Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

“Ẹ Má Ṣe Fi Àìdọ́gba So Pọ̀”

“Ẹ Má Ṣe Fi Àìdọ́gba So Pọ̀”

“Ẹ Má Ṣe Fi Àìdọ́gba So Pọ̀”

GẸ́GẸ́ bó o ṣe rí i nínú àwòrán yìí, inú ìnira ni ràkúnmí àti akọ màlúù yìí ti ń túlẹ̀ pa pọ̀. Àjàgà tí a fi so wọ́n pọ̀, èyí tá a ṣe fún ẹran méjì tí kò tóbi ju ara wọn lọ, ló ǹ fa ìnira fún wọn. Nítorí pé Ọlọ́run gba ti àwọn ẹran tá a fi ń fa ẹ̀rù yìí rò, ó sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé: “Ìwọ kò gbọ́dọ̀ fi akọ màlúù àti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ túlẹ̀ pa pọ̀.” (Diutarónómì 22:10) Ìlànà kan náà yìí ló wà fún akọ màlúù àti ràkúnmí.

Ní ti tòótọ́, kò sí àgbẹ̀ kan tó lè kó irú ìnira bẹ́ẹ̀ bá àwọn ẹran rẹ̀. Àmọ́ tí kò bá ní akọ màlúù méjì, ó lè so àwọn ẹran méjì tó bá ní pa pọ̀. Ó ṣe kedere pé ohun tí àgbẹ̀ ọ̀rúndún kọkàndínlógún tó wà nínú àwòrán yìí pinnu láti ṣe nìyẹn. Nítorí pé àwọn ẹran náà tóbi jura wọn lọ, ìnira ló máa jẹ́ fún èyí tí kò lágbára láti rìn ní ìfẹ̀gbẹ́kẹ̀gbẹ́ pẹ̀lú èyí tó lágbára, èyí tó lágbára sì ni yóò gbé èyí tó pọ̀ jù nínú ìnira náà.

Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù lo àpèjúwe àwọn ẹran méjì tí wọ́n tóbi jura wọn lọ yìí láti fi kọ́ wa lẹ́kọ̀ọ́ pàtàkì kan. Ó kọ̀wé pé: “Ẹ má ṣe fi àìdọ́gba so pọ̀ pẹ̀lú àwọn aláìgbàgbọ́. Nítorí àjọṣe wo ni òdodo àti ìwà àìlófin ní? Tàbí àjọpín wo ni ìmọ́lẹ̀ ní pẹ̀lú òkùnkùn?” (2 Kọ́ríńtì 6:14) Báwo ni Kristẹni ṣe lè fi àìdọ́gba so pọ̀ pẹ̀lú ẹnì kan?

Ọ̀nà kan ni pé kí Kristẹni kan yàn láti ṣègbéyàwó pẹ̀lú ẹni tó ń ṣe ẹ̀sìn mìíràn. Irú àjọṣe bẹ́ẹ̀ yóò kó ìṣòro bá àwọn méjèèjì ni, wọn ò sì ní lè máa fohùn ṣọ̀kan lórí àwọn ọ̀ràn tó ṣe pàtàkì.

Nígbà tí Jèhófà dá ìgbéyàwó sílẹ̀, ó ní kí aya jẹ́ “àṣekún.” (Jẹ́nẹ́sísì 2:18) Bákan náà ni Ọlọ́run gba ẹnu wòlíì Málákì sọ pé kí aya jẹ́ “ẹnì kejì.” (Málákì 2:14) Ẹlẹ́dàá wa fẹ́ kí àwọn tọkọtaya jọ máa ṣe nǹkan pa pọ̀ nípa tẹ̀mí, kí wọn jọ máa gbé ohun tó bá nira, kí wọ́n sì jọ máa jàǹfààní kan náà.

Ìmọ̀ràn tó wá látọ̀dọ̀ Baba wa ọ̀run ni Kristẹni kan ń bọ̀wọ̀ fún nígbà tó bá ṣègbéyàwó “kìkì nínú Olúwa.” (1Kóríńtì 7:39) Èyí jẹ́ ìpìlẹ̀ fún ìgbéyàwó tó máa wà níṣọ̀kan, tí yóò mú ìyìn àti ọlá wá fún Ọlọ́run. Bí àwọn tọkọtaya náà ṣe ń sìn ín, wọ́n á jẹ́ “ojúlówó alájọru àjàgà” lọ́nà àrà ọ̀tọ̀.—Fílípì 4:3.

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 32]

Ràkúnmí àti màlúù: Láti inú ìwé La Tierra Santa, Ìdìpọ̀ Kìíní, 1830