Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìbéèrè Pọ̀—Àmọ́ Ìdáhùn Ò Tó Nǹkan

Ìbéèrè Pọ̀—Àmọ́ Ìdáhùn Ò Tó Nǹkan

Ìbéèrè Pọ̀—Àmọ́ Ìdáhùn Ò Tó Nǹkan

NÍ ÒWÚRỌ̀ November 1, 1755, nígbà tí wọ́n ń ṣe ayẹyẹ Ọjọ́ Àwọn Ẹni Mímọ́, ilẹ̀ ríri kan tó lágbára ṣẹlẹ̀ ní Lisbon lákòókò tí ọ̀pọ̀ jù lọ èèyàn wà ní ṣọ́ọ̀ṣì. Ẹgbẹẹgbẹ̀rún ilé ló wó lulẹ̀, àìmọye èèyàn ló sì kú.

Kété lẹ́yìn àjálù yìí ni Voltaire, ìyẹn òǹkọ̀wé ọmọ ilẹ̀ Faransé nì, gbé ewì rẹ̀ tó kọ lédè Faransé tó pé ní Poème sur le désastre de Lisbonne (Ewì Lórí Àjálù Lisbon) jáde, nínú èyí tó ti ta ko sísọ táwọn èèyàn ń sọ pé àjálù náà jẹ́ àmúwá Ọlọ́run nítorí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn èèyàn. Ohun tí Voltaire kọ láti fi hàn pé irú àjálù bẹ́ẹ̀ kọjá ìmọ̀ èèyàn tàbí ohun téèyàn lè ṣàlàyé ni pé:

Ìṣẹ̀dá kò lè sọ̀rọ̀, àsán ni gbogbo ìbéèrè tá a ń béèrè lọ́wọ́ rẹ̀;

Ọlọ́run tó lè bá ẹ̀dá èèyàn sọ̀rọ̀ ló yẹ ká bi.

Ká sòótọ́, kì í ṣe Voltaire ló kọ́kọ́ gbé ìbéèrè dìde nípa Ọlọ́run. Jálẹ̀ ìtàn ẹ̀dá ènìyàn ni àwọn àjálù àti ìṣẹ̀lẹ̀ búburú tí ń jẹ́ kí ọ̀pọ̀ ìbéèrè ru gùdù lọ́kàn ọmọ aráyé. Ní ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún sẹ́yìn, Jóòbù baba ńlá, tí gbogbo ọmọ rẹ̀ ṣe aláìsí tí àìsàn búburú sì kọlù òun fúnra rẹ̀, béèrè ìbéèrè nípa Ọlọ́run pé: “Èé ṣe tí [Ọlọ́run] fi fún ẹni tí ó ní ìdààmú ní ìmọ́lẹ̀, tí ó sì fún àwọn ọlọ́kàn kíkorò ní ìyè?” (Jóòbù 3:20) Lóde òní, ọ̀pọ̀ ló ń ṣe kàyéfì nípa ìdí tí Ọlọ́run olóore àti onífẹ̀ẹ́ ṣe ní láti dákẹ́ tó ń wo ìyà tó ń jẹ àwọn èèyàn táwọn kan sì ń gbé ẹ̀bi fún aláre.

Ọ̀pọ̀ ní kì í tiẹ̀ fẹ́ gbọ́ rárá pé Ẹlẹ́dàá kan wà tó bìkítà nípa ẹ̀dá èèyàn nígbà tí wọ́n bá rí i tí ìyàn mú, tí ogun ń jà, tí àìsàn ń ṣe wọ́n, àti nígbà tí èèyàn wọ́n bá kú. Onímọ̀ ọgbọ́n orí kan tí kò gbà pé Ọlọ́run wà sọ pé: “Kò sí bá a ò ṣe ní dá Ọlọ́run lẹ́bi fún ìyà tó ń jẹ àwọn ọmọdé, . . . àyàfi tí Ọlọ́run ò bá sí ló kù.” Àwọn àjálù búburú, bí Ìpakúpa Rẹpẹtẹ tó wáyé nígbà Ogun Àgbáyé Kejì, mú káwọn èèyàn ronú lọ́nà kan náà yìí. Kíyè sí ohun tí òǹkọ̀wé kan tó jẹ́ Júù sọ sínú ìwé ìròyìn kan, ó ní: “Àlàyé tó rọrùn jù lọ téèyàn lè ṣe nípa ìjìyà tó wáyé ní Auschwitz ni pé kò sí Ọlọ́run tó lè dá sí ọ̀ràn àwọn èèyàn.” Ohun tí ìwádìí kan tí wọ́n ṣe ní 1997, nílẹ̀ Faransé, tó jẹ́ orílẹ̀-èdè táwọn ẹlẹ́sìn Kátólíìkì pọ̀ sí gan-an, fi hàn ni pé, nǹkan bí ìpín ogójì nínú ọ̀gọ́rùn-ún àwọn èèyàn ibẹ̀ ni kò dá lójú pé Ọlọ́run wà nítorí pípa táwọn èèyàn máa ń pa odindi ẹ̀yà kan run, bí irú èyí tó wáyé ní Rwanda lọ́dún 1994.

Ǹjẹ́ Kì Í Ba Ìgbàgbọ́ Jẹ́?

Kí nìdí tí Ọlọ́run ò fi dá sí ọ̀ràn náà, tó ń jẹ́ kí ohun búburú ṣẹlẹ̀? Ẹnì kan tó máa ń kọ ìròyìn àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ńláńlá sílẹ̀ nínú ìjọ Kátólíìkì sọ pé ìbéèrè yìí jẹ́ “ohun tó lè ba ìgbàgbọ́ jẹ́.” Ó béèrè pé: “Ká sòótọ́, ǹjẹ́ ó ṣeé ṣe láti ní ìgbàgbọ́ nínú Ọlọ́run kan tó dúró tó sì ń wo bí àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn aláìmọwọ́mẹsẹ̀ ṣe ń kú, tí wọ́n ń pa odindi ẹ̀yà kan nínú ayé run, tí kò sì ṣe ohunkóhun láti dáwọ́ iṣẹ́ ibi náà dúró?”

Bákan náà ni ọ̀rọ̀ olótùú kan nínú ìwé ìròyìn Kátólíìkì tí wọ́n ń pè ní La Croix sọ pé: “Yálà nígbà tí ohun búburú kan bá ṣẹlẹ̀, tàbí tí ìdàgbàsókè nínú ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ bá fa ohun kan, tí àjálù bá ṣẹlẹ̀, tí àwọn ẹgbẹ́ ọ̀daràn paraku ń ṣọṣẹ́ tàbí tí èèyàn ẹni kan kú, nínú gbogbo èyí, ojú Ọlọ́run láwọn èèyàn máa ń wò fún àlàyé. Wọ́n á béèrè pé Ọlọ́run dà? Wọ́n á sì fẹ́ káwọn rí ìdáhùn gbà. Ǹjẹ́ kì í ṣe òun ni Ẹni Tó Dágunlá Jù Lọ, tí ò tiẹ̀ Bìkítà rárá?”

Póòpù John-Paul Kejì dáhùn ìbéèrè yìí nínú lẹ́tà àpọ́sítélì rẹ̀ tó kọ ní 1984, èyí tó pè ní Salvifici Doloris. Ohun tó kọ ni pé: “Bó tilẹ̀ jẹ́ pé wíwà tí ayé wà jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé Ọlọ́run kan ńbẹ, tó jẹ ọlọgbọ́n, alágbára àti ẹni ńlá, síbẹ̀ ìwà ibi àti ìjìyà kò jẹ́ ká rí àwọn ànímọ́ rẹ̀ wọ̀nyí, ìgbà mìíràn sì wà táwọn ohun búburú wọ̀nyí máa ń ba àwọn ànímọ́ náà jẹ́ gan-an, pàápàá jù lọ nígbà tí ìjìyà tàbí ìwà ibi bá di ohun tó ń ṣẹlẹ̀ lójoojúmọ́ láìsí ìyà tó tọ́ fún àwọn oníṣẹ́ ibi náà.”

Ǹjẹ́ ìyà tó ń jẹ ẹ̀dá ènìyàn nílé lóko yìí fi hàn pé Ọlọ́run kan tó jẹ́ onífẹ̀ẹ́ tó sì lágbára wà gẹ́gẹ́ bí Bíbélì ti sọ? Ǹjẹ́ ó ń dá sí ọ̀ràn wa láti má ṣe jẹ́ kí ohun búburú ṣẹlẹ̀ sí wa yálà lẹ́nì kọ̀ọ̀kan tàbí lápapọ̀? Ǹjẹ́ ó ń ṣe ohunkóhun fún wa lónìí? Gẹ́gẹ́ bí ohun tí Voltaire sọ, ǹjẹ́ “Ọlọ́run kan tiẹ̀ wà tó ń bá ọmọ aráyé sọ̀rọ̀,” tó lè dáhùn àwọn ìbéèrè wọ̀nyí? Jọ̀wọ́ ka àpilẹ̀kọ tó tẹ́ lé e láti rí ìdáhùn sí ìbéèrè wọ̀nyí.

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 3]

Àjálù tó wáyé ní Lisbon lọ́dún 1755 ló mú kí Voltaire sọ pé irú ìṣẹ̀lẹ̀ bẹ́ẹ̀ kọjá òye ẹ̀dá èèyàn

[Àwọn Credit Line]

Voltaire: Láti inú ìwé Great Men and Famous Women; Lisbon: J.P. Le Bas, Praça da Patriarcal depois do terramoto de 1755. Fọ́tò: Museu da Cidade/Lisboa

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 4]

Ọ̀pọ̀ ló rò pé kò sí Ọlọ́run nítorí ohun búburú tí pípa odindi ẹ̀yà kan run ń fà, bí irú èyí tó ṣẹlẹ̀ ní Rwanda

[Credit Line]

AFP FỌ́TÒ

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 2]

Ẹ̀YÌN ÌWÉ, àwọn ọmọdé: USHMM, nípasẹ̀ ìyọ̀ǹda Main Commission for the Prosecution of the Crimes against the Polish Nation