“Mi Ò Gbọ́ Irú Èyí Rí!”
Àwọn Olùpòkìkí Ìjọba Ròyìn
“Mi Ò Gbọ́ Irú Èyí Rí!”
ÒJÍṢẸ́ alákòókò kíkún ti àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni Dorota nílùú Poland. Ó bá ọmọkùnrin rẹ̀ ọlọ́dún mẹ́rìnlá lọ sí ọsibítù ilé ẹ̀kọ́ rẹ̀ fún àyẹ̀wò ìtọ́jú àtìgbàdégbà. Lákòókò àyẹ̀wò náà, dókítà tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Janina a bi Dorota léèrè nípa iṣẹ́ ilé tí ọmọ rẹ̀ máa ń ṣe.
Dorota dáhùn pé: “Ó máa ń ṣe oúnjẹ fún àwa mẹ́fẹ̀ẹ̀fà tó wà nínú ìdílé mi, nígbà tí mi ò bá lè ṣe é. Ó tún máa ń mú kí ilé wà ní mímọ́ tónítóní, ó sì tún máa ń ṣàtúnṣe àwọn nǹkan nínú ilé. Ó fẹ́ràn láti máa kàwé. Kò sì fi ẹ̀kọ́ rẹ̀ ṣeré nílé ìwé.”
Janina dáhùn pé: Mi ò rírú ẹ̀ rí. Ọdún kejìlá rèé ti mo ti ń ṣiṣẹ́ níbí yìí, mi ò sì tíì gbọ́ irú èyí rí.”
Nígbà tí Dorota rí i pé àǹfààní láti wàásù ló ṣí sílẹ̀ yìí, ó ṣàlàyé pé: “Ọ̀pọ̀ àwọn òbí lónìí ti kùnà láti tọ́ àwọn ọmọ wọn bó ti tọ́ àti bó ti yẹ. Ìdí nìyẹn táwọn ọmọ wọn fi máa ń rò pé àwọn ò jámọ́ nǹkankan.”
Janina béèrè pé: “Báwo lo ṣe mọ gbogbo èyí? Ọ̀pọ̀ àwọn òbí ni kò mọ nǹkankan nípa èyí.”
Dorota fèsì pé: “Bíbélì ni orísun ìsọfúnni ṣíṣeyebíye náà. Bí àpẹẹrẹ, gẹ́gẹ́ bí ohun tí Diutarónómì 6:6-9 sọ, a ní láti kọ́kọ́ dá ara wa lẹ́kọ̀ọ́ kí á tó lè dá àwọn ọmọ wa lẹ́kọ̀ọ́. Ṣé kò yẹ kí a kọ́kọ́ gbin ìwà rere tá a fẹ́ sínú ọkàn àti èrò àwa fúnra wa kí á tó lè gbìn wọ́n sínú àwọn ọmọ wa ni?”
Janina sọ pé: “Èyí mà ga lọ́lá o. Èyí mà ga lọ́lá o!” Ó wá béèrè lọ́wọ́ Dorota bí Bíbélì ṣe ràn án lọ́wọ́ láti tọ́ àwọn ọmọ rẹ̀ bó ti tọ́ àti bó ṣe yẹ.
Dorota ṣàlàyé pé: “A máa ń kọ́ àwọn ọmọ wa lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ní ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀. A máa ń lo ìwé tí a pè ní Awọn Ìbéèrè Tí Awọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè—Awọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́.” b Ó tẹ̀ síwájú láti ṣàlàyé ìwé náà ó sì mẹ́nu bá díẹ̀ lára àwọn àkòrí tó wà nínú rẹ̀.
Janina lahùn, ó ní: “Mi ò gbọ́ irú èyí rí! Ǹjẹ́ o lè jẹ́ kí ń rí ìwé náà?”
Dorota mú ìwé náà wá fún un ní wákàtí kan lẹ́yìn náà.
Bí Janina ti ń yẹ ìwé náà wò, ó béèrè pé: “Ẹ̀sìn wo lò ń ṣe?”
Ó dáhùn pé: “Ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni mí.”
Janina béèrè pé: “Báwo ni àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe ń ṣe sí àwọn ẹlẹ́sìn mìíràn?”
Dorota dáhùn, ó ní: “Bí mo ṣe ṣe sí ọ gan-an ni—pẹ̀lú ọ̀wọ̀.” Ó tún fi kún un pé: “Àmọ́ ṣá o, à ń fẹ́ kí àwọn náà wá mọ òtítọ́ tí Bíbélì fi ń kọ́ni.”
Janina sọ bọ́rọ̀ náà ṣe rí lára rẹ̀, o ní: “Ara tiẹ̀ ti tù mí báyìí.”
Nígbà tí Dorota fẹ́ kúrò níbẹ̀, ó rọ Janina láti máa ka Bíbélì. Ó ní: “Yóò mú kí ìgbésí ayé rẹ nítumọ̀, yóò sì ràn ọ́ lọ́wọ́ nídìí iṣẹ́ rẹ.”
Janina sòótọ́, o ní: “O ti fún mi lókun gan-an láti máa ṣe bẹ́ẹ̀.”
Nípa lílo ọgbọ́n pẹ̀lú ìmúratán, Dorota lo àkókò tó fi wà lọ́dọ̀ dókítà yìí láti wàásù fún un lọ́nà rere.—1 Pétérù 3:15.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Kì í ṣe orúkọ rẹ̀ gan-gan.
b Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la tẹ̀ ẹ́ jáde.