Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Kí nìdí tí Èlíṣà fi béèrè “ipa méjì” nínú ẹ̀mí Èlíjà?

Nígbà tó kù díẹ̀ kí Èlíjà parí iṣẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ wòlíì ní Ísírẹ́lì, wòlíì Èlíṣà tó kéré sí i lọ́jọ́ orí béèrè tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ lọ́wọ́ rẹ̀ pé: “Jọ̀wọ́, kí ipa méjì nínú ẹ̀mí rẹ lè bà lé mi.” (2 Àwọn Ọba 2:9) Tá a bá ní ká sọ ọ́ nípa tẹ̀mí, ó ṣe kedere pé Èlíṣà fẹ́ gba ìpín méjì gẹ́gẹ́ bí irú èyí tí wọ́n máa ń fún àkọ́bí ọmọkùnrin. (Diutarónómì 21:17) Gbígbé àkọsílẹ̀ yìí yẹ̀ wò ní ṣókí yóò mú kí ọ̀rọ̀ náà yéni yóò sì ràn wá lọ́wọ́ láti rí ẹ̀kọ́ kọ́ nínú ìṣẹ̀lẹ̀ náà.

Gẹ́gẹ́ bí Jèhófà ti darí wòlíì Èlíjà, o fòróró yan Èlíṣà láti rọ́pò rẹ̀. (1 Àwọn Ọba 19:19-21) O ti tó nǹkan bí ọdún mẹ́fà tí Èlíṣà ti ń sin Èlíjà tọkàntọkàn gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ rẹ̀, ó sì ti pinnu pé òun máa ṣe bẹ́ẹ̀ títí dópin. Kódà lọ́jọ́ tí Èlíjà lò kẹ́yìn gẹ́gẹ́ bí wòlíì ní Ísírẹ́lì, Èlíṣà dúró ti olùkọ́ rẹ̀ yìí gbágbáágbá. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Èlíjà rọ̀ Èlíṣà pé kó má ṣe tẹ̀ lé òun, wòlíì kékeré náà sọ nígbà mẹ́ta pé: “Èmi kì yóò fi ọ́ sílẹ̀.” (2 Àwọn Ọba 2:2, 4, 6; 3:11) Ní tòótọ́, Èlíṣà wo wòlíì àgbà yìí gẹ́gẹ́ bí bàbá rẹ̀ nípa tẹ̀mí.—2 Àwọn Ọba 2:12.

Bó ti wù kó rí, kì í ṣe Èlíṣà nìkan ṣoṣo ni ọmọ Èlíjà nípa tẹ̀mí. Èlíjà àti Èlíṣà ń dara pọ̀ mọ́ àwùjọ kan tá a mọ̀ sí “àwọn ọmọ àwọn wòlíì.” (2 Àwọn Ọba 2:3) Àkọsílẹ̀ tó wà nínú Àwọn Ọba Kejì fi hàn pé “àwọn ọmọ” wọ̀nyí tún ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Èlíjà, tó jẹ́ bàbá wọn nípa tẹ̀mí. (2 Àwọn Ọba 2:3, 5, 7, 15-17) Síbẹ̀síbẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ẹni tá a fòróró yàn láti jẹ́ arọ́pò, Èlíṣà ló jẹ́ ẹni àkọ́kọ́ lára àwọn ọmọ Èlíjà nípa tẹ̀mí, ńṣe ló dà bí àkọ́bí. Ní Ísírẹ́lì ìgbàanì, àkọ́bí ọmọkùnrin ló máa ń gba ipa méjì nínú ogún bàbá rẹ̀, àmọ́ àwọn ọmọ yòókù máa ń gba ipa kan ṣoṣo. Nítorí náà Èlíṣà béèrè ipa méjì nínú ẹ̀mí Èlíjà gẹ́gẹ́ bí ogún.

Kí nìdí tí Èlíṣà fi béèrè nǹkan yìí ni àkókò yẹn gan-an? Nítorí ó fẹ́ tẹ́wọ́ gba iṣẹ́ bàǹtàbanta kan, iṣẹ́ rírọ́pò Èlíjà gẹ́gẹ́ bí wòlíì ní Ísírẹ́lì. Èlíṣà mọ̀ pé kí òun tó lè ṣe iṣẹ́ bàǹtàbanta tá a yàn fún òun yìí láṣeyanjú, òun nílò agbára tẹ̀mí tó ju agbára òun lọ, èyí tó jẹ́ pé Jèhófà nìkan ló lè fúnni. Ó yẹ kí ó jẹ́ onígboyà bíi ti Èlíjà. (2 Àwọn Ọba 1:3, 4, 15, 16) Nítorí náà, ó béèrè fún ipa méjì nínú ẹ̀mí Èlíjà, ẹ̀mí ìgboyà àti ẹ̀mí ‘jíjowú fún Jèhófà,’ ànímọ́ yíyẹ tí ẹ̀mí Ọlọ́run ń pèsè. (1 Àwọn Ọba 19:10, 14) Kí ni Èlíjà ṣe?

Èlíjà mọ̀ pé òun kò lè fún Èlíṣà ní ohun tó béèrè yìí, Ọlọ́run nìkan ṣoṣo ló lè fún un. Nítorí náà, ó fèsì tìrẹ̀lẹ̀tìrẹ̀lẹ̀ pé: “Ìwọ béèrè ohun kan tí ó ṣòro. Bí o bá rí mi nígbà tí a bá mú mi kúrò lọ́dọ̀ rẹ, yóò ṣẹlẹ̀ bẹ́ẹ̀ fún ọ.” (2 Àwọn Ọba 2:10) Lóòótọ́, Jèhófà jẹ́ kí Èlíṣà rí Èlíjà nígbà tí ìjì ń gbé e lọ. (2 Àwọn Ọba 2:11, 12) A fún Èlíṣà ní ohun tó béèrè. Jèhófà fún un ní ẹ̀mí tó nílò láti fi bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ tuntun tó gbà, tí yóò sì tún fi kojú àwọn àdánwò tó ń bọ̀.

Lónìí, àwọn ẹni àmì òróró (tá a máa ń pè ní ẹgbẹ́ Èlíṣà nígbà mìíràn) àtàwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run lápapọ̀ lè rí ìṣírí gbà látinú àkọsílẹ̀ Bíbélì yìí. Nígbà mìíràn, ó lè máa ṣe wa bíi pé ọ̀ràn tojú sú wa, tá a ń rò pé a ò tóótun láti ṣe iṣẹ́ tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ yàn fún wa, tàbí kí a má fi bẹ́ẹ̀ ní ìgboyà mọ́ láti máa ṣe iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba náà nìṣó nítorí àwọn èèyàn ò fẹ́ gbọ́ rárá tàbí nítorí pé wọ́n ń ṣàtakò gan-an ní ìpínlẹ̀ wa. Àmọ́, bí a bá bẹ Jèhófà pé kí ó ràn wá lọ́wọ́, yóò fún wa ní ẹ̀mí mímọ́ tí a nílò láti fi kojú àwọn ìṣòro àti ipò àwọn nǹkan tó ń yí padà. (Lúùkù 11:13; 2 Kọ́ríńtì 4:7; Fílípì 4:13) Ó dájú pé, gẹ́gẹ́ bí Jèhófà ti fún Èlíṣà lókun láti ṣe iṣẹ́ bàǹtàbanta tó gbà, bẹ́ẹ̀ náà ni yóò ràn tàgbà tèwe wa lọ́wọ́ láti ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa láṣeyanjú.—2 Tímótì 4:5.