Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ẹ̀yin Ọ̀dọ́, Ẹ Máa Rìn ní Ọ̀nà Tó Wu Jèhófà

Ẹ̀yin Ọ̀dọ́, Ẹ Máa Rìn ní Ọ̀nà Tó Wu Jèhófà

Ẹ̀yin Ọ̀dọ́, Ẹ Máa Rìn ní Ọ̀nà Tó Wu Jèhófà

Ó TI di dandan káwọn ọ̀dọ́ Kristẹni kan fi ìdílé àti ìjọ wọn sílẹ̀ fúngbà díẹ̀. Àwọn kan ti ṣe bẹ́ẹ̀ kí wọ́n lè mú kí iṣẹ́ òjíṣẹ́ wọn gbòòrò sí i. Àwọn mìíràn sì ti fi ìlú wọn sílẹ̀ nítorí pé wọn ò fẹ́ dá sí tọ̀túntòsì nínú ọ̀ràn ìṣèlú ayé yìí. (Aísáyà 2:4; Jòhánù 17:16) Àwọn orílẹ̀-èdè kan sì wà tí “Késárì” ti ní kí àwọn ọ̀dọ́ tó ń pa ìwà títọ́ mọ́ lọ ṣẹ̀wọ̀n tàbí kí wọ́n lọ ṣe iṣẹ́ sin ìlú. aMáàkù 12:17; Títù 3:1, 2.

Ó lè jẹ́ ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ tó ti ya pòkíì ni wọ́n máa kó àwọn ọ̀dọ́ wọ̀nyí sí fún ìgbà gígùn lákòókò tí wọ́n fi ń ṣẹ̀wọ̀n nítorí àìdásí-tọ̀túntòsì wọn yìí. Kíkúrò nílé nítorí ìdí mìíràn tún lè jẹ́ káwọn ọ̀dọ́ lọ ṣiṣẹ́ lágbègbè táwọn èèyàn ti ń hù ìwà burúkú. Báwo làwọn Kristẹni ọ̀dọ́ wọ̀nyí tàbí àwọn mìíràn tó bára wọn nínú irú ipò bẹ́ẹ̀ ṣe lè kojú ìṣòro àti ẹ̀mí ṣohun-tẹ́gbẹ́-ń-ṣe tí wọ́n lè dojú kọ bí wọ́n ti ń làkàkà láti ‘máa bá a lọ ní rírìn lọ́nà tó wu Ọlọ́run?’ (1 Tẹsalóníkà 2:12) Báwo làwọn òbí wọn ṣe lè ràn wọ́n lọ́wọ́ láti múra sílẹ̀ fún ipò tí kò bára dé tí wọ́n lè bára wọn?—Òwe 22:3.

Ìṣòro Tó Dojú Kọ Àwọn Ọ̀dọ́

Tákis, ọmọ ọdún mọ́kànlélógún tó di dandan fún láti kúrò nílé fún odindi ọdún mẹ́ta àti oṣù kan sọ pé: “Kíkúrò lábẹ́ ààbò àwọn òbí mi àti lábẹ́ àbójútó onífẹ̀ẹ́ àwọn alàgbà tó mọ̀ mi dáadáa jẹ́ ohun tó ṣòro gan-an tó sì dáyà fò mí.” b Ó tún sọ pé: “Ìgbà mìíràn wà tó máa ń ṣe mi bíi pé mi ò ní alábàárò kankan.” Pétros tó jẹ́ ọmọ ogún ọdún ni láti fi ilé sílẹ̀ fún ohun tó lé ní ọdún méjì gbáko. Ó jẹ́wọ́ pé: “Ìgbà àkọ́kọ́ nínú ìgbésí ayé mi rèé tí mo ní láti dá nìkan ṣe àwọn ìpinnu nípa eré ìnàjú àti nípa irú àwọn èèyàn tí mò ń bá kẹ́gbẹ́, ìpinnu tí mo sì máa ń ṣe kì í sábàá mọ́gbọ́n dání.” Ó wá sọ pé: “Ìgbà mìíràn wà tí mo máa ń dààmú gan-an nítorí ẹrù iṣẹ́ púpọ̀ tí òmìnira tí mo wá ní báyìí gbé lé mi léjìká.” Tássos, ìyẹn Kristẹni alàgbà kan tó máa ń bá àwọn Kristẹni ọ̀dọ́ tó wà nínú irú ipò bẹ́ẹ̀ pàdé déédéé, sọ pé: “Ọrọ̀ rírùn, ìwà ọ̀tẹ̀, àti ìwà ipá àwọn ẹlẹ́gbẹ́ wọn tó jẹ́ aláìgbàgbọ́ lè nípa lórí àwọn ọ̀dọ́ tí kò fura tí wọ́n sì wà nínú ewu.”

Àwọn Kristẹni ọ̀dọ́ tó ń gbé láàárín àwọn èèyàn tí kò bọ̀wọ̀ fún ìlànà Bíbélì, tí wọ́n sì tún ń ṣiṣẹ́ láàárín wọn ní láti ṣọ́ra kí wọ́n má bàa kó sínú ìdẹwò. Kí wọ́n yẹra fún ìdẹwò fífara wé ìwà búburú tàwọn ojúgbà wọn ń hù àti àwọn ọ̀nà tí kò bá Ìwé Mímọ́ mu tí wọ́n ń tọ̀. (Sáàmù 1:1; 26:4; 119:9) Dídá kẹ́kọ̀ọ́, lílọ́ sáwọn ìpàdé àti òde ẹ̀rí déédéé lè jẹ́ ohun tó ṣòro. (Fílípì 3:16) Gbígbé ohun tí wọ́n á máa lépa nípa tẹ̀mí kalẹ̀ kí wọ́n sì lé e bá lè má rọrùn rárá.

Ó dájú pé ńṣe làwọn Kristẹni ọ̀dọ́ tí wọ́n jẹ́ olóòótọ́ fẹ́ kí ìwà àti ọ̀rọ̀ ẹnu àwọn máa múnú Jèhófà dùn. Tọkàntọkàn ni wọ́n fi ń gbìyànjú láti ṣe ohun tí Baba wọn ọ̀run ń rọ̀ wọ́n pé kí wọ́n ṣe, ó ní: “Ọmọ mi, jẹ́ ọlọ́gbọ́n, kí o sì mú ọkàn-àyà mi yọ̀, kí n lè fún ẹni tí ń ṣáátá mi lésì.” (Òwe 27:11) Wọ́n mọ̀ pé ó nípa tí ìrísí àti ìwà wọn ń kó nínú ojú tàwọn ẹlòmíràn fi ń wo Jèhófà àtàwọn èèyàn rẹ̀.—1 Pétérù 2:12.

Ó dùn mọ́ni nínú pé ọ̀pọ̀ jù lọ irú àwọn ọ̀dọ́ bẹ́ẹ̀ ló ń sa gbogbo ipá wọn láti dà bí àwọn arákùnrin wọn ọ̀rúndún kìíní, ìyẹn àwọn tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù gbàdúrà fún pé: “Kí ẹ lè máa rìn lọ́nà tí ó yẹ Jèhófà fún ète wíwù ú ní kíkún bí ẹ ti ń bá a lọ ní síso èso nínú iṣẹ́ rere gbogbo . . . kí ẹ bàa lè fara dà á ní kíkún, kí ẹ sì máa ní ìpamọ́ra pẹ̀lú ìdùnnú.” (Kólósè 1:9-11) Bíbélì fún wa lápẹẹrẹ àwọn ọ̀dọ́ bíi mélòó kan tí wọ́n rin ní ọ̀nà tó wu Ọlọ́run ní àwọn ibi tó ṣàjèjì, tí kò bára dé, tó sì kún fún ìbọ̀rìṣà.—Fílípì 2:15.

“Jèhófà Wà Pẹ̀lú Jósẹ́fù”

Jósẹ́fù tó jẹ́ àyànfẹ́ ọmọ fún Jékọ́bù àti Rákélì ṣì kéré gan-an nígbà tó bá ara rẹ̀ níbi tó jìnnà gan-an síbi tí bàbá rẹ̀ tó bẹ̀rù Ọlọ́run ti lè dáàbò bó o. Wọ́n tà á sóko ẹrú ní Íjíbítì. Jósẹ́fù fi àpẹẹrẹ tó wúni lórí gan-an lélẹ̀, ní ti pé ó jẹ́ ọ̀dọ́ aláápọn, tó ṣeé fọkàn tán, tó sì níwà rere. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹrú ni Jósẹ́fù jẹ́ fún Pọ́tífárì tí kì í ṣe olùjọsìn Jèhófà, síbẹ̀ tọkàntọkàn àti taápọntaápọn ló fi ṣiṣẹ́ débi pé ọ̀gá rẹ̀ ní láti fi gbogbo ohun tó wà nínú agboolé rẹ̀ síkàáwọ́ Jósẹ́fù níkẹyìn. (Jẹ́nẹ́sísì 39:2-6) Jósẹ́fù pa ìwà títọ́ rẹ̀ mọ́ sí Jèhófà, nígbà tí èyí sì wá yọrí sí jíjù ú sí ọgbà ẹ̀wọ̀n, kò bẹ̀rẹ̀ sí í sọ pé: “Kí làǹfààní pípa tí mò ń pa ìwà títọ́ mọ́?” Kódà ó fi àwọn ànímọ́ tó dára gan-an hàn nínú ọgbà ẹ̀wọ̀n, kò sì pẹ́ tó fi bẹ̀rẹ̀ sí bójú tó gbogbo nǹkan tó ń lọ nínú ọgbà ẹ̀wọ̀n náà. (Jẹ́nẹ́sísì 39:17-22) Ọlọ́run bù kún un, Jẹ́nẹ́sísì 39:23 sì sọ pé, “Jèhófà wà pẹ̀lú Jósẹ́fù.”

Nítorí pé Jósẹ́fù kò sí lọ́dọ̀ ìdílé rẹ̀ tó bẹ̀rù Ọlọ́run, ẹ ò rí i pé ì bá rọrùn fún un gan-an láti mú ìwà rẹ̀ bá ti àwọn kèfèrí tó yí i ká mu, kó máa tọ ọ̀nà ìgbésí ayé oníwà pálapàla tàwọ́n ará Íjíbítì ń tọ̀! Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ló rọ̀ mọ́ ìlànà Ọlọ́run tó sì ń hu ìwà mímọ́ láìfi àwọn ìdẹwò líle koko tó dojú kọ ọ́ pè. Nígbà tí aya Pọ́tífárì ń fi gbogbo ìgbà rọ̀ ọ́ pé kó bá òun lò pọ̀, ìdáhùn tó sojú abẹ níkòó tó sọ fún un ni pé: “Báwo ni èmi ṣe lè hu ìwà búburú ńlá yìí, kí n sì dẹ́ṣẹ̀ sí Ọlọ́run ní ti gidi?”—Jẹ́nẹ́sísì 39:7-9.

Lónìí, àwọn ọ̀dọ́ tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí gbọ́dọ̀ kọbi ara sí àwọn ìkìlọ̀ tí Bíbélì fún wọn nípa ẹgbẹ́kẹ́gbẹ́, eré ìnàjú oníwà pálapàla, àwọn ohun arùfẹ́-ìṣekúṣe-sókè àtàwọn orin tó ń gbé ìwà ìbàjẹ́ lárugẹ. Wọ́n mọ̀ pé “ojú Jèhófà ń bẹ ní ibi gbogbo, ó ń ṣọ́ àwọn ẹni búburú àti àwọn ẹni rere.”—Òwe 15:3.

Mósè Kọ̀ Láti Jẹ “Ìgbádùn Ẹ̀ṣẹ̀”

Àgbàlá Fáráò tí ìbọ̀rìṣà ti gbilẹ̀ táwọn èèyàn ibẹ̀ sì nífẹ̀ẹ́ fàájì bi nǹkan míì ni Mósè ti dàgbà. Bíbélì sọ nípa rẹ̀ pé: “Nípa ìgbàgbọ́ ni Mósè . . . fi kọ̀ kí a máa pe òun ní ọmọkùnrin ti ọmọbìnrin Fáráò, ó yàn pé kí a ṣẹ́ òun níṣẹ̀ẹ́ pẹ̀lú àwọn ènìyàn Ọlọ́run dípò jíjẹ ìgbádùn ẹ̀ṣẹ̀ fún ìgbà díẹ̀.”—Hébérù 11:24, 25.

Bíbá ayé dọ́rẹ̀ẹ́ lè fúnni ní àwọn àǹfààní kan, àmọ́ fúngbà díẹ̀ ni. Bó ti wù kó pẹ́ tó, kò lè pẹ́ títí kó kọjá àkókò tó ṣẹ́ kù fún ayé yìí. (1 Jòhánù 2:15-17) Ǹjẹ́ kó ni dára láti tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Mósè? Bíbélì sọ pé: “ó ń bá a lọ ní fífẹsẹ̀múlẹ̀ ṣinṣin bí ẹni tí ń rí Ẹni tí a kò lè rí.” (Hébérù 11:27) Ó gbé ọkàn rẹ̀ lé ogún tẹ̀mí tàwọn baba ńlá rẹ̀ tó bẹ̀rù Ọlọ́run fi lélẹ̀. Ó jẹ́ kí ìfẹ́ Jèhófà jẹ́ ohun tóun ń lépa nínú ìgbésí ayé òun, ṣíṣe ìfẹ́ Ọlọ́run ló sì wà lórí ẹ̀mí rẹ̀.—Ẹ́kísódù 2:11; Ìṣe 7:23, 25.

Nígbà táwọn ọ̀dọ́ tó bẹ̀rù Ọlọ́run bá bára wọn láyìíká tí kò bá ìfẹ́ Ọlọ́run mu tí kò sì bára dé, wọ́n lè mú kí àjọṣe àárín àwọn àti Jèhófà túbọ̀ lágbára sí i nípasẹ̀ ìdákẹ́kọ̀ọ́, kí wọ́n wá bí wọn ṣe máa túbọ̀ mọ “Ẹni tí a kò lè rí.” Ṣíṣètò fún gbogbo ìgbòkègbodò Kristẹni títí kan lílọ sípàdé àti òde ẹ̀rí déédéé yóò ran àwọn ọ̀dọ́ wọ̀nyí lọ́wọ́ láti gbájú mọ́ àwọn nǹkan tẹ̀mí. (Sáàmù 63:6; 77:12) Wọ́n gbọ́dọ̀ sapá láti ní ìgbàgbọ́ àti ìrètí tó lágbára bíi ti Mósè. Wọ́n ní láti gbé èrò àti ìṣe wọn karí ohun tí Jèhófà fẹ́, kínú wọn sì máa dùn láti jẹ́ ọ̀rẹ́ rẹ̀.

Ó Fi Ahọ́n Rẹ̀ Yin Ọlọ́run

Ọ̀dọ́ mìíràn tó tún jẹ́ àwòfiṣàpẹẹrẹ nígbà tó wà níbi to jìnnà sílé ni ọmọdébìnrin ará Ísírẹ́lì táwọn ará Síríà mú lẹ́rú nígbà ayé Èlíṣà, wòlíì Ọlọ́run. Ó di ìránṣẹ́ fún aya Náámánì adẹ́tẹ̀ tó jẹ́ olórí ogun Síríà. Ọmọdébìnrin yìí sọ fún ọ̀gá rẹ̀ pé: “Ká ní olúwa mi wà níwájú wòlíì tí ó wà ní Samáríà ni! Bí ọ̀ràn bá rí bẹ́ẹ̀, ì bá wò ó sàn nínú ẹ̀tẹ̀ rẹ̀.” Nítorí ẹ̀rí tó jẹ́ yìí, Náámánì forí lé ọ̀dọ̀ Èlíṣà ní Ísírẹ́lì, Èlíṣà sì wo ẹ̀tẹ̀ rẹ̀ sàn. Kò tán síbẹ̀ o, Náámánì tún di olùjọsìn Jèhófà.—2 Àwọn Ọba 5:1-3, 13-19.

Àpẹẹrẹ ọmọdébìnrin yìí jẹ́ ká túbọ̀ rídìí tó fi yẹ káwọn ọ̀dọ́ máa lo ahọ́n wọn lọ́nà tó ń bọlá fún Ọlọ́run, kódà nígbà tí wọ́n bá wà níbi tó jìnnà sáwọn òbí wọn. Tó bá jẹ́ pé “ọ̀rọ̀ òmùgọ̀” tàbí “ìṣẹ̀fẹ̀ rírùn” ló máa ń tẹnu ọmọdébìnrin yìí jáde tẹ́lẹ̀, ǹjẹ́ ì bá rọrùn fún un láti lo ahọ́n rẹ̀ lọ́nà tó gbéṣẹ́ bẹ́ẹ̀ nígbà tí àǹfààní rẹ̀ ṣí sílẹ̀? (Éfésù 5:4; Òwe 15:2) Níkos, ọ̀dọ́kùnrin kan tó ṣẹ̀ṣẹ̀ lé lọ́mọ ogún ọdún, tí wọ́n fi sẹ́wọ̀n nítorí pé kò dá sí tọ̀túntòsì gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni, sọ pé: “Nígbà tí mo wà pẹ̀lú àwọn arákùnrin mìíràn tá a jọ jẹ́ ọ̀dọ́ nínú ọgbà ẹ̀wọ̀n tí wọ́n ti ń kó wa ṣe iṣẹ́ àgbẹ̀, tá ò sí lábẹ́ àṣẹ àwọn òbí àti ti ìjọ mọ́, mo ṣàkíyèsí pé ọ̀rọ̀ tó ń ti ẹnu wa jáde kò dára bíi ti tẹ́lẹ̀ mọ́. Ó dájú pé kò fi ìyìn fún Jèhófà rárá.” Ó dùn mọ́ni nínú pé wọ́n ti ran Níkos àtàwọn tó kù lọ́wọ́ báyìí láti ṣègbọràn sí ìmọ̀ràn tí Pọ́ọ̀lù fúnni lórí ọ̀ràn yìí pé: “Kí a má tilẹ̀ mẹ́nu kan àgbèrè àti ìwà àìmọ́ onírúurú gbogbo tàbí ìwà ìwọra láàárín yín, gẹ́gẹ́ bí ó ti yẹ àwọn ènìyàn mímọ́.”—Éfésù 5:3.

Jèhófà Jẹ́ Ẹni Gidi Lójú Wọn

Ìrírí àwọn Hébérù mẹ́ta tó jẹ́ alábàákẹ́gbẹ́ Dáníẹ́lì ní ilẹ̀ Bábílónì ìgbàanì fi hàn pé òótọ́ pọ́ńbélé ni ohun tí Jésù sọ pé, jíjẹ́ olóòótọ́ nínú ohun kékeré yóò mú kéèyàn jẹ́ olóòótọ́ nínú àwọn ohun ńlá pẹ̀lú. (Lúùkù 16:10) Nígbà tí ọ̀ràn jíjẹ oúnjẹ tí Òfin Mósè kà léèwọ̀ délẹ̀, wọn lè bẹ̀rẹ̀ sí wí àwíjàre pé ìgbèkùn ni àwọn wà nílẹ̀ àjèjì, kò sì sí ohun táwọn lè ṣe nínú ọ̀ràn náà. Ẹ ò rí i bá a ṣe bù kún wọn tó nítorí pé wọn ò fọwọ́ yẹpẹrẹ mú ohun tó dà bí nǹkan kékeré yìí! Ara wọn le, wọ́n sì tún gbọ́n jù àwọn yòókù tó ń jẹ oúnjẹ adùnyùngbà ọba nígbèkùn tí wọ́n jọ wà. Ó dájú pé jíjẹ́ olóòótọ́ nínú ohun kékeré yìí ló fún wọn lókun, tí wọn ò fi juwọ́ sílẹ̀ nígbà tí wọ́n dojú kọ àdánwò tó lè ju ìyẹn lọ, ìyẹn àdánwò fíforí balẹ̀ fún ère òrìṣà.—Dáníẹ́lì 1:3-21; 3:1-30.

Jèhófà jẹ́ ẹni gidi gan-an lójú àwọn ọ̀dọ́kùnrin mẹ́ta wọ̀nyí. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ibi tí wọ́n wà jìnnà gan-an sí ìlú wọn àti sí ibi tí wọ́n ti ń jọ́sìn Ọlọ́run, síbẹ̀ wọ́n pinnu pé àwọn ò ní jẹ́ kí ayé kó àbààwọ́n bá àwọn. (2 Pétérù 3:14) Àjọṣe tí wọ́n ní pẹ̀lú Jèhófà ṣeyebíye lójú wọn débi pé wọ́n múra tán láti fi ẹ̀mí wọn lélẹ̀ nítorí àjọṣe náà.

Jèhófà Kò Ní Fi Yín Sílẹ̀

Nígbà táwọn ọ̀dọ́ bá wa níbi tó jìnnà sáwọn tí wọ́n fẹ́ràn tí wọ́n sì fọkàn tán, ó lè máa ṣe wọ́n bíi pé àwọn ò láàbò, wọ́n lè máà dá ara wọn lójú mọ́, kí ọkàn wọn má sì balẹ̀. Àmọ́, wọ́n lè kojú ìdánwò àti àdánwò wọn pẹ̀lú ìgbọ́kànlé kíkún pé ‘Jèhófà kì yóò ṣá àwọn tì.’ (Sáàmù 94:14) Bí irú àwọn ọ̀dọ́ bẹ́ẹ̀ bá “jìyà nítorí òdodo,” Jèhófà yóò ràn wọ́n lọ́wọ́ láti máa bá a lọ ní rírìn ní “ipa ọ̀nà òdodo.”—1 Pétérù 3:14; Òwe 8:20.

Jèhófà fún Jósẹ́fù, Mósè, ọmọdébìnrin Ísírẹ́lì tó jẹ́ ẹrú, àtàwọn olóòótọ́ ọ̀dọ́ Hébérù mẹ́ta nì lókun, ó sì bù kún wọn lọ́nà tó bùáyà. Ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀, Ọ̀rọ̀ rẹ̀, àti ètò àjọ rẹ̀ ló fi ń mẹ́sẹ̀ àwọn tó ń “ja ìjà àtàtà ti ìgbàgbọ́” dúró lóde òní, ó sì ń tipa bẹ́ẹ̀ gbé èrè “ìyè àìnípẹ̀kun” ka iwájú wọn. (1 Tímótì 6:11, 12) Bẹ́ẹ̀ ni o, ó ṣeé ṣe láti rìn ní ọ̀nà tó wu Jèhófà, ìyẹn sì jẹ́ ohun tó bọ́gbọ́n mu láti ṣe.—Òwe 23:15, 19.

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Wo Ilé Ìṣọ́ May 1, 1996, ojú ìwé 18 sí 20.

b A ti yí àwọn orúkọ kan padà.

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 25]

Ẹ̀YIN ÒBÍ—Ẹ MÚRA ÀWỌN ỌMỌ YÍN SÍLẸ̀!

“Bí àwọn ọfà ní ọwọ́ alágbára ńlá, bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọ ìgbà èwe rí.” (Sáàmù 127:4) Kò sí bí ọfà ṣe lè dé ibi tá a fẹ́ kó dé, láì jẹ́ pé a fara balẹ̀ ta á síbi tá a fojú sùn. Bákan náà, kò sí báwọn ọmọ ṣe lè múra láti kojú ohun tó máa ń ṣẹlẹ̀ nígbà tí wọ́n bá kúrò nílé láìjẹ́ pé àwọn òbí kọ́ wọn dáadáa tẹ́lẹ̀.—Òwe 22:6.

Àwọn èwe kì í ronú jinlẹ̀ kí wọ́n tó ṣe nǹkan, wọ́n sì máa ń tètè juwọ́ sílẹ̀ “fún àwọn ìfẹ́-ọkàn tí ó máa ń bá ìgbà èwe rìn.” (2 Tímótì 2:22) Bíbélì kìlọ̀ pé: “Ọ̀pá àti ìbáwí àfitọ́nisọ́nà ni ohun tí ń fúnni ní ọgbọ́n; ṣùgbọ́n ọmọdékùnrin tí a jọ̀wọ́ rẹ̀ sílẹ̀ fàlàlà yóò máa kó ìtìjú bá ìyá rẹ̀.” (Òwe 29:15) Kíkùnà láti ṣàkóso ìwà àwọn ọmọdé lè sọ ọmọ kan di ẹni tí kò múra sílẹ̀ láti kojú ẹ̀mí-ṣohun-tẹ́gbẹ́-ń-ṣe àtàwọn pákáǹleke tí gbígbé níbi tó jìnnà sílé máa ń fà.

Àwọn òbí Kristẹni gbọ́dọ̀ to àwọn ìṣòro, pákáǹleke, àti bí nǹkan ṣe rí gan-an nínú ètò nǹkan ìsinsìnyí lẹ́sẹẹsẹ fún àwọn ọmọ wọn lọ́nà tó ṣe kedere tó sì bọ́gbọ́n mu. Láìmú kí wọn sọ̀rètí nù tàbí kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá wọn, àwọn òbí lè ṣàpèjúwe àwọn ipò tí kò bára dé tí ọ̀dọ́ kan lè bá ara rẹ̀ tó bá ṣẹlẹ̀ pé ó lọ gbé níbi tó jìnnà sílé. Ìdálẹ́kọ̀ọ́ yìí, pa pọ̀ mọ́ ọgbọ́n tí Ọlọ́run fúnni yóò ‘fún àwọn aláìní ìrírí ní ìfọgbọ́nhùwà, yóò sì fún ọ̀dọ́kùnrin ní ìmọ̀ àti agbára láti ronú.’—Òwe 1:4.

Àwọn òbí tó ń gbin ẹ̀kọ́ Ọlọ́run àti àwọn ìlànà ìwà rere sọ́kàn àwọn ọmọ wọn yóò mú kó ṣeé ṣé fáwọn ọmọ náà láti borí àwọn ìṣòro ìgbésí ayé. Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tí ìdílé ń ṣe déédéé, jíjùmọ̀ sọ̀rọ̀ fàlàlà, àti ìfẹ́ jíjinlẹ̀ tàwọn òbí ní nínú ire àwọn ọmọ wọn, lè jẹ́ kí wọ́n ṣe àṣeyọrí. Àwọn òbí gbọ́dọ̀ fi ẹ̀kọ́ Ọlọ́run kọ́ àwọn ọmọ wọn bó ṣe tọ́ àti bó ṣe yẹ, kí wọ́n sì múra àwọn ọmọ náà sílẹ̀ kí wọ́n bàa lè máa dá ṣèpinnu fúnra wọn nígbà tí wọ́n bá dàgbà. Àwọn òbí lè fi àpẹẹrẹ tiwọn kọ́ àwọn ọmọ wọn pé ó ṣeé ṣe láti wà nínú ayé kéèyàn má sì jẹ́ apá kan rẹ̀.—Jòhánù 17:15, 16.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]

Ó ti di dandan fáwọn ọ̀dọ́ Kristẹni kan láti fi ilé wọn sílẹ̀

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]

Nípa dídènà ìdẹwò, àwọn ọ̀dọ́ lè fara wé Jósẹ́fù kí wọ́n sì jẹ́ oníwà rere

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]

Fara wé ọmọdébìnrin Ísírẹ́lì tó jẹ́ ẹrú, ẹni tó lo ahọ́n rẹ̀ láti fi ìyìn fún Jèhófà