A Ṣe Inúnibíni Sí Wọn Nítorí Wọ́n Jẹ́ Olódodo
A Ṣe Inúnibíni Sí Wọn Nítorí Wọ́n Jẹ́ Olódodo
“Aláyọ̀ ni àwọn tí a ti ṣe inúnibíni sí nítorí òdodo.”—MÁTÍÙ 5:10.
1. Kí ló gbé Jésù déwájú Pọ́ńtíù Pílátù, kí sì ni Jésù sọ?
“NÍTORÍ èyí ni a ṣe bí mi, nítorí èyí sì ni mo ṣe wá sí ayé, kí n lè jẹ́rìí sí òtítọ́.” (Jòhánù 18:37) Iwájú Pọ́ńtíù Pílátù ará Róòmù tí í ṣe Gómìnà Jùdíà ni Jésù wà nígbà tó sọ̀rọ̀ yìí. Kì í ṣe pé ó wu Jésù láti lọ síwájú Pílátù o, kì í sì í ṣe ẹni yẹn ló pè é pé kó wá. Kàkà bẹ́ẹ̀, ohun tó gbé e débẹ̀ ni irọ́ táwọn aṣáájú ẹ̀sìn Júù pa mọ́ ọ pé oníṣẹ́ ibi ní, ó sì yẹ kó kú.—Jòhánù 18:29-31.
2. Kí lohun tí Jésù ṣe, kí ló sì tẹ̀yìn rẹ̀ jáde?
2 Jésù mọ̀ dáadáa pé Pílátù ní agbára láti dá òun sílẹ̀ bẹ́ẹ̀ náà ló sì tún lágbára láti pa òun. (Jòhánù 19:10) Àmọ́ ẹ̀rù kò bà á nítorí èyí, ó sì fìgboyà wàásù nípa Ìjọba náà fún Pílátù. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé inú ewu ni ẹ̀mí Jésù wà, síbẹ̀ ó lo àǹfààní yẹn láti wàásù fún àwọn aláṣẹ gíga jù lọ ní àgbègbè náà. Pẹ̀lú gbogbo ìwàásù yẹn náà, wọ́n dájọ́ ikú fún Jésù wọ́n sì pa á, ó tipa bẹ́ẹ̀ kú ikú oró lórí òpó igi nítorí ìgbàgbọ́ rẹ̀.—Mátíù 27:24-26; Máàkù 15:15; Lúùkù 23:24, 25; Jòhánù 19:13-16.
Ṣé Ajẹ́rìí Ni Àbí Ajẹ́rìíkú?
3. Kí ni ọ̀rọ̀ náà “ajẹ́rìíkú” túmọ̀ sí lákòókò tí wọ́n kọ Bíbélì, kí ló sì túmọ̀ sí lónìí?
3 Lójú ọ̀pọ̀ èèyàn lónìí, ajẹ́rìíkú túmọ̀ sí agbawèrèmẹ́sìn, aláṣejù nídìí ẹ̀sìn. Àwọn tí wọ́n múra tán láti kú nítorí ohun tí wọ́n gbà gbọ́, pàápàá tó bá jẹ mọ́ ọ̀rọ̀ ẹ̀sìn, ni àwọn èèyàn máa ń fura sí pé wọ́n jẹ́ apániláyà tàbí eléwu ẹ̀dá. Àmọ́ ṣá o, ọ̀rọ̀ náà “ajẹ́rìíkú” wá látinú ọ̀rọ̀ Gíríìkì náà marʹtys. Lákòókò tí wọ́n kọ Bíbélì, ọ̀rọ̀ yìí kọ́kọ́ túmọ̀ sí “ajẹ́rìí,” ìyẹn ẹnì kan tó jẹ́rìí nílé ẹjọ́ sí ọ̀rọ̀ kan tó jẹ mọ́ ohun tó gbà gbọ́. Ìgbà tó wá yá ni ọ̀rọ̀ náà gbé ìtumọ̀ mìíràn rù, tó wá túmọ̀ sí “ẹni tó fi ẹ̀mí rẹ̀ rúbọ nítorí pé ó jẹ́rìí,” tàbí ẹni tó jẹ́rìí nípa fífi ẹ̀mí ara rẹ̀ rúbọ.
4. Ọ̀nà wo ni Jésù gbà jẹ́ ajẹ́rìí níbàámu pẹ̀lú ohun tí ọ̀rọ̀ náà “ajẹ́rìíkú” kọ́kọ́ túmọ̀ sí?
4 Jésù jẹ́ ajẹ́rìí níbàámu pẹ̀lú ohun tí ọ̀rọ̀ náà “ajẹ́rìíkú” kọ́kọ́ túmọ̀ sí. Ó sọ fún Pílátù pé ńṣe lòun wá “jẹ́rìí sí òtítọ́.” Onírúurú ọ̀nà làwọn èèyàn gbà hùwà nígbà tó jẹ́rìí fún wọn. Ohun táwọn kan lára àwọn aráàlú gbọ́ àtèyí tí wọ́n fojú ara wọn rí wú wọn lórí gan-an, èyí sì mú kí wọ́n nígbàgbọ́ nínú Jésù. (Jòhánù 2:23; 8:30) Gbogbo àwọn èèyàn tó kù ló ta kò ó, àgàgà àwọn olórí ẹ̀sìn. Jésù sọ fún àwọn mọ̀lẹ́bí rẹ̀ tí wọn kì í ṣe onígbàgbọ́ pé: “Ayé kò ní ìdí kankan láti kórìíra yín, ṣùgbọ́n ó kórìíra mi, nítorí mo ń jẹ́rìí nípa rẹ̀ pé àwọn iṣẹ́ rẹ̀ burú.” (Jòhánù 7:7) Jésù rí ìbínú àwọn aṣáájú ayé ìgbà yẹn nítorí pé ó jẹ́rìí sí òtítọ́, èyí ló sì yọrí sí ikú rẹ̀. Dájúdájú, òun ni “ẹlẹ́rìí aṣeégbíyèlé àti olóòótọ́ (marʹtys).”—Ìṣípayá 3:14.
“Ẹ Ó Sì Jẹ́ Ẹni Ìkórìíra”
5. Kí ni Jésù sọ nípa inúnibíni nígbà tó ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀?
5 Yàtọ̀ sí pé àwọn èèyàn ṣe inúnibíni líle koko sí Jésù, òun fúnra rẹ̀ tún sọ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé wọn á ṣenúnibíni sí àwọn náà. Nígbà tí Jésù ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀, ó sọ fáwọn tó gbọ́ Ìwàásù tó ṣe lórí Òkè pé: “Aláyọ̀ ni àwọn tí a ti ṣe inúnibíni sí nítorí òdodo, níwọ̀n bí ìjọba ọ̀run ti jẹ́ tiwọn. Aláyọ̀ ni yín nígbà tí àwọn ènìyàn bá gàn yín, tí wọ́n sì ṣe inúnibíni sí yín, tí wọ́n sì fi irọ́ pípa sọ gbogbo onírúurú ohun burúkú sí yín nítorí mi. Ẹ yọ̀, kí ẹ sì fò sókè fún ìdùnnú, níwọ̀n bí èrè yín ti pọ̀ ní ọ̀run.”—Mátíù 5:10-12.
6. Kí ni Jésù sọ fáwọn àpọ́sítélì rẹ̀ méjìlá nígbà tó fẹ́ rán wọn jáde?
6 Nígbà tó yá tí Jésù fẹ́ rán àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ méjìlá jáde, ó sọ fún wọn pé: “Ẹ máa ṣọ́ra yín lọ́dọ̀ àwọn ènìyàn; nítorí wọn yóò fà yín lé àwọn kóòtù àdúgbò lọ́wọ́, wọn yóò sì nà yín lọ́rẹ́ nínú àwọn sínágọ́gù wọn. Họ́wù, wọn yóò fà yín lọ síwájú àwọn gómìnà àti àwọn ọba nítorí mi, láti ṣe ẹ̀rí fún wọn àti fún àwọn orílẹ̀-èdè.” Kì í ṣe àwọn aṣáájú ẹ̀sìn nìkan ló máa ṣe inúnibíni sáwọn ọmọ ẹ̀yìn náà. Jésù tún sọ pé: “Arákùnrin yóò fa arákùnrin lé ikú lọ́wọ́, àti baba, ọmọ rẹ̀, àwọn ọmọ yóò sì dìde sí àwọn òbí, wọn yóò sì ṣe ikú pa wọ́n. Ẹ ó sì jẹ́ ẹni ìkórìíra lọ́dọ̀ gbogbo ènìyàn ní tìtorí orúkọ mi; ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá fara dà á dé òpin ni ẹni tí a ó gbà là.” (Mátíù 10:17, 18, 21, 22) Àkọsílẹ̀ tó fi hàn pé ojú àwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní rí màbo jẹ́ ẹ̀rí pé òótọ́ làwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí.
Àpẹẹrẹ Àwọn Tó Ti Fara Da Inúnibíni Láìjuwọ́sílẹ̀
7. Kí ló mú kí Sítéfánù di ajẹ́rìíkú?
7 Kété lẹ́yìn ikú Jésù ni Sítéfánù di Kristẹni àkọ́kọ́ tó kú nítorí pé ó jẹ́rìí sí òtítọ́. Ó “kún fún oore ọ̀fẹ́ àti agbára, [ó sì] ń ṣe àwọn àmì àgbàyanu ńlá àti àwọn iṣẹ́ àmì láàárín àwọn ènìyàn.” Àwọn ọ̀tá rẹ̀ tí wọ́n jẹ́ ẹlẹ́sìn “kò lè dúró lòdì sí ọgbọ́n àti ẹ̀mí tí ó fi ń sọ̀rọ̀.” (Ìṣe 6:8, 10) Nígbà tí owú wọ̀ wọ́n lára, wọ́n wọ́ Sítéfánù lọ síwájú Sànhẹ́dírìn, ìyẹn ilé ẹjọ́ gíga jù lọ ti àwọn Júù, ibẹ̀ ló ti kojú àwọn tó fẹ̀sùn èké kàn án, ó sì jẹ́rìí fún wọn lọ́nà tó fakíki. Àmọ́ lópin gbogbo rẹ̀, àwọn ọ̀tá pa Sítéfánù ẹlẹ́rìí olóòótọ́ yìí.—Ìṣe 7:59, 60.
8. Kí làwọn ọmọ ẹ̀yìn ní Jerúsálẹ́mù ṣe nígbà tí inúnibíni dé bá wọn lẹ́yìn ikú Sítéfánù?
8 Lẹ́yìn tí wọ́n ti pa Sítéfánù, “inúnibíni ńlá dìde sí ìjọ tí ó wà ní Jerúsálẹ́mù; gbogbo wọn àyàfi àwọn àpọ́sítélì ni a tú ká jákèjádò àwọn ẹkùn ilẹ̀ Jùdíà àti Samáríà.” (Ìṣe 8:1) Ǹjẹ́ inúnibíni wá jẹ́ kí iṣẹ́ ìjẹ́rìí táwọn Kristẹni ń ṣe dáwọ́ dúró? Rárá o, àkọsílẹ̀ náà sọ fún wa pé “àwọn tí a tú ká la ilẹ̀ náà já, wọ́n ń polongo ìhìn rere ọ̀rọ̀ náà.” (Ìṣe 8:4) Wọ́n á ti ní irú èrò tí àpọ́sítélì Pétérù ní tó fi sọ nígbà kan pé: “Àwa gbọ́dọ̀ ṣègbọràn sí Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí olùṣàkóso dípò àwọn ènìyàn.” (Ìṣe 5:29) Láìfi inúnibíni náà pè, àwọn ọmọ ẹ̀yìn tí wọ́n jẹ́ olóòótọ́ àti onígboyà yẹn kò jáwọ́ nínú jíjẹ́rìí sí òtítọ́, bí wọ́n tilẹ̀ mọ̀ pé èyí á túbọ̀ fa ìṣòro fáwọn.—Ìṣe 11:19-21.
9. Inúnibíni wo ló tún ṣẹlẹ̀ sáwọn ọmọlẹ́yìn Jésù?
9 Ó dájú pé ìṣòro tó dé bá wọn ń peléke sí i ni. Lákọ̀ọ́kọ́, a kà á pé Sọ́ọ̀lù tó fọwọ́ sí i pé kí wọ́n sọ Sítéfánù lókùúta pa tó “ṣì ń mí èémí ìhalẹ̀mọ́ni àti ìṣìkàpànìyàn sí àwọn ọmọ ẹ̀yìn Olúwa, lọ bá àlùfáà àgbà, ó sì béèrè fún àwọn lẹ́tà sí àwọn sínágọ́gù ní Damásíkù, kí ó lè mú ẹnikẹ́ni tí ó bá rí tí ó jẹ́ ti Ọ̀nà Náà wá sí Jerúsálẹ́mù ní dídè, àti ọkùnrin àti obìnrin.” (Ìṣe 9:1, 2) Lẹ́yìn náà, ní nǹkan bí ọdún 44 Sànmánì Tiwa, “Hẹ́rọ́dù ọba na ọwọ́ rẹ̀ sí fífojú àwọn kan lára àwọn tí ó jẹ́ ti ìjọ gbolẹ̀. Ó fi idà pa Jákọ́bù arákùnrin Jòhánù.”—Ìṣe 12:1, 2.
10. Ìtàn tó dá lórí inúnibíni wo ló wà nínú ìwé Ìṣe àti ìwé Ìṣípayá?
10 Apá tó kù nínú ìwé Ìṣe ní àwọn ìtàn mánigbàgbé nínú, èyí tó dá lórí àdánwò, ìfisẹ́wọ̀n àti inúnibíni táwọn adúróṣinṣin bíi Pọ́ọ̀lù fara dà. Ọkùnrin yìí ló máa ń ṣenúnibíni sáwọn èèyàn tẹ́lẹ̀ àmọ́ òun náà wá di àpọ́sítélì, tó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé tìtorí ìgbàgbọ́ rẹ̀ ni Nérò Olú Ọba Róòmù ṣe pa á ní nǹkan bí ọdún 65 Sànmánì Tiwa. (2 Kọ́ríńtì 11:23-27; 2 Tímótì 4:6-8) Níkẹyìn, nínú ìwé Ìṣípayá tá a kọ lápá ìparí ọ̀rúndún kìíní, a rí i níbẹ̀ pé wọ́n fi àpọ́sítélì Jòhánù tó ti darúgbó sẹ́wọ̀n níbi tí wọ́n ti máa ń fìyà jẹni ní erékùṣù Pátímọ́sì ‘nítorí pé ó sọ̀rọ̀ nípa Ọlọ́run ó sì jẹ́rìí Jésù.’ Ìṣípayá tún sọ̀rọ̀ nípa “Áńtípà, ẹlẹ́rìí mi, olùṣòtítọ́, ẹni tí a pa” ní Págámù.—Ìṣípayá 1:9; 2:13.
11. Báwo ni ẹ̀mí táwọn Kristẹni ìjímìjí ní ṣe fi hàn pé òótọ́ làwọn ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ nípa inúnibíni?
11 Gbogbo èyí fi hàn pé òótọ́ lọ̀rọ̀ tí Jésù sọ fáwọn àpọ́sítélì rẹ̀ pé: “Bí wọ́n bá ti ṣe inúnibíni sí mi, wọn yóò ṣe inúnibíni sí yín pẹ̀lú.” (Jòhánù 15:20) Àwọn Kristẹni ìjímìjí tí wọ́n jẹ́ adúróṣinṣin múra tán láti dojú kọ àdánwò tó ga jù lọ, ìyẹn ikú, yálà nípa dídá wọn lóró, tàbí káwọn èèyàn jù wọ́n sẹ́nu ẹranko ẹhànnà tàbí kí wọ́n gba ọ̀nà mìíràn pa wọ́n. Wọ́n múra tán láti fara da èyí kí wọ́n bàa lè ṣe iṣẹ́ tí Jésù Kristi Olúwa gbé lé wọn lọ́wọ́ pé: “Ẹ ó sì jẹ́ ẹlẹ́rìí mi ní Jerúsálẹ́mù àti ní gbogbo Jùdíà àti Samáríà àti títí dé apá ibi jíjìnnà jù lọ ní ilẹ̀ ayé.”—Ìṣe 1:8.
12. Kí nìdí tí inúnibíni tí wọ́n ṣe sáwọn Kristẹni kì í fi í ṣe ọ̀rọ̀ ayé àtijọ́ nìkan?
12 Bí ẹnikẹ́ni bá rò pé ayé àtijọ́ nìkan ni irú ìwà rírorò táwọn èèyàn hù sáwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù lè ṣẹlẹ̀, èrò òdì gbáà lonítọ̀hún ní o. A ti rí i pé ìṣòro tó bá Pọ́ọ̀lù kúrò ní kékeré, òun náà sì wá kọ̀wé pé: “Gbogbo àwọn tí ń ní ìfẹ́-ọkàn láti gbé pẹ̀lú fífọkànsin Ọlọ́run ní ìbákẹ́gbẹ́ pẹ̀lú Kristi Jésù ni a ó ṣe inúnibíni sí pẹ̀lú.” (2 Tímótì 3:12) Nígbà tí Pétérù ń sọ̀rọ̀ nípa inúnibíni, ó sọ pé: “Ní ti tòótọ́, ipa ọ̀nà yìí ni a pè yín sí, nítorí Kristi pàápàá jìyà fún yín, ó fi àwòkọ́ṣe sílẹ̀ fún yín kí ẹ lè tẹ̀ lé àwọn ìṣísẹ̀ rẹ̀ pẹ́kípẹ́kí.” (1 Pétérù 2:21) Látìgbà yẹn títí di “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” ètò àwọn nǹkan yìí, àwọn èèyàn ṣì ń kórìíra àwọn èèyàn Jèhófà, wọ́n sì ń ṣe inúnibíni sí wọn. (2 Tímótì 3:1) Káàkiri ayé, ì báà jẹ́ lábẹ́ ìjọba bóofẹ́-bóokọ̀ tàbí ìjọba olóṣèlú, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti fojú winá inúnibíni lẹ́nì kọ̀ọ̀kan tàbí lápapọ̀.
Kí Nìdí Táwọn Èèyàn Fi Kórìíra Wọn Tí Wọ́n Sì Ṣenúnibíni Sí Wọn?
13. Kí làwọn ìránṣẹ́ Jèhófà lóde òní gbọ́dọ̀ fi sọ́kàn nípa inúnibíni?
13 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ lára wa lónìí ló ní òmìnira dé ìwọ̀n àyè kan láti wàásù àti láti pàdé pọ̀ ní àlàáfíà, síbẹ̀ ó yẹ ká fi ohun tí Bíbélì rán wa létí rẹ̀ sọ́kàn pé “ìrísí ìran ayé yìí ń yí padà.” (1 Kọ́ríńtì 7:31) Àwọn nǹkan lè yí padà bìrí láìròtẹ́lẹ̀, èyí sì lè tètè múni kọsẹ̀ téèyàn ò bá ti ń ronú nípa rẹ̀ tẹ́lẹ̀ kó sì ti gbára dì dè é nípa tẹ̀mí. Nígbà náà, ọ̀nà wo la lè gbà dáàbò bo ara wa? Ọ̀nà kan tó gbéṣẹ́ tá a lè gbà dáàbò bo ara wa ni pé ká máa rántí ìdí táwọn èèyàn fi ń ṣenúnibíni sáwọn Kristẹni tí wọ́n fẹ́ràn àlàáfíà tí wọ́n sì ń pòfin mọ́.
14. Kí ni Pétérù sọ pé ó fa inúnibíni táwọn èèyàn ṣe sáwọn Kristẹni?
14 Àpọ́sítélì Pétérù sọ̀rọ̀ nípa kókó yìí nínú lẹ́tà rẹ̀ àkọ́kọ́ tó kọ ní nǹkan bí ọdún 62 Sànmánì Tiwa sí ọdún 64 Sànmánì Tiwa. Nígbà yẹn, gbogbo àwọn Kristẹni tó wà ní Ilẹ̀ Ọba Róòmù ló ń fojú winá àdánwò àti inúnibíni. Ó sọ pé: “Ẹ̀yin olùfẹ́ ọ̀wọ́n, ẹ má ṣe jẹ́ kí iná tí ń jó láàárín yín rú yín lójú, èyí tí ń ṣẹlẹ̀ sí yín fún àdánwò, bí ẹni pé ohun àjèjì ni ó ń ṣẹlẹ̀ sí yín.” Káwọn èèyàn bàa lè lóye ohun tí Pétérù ń sọ, ó tún sọ pé: “Kí ẹnikẹ́ni nínú yín má jìyà gẹ́gẹ́ bí òṣìkàpànìyàn tàbí olè tàbí aṣebi tàbí gẹ́gẹ́ bí olùyọjúràn sí ọ̀ràn àwọn ẹlòmíràn. Ṣùgbọ́n bí òun bá jìyà gẹ́gẹ́ bí Kristẹni, kí ó má ṣe tijú, ṣùgbọ́n kí ó máa bá a nìṣó ní yíyin Ọlọ́run lógo ní orúkọ yìí.” Pétérù sọ fún wọn pé kì í ṣe nítorí pé wọ́n hu ìwàkiwà kankan ni wọ́n ṣe ń jìyà o, àmọ́ jíjẹ́ tí wọ́n jẹ́ Kristẹni ló fà á. Ká ní àwọn náà ti ń yíràá nínú ‘kòtò ẹ̀gbin tó kún fún ìwà wọ̀bìà’ bíi tàwọn èèyàn tó yí wọn ká ni, wọn ì bá máà kórìíra wọn. Àmọ́ òtítọ́ ibẹ̀ ni pé bí wọ́n ṣe ń ṣe àwọn ohun tó yẹ kí wọ́n ṣe gẹ́gẹ́ bí ọmọ ẹ̀yìn Kristi ló mú kí wọ́n jìyà. Bó sì ṣe rí fáwọn Kristẹni tòótọ́ lóde òní nìyẹn.—1 Pétérù 4:4, 12, 15, 16.
15. Kí ló ń ṣeni ní kàyéfì nínú ohun táwọn èèyàn ń ṣe sí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lónìí?
15 Níbi púpọ̀ kárí ayé, àwọn èèyàn ti gbóríyìn fún àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nítorí ìṣọ̀kan àti ìfọwọ́sowọ́pọ̀ tó wà láàárín wọn, èyí tó hàn láwọn àpéjọ wọn, níbi tí wọ́n bá ti ń ṣiṣẹ́ ìkọ́lé, àti nítorí pé wọn kì í fi dúdú pe funfun, wọ́n kì í sì í ṣọ̀lẹ, àti nítorí ìwà wọn tí kò lábàwọ́n àti ìdílé wọn tó jẹ́ àwòfiṣàpẹẹrẹ. Bákan náà la tún ń yìn wọ́n nítorí ìmúra wọn tó jẹ́ ti ọmọlúàbí. a Láìka gbogbo ohun tó dára wọ̀nyí sí, wọ́n ṣì fòfin de iṣẹ́ wọn ní odidi ilẹ̀ méjìdínlọ́gbọ̀n ní àkókò tá a ń kọ àpilẹ̀kọ yìí, ọ̀pọ̀ lára àwọn Ẹlẹ́rìí náà ni wọ́n lù ní àlùbami tí wọ́n sì pàdánù ohun ìní wọn nítorí ìgbàgbọ́ wọn. Kí ló wá dé tí wọ́n fi ń ṣe inúnibíni sáwọn èèyàn yìí? Kí sì nìdí tí Ọlọ́run fi fàyè gba èyí?
16. Kí nìdí tó ṣe pàtàkì jù lọ tí Ọlọ́run fi fàyè gba inúnibíni tí wọ́n ń ṣe sáwọn èèyàn rẹ̀?
16 Lákọ̀ọ́kọ́ ná, a gbọ́dọ̀ fi ọ̀rọ̀ tó wà nínú Òwe 27:11 sọ́kàn, tó sọ pé: “Ọmọ mi, jẹ́ ọlọ́gbọ́n, kí o sì mú ọkàn-àyà mi yọ̀, kí n lè fún ẹni tí ń ṣáátá mi lésì.” Dájúdájú, ọ̀ràn ipò ọba aláṣẹ ayé òun ọ̀run tó ti ń jà ràn-ín látọjọ́ pípẹ́ kò tíì tán nílẹ̀. Pẹ̀lú ẹ̀rí rẹpẹtẹ látọ̀dọ̀ àwọn tó pa ìwà títọ́ wọn mọ́ sí Jèhófà láti ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún wá, Sátánì kò tíì jáwọ́ nínú ṣíṣáátá tó ń ṣáátá Jèhófà gẹ́gẹ́ bó ṣe ṣe nígbà ayé Jóòbù olódodo. (Jóòbù 1:9-11; 2:4, 5) Láìsí àní-àní, Sátánì ti wá gboró gan-an nínú ìjà àjàkẹ́yìn tó ń jà káwọn èèyàn lè gba tiẹ̀, àgàgà nísinsìnyí tí Ìjọba Ọlọ́run ti fìdí múlẹ̀ gbọn-in tó sì ní àwọn tó wà lábẹ́ àkóso rẹ̀ àtàwọn aṣojú rẹ̀ kárí ayé. Ǹjẹ́ àwọn wọ̀nyí máa fi ìdúróṣinṣin hàn sí Ọlọ́run lójú ìjìyà àti ìpọ́njú tó bá dé bá wọn? Àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà lẹ́nìkọ̀ọ̀kan ló máa fúnra wọn dáhùn ìbéèrè yìí.—Ìṣípayá 12:12, 17.
17. Kí ni Jésù ní lọ́kàn nígbà tó sọ pé “yóò já sí ẹ̀rí fún yín”?
17 Nígbà tí Jésù ń sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ nípa àwọn ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ ní “ìparí ètò àwọn nǹkan” ó fi ìdí mìíràn hàn tí Jèhófà fi fàyè gba inúnibíni tí wọ́n ń ṣe sáwọn ìránṣẹ́ rẹ̀. Ó sọ fún wọn pé: “A ó fà yín lọ síwájú àwọn ọba àti àwọn gómìnà nítorí orúkọ mi. Yóò já sí ẹ̀rí fún yín.” (Mátíù 24:3, 9; Lúùkù 21:12, 13) Jésù fúnra rẹ̀ jẹ́rìí níwájú Hẹ́rọ́dù àti Pọ́ńtíù Pílátù. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù pẹ̀lú ni wọ́n ‘fà lọ síwájú àwọn ọba àti àwọn gómìnà.’ Jésù Kristi Olúwa darí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù láti wá ọ̀nà láti jẹ́rìí fún alákòóso tó lágbára jù lọ ní àkókò yẹn, nígbà tí Pọ́ọ̀lù polongo pé: “Mo ké gbàjarè sí Késárì!” (Ìṣe 23:11; 25:8-12) Bẹ́ẹ̀ ló rí lónìí, a máa ń lo àwọn ipò ìṣòro láti jẹ́rìí fún àwọn onípò àṣẹ àti gbogbo àwọn èèyàn. b
18, 19. (a) Báwo ni fífarada inúnibíni ṣe lè ṣe wá láǹfààní? (b) Àwọn ìbéèrè wo ni a ó gbé yẹ̀ wò nínú àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé e?
18 Lákòótán, fífara da àwọn àdánwò àti ìpọ́njú lè ṣe wá láǹfààní lẹ́nìkọ̀ọ̀kan. Lọ́nà wo? Ọmọ ẹ̀yìn náà Jákọ́bù rán àwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ létí pé: “Ẹ ka gbogbo rẹ̀ sí ìdùnnú, ẹ̀yin ará mi, nígbà tí ẹ bá ń bá onírúurú àdánwò pàdé, gẹ́gẹ́ bí ẹ ti mọ̀ ní tòótọ́ pé ìjójúlówó ìgbàgbọ́ yín yìí tí a ti dán wò ń ṣiṣẹ́ yọrí sí ìfaradà.” Bẹ́ẹ̀ ni o, inúnibíni ń sọ ìgbàgbọ́ wa dọ̀tun, ó sì túbọ̀ ń jẹ́ ká ní ìfaradà. Nítorí náà, inúnibíni kò bà wá lẹ́rù, a ò sì ní wá ọ̀nà tí kò bá Ìwé Mímọ́ mu láti yẹ̀ ẹ́ sílẹ̀ tàbí ká fòpin sí i. Kàkà bẹ́ẹ̀, a ó tẹ̀ lé ìmọ̀ràn tí Jákọ́bù fúnni pé: “Ẹ jẹ́ kí ìfaradà ṣe iṣẹ́ rẹ̀ pé pérépéré, kí ẹ lè pé pérépéré, kí ẹ sì yè kooro ní gbogbo ọ̀nà, láìṣe aláìní ohunkóhun.”—Jákọ́bù 1:2-4.
19 Àní bí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tilẹ̀ ràn wá lọ́wọ́ láti lóye ìdí tí wọ́n fi ń ṣe inúnibíni sáwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run àti ìdí tí Jèhófà fi fàyè gbà á, ìyẹn kò sọ pé inúnibíni rọrùn láti fara dà. Kí ló lè fún wa lókun láti kojú inúnibíni? Kí ni a lè ṣe nígbà tá a bá dojú kọ inúnibíni? A ó gbé àwọn kókó pàtàkì yìí yẹ̀ wò nínú àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé e.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Wo Ilé Ìṣọ́ December 15, 1995, ojú ìwé 27 sí 29; April 15, 1994, ojú ìwé 16 àti 17; àti Jí! December 22, 1993, ojú ìwé 6 sí 13.
Ǹjẹ́ O Lè Ṣàlàyé?
• Ọ̀nà wo ni Jésù gbà jẹ́ ajẹ́rìí níbàámu pẹ̀lú ohun tí ọ̀rọ̀ náà “ajẹ́rìíkú” kọ́kọ́ túmọ̀ sí?
• Ìyọrísí wo ni inúnibíni ní lórí àwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní?
• Kí ló fà á tí wọ́n fi ṣe inúnibíni sáwọn Kristẹni ìjímìjí gẹ́gẹ́ bí Pétérù ṣe ṣàlàyé?
• Kí nìdí tí Jèhófà fi fàyè gba inúnibíni tí wọ́n ń ṣe sáwọn ìránṣẹ́ rẹ̀?
[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10, 11]
Kì í ṣe nítorí pé àwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní hùwà búburú ni wọ́n ṣe jìyà, bí kò ṣe nítorí jíjẹ́ tí wọ́n jẹ́ Kristẹni
PỌ́Ọ̀LÙ
JÒHÁNÙ
ÁŃTÍPÀ
JÁKỌ́BÙ
SÍTÉFÁNÙ