Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìhìn Rere Náà Méso Jáde ní São Tomé àti Príncipe

Ìhìn Rere Náà Méso Jáde ní São Tomé àti Príncipe

Ìhìn Rere Náà Méso Jáde ní São Tomé àti Príncipe

Ó ṢEÉ ṢE kí ọ̀pọ̀ èèyàn máà tíì gbọ́ orúkọ náà São Tomé àti Príncipe rí. Orúkọ àwọn erékùṣù wọ̀nyí kò sí nínú ìwé pẹlẹbẹ táwọn èèyàn máa ń wo láti mọ ibi tí wọ́n ti fẹ́ lọ gbafẹ́. Lórí Máàpù àgbáyé, erékùṣù tí à ń sọ̀rọ̀ wọn yìí rí tó-tò-tó, wọ́n sì wà ní Ibi Tí Òkun Ti Ya Wọ Ilẹ̀ Guinea. Ó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ kan tí a bá dojú kọ etíkun ìwọ̀ oòrùn Áfíríkà. Ibi tí São Tomé wà fẹ́rẹ̀ẹ́ bọ́ sí agbedeméjì ayé nígbà tí Príncipe wà ní àríwá São Tomé ní apá ìlà oòrùn. Nítorí pé òjò máa ń rọ̀ gan-an tí ojú ọjọ́ sì máa ń ní ọ̀rinrin, ìyẹn ló mú kí igbó kìjikìji bo àwọn gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè ńlá tó wà níbẹ̀, àwọn òkè wọ̀nyẹn sì ga tó ẹgbẹ̀rún mẹ́fà àti ọgọ́rùn-ún mẹ́fà (6,600) ẹsẹ̀ bàtà.

Ní erékùṣù olóoru tí omi tó ń ṣẹ́ lẹ́lẹ́ àti ọ̀pẹ púpọ̀ wà ní etíkun rẹ̀ yìí, àwọn ènìyàn tó ń gbé ibẹ̀ jẹ́ ẹni bí ọ̀rẹ́, wọ́n sì jẹ́ ọlọ́yàyà. Nítorí pé díẹ̀ lára àwọn tó ń gbé ibẹ̀ wá láti Ilẹ̀ Áfíríkà tí díẹ̀ sì wá láti Yúróòpù, ìyẹn ló mú kí àṣà wọn wọnú ara wọn tó sì gbádùn mọ́ni. Fífi nǹkan ránṣẹ́ sókè òkun, òwò kòkó, iṣẹ́ àgbẹ̀ àti iṣẹ́ ẹja pípa ni àwọn èèyàn tó tó ẹgbàá márùnlélọ́gọ́rin (170,000) tó wà níbẹ̀ yàn láàyò. Lẹ́nu bí ọdún mélòó yìí wá, ipò nǹkan le débi pé kódà àtirí oúnjẹ òòjọ́ jẹ di ìjàngbọ̀n.

Àmọ́ ṣá o, ohun tó ṣẹlẹ̀ ní ẹ̀wádún tó gbẹ̀yìn ọ̀rúndún lọ́nà ogún yìí nípa lórí ìgbésí ayé àwọn èèyàn púpọ̀ láwọn erékùṣù wọ̀nyí. Ní June 1993, wọ́n fìdí iṣẹ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà múlẹ̀ lábẹ́ òfin ní São Tomé àti Príncipe, tó sì tipa bẹ́ẹ̀ fòpin sí ìṣòro táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti wà nínú rẹ fún ọjọ́ pípẹ́ sẹ́yìn ní àwọn erékùṣù yìí.

Wọ́n Fúnrúgbìn Náà Lákòókò Ìṣòro

Ní ìbẹ̀rẹ̀ àwọn ọdún 1950 ló jọ pé àwọn Ẹlẹ́rìí kọ́kọ́ wá sí àwọn erékùṣù wọ̀nyí, nígbà tá a rán àwọn ẹlẹ́wọ̀n wá láti àwọn ibi tó kù ní Áfíríkà tí àwọn Potogí ń ṣàkóso lé lórí. Wọ́n rán àwọn ẹlẹ́wọ̀n náà wá kí wọ́n lè ṣiṣẹ́ ní àgọ́ iṣẹ́ àṣekúdórógbó tó wà láwọn erékùṣù náà. Ọmọ ilẹ̀ Áfíríkà kan tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí, tó sì ń ṣe iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà tàbí òjíṣẹ́ alákòókò kíkún ni wọ́n fòfin lé kúrò ní Mòsáńbíìkì nítorí pé ó ń wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run ní ilẹ̀ náà. Ẹlẹ́rìí kan ṣoṣo yìí ló kọ́kọ́ ń wàásù lójú méjèèjì, ṣùgbọ́n láàárín oṣù mẹ́fà àwọn mẹ́tàlá mìíràn ti dara pọ̀ nínú títan ìhìn rere náà kálẹ̀. Nígbà tó yá, irú nǹkan tó ṣẹlẹ̀ yìí gbé àwọn Ẹlẹ́rìí mìíràn wá láti Àǹgólà. Nígbà tí wọ́n wà lẹ́wọ̀n, wọ́n ń lo gbogbo àǹfààní tó bá ti yọjú láti wàásù ìhìn rere náà fún àwọn tó ń gbé ní erékùṣù náà.

Nígbà to fi máa di ọdún 1966, gbogbo àwọn arákùnrin to wà ní àgọ́ iṣẹ́ àṣekúdórógbó ní São Tomé ti padà sí ilẹ̀ Áfíríkà. Àwùjọ àwọn akéde Ìjọba kéréje tí wọ́n fi sílẹ̀ ń fi ìgboyà báṣẹ́ lọ ní pẹrẹu. Wọ́n ṣe inúnibíni sí wọn, wọ́n lù wọ́n, wọ́n sì fi wọ́n sẹ́wọ̀n nítorí pé wọ́n ń pàdé pọ̀ láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, kò sì sí ẹni tí yòó bẹ̀ wọ́n wò láti fún wọ́n ní ìṣírí. Orílẹ̀-èdè yẹn gba òmìnira kúrò lábẹ Potogí ní ọdún 1975, ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀ irúgbìn Ìjọba náà bẹ̀rẹ̀ sí so èso.

Ìmúgbòòrò Àti Iṣẹ́ Ìkọ́lé

Ní oṣù ti a fìdí iṣẹ́ àwọn Ẹlẹ́rìí múlẹ̀ lábẹ́ òfin ní ọdún 1993, gbogbo akéde Ìjọba to wà nígbà yẹn jẹ́ ọgọ́rùn-ún. Ní ọdún kan náà yẹn ni àwọn aṣáájú ọ̀nà àkànṣe wá láti ilẹ̀ Potogí. Ìsapá wọn láti kọ́ èdè Potogí tí a mú rọrùn ló mú kí àwọn ará ìlú nífẹ̀ẹ́ wọn gan-an. Ní báyìí, ohun tó wà lórí ẹ̀mí wọn ni bí wọ́n ṣe máa rí ilẹ̀ tí wọ́n á fi kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba. Nígbà tí obìnrin kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Maria gbọ́, ó yọ̀ǹda ìdajì nínú ilẹ̀ tó kọ́ ilé rẹ̀ kékeré sí. Ilẹ̀ yìí lè gba Gbọ̀ngàn Ìjọba kan tó tóbi dáadáa. Maria ò mọ̀ pé ojú àwọn kọ́lékọ́lé tó ń kánjú àtilà ti wà lára ilẹ̀ yìí, ṣé kò kúkú ní mọ̀lẹ́bí kankan tó wà láàyè mọ́. Lọ́jọ́ kan, ọkùnrin oníṣòwò kan tó gbajúmọ̀ wá bá Maria sọ̀rọ̀.

Ó sọ fún un pé: “Ohun tí mo gbọ́ nípa ẹ ò dáa! Mó gbọ́ pe o ti fi ilẹ̀ rẹ ṣètọrẹ. Ṣé o kò mọ̀ pé owó gidi nì wàá rí tó o bá ta ilẹ̀ yìí nítorí pe àárín ìlú gan-an ló bọ́ sí?”

Maria béèrè pé: “Èló ni wàá san tí mo bá ta ilẹ̀ yẹn fún ọ?” Nígbà tọkùnrin ọ̀hún ò fèsì, Maria ń bá ọ̀rọ̀ rẹ lọ, ó ni: “Kódà ká sọ pé gbogbo owó ayé yìí lo fẹ́ fún mi, kò lè tó nítorí owó kò lè ra ìyè.”

Ọkùnrin náà béèrè pé: “O kò ní ọmọ, àbí o ní?”

Láti ké ìjíròrò náà kúrú, Maria sọ pe: “Jèhófà ló ni ilẹ̀ náà. Ńṣe ló yá mi lò fún ọ̀pọ̀ ọdún, báyìí mo sì ti dá a padà fún un. Mò ń wọ̀nà fún wíwà láàyè títí láé.” Ó wá bi ọkùnrin náà pé: “O ò lè fún mi ní ìyè àìnípẹ̀kun, àbó o lè fún mi?” Ọkùnrin náà kò sọ ohunkóhun mọ́ tó fi pẹ̀yìn da tó sì bá tiẹ̀ lọ.

Ní àbárèbábọ̀, àwọn arákùnrin tó jẹ́ akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ láti ilẹ̀ Potogí ṣèrànwọ́ láti kọ́ ilé alájà méjì tó fani mọ́ra gan-an sórí ilẹ̀ yẹn. Ilé náà ni àjà ilẹ̀, ó ní Gbọ̀ngàn Ìjọba kan to fẹ̀ dáadáa àti àwọn ibùgbé. Ó tún ní iyàrá ìkẹ́kọ̀ọ́ fún ilé ẹ̀kọ́ àwọn alàgbà, ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́, àtàwọn aṣáájú ọ̀nà. Ìjọ méjì ló ń ṣèpàdé níbẹ̀ báyìí, ó sì tipa bẹ́ẹ̀ di ibùdó ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ fún ìjọsìn tòótọ́ ní olú ìlú náà.

Ní Mé-Zochi, ìjọ kan wà níbẹ̀ tó ní ọgọ́ta akéde onítara. Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé ahéré kan tó wà nínú agbo ọ̀gẹ̀dẹ̀ ni wọ́n fi ṣe Gbọ̀ngàn Ìjọba tí wọ́n ti ń ṣèpàdé, ó hàn gbangba pé wọ́n nílò Gbọ̀ngàn Ìjọba kan tó bójú mu. Wọ́n sọ ohun tí wọ́n ń fẹ́ yìí fáwọn ará ìlú, àwọn aláṣẹ tó lẹ́mìí ìbánikẹ́dùn sì fún wọn ní ilẹ̀ dídára kan tó bọ́ sí ẹ̀bá ojú ọ̀nà. Láàárín oṣù méjì, àwọn arákùnrin láti ilẹ̀ Potogí lo ọ̀nà ìkọ́lé to yára kánkán láti kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba kan tó dùn ún wò. Ìyàlẹ́nu ńlá ló jẹ́ fún àwọn ará ìlú yẹn. Ẹnu ya onímọ̀ ẹ̀rọ ọmọ ilẹ̀ Sweden kan tí òun náà ń ṣe ìṣẹ́ ìkọ́lé ní ìlú yẹn nígbà tó rí i báwọn ará ṣe ń ṣiṣẹ́. Ó sọ pé: “Ohun ìyàlẹ́nu gbáà ló jẹ́ láti rí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni Mé-Zochi tó ń kọ́lé lọ́nà tó yára kánkán bí èyí! Ọ̀nà yìí ló yẹ kí àwa náà máa gbà ṣe iṣẹ́ ìkọ́lé.” Àwọn èèyàn igba àti méjìlélọ́gbọ̀n ló pésẹ̀ ní June 12, 1999, nígbà tá a ya Gbọ̀ngàn Ìjọba náà sí mímọ́. Gbọ̀ngàn Ìjọba náà wá di ìran àpéwò fún àwọn àjèjì to bá ti wá si ìlú Mé-Zochi.

Àpéjọ Mánigbàgbé Kan

Ìṣẹ̀lẹ̀ mánigbàgbé ni Àpèjọ Àgbègbè ọlọ́jọ́ mẹ́ta náà “Ẹ̀kọ́ Àtọ̀runwá” tí a ṣe ní January ọdún 1994 jẹ́ fún àwọn Ẹlẹ́rìí tó wà ní São Tomé àti Príncipe nítorí pé àkọ́kọ́ irú ẹ̀ nìyẹn ní àwọn erékùṣù náà. Inú gbọ̀ngàn tó dára jù lọ, tó sì ní ẹ̀rọ amúlétutù lá ti ṣé é ní orílẹ̀-èdè náà. Ǹjẹ́ o lè fojú inú wo bí ayọ̀ àwọn akéde Ìjọba tó jẹ́ mẹ́rìndínlọ́gọ́fà náà ṣe pọ tó nígbà tí wọ́n rí irinwó èrò àti márùn-ún fún ìgbà àkọ́kọ́ tí wọ́n ń wo àṣefihàn tí a gbé ka Bíbélì tí wọ́n sì ń gbà àwọn ìwé tuntun tó jáde? Etí òkun tó wà níbẹ̀ ni ogun èèyàn tó ti ya ara wọn si mímọ́ ti ṣèrìbọmi.

Ohun kan tó ṣàjèjì tó sì gbà àfiyèsí àwọn èèyàn ni káàdì àyà táwọn èèyàn tó wá sí àpéjọ náà lò. Àwọn àlejò mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n tó wá láti ilẹ̀ Potogí àti Àǹgólà mú kí àpéjọ náà dà bí àpéjọ àgbáyé. Kíá ni ìfẹ́ Kristẹni ti so àwọn ará pa pọ̀ dé bi pé ńṣe ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí da omi lójú nígbà tí ìpàdé parí tí wọ́n ń kí ara wọn pé ó dìgbà o.—Jòhánù 13:35.

Àwọn oníròyìn láti ilé iṣẹ́ Rédíò Ìjọba Àpapọ̀ wà níbẹ̀, wọ́n si fọ̀rọ̀ wá ọ̀rọ̀ wò lẹ́nu alábòójútó àpéjọ. Kódà wọ́n gbé púpọ̀ lára àwọn àwíyé àpéjọ náà sáfẹ́fẹ́. Ìṣẹ̀lẹ̀ mánigbàgbé ló jẹ́, ó sì tún mú kí àwọn Ẹlẹ́rìí olóòótọ́ wọ̀nyí tó ti wà ní àdádó fún ọjọ́ pípẹ́ wá túbọ̀ mọ ètò àjọ Jèhófà tó ṣeé fojú rí dáadáa.

Èso Ìjọba Náà Ń Fi Ìyìn fún Jèhófà

Nígbà tí ìhìn Ìjọba náà bẹ̀rẹ̀ sí í so èso, ó mú káwọn èèyàn máa hu ìwà to dára tó ń fi ìyìn àti ọlá fún Jèhófà. (Títù 2:10) Ọ̀dọ́bìnrin kan tí ò tíì pé ọmọ ogún ọdún ń gbádùn ẹ̀kọ́ Bíbélì tó ń kọ́ lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀. Bàbá rẹ̀ sọ pé kò gbọ́dọ̀ lọ si ìpàdé ìjọ mọ́. Nígbà tó fi tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ ṣàlàyé ìjẹ́pàtàkì ìpàdé Kristẹni tó sì sọ fún bàbá rẹ̀ pé òun ṣì fẹ́ máa lọ síbẹ̀, ni bàbá yẹn bá lé e jáde kúrò nílé. Ó dájú pé ohun tí bàbá yẹn rò ni pé kí ọmọbìnrin náà ṣe bí àwọn ọ̀dọ́bìnrin yòókù ṣe máa ń ṣe, kó sá lọ bá ọkùnrin kan tí yóò máa tọ́jú rẹ̀. Nígbà tí bàbá rẹ̀ gbọ́ pé ìgbésí ayé tó mọ́, téèyàn sì lé fi ṣe àwòkọ́ṣe ló ń gbé gẹ́gẹ́ bí Kristẹni, ìyẹn ló wú u lórí tó fi gbà á padà sílé tó sì fún lómìnira pátápátá láti sin Jèhófà.

Àpẹẹrẹ mìíràn ni ti ọ̀gá olórin kan. Gbogbo nǹkan tojú sú u nítorí ìgbésí ayé játijàti tó ń gbé. Ó wá pàdé àwọn Ẹlẹ́rìí nígbà tó ń wá bí ìgbésí ayé rẹ̀ ṣe máa lójú. Gbogbo èèyàn ló ǹ sọ̀rọ̀ rẹ̀ nígbà tó bẹ̀rẹ̀ sí gbé ìgbésí ayé rẹ̀ ní ìbámu pẹ̀lú ìlànà ìwà rere tó wà nínú Bíbélì. Kò pẹ́ tó fi rí ìdí tó fi yẹ kí òun jáwọ́ nínú àwọn ẹgbẹ́ burúkú. (1 Kọ́ríńtì 15:33) Lẹ́yìn náà, ó ṣèrìbọmi tó fi hàn pé ó ti ya ara rẹ̀ sí mímọ́ fún Jèhófà.

Ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀dọ́ ló ń wá ìsìn tòótọ́. Ìwádìí wọn ti jẹ́ kí wọ́n bá ọ̀pọ̀ àlùfáà jíròrò, ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ náà kò yé wọn, gbogbo nǹkan sì tojú sú wọn. Ìyẹn ló wá jẹ́ kí wọ́n ya alárìnkiri àti pẹ̀gànpẹ̀gàn tó gboró gan-an lórí ọ̀ràn ẹ̀sìn.

Lọ́jọ́ kan, míṣọ́nnárì kan to jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà gba ibi táwọn ọ̀dọ́ wọ̀nyí wà kọjá nígbà tó fẹ́ lọ darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kan. Àwọn ọ̀dọ́ náà fẹ́ kí míṣọ́nnárì yìí dáhùn àwọn ìbéèrè kan, ni wọ́n bá mú un lọ sí ẹ̀yìnkùlé tí wọ́n sì gbé ìjókòó fún un. Bí wọ́n ṣe bẹ̀rẹ̀ sí da ìbéèrè bò ó lọ́tùn-ún lósì nìyẹn, wọ́n béèrè nípa ọkàn, ọ̀run àpáàdì, ìwàláàyè ní ọ̀run àti òpin ayé. Bíbélì tí olórí àwọn ọ̀dọ́ náà fún Ẹlẹ́rìí yìí ló fi dáhùn gbogbo ìbéèrè wọn. Wákàtí kan lẹ́yìn náà, olórí àwọn ọ̀dọ̀ náà tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Law sọ fun míṣọ́nnárì náà pé: “Nígbà tá a sọ pé kó o wá dáhùn àwọn ìbéèrè, a wulẹ̀ fẹ́ fi ọ ṣe yẹ̀yẹ́ ni, bá a ti ṣe sí àwọn ẹlẹ́sìn tó kù. A ti rò pé kò sẹ́nì tó lè dáhùn àwọn ìbéèrè wọ̀nyẹn. Ṣùgbọ́n o ti dáhùn wọn, Bíbélì lo sì fi dáhùn wọn! Sọ fún mi, báwo ni mo ṣe lè túbọ̀ mọ̀ nípa Bíbélì?” Bí Law ṣe bẹ̀rẹ̀ sí kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nìyẹn, kò sì pẹ́ tó fí ń wá sípàdé. Kò pẹ́ lẹ́yìn náà tó fi pa ẹgbẹ́ náà ti, tó sì fi ìgbésí ayé ẹhànnà sílẹ̀. Láàárín ọdún kan, ó ya ìgbésí ayé rẹ̀ sí mímọ́ fún Jèhófà, ó sì ṣèrìbọmi. Ó ti ń sìn gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ báyìí.

Àṣà kan tó gbilẹ̀ ládùúgbò yìí ni kí ọkùnrin àti obìnrin máa gbé pọ̀ láì ṣègbéyàwó lábẹ́ òfin. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ló tí ń gbé pọ̀ bẹ́ẹ̀ fún ọ̀pọ̀ ọdún tí wọ́n si ti bímọ. Kò rọrùn fún wọn láti gba ohun ti Ọlọ́run sọ lórí ọ̀ràn náà. Inú wa dùn láti rí bí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣe ran ẹni kan lọ́wọ́ láti borí ìṣòro yìí.—2 Kọ́ríńtì 10:4-6; Hébérù 4:12.

Antonio mọ̀ pé ó yẹ ki òun fìdí ìgbéyàwó òun múlẹ̀ lábẹ́ òfin ó sì pinnu láti ṣe bẹ́ẹ̀ tó bá ti kórè àgbàdo rẹ̀ kó lè rí owó ṣayẹyẹ ìgbéyàwó. Ó ku ọ̀la tó máa lọ kórè làwọn olè lọ jí àgbàdo rẹ kó. Ó pinnu láti dúró de ìkórè ti ọdún to tẹ̀ lé e, ó kù díẹ̀ kó tún lọ kórè làwọn olè tún lọ jí àgbàdo rẹ kó. Bó ṣe tún ṣẹlẹ̀ nìyẹn nígbà kẹta, ìgbà yẹn ni Antonio wá mọ̀ ọ̀tá rẹ̀ gan-an, ó ní: “Mì ò ní jẹ́ kí Sátánì tàn mí jẹ mọ́, ní oṣù kan ààbọ̀ sí ìgbà tá a wà yìí, bóyá a ṣayẹyẹ tàbí à kò ṣayẹyẹ, á gbọ́dọ̀ ṣègbéyàwó lábẹ́ òfin!” Bí wọ́n ṣe ṣègbéyàwó lábẹ́ òfin nìyẹn, ó sì yà wọ́n lẹ́nu gan-an lọ́jọ́ yẹn pé àwọn ọ̀rẹ́ wọn fún wọn ní adìyẹ, pẹ́pẹ́yẹ àti ewúrẹ́ láti fi ṣayẹyẹ. Lẹ́yìn tí wọ́n ti fìdí ìgbéyàwó wọn múlẹ̀ lábẹ́ òfin, Antonio àti ìyàwó rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ọmọ wọn mẹ́fà ṣèrìbọmi gẹ́gẹ́ bí ẹ̀rí ìyàsímímọ́ wọn sí Jèhófà.

Ọ̀rọ̀ Kan Erékùṣù Príncipe Wàyí

Láwọn ọdún àìpẹ́ yìí, alábòójútó àyíká àti àwọn aṣáájú ọ̀nà láti São Tomé ti ṣèbẹ̀wò si àwọn ẹgbẹ̀ta èèyàn tó ń gbé Príncipe. Àwọn tó ń gbé ní erékùṣù náà jẹ́ olùfẹ́ àlejò wọ́n sì ń hára gàgà láti gbọ́ ohun tí àwọn Ẹlẹ́rìí fẹ́ sọ. Lẹ́yìn tí ọkùnrin kan ka ìwé ìléwọ́ tí wọ́n fún un tán, ńṣe ló ń wá àwọn aṣáájú ọ̀nà náà kiri lọ́jọ́ kejì, ó fẹ bá wọn pín ìwé ìléwọ́ náà. Àwọn aṣáájú ọ̀nà náà sọ fún un pé kì í ṣe ìṣẹ́ tó lè báwọn ṣe ni, ṣùgbọ́n ó rin kinkin mọ́ ọn pé òun á máa tẹ̀lé wọ́n láti ẹnu ọ̀nà kan sí èkejì kí òun lè máa sọ fún àwọn onílé pé kí wọ́n fetí sí ọ̀rọ̀ wọn dáadáa. Níkẹyìn, ọkùnrin náà yìn wọn fún iṣẹ́ pàtàkì tí wọ́n ń ṣe, ó si kúrò lọ́dọ̀ wọn.

Ní 1998, àwọn aṣáájú ọ̀nà méjì kan ṣí wá sí Príncipe láti São Tomé, kò sì pẹ́ tí wọ́n fi ń darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì mẹ́tàdínlógún. Ìṣẹ́ wọn tẹ̀ síwájú nítorí kò pẹ́ tí iye àwọn tó ń wá sí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ fi di mẹ́rìndínlógún ní ìpíndọ́gba tí àwọn tó ń gbọ́ àwíyé sì lé ní ọgbọ̀n. Wọ́n nílò ibí tí wọ́n á ti máa ṣe ìpàdé báyìí, wọ́n sì fi to àwọn ará ìlú létí, a dúpẹ́ pé wọ́n fún wọn ni ilẹ̀ láti fi kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba. Àwọn Arákùnrin láti São Tomé yọ̀ǹda láti kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba kékeré kan tó ní ilé gbígbé fún àwọn aṣáájú ọ̀nà àkànṣe méjì.

Láì sí tàbí ṣùgbọ́n, ìhìn rere ń méso jáde ó sì ń tẹ̀ síwájú ní àwọn erékùṣù jíjìnnà wọ̀nyí. (Kólósè 1:5, 6) Ní January 1990, akéde mẹ́rìndínlọ́gọ́ta ló wà ní São Tomé àti Príncipe. Ṣùgbọ́n ní ọdún iṣẹ́ ìsìn 2002, àwọn olùpòkìkí Ìjọba irinwó ó dín méjìlá (388) ló wà níbẹ̀, èyí sì jẹ́ iye tó tíì pọ̀ ju ti ìgbàkígbà rí lọ! Iye tí ó ju ìdá ogún nínú ọgọ́rùn-ún àwọn akéde ibẹ̀ ló wà nínú iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún, tí wọ́n sì ń darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó egbèje. (1,400) Iye àwọn tó jẹ́ ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀wá ó lé méje (1,907) tó wá sí Ìṣe Ìrántí ni ọdún 2001 ló tíì pọ ju ti ìgbàkígbà rí lọ. Bẹ́ẹ̀ ni o, ní àwọn erékùṣù olóoru wọ̀nyí, ọ̀rọ̀ Jèhófà ń tẹ̀ síwájú, a sì ń ṣe é lógo gan-an ni.—2 Tẹsalóníkà 3:1.

[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 12]

Ètò Orí Rédíò Kan Tí Gbogbo Èèyàn Mọ̀

Ìtẹ̀jáde kan táwọn èèyàn gbádùn gàn-an ní àwọn erékùṣù wọ̀nyí ni ìwé náà Awọn Ìbéèrè Tí Awọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè Awọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́. a Ní ọ̀sẹ̀ méjìméjì, ni wọ́n máa ń fi àkòrí ìwé yìí ṣe ètò oníṣẹ̀ẹ́jú mẹ́ẹ̀ẹ́dógún lórí Rédíò Ìjọba Àpapọ̀. Ẹ wò bó ti máa ń dùn mọ́ni tó láti gbọ́ bí ẹni tó ń darí ètò náà ṣe ń béèrè pé: “Ẹ̀yin ọ̀dọ́, báwo lẹ ṣe lè mọ̀ bóyá ìfẹ́ tòótọ́ ni tàbí ìfẹ́ aláìnírònú?” tí yóò sì wá ka àpá kan nínú ìwé náà lẹ́yìn tí tó béèrè ìbéèrè náà! (Wo orí 31.) Irú ètò kan náà ń gbé àwọn apá kan jáde nínú ìwé Àṣírí Ayọ̀ Ìdílé. b

[Àwọn àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ló ṣe é.

b Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ló ṣe é.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]

Ní 1994, Gbọ̀ngàn Ìjọba àkọ́kọ́ nìyí ní São Tomé

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]

1. Gbọ̀ngàn Ìjọba tí a yara kọ́ ní Mé-Zochi

2. Inú gbọ̀ngàn yìí ni à ti ṣe àpéjọ àgbègbè mánigbàgbé kan

3. Àwọn èèyàn aláyọ̀ tó fẹ́ ṣèrìbọmi ní àpéjọ náà

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 8]

Àwòrán Òbìrí Ayé: Mountain High Maps® Copyright © 1997 Digital Wisdom, Inc.