Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwọn Obìnrin Kristẹni Olóòótọ́ Jẹ́ Ẹni Ọ̀wọ́n Tó Ń Sin Ọlọ́run

Àwọn Obìnrin Kristẹni Olóòótọ́ Jẹ́ Ẹni Ọ̀wọ́n Tó Ń Sin Ọlọ́run

Àwọn Obìnrin Kristẹni Olóòótọ́ Jẹ́ Ẹni Ọ̀wọ́n Tó Ń Sin Ọlọ́run

“Òòfà ẹwà lè jẹ́ èké, ẹwà ojú sì lè jẹ́ asán; ṣùgbọ́n obìnrin tí ó bẹ̀rù Jèhófà ni ẹni tí ó gba ìyìn fún ara rẹ̀.”—ÒWE 31:30.

1. Kí ni ìyàtọ̀ tó wà láàárín bí Jèhófà ṣe ń wo ẹ̀wà àti bí ayé ṣe ń wò ó?

 ÀWỌN èèyàn nínú ayé lónìí ka ìrísí ẹnì kan sí pàtàkì gan-an àgàgà ìrísí obìnrin. Ṣùgbọ́n ní ti Jèhófà, ohun tó jẹ ẹ́ lógún jù lọ ni bí ẹ̀wà ẹnì kan ṣe rí nínú lọ́hùn-ún èyí tó jẹ́ pé bí irú ẹnì bẹ́ẹ̀ ṣe ń dàgbà sí i, ni ẹ̀wà náà ṣe máa ń pọ̀ si i. (Òwe 16:31) Nítorí náà, Bíbélì gbà àwọn obìnrin níyànjú pé: “Kí ọ̀ṣọ́ yín má sì jẹ́ ti irun dídì lóde ara àti ti fífi àwọn ohun ọ̀ṣọ́ wúrà sára tàbí ti wíwọ àwọn ẹ̀wù àwọ̀lékè, ṣùgbọ́n kí ó jẹ́ ẹni ìkọ̀kọ̀ ti ọkàn-àyà nínú aṣọ ọ̀ṣọ́ tí kò lè díbàjẹ́ ti ẹ̀mí ìṣejẹ́ẹ́jẹ́ẹ́ àti ti ìwà tútù, èyí tí ó níye lórí gidigidi lójú Ọlọ́run.”—1 Pétérù 3:3, 4.

2, 3. Báwo ni àwọn obìnrin ṣe kópa nínú títan ìhìn rere náà kálẹ̀ ní ọ̀rúndún kìíní, báwo sì ni a ṣe sọ èyí tẹ́lẹ̀?

2 Ọ̀pọ̀ obìnrin tá a mẹ́nu kàn nínú Bíbélì ló fi irú ẹ̀mí tó yẹ fún ìyìn yìí hàn. Ní ọ̀rúndún kìíní, díẹ̀ nínú àwọn wọ̀nyí ní àǹfààní láti ṣe ìṣẹ́ ìránṣẹ́ fún Jésù àtàwọn àpọ́sítélì rẹ̀. (Lúùkù 8:1-3) Nígbà tó yá, àwọn obìnrin Kristẹni di ajíhìnrere onítara; àwọn mìíràn ṣe ìtìlẹ́yìn fún àwọn ọkùnrin Kristẹni kan tó ń mú ipò iwájú títí kan àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù; àwọn mìíràn fi ẹ̀mí aájò àlejò tó tayọ hàn, kódà wọ́n yọ̀ǹda ilé wọn fún ìpàdé ìjọ.

3 A sọ tẹ́lẹ̀ nínú Ìwé Mímọ́ pé Jèhófà yóò lo àwọn obìnrin lọ́nà kan tó kàmàmà láti mú àwọn ète rẹ̀ ṣẹ. Bí àpẹẹrẹ, Jóẹ́lì 2:28, 29 sọ tẹ́lẹ̀ pé àtọkùnrin àtobìnrin, àtọmọdé àtàgbà ni yóò gbà ẹ̀mí mímọ́ tí wọn yóò sì kópa nínú títan ìhìn rere Ìjọba náà kálẹ̀. Àsọtẹ́lẹ̀ yẹn bẹ̀rẹ̀ sí í ṣẹ ní Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Tiwa. (Ìṣe 2:1-4, 16-18) Díẹ̀ lára àwọn obìnrin tá a fi ẹ̀mí yàn la fún ní àgbàyanu ẹ̀bùn ẹ̀mí irú bíi sísọ àsọtẹ́lẹ̀. (Ìṣe 21:8, 9) Nípasẹ̀ ìtara wọn nínú ìṣẹ́ òjíṣẹ́, àwọn arábìnrin olóòótọ́ tó jẹ́ ẹgbẹ́ ọmọ ogun ńlá tẹ̀mí yìí kópa nínú bí ẹ̀sìn Kristẹni ṣe yára tàn kálẹ̀ ní ọ̀rúndún kìíní. Kódà nígbà tó fi máa di ọdún 60 Sànmánì Tiwa, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé nípa ìhìnrere náà pé a ‘tí wàásù rẹ̀ nínú gbogbo ìṣẹ̀dá tí ń bẹ lábẹ́ ọ̀run.’—Kólósè 1:23.

A Yìn Wọ́n Nítorí Ìgboyà, Ìtara, àti Ẹ̀mí Aájò Àlejò Tí Wọ́n Ní

4. Kí ni àwọn ohun tó mú kí Pọ́ọ̀lù yin àwọn obìnrin mélòó kan nínú ìjọ Kristẹni ọ̀rúndún kìíní?

4 Bí àpẹẹrẹ, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù mọyì iṣẹ́ òjíṣẹ́ àwọn obìnrin kan dáadáa gẹ́gẹ́ bí àwọn Kristẹni alábòójútó náà ṣe mọyì iṣẹ́ òjíṣẹ́ àwọn obìnrin onítara lónìí. Lára àwọn obìnrin tí Pọ́ọ̀lù dárúkọ ni “Tírífénà àti Tírífósà, àwọn obìnrin tí ń ṣiṣẹ́ kára nínú Olúwa” àti “Pésísì olùfẹ́ wa ọ̀wọ́n, nítorí ó ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ òpò nínú Olúwa.” (Róòmù 16:12) Pọ́ọ̀lù kọ̀wé nípa Yúódíà àti Síńtíkè pé wọ́n “làkàkà ní ìfẹ̀gbẹ́kẹ̀gbẹ́ pẹ̀lú [òun] nínú ìhìn rere.” (Fílípì 4:2, 3) Pírísílà àti Ákúílà ọkọ rẹ̀ náà sìn ní ìfẹ̀gbẹ́kẹ̀gbẹ́ pẹ̀lú Pọ́ọ̀lù. Òun àti Ákúílà tiẹ̀ “fi ọrùn ara wọn wewu” nítorí Pọ́ọ̀lù, ìyẹn ló sún un láti kọ̀wé pé, ‘Kì í ṣe èmi nìkan ṣùgbọ́n gbogbo ìjọ àwọn orílẹ̀-èdè pẹ̀lú ń fi ọpẹ́ fún wọn.’—Róòmù 16:3, 4; Ìṣe 18:2.

5, 6. Àwọn ọ̀nà wo ni Pírísílà gbà fi àpẹẹrẹ rere lélẹ̀ fàwọn arábìnrin lónìí?

5 Kí ló fà á tí Pírísílà fi nítara tó sì nígboyà bẹ́ẹ̀? Àkọsílẹ̀ kan tó wà nínú Ìṣe 18:24-26, sọ ohun tó fà á níbi tá a ti kà nípa bó ṣe ti ọkọ rẹ̀ lẹ́yìn láti ran Àpólò ẹni tó lẹ́bùn ọ̀rọ̀ sísọ lọ́wọ́ kí ó lè mọ̀ nípa òtítọ́ tí kò tíì mọ̀. Nígbà náà, ó hàn gbangba pé Pírísílà máa ń kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run déédéé, ó sì máa ń fetí sí ẹ̀kọ́ àwọn àpọ́sítélì tọkàntọkàn. Ó wá tipa bẹ́ẹ̀ ní àwọn ànímọ́ dáradára to sọ ọ́ di ẹni ọ̀wọ́n lójú Ọlọ́run àti ọkọ rẹ̀, ó sì di ẹni tó wúlò nínú ìjọ Kristẹni àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀. Bákan náà, àwọn tó tún jẹ́ ẹni ọ̀wọ́n lónìí ni ọ̀pọ̀ àwọn obìnrin Kristẹni tó ń ṣiṣẹ́ kára, tí wọ́n ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì taápọntaápọn, tí wọ́n sì ń jẹ oúnjẹ tẹ̀mí tí Jèhófà ń pèsè nípasẹ̀ “olóòótọ́ ìríjú náà.”—Lúùkù 12:42.

6 Ákúílà àti Pírísílà ní ẹ̀mí aájò àlejò lọ́nà tó tayọ. Ilé wọn ni Pọ́ọ̀lù gbé nígbà tó ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú wọn ní Kọ́ríńtì níbí tí wọ́n tí ń ṣòwò àgọ́ pípa. (Ìṣe 18:1-3) Nígbà táwọn tọkọtaya náà kó lọ sí Éfésù, àti ìgbà tí wọ́n lọ sí Róòmù, wọn kò jáwọ́ nínú fífi ẹ̀mí aájò àlejò Kristẹni hàn, kódà wọ́n yọ̀ǹda ilé wọn fún àwọn ìpàdé ìjọ. (Ìṣe 18:18, 19; 1 Kọ́ríńtì 16:8, 19) Nímífà àti Màríà tó jẹ́ ìyá Jòhánù tí àpèlé rẹ̀ ń jẹ́ Máàkù náà yọ̀ǹda ilé wọn fún àwọn ìpàdé ìjọ.—Ìṣe 12:12; Kólósè 4:15.

Wọ́n Ṣeyebíye Gan-an Lónìí

7, 8. Iṣẹ́ ìsìn mímọ́ tó ṣeé gbóríyìn fún wo làwọn obìnrin Kristẹni ti ṣe lóde òní, kí ló sì yẹ kó dá wọ́n lójú?

7 Gẹ́gẹ́ bó ṣe rí ní ọ̀rúndún kìíní, àwọn obìnrin Kristẹni olóòótọ́ lóde òní pẹ̀lú ń kópa pàtàkì nínú mímú ète Ọlọ́run ṣẹ, pàápàá nínú iṣẹ́ wíwàásù ìhìn rere. Ẹ wo iṣẹ́ rere táwọn arábìnrin wọ̀nyí ti ṣe! Bí àpẹẹrẹ, wo Gwen, ẹni tó fi ìṣòtítọ́ sin Jèhófà fún ohun tó lé ní àádọ́ta ọdún, kó tó kú ní 2002. Ọkọ rẹ̀ sọ pé: “Gbogbo àwọn ara ìlú wa ló mọ Gwen dáadáa pé ó jẹ́ ajíhìnrere tó nítara gan-an. Ó sì gbà pé gbogbo èèyàn pátá ni Jèhófà nífẹ̀ẹ́ sí, tí wọn yóò sì rí ìmúṣẹ àwọn ìlérí rẹ̀. Ìdúróṣinṣin rẹ̀ sí Ọlọ́run, sí ètò àjọ rẹ̀, àti sí ìdílé wa, pa pọ̀ pẹ̀lú ìṣírí onífẹ̀ẹ́ tó máa ń fún wa nígbà tá a bá rẹ̀wẹ̀sì ti jẹ́ ìtìlẹyìn ńlá fún èmi àtàwọn ọmọ wa jálẹ̀ ọ̀pọ̀ ọdún tó lérè nínú tá a jọ lò pa pọ̀. Àárò rẹ̀ sọ wá gan-an ni.” Ọdún mọ́kànlélọ́gọ́ta ni Gwen àti ọkọ rẹ̀ lò pa pọ̀ gẹ́gẹ́ bí tọkọtaya.

8 Ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ àwọn obìnrin Kristẹni bóyá tí wọ́n ti ṣègbéyàwó tàbí tí wọ́n kò tíì ṣègbéyàwó ló ń sìn bí òjíṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà àti míṣọ́nnárì. Wọ́n ń tan ìhìn Ìjọba náà kálẹ̀, bóyá ní àwọn ìpínlẹ̀ téèyàn ti pọ̀ tàbí ní àdádó, àwọn ohun kòṣeémáàní nìkan sì ti tẹ́ wọn lọ́rùn. (Ìṣe 1:8) Ọ̀pọ̀ ló ti yááfì ilé kíkọ́ tàbí ọmọ bíbí kí wọ́n bàa lè túbọ̀ sin Jèhófà ní kíkún. Ọ̀pọ̀ ló sì ń fi ìdúróṣinṣin ti ọkọ wọn lẹ́yìn kó lè máa sìn gẹ́gẹ́ bí alábòójútó àyíká, nígbà tí ọ̀pọ̀ àwọn arábìnrin sì ń sìn ní àwọn ilé Bẹ́tẹ́lì kárí ayé. Ó dájú pé àwọn arábìnrin tó ní ẹ̀mí ìfara ẹni rúbọ yìí wà lára àwọn “ohun fífani-lọ́kàn-mọ́ra tí ń bẹ nínú gbogbo orílẹ̀-èdè” tó ń fi ògo kún ilé Jèhófà.—Hágáì 2:7.

9, 10. Báwo ni àwọn tó jẹ́ ara ìdílé mélòó kan ṣe sọ bí wọ́n ṣe mọyì àpẹẹrẹ rere táwọn Kristẹni aya àti ìyá fi lélẹ̀?

9 Lóòótọ́, ọ̀pọ̀ Kristẹni obìrin ló ni ìdílé tí wọn ń bójú tó; síbẹ̀ wọ́n ń fi ire Ìjọba sí ipò àkọ́kọ́. (Mátíù 6:33) Arábìnrin aṣáájú ọ̀nà kan tí kò tíì lọ́kọ kọ̀wé pé: “Ìgbàgbọ́ màmá mi tí kò yẹ̀ àti àpẹẹrẹ rere rẹ̀ kó ipa pàtàkì nínú bí mo ṣe di aṣáájú ọ̀nà. Ká sọ tòótọ́, òun ni aṣáájú ọ̀nà tí mo máa ń bá ṣiṣẹ́ jù lọ.” Ọkọ kan sọ nípa ìyàwó rẹ̀ tó jẹ́ ìyá àwọn ọmọbìnrin márùn tó ti dàgbà pé: “Ilé wa máa ń wà ní mímọ́ tónítóní ó sì máa ń wà létòlétò. Bonnie kì í jẹ́ kí ẹrù pọ̀ jù níbẹ̀, kì í sì í jẹ́ kó rí wúruwùru, ìyẹn sì ti jẹ́ kí ìdílé wa lè pọkàn pọ̀ sórí lílépa ohun tẹ̀mí. Ìtìlẹ́yìn rẹ̀ lórí bá a ṣe lè fi ọgbọ́n ṣọ́ owó ná ti jẹ́ kó ṣeé ṣe fún mi láti ṣe iṣẹ́ àbọ̀ṣẹ́ fún odindi ọdún méjìlélọ́gbọ̀n gbáko, ìyẹn sì ti jẹ́ kí n ní àkókò púpọ̀ sí i fún ìdílé wa àti àwọn nǹkan tẹ̀mí. Ìyàwó mi tún jẹ́ kí àwọn ọmọ mọ ìníyelórí jíjẹ́ òṣìṣẹ́ aláápọn. Kò sí ohun mìíràn tí mo lè ṣe ju kí n máa dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀.” Lónìí, àwọn tọkọtaya yìí ń sìn ní orílé iṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà lágbàáyé.

10 Ọkọ kan kọ̀wé nípa ìyàwó rẹ̀ tó jẹ́ ìyá àwọn ọmọ tó ti dàgbà pé: “Àwọn ànímọ́ tí mó gbádùn jù lára Susan ni bó ṣe nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run àti àwọn èèyàn lọ́nà tó ga, bákan náà, bó ṣe jẹ́ olóye, tó ní ẹ̀mí ìfọ̀rọ̀rora ẹni wò, tó sì jẹ́ olóòótọ́. Ohun tó máa ń ní lọ́kàn nígbà gbogbo ni pé ohun tó dára jù lọ ló yẹ ká fún Jèhófà, ìlànà yìí ló sì máa ń lò fún ara rẹ̀ gẹ́gẹ́ bi ìránṣẹ́ Ọlọ́run àti gẹ́gẹ́ bí ìyá.” Nítorí pé ìyàwó rẹ̀ tì í lẹ́yìn, ọkọ yìí tí ní àwọn àǹfààní tẹ̀mí bíi sísìn gẹ́gẹ́ bí alàgbà, aṣáájú ọ̀nà, adelé alábòójútó àyíká àti ara Ìgbìmọ̀ Alárinà Ilé Ìwòsàn. Àwọn obìnrin wọ̀nyí ṣeyebíye gan-an lójú ọkọ wọn, lójú àwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ wọn àti lékè gbogbo rẹ̀, lójú Jèhófà!—Òwe 31:28, 30.

Àwọn Obìnrin Tí Kò Lọ́kọ, Síbẹ̀ Tí Wọ́n Jẹ́ Ẹni Ọ̀wọ́n

11. (a) Báwo ni Jèhófà ṣe fi àníyàn rẹ̀ nípa àwọn obìnrin olóòótọ́ hàn, pàápàá àwọn opó? (b) Kí ló yẹ kó dá àwọn Kristẹni opó àtàwọn Kristẹni olóòótọ́ arábìnrin tí kò lọ́kọ lójú?

11 Jèhófà sábà máa ń fi hàn pé òun ń ṣàníyàn nípa àwọn opó. (Diutarónómì 27:19; Sáàmù 68:5; Aísáyà 10:1, 2) Kò sì tíì yí padà. Ire àwọn opó sì ń jẹ ẹ́ lọ́kàn, kì í wá ṣe tiwọn nìkan o, ṣùgbọ́n ire àwọn ìyá anìkàntọ́mọ, ire àwọn obìnrin tó yàn láti máà lọ́kọ àti tàwọn tí kò tíì rí ọkọ Kristẹni tó tẹ́ wọn lọ́rùn tún jẹ ẹ́ lọ́kàn pẹ̀lú. (Málákì 3:6; Jákọ́bù 1:27) Tó o bá wà lára àwọn tó ń fi ìṣòtítọ́ sin Jèhófà láì sí àtìlẹ́yìn ọkọ tó jẹ́ Kristẹni, a fẹ́ kó o mọ̀ dájú pé o jẹ́ ẹni ọ̀wọ́n lójú Ọlọ́run.

12. (a) Báwo làwọn Kristẹni arábìnrin kan ṣe fì hàn pé àwọn jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà? (b) Kí ni ohun tí díẹ̀ lára àwọn arábìnrin wa ń bá yí?

12 Bí àpẹẹrẹ, wo àwọn Kristẹni arábìnrin wa tí kò tíì lọ́kọ nítorí pé wọ́n ń fi ìdúróṣinṣin ṣègbọràn sí ìmọ̀ràn Jèhófà láti ṣègbéyàwó “kìkì nínú Olúwa.” (1 Kọ́ríńtì 7:39; Òwe 3:1) Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run mú un dá wọn lójú pé: “[Jèhófà] yóò hùwà lọ́nà ìdúróṣinṣin sí ẹni ìdúróṣinṣin.” (2 Sámúẹ́lì 22:26) Síbẹ̀, ìjàkadì ńlá ni bí wọ́n ṣe wà láì lọ́kọ yẹn jẹ́ fún èyí tó pọ̀ jù nínú wọn. Arábìnrin kan sọ pé: “Mo pinnu pé máa lọ́kọ kìkì nínú Olúwa, ṣùgbọ́n àìmọye ìgbà ni mo ti sunkún nígbà tí mó bá ń wo àwọn ọ̀rẹ́ mi tí wọ́n ń fẹ́ àwọn arákùnrin tó ń ṣe dáadáa tí èmi sì wa láìlọ́kọ.” Arábìnrin mìíràn sọ pé: “Mo ti sin Jèhófà fún ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n báyìí. Síbẹ̀, ìpinnu mi ni láti jẹ́ adúróṣinṣin, ṣùgbọ́n bí mo ṣe máa ń nímọ̀lára ìdánìkanwà yìí sábà máa ń bà mí nínú jẹ́.” Ó fi kún pé: “Àwọn arábìnrin bíi tèmi ń fẹ́ ìṣírí.” Báwo la ṣe lè ran irú àwọn adúróṣinṣin bẹ́ẹ̀ lọ́wọ́?

13. (a) Kí la rí kọ́ nínú àpẹẹrẹ àwọn tó ń ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ ọmọbìnrin Jẹ́fútà? (b) Àwọn ọ̀nà mìíràn wo lá tún lè gbà fi hàn pé à bìkítà fún àwọn arábìnrin tí kò lọ́kọ nínú ìjọ wa?

13 Ohun kan tó ṣẹlẹ̀ láyé ọjọ́un fún wa ní àpẹẹrẹ ọ̀nà kan tá a lè gbà ṣèrànwọ́. Nígbà tí ọmọbìnrin Jẹ́fútà fi àǹfààní láti lọ́kọ du ara rẹ̀, àwọn èèyàn mọ̀ pé ńṣe ló fara rẹ̀ rúbọ. Kí ni wọ́n ṣe láti fún un ní ìṣírí? “Láti ọdún dé ọdún, àwọn ọmọbìnrin Ísírẹ́lì a lọ láti gbóríyìn fún ọmọbìnrin Jẹ́fútà tí í ṣe ọmọ Gílíádì, ní ọjọ́ mẹ́rin lọ́dún.” (Àwọn Onídàájọ́ 11:30-40) Bákan náà, ó yẹ ká gbóríyìn tọkàntọkàn fún àwọn arábìnrin wa tí kò lọ́kọ tí wọ́n sì ń fi ìdúróṣinṣin ṣègbọràn sí òfin Ọlọ́run. a Ọ̀nà mìíràn wo la tún lè gbà fi hàn pé a bìkítà? Nígbà tá a bá ń gbàdúrà, ó yẹ ká bẹ Jèhófà pé kó ti irú àwọn arábìnrin olóòótọ́ tó jẹ́ ẹni ọ̀wọ́n bẹ́ẹ̀ lẹ́yìn kí wọ́n lè máa fi ìdúróṣinṣin bá ìṣẹ́ ìsìn wọn lọ. Ó yẹ ká jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé Jèhófà àti gbogbo ìjọ Kristẹni nífẹ̀ẹ́ wọn àti pé a mọyì wọn dáadáa.—Sáàmù 37:28.

Bí Àwọn Òbí Anìkàntọ́mọ Ṣe Lè Ṣàṣeyọrí

14, 15. (a) Kí nìdí tó fi yẹ kí àwọn Kristẹni tó jẹ́ ìyá anìkàntọ́mọ ké pe Jèhófà fún ìrànlọ́wọ́? (b) Báwo ni àwọn òbí anìkàntọ́mọ ṣe lè ṣiṣẹ́ ní ìbámu pẹ̀lú àdúrà wọn?

14 Àwọn Kristẹni obìnrin tó jẹ́ òbí anìkàntọ́mọ náà ń dojú kọ ọ̀pọ̀ ìṣòro. Àmọ́ ṣá o, wọ́n lè yíjú sí Jèhófà fún ìrànlọ́wọ́ láti tọ́ àwọn ọmọ wọn ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ìlànà Bíbélì. Ká sòótọ́, tó o bá jẹ́ òbí anìkàntọ́mọ, kò lè ṣeé ṣe láti ṣe bí bàbá àti ìyá ní gbogbo ọ̀nà. Síbẹ̀síbẹ̀, tó o bá fi ìgbàgbọ́ béèrè fún ìrànlọ́wọ́ Jèhófà, yóò ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti bójú tó èyí tó pọ̀ jù lọ nínú ẹrù iṣẹ́ rẹ. Bí àpẹẹrẹ: Ká sọ pé o ru ẹrù iṣu kan tó wúwo, tí ibi tó ò ń gbé e lọ sì jìnnà. Bí ọ̀rẹ́ rẹ kan bá ń wa mọ́tò kọjá tó sì sọ pé kí o wọlé kí òun bá ẹ gbé ẹrù náà délé, ṣé wàá wọ mọ́tò náà àbí ò kò ní wọ̀ ọ́? Ó dájú pé wàá wọ̀ ọ́! Bákan náà, má ṣe gbìyànjú láti máa dá gbé àwọn ẹrù ìnira rẹ nígbà tó o lè sọ fún Jèhófà pé kí ó ràn ẹ́ lọ́wọ́. Kódà ó sọ pé kí o ké pe òun. Sáàmù 68:19 sọ pé: “Ìbùkún ni fún Jèhófà, ẹni tí ń bá wa gbé ẹrù lójoojúmọ́.” Bákan náà, 1 Pétérù 5:7 rọ̀ wá láti kó gbogbo àníyàn wa lé Jèhófà “nítorí ó bìkítà fún [wa].” Nítorí náà, bí àwọn ìṣòro àti àníyàn bá dẹ́rù pa yín, ẹ sọ ohun tó ń dẹ́rù pa yín yẹn fún Bàbá yín ọ̀run, kí ẹ sì máa ṣe bẹ́ẹ̀ “láìdabọ̀.”—1 Tẹsalóníkà 5:17; Sáàmù 18:6; 55:22.

15 Bí àpẹẹrẹ, ká sọ pé o jẹ́ ìyá kan, kò sí iyèméjì níbẹ̀ pé wàá máa ṣàníyàn lórí ipa tí ojúgbà lè ní lórí àwọn ọmọ rẹ ní ilé ìwé tàbí àwọn àdánwò tí wọ́n lè dojú kọ látàrí pé wọ́n ń di ìwà títọ́ mú. (1 Kọ́ríńtì 15:33) Àwọn ohun tó yẹ kéèyàn ṣàníyàn nípa rẹ̀ ni lóòótọ́. Ṣùgbọ́n àwọn ọ̀ràn téèyàn lè gbàdúrà lé lórí ni wọ́n pẹ̀lú. Kí ló dé tí o kò gbàdúrà nípa irú àwọn ọ̀ràn bẹ́ẹ̀ ṣáájú káwọn ọmọ rẹ tó lọ sílé ìwé, bóyá lẹ́yìn tẹ́ ẹ bá ṣàyẹ̀wò ẹ̀kọ́ ojoojúmọ́ pa pọ̀ tán? Àdúrà àtọkànwá to ṣe ṣàkó máa ń wọ àwọn ọmọ lọ́kàn ṣinṣin. Lékè gbogbo rẹ̀, ẹ ó rí ìbùkún Jèhófà gbà nígbà tẹ́ ẹ bá fi sùúrù làkàkà láti tẹ Ọ̀rọ̀ rẹ̀ mọ́ àwọn ọmọ yín lọ́kàn. (Diutarónómì 6:6, 7; Òwe 22:6) Má gbàgbé pé “ojú Jèhófà ń bẹ lára àwọn olódodo, etí rẹ̀ sì ṣí sí ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ wọn.”—1 Pétérù 3:12; Fílípì 4:6, 7.

16, 17. (a) Kí ni ọmọkùnrin kan sọ nípa ìfẹ́ tí ìyá rẹ̀ fi hàn? (b) Báwo ni ọwọ́ tí ìyá náà fi mú nǹkan tẹ̀mí ṣe nípa lórí àwọn ọmọ rẹ̀?

16 Wo àpẹẹrẹ Olivia, tó bí ọmọ mẹ́fà. Ọkọ rẹ̀ tó jẹ́ aláìgbàgbọ́ sá lọ lẹ́yìn tó bí èyí tó gbẹ́yìn nínú àwọn ọmọ rẹ̀, ṣùgbọ́n ńṣe lóbìnrin yìí múra gírí láti gbé ẹrù iṣẹ́ kíkọ́ àwọn ọmọ náà ní ọ̀nà Ọlọ́run. Darren, ọmọkùnrin Olivia to ti di ẹni ọdún mọ́kànlélọ́gbọ̀n báyìí, tó sì ń sìn gẹ́gẹ́ bí alàgbà àti aṣáájú ọ̀nà, kò ju ọmọ ọdún márùn lọ nígbà yẹn. Ohun tó túbọ̀ fi kún àníyàn Olivia ni àìsàn ńlá kan tó kọ lu Darren, àìsàn náà sì ń yọ ọ́ lẹ́nu di bá a ti ń sọ̀rọ̀ yìí. Nígbà tí Darren ń rántí ìgbà tó wà lọ́mọdé, ó kọ̀wé pé: “Mò ṣì lè rántí bí mo ṣe máa ń jókòó lórí ibùsùn nílé ìwòsàn tí mo bá ń retí Màmá. Màmá máa ń jókòó sẹ́gbẹ̀ẹ́ mi, ó sì máa ń ka Bíbélì fún mi lójoojúmọ́. Lẹ́yìn náà, yóò wá kọrin Ìjọba náà to sọ pé ‘A Dupẹ Lọwọ Rẹ, Jehofa.’ b Títí dòní yìí, orin yìí ni orin Ìjọba tí mo gbádùn jù lọ.”

17 Ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Jèhófà àti ìfẹ́ tí Olivia ní fún Ọlọ́run ló ràn án lọ́wọ́ láti ṣàṣeyọrí gẹ́gẹ́ bí ìyá anìkàntọ́mọ. (Òwe 3:5, 6) Ànímọ́ rere tó ní hàn nínú góńgó tó gbé kalẹ̀ fún àwọn ọmọ rẹ̀ láti máa lépa. Darren sọ pé: “Màmá máa ń gbà wá níyànjú láti lépa ìṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún. Ìyẹn ló jẹ́ kí èmi àti mẹ́rin nínú àwọn arábìnrin mi márùn bẹ̀rẹ̀ ìṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún. Síbẹ̀síbẹ̀, Màmá ò fi èyí yangàn rí lójú àwọn mìíràn. Mò ń sapá gan-an láti ní àwọn ànímọ́ dáradára wọ̀nyí.” Lóòótọ́, kì í ṣe gbogbo àwọn ọmọ ló máa ń sin Ọlọ́run nígbà tí wọ́n bá dàgbà tán bíi ti àwọn ọmọ Olivia. Ṣùgbọ́n, bí ìyá kan bá ṣe gbogbo ohun tó lè ṣe láti gbé ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ìlànà Bíbélì, ó dájú pé irú ìyá bẹ́ẹ̀ yóò rí ìtọ́sọ́nà àti ìtìlẹ́yìn onífẹ̀ẹ́ Jèhófà.—Sáàmù 32:8.

18. Báwo la ṣe lè fi hàn pé a mọyì ìjọ Kristẹni tí Jèhófà pèsè?

18 Èyí tó pọ̀ jù lọ nínú àwọn ìtìlẹyìn tí Ọlọ́run ń pèsè ló ń wá nípasẹ̀ ìjọ Kristẹni, àwọn ìtòlẹ́sẹẹsẹ oúnjẹ tẹ̀mí tó ṣe déédéé, ẹgbẹ́ àwọn ará tó jẹ́ Kristẹni àti àwọn “ẹ̀bùn [tí ó jẹ́] ènìyàn” tí wọ́n dàgbà dénú nípa tẹ̀mí. (Éfésù 4:8) Àwọn alàgbà tó jẹ́ adúróṣinṣin ń ṣiṣẹ́ kára láti gbé ìjọ ró, wọ́n pàfiyèsí àrà ọ̀tọ̀ sí ohun tí “àwọn ọmọ òrukàn àti àwọn opó nínú ìpọ́njú wọn” nílò. (Jákọ́bù 1:27) Nítorí náà, ẹ sún mọ́ àwọn èèyàn Ọlọ́run, kí ẹ má ṣe dá nìkan wà láé.—Òwe 18:1; Róòmù 14:7.

Ìtẹríba Jẹ́ Ànímọ́ Tó Fani Mọ́ra

19. Kí nìdí tí ìtẹríba aya kan kò fi túmọ̀ sí pé kò jámọ́ nǹkan kan, àpẹẹrẹ wo nínú Bíbélì ló sì jẹ́rìí sí èyí?

19 Jèhófà dá obìnrin láti jẹ́ àṣekún fún ọkùnrin. (Jẹ́nẹ́sísì 2:18) Nítorí náà, bí aya bá tẹrí ba fún ọkọ rẹ̀, kò fi hàn pé kò jámọ́ nǹkan kan. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó buyì kún obìnrin kan, ó sì fún un láyè láti lo àwọn ẹ̀bùn àbínibí rẹ̀ ní ìbámu pẹ̀lú ìfẹ́ Ọlọ́run. Òwe orí 31 ṣàlàyé oríṣiríṣi iṣẹ́ aya kan tó dáńgájíá ní Ísírẹ́lì ìgbàanì. Ó máa ń ṣèrànwọ́ fún àwọn aláìní, ó máa ń gbin ọgbà àjàrà, ó sì máa ń ra pápá. Bẹ́ẹ̀ ni o, “ọkàn-àyà olúwa rẹ̀ gbẹ́kẹ̀ lé e, kò sì ṣaláìní èrè.”—Ẹsẹ 11, 16, 20.

20. (a) Ojú wo ló yẹ kí Kristẹni obìnrin kan fi wo agbára tàbí ẹ̀bùn tí Ọlọ́run fún un? (b) Àwọn ànímọ́ dáradára wo ni Ẹ́sítérì fi hàn, báwo sì ni Jèhófà ṣe lò ó nítorí ìyẹn?

20 Aya kan tó bá mẹ̀tọ́mọ̀wà kì í lépa bí yóò ṣe yọrí ọlá ju ọkọ rẹ̀ lọ tàbí kó máa figa gbága pẹ̀lú ọkọ rẹ̀. (Òwe 6:18) Kì í lépa bí yóò ṣe kọ́kọ́ tẹ́ ara rẹ̀ lọ́rùn nínú iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ ṣùgbọ́n ó máa ń lo ẹ̀bùn tí Ọlọ́run fún un, kìkì láti fi sin àwọn ẹlòmíràn, ìyẹn ìdílé rẹ̀, àwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ rẹ̀, àwọn aládùúgbò rẹ̀ àti lékè gbogbo rẹ̀, Jèhófà. (Gálátíà 6:10; Títù 2:3-5) Gbé àpẹẹrẹ Ayaba Ẹ́sítérì inú Bíbélì yẹ̀ wò. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé arẹwà obìnrin ni, ó mẹ̀tọ́mọ̀wà ó sì nítẹríba. (Ẹ́sítérì 2:13, 15) Nígbà tó lọ́kọ, ó ní ọ̀wọ̀ tó jinlẹ̀ fún ọkọ rẹ̀, ìyẹn Ọba Ahasuwérúsì, kò sì ṣe bíi ti Fáṣítì tó jẹ́ ayaba tẹ́lẹ̀. (Ẹ́sítérì 1:10-12; 2:16, 17) Bákan náà, tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ ni Ẹ́sítérì fi gbà pẹ̀lú ẹ̀gbọ́n rẹ̀ Módékáì lórí àwọn ọ̀ràn tó bójú mu, kódà lẹ́yìn ìgbà tó dì ayaba. Ṣùgbọ́n ìyẹn ò túmọ̀ sí pé dọ̀bọ̀sìyẹsà ni Ẹ́sítérì o! Tìgboyàtìgboyà ló fi tú àṣírí Hámánì, ọkùnrin alágbára kan báyìí tí kò láàánú tó dìtẹ̀ láti pa àwọn Júù run. Jèhófà lò Ẹ́sítérì lọ́nà ìyanu láti pa àwọn ènìyàn rẹ̀ mọ́.—Ẹ́sítérì 3:8-4:17; 7:1-10; 9:13.

21. Báwo ni obìnrin Kristẹni ṣe lè túbọ̀ máa jẹ́ ẹni ọ̀wọ́n lójú Jèhófà?

21 Ó ṣe kedere pé láyé ọjọ́un àti lóde òní pẹ̀lú, àwọn obìnrin tó bẹ̀rù Ọlọ́run ti fi ìfọkànsìn tí a yà sọ́tọ̀ gedegbe han sí Jèhófà àti ìjọsìn rẹ̀. Nítorí náà, àwọn obìnrin tó bẹ̀rù Ọlọ́run jẹ́ ẹni ọ̀wọ́n lójú Jèhófà. Ẹ̀yin Kristẹni arábìnrin, ẹ jẹ́ kí Jèhófà tipasẹ̀ ẹ̀mí rẹ̀ máa mọ yín díẹ̀díẹ̀, kí ẹ lè di “ohun èlò” tó túbọ̀ dára fún ète ọlọ́lá, èyí “tí a múra sílẹ̀ fún gbogbo iṣẹ́ rere.” (2 Tímótì 2:21; Róòmù 12:2) Nítorí àwọn olùjọsìn tó jẹ́ ẹni ọ̀wọ́n bẹ́ẹ̀ ni Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣe sọ pé: “Ẹ fún un lára èso ọwọ́ rẹ̀, kí àwọn iṣẹ́ rẹ̀ sì máa yìn ín ní àwọn ẹnubodè pàápàá.” (Òwe 31:31) Ǹjẹ́ kí ọ̀ràn ẹnì kọ̀ọ̀kan yín rí bẹ́ẹ̀.

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Fún ìmọ̀ràn lórí ọ̀nà tá a lè gbà láti yin irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀, wo Ìlé Ìṣọ́ March 15, 2002, ojú ìwé 26 sí 28.

b Orin 212 nínú ìwé orin Kọrin Ìyìn si Jehofa tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe.

Ǹjẹ́ O Rántí?

• Báwo ni díẹ̀ lára àwọn Kristẹni obìnrin ní ọ̀rúndún kìíní ṣe fi hàn pé àwọn jẹ́ ẹni ọ̀wọ́n lójú Jèhófà?

• Lákòókò tiwa yìí, báwo ni ọ̀pọ̀ arábìnrin ṣe sọ ara wọn dẹni ọ̀wọ́n lójú Ọlọ́run?

• Ní àwọn ọ̀nà wo ni Jèhófà gbà ṣètìlẹyìn fún àwọn ìyá anìkàntọ́mọ àtàwọn arábìnrin tí kò lọ́kọ?

• Báwo ni obìnrin kan ṣe lè fi ọ̀wọ̀ hàn fún ìṣètò ipò orí?

[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 17]

ÀWỌN ÀPẸẸRẸ TÁ A LÈ GBÉ YẸ̀ WÒ

Ṣé wàá fẹ́ láti gbé díẹ̀ yẹ̀ wò nínú àpẹẹrẹ àwọn obìnrin mìíràn tó tún jẹ́ adúróṣinṣin tí a mẹ́nu kan nínú Bíbélì? Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, jọ̀wọ́ ka àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tá a tò sí ìsàlẹ̀ yìí. Bó o ṣe ń ṣàṣàrò lórí ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn, gbìyànjú láti fòye mọ̀ àwọn ìlànà tí o lè lò dé ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ nínú ìgbésí ayé rẹ.—Róòmù 15:4.

Sárà: Jẹ́nẹ́sísì 12:1, 5; 13:18a; 21:9-12; 1 Pétérù 3:5, 6.

Àwọn obìnrin Ísírẹ́lì tó ní ìwà ọ̀làwọ́: Ẹ́kísódù 35:5, 22, 25, 26; 36:3-7; Lúùkù 21:1-4.

Dèbórà: Àwọn Onídàájọ́ 4:1-5:31.

Rúùtù: Rúùtù 1:4, 5, 16, 17; 2:2, 3, 11-13; 4:15.

Obìnrin ará Ṣúnémù: 2 Àwọn Ọba 4:8-37.

Obìnrin ará Fòníṣíà: Mátíù 15:22-28.

Màtá àti Màríà: Máàkù 14:3-9; Lúùkù 10:38-42; Jòhánù 11:17-29; 12:1-8.

Tàbítà: Ìṣe 9:36-41.

Àwọn ọmọbìnrin mẹ́rin tí Fílípì bí: Ìṣe 21:9.

Fébè: Róòmù 16:1, 2.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]

Ṣé o máa ń gbóríyìn fún àwọn arábìnrin tí kò lọ́kọ tí wọ́n sì ń fi ìdúróṣinṣin ṣègbọràn sí òfin Ọlọ́run?

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]

Àwọn nǹkan wo ní pàtó lo lè mẹ́nu kan nínú àdúrà ṣáájú káwọn ọmọ tó lọ sílé ìwé?