Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwọn Obìnrin Tó Mú Inú Jèhófà Dùn

Àwọn Obìnrin Tó Mú Inú Jèhófà Dùn

Àwọn Obìnrin Tó Mú Inú Jèhófà Dùn

“Kí Jèhófà san ọ́ lẹ́san fún bí o ṣe hùwà, kí owó ọ̀yà pípé sì wà fún ọ láti ọ̀dọ̀ Jèhófà.”—RÚÙTÙ 2:12.

1, 2. Báwo ni ríronú jinlẹ̀ lórí àwọn àpẹẹrẹ inú Bíbélì tó sọ nípa àwọn obìnrin tó múnú Jèhófà dùn ṣe lè ṣe wá láǹfààní?

 ÌBẸ̀RÙ Ọlọ́run ló sún àwọn obìnrin méjì kan tí wọ́n fì kọ̀ láti ṣe ohun tí Fáráò ní kí wọ́n ṣe. Ìgbàgbọ́ ló sún kárùwà kan láti fi ìwàláàyè rẹ̀ wewu kó lè dáàbò bo àwọn amí méjì tó jẹ́ ọmọ Ísírẹ́lì. Nígbà tí wàhálà dé, orí pípé àti ìwà ìrẹ̀lẹ̀ ló ran obìnrin kan lọ́wọ́ tó fi gbà ọ̀pọ̀ ẹ̀mí là, tí kò sì jẹ́ kí ẹni àmì òróró Jèhófà jẹ̀bi ẹ̀jẹ̀. Ìgbàgbọ́ nínú Jèhófà Ọlọ́run àti ẹ̀mí aájò àlejò ló sún ìyá kan tó jẹ́ opó láti fún wòlíì Ọlọ́run ni gbogbo oúnjẹ tó kù sílé rẹ̀. Díẹ̀ nìyí nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ àpẹẹrẹ inú Ìwé Mímọ́ nípa àwọn obìnrin tó mú inú Jèhófà dun.

2 Ojú tí Jèhófà fi wo àwọn obìnrin wọ̀nyí àti bó ṣe bù kún wọn fi hàn pé ohun tó dùn mọ ọn nínú jù lọ ni àwọn ànímọ́ tẹ̀mí tó ṣe pàtàkì ju jíjẹ́ tí ẹni kan jẹ́ ọkùnrin tàbí obìnrin. Láyé òde òní táwọn èèyàn ti ka nǹkan tara sí bàbàrà, ìpèníjà ló jẹ́ láti fi nǹkan tẹ̀mí sí ipò àkọ́kọ́. Ṣùgbọ́n a lè borí ìpèníjà náà, gẹ́gẹ́ bí ọ̀kẹ́ àìmọye àwọn obìnrin tó bẹ̀rù Ọlọ́run, tó jẹ́ pé àwọn ló pọ̀ jù lọ nínú àwọn èèyàn Ọlọ́run lónìí ṣe fi hàn kedere. Irú àwọn Kristẹni obìnrin bẹ́ẹ̀ fara wé ìgbàgbọ́, ọgbọ́n, ẹ̀mí aájò àlejò àti àwọn ànímọ́ rere mìíràn táwọn obìnrin tó bẹ̀rù Ọlọ́run tá a dárúkọ wọn nínú Bíbélì fi hàn. Lóòótọ́, àwọn Kristẹni ọkùnrin pẹ̀lú á fẹ́ fara wé àwọn ànímọ́ táwọn obìnrin àwòfiṣàpẹẹrẹ ayé ọjọ́un fi hàn yìí. Láti lè mọ bá a ṣe lè ṣe é ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́, ẹ jẹ́ ká túbọ̀ ṣàgbéyẹ̀wò àwọn àkọsílẹ̀ inú Bíbélì tó sọ nípa àwọn obìnrin tá a mẹ́nu kan níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí fínnífínní.—Róòmù 15:4; Jákọ́bù 4:8.

Àwọn Obìnrin Tó Kọ̀ Láti Ṣe Ohun Tí Fáráò Ní Kí Wọ́n Ṣe

3, 4. (a) Kí nìdí tí Ṣífúrà àti Púà kò fi ṣègbọràn sí Fáráò nígbà tó pàṣẹ pé kí wọ́n máa pa gbogbo ọmọkùnrin Ísírẹ́lì tí wọ́n bá ṣẹ̀ṣẹ̀ bí? (b) Báwo ni Jèhófà ṣe san èrè fún àwọn agbẹ̀bí méjì wọ̀nyí nítorí ìgboyà àti ìbẹ̀rù Ọlọ́run tí wọ́n ní?

3 Nígbà ìgbẹ́jọ́ Nuremberg tá a ṣe nílẹ̀ Jámánì lẹ́yìn Ogun Àgbáyé Kejì, ọ̀pọ̀ nínú àwọn tó jẹ̀bi ìpakúpa rẹpẹtẹ ló gbìyànjú láti wí àwíjàre pé, ṣíṣe ìgbọràn sí àṣẹ ló jẹ́ káwọn hu irú ìwà ọ̀daràn bẹ́ẹ̀. Ó dára, ẹ jẹ́ ká wá fi àwọn wọ̀nyí wéra pẹ̀lú Ṣífúrà àti Púà, ìyẹn àwọn agbẹ̀bí méjì tí wọ́n jẹ́ ọmọ Ísírẹ́lì, tí wọ́n gbé ní Íjíbítì ìgbàanì nígbà tí Fáráò olubi kan tá ò mọ orúkọ rẹ̀ ń ṣàkóso. Bí àwọn Hébérù ṣe ń pọ̀ sí i ló ba Fáráò lẹ́rù tó fi pàṣẹ fún àwọn agbẹ̀bí méjì yẹn pé kí wọ́n máa pa gbogbo ọmọkùnrin Hébérù tí wọ́n bá ṣẹ̀ṣẹ̀ bí. Kí ni àwọn obìnrin wọ̀nyí ṣe nígbà tí wọ́n gbọ́ àṣẹ burúkú yìí? ‘Wọn ṣe gẹ́gẹ́ bí ọba Íjíbítì ti sọ fún wọn, ṣùgbọ́n wọn pa àwọn ọmọkùnrin mọ́ láàyè.’ Kí nìdí tí ìbẹ̀rù èèyàn kò fi mú káwọn obìnrin wọ̀nyí ṣe ohun tí kò dáa? Nítorí pé wọ́n “bẹ̀rù Ọlọ́run tòótọ́” ni.—Ẹ́kísódù 1:15, 17; Jẹ́nẹ́sísì 9:6.

4 Bẹ́ẹ̀ ni o, àwọn agbẹ̀bí wọ̀nyí sá di Jèhófà, òun pẹ̀lú sì di “apata” fún wọn, ó pa wọ́n mọ́ kúrò lọ́wọ́ ìbínú Fáráò. (2 Sámúẹ́lì 22:31; Ẹ́kísódù 1:18-20) Ṣùgbọ́n ìyẹn nìkan kọ́ ni èrè tí Jèhófà san fún wọn o. Ó tún jẹ́ kí Ṣífúrà àti Púà ní ìdílé tiwọn. Kódà, ó tún bọlá fún àwọn obìnrin wọ̀nyí nítorí pé ó jẹ́ kí á kọ orúkọ àti iṣẹ́ wọn sínú Ọ̀rọ̀ rẹ̀ tó mí sí, kí àwọn ìran ọjọ́ iwájú lè máa kà á, ṣùgbọ́n ó mú kí orúkọ Fáráò náà pòórá pátápátá nínú ìtàn.—Ẹ́kísódù 1:21; 1 Sámúẹ́lì 2:30b; Òwe 10:7.

5. Báwo ni ọ̀pọ̀ Kristẹni obìnrin lónìí ṣe ń ṣe bíi Ṣífúrà àti Púà, báwo sì ní Jèhófà yóò ṣe san èrè fún wọn?

5 Ǹjẹ́ a rí àwọn obìnrin tó dà bíi Ṣífúrà àti Púà lónìí? Bẹ́ẹ̀ ni, wọ́n wà! Lọ́dọọdún, ọ̀pọ̀lọpọ̀ irú àwọn obìnrin bẹ́ẹ̀ ló ń fi àìṣojo wàásù ìhìn ìṣẹ́ inú Bíbélì tó ń gbẹ̀mí là láwọn ilẹ̀ tí ‘àṣẹ ọba’ ti kà á léèwọ̀, wọ́n sì ń tipa bẹ́ẹ̀ fi òmìnira wọn sínú ewu, ìwàláàyè wọn pàápàá sì tún wà nínú ewu. (Hébérù 11:23; Ìṣe 5:28, 29) Nítorí pé ìfẹ́ fun Ọlọ́run àti aládùúgbò ló ń sún wọn láti máa wàásù, irú àwọn obìnrin onígboyà bẹ́ẹ̀ kò jẹ́ kí ẹnikẹ́ni dí àwọn lọ́wọ́ sísọ ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run fún àwọn ẹlòmíràn. Abájọ tí ọ̀pọ̀ Kristẹni obìnrin fi ń dojú kọ àtakò àti inúnibíni. (Máàkù 12:30, 31; 13:9-13) Bó ṣe rí nígbà ayé Ṣífúrà àti Púà, Jèhófà mọ iṣẹ́ rere tí àwọn onígboyà obìnrin tó tayọ lọ́lá yìí ń ṣe, yóò sì fi ìfẹ́ hàn sí wọ́n nípa pípa orúkọ wọn mọ́ sínú “ìwé ìyè” rẹ̀, ìyẹn tí wọ́n bá fi ìṣòtítọ́ fara dà á títí dópin.—Fílípì 4:3; Mátíù 24:13.

Obìnrin Kan Tó Jẹ́ Kárùwà Tẹ́lẹ̀ Mú Inú Jèhófà Dùn

6, 7. (a) Kí ni Ráhábù mọ̀ nípa Jèhófà àti àwọn èèyàn rẹ̀, ipa wo sì ní ìmọ̀ yìí ní lórí rẹ̀? (b) Báwo la ṣe bọlá fún Ráhábù nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run?

6 Ní ọdún 1473 ṣááju Sànmánì Tiwa, kárùwà kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Ráhábù gbé ní ìlú Kénáánì ti Jẹ́ríkò. Ó dájú pé Ráhábù mọ ìtàn ohun tó ti ṣẹlẹ̀ sẹ́yìn dáadáa. Nígbà tí àwọn amí méjì tó jẹ́ ọmọ Ísírẹ́lì wá ibi ìsádi wá sí ilé rẹ̀, ó sọ kúlẹ̀kúlẹ̀ nípa báwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe kúrò ní Íjíbítì lọ́nà àrà, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìyẹn ti ṣẹlẹ̀ ní ogójì ọdún ṣáájú ìgbà yẹn! Ó tún mọ̀ nípa èyí tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣẹlẹ̀, ìyẹn bí Ísírẹ́lì ṣe ṣẹ́gun àwọn Ọba Ámónì méjì náà, Síhónì àti Ógù. Kíyè sí ipa tí ìmọ̀ tó ní yẹn ní lórí rẹ̀. Ó sọ fún àwọn amí náà pé: “Mo mọ̀ pé Jèhófà yóò fi ilẹ̀ yìí fún yín dájúdájú, . . . nítorí Jèhófà Ọlọ́run yín ni Ọlọ́run nínú ọ̀run lókè àti lórí ilẹ̀ ayé nísàlẹ̀.” (Jóṣúà 2:1, 9-11) Bẹ́ẹ̀ ni, ohun tí Ráhábù ti gbọ́ nípa Jèhófà àti àwọn ohun tó ti ṣe fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì wọ̀ ọ́ lọ́kàn ṣinṣin, ó sì jẹ́ kó nígbàgbọ́ nínú rẹ̀.—Róòmù 10:10.

7 Ìgbàgbọ́ tí Ráhábù ní ló jẹ́ kó ṣe ohun tó tọ́. “Ẹ̀mí àlàáfíà” lo fi gba àwọn amí ọmọ Ísírẹ́lì tó sì ṣègbọràn sí àwọn ìtọ́ni tó ń gbẹ̀mí là tí wọ́n fún un nígbà tí Ísírẹ́lì gbógun ti Jẹ́ríkò. (Hébérù 11:31; Jóṣúà 2:18-21) Ó dájú pé iṣẹ́ ìgbàgbọ́ tí Ráhábù ṣe mú inú Jèhófà dùn, nítorí pé ó mí sí Kristẹni ọmọ ẹ̀yìn náà Jákọ́bù láti to orúkọ rẹ̀ síbi tórúkọ Ábúráhámù, tó jẹ́ ọ̀rẹ́ Ọlọ́run wà gẹ́gẹ́ bí àpẹẹrẹ fún àwa Kristẹni láti tẹ̀ lé. Jákọ́bù kọ̀wé pé: “Lọ́nà kan náà, a kò ha polongo Ráhábù aṣẹ́wó pẹ̀lú ní olódodo nípa àwọn iṣẹ́, lẹ́yìn tí ó ti gba àwọn ońṣẹ́ pẹ̀lú ẹ̀mí aájò àlejò, tí ó sì rán wọn jáde gba ọ̀nà mìíràn?”—Jákọ́bù 2:25.

8. Báwo ni Jèhófà ṣe bù kún Ráhábù nítorí ìgbàgbọ́ àti ìgbọràn rẹ̀?

8 Ọ̀pọ̀ ọ̀nà ni Jèhófà gbà bú kún Ráhábù. Lákọ̀ọ́kọ́, ọ̀nà ìyanu ló gbà dá ìwàláàyè rẹ̀ sí àti tàwọn tó wá ibi ìsádi wá sínú ilé rẹ̀, ìyẹn, “agbo ilé baba rẹ̀ àti gbogbo ẹni tí ó jẹ́ tirẹ̀.” Lẹ́yìn náà, ó jẹ́ kí wọ́n máa gbé “ní àárín Ísírẹ́lì,” níbi tá a ti kà wọ́n sí ọmọ ìbílẹ̀. (Jóṣúà 2:13; 6:22-25; Léfítíkù 19:33, 34) Ṣùgbọ́n kò tán síbẹ̀ yẹn o. Jèhófà tún bọlá fún Ráhábù láti jẹ́ kó di ìyá ńlá fún Jésù Kristi. Inú rere onífẹ̀ẹ́ tá a fi hàn sí obìnrin ará Kénáánì tó ti fìgbà kan rí jẹ́ abọ̀rìṣà yìí mà pọ̀ gan-an o! aSáàmù 130:3, 4.

9. Báwo ni ohun tí Jèhófà ṣe fún Ráhábù àti àwọn Kristẹni obìnrin kan ní ọ̀rúndún kìíní ṣe jẹ́ ìṣírí fún àwọn obìnrin kan lónìí?

9 Gẹ́gẹ́ bíi Ráhábù, láti ọ̀rúndún kìíní títí di ọjọ́ wa lónìí, àwọn Kristẹni obìnrin kan ti kọ ọ̀nà ìgbésí ayé oníṣekúṣe sílẹ̀ kí wọ́n bàa le mú inú Ọlọ́run dùn. (1 Kọ́ríńtì 6:9-11) Ó dájú pé àyíká tá a lè fi wé ti Kénáánì àtijọ́ níbi tí ìṣekúṣe ti wọ́pọ̀, tí wọn ò sì kà á sí ohun tí kò dáa làwọn kan ti dàgbà. Síbẹ̀, wọ́n yí ìgbésí ayé wọn padà, ìgbàgbọ́ tá a gbé kà ìmọ̀ pípéye nínú Ìwé Mímọ́ ló sì sún wọn ṣe bẹ́ẹ̀. (Róòmù 10:17) Nítorí náà, a lè wá sọ nípa irú àwọn obìnrin bẹ́ẹ̀ pé “wọn kò ti Ọlọ́run lójú, pé kí a máa ké pè é gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run wọn.” (Hébérù 11:16) Dájúdájú, iyì ńlá nìyẹn jẹ́!

A Bù Kún Obìnrin Kan Nítorí Pé Ó Lo Làákàyè

10, 11. Kí lo ṣẹlẹ̀ láàárín Nábálì àti Dáfídì tó mú kí Ábígẹ́lì ṣe nǹkan kan?

10 Ọ̀pọ̀ olóòótọ́ obìnrin ayé ọjọ́un ló lo làákàyè lọ́nà tó tayọ, ìyẹn ló sì sọ wọ́n dẹni tó ṣeyebíye lójú àwọn èèyàn Jèhófà. Ọ̀kan nínú irú àwọn obìnrin bẹ́ẹ̀ ni Ábígẹ́lì ìyàwó Nábálì, ọlọ́rọ̀ ọmọ Ísírẹ́lì kan tó ní ilẹ̀. Làákàyè tí Ábígẹ́lì lò ló jẹ́ kó gba ẹ̀mí àwọn èèyàn kan là tí kò sí tún jẹ́ kí Dáfídì tó máa di ọba Ísírẹ́lì lọ́la jẹ̀bi ẹ̀jẹ̀. Ẹ jẹ́ kí á kà nípa àkọsílẹ̀ Ábígẹ́lì nínú 1 Sámúẹ́lì orí 25.

11 Gẹ́gẹ́ bí ìtàn yẹn ṣe bẹ̀rẹ̀, Dáfídì àti àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pabùdó sítòsí agbo ẹran Nábálì, tọ̀sán tòru ni wọ́n sì ń ṣọ́ agbo ẹran yẹn láìgbà owó kankan. Wọ́n kà á sí fífi inú rere han sí Nábálì tó jẹ́ ọmọ Ísírẹ́lì ẹlẹgbẹ́ wọn. Nígbà tí oúnjẹ Dáfídì ń tán lọ, ó rán mẹ́wàá nínú àwọn ọkùnrin tó wà lọ́dọ̀ rẹ̀ sí Nábálì pé kó fún òun lóúnjẹ. Àkókò yìí gan-an ni Nábálì láǹfààní láti mọyì Dáfídì kó sì bọlá fún un gẹ́gẹ́ bí ẹni àmì òróró Jèhófà. Ṣùgbọ́n Nábálì kò ṣe bẹ́ẹ̀. Tìbínú-tìbínú ló fi tàbùkù sí Dáfídì tó sì rán àwọn ọmọkùnrin náà padà lọ́wọ́ òfo. Nígbà tí Dáfídì gbọ́, ó kó irinwó ọmọ ogun jọ, ó si gbéra láti lọ gbẹ̀san. Bí Ábígẹ́lì ṣe gbọ́ pé ìwà burúkú lọkọ òun hù, kíá ló yára fọgbọ́n ṣe nǹkan kan láti tu Dáfídì lójú, ó fi ọ̀pọ̀ ẹrù àti ohun èlò ránṣẹ́ sí i. Lẹ́yìn náà lòun fúnra rẹ̀ wá lọ pàdé Dáfídì.—Ẹsẹ 2 sí 20.

12, 13. (a) Báwo ni Ábígẹ́lì ṣe lo làákàyè tí o sì fi hàn pé òun jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà àti ẹni àmì òróró rẹ̀? (b) Kí ni Ábígẹ́lì ṣe nígbà tó padà délé, kí sì ló gbẹ̀yìn ọ̀rọ̀ náà fún un?

12 Nígbà tí Ábígẹ́lì pàdé Dáfídì, bó ṣe fi ìrẹ̀lẹ̀ bẹ̀bẹ̀ fún àánú jẹ́ kó hàn pé ó ní ọ̀wọ̀ tó jinlẹ̀ fún ẹni àmì òróró Jèhófà. Ó sọ pé “Jèhófà yóò ṣe ilé wíwà pẹ́ títí fún olúwa mi, nítorí pé àwọn ogun Jèhófà ni olúwa mi ń jà,” ó tún fi kún un pé Jèhófà yóò yan Dáfídì ṣe aṣáájú lórí Ísírẹ́lì. (Ẹsẹ 28 sí30) Bákan náà, Ábígẹ́lì tún fìgboyà sọ fún Dáfídì pé bí kò bá kíyè sára pẹ̀lú bó ṣe fẹ́ gbẹ̀san yẹn, yóò jẹ̀bi ẹ̀jẹ̀. (Ẹsẹ 26 àti 31) Ìwà ìrẹ̀lẹ̀ Ábígẹ́lì, ọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀ àti bó ṣe tètè mọ ohun tó yẹ kó ṣe ló pe orí Dáfídì wálé. Dáfídì sọ pé: “Ìbùkún ni fún Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì, tí ó rán ọ lónìí yìí láti pàdé mi! Ìbùkún sì ni fún ìlóyenínú rẹ, ìbùkún sì ni fún ìwọ tí o ti dá mi dúró lónìí yìí kí n má bàa wọnú ẹ̀bi ẹ̀jẹ̀.”—Ẹsẹ 32 àti 33.

13 Nígbà tí Ábígẹ́lì padà délé, ó fọgbọ́n wá ọ̀nà láti sọ fún ọkọ rẹ̀ nípa ẹ̀bùn tó fún Dáfídì. Nígbà tó rí i, ó ti “mutí yó bìnàkò.” Nítorí náà, ó dúró dìgbà tí wáìnì dá lójú rẹ̀ kó tó sọ fún un. Kí ni Nábálì ṣe? Àyà rẹ̀ já débi tó fi kú sára. Ọjọ́ mẹ́wàá lẹ́yìn náà ló kú nígbà tí Ọlọ́run kọ lù ú. Nígbà tí Dáfídì gbọ́ pé Nábálì ti kú, ó sọ pé òun á fẹ́ Ábígẹ́lì ẹni tọ́kàn rẹ́ fẹ́ tó sì bọ̀wọ̀ fún gidigidi. Ábígẹ́lì gbà láti fẹ́ Dáfídì.—Ẹsẹ 34 sí42.

Ǹjẹ́ O Lè Dà Bí Ábígẹ́lì?

14. Èwo nínú àwọn ànímọ́ Ábígẹ́lì ló wù wá láti ní dáadáa?

14 Bóyá ọkùnrin ni ọ́ tàbí obìnrin, ǹjẹ́ o rí àwọn ànímọ́ kan lára Ábígẹ́lì tó wù ẹ́ láti ní dáadáa? Bóyá o fẹ́ láti fọgbọ́n hùwà kó o sì lo làákàyè nígbà tí wàhálà bá dìde. Àbí ó fẹ́ kọ́ bó o ṣe lè fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ sọ̀rọ̀ lọ́nà tó mọ́gbọ́n dání nígbà táwọn tó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ bá gbaná jẹ. Bó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, kí ló dé tí o kò gbàdúrà sí Jèhófà lórí ọ̀ràn náà? Ó ṣèlérí láti fi ọgbọ́n, ìfòyemọ̀ àti agbára láti lè ronú fún gbogbo àwọn tó bá ń “bá a nìṣó ní bíbéèrè nínú ìgbàgbọ́.”—Jákọ́bù 1:5, 6; Òwe 2:1-6, 10, 11.

15. Irú àwọn ipò wo ló lè mú kó túbọ̀ pọn dandan fún àwọn Kristẹni obìnrin láti lo àwọn ànímọ́ tí Ábígẹ́lì fi hàn?

15 Irú àwọn ànímọ́ rere bẹ́ẹ̀ ṣe pàtàkì gan-an fún obìnrin tó bá ní ọkọ aláìgbàgbọ́ tí kì í ṣègbọràn sí àwọn ìlànà Bíbélì. Bóyá ó máa ń mu ọtí yó bìnàkò. Ó ṣe é ṣe kí irú àwọn ọkùnrin bẹ́ẹ̀ yí padà. Ọ̀pọ̀ ló ti ṣe bẹ́ẹ̀, bó ti sábà máa ń rí nígbà tí wọ́n rí ìwà pẹ̀lẹ́, ọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀, àti ìwà mímọ́ àwọn aya wọn.—1 Pétérù 3:1, 2, 4.

16. Báwo ni Kristẹni arábìnrin kan ṣe lè fi hàn pé òun mọrírì àjọṣe tó wà láàárín òun àti Jèhófà ju ohunkóhun mìíràn lọ láì ka bí ipò nǹkan ṣe rí nínú ilé rẹ̀ sí?

16 Ipò yòówù kó o máa bá yí nínú ilé rẹ, má gbàgbé pé Jèhófà á tì ọ́ lẹ́yìn nígbà gbogbo. (1 Pétérù 3:12) Nítorí náà, làkàkà láti fún ara rẹ lókun nípa tẹ̀mí. Gbàdúrà pé kí Ọlọ́run fún ọ ní ọgbọ́n àti ìbàlẹ̀ ọkàn. Bẹ́ẹ̀ ni o, túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà nípasẹ̀ kíkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì déédéé, gbígbàdúrà, ṣíṣàṣàrò àti kíkẹ́gbẹ́ pọ̀ pẹ̀lú àwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ rẹ. Ojú tara tí Nábálì fi máa ń wo ọ̀rọ̀ kò nípa lórí ìfẹ́ tí Ábígẹ́lì ní fún Ọlọ́run àti bó ṣe bá ẹni àmì òróró Ọlọ́run lò. Àwọn ìlànà òdodo ló fì ṣèwà hù. Kódà nínú ilé tí ọkọ ti jẹ́ àwòfiṣàpẹẹrẹ ìránṣẹ́ Ọlọ́run, Kristẹni aya kan ní láti ṣiṣẹ́ kára láti mú kí ipò tẹ̀mí òun lágbára kó sì máa bá a lọ bẹ́ẹ̀. Lóòótọ́, ẹrù iṣẹ́ tí Ìwé Mímọ́ gbé lé ọkọ léjìká ni láti bójú tó ìyàwó rẹ̀ nípa tara àti nípa tẹ̀mí, ṣùgbọ́n ní àbárèbábọ̀, aya kan gbọ́dọ̀ “ṣiṣẹ́ ìgbàlà [rẹ̀] yọrí pẹ̀lú ìbẹ̀rù àti ìwárìrì.”—Fílípì 2:12; 1 Tímótì 5:8.

Obìnrin Kan Gba “Èrè Wòlíì”

17, 18. (a) Báwo la ṣe dán ìgbàgbọ́ opó ara Sáréfátì wò lọ́nà tó ṣàrà ọ̀tọ̀? (b) Kí ni ohun tí opó yẹn ṣe nípa ohun tí Èlíjà béèrè lọ́wọ́ rẹ̀, báwo sì ni Jèhófà ṣe san èrè fún un?

17 Ọ̀nà tí Jèhófà gbà bójú tó opó kan tó jẹ́ aláìní lákòókò wòlíì Èlíjà fi hàn pé ó mọyì àwọn tó ń ti ìsìn tòótọ́ lẹ́yìn nípa lílo ara wọn àti ohun ìní wọn. Nítorí ọ̀dá tó wà fún àkókò gígùn ní ọjọ́ Èlíjà, ìyàn ńlá kan bẹ́ sílẹ̀ tó nípa lórí gbogbo èèyàn títí kan opó kan àti ọmọkùnrin rẹ̀ kékeré ní Sáréfátì. Nígbà tí gbogbo oúnjẹ tó kù sílé wọn kò ju ohun tí wọ́n á jẹ lẹ́ẹ̀kan lọ ni àlejò kan wọlé wẹ́rẹ́, ìyẹn wòlíì Èlíjà. Ó béèrè ohun kan tí a kò retí. Bó tilẹ̀ mọ̀ pé ipò tóbìnrin náà wà kò fara rọ, ó ní kó fi òróró àti ìyẹ̀fun tó kù nílé rẹ̀ ṣe “àkàrà ribiti kékeré kan” fún òun. Àmọ́ ó fi kún pé: “Nítorí èyí ni ohun tí Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì wí, ‘Ìṣà títóbi ti ìyẹ̀fun kì yóò ṣófo, ìṣà kékeré ti òróró kì yóò sì gbẹ, títí di ọjọ́ tí Jèhófà yóò mú kí eji wọwọ dé sórí ilẹ̀.’”—1 Ọba 17:8-14.

18 Kí ni wàá ṣe káni ìwọ ni wọ́n sọ pé kó o ṣe ohun tó ṣàrà ọ̀tọ̀ bẹ́ẹ̀? Opó Sáréfátì náà “ṣe gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Èlíjà,” bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ṣeé ṣe kó ti mọ̀ pé wòlíì Jèhófà ni Èlíjà. Kí ni ohun tí Jèhófà ṣe sí ẹ̀mí aájò àlejò tó fi hàn yìí? Ọ̀nà àrà ni Jèhófà gbà pèsè oúnjẹ fún obìnrin yìí, ọmọkùnrin rẹ̀ àti Èlíjà jálẹ̀ gbogbo àkókò tí ọ̀dá náà fi wà. (1 Ọba 17:15, 16) Bẹ́ẹ̀ ni, Jèhófà fún opó Sáréfátì náà ní “èrè wòlíì” bó tilẹ̀ jẹ́ pé kì í ṣe ọmọ Ísírẹ́lì. (Mátíù 10:41) Ọmọ Ọlọ́run náà sọ ohun tó dáa nípa opó yìí nígbà tó dárúkọ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àpẹẹrẹ àwòkọ́ṣe fún àwọn èèyàn aláìnígbàgbọ́ ìlú rẹ̀, ìyẹn Násárétì.—Lúùkù 4:24-26.

19. Ní àwọn ọ̀nà wo ni ọ̀pọ̀ Kristẹni obìnrin lónìí gbà ń fi irú ẹ̀mí tí opó Sáréfátì ní hàn, ojú wo ni Jèhófà sì fi ń wo irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀?

19 Lónìí, ọ̀pọ̀lọpọ̀ Kristẹni obìnrin ló ń fi irú ẹ̀mí opó ará Sáréfátì yìí hàn. Bí àpẹẹrẹ, lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ ni àwọn Kristẹni arábìnrin tí wọn kò ní ìmọtara ẹni nìkan, tí ọ̀pọ̀ nínú wọn ò sì fi bẹ́ẹ̀ rí jájẹ, tí wọ́n sì tún ní ìdílé tí wọ́n ń bojú tó, máa ń fi ẹ̀mí aájò àlejò hàn sí àwọn alábòójútó arìnrìn-àjò àti ìyàwó wọn. Àwọn mìíràn máa ń ṣàjọpín oúnjẹ pẹ̀lú àwọn òjíṣẹ́ alákòókò kíkún tó wà nínú ìjọ wọn, wọ́n máa ń ṣèrànwọ́ fún àwọn tó jẹ́ aláìní, tàbí kí wọ́n yọ̀ǹda ara wọn àti ohun ìní wọn ní àwọn ọ̀nà mìíràn láti ti iṣẹ́ Ìjọba náà lẹ́yìn. (Lúùkù 21:4) Ǹjẹ́ Jèhófà ń kíyè sí irú ìrúbọ bẹ́ẹ̀? Dájúdájú, ó ń kíyè sí i! “Nítorí Ọlọ́run kì í ṣe aláìṣòdodo tí yóò fi gbàgbé iṣẹ́ yín àti ìfẹ́ tí ẹ fi hàn fún orúkọ rẹ̀, ní ti pé ẹ ti ṣe ìránṣẹ́ fún àwọn ẹni mímọ́, ẹ sì ń bá a lọ ní ṣíṣe ìránṣẹ́.”—Hébérù 6:10.

20. Kí là ó gbé yẹ̀ wò nínú àpilẹ̀kọ tí yóò tẹ̀lé e?

20 Ní ọ̀rúndún kìíní àwọn obìnrin bíi mélòó kan tó bẹ̀rù Ọlọ́run ní àǹfààní láti ṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ fún Jésù àti àwọn àpọ́sítélì rẹ̀. Nínú àpilẹ̀kọ tí yóò tẹ̀lé e, à ó jíròrò bí àwọn obìnrin wọ̀nyí ṣe mú inú Jèhófà dùn, à ó sì ṣàgbéyẹ̀wò àpẹẹrẹ àwọn obìnrin ayé òde òní tó ń sin Jèhófà tọkàntọkàn, kódà nínú àwọn ipò tó le koko.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Gẹ́gẹ́ bíi Mátíù ṣe ṣàkọsílẹ̀ ìtàn ìlà ìdílé Jésù, a dárúkọ àwọn obìnrin mẹ́rin wọ̀nyí—Támárì, Ráhábù, Rúùtù, àti Màríà. Gbogbo wọn ni Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run buyì fún gidigidi.—Mátíù 1:3, 5, 16.

Àtúnyẹ̀wò

• Báwo ni àwọn obìnrin wọ̀nyí ṣe mú inú Jèhófà dùn?

• Ṣífúrà àti Púà

• Ráhábù

• Ábígẹ́lì

• Opó Sáréfátì

• Báwo ni ṣíṣàṣàrò lórí àwọn àpẹẹrẹ tí àwọn obìnrin wọ̀nyí fi lélẹ̀ ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ lẹ́nì kọ̀ọ̀kan? Ṣàpèjúwe.

[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]

Ọ̀pọ̀ obìnrin tó jẹ́ adúróṣinṣin ló ti sin Ọlọ́run láìfi ‘àṣẹ ọba’ pè

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]

Kí ló mú kí Ráhábù jẹ́ àpẹẹrẹ rere ẹni tó ní ìgbàgbọ́?

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]

Àwọn ànímọ́ tí Ábígẹ́lì fi hàn wo ni wàá fẹ láti fára wé?

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 12]

Ọ̀pọ̀ Kristẹni obìnrin lónìí ló ń fi irú ẹ̀mí tí opó Sáréfátì ní hàn