Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Fífarada Àdánwò Ń fi Ìyìn Fún Jèhófà

Fífarada Àdánwò Ń fi Ìyìn Fún Jèhófà

Fífarada Àdánwò Ń fi Ìyìn Fún Jèhófà

“Bí ẹ bá fara dà á nígbà tí ẹ bá ń ṣe rere, tí ẹ sì ń jìyà, èyí jẹ́ ohun tí ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà lọ́dọ̀ Ọlọ́run.”—1 PÉTÉRÙ 2:20.

1. Níwọ̀n bí àwọn Kristẹni ti fẹ́ láti mú ẹ̀jẹ̀ ìyàsímímọ́ wọn ṣẹ, ìbéèrè wo ló yẹ ká gbé yẹ̀ wò?

 ÀWỌN Kristẹni ya ara wọn sí mímọ́ fún Jèhófà, wọ́n sì fẹ́ ṣe ìfẹ́ rẹ̀. Kí wọ́n lè mú ẹ̀jẹ́ ìyàsímímọ́ wọn ṣẹ, wọ́n ń sa gbogbo ipá wọn láti tẹ̀ lé ìṣísẹ̀ Jésù Kristi, tó jẹ́ Àwòfiṣàpẹẹrẹ wọn, wọ́n sì ń jẹ́rìí sí òtítọ́. (Mátíù 16:24; Jòhánù 18:37; 1 Pétérù 2:21) Àmọ́, Jésù àtàwọn olóòótọ́ mìíràn fi ẹ̀mí wọn rúbọ, wọ́n sì tipa bẹ́ẹ̀ kú nítorí ìgbàgbọ́ wọn. Ṣé ìyẹn wá túmọ̀ sí pé gbogbo Kristẹni ló máa kú nítorí ìgbàgbọ́ wọn?

2. Ojú wo làwọn Kristẹni fi ń wo àdánwò àti ìjìyà?

2 Gẹ́gẹ́ bí Kristẹni, a gbà wá níyànjú láti jẹ́ olóòótọ́ títí di ọjọ́ ikú wa, kì í ṣe dandan pé ká kú nítorí ìgbàgbọ́ wa. (2 Tímótì 4:7; Ìṣípayá 2:10) Èyí túmọ̀ sí pé bá a ṣe múra tán láti jìyà, tá a tiẹ̀ múra tán pàápàá láti kú nítorí ìgbàgbọ́ wa, kì í ṣe pé ó wu àwa náà bẹ́ẹ̀. Kì í ṣe pé ó máa ń wù wá láti jìyà, kò sì sí adùn kankan téèyàn ń rí nínú ìrora tàbí fífi àbùkù kanni. Àmọ́, níwọ̀n bá a ti mọ̀ pé àdánwò àti inúnibíni lé dè, ó yẹ ká máa ronú lórí ohun tá a lè ṣe nígbà tí irú nǹkan bẹ́ẹ̀ bá kàn wá.

Jíjẹ́ Olódodo Nígbà Àdánwò

3. Àwọn àpẹẹrẹ báwọn èèyàn ṣe kojú inúnibíni wo ló wà nínú Bíbélì tó o lè mẹ́nu kàn? (Wo àpótí “Ohun Tí Wọ́n Ṣe Lákòókò Inúnibíni,” ní ojú ewé tó tẹ̀ lé e.)

3 Onírúurú àkọsílẹ̀ la rí nínú Bíbélì tó jẹ́ ká mọ ohun tí àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run ṣe nígbà tí wọ́n bá ara wọn nínú ipò tó fi ìwàláàyè wọn sínú ewu láyé ọjọ́hun. Ọ̀nà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tí wọ́n gbà kojú àwọn àdánwò wọn jẹ́ àpẹẹrẹ táwọn Kristẹni òde òní lè tẹ̀ lé tó bá ṣẹlẹ̀ pé àwọn náà dojú kọ àdánwò tó fara jọ ìyẹn. Ṣàyẹ̀wò àwọn ìtàn tó wà nínú àpótí náà, “Ohun Tí Wọ́n Ṣe Lákòókò Inúnibíni,” kó o sì wo ẹ̀kọ́ tó o lè rí kọ́ lára wọn.

4. Kí la lè sọ nípa ohun tí Jésù àtàwọn ìránṣẹ́ olóòótọ́ mìíràn ṣe nígbà tí wọ́n wà nínú àdánwò?

4 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ohun tí Jésù àtàwọn mìíràn tó jẹ́ olóòótọ́ ìránṣẹ́ Ọlọ́run ṣe lákòókò inúnibíni yàtọ̀ síra, tíyẹn sì sinmi lórí irú inúnibíni tó jẹ́, síbẹ̀ ó hàn gbangba pé wọn ò fi ẹ̀mí ara wọn sínú ewu láìnídìí. Nígbà tí wọ́n bá bá ara wọn nínú ipò tó lè wu ẹ̀mí wọn léwu, wọ́n máa ń ní ìgboyà síbẹ̀ wọ́n tún máa ń ṣọ́ra. (Mátíù 10:16, 23) Ohun tó wà lórí ẹ̀mí wọn ni pé kí wọ́n mú kí iṣẹ́ ìwàásù náà tẹ̀ síwájú kí wọ́n sì pa ìwà títọ́ wọn mọ́ sí Jèhófà. Ohun tí wọ́n ṣe nínú onírúurú ipò tí wọ́n bá ara wọn jẹ́ àpẹẹrẹ fáwọn Kristẹni tí wọ́n dojú kọ inúnibíni lóde òní.

5. Inúnibíni wo ló dìde ní Màláwì làwọn ọdún 1960, kí sì làwọn Ẹlẹ́rìí tó wa níbẹ̀ ṣe?

5 Lóde òní, ọ̀pọ̀ ìgbà làwọn èèyàn Jèhófà ti bá ara wọn nínú ìṣòro tó burú jáì àti ìkálọ́wọ́kò nítorí ogun, ìfòfindè, tàbí inúnibíni tó gbóná. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n ṣe inúnibíni tó gbóná gan-an sáwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Màláwì láwọn ọdún 1960. Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ gbogbo ohun tí wọ́n ní pátá ló ṣègbé, títí kan Gbọ̀ngàn Ìjọba wọn, ilé wọn, oko wọn, àti ibi okòwò wọn pàápàá. Wọ́n lù wọ́n bí ẹní máa kú, wọ́n sì tún dá wọn lóró làwọn ọ̀nà mìíràn. Kí làwọn arákùnrin wọ̀nyẹn wá ṣe? Ẹgbẹẹgbẹ̀rún ní láti sá kúrò lábúlé wọn. Ọ̀pọ̀ ló lọ sá pa mọ́ sínú igbó, nígbà táwọn mìíràn lọ fara pa mọ́ fúngbà díẹ̀ ní Mòsáńbíìkì tó múlé gbè wọ́n. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ olóòótọ́ ló pàdánù ìwàláàyè wọn, síbẹ̀ àwọn mìíràn yàn láti sá kúrò làwọn àgbègbè eléwu náà, ìyẹn sì jẹ́ ohun tó mọ́gbọ́n dání láti ṣe nínú irú ipò yẹn. Nípa ṣíṣe bẹ́ẹ̀, àwọn arákùnrin wọ̀nyí tẹ̀ lé àpẹẹrẹ tí Jésù àti Pọ́ọ̀lù fi lélẹ̀.

6. Kí ni àwọn Ẹlẹ́rìí tó wà ní Màláwì ò gbàgbé bí wọ́n tilẹ̀ wà nínú inúnibíni líle koko?

6 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn arákùnrin tó wà ní Màláwì ní láti sá, tàbí kí wọ́n lọ fara pa mọ́, síbẹ̀ wọ́n ń wá ìtọ́sọ́nà látọ̀dọ̀ ètò Ọlọ́run, wọ́n sì ń tẹ̀ lé e, wọ́n tún ń bá ìgbòkègbodò Kristẹni wọn lọ lábẹ́lẹ̀ bí wọ́n ṣe lè ṣe é tó. Kí wá ni àbájáde rẹ̀? Wọ́n ti ní àwọn akéde Ìjọba tó pọ̀ tó 18,519 kó tó di pé wọ́n fòfin de iṣẹ́ wọn lọ́dún 1967. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìfòfindè náà ṣì wà nílẹ̀ tí ọ̀pọ̀ lára wọn sì ti sá lọ sí Mòsáńbíìkì, síbẹ̀ àwọn akéde tí ìyè wọ́n jẹ́ 23,398 la gbọ́ pé ó wà níbẹ̀ lọ́dún 1972. Tá a bá pín wákàtí tí wọ́n lò dọ́gbadọ́gba, wákàtí tí ẹnì kọ̀ọ̀kan wọ́n lò nínú iṣẹ́ ìwàásù lóṣooṣù lé ní mẹ́rìndínlógún. Láìsí àní-àní, ohun tí wọ́n ṣe yìí fi ìyìn fún Jèhófà, Jèhófà sì ti àwọn ará wọ̀nyẹn lẹ́yìn ní gbogbo àkókò líle koko yẹn. a

7, 8. Kí nìdí táwọn kan ò fi sá kúrò nílùú, kódà nígbà tí àtakò ń fa ìṣòro fún wọn?

7 Ní òdìkejì ẹ̀wẹ̀, ní àwọn orílẹ̀-èdè tí àtakò ti ń fa ìṣòro, àwọn arákùnrin kan lè pinnu pé àwọn ò ní lọ, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ṣeé ṣe fún wọn láti ṣe bẹ́ẹ̀. Sísá lọ nílùú lè yanjú àwọn ìṣòro kan, àmọ́ ó tún lè dá àwọn ìṣòro mìíràn sílẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, ǹjẹ́ wọ́n á lè máa rí àwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ wọn kí wọ́n lè máa jùmọ̀ ṣe nǹkan pọ̀ nípa tẹ̀mí? Ǹjẹ́ wọ́n á lè máa bá àwọn ìgbòkègbodò tẹ̀mí lọ níbi tí wọ́n ti ń là kàkà láti fìdí kalẹ̀ síbòmíràn, bóyá lórílẹ̀-èdè kan tí nǹkan ti rọ̀ ṣọ̀mù tàbí níbi tí àǹfààní ti wà fún wọn láti kó ọ̀rọ̀ jọ?—1 Tímótì 6:9.

8 Àwọn mìíràn ò fẹ́ kúrò lórílẹ̀-èdè wọn nítorí pé wọ́n ń ṣàníyàn nípa ire tẹ̀mí àwọn arákùnrin wọn. Wọ́n yàn láti dúró kí wọ́n sì dojú kọ ipò náà kí wọ́n lè máa bá iṣẹ́ ìwàásù náà lọ nílùú wọn kí wọ́n sì jẹ́ orísun ìṣírí fún àwọn olùjọsìn ẹlẹgbẹ́ wọn. (Fílípì 1:14) Nípa ṣíṣe bẹ́ẹ̀, ó ti ṣeé ṣe fáwọn kan láti jàre ẹjọ́ táwọn èèyàn pè wọ́n sílé ẹjọ́ ní orílẹ̀-èdè wọn. b

9. Àwọn kókó wo ló yẹ kí ẹnì kan gbé yẹ̀ wò nígbà tó bá fẹ́ pinnu bóyá kí òun dúró tàbí kí òun sá kúrò nílùú nítorí inúnibíni?

9 Ọ̀ràn dídúró tàbí kéèyàn sá kúrò nílùú jẹ́ ohun tẹ́nì kan yóò pinnu fúnra rẹ̀. Àmọ́ irú ìpinnu yẹn jẹ́ èyí tá a gbọ́dọ̀ ṣe kìkì lẹ́yìn tá a bá ti gbàdúrà láti rí ìtọ́sọ́nà gbà lọ́dọ̀ Jèhófà. Àmọ́, ìpinnu èyíkéyìí tá a bá ṣe, a gbọ́dọ̀ máa rántí ọ̀rọ̀ àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù pé: “Olúkúlùkù wa ni yóò ṣe ìjíhìn ara rẹ̀ fún Ọlọ́run.” (Róòmù 14:12) Gẹ́gẹ́ bá a ti sọ ṣáájú, ohun tí Jèhófà fẹ́ ni pé kí àwọn ìránṣẹ́ òun lẹ́nì kọ̀ọ̀kan jẹ́ olóòótọ́ nínú gbogbo ipò tí wọ́n bá bá ara wọn. Àwọn kan lára àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ ń fojú winá àdánwò àti inúnibíni lónìí; ti àwọn mìíràn lè dé lọ́la. Gbogbo wa pátá la ó dán wò lọ́nà kan ṣá, kí ẹnikẹ́ni má ṣe rò pé tòun ò ní í dé. (Jòhánù 15:19, 20) Níwọ̀n bá a ti jẹ́ ìránṣẹ́ tó ti ya ara wa sí mímọ́ fún Jèhófà, kò sí bá a ṣe lè bọ́ nínú ọ̀ràn tó kan gbogbo èèyàn, ìyẹn sísọ orúkọ Jèhófà di mímọ́ àti dídá ipò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba aláṣẹ láre.—Ìsíkíẹ́lì 38:23; Mátíù 6:9, 10.

“Ẹ Má Ṣe Fi Ibi San Ibi fún Ẹnì Kankan”

10. Àpẹẹrẹ pàtàkì wo ni Jésù àtàwọn àpọ́sítélì rẹ̀ fi lélẹ̀ fún wa nípa bó ṣe yẹ ká kojú àwọn ìṣòro àti àtakò?

10 Ìlànà pàtàkì mìíràn tá a lè kọ́ látinú ohun tí Jésù àtàwọn àpọ́sítélì rẹ̀ ṣe nígbà tí wọ́n wà nínú ìṣòro ni pé kí a má ṣe gbẹ̀san lára àwọn tó ń ṣe inúnibíni sí wa. Kò sí ibi kankan nínú Bíbélì tá a ti rí ohun tó jọ pé Jésù àtàwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ ṣètò ara wọn sí àjọ ajàjàgbara tàbí tí wọ́n hu ìwà ipá láti bá àwọn tó ń ṣe inúnibíni sí wọn jà. Ní ìyàtọ̀ pátápátá síyẹn, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù gba àwọn Kristẹni nímọ̀ràn pé, kí wọ́n “má ṣe fi ibi san ibi fún ẹnì kankan. Ẹ má ṣe gbẹ̀san ara yín, ẹ̀yin olùfẹ́ ọ̀wọ́n, ṣùgbọ́n ẹ yàgò fún ìrunú; nítorí a ti kọ̀wé rẹ̀ pé: ‘Tèmi ni ẹ̀san; dájúdájú, èmi yóò san ẹ̀san, ni Jèhófà wí.’” Síwájú sí i, “má ṣe jẹ́ kí ibi ṣẹ́gun rẹ, ṣùgbọ́n máa fi ire ṣẹ́gun ibi.”—Róòmù 12:17-21; Sáàmù 37:1-4; Òwe 20:22.

11. Kí ni òpìtàn kan sọ nípa ìwà àwọn Kristẹni ìjímìjí sí àwọn aláṣẹ Orílẹ̀-èdè?

11 Àwọn Kristẹni ìjímìjí fi ìmọ̀ràn yìí sọ́kàn. Nínú ìwé The Early Church and the World, tí òpìtàn nì, Cecil J. Cadoux kọ, ó ṣàpèjúwe ìwà àwọn Kristẹni sí àwọn aláṣẹ orílẹ̀-èdè láàárín ọ̀rúndún ọgbọ̀n sí ọ̀rúndún àádọ́rin Sànmánì Tiwa. Ó kọ̀wé pé: “A ò ní ẹ̀rí kankan tó fi hàn pé àwọn Kristẹni àkókò náà hu ìwa ipá kankan láti kojú inúnibíni. Wọn ò ṣe kọjá pé kí wọ́n sọ̀rọ̀ tó le sáwọn aláṣẹ tàbí kí wọ́n sá mọ́ àwọn aláṣẹ wọ̀nyí lọ́wọ́. Àmọ́ ṣá o, ohun táwọn Kristẹni máa ń ṣe nígbà inúnibíni kò ju pé kí wọ́n kọ̀ láti ṣègbọràn sí òfin ìjọba èyí tí wọ́n rí i pé ó lòdì sí àṣẹ Kristi, wọn kì í sì í ki àṣejù bọ̀ ọ́.”

12. Kí nìdí tó fi sàn láti fara da ìjìyà ju kéèyàn gbẹ̀san lọ?

12 Ṣé irú ìwà àìjanpata yìí bọ́gbọ́n mu? Ṣé ẹni tó bá ń hu irú ìwà yìí kò ní mú nǹkan rọrùn fún àwọn to ti ń wá ọ̀nà láti tẹ̀ wọ́n rẹ́? Ǹjẹ́ kò ní bọ́gbọ́n mu láti gbèjà ara ẹni? Ìyẹn lè dà bí ohun tó bọ́gbọ́n mu jù lọ lójú èèyàn. Àmọ́, gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ Jèhófà, ó dá wa lójú pé títẹ̀lé ìtọ́sọ́nà Jèhófà nínú gbogbo ọ̀ràn ni ohun tó dára jù lọ láti ṣe. A ń fi ọ̀rọ̀ Pétérù sọ́kàn pé: “Bí ẹ bá fara dà á nígbà tí ẹ bá ń ṣe rere, tí ẹ sì ń jìyà, èyí jẹ́ ohun tí ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà lọ́dọ̀ Ọlọ́run.” (1 Pétérù 2:20) Ó dá wa lójú pé Jèhófà rí gbogbo ohun tó ń ṣẹlẹ̀, kò sì ní jẹ́ kí ọ̀ràn náà máa bá a lọ bẹ́ẹ̀ láìlópin. Báwo nìyẹn ṣe lè dá wa lójú? Jèhófà sọ fún àwọn èèyàn rẹ̀ tó wà nígbèkùn ní Bábílónì pé: “Ẹni tí ó bá fọwọ́ kàn yín ń fọwọ́ kan ẹyinjú mi.” (Sekaráyà 2:8) Ǹjẹ́ a rí ẹni tó lè la ojú rẹ̀ sílẹ̀ kí ẹnì kan sì máa tọwọ́ bọ̀ ọ́? Jèhófà yóò dá àwọn èèyàn rẹ̀ nídè ní àkókò tó tọ́ lójú rẹ̀. Ó sì dájú pé ìyẹn máa rí bẹ́ẹ̀.—2 Tẹsalóníkà 1:5-8.

13. Kí nìdí tí Jésù fi gbà láìjanpata pé kí àwọn ọ̀tá mú òun?

13 Nínú irú ọ̀ràn bẹ́ẹ̀, a lè máa wo Jésù gẹ́gẹ́ bí àwòfiṣàpẹẹrẹ wa. Nígbà tó jẹ́ kí àwọn ọ̀tá rẹ̀ mú un nínú ọgbà Gẹtisémánì, kì í ṣe pé kò lè gbèjà ara rẹ̀. Kódà ó sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Ìwọ ha rò pé èmi kò lè ké gbàjarè sí Baba mi láti pèsè àwọn áńgẹ́lì tí ó ju líjíónì méjìlá fún mi ní ìṣẹ́jú yìí? Bí ọ̀ràn bá rí bẹ́ẹ̀, báwo ni a ó ṣe mú Ìwé Mímọ́ ṣẹ pé ó gbọ́dọ̀ ṣẹlẹ̀ lọ́nà yìí?” (Mátíù 26:53, 54) Mímú ìfẹ́ Jèhófà ṣẹ ni ohun tó ṣe pàtàkì jù lọ lójú Jésù, bí ìyẹn tiẹ̀ máa fìyà jẹ ẹ́ pàápàá. Ó ní ìgbọ́kànlé kíkún nínú sáàmù alásọtẹ́lẹ̀ tí Dáfídì kọ pé: “Ìwọ kì yóò fi ọkàn mi sílẹ̀ sínú Ṣìọ́ọ̀lù. Ìwọ kì yóò jẹ́ kí ẹni ìdúróṣinṣin rẹ rí kòtò.” (Sáàmù 16:10) Ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn ìyẹn ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ nípa Jésù pé: “Nítorí ìdùnnú tí a gbé ka iwájú rẹ̀, ó fara da òpó igi oró, ó tẹ́ńbẹ́lú ìtìjú, ó sì ti jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún ìtẹ́ Ọlọ́run.”—Hébérù 12:2.

Ayọ̀ Tó Wà Nínú Sísọ Orúkọ Jèhófà Di Mímọ́

14. Ayọ̀ wo ló mẹ́sẹ̀ Jésù dúró ní gbogbo àkókò tó fi wà nínú àdánwò?

14 Ayọ̀ wo ló mẹ́sẹ̀ Jésù dúró ní gbogbo àkókò tó fi kojú àdánwò tó burú jáì yẹn? Nínú gbogbo ìránṣẹ́ Jèhófà, Jésù, tó jẹ́ Ọmọ ọ̀wọ́n fún Ọlọ́run ni ẹni tí Sátánì kà sí ọ̀tá òun jù lọ. Nítorí náà, bí Jésù ṣe pa ìwà títọ́ rẹ̀ mọ́ lábẹ́ àdánwò yẹn jẹ́ èsì tó ga ju lọ sí ṣíṣáátá tí Sátánì ń ṣáátá Jèhófà. (Òwe 27:11) Ǹjẹ́ o lè fojú inú wo bí ayọ̀ Jésù á ṣe pọ̀ tó àti bí ọkàn rẹ̀ ṣe máa balẹ̀ tó nígbà tó jíǹde? Inú rẹ̀ á mà dùn gan-an o, pé òun ti ṣe ipa tá a ní kí òun ṣe gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá ènìyàn pípé láti dá ipò Jèhófà láre gẹ́gẹ́ bí ọba aláṣẹ àti láti sọ orúkọ Rẹ̀ di mímọ́! Láfikún sí i, kò sí àní-àní pe jíjókòó ‘sí ọwọ́ ọ̀tún ìtẹ́ Ọlọ́run’ ti ní láti jẹ́ àgbàyanu ọlá àti orísun ayọ̀ gíga jù lọ fún Jésù.—Sáàmù 110:1, 2; 1 Tímótì 6:15, 16.

15, 16. Inúnibíni tó burú jáì wo ni àwọn Ẹlẹ́rìí tó wà ní Sachsenhausen fara dà, kí ló sì fún wọn lókun láti ṣe bẹ́ẹ̀?

15 Bákan náà ló jẹ́ ayọ̀ àwa Kristẹni láti kópa nínú sísọ orúkọ Jèhófà di mímọ́ nípa fífarada àwọn àdánwò àti inúnibíni, ká sì tipa bẹ́ẹ̀ tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù. Àpẹẹrẹ kan ni ti ìrírí àwọn Ẹlẹ́rìí tó jìyà ní àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ tó wà ní Sachsenhausen, tí wọ́n sì tún la ìrìn àjò àfẹsẹ̀rìn tó lè ṣekú pani já nígbà tó kù díẹ̀ kí Ogun Àgbáyé Kejì parí. Nígbà tí wọ́n ń rin ìrìn náà, ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn ẹlẹ́wọ̀n ló kú nítorí òtútù, àìsàn, tàbí ebi tàbí pípa táwọn ẹ̀ṣọ́ tí à ń pè ní SS ń pa wọ́n nípakúpa sẹ́gbẹ̀ẹ́ ọ̀nà. Gbogbo àwọn Ẹlẹ́rìí tó wà níbẹ̀, tí iye wọ́n jẹ́ igba ó lé ọgbọ̀n, ló là á já nítorí pé wọ́n ṣe ara wọn ní òṣùṣù ọwọ́ tí wọ́n sì ran ara wọn lọ́wọ́ bó tilẹ̀ jẹ́ pé èyí lè fi ìwàláàyè wọn sínú ewu.

16 Kí ló fún àwọn Ẹlẹ́rìí wọ̀nyẹn lókun láti fara da irú inúnibíni tó burú jáì yẹn? Gbàrà tí wọ́n dé ibi tí wọ́n ń lọ ni wọ́n fi ayọ̀ àti ọpẹ́ wọn hàn fún Jèhófà tí wọ́n sì kọ ọ́ sínú ìwé kan tí wọ́n pe àkòrí rẹ̀ ní “Ìpinnu táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí iye wa jẹ́ igba ó lé ọgbọ̀n láti orílẹ̀-èdè mẹ́fà ṣe, nínú igbó kan tí a kó ara wa jọ sí nítòsí Schwerin ní Mecklenburg.” Wọ́n sọ nínú ìwé yẹn pé: “Àkókò tí nǹkan le koko bí ojú ẹja ti kọjá, àwọn tó sì là á já dà bi ẹni pé ńṣe la yọ wọ́n nínú iná, òórùn iná kò sì sí lára wọn. (Wo Dáníẹ́lì 3:27) Kàkà bẹ́ẹ̀, koko lara wọn le, Jèhófà fún wọn lágbára, wọ́n sì ń fi gbogbo ara retí àṣẹ mìíràn tí Ọba náà yóò fún wọn láti mú kí ire Ìjọba náà tẹ̀ síwájú.” c

17. Irú àwọn àdánwò wo làwọn èèyàn Ọlọ́run ń dojú kọ lónìí?

17 Bíi ti àwọn olóòótọ́ igba ó lé ọgbọ̀n yẹn, wọ́n lè dán ìgbàgbọ́ ti àwa náà wò, bó tilẹ̀ jẹ́ pé a kò “tíì dúró tiiri títí dé orí ẹ̀jẹ̀.” (Hébérù 12:4) Àmọ́ àwọn àdánwò pọ̀ lónírúurú. Àwọn ọmọ kíláàsì lè máa fini ṣẹ̀sín, tàbí kí ẹ̀mí ṣohun-tẹ́gbẹ́-ń-ṣe mú kí ẹnì kan fẹ́ hù ìwà pálapàla àtàwọn ìwà búburú mìíràn. Bákan náà, ìpinnu láti má ṣe gba ẹ̀jẹ̀ sára, láti gbéyàwó kìkì nínú Olúwa, tàbí láti tọ́ ọmọ dàgbà nínú ìgbàgbọ́ nínú ilé kan ti ẹ̀sìn ti yàtọ̀ síra lè fa ìṣòro àti àdánwò líle koko nígbà mìíràn.—Ìṣe 15:29; 1 Kọ́ríńtì 7:39; Éfésù 6:4; 1 Pétérù 3:1, 2.

18. Ẹ̀rí ìdánilójú wo la ní pé a lè fara da àdánwò tó burú jù lọ pàápàá?

18 Àmọ́ ṣá o, àdánwò èyíkéyìí tó lè dojú kọ wá, a mọ̀ pé ìdì tá a fi ń jìyà ni pé a fi Jèhófà àti Ìjọba rẹ̀ sí ipò kìíní, a sì gbà pé àǹfààní àti ayọ̀ ńlá ló jẹ́ fún wa láti ṣe bẹ́ẹ̀. Ọ̀rọ̀ tí Pétérù sọ fi wá lọ́kàn balẹ̀ gan-an pé: “Bí a bá ń gàn yín nítorí orúkọ Kristi, ẹ̀yin jẹ́ aláyọ̀, nítorí pé ẹ̀mí ògo, àní ẹ̀mí Ọlọ́run, ti bà lé yín.” (1 Pétérù 4:14) Ní agbára ẹ̀mí Jèhófà, a ní okun láti fara da àwọn àdánwò tó le koko jù lọ pàápàá, gbogbo rẹ̀ sì jẹ́ sí ògo àti ìyìn rẹ̀.—2 Kọ́ríńtì 4:7; Éfésù 3:16; Fílípì 4:13.

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó wáyé láwọn ọdún 1960 wulẹ̀ jẹ́ ìbẹ̀rẹ̀ onírúurú inúnibíni rírorò táwọn Ẹlẹ́rìí tó wà ní Màláwì ní láti fara dà fún ohun tó fẹ́rẹ̀ẹ́ lé ní ọgbọ̀n ọdún. Fún ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìtàn náà, wo ìwé 1999 Yearbook of Jehovah’s Witnesses, ojú ìwé 171 sí 212.

b Wo àpilẹ̀kọ náà, “Ilé Ẹjọ́ Gíga Ti Ìsìn Tòótọ́ Lẹ́yìn ní ‘Ilẹ̀ Árárátì,’” nínú Ilé Ìṣọ́ ti April 1, 2003, ojú ìwé 11 sí 14.

c Láti rí ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìpinnu yìí, wo ìwé 1974 Yearbook of Jehovah’s Witnesses, ojú ìwé 208 àti 209. Ọ̀rọ̀ tí ọ̀kan lára àwọn tó rù ú la nínú ìrìn àjò tó lè ṣekú pani náà sọ wà nínú Ilé Ìṣọ́ ti January 1, 1998, ojú ìwé 25 sí 29.

Ǹjẹ́ O Lè Ṣàlàyé?

• Ojú wo làwọn Kristẹni fi ń wo ìjìyà àti inúnibíni?

• Ẹ̀kọ́ wo la lè rí kọ́ látinú ohun tí Jésù àtàwọn olóòótọ́ mìíràn ṣe nígbà tí wọ́n wà nínú àdánwò?

• Kí nìdí tí kò fi bọ́gbọ́n mu láti gbẹ̀san nígbà tá a bá dojú kọ inúnibíni?

• Ayọ̀ wo ló mẹ́sẹ̀ Jésù dúró lákòókò àdánwò, ẹ̀kọ́ wo la sì lè rí kọ́ látinú èyí?

[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]

[Àpótí/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]

Ohun Tí Wọ́n Ṣe Lákòókò Inúnibíni

• Kó tó di pé àwọn sójà Hẹ́rọ́dù dé sí Bẹ́tílẹ́hẹ́mù láti pa gbogbo ọmọ ọwọ́ tí wọ́n jẹ́ ọmọkùnrin ọlọ́dùn méjì sísàlẹ̀, Jósẹ́fù àti Màríà gbé Jésù tó jẹ́ ọmọ ọwọ́ nígbà yẹn, wọ́n sì forí lé Íjíbítì lábẹ́ ìdarí áńgẹ́lì kan.—Mátíù 2:13-16.

• Lákòókò tí Jésù ń ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀, ọ̀pọ̀ ìgbà làwọn ọ̀tá rẹ̀ fẹ́ pa á nítorí ẹ̀rí lílágbára tó ń jẹ́. Jésù sì sá mọ́ wọ́n lọ́wọ́ làwọn àkókò wọ̀nyí.—Mátíù 21:45, 46; Lúùkù 4:28-30; Jòhánù 8:57-59.

• Nígbà táwọn sójà àtàwọn tó wà nípò àṣẹ wá sí ọgbà Gẹtisémánì láti wá mú Jésù, ẹ̀ẹ̀méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ló fara hàn wọ́n ní gbangba pé: “Èmi ni ẹni náà.” Ó tiẹ̀ sọ pé kí àwọn ọmọlẹ́yìn òun má gbèjà òun rárá, pé kí wọ́n jẹ́ kí àwọn jàǹdùkú náà máa mú òun lọ.—Jòhánù 18:3-12.

• Wọ́n mú Pétérù àtàwọn mìíràn ní Jerúsálẹ́mù, wọ́n nà wọ́n, wọ́n sì pàṣẹ fún wọn láti má ṣe sọ̀rọ̀ nípa Jésù mọ́. Síbẹ̀, bí wọ́n ṣe dá wọn sílẹ̀ báyìí ni wọ́n “bá ọ̀nà wọn lọ . . . . , ní ojoojúmọ́ nínú tẹ́ńpìlì àti láti ilé dé ilé ni wọ́n sì ń bá a lọ láìdábọ̀ ní kíkọ́ni àti pípolongo ìhìn rere nípa Kristi náà, Jésù.”—Ìṣe 5:40-42.

• Nígbà tí Sọ́ọ̀lù tó wá di àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù gbọ́ nípa ọ̀tẹ̀ tí àwọn Júù tó wà ní Damásíkù dì láti pa òun, àwọn arákùnrin gbé e sínú apẹ̀rẹ̀ wọ́n sì gbé e gba ojú ihò kan lára ògiri ìlú náà lóru, wọn ò sì rí i pa.—Ìṣe 9:22-25.

• Ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn náà, Pọ́ọ̀lù yàn pé ká gbé ẹjọ́ òun lọ síwájú Késárì, bó tilẹ̀ jẹ́ pé Fẹ́sítọ́ọ̀sì tó jẹ́ Gómìnà àti Àgírípà Ọba rí i pé kò ṣe “nǹkan kan tí ó yẹ fún ikú tàbí àwọn ìdè.”—Ìṣe 25:10-12, 24-27; 26:30-32.

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16, 17]

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé inúnibíni líle koko mú káwọn kan sá kúrò nílùú, síbẹ̀ ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn olóòótọ́ tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí ní Màláwì ló ń bá iṣẹ́ ìsìn Ìjọba náà lọ tayọ̀tayọ̀

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]

Ayọ̀ sísọ orúkọ Jèhófà di mímọ́ ló mẹ́sẹ̀ àwọn olóòótọ́ wọ̀nyí dúró ní gbogbo àkókò ìrìn aṣekúpani ti Ìjọba Násì àti làwọn àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́

[Credit Line]

Ìrìn àjò àfẹsẹ̀rìn tó lè ṣekú pani: KZ-Gedenkstätte Dachau, nípasẹ̀ ìyọ̀ǹda the USHMM Photo Archives

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]

Onírúurú ọ̀nà ni àwọn àdánwò àti ìṣòro lè gbà wá