Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Báwo Lo Ṣe Lè Ṣe Ìpinnu Tó Mọ́gbọ́n Dání?

Báwo Lo Ṣe Lè Ṣe Ìpinnu Tó Mọ́gbọ́n Dání?

Báwo Lo Ṣe Lè Ṣe Ìpinnu Tó Mọ́gbọ́n Dání?

SÓLÓMỌ́NÌ ọba Ísírẹ́lì ìgbàanì sọ pé: “Ọlọ́gbọ́n yóò fetí sílẹ̀, yóò sì gba ìtọ́ni púpọ̀ sí i.” Ọ̀pọ̀ nínú wa ló ti ṣe àwọn ìpinnu tí kò mọ́gbọ́n dání rí, kò sì sí ohun mìíràn tó fà á ju pé a kọ̀ láti fetí sí ìmọ̀ràn àwọn ẹlòmíràn.—Òwe 1:5.

Nígbà tó yá, àwọn ọ̀rọ̀ Sólómọ́nì wọ̀nyẹn la kọ sínú Bíbélì pa pọ̀ pẹ̀lú àwọn mìíràn lára “ẹgbẹ̀rún mẹ́tà òwe” tó pa. (1 Ọba 4:32) Ǹjẹ́ a lè jàǹfààní tá a bá mọ àwọn ọ̀rọ̀ ọlọgbọ́n wọ̀nyí tí à sì fì wọ́n sílò? Bẹ́ẹ̀ ni. Wọ́n ràn wá lọ́wọ́ “láti mọ ọgbọ́n àti ìbáwí, láti fi òye mọ àwọn àsọjáde òye, láti gba ìbáwí tí ń fúnni ní ìjìnlẹ̀ òye, òdodo àti ìdájọ́ àti ìdúróṣánṣán.” (Òwe 1:2, 3) Ẹ jẹ́ ká jíròrò àwọn ìlànà márùn-ún tá a gbé karí Bíbélì tó lè ràn wá lọ́wọ́ láti ṣe àwọn ìpinnu tó mọ́gbọ́n dání.

Ronú Nípa Àbájáde Tó Máa Wà Pẹ́ Títí

Àwọn ìpinnu kan wà tí àbájáde wọn fa kíki. Nítorí náà, kọ́kọ́ wádìí ohun tó máa jẹ́ àbájáde ìpinnu tó o fẹ́ ṣe. Má ṣe jẹ́ kí àǹfààní tó wà fún ìgbà díẹ̀ tí irú ìpinnu bẹ́ẹ̀ lè ní bò ọ́ lójú tó ò fí ní lè rí àwọn àbájáde tí kò dára tó sì máa wà pẹ́ títí. Òwe 22:3 sọ pé: “Afọgbọ́nhùwà ni ẹni tí ó ti rí ìyọnu àjálù, tí ó sì bẹ̀rẹ̀ sí fi ara rẹ̀ pa mọ́, ṣùgbọ́n aláìní ìrírí gba ibẹ̀ kọjá, yóò sì jìyà àbájáde rẹ̀.”

Ó lè ràn ọ́ lọ́wọ́ tó o bá kọ àwọn àbájáde tó máa wà fún ìgbà kúkúrú àti àbájáde tó máa wà pẹ́ títí tí ìpinnu kan lè ní sínú ìwé kan. Ká sọ pé iṣẹ́ kan lò yàn láti ṣe, irú iṣẹ́ bẹ́ẹ̀ lè jẹ́ èyí tó lówó lórí téèyàn á sì gbádùn fún ìgbà kúkúrú. Ṣùgbọ́n, ṣé iṣẹ́ tó ṣeé gbára lé ni? Ṣé kì í ṣe ìṣẹ́ tá á jẹ́ kó o lọ máa gbé níbòmíràn, bóyá tí ìwọ àti àwọn ọ̀rẹ́ rẹ tàbí ìdílé rẹ kó ní gbé pọ̀ mọ́? Ṣé kì í ṣe iṣẹ́ tí wàá máa ṣe ní sàkáání tó léwu tàbí iṣẹ́ tí kò lárinrin tó sì lè máyé súni? Ó yẹ kí o wo gbogbo àǹfààní àti ìṣòro tí ìṣẹ́ kán ní, kó o wá pinnu èwo ló ṣe pàtàkì jù nínú àwọn kókó tó o kà sílẹ̀ wọ̀nyẹn.

Máà Kánjú

Kíkánjú ṣe ìpinnu kì í ṣe ohun tó bọ́gbọ́n mú. Òwe 21:5 sọ pé: “Dájúdájú, àwọn ìwéwèé ẹni aláápọn máa ń yọrí sí àǹfààní, ṣùgbọ́n ó dájú pé àìní ni olúkúlùkù ẹni tí ó bá ń kánjú forí lé.” Bí àpẹẹrẹ, ó yẹ káwọn ọ̀dọ́langba tó bá ní ìfẹ́ onígbòónára fara balẹ̀ dáadáa kí wọ́n tó ṣèpinnu láti ṣègbéyàwó. Bi bẹ́ẹ̀ kọ́, ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sí wọn ní William Congreve, tó jẹ́ òǹkọ̀wé eré onítàn lédè Òyìnbó ní ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀rúndún kejìdínlógún sọ pé: “Ẹni tó bá kánjú gbéyàwó lè kábàámọ̀ títí ayé.”

Bó ti wù kó rí, kéèyàn fara balẹ̀ ò túmọ̀ sí kéèyàn máa fòní dónìí fọ̀la dọ́la o. Àwọn ìpinnu kan ṣe pàtàkì gan-an débi pé ó gba ká tètè ṣèpinnu lórí wọ́n bó bá ti lè ṣeé ṣé kó yá tó. Tá a bá lọ fi falẹ̀ láì nídìí, ó lè ṣe ìpalára fún wa tàbí àwọn ẹlòmíràn. Tá a bá ń fòní dónìí tá à ń fọ̀la dọ́la láì nídìí ká to ṣèpinnu, ìpinnu kan nìyẹn náà jẹ́, àmọ́, ó lè jẹ́ ìpinnu tí kò bọ́gbọ́n mu.

Máa Gba Ìmọ̀ràn

Níwọ̀n ìgbà tó jẹ́ pé, ipò tó yí ọ̀ràn méjì ká kò lè rí bákan náà, bẹ́ẹ̀ náà ni èèyàn méjì lè máà ṣèpinnu kan náà nínú ipò tó jọra. Síbẹ̀síbẹ̀, ó máa ń ṣèrànwọ́ tá a bá mọ ìpinnu táwọn kan ṣe nígbà tí wọ́n wà nínú irú ipò tó jọ tiwa. Bi wọ́n léèrè àwọn kókó tí wọ́n máa ń gbé yẹ̀ wò kí wọ́n tó ṣèpinnu. Bí àpẹẹrẹ, ká sọ pé ó fẹ́ dáwọ́ lé òwò kan, béèrè àwọn àǹfààní àti ìṣòro tó wà nínú òwò náà lọ́wọ́ àwọn tó ń ṣe irú òwò bẹ́ẹ̀. Kí ni àwọn àǹfààní táwọn gan-an ti jẹ lára òwò yẹn, kí sì ní àwọn nǹkan to lè jẹ́ ìfàsẹ́yìn tàbí ohun tó ṣeé ṣe kó fa ìṣòro?

Bíbélì sọ fún wa pé: “Àwọn ìwéwèé máa ń já sí pàbó níbi tí kò bá ti sí ọ̀rọ̀ ìfinúkonú, ṣùgbọ́n àṣeparí ń bẹ nínú ògìdìgbó àwọn agbani-nímọ̀ràn.” (Òwe 15:22) Lóòótọ́, nígbà tá a bá gbà ìmọ̀ràn tàbí tá a bá kẹ́kọ̀ọ́ látinú ìrírí àwọn ẹlòmíràn, ó dájú pé àwa la ṣì máa ṣe ìpinnu náà nígbẹ̀yìngbẹ́yín àti pé gbogbo ohun tó bá jẹ́ àbájáde ìpinnu yẹn, àwa fúnra wa ló máa gbé e.—Gálátíà 6:4, 5.

Fetí Sí Ohun Tí Ẹ̀rí Ọkàn Tá A Kọ́ Dáadáa Bá Sọ

Ẹ̀rí ọkàn le ràn wá lọ́wọ́ láti ṣèpinnu tí yóò bá àwọn ìlànà tí a yàn láti máà tẹ̀lé nínú ìgbésí ayé wa mu. Ohun tí èyí túmọ̀ sí fún Kristẹni kan ni pé kó kọ́ ẹ̀rí ọkàn rẹ̀ kó lè bá èrò Ọlọ́run mu. (Róòmù 2:14, 15) Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ fún wa pé: “Ṣàkíyèsí [Ọlọ́run] ní gbogbo ọ̀nà rẹ, òun fúnra rẹ̀ yóò sì mú àwọn ipa ọ̀nà rẹ tọ́.” (Òwe 3:6) A mọ̀ pé, nínú àwọn ọ̀ràn kan, èèyàn méjì, tí ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn ní ẹ̀rí ọkàn tá a kọ́ dáadáa lè parí èrò síbi tó yàtọ̀ síra kí wọ́n sì tipa bẹ́ẹ̀ ṣe ìpinnu tó yàtọ̀ síra.

Àmọ́ ṣá o, ẹ̀rí ọkàn tá a kọ́ dáadáa kò ní ṣèpinnu tó yàtọ̀ tó bá dorí àwọn ọ̀ràn tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ka léèwọ̀ ní tààràtà. Bí àpẹẹrẹ, ẹ̀rí ọkàn tí a kò tíì fi àwọn ìlànà Bíbélì kọ́ lè gba ọkùnrin àti obìnrin kan láyè láti kọ́kọ́ máa gbé pọ̀ kí wọ́n tó ṣègbéyàwó láti lè mọ̀ bóyá wọ́n bá ara mu tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́. Wọ́n lè tí máa rò pé àwọn ti ṣèpinnu tó bọ́gbọ́n mu, kí wọ́n máa rò pé ìyẹn kò ní jẹ́ káwọn kánjú kó wọnú ìgbéyàwó tí kò mọ́gbọ́n dáni. Ẹ̀rí ọkàn wọn lè máà dá wọn lẹ́bi. Ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tó bá fara mọ́ ohun tí Ọlọ́run sọ lórí ìbálòpọ̀ àti ìgbéyàwó kò ní ṣe irú ìgbéyàwó jẹ́-ká-dán–an-wò tó sì jẹ́ ti oníṣekúṣe bẹ́ẹ̀.—1 Kọ́ríńtì 6:18; 7:1, 2; Hébérù 13:4.

Bí Àwọn Ìpinnu Rẹ Ṣe Kan Àwọn Ẹlòmíràn

Ìgbà púpọ̀ ní àwọn ìpinnu rẹ lè kan àwọn ẹlòmíràn. Nítorí náà, má ṣe mọ̀ọ́mọ̀ ṣèpinnu tí kò mọ́gbọ́n dání, àní tó jẹ́ ti òmùgọ̀ tó lè ba àjọṣe dáradára tó wà láàárín ìwọ, àwọn ọ̀rẹ́ rẹ àti àwọn mọ̀lẹ́bí rẹ jẹ́, tàbí lékè gbogbo rẹ̀ àjọṣe rẹ pẹ̀lú Ọlọ́run. Òwe 10:1 sọ pé: “Ọlọ́gbọ́n ọmọ ni ẹni tí ń mú kí baba yọ̀, arìndìn ọmọ sì ni ẹ̀dùn-ọkàn ìyá rẹ̀.”

Yàtọ̀ sí ìyẹn, a gbọ́dọ̀ mọ̀ pé a ò lè fìgbà gbogbo ṣe ohun tó tẹ́ gbogbo èèyàn lọ́rùn. Bí àpẹẹrẹ, o lè pinnu láti kọ ìsìn tó ò ń ṣe tẹ́lẹ̀ sílẹ̀ nítorí pé o ti kẹ́kọ̀ọ́ báyìí pé kò bá Ìwé Mímọ́ mu. Ó sì lè jẹ́ pé ńṣe lo pinnu láti ṣe àwọn ìyípadà kan nítorí pé o fẹ́ kí ìgbésí ayé rẹ wà ní ìbámu pẹ̀lú ìfẹ́ Ọlọ́run tó o ṣẹ̀ṣẹ̀ mọ̀ báyìí. Ìpinnu tó o ṣe yẹn lè má dùn mọ́ díẹ̀ lára àwọn ọ̀rẹ́ tàbí àwọn mọ̀lẹ́bí rẹ nínú, ṣùgbọ́n ìpinnu èyíkéyìí tí inú Ọlọ́run dùn sí ni ìpinnu tó mọ́gbọ́n dáni.

Jẹ́ Ọlọ́gbọ́n, Ṣe Ìpinnu Tó Tóbi Jù Lọ

Lónìí, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni kò mọ̀ pé gbogbo wa ló gbọ́dọ̀ ṣe ìpinnu yíyan ìyè tàbí ikú. Irú yíyàn yìí ló dojú kọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ìgbàanì nígbà tí wọ́n wà ní ẹnubodè Ilẹ̀ Ìlérí ní 1473 ṣááju Sànmánì Tiwa. Mósè tó jẹ́ agbẹnusọ fún Ọlọ́run sọ fún wọn pé: “Èmi ti fi ìyè àti ikú sí iwájú rẹ, ìbùkún àti ìfiré; kí o sì yan ìyè, kí o lè máa wà láàyè nìṣó, ìwọ àti ọmọ rẹ, nípa nínífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run rẹ, nípa fífetí sí ohùn rẹ̀ àti nípa fífà mọ́ ọn; nítorí òun ni ìyè rẹ àti gígùn ọjọ́ rẹ, kí ìwọ lè máa gbé lórí ilẹ̀ tí Jèhófà búra fún àwọn baba ńlá rẹ Ábúráhámù, Ísákì àti Jékọ́bù láti fi fún wọn.”—Diutarónómì 30:19, 20.

Àsọtẹ́lẹ̀ àti ìṣirò ọjọ́ ìṣẹ̀lẹ̀ inú Bíbélì fì hàn pé à ń gbé ní “àwọn àkókò lílekoko tí ó nira láti bá lò” àti pé “ìrísí ìran ayé yìí ń yí padà.” (2 Tímótì 3:1; 1 Kọ́ríńtì 7:31) Ìyípadà tí a sọ tẹ́lẹ̀ yìí yóò dé òtéńté rẹ̀ nígbà tí ètò tí àwọn ènìyàn gbé kalẹ̀ tó ti dì kọ̀ǹdẹ̀ yìí bá pa run tí ayé tuntun òdodo Ọlọ́run yóò sì rọ́pò rẹ̀.

A ti wà ní bèbè ayé tuntun yẹn báyìí. Ṣé wàá wọ inú ayé tuntun yẹn láti gbádùn ìyè tí kò lópin lábẹ́ Ìjọba Ọlọ́run? Àbí wàá wà lára àwọn tí yóò pa run nígbà tí ètò Sátánì kò bá sí mọ́? (Sáàmù 37:9-11; Òwe 2:21, 22) Ìwọ lo máa pinnu láti yan ọ̀nà tó o máa tẹ̀lé, ká sòótọ́, ìpinnu ọ̀hún jẹ́ ọ̀ràn ìyè tàbí ikú. Ṣé wàá fẹ́ gba ìrànlọ́wọ́ láti ṣe ìpinnu tó tọ́, àní èyí tó mọ́gbọ́n dání?

Kéèyàn tó lè pinnu láti tọ ọ̀nà ìyè, ó gba pé kí onítọ̀hún kọ́kọ́ kẹ́kọ̀ọ́ láti mọ àwọn ohun tí Ọlọ́run ń béèrè. Fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún sẹ́yìn ni àwọn ṣọ́ọ̀ṣì ti kùnà gan-an láti kọ́ àwọn èèyàn ní ohun tí Ọlọ́run fẹ́ bó ṣe tọ́ àti bó ṣe yẹ. Àwọn aṣáájú wọn ti máa ń fìgbà gbogbo ṣì wọ́n lọ́nà láti gba irọ́ àti àwọn ohun tí kò dùn mọ́ Ọlọ́run nínú gbọ́. Wọ́n ti kùnà láti ṣàlàyé ìjẹ́pàtàkì ṣíṣe ìpinnu láti sin Ọlọ́run “ní ẹ̀mí àti òtítọ́.” (Jòhánù 4:24) Ohun tó fà á gan-an nìyẹn tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn èèyàn kì í fi í sin Ọlọ́run ní ẹ̀mí àti òtítọ́. Ṣùgbọ́n ṣàkíyèsí ohun tí Jésù sọ pé: “Ẹni tí kò bá sí ní ìhà ọ̀dọ̀ [òun] lòdì sí [òun], ẹni tí kò bá sì kó jọ pẹ̀lú [òun] ń tú ká.”— Mátíù 12:30.

Tayọ̀tayọ̀ ni àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń ran àwọn èèyàn lọ́wọ̀ láti ní ìmọ̀ tó péye nípa Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Wọ́n máa ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́nì kọ̀ọ̀kan tàbí láwùjọ lápapọ̀ ní ẹ̀kọ́ Bíbélì déédéé ní àkókò tó rọrùn àti ní ibi tó bá tù àwọn èèyàn lára. Kí àwọn tó bá fẹ́ jàǹfààní ìpèsè yìí kàn sí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó bá wà ládùúgbò wọn tàbí kí wọ́n kọ̀wé sí àwọn tó ń tẹ́ Ilé Ìṣọ́ jáde.

A mọ̀ pé, ó ṣeé ṣe káwọn kan ti mọ díẹ̀ nínú àwọn ohun tí Ọlọ́run ń béèrè. Wọ́n tìẹ lè gbà pé òtítọ́ pọ́ńbélé lọ̀rọ̀ tó wà nínú Bíbélì àti pé ó ṣeé gbára lé. Síbẹ̀síbẹ̀ ọ̀pọ̀ nínú wọn ló sì ń fòní dónìí fọ̀la dọ́la tó bá di ọ̀ràn pé kí wọ́n pinnu láti ya ara wọn sí mímọ́ fún Ọlọ́run kí wọ́n sì ṣe ìrìbọmi. Kí ló fà á? Ọ̀pọ̀ àwọn nǹkan ló lè fà á.

Bóyá wọn ò tiẹ̀ mọ ìdí tó fi ṣe pàtàkì láti ya ara wọn sí mímọ́ fún Ọlọ́run? Jésù sọ gbangba gbàǹgbà pé: “Kì í ṣe olúkúlùkù ẹni tí ń wí fún mi pé, ‘Olúwa, Olúwa,’ ni yóò wọ ìjọba ọ̀run, bí kò ṣe ẹni tí ń ṣe ìfẹ́ Baba mi tí ń bẹ ní ọ̀run ni yóò wọ̀ ọ́.” (Mátíù 7:21) Rírọ́ ìmọ̀ Bíbélì sórí nìkan ò tó, wọ́n gbọ́dọ̀ ṣe nǹkan kan. Ìjọ Kristẹni àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ fi àpẹẹrẹ lélẹ̀ nínú èyí. À kà nípa àwọn kan ní ọ̀rùndún kìíní pé: “Nígbà tí wọ́n gba Fílípì gbọ́, ẹni tí ń polongo ìhìn rere ìjọba Ọlọ́run àti orúkọ Jésù Kristi, a bẹ̀rẹ̀ sí batisí wọn, lọ́kùnrin àti lóbìnrin.” (Ìṣe 2:41; 8:12) Nítorí náà, bí ẹni kan bá gba Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run gbọ́ tọkàntọkàn, tó sì nígbàgbọ́ nínú àwọn ọ̀rọ̀ rẹ̀, tó ń gbé ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ìlànà Ọlọ́run, kí ló yẹ kó tún máa dá irú ẹni bẹ́ẹ̀ dúró láti ṣe ìrìbọmi gẹ́gẹ́ bí ẹ̀rí ìyàsímímọ́ rẹ̀? (Ìṣe 8:34-38) Lóòótọ́, kí inú Ọlọ́run tó lè dùn sí irú ẹni bẹ́ẹ̀, gbogbo àwọn ohun wọ̀nyí ló yẹ kó ṣe láì lọ́ tìkọ̀ kó sì ṣe bẹ́ẹ̀ tìdùnnú-tìdùnnú.—2 Kọ́ríńtì 9:7.

Àwọn kan lè rò pé àwọn ò ní ìmọ̀ tó pọ̀ tó láti ya ara àwọn sí mímọ́ fún Ọlọ́run. Ṣùgbọ́n ká rántí pé téèyàn bá ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ kan ìmọ̀ rẹ̀ kì í fi bẹ́ẹ̀ pọ̀ lórí iṣẹ́ náà. Àbí, akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ wo ló lè sọ pé ọjọ́ tí òun bẹ̀rẹ̀ sí ní kọ́ṣẹ́ lòhún ti mọ gbogbo ohun tí òun mọ̀ báyìí? Ohun tí ìpinnu láti sin Ọlọ́run wulẹ̀ ń béèrè kò jú ìmọ̀ nípa ìpìlẹ̀ àwọn ẹ̀kọ́ àti àwọn ìlànà inú Bíbélì, pa pọ̀ pẹ̀lú ìfẹ́ ọkàn tòótọ́ láti gbé ní ìbámu pẹ̀lú wọn.

Ṣé kì í ṣe nítorí pe àwọn kan rò pé àwọn ò ní lè máa gbé ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ìlànà Ọlọ́run ló jẹ́ kí wọ́n máa fi ìyàsímímọ́ wọn falẹ̀? Kò sí ẹni tí àyà rẹ̀ kì í já pé ohun lè kùnà nínú àdéhùn tó bá àwọn èèyàn ṣe. Ọ̀kùnrin kan tó pinnu láti gbéyàwó kó sì bímọ lè máa rò pé òun ò ní lè gbọ́ bùkátà tó wá nídìí rẹ̀, àmọ́ àdéhùn tó ti ṣe á máa mú kórí rẹ̀ yá láti máa ṣe ohun gbogbo tó bá lè ṣe. Bákan náà ni ọ̀dọ́ kan tó ṣẹ̀ṣẹ̀ gba ìwé àṣẹ ìrìnnà lè máa bẹ̀rù jàǹbá lójú pópó pàápàá tó bá tiẹ̀ tún wá mọ̀ pé ohun tí àkọsílẹ̀ oníṣirò fi hàn ni pé iye àwọn ọ̀dọ́ tó ń kú pọ̀ ju iye àwọn àgbà tó ń kú látàrí jàǹbá mọ́tò. Àmọ́ ṣá o, irú ìmọ̀ báyìí lè ṣàǹfààní gan-an ní ti pé á jẹ́ kó lè túbọ̀ máa fi ìṣọ́ra wa mọ́tò. Ṣùgbọ́n tó bá kọ̀, tí kò gba ìwé àṣẹ ìrìnnà, ìyẹn ò yanjú ìṣòro náà!

Pinnu Láti Tọ Ọ̀nà Ìyè!

Bíbélì fi hàn pé ètò ìṣèlú, ètò ọrọ̀ ajé àti ètò ìsìn èké tó wà kárí ayé nísinsìnyí pa pọ̀ pẹ̀lú àwọn tó ń tì wọ́n lẹ́yìn máa tó pòórá lórí ilẹ̀ ayé. Ṣùgbọ́n gbogbo àwọn tó bá ti pinnu láti tọ ọ̀nà ìyè tí wọ́n sì ṣiṣẹ́ ní ìbámu pẹ̀lú ìpinnu wọn ni yóò là á já. Nítorí pé wọ́n jẹ́ ìpìlẹ̀ ayé tuntun, wọ́n á kópa nínú sísọ ayé di Párádísè, gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run ṣe fẹ́ kó rí ní ìpilẹ̀ṣẹ̀. Ṣé wàá fẹ́ kópa nínú ìṣẹ́ aláyọ̀ tí Ọlọ́run ń darí yìí?

Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, pinnu láti kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Pinnu láti mọ àwọn ohun tí Ọlọ́run ń béèrè ká baà le wù Ú. Pinnu láti máa ṣe àwọn ohun tó béèrè yẹn. Ju gbogbo rẹ̀ lọ, pinnu láti dúró ti ìpinnu rẹ títí dópin. Lọ́rọ̀ kan, pinnu láti tọ ọ̀nà ìyè!

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 4]

Má ṣe kánjú nígbà tó o bá fẹ ṣèpinnu tó gbàrònú

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 5]

Gba ìmọ̀ràn nígbà tó o bá fẹ́ yan ìṣẹ́ ìgbésí ayé

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]

Àwọn tó pinnu láti sin Ọlọ́run nísinsìnyí yóò kópa nínú sísọ ayé di Párádísè