Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Kó Ara Rẹ Níjàánu Kí o Lè Gba Èrè Náà!

Kó Ara Rẹ Níjàánu Kí o Lè Gba Èrè Náà!

Kó Ara Rẹ Níjàánu Kí o Lè Gba Èrè Náà!

“Olúkúlùkù ènìyàn tí ń kó ipa nínú ìdíje a máa lo ìkóra-ẹni-níjàánu nínú ohun gbogbo.”—1 KỌ́RÍŃTÌ 9:25.

1. Ní ìbámu pẹ̀lú ohun tó wà nínú Éfésù 4:22-24, ọ̀nà wo ni ọ̀kẹ́ àìmọye ti gbà sọ pé àwọn fẹ́ ṣe ìfẹ́ Jèhófà?

 TÓ O bá ti ṣe batisí gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ohun tó túmọ̀ sí ni pé o ti jẹ́ kí gbogbo èèyàn mọ̀ pé ó fẹ́ kópa nínú ìdíje kan tí ìyè ayérayé jẹ́ èrè rẹ̀. O ti sọ pé mo ṣe tán láti ṣe ìfẹ́ Jèhófà. Ọ̀pọ̀ lára wa ló ní láti ṣe àwọn àtúnṣe kan kí wọ́n tó lè ya ara wọn sí mímọ́ fún Jèhófà, kí ìyàsímímọ́ wọn bàa lè jẹ́ ojúlówó kó ṣì ṣe ìtẹ́wọ́gbà lọ́dọ̀ Ọlọ́run. Ìmọ̀ràn tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fún àwa Kristẹni la sì ń tẹ̀ lé pé: “Kí ẹ bọ́ ògbólógbòó àkópọ̀ ìwà sílẹ̀, èyí tí ó bá ipa ọ̀nà ìwà yín àtijọ́ ṣe déédéé, tí a sì ń sọ di ìbàjẹ́ ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ìfẹ́-ọkàn rẹ̀ atannijẹ . . . Kí ẹ sì gbé àkópọ̀ ìwà tuntun wọ̀, èyí tí a dá ní ìbámu pẹ̀lú ìfẹ́ Ọlọ́run nínú òdodo tòótọ́ àti ìdúróṣinṣin.” (Éfésù 4:22-24) Ohun tá a ń sọ ni pé ká tó lè sọ pé a fẹ́ ṣe ìyàsímímọ́, a gbọ́dọ̀ fi ọ̀nà tí ò dáa tá a gbà ń gbé ìgbésí ayé wa sílẹ̀.

2, 3. Báwo ni ìwé 1 Kọ́ríńtì 6:9-12 ṣe fi hàn pé oríṣi ìyípadà méjì léèyàn gbọ́dọ̀ ṣe kó tó lè rí ojú rere Ọlọ́run?

2 Apá kan lára àwọn ògbólógbòó ìwà tí àwọn tó fẹ́ di Ẹlẹ́rìí Jèhófà gbọ́dọ̀ kọ̀ sílẹ̀ làwọn ohun tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run kà léèwọ̀ ní tààràtà. Pọ́ọ̀lù to díẹ̀ lára wọn lẹ́sẹẹsẹ sínú lẹ́tà tó kọ sí àwọn ará Kọ́ríńtì, tó sọ pé: “Kì í ṣe àwọn àgbèrè, tàbí àwọn abọ̀rìṣà, tàbí àwọn panṣágà, tàbí àwọn ọkùnrin tí a pa mọ́ fún àwọn ète tí ó lòdì sí ti ẹ̀dá, tàbí àwọn ọkùnrin tí ń bá ọkùnrin dà pọ̀, tàbí àwọn olè, tàbí àwọn oníwọra, tàbí àwọn ọ̀mùtípara, tàbí àwọn olùkẹ́gàn, tàbí àwọn alọ́nilọ́wọ́gbà ni yóò jogún ìjọba Ọlọ́run.” Ó wá jẹ́ ká mọ̀ pé àwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní ṣe àwọn ìyípadà tó ṣe pàtàkì, ó fi kún un pé: “Síbẹ̀, ohun tí àwọn kan lára yín ti jẹ́ rí nìyẹn.” Kíyè sí i pé, ti jẹ́ rí ló sọ, kò sọ pé wọ́n jẹ́ bẹ́ẹ̀ nísinsìnyí.1 Kọ́ríńtì 6:9-11.

3 Pọ́ọ̀lù fi hàn pé ó tún lè pọn dandan láti ṣe àwọn ìyípadà mìíràn, ó ní: “Ohun gbogbo ni ó bófin mu fún mi; ṣùgbọ́n kì í ṣe ohun gbogbo ni ó ní àǹfààní.” (1 Kọ́ríńtì 6:12) Abájọ tí ọ̀pọ̀ tó fẹ́ di Ẹlẹ́rìí Jèhófà lónìí fi ri í pé ó pọn dandan fáwọn láti sọ pé rárá, àwọn ò ní ṣe ohun tí kò láǹfààní tàbí tí kò fi bẹ́ẹ̀ ṣe pàtàkì, àní bí àwọn ohun náà tilẹ̀ bófin mu pàápàá. Àwọn nǹkan wọ̀nyí lè jẹ́ ohun tó ń gba àkókò tí kò sì ní fún wọn láyè láti lépa àwọn ohun tó ṣe pàtàkì jù.

4. Kí ni àwọn Kristẹni tó ti ya ara wọn sí mímọ́ bá Pọ́ọ̀lù fohùn ṣọ̀kan lé lórí?

4 Tinútinú léèyàn fi ń ya ara rẹ̀ sí mímọ́ fún Ọlọ́run, kì í ṣe pẹ̀lú ìlọ́tìkọ̀, bí ẹni pé nǹkan ńlá la fi ń du ara wa. Àwọn Kristẹni tó ti ya ara wọn sí mímọ́ fohùn ṣọ̀kan pẹ̀lú Pọ́ọ̀lù, tó sọ lẹ́yìn tó di ọmọlẹ́yìn Kristi pé: “Ní tìtorí [Jésù], èmi ti gba àdánù ohun gbogbo, mo sì kà wọ́n sí ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ pàǹtírí, kí n lè jèrè Kristi.” (Fílípì 3:8) Tayọ̀tayọ̀ ni Pọ́ọ̀lù fi kọ àwọn ohun tí kò ní láárí sílẹ̀ kí ó bàa lè fi ara rẹ̀ fún Ọlọ́run.

5. Irú eré ìje wo ni Pọ́ọ̀lù sá dé ìparí, báwo làwa náà ṣe lè ṣe bákan náà?

5 Pọ́ọ̀lù lo ìkóra-ẹni-níjàánu nínú eré ìje tẹ̀mí tó ń sá, ìdí nìyẹn tó fi lè sọ níkẹyìn pé: “Mo ti ja ìjà àtàtà náà, mo ti sáré ní ipa ọ̀nà eré ìje náà dé ìparí, mo ti pa ìgbàgbọ́ mọ́. Láti àkókò yìí lọ, a ti fi adé òdodo pa mọ́ dè mí, èyí tí Olúwa, onídàájọ́ òdodo, yóò fi san mí lẹ́san ní ọjọ́ yẹn, síbẹ̀ kì í ṣe fún èmi nìkan, ṣùgbọ́n fún gbogbo àwọn tí ó ti nífẹ̀ẹ́ ìfarahàn rẹ̀ pẹ̀lú.” (2 Tímótì 4:7, 8) Ǹjẹ́ á ṣeé ṣe fún àwa náà láti sọ irú ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ lọ́jọ́ kan? A ó ṣe bẹ́ẹ̀ tá a bá kó ara wa níjàánu tọkàntọkàn nínú eré ìje Kristẹni tá à ń sá, tá a sì sá a títí dópin láì juwọ́ sílẹ̀.

A Nílò Ìkóra-Ẹni-Níjàánu Láti Ṣe Ohun Tó Dáa

6. Kí ni ìkóra-ẹni-níjàánu, kí sì ni àwọn ọ̀nà méjì tó yẹ ká gbà kó ara wa níjàánu?

6 Ohun tí ọ̀rọ̀ Hébérù àti ti Gíríìkì tá a túmọ̀ sí “ìkóra-ẹni-níjàánu” nínú Bíbélì túmọ̀ sí gan-an ni pé kéèyàn lágbára láti ṣàkóso ara rẹ̀. Èrò tó fi síni lọ́kàn ni pé kéèyàn yẹra fún ṣíṣe ohun búburú. Àmọ́, ó tún hàn gbangba pé ìkóra-ẹni-níjàánu ṣe pàtàkì tá a bá fẹ́ lo ara wa fún àwọn iṣẹ́ rere. Èrò àtiṣe ohun tí kò dáa ló sábà máa ń wá sọ́kàn ẹ̀dá aláìpé, ìdí nìyẹn tá a fi ní láti làkàkà lọ́nà méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. (Oníwàásù 7:29; 8:11) Bá a ṣe ń sá fún ṣíṣe ibi, bẹ́ẹ̀ náà la ó máa wa ọ̀nà láti ṣe ohun tó dáa. Ká sòótọ́, ṣíṣàkóso ara wa láti ṣe ohun tó dáa jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ọ̀nà tó dára jù lọ láti yẹra fún ṣíṣe ohun búburú.

7. (a) Kí la gbọ́dọ̀ gbàdúrà fún bíi ti Dáfídì? (b) Kí la máa ṣe àṣàrò lé lórí tó máa ràn wá lọ́wọ́ láti túbọ̀ lo ìkóra-ẹni-níjàánu?

7 Ní kedere, ìkóra-ẹni-níjàánu ṣe pàtàkì gan-an tá a bá fẹ́ mú ẹ̀jẹ́ ìyàsímímọ́ wa sí Ọlọ́run ṣẹ. A ní láti máa gbàdúrà bíi ti Dáfídì pé: “Àní kí o dá ọkàn-àyà mímọ́ gaara sínú mi, Ọlọ́run, kí o sì fi ẹ̀mí tuntun sínú mi, ọ̀kan tí ó fẹsẹ̀ múlẹ̀ ṣinṣin.” (Sáàmù 51:10) A lè ṣàṣàrò lórí àwọn àǹfààní tó wà nínú yíyẹra fún àwọn ohun tó ń ba ìwà rere jẹ́ tó sì lè pani lára. Ronú nípa àwọn àbájáde búburú tó lè ṣẹlẹ̀ tá ò bá yẹra fún irú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀, ó lè fa: àìsàn líle koko, àjọṣe tí kò dán mọ́rán, ó tiẹ̀ lè mú kéèyàn kú ní rèwerèwe pàápàá. Ní òdìkejì ẹ̀wẹ̀, ronú nípa ọ̀pọ̀ àǹfààní téèyàn lè rí nínú títẹ̀lé ọ̀nà ìgbésí ayé tí Jèhófà là sílẹ̀. Àmọ́, tá a bá fẹ́ sọ̀rọ̀ síbi tọ́rọ̀ wà, a ò gbọ́dọ̀ gbàgbé pé ọkàn wa ṣe àdàkàdekè. (Jeremáyà 17:9) A ò gbọ́dọ̀ jẹ́ kí ọkàn wa máa fojú kéré títẹ̀lé àwọn ìlànà Jèhófà.

8. Kí ni ohun náà gan-an tá a rí kọ́ látinú ohun tójú wa ti rí? Ṣàpèjúwe.

8 Ohun tójú ọ̀pọ̀ jù lọ lára wa ti rí ti jẹ́ ká mọ̀ pé ẹran ara tó ń lọ́ tìkọ̀ máa ń pa iná ẹ̀mí tó múra tán láti ṣe nǹkan. Bí àpẹẹrẹ, ronú nípa iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba Ọlọ́run. Báwọn èèyàn ṣe múra tán láti kópa nínú iṣẹ́ tó ń fúnni níyè yìí ń múnú Jèhófà dùn. (Sáàmù 110:3; Mátíù 24:14) Àmọ́ ọ̀pọ̀ jù lọ wa ni kò tètè rọrùn fún láti wàásù ní gbangba. Ó gba pé ká ṣàkóso ara wa, ìyẹn ni pé ká “lu” ara wa, ká sì “darí rẹ̀ bí ẹrú,” dípò tá a ó fi jẹ́ kó sún wa máa gbé ìgbésí ayé jẹ̀lẹ́ńkẹ́.—1 Kọ́ríńtì 9:16, 27; 1 Tẹsalóníkà 2:2.

Ṣe “Nínú Ohun Gbogbo” Ni?

9, 10. Kí ni lílo “ìkóra-ẹni-níjàánu nínú ohun gbogbo” wé mọ́?

9 Ìmọ̀ràn Bíbélì tó sọ pé ká lo “ìkóra-ẹni-níjàánu nínú ohun gbogbo” fi hàn pé a ní láti ṣe ju yíyẹra fún bíbínú sódì àti sísá fún ìwà pálapàla nìkan. A lè rí i pé a ti ń lò ìkóra-ẹni-níjàánu láwọn ibi tá a mẹ́nu kàn yìí, tó bá sì rí bẹ́ẹ̀, ńṣe ló yẹ ká máa dúpẹ́. Àmọ́, àwọn apá ibòmíràn tó lè má hàn síta pé a ti nílò ìkóra-ẹni-níjàánu ńkọ́? Bí àpẹẹrẹ, ká sọ pé à ń gbé ní orílẹ̀-èdè ti nǹkan ti rọ̀ ṣọ̀mù, táwọn èèyàn ibẹ̀ sì ń gbé ìgbésí ayé ọlọ́lá. Ǹjẹ́ kò ní bọ́gbọ́n mu ká kọ́ bá a ó ṣe máa ṣọ́wó ná? Ì bá dára káwọn òbí kọ́ àwọn ọmọ wọn láti má ṣe ra ohunkóhun tí wọ́n bá ṣáà ti rí, kìkì nítorí pé nǹkan náà wà lárọ̀ọ́wọ́tó wọn, nítorí pé ó wù wọn, tàbí nítorí pé wọ́n ni owó tí wọ́n máa fi rà á. Àmọ́ ṣá o, kí irú ẹ̀kọ́ bẹ́ẹ̀ tó lè gbéṣẹ́, àwọn òbí ní láti fi àpẹẹrẹ rere lélẹ̀.—Lúùkù 10:38-42.

10 Kíkẹ́kọ̀ọ́ láti má ṣe ra gbogbo ohun tó bá wù wá lè mú kí ìpinnu tá a ṣe láti máa kóra wa níjàánu túbọ̀ lágbára sí i. Ìyẹn tún lè jẹ́ ká túbọ̀ mọ bá a ó ṣe máa lo àwọn ohun ìní wa, ká sì máa káàánú àwọn tó yẹ kó ní àwọn ohun kan àmọ́ tí wọn ò rówó fi rà wọ́n. Ká sòótọ́, ìgbésí ayé oníwọ̀ntúnwọ̀nsì yàtọ̀ pátápátá sí èrò táwọn èèyàn ní tí wọ́n máa ń sọ pé “jayé orí ẹ” tàbí “arojú owó kì í ṣẹ̀ṣọ́.” Àwọn tó ń polówó ọjà máa ń fẹ́ kéèyàn tẹ́ ara rẹ̀ lọ́rùn lójú ẹsẹ̀, bẹ́ẹ̀ èrè tiwọn ni wọ́n ń wá. Èyí lè máà jẹ́ kó rọrùn fún wa láti kó ara wa níjàánu. Ìwé ìròyìn kan tí wọ́n kọ ní orílẹ̀-èdè tí nǹkan ti rọ̀ ṣọ̀mù nílẹ̀ Yúróòpù sọ lẹ́nu àìpẹ́ yìí pé: “Tó bá ṣòro fáwọn tó wà nínú ipò òṣì paraku láti kóra wọn níjàánu nínú ohun tí wọ́n ń rà, mélòómélòó wá ni tàwọn tó ń gbé níbi tí nǹkan ti rọ̀ ṣọ̀mù, ìyẹn láwọn orílẹ̀-èdè tó lọ́rọ̀ gan-an lóde òní!”

11. Kí nìdí tó fi ṣàǹfààní láti kọ́ béèyàn ṣe ń fi nǹkan du ara rẹ̀, àmọ́ kí ló fà á tí èyí fi ṣòroó ṣe?

11 Tó bá ṣòro fún wa láti fìyàtọ̀ sáàárín ohun tó kàn wù wá àti ohun tá a dìídì nílò, ohun tó dára ni pé ká ṣọ́ra láti rí i dájú pé a ò ṣe ohun tí kò bọ́gbọ́n mu. Bí àpẹẹrẹ, tá a bá fẹ́ jáwọ́ nínú nínáwó jù bó ṣe yẹ, a lè pinnu pé a ò ní máa rajà àwìn tàbí ká pinnu láti máa mówó táṣẹ́rẹ́ lọ sọ́jà nígbà tá a bá fẹ lọ ra nǹkan. Rántí ohun tí Pọ́ọ̀lù sọ pé, “fífọkànsin Ọlọ́run pa pọ̀ pẹ̀lú ẹ̀mí ohun-moní-tómi” jẹ́ “ọ̀nà èrè ńlá.” Ó ṣàlàyé pé: “A kò mú nǹkan kan wá sínú ayé, bẹ́ẹ̀ ni a kò sì lè mú ohunkóhun jáde. Nítorí náà, bí a bá ti ní ohun ìgbẹ́mìíró àti aṣọ, àwa yóò ní ìtẹ́lọ́rùn pẹ̀lú nǹkan wọ̀nyí.” (1 Tímótì 6:6-8) Ǹjẹ́ àwa náà ní ìtẹ́lọ́rùn? Kíkọ́ béèyàn ṣe ń gbé ìgbésí ayé ṣe-bóo-ti-mọ, kéèyàn má sì fi ohunkóhun tí kò ní láárí kẹ́ ara rẹ̀ bà jẹ́ gba pé kéèyàn lè dúró lórí ìpinnu tó ṣe, kó sì lo ìkóra-ẹni-níjàánu. Ẹ̀kọ́ tó yẹ kéèyàn kọ́ nìyẹn lóòótọ́.

12, 13. (a) Àwọn ọ̀nà wo làwọn ìpàdé Kristẹni gbà nílò ìkóra-ẹni-níjàánu? (b) Àwọn apá ibòmíràn wo la tún ti nílò ìkóra-ẹni-níjàánu?

12 Lílọ sáwọn ìpàdé Kristẹni, àwọn àpéjọ àyíká, àtàwọn àpéjọ àgbègbè tún jẹ́ ọ̀nà àrà ọ̀tọ̀ kan láti kó ara wa níjàánu. Bí àpẹẹrẹ, ànímọ́ yẹn ṣe pàtàkì gan-an tá ò bá fẹ́ kí ọkàn wa máa ro tìhín, ro tọ̀hún nígbà tí ìtòlẹ́sẹẹsẹ bá ń lọ lọ́wọ́. (Òwe 1:5) Ìkóra-ẹni-níjàánu ni kò ní jẹ́ ká dí àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ nípa bíbá ẹni tó jókòó sí tòsí wa sọ̀rọ̀ dípò ká tẹ́tí bẹ̀lẹ̀jẹ́ sí ohun tí olùbánisọ̀rọ̀ ń sọ. Ṣíṣètò àwọn ìtòlẹ́sẹẹsẹ wa ká lè máa tètè dé sí àwọn ìpàdé tún gba ìkóra-ẹni-níjàánu. Síwájú sí i, a tún lè nílò ìkóra-ẹni-níjàánu láti wá àkókò tá a ó fi múra àwọn ìpàdé sílẹ̀ ká sì máa kópa nínú wọn.

13 Kíkó ara wa níjàánu nínú àwọn ohun kéékèèké yóò fún wa lókùn láti ṣe bẹ́ẹ̀ nínú àwọn ọ̀ràn ńlá. (Lúùkù 16:10) Ẹ ò rí i bó ṣe dára tó láti máa lo ìkóra-ẹni-níjàánu ká lè máa ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run àti àwọn ìtẹ̀jáde tá a gbé karí Bíbélì, ká máa kẹ́kọ̀ọ́ nínú wọn, ká sì máa ṣe àṣàrò lórí ohun tá a bá kà! Ẹ ò rí i pé ó bọ́gbọ́n mu gan-an láti lo ìkóra-ẹni-níjàánu nípa yíyẹra fún iṣẹ́ tí kò bójú mu, yíyẹra fún ọ̀rẹ́ burúkú, àti ṣíṣíwọ́ ìwà burúkú tá à ń hù, ká sì yẹra fún àwọn ìgbòkègbodò tó lè gbà àkókò ṣíṣeyebíye tó yẹ ká lò nínú ìṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run mọ́ wa lọ́wọ́! Jíjẹ́ kí ọwọ́ wa dí nínú iṣẹ́ ìsìn Jèhófà jẹ́ ohun tó dára gan-an láti dáàbò bo wá kúrò lọ́wọ́ àwọn nǹkan tó lè fà wá kúrò nínú Párádísè tẹ̀mí nínú ìjọ Jèhófà tó wà jákèjádò ayé.

Ẹ Jẹ́ Kí Ìkóra-Ẹni-Níjàánu Sọ Yín Di Géńdé

14. (a) Báwo làwọn ọmọdé ṣe ní láti kọ́ béèyàn ṣe ń lo ìkóra-ẹni-níjàánu? (b) Àǹfààní wo la lè rí nígbà táwọn ọmọdé bá tètè kọ́ irú ẹ̀kọ́ bẹ́ẹ̀ láti kékeré?

14 Ọmọ tá a ṣẹ̀ṣẹ̀ bí ò lè ní ìkóra-ẹni-níjàánu. Ìwé ìléwọ́ kan táwọn ògbógi nínú ìwà àwọn ọmọdé kọ ṣàlàyé pé: “Ìkóra-ẹni-níjàánu kì í ṣe ohun tá a bí mọ́ni tàbí ohun tó ń dé lójijì. Àwọn ìkókó àtàwọn ọmọ tá a ń fà ní tẹ̀ẹ̀tẹ́ nílò ìtọ́sọ́nà àti ìtìlẹ́yìn àwọn òbí wọn kí wọ́n tó lè bẹ̀rẹ̀ sí lo ìkóra-ẹni-níjàánu. . . . Bí àwọn òbí ṣe ń bójú tó wọn yẹn á jẹ́ kí ìkóra-ẹni-níjàánu wọn túbọ̀ máa pọ̀ sí i ní gbogbo ọdún tí wọ́n fi wà nílé ìwé.” Ìwádìí táwọn kan ṣe nípa àwọn ọmọdé tó wà lọ́mọ ọdún mẹ́rin fi hàn pé àwọn ọmọ tá a ti kọ́ ní béèyàn ṣe ń lo ìkóra-ẹni-níjàánu dé àyè kan “sábà máa ń dàgbà di ọ̀dọ́langba tó ń fara balẹ̀, wọ́n máa ń lókìkí, wọ́n máa ń láyà, wọ́n máa ń jẹ́ onígboyà àti ẹni tó ṣeé gbára lé.” Àwọn tí ò tíì bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ ẹ̀kọ́ yìí “sábà máa ń dá nìkan wà, nǹkan máa ń tètè sú wọn, wọ́n sì máa ń ya ìpátá. Wọ́n tètè máa ń juwọ́ sílẹ̀ nígbà tí ìṣòro bá dé, wọ́n tún máa ń sá fún ohun tó bá le.” Dájúdájú, kí ọmọ kan tó lè di àgbá tó dáa, ó gbọ́dọ̀ kọ́ béèyàn ṣe ń kó ara rẹ̀ níjàánu.

15. Kí ni àìní ìkóra-ẹni-níjàánu fi hàn, tó yàtọ̀ pátápátá sí ohun wo tí Bíbélì ní ká máa lépa?

15 Bákan náà, tá a bá fẹ di Kristẹni tó dàgbà di géńdé, a gbọ́dọ̀ kọ́ béèyàn ṣe ń kó ara rẹ̀ níjàánu. Àìní ìkóra-ẹni-níjàánu jẹ́ ẹ̀rí pé a ṣì jẹ́ ìkókó nípa tẹ̀mí. Bíbélì gbà wá níyànjú pé ká “dàgbà di géńdé nínú agbára òye.” (1 Kọ́ríńtì 14:20) Ohun tá à ń lépa ni pé ká “dé ìṣọ̀kanṣoṣo nínú ìgbàgbọ́ àti nínú ìmọ̀ pípéye nípa Ọmọ Ọlọ́run, tí a ó fi di géńdé ọkùnrin, tí a ó fi dé orí ìwọ̀n ìdàgbàsókè tí ó jẹ́ ti ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ Kristi.” Kí nìdí? Nítorí “kí a má bàa tún jẹ́ ìkókó mọ́, tí a ń bì kiri gẹ́gẹ́ bí nípasẹ̀ àwọn ìgbì òkun, tí a sì ń gbé síhìn-ín sọ́hùn-ún nípasẹ̀ gbogbo ẹ̀fúùfù ẹ̀kọ́ nípasẹ̀ ìwà àgálámàṣà àwọn ènìyàn, nípasẹ̀ àlùmọ̀kọ́rọ́yí nínú dídọ́gbọ́n hùmọ̀ ìṣìnà.” (Éfésù 4:13, 14) Ní kedere, kíkọ́ béèyàn ṣe ń kó ara rẹ̀ níjàánu ṣe pàtàkì gan-an fún ire tẹ̀mí wa.

Bá A Ṣe Lè Mú Kí Ìkóra-Ẹni-Níjàánu Wa Pọ̀ Sí I

16. Báwo ni Jèhófà ṣe ń pèsè ìrànlọ́wọ́?

16 A nílò ìrànlọ́wọ́ Ọlọ́run tá bá fẹ́ kí ìkóra-ẹni-níjàánu wa túbọ̀ pọ̀ sí i, ìrànlọ́wọ́ náà sì wà lárọ̀ọ́wọ́tó wa. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tó dà bíi dígí tó mọ́lẹ̀ kedere ń jẹ́ ká rí àwọn ibi tó ti yẹ ká ti ṣàtúnṣe, ó sì ń pèsè ìmọ̀ràn lórí ọ̀nà tá a ó gbà ṣe bẹ́ẹ̀. (Jákọ́bù 1:22-25) Àwọn arákùnrin wa onífẹ̀ẹ́ múra tán láti ràn wá lọ́wọ́. Àwọn Kristẹni alàgbà ń fòye báni lò nípa pípèsè ìrànlọ́wọ́. Jèhófà fúnra rẹ̀ máa ń fúnni ni ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ fàlàlà tá a ba tọrọ rẹ̀ nínú àdúrà wa. (Lúùkù 11:13; Róòmù 8:26) Nítorí náà, ẹ jẹ́ ká fi tayọ̀tayọ̀ lo àwọn ìpèsè wọ̀nyí. Àwọn àbá tó wà nínú àpótí tó wà lójú ìwé 21 lè ṣèrànwọ́.

17. Ìṣírí wo ni ìwé Òwe 24:16 fún wa?

17 Ó mà tuni nínú o, láti mọ̀ pé Jèhófà mọyì àwọn ìsapá wa nígbà tá a bá gbìyànjú láti múnú rẹ̀ dùn! Èyí yẹ kó ràn wá lọ́wọ́ láti máa bá a lọ ní sísapá láti ní ìkóra-ẹni-níjàánu púpọ̀ sí i. Láìka iye ìgbà tá a lè kọsẹ̀ sí, a ò gbọ́dọ̀ dáwọ́ dúró nínú ìsapá wa. “Olódodo lè ṣubú ní ìgbà méje pàápàá, yóò sì dìde dájúdájú.” (Òwe 24:16) Gbogbo ìgbà tá a bá jagun mólú ló yẹ kí inú wa máa dùn. A sì tún lè ní ìdánilójú pé inú Jèhófà dùn sí wa. Ẹlẹ́rìí kan sọ pé kó tó di pé òun ya ara ohun sí mímọ́ fún Jèhófà, ohun tóun máa ń ṣe ní gbogbo ìgbà tóun bá ti ṣàṣeyọrí ní yíyàgò fún sìgá mímú fún odindi ọ̀sẹ̀ kan ni pé, òun á fi owó tí ìkóra-ẹni-níjàánu ran òun lọ́wọ́ láti tọ́jú yìí ra ohun kan tó wúlò.

18. (a) Kí ni jíjà tá ń jà fitafita láti ní ìkóra-ẹni-níjàánu wé mọ́? (b) Ẹ̀rí ìdánilójú wo ni Jèhófà fún wa?

18 Lékè gbogbo rẹ̀, a gbọ́dọ̀ máa rántí pé ìkóra-ẹni-níjàánu wé mọ́ èrò inú àti ìmọ̀lára wa. A lè rí èyí nínú ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ pé: “Olúkúlùkù ẹni tí ń bá a nìṣó ní wíwo obìnrin kan láti ní ìfẹ́ onígbòónára sí i, ti ṣe panṣágà pẹ̀lú rẹ̀ ná nínú ọkàn-àyà rẹ̀.” (Mátíù 5:28; Jákọ́bù 1:14, 15) Ẹni tó bá ti kọ́ bó ṣe máa ṣàkóso èrò inú àti ìmọ̀lára rẹ̀ yóò rí i pé ó rọrùn láti ṣàkóso gbogbo ara òun pẹ̀lú. Nítorí náà, kì í ṣe pé a fẹ́ kí ìpinnu wa láti yẹra fún ṣíṣe ohun búburú lágbára sí i nìkan àmọ́ a tún fẹ́ yẹra fún ríronú nípa ohun búburú pẹ̀lú. Bí èròkerò bá wá sọ́kàn wa, ẹ jẹ́ ká gbá a dànù lójú ẹsẹ̀. A lè sá fún ìdẹwò tá a bá ń wojú Jésù tàdúràtàdúrà. (1 Tímótì 6:11; 2 Tímótì 2:22; Hébérù 4:15, 16) Bá a ṣe ń sa gbogbo ipá wa, a ó máa tẹ̀ lé ìmọ̀ràn inú Sáàmù 55:22, tó sọ pé: “Ju ẹrù ìnira rẹ sọ́dọ̀ Jèhófà fúnra rẹ̀, òun fúnra rẹ̀ yóò sì gbé ọ ró. Kì yóò jẹ́ kí olódodo ta gbọ̀n-ọ́n gbọ̀n-ọ́n láé.”

Ǹjẹ́ O Rántí?

• Àwọn ọ̀nà méjì wo ló yẹ ká gbà kó ara níjàánu?

• Kí ni lílo “ìkóra-ẹni-níjàánu nínú ohun gbogbo” túmọ̀ sí?

• Àwọn àbá tó ṣeé múlò wo nípa ìkóra-ẹni-níjàánu lo fiyè sí gidigidi lákòókò ìkẹ́kọ̀ọ́ wa yìí?

• Ibo ni ìkóra-ẹni-níjàánu ti ń bẹ̀rẹ̀?

[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]

[Àpótí/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 21]

Bá A Ṣe Lè Jẹ́ Kí Ìkóra-Ẹni-Níjàánu Wa Lágbára Sí I

• Ló o nínú àwọn ohun kéékèèké pàápàá

• Ṣàṣàrò lórí àǹfààní tó máa fún ọ nísinsìnyí àti lọ́jọ́ iwájú

• Fi àwọn ohun tí Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ sí rọ́pò àwọn ohun tó ní a ò gbọ́dọ̀ ṣe

• Gbá àwọn èròkerò dànù lójú ẹsẹ̀

• Jẹ́ kí àwọn ohun tó ń gbéni ró nípa tẹ̀mí máa wà nínú ọkàn rẹ

• Tẹ́wọ́ gba ìrànlọ́wọ́ táwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ tó dàgbà dénú lè fún ọ

• Yàgò fún àwọn ipò tó lè fà ọ́ sínú ìdẹwò

• Gbàdúrà pé kí Ọlọ́run ràn ọ́ lọ́wọ́ lákòókò ìdẹwò

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18, 19]

Ìkóra-ẹni-níjàánu ń mú ká ṣe ohun tó dáa