Ẹ Fi Ìkóra-ẹni-níjàánu Kún Ìmọ̀ Yín
Ẹ Fi Ìkóra-ẹni-níjàánu Kún Ìmọ̀ Yín
“Ẹ pèsè . . . ìkóra-ẹni-níjàánu kún ìmọ̀ yín.” —2 PÉTÉRÙ 1:5-8.
1. Kí ni ohun táwọn èèyàn kì í lè sọ, tíyẹn sì wá fà ọ̀pọ̀ jù lọ ìṣòro ẹ̀dá èèyàn?
NÍGBÀ tí wọ́n ṣe ìpolongo kan tó fa kíki láti gbógun ti lílo oògùn olóró, wọ́n rọ àwọn ọ̀dọ́ tó wà ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà pé: “Ṣáà sọ pé rárá, mi ò fẹ́.” Ẹ wo bí nǹkan ì bá ṣe dára tó ká ní gbogbo èèyàn lè máa sọ pé rárá, mi ò fẹ́ oògùn olóró, kí wọ́n tún máa sọ bẹ́ẹ̀ sí ọtí àmupara, sí ọ̀nà ìgbésí ayé tó jẹ́ ti oníṣekúṣe, sí àìṣòótọ́ nídìí ìṣòwò, kí wọ́n sì tún máa sọ bẹ́ẹ̀ sí ‘àwọn ìfẹ́ ti ara’! (Róòmù 13:14) Síbẹ̀, ta ni ò mọ̀ pé kì í sábà rọrùn láti sọ pé rárá nígbà tí wọ́n bá fi ohun tí ò dáa lọni?
2. (a) Àwọn àpẹẹrẹ inú Bíbélì wo ló fi hàn pé bó ṣe ṣòro láti sọ pé rárá, mi ò ṣe ohun tí ò dáa, kì í ṣe tuntun? (b) Kí ló yẹ káwọn àpẹẹrẹ wọ̀nyí sún wa láti ṣe?
2 Níwọ̀n bó ti ṣòro fún gbogbo ẹ̀dá aláìpé láti kó ara wọn níjàánu, ó yẹ kó wù wá láti kọ́ bá a ṣe lè borí àwọn kùdìẹ̀-kudiẹ èyíkéyìí tá a ní. Bíbélì sọ nípa àwọn èèyàn kan tó sapá láti sin Ọlọ́run láyé ọjọ́hun àmọ́ tó jẹ́ pé ẹ̀ẹ̀kọ̀ọ̀kan wà tó ṣòro fún wọn láti sọ pé rárá, mi ò ṣe ohun tí ò dáa. Rántí Dáfídì àti ẹ̀ṣẹ̀ panṣágà tó dá pẹ̀lú Bátí-ṣébà. Ó yọrí sí ikú ọmọ tí wọ́n fi panṣágà náà lóyún rẹ̀ àti ikú ọkọ Bátí-ṣébà pàápàá, bẹ́ẹ̀ àwọn méjèèjì tó kú yìí ò mọwọ́mẹsẹ̀ nínú ọ̀ràn náà. (2 Sámúẹ́lì 11:1-27; 12:15-18) Tún ronú nípa àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù, tó jẹ́wọ́ gbangba pé: “Nítorí rere tí mo fẹ́ ni èmi kò ṣe, ṣùgbọ́n búburú tí èmi kò fẹ́ ni èmi fi ń ṣe ìwà hù.” (Róòmù 7:19) Ṣé nǹkan máa ń tojú sú ìwọ náà bẹ́ẹ̀ lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan? Pọ́ọ̀lù tún sọ pé: “Ní ti gidi, mo ní inú dídùn sí òfin Ọlọ́run ní ìbámu pẹ̀lú ẹni tí mo jẹ́ ní inú, ṣùgbọ́n mo rí òfin mìíràn nínú àwọn ẹ̀yà ara mi tí ń bá òfin èrò inú mi jagun, tí ó sì ń mú mi lọ ní òǹdè fún òfin ẹ̀ṣẹ̀ tí ó wà nínú àwọn ẹ̀yà ara mi. Èmi abòṣì ènìyàn! Ta ni yóò gbà mí lọ́wọ́ ara tí ń kú ikú yìí?” (Róòmù 7:22-24) Ó yẹ káwọn àpẹẹrẹ inú Bíbélì túbọ̀ fún ìpinnu tá a ṣe lókun pé a ò ní juwọ́ sílẹ̀ nínú ba a ṣe ń sapá láti túbọ̀ máa kó ara wa níjàánu.
Ìkóra-Ẹni-Níjàánu Jẹ́ Ohun Tá A Gbọ́dọ̀ Kọ́
3. Ṣàlàyé ìdí tá ò fi lè retí pé yóò rọrùn láti lo ìkóra-ẹni-níjàánu.
3 Ìkóra-ẹni-níjàánu tó ní í ṣe pẹ̀lú kéèyàn lè sọ pé rárá, mi ò ṣe ohun tí ò dáa, la mẹ́nu kan nínú 2 Pétérù 1:5-7, pa pọ̀ pẹ̀lú ìgbàgbọ́, ìwà funfun, ìmọ̀, ìfaradà, ìfọkànsin Ọlọ́run, ìfẹ́ni ará, àti ìfẹ́. Kò sí èyí tá a bí mọ́ wa nínú àwọn ànímọ́ rere yòókù wọ̀nyí. Ohun tá a gbọ́dọ̀ kọ́ ni wọ́n. Ó si gba ìmúratán àti ìsapá ká tó lè lò wọ́n dé àyè kan. Ṣé ó wá yẹ ká retí pé yóò rọrùn láti lo ìkóra-ẹni-níjàánu?
4. Kí nìdí tí ọ̀pọ̀ èèyàn fi rò pé ìkóra-ẹni-níjàánu kì í ṣe ìṣòro tàwọn, àmọ́ kì ni èyí jẹ́ ẹ̀rí sí?
4 Lóòótọ́, ọ̀pọ̀ èèyàn lè ronú pé lílo ìkóra-ẹni-níjàánu kì í ṣe ìṣòro fáwọn rárá. Bó ṣe wù wọ́n ni wọ́n ń lo ìgbésí ayé wọn, yálà wọ́n mọ̀ọ́mọ̀ tàbí wọn ò mọ̀ọ́mọ̀, ohun tí àìpé ara wọ́n fẹ́ ni wọ́n ń ṣe láìronú lórí ipa tí èyí ń ní lórí àwọn fúnra wọn tàbí lórí àwọn ẹlòmíràn. (Júúdà 10) Àkókò tá a wà yìí gan-an ló túbọ̀ hàn gbangba ju ti ìgbàkigbà rí lọ pé àwọn èèyàn ó nígboyà láti sọ pé rárá, mi ò ṣe ohun tí ò dáa, wọn ò sì fẹ́ sọ bẹ́ẹ̀. Èyí jẹ́ ẹ̀rí pé lóòótọ́ là ń gbé ní “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” tí Pọ́ọ̀lù sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ nígbà tó sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé: “Àwọn àkókò lílekoko tí ó nira láti bá lò yóò wà níhìn-ín. Nítorí àwọn ènìyàn yóò jẹ́ olùfẹ́ ara wọn, olùfẹ́ owó, ajọra-ẹni-lójú, onírera, asọ̀rọ̀ òdì, . . . aláìní ìkóra-ẹni-níjàánu.”—2 Tímótì 3:1-3.
5. Kí nìdí táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi nífẹ̀ẹ́ sí ọ̀rọ̀ nípa ìkóra-ẹni-níjàánu, kí sì ni ìmọ̀ràn tó ṣì wúlò lọ́jọ́ òní?
5 Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà mọ̀ pé kíkó ara ẹni níjàánu gba ìsapá gidigidi. Bíi ti Pọ́ọ̀lù, àwọn náà mọ̀ pé ìṣòro wà nínú kó máa wu èèyàn láti múnú Ọlọ́run dùn nípa gbígbé níbàámu pẹ̀lú àwọn ìlànà rẹ̀ àti kí àìpé ara máa rọ̀ èèyàn láti tọ̀ ipa ọ̀nà tó burú. Nítorí ìdí èyí, ó ti pẹ́ gan-an tó ti wù wọ́n láti borí ìjàkadì yìí. Nígbà yẹn lọ́hùn-ún, ní ọdún 1916, ọ̀kan lára àwọn ẹ̀dà tó kọ́kọ́ jáde nínú ìwé ìròyìn tó ò ń kà lọ́wọ́ yìí sọ nípa “ohun tó dára jù lọ fún wa láti ṣe ká tó lè darí ara wa, èrò inú wa, àwọn ọ̀rọ̀ ẹnu wa àti ìṣe wa.” Ó dá a lábàá pé ká máa fi ìwé Fílípì 4:8 sọ́kàn. Àwọn ìmọ̀ràn tí Ọlọ́rùn fúnni nínú ẹsẹ Bíbélì yẹn ṣì wúlò fún wa lọ́jọ́ òní, bó tilẹ̀ jẹ́ pé nǹkan bí ẹgbàá ọdún sẹ́yìn ni wọ́n kọ ọ́. Ó sì ṣeé ṣe kó ṣòro gan-an láti tẹ̀ lé e lákòókò tá a wà yìí ju ti ìgbà tí wọ́n kọ ọ́ tàbí ìgbà tí wọ́n sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ lọ́dún 1916 yẹn. Bó ti wù kó rí, àwọn Kristẹni ń sapá láti sọ pé rárá, àwọn ò ní ṣe ohun táyé ń fẹ́, wọ́n mọ̀ pé táwọn bá sọ bẹ́ẹ̀, ohun tí wọ́n ń wí ni pé bẹ́ẹ̀ ni, ti Ẹlẹ́dàá àwọn làwọn máa ṣe.
6. Kí nìdí tí kò fi yẹ ká sọ̀rètí nù bá a ṣe ń sapá láti ní ìkóra-ẹni-níjàánu?
6 A mẹ́nu kan ìkóra-ẹni-níjàánu nínú Gálátíà 5:22, 23 gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan lára àwọn “èso ti ẹ̀mí [mímọ́].” Tá a bá ní ànímọ́ yìí pa pọ̀ pẹ̀lú “ìfẹ́, ìdùnnú, àlàáfíà, ìpamọ́ra, inú rere, ìwà rere, ìgbàgbọ́, [àti] ìwà tútù,” a ó jàǹfààní tó pọ̀. Gẹ́gẹ́ bí Pétérù ṣe ṣàlàyé, ṣíṣe bẹ́ẹ̀ kò ní jẹ́ ká di “aláìṣiṣẹ́ tàbí aláìléso” nínú iṣẹ́ ìsìn wa sí Ọlọ́run. (2 Pétérù 1:8) Àmọ́, a ò gbọ́dọ̀ sọ̀rètí nù tàbí ká máa rò pé a ò lè ṣe ohun tó dáa mọ́, tó bá ṣẹlẹ̀ pé a ò tètè fi àwọn ànímọ̀ wọ̀nyí hàn tó bó ṣe wù wá láti fi hàn. Ó ṣeé ṣe kó o ti ṣàkíyèsí pé àwọn ọmọ kan tètè máa ń lóye nǹkan ju àwọn ọmọ mìíràn lọ nílé ẹ̀kọ́. Kódà lẹ́nu iṣẹ́ pàápàá, àwọn kan tètè máa ń lóye iṣẹ́ tuntun tó bá dé jù bí àwọn òṣìṣẹ́ mìíràn ṣe ń lóye rẹ̀ lọ. Bákan náà làwọn kan tètè máa ń kọ́ àwọn ànímọ́ Kristẹni tí wọ́n sì tètè máa ń fi wọ́n sílò jù ti àwọn ẹlòmíràn lọ. Ohun tó ṣe pàtàkì níbẹ̀ ni pé ká máa ṣiṣẹ́ lórí àwọn ànímọ́ wọ̀nyí débi tí agbára wa bá gbé e dé. A lè ṣe èyí nípa fífi tọkàntọkàn tẹ́wọ́ gba ìrànlọ́wọ́ tí Jèhófà ń pèsè nípasẹ̀ Ọ̀rọ̀ rẹ̀ àti ìjọ rẹ̀. Yíyára mú àwọn ànímọ́ yìí dàgbà kò ṣe pàtàkì tó kéèyàn múra tán láti máa tẹ̀ síwájú nínú fífi wọ́n ṣèwà hù.
7. Kí ló fi hàn pé ìkóra-ẹni-níjàánu ṣe pàtàkì?
7 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìkóra-ẹni-níjàánu la mẹ́nu kan gbẹ̀yìn nínú àwọn ànímọ́ tí ẹ̀mí ń mú jáde, síbẹ̀ kò túmọ̀ sí pé kò ṣe pàtàkì tó àwọn yòókù. Dípò tá a ó fi ronú bẹ́ẹ̀. Ń ṣe ló yẹ ká ní in lọ́kàn pé gbogbo “àwọn iṣẹ́ ti ara” la lè yàgò fún tá a bá ní ìkóra-ẹni-níjàánu ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́. Àmọ́, ọkàn ẹ̀dá ènìyàn aláìpé máa ń fà sí àwọn kan lára “iṣẹ́ ti ara . . . , [bí] àgbèrè, ìwà àìmọ́, ìwà àìníjàánu, ìbọ̀rìṣà, bíbá ẹ̀mí lò, ìṣọ̀tá, gbọ́nmi-si omi-ò-to, owú, ìrufùfù ìbínú, asọ̀, ìpínyà, ẹ̀ya ìsìn.” (Gálátíà 5:19, 20) Nítorí náà, a gbọ́dọ̀ máa fi gbogbo ìgbà ja ìjàkadì, ká pinnu láti fa gbogbo èrò òdì tu kúrò nínú ọkàn àti èrò inú wa.
Ó Ṣòro Gan-An Fáwọn Kan Láti Kó Ara Wọn Níjàánu
8. Kí làwọn ohun tó fà á tó fi ṣòro fáwọn kan láti kó ara wọn níjàánu?
8 Ó ṣòro gan-an fáwọn Kristẹni kan láti kó ara wọn níjàánu ju bó ṣe ṣòro fáwọn ẹlòmíràn lọ. Kí nìdí? Ó lè jẹ́ nítorí ọ̀nà táwọn òbí wọn gbà tọ́ wọn tàbí nítorí irú ìgbésí ayé tí wọ́n gbé sẹ́yìn. Bí níní ìkóra-ẹni-níjàánu àti lílò ó kò bá tíì dà bí ìṣòro fún wa, ńṣe ló yẹ ká máa yọ̀. Ṣùgbọ́n a gbọ́dọ̀ máa lo ìyọ́nú àti òye nígbà tí nǹkan bá da wá pọ̀ pẹ̀lú àwọn tí kò rọrùn fún láti lo ànímọ́ yìí, kódà bí àìní ìkóra-ẹni-níjàánu wọn tiẹ̀ fẹ́ mú kí nǹkan ṣòro fún wa. Níwọ̀n bí a ti jẹ́ aláìpé, èwo nínú wa ló yẹ kó jẹ́ olódodo lójú ara rẹ̀?—Róòmù 3:23; Éfésù 4:2.
9. Àwọn ìkùdíẹ̀-káàtó wo làwọn kan ní, ìgbà wo sì ni wọ́n máa ṣẹ́pá àwọn ìkùdíẹ̀-káàtó náà pátápátá?
9 Bí àpẹẹrẹ, a lè mọ̀ pé ọkàn àwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ wa kan tí wọ́n ò mu tábà mọ́ tàbí tí wọ́n ò fi oògùn líle “ṣe fàájì” mọ́ ṣì lè máa fà sí irú àṣà bẹ́ẹ̀ lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan. Kódà àwọn kan rí i pé ó ṣòro fáwọn láti dín oúnjẹ àjẹjù àti ọtí àmujù kù. Ìṣòro tàwọn ẹlòmíràn ni bí wọ́n ṣe máa ṣàkóso ọ̀rọ̀ ẹnu wọn, ìyẹn ló ń mú kí wọ́n sọ ohun tí kò yẹ kí wọ́n sọ lọ́pọ̀ ìgbà. Bíborí irú àwọn kùdìẹ̀-kudiẹ wọ̀nyẹn gba kéèyàn sa gbogbo ipá rẹ̀ láti ní ìkóra-ẹni-níjàánu. Kí nìdí? Ìwé Jákọ́bù 3:2 sọ ọ́ ní kedere pé: “Gbogbo wa ni a máa ń kọsẹ̀ lọ́pọ̀ ìgbà. Bí ẹnì kan kò bá kọsẹ̀ nínú ọ̀rọ̀, ẹni yìí jẹ́ ènìyàn pípé, tí ó lè kó gbogbo ara rẹ̀ pẹ̀lú níjàánu.” Àwọn kan tún wà tó máa ń ṣe wọ́n bíi pé kí wọ́n lọ ta tẹ́tẹ́. Kódà ó ṣòro fáwọn kan láti ṣíwọ́ bíbínú sódì. Ó lè gba àkókò kéèyàn tó mọ bóun ṣe máa bọ́ lọ́wọ́ àwọn ìkùdíẹ̀-káàtó wọ̀nyí àtàwọn mìíràn tó fara pẹ́ ẹ. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé a lè ṣe àtúnṣe dé àyè kan nísinsìnyí, síbẹ̀ ìgbà tá a bá dé ìjẹ́pípé nìkan ni àwọn ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ yóò kásẹ̀ nílẹ̀ pátápátá. Ní báyìí ná, sísapá láti kóra wa níjàánu yóò ràn wá lọ́wọ́ láti yẹra fún pípadà sínú gbígbé ìgbésí ayé ẹ̀ṣẹ̀. Bá a ṣe ń sapá láti kó ara wa níjàánu, ẹ jẹ́ ká máa ran ara wa lọ́wọ́ kí a má bàa juwọ́ sílẹ̀.—Ìṣe 14:21, 22.
10. (a) Kí nìdí tó fi ṣòro gan-an fáwọn kan láti kó ara wọn níjàánu nínú ọ̀ràn ìbálòpọ̀? (b) Ìyípadà tó gbàfiyèsí wo ni arákùnrin kan ṣe? (Wo àpótí tó wà lójú ìwé 16.)
10 Ibòmíràn tó tún ti ṣòro fáwọn kan láti kó ara wọn níjàánu ni ọ̀ràn ìbálòpọ̀ takọtabo. Ká sòótọ́, ìbálòpọ̀ takọtabo jẹ́ ara ohun tí Jèhófà Ọlọ́run dá mọ́ wa. Àmọ́ ìṣòro àwọn kan ni pé wọn ò mọ bí wọ́n ṣe máa fi ìbálòpọ̀ sípò tó yẹ kó wà, lọ́nà tó bá ìlànà Ọlọ́run mu. Ìṣòro wọn lè légbá kan nítorí pé òòfà ìbálòpọ̀ wọn jẹ́ èyí tó ń gbóná sódì. Inú ayé tí ìbálòpọ̀ takọtabo ń sin níwín là ń gbé, èyí sì máa ń jẹ́ kí ìbálòpọ̀ mú ara àwọn èèyàn túbọ̀ gbóná sódì. Èyí lè fa ìṣòro díẹ̀ fáwọn Kristẹni tó fẹ́ wà lápọ̀n-ọ́n fúngbà díẹ̀, kí wọ́n lè ráyè sin Ọlọ́run láìsí ìpínyà ọkàn tí ìgbéyàwó máa ń fà. (1 Kọ́ríńtì 7:32, 33, 37, 38) Àmọ́ wọ́n lè pinnu láti ṣègbéyàwó ní ìbámu pẹ̀lú ohun tó wà nínú Ìwé Mímọ́ pé “ó sàn láti gbéyàwó ju kí ìfẹ́ onígbòónára máa mú ara ẹni gbiná,” irú ìgbéyàwó bẹ́ẹ̀ á sì jẹ́ èyí tó lọ́lá. Lákòókò kan náà, wọ́n á tún pinnu láti gbéyàwó “kìkì nínú Olúwa,” gẹ́gẹ́ bí Ìwé Mímọ́ ṣe gbáni nímọ̀ràn. (1 Kọ́ríńtì 7:9, 39) Ó yẹ kó dá wa lójú pé inú Jèhófà máa ń dùn sí bó ṣe jẹ́ ìfẹ́ ọkàn wọn láti pa àwọn ìlànà òdodo rẹ̀ mọ́. Àwọn Kristẹni bíi tiwọn kà á sí nǹkan ayọ̀ láti dara pọ̀ mọ́ àwọn olùjọ́sìn tòótọ́ tí wọ́n ní irú ìlànà ìwà rere gíga bẹ́ẹ̀ tí wọ́n sì ń pa ìwà títọ́ mọ́.
11. Báwo la ṣe lè ṣèrànwọ́ fún arákùnrin tàbí arábìnrin kan tó wù láti ṣègbéyàwó àmọ́ tí kò tíì ṣeé ṣe fún un láti ṣe é?
11 Téèyàn ò bá wá rí ẹni tó tẹ́ ẹ lọ́rùn láti fẹ́ ńkọ́? Ronú nípa ìbànújẹ́ tó lè bá ẹnì kan tó fẹ́ ṣègbéyàwó àmọ́ tí kò tíì ṣeé ṣe fún un láti ṣe bẹ́ẹ̀! Ó lè máa rí àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ tó ń ṣègbéyàwó tínú wọn sì ń dùn, nígbà tóun ṣì ń wá ẹni tó máa fẹ́. Ìwà àìmọ́ ti fífi ọwọ́ pa ẹ̀ya ìbímọ ara ẹni láti mára ẹni gbóná lè jẹ́ ìṣòro tí àwọn tó wà nínú irú ipò bẹ́ẹ̀ ń bá yí. Bó ti wù kó rí, kò sí Kristẹni kankan tí yóò fẹ́ kó ìbànújẹ́ ọkàn bà ẹni tó ń tiraka láti pa ara rẹ̀ mọ́. A lè kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá wọn láìmọ̀ọ́mọ̀, tá a bá ń sọ àwọn ọ̀rọ̀ tí kò gbéni ró bíi, “Ìgbà wo lo máa ṣègbéyàwó?” Ẹni tó sọ bẹ́ẹ̀ lè má ní èrò búburú lọ́kàn o, àmọ́ ì bá dára jù lọ tá a bá lè lo ìkóra-ẹni-níjàánu nínú ọ̀rọ̀ tó ń ti ẹnu wa jáde! (Sáàmù 39:1) Ó yẹ ká yin àwọn kan láàárín wa tí wọn ò tíì ṣègbéyàwó, síbẹ̀ tí wọ́n jẹ́ oníwà mímọ́. Dípò tá a ó fi máa sọ àwọn ohun tó ń kó ìrẹ̀wẹ̀sì báni, a lè làkàkà láti jẹ́ ẹni tó ń fúnni níṣìírí. Bí àpẹẹrẹ, a lè sapá láti pe ẹni kan tí kò tíì ṣègbéyàwó síbi tí àwùjọ àwọn tó dàgbà dénú kóra jọ sí láti jẹun tàbí láti ní ìbákẹ́gbẹ́pọ̀ Kristẹni tó gbámúṣé.
Ìkóra-Ẹni-Níjàánu Nínú Ìgbéyàwó
12. Kí nìdí tí ìkóra-ẹni-níjàánu fi pọn dandan kódà fún àwọn tó ti ṣègbéyàwó pàápàá?
12 Pé èèyàn ṣègbéyàwó kò túmọ̀ sí pé èèyàn ò ní lo ìkóra-ẹni-níjàánu nínú ọ̀ràn ìbálòpọ̀. Bí àpẹẹrẹ, ọkọ àti aya lè máà nífẹ̀ẹ́ sí ìbálòpọ̀ bákan náà. Àìlera ọkọ tàbí aya lè mú kó ṣòro fún wọn láti ní ìbálòpọ̀ bó ṣe yẹ nígbà mìíràn tàbí kó má tiẹ̀ jẹ́ kí wọ́n lè ní ìbálòpọ̀ rárá. Ọ̀nà tẹ́nì kan gbà gbé ìgbésí ayé rẹ̀ tẹ́lẹ̀ lè mú kó ṣòro fún un láti tẹ̀ lé àṣẹ tó sọ pé: “Kí ọkọ máa fi ohun ẹ̀tọ́ aya rẹ̀ fún un; ṣùgbọ́n kí aya pẹ̀lú máa ṣe bákan náà fún ọkọ rẹ̀.” Ní irú ipò bẹ́ẹ̀, ọkọ tàbí aya ní láti túbọ̀ lo ìkóra-ẹni-níjàánu. Àmọ́ àwọn méjèèjì lè fi ìmọ̀ràn onífẹ̀ẹ́ tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fún àwọn Kristẹni tó ti ṣègbéyàwó sọ́kàn pé: “Ẹ má ṣe máa fi du ara yín lẹ́nì kìíní-kejì, àyàfi nípasẹ̀ àjọgbà fún àkókò tí a yàn kalẹ̀, kí ẹ lè ya àkókò sọ́tọ̀ fún àdúrà, kí ẹ sì tún lè jùmọ̀ wà pa pọ̀, kí Sátánì má bàa máa dẹ yín wò nítorí àìlèmáradúró yín.”—1 Kọ́ríńtì 7:3, 5.
13. Kí la lè ṣe láti ṣèrànwọ́ fún àwọn tó ń sapá láti kó ara wọn níjàánu?
13 Ọpẹ́ tọkọtaya kan á mà pọ̀ o, táwọn méjèèjì bá ti kọ́ béèyàn ṣe ń lo ìkóra-ẹni-níjàánu nínú àjọṣe tímọ́tímọ́ yìí. Lákòókò kan náà, a dára kí wọ́n máa fi òye bá àwọn olùjọsìn ẹlẹgbẹ́ wọn lò, ìyẹn àwọn tó ṣì ń làkàkà láti máa lo ànímọ́ yìí nínú ọ̀ràn ìbálòpọ̀. A ò gbọ́dọ̀ gbàgbé láti gbàdúrà sí Jèhófà pé kó fún àwọn arákùnrin àti arábìnrin wa nípa tẹ̀mí ní ìjìnlẹ̀ òye, ìgboyà, àti ìmúratán láti máa bá a lọ ní sísapá gidigidi láti máa kó ara wọn níjàánu kí wọ́n sì gbé ìgbésẹ̀ láti ṣẹ́pá ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́.—Fílípì 4:6, 7
Ẹ Máa Ran Ara Yín Lọ́wọ́
14. Kí nìdí tó fi yẹ ká máa fi ìyọ́nú àti òye bá àwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ wa lò?
14 Nígbà mìíràn, ó lè ṣòro fún wa láti lóye àwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ wa tí wọ́n ń tiraka láti lo ìkóra-ẹni-níjàánu nínú ọ̀ràn táwa ò kà sí ìṣòro rárá. Àmọ́ àwa èèyàn yàtọ̀ síra. Bí ọ̀ràn ṣe ń rí lára àwọn kan kì í jẹ́ kí wọ́n mọ ohun tí wọ́n ń ṣe; àwọn ẹlòmíràn ò sì rí bẹ́ẹ̀. Ó rọrùn gan-an fún àwọn kan láti ṣàkóso ara wọn, ìkóra-ẹni-níjàánu kì í ṣe ìṣòro fún irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀. Ìyẹn sì ṣòro gan-an fún àwọn mìíràn. Àmọ́ rántí pé ẹni tó ń sapá láti borí àwọn kùdìẹ̀-kudiẹ tó ní kí i ṣe èèyàn burúkú. A gbọ́dọ̀ máa fi òye àti ìyọ́nú bá àwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ wa lò. Ayọ̀ wa yóò máa pọ̀ sí i bá a ṣe ń bá a lọ ní fífi àánú hàn sáwọn tó ṣì ń tiraka láti túbọ̀ ní ìkóra-ẹni-níjàánu. A lè rí ìyẹn látinú ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ nínú Mátíù 5:7.
15. Kí nìdí táwọn ọ̀rọ̀ inú Sáàmù 130:3 fi jẹ́ ìtùnú fún wa lórí ọ̀ràn ìkóra-ẹni-níjàánu?
15 Ká má ṣi àwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ wa lóye láé, ìyẹn àwọn tó lè kùnà láti fi àwọn ànímọ́ Kristẹni hàn nígbà mìíràn. Ẹ ò rí bó ṣe jẹ́ ìṣírí fún wa tó láti mọ̀ pé kì í ṣe ibi tá a ti kùnà láti kóra wa níjàánu lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan nìkan ni Jèhófà ń wò, ó tún ń wo ọ̀pọ̀ ibi tá a ti kó ara wa níjàánu pẹ̀lú, kódà nígbà táwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ wa ò bá tiẹ̀ rí wa pàápàá. Ìtùnú gidi ló jẹ́ fún wa láti máa rántí ọ̀rọ̀ inú Sáàmù 130:3 pé: “Bí ó bá jẹ́ pé àwọn ìṣìnà ni ìwọ ń ṣọ́, Jáà, Jèhófà, ta ni ì bá dúró?”
16, 17. (a) Báwo la ṣe lè fi ohun tó wà nínú Gálátíà 6:2, 5 sílò nínú ọ̀ràn ìkóra-ẹni-níjàánu? (b) Kí ló kàn tá a máa gbé yẹ̀ wò nípa ìkóra-ẹni-níjàánu?
16 Tá a bá fẹ́ máa múnú Jèhófà dùn, ẹnì kọ̀ọ̀kan wa gbọ́dọ̀ máa kó ara rẹ̀ níjàánu, àmọ́ ọkàn wa tún lè balẹ̀ pé àwọn Kristẹni arákùnrin wa yóò ràn wá lọ́wọ́. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé olúkúlùkù wa ni yóò ru ẹrù ara rẹ̀, síbẹ̀ a gbà wá níyànjú pé ká máa ran ara wa lọ́wọ́ láti borí ìkùdíẹ̀-káàtó wa. (Gálátíà 6:2, 5) Ìyẹn á jẹ́ ká mọyì òbí, ọkọ tàbí aya, tàbí ọ̀rẹ́ tí kò jẹ́ ká lọ sáwọn ibi tí kò yẹ ká lọ, tí kò jẹ́ ká wo ohun tí kò yẹ ká wò, tàbí tí kò jẹ́ ká ṣe àwọn ohun tí kò yẹ ká ṣe. Ńṣe lonítọ̀hún ń ràn wá lọ́wọ́ láti ní ìkóra-ẹni-níjàánu, àti láti nígboyà láti sọ pé rárá sí ohun tí ò dáa, ká sì dúró lórí ìpinnu wa!
17 Ọ̀pọ̀ Kristẹni ti lè máa ṣe àwọn ohun tá a ti sọ nípa ìkóra-ẹni-níjàánu yìí, àmọ́ àwọn fúnra wọn lè mọ̀ pé àwọn ṣì ní ibi púpọ̀ láti ṣiṣẹ́ lé lórí. Ó lè wù wọ́n láti túbọ̀ lo ìkóra-ẹni-níjàánu dé ẹ̀kúnrẹ́rẹ́, ìyẹn ni pé kí wọ́n fẹ́ lo ànímọ́ yìí dé ibi tí wọ́n gbà pé ó ṣeé ṣe fún ẹ̀dá aláìpé láti lò ó dé. Ṣé ó máa ń ṣe ìwọ náà bẹ́ẹ̀? Kí lo wá lè ṣe láti túbọ̀ ní ànímọ́ tá a ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ yìí nínú àwọn èso ti ẹ̀mí Ọlọ́run? Báwo ni ṣíṣe bẹ́ẹ̀ ṣe lè ràn ọ́ lọ́wọ́ láti jẹ́ kí ọwọ́ rẹ tẹ ohun tó ti wà lórí ẹ̀mí rẹ̀ tipẹ́tipẹ́ gẹ́gẹ́ bí Kristẹni? Ẹ jẹ́ ká wò ó nínú àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé e.
Ǹjẹ́ O Rántí?
Kí Nìdí Tí Ìkóra-Ẹni-Níjàánu . . .
• fi jẹ́ ohun tó ṣe pàtàkì fáwọn Kristẹni láti ní?
• fi jẹ́ ìṣòro ńlá fáwọn kan?
• fi ṣe pàtàkì nínú ìgbéyàwó?
• fi jẹ́ ànímọ́ kan tá a lè ran ara wa lọ́wọ́ láti ní?
[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]
[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]
Ó Kọ́ Béèyàn Ṣe Ń Sọ Pé Rárá, Mi Ò Ṣe Ohun Tí Ò Dáa
Wọ́n gba Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan sí iṣẹ́ bíbójú tó ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ ní ilẹ̀ Jámánì. Iṣẹ́ rẹ̀ gba pé kó máa bójú tó ètò ẹ̀rọ tó ń gbé nǹkan bí ọgbọ̀n ìtòlẹ́sẹẹsẹ tó yàtọ̀ síra jáde lórí tẹlifíṣọ̀n àti rédíò. Nígbà tí ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà bá já lu ara wọn, ó ní láti fara balẹ̀ wo ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà dáadáa kó lè mọ ibi tí ìṣòro náà wà. Ó sọ pé: “Àkókò tí kò dára rárá ni àwọn ìtòlẹ́sẹẹsẹ wọ̀nyí máa ń já lu ara wọn, ìyẹn sì máa ń jẹ́ ìgbà tí wọ́n bá ń fi ìwà ipá tàbí ìbálòpọ̀ hàn. Ìran burúkú náà sì máa ń wà nínú ọpọlọ mi fún ọjọ́ pípẹ́ kódà ó máa ń wà níbẹ̀ fún ọ̀pọ̀ ọ̀sẹ̀ nígbà mìíràn, ńṣe ló máa ń dà bíi pé wọ́n ti ya àwòrán náà sínú ọpọlọ mi tí ò sì ṣeé pa rẹ́.” Ó jẹ́wọ́ pé èyí ń ṣàkóbá fún òun nípa tẹ̀mí, ó ní: “Oníwàǹwara èèyàn ni mí, wíwo àwọn ìran oníwà ipá bẹ́ẹ̀ ti jẹ́ kó ṣòro fún mi láti kó ara mi níjàánu. Àwọn ìran ìbálòpọ̀ tí mò ń wò ń dá wàhálà sílẹ̀ láàárín èmi àti ìyàwó mi. Ojoojúmọ́ ló ń dà mí lọ́kàn rú. Kí n lè bọ́ lọ́wọ́ ìṣòro yìí, mo pinnu láti wá iṣẹ́ mìíràn, bó tiẹ̀ jẹ́ pé owó tí mò máa gbà lè máà tó ti tẹ́lẹ̀. Ẹnu àìpẹ́ yìí ni mo rí iṣẹ́ mìíràn. Ọwọ́ mi ti tẹ ohun tí mò ń wá.”
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]
Ìmọ̀ tá a jèrè látinú ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ń ràn wá lọ́wọ́ láti lo ìkóra-ẹni-níjàánu