Luther wá kọ nípa àwọn Júù tó kọ̀ láti di Kristẹni, pàápàá ọ̀kan tó pe àkọlé rẹ̀ ní On the Jews and Their Lies, mú kí ọ̀pọ̀ èèyàn kà á sí ẹni tó kórìíra àwọn Júù.

Ogún Tí Luther Fi Sílẹ̀

Àtúnṣe Ìsìn tí àwọn èèyàn bíi Luther, Calvin àti Zwingli ṣe, ló mú ẹ̀sìn tuntun kan jáde èyí tí wọ́n pè ní ẹ̀sìn Pùròtẹ́sítáǹtì. Ogún pàtàkì tí Luther fi sílẹ̀ nínú ẹ̀sìn Pùròtẹ́sítáǹtì ni ẹ̀kọ́ pàtàkì tó fi ń kọ́ni pé ìgbàgbọ́ nìkan ló lè fúnni ní ìgbàlà. Ó di pé káwọn gbáàtúù ará Jámánì yan ẹ̀sìn kan, yálà ẹ̀sìn Pùròtẹ́sítáǹtì tàbí ẹ̀sìn Kátólíìkì. Ẹ̀sìn Pùròtẹ́sítáǹtì gbalẹ̀ gan-an ní Scandinavia, Switzerland, ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì àti Netherlands. Lónìí, ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn ló ń ṣe ẹ̀sìn náà.

Ọ̀pọ̀ èèyàn tí kò tẹ́wọ́ gba gbogbo ohun tí Luther gbà gbọ́ ló ṣì ń kan sáárá sí ọkùnrin yìí dòní. Ilẹ̀ Olómìnira ti Jámánì tẹ́lẹ̀, ìyẹn Eisleben, Erfurt, Wittenberg àti Wartburg, ṣayẹyẹ ìrántí ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta ọdún tí wọ́n ti bí Luther ní 1983. Ilẹ̀ Oníjọba Àjùmọ̀ni yìí kà á sí ẹnì kan tó ta yọ lọ́lá nínú ìtàn àti àṣà ilẹ̀ Jámánì. Síwájú sí i, ẹnì kan tó jẹ́ ẹlẹ́kọ̀ọ́ ìsìn Kátólíìkì láwọn ọdún 1980 ṣàkópọ̀ iṣẹ́ ribiribi tí Luther ti gbé ṣe, ó sì sọ pé: “Kò sí ẹlòmíì tó dìde lẹ́yìn Luther tó dà bí rẹ̀.” Ọ̀jọ̀gbọ́n Aland kọ̀wé pé: “Ọdọọdún làwọn èèyàn máa ń kọ àwọn ìwé tuntun tó lé ní ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta nípa Martin Luther àti Àtúnṣe Ìsìn tó ṣe—ó sì fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ gbogbo èdè táwọn èèyàn ń sọ jù lọ láyé ni wọ́n fi ń tẹ̀ àwọn ìwé náà jáde.”

Orí Martin Luther pé gan-an ni, kì í gbàgbé nǹkan, ọ̀gá ni níbi pé ká lo ọ̀rọ̀ bó ṣe yẹ, kì í sì í ṣọ̀lẹ. Oníwàdùwàdù èèyàn ni, ó sì máa ń bẹnu àtẹ́ lu nǹkan. Bákan náà ni kì í fara mọ́ ohun tó bá jẹ́ àgàbàgebè lójú rẹ̀. Nígbà tí Luther ń kú lọ nílùú Eisleben ní February 1546, àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé ṣé ó ṣì dúró lórí ẹ̀kọ́ ìgbàgbọ́ tó fi kọ́ àwọn ẹlòmíràn. Ó dáhùn pé “Bẹ́ẹ̀ ni.” Luther ti kú o, àmọ́ ọ̀pọ̀ èèyàn ló ṣì dìrọ̀ mọ́ àwọn ẹ̀kọ́ ìgbàgbọ́ tó fi kọ́ni.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 27]

Luther kò fara mọ́ sísan owó ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀

[Credit Line]

Mit freundlicher Genehmigung: Wartburg-Stiftung

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 28]

Luther kọ̀ láti kó ọ̀rọ̀ rẹ̀ jẹ, ó ní àyàfi bí àwọn alátakò òun bá lè fi hàn látinú Bíbélì pé nǹkan tóun ṣe kò tọ̀nà

[Credit Line]

Látinú ìwé The Story of Liberty, 1878

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 29]

Iyàrá Luther nínú Ilé Ńlá tó wà ní Wartburg, níbi tó ti túmọ̀ Bíbélì

[Credit Line]

Àwòrán méjèèjì: Mit freundlicher Genehmigung: Wartburg-Stiftung

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 26]

Látinú ìwé Martin Luther The Reformer, Ìtẹ̀jáde Ẹlẹ́ẹ̀kẹta, Látọwọ́ Toronto Willard Tract Depository, Toronto, Ontario

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 30]

Látinú ìwé The History of Protestantism (Apá kìíní)