Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Jèhófà Kọ́ Mi Láti Ìgbà Èwe Mi

Jèhófà Kọ́ Mi Láti Ìgbà Èwe Mi

Ìtàn Ìgbésí Ayé

Jèhófà Kọ́ Mi Láti Ìgbà Èwe Mi

GẸ́GẸ́ BÍ RICHARD ABRAHAMSON ṢE SỌ Ọ́

“Ọlọ́run, ìwọ ti kọ́ mi láti ìgbà èwe mi wá, títí di ìsinsìnyí, mo sì ń bá a nìṣó ní sísọ nípa àwọn iṣẹ́ àgbàyanu rẹ.” Ẹ jẹ́ kí n ṣàlàyé ìdí tí àwọn ọ̀rọ̀ tó wà nínú Sáàmù 71:17 yẹn ṣe ní ìtumọ̀ pàtàkì sí mi.

ỌDÚN 1924 ni àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, gẹ́gẹ́ bá a ṣe máa ń pe àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nígbà yẹn lọ́hùn-ún, wá sọ́dọ̀ màmá mi tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Fannie Abrahamson. Ọmọ ọdún kan péré ni mí nígbà yẹn. Bí wọ́n ṣe ń kọ́ Màmá ní ẹ̀kọ́ òtítọ́ Bíbélì ló ń sáré lọ sọ́dọ̀ àwọn aládùúgbò rẹ̀ tó lọ ń sọ àwọn ohun tó ń kọ́ fún wọn, ó sì tún kọ́ èmi àti ẹ̀gbọ́n mi ọkùnrin àti obìnrin lẹ́kọ̀ọ́ pẹ̀lú. Kó tó di pé mo mọ̀wé kà ló ti ràn mí lọ́wọ́ láti há ọ̀pọ̀ ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó sọ̀rọ̀ nípa àwọn ìbùkún Ìjọba Ọlọ́run sórí.

Ní òpin àwọn ọdún 1920, àwọn obìnrin díẹ̀ àtàwọn ọmọdé ti wà nínú àwùjọ àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tó wà ní La Grande, ní ìpínlẹ̀ Oregon, ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, níbi tí wọ́n ti bí mi tí wọ́n sì ti tọ́ mi dàgbà. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àdádó la wà, àwọn òjíṣẹ́ arìnrìn-àjò tá a mọ̀ sí àwọn arìnrìn-àjò ìsìn nígbà yẹn lọ́hùn-ún máa ń bẹ̀ wá wò lẹ́ẹ̀kan tàbí ẹ̀ẹ̀mejì lọ́dún. Wọ́n máa ń sọ àwọn àsọyé tó fúnni níṣìírí, wọ́n ń bá wa jáde òde ẹ̀rí, wọ́n sì nífẹ̀ẹ́ àwọn ọmọdé gan-an. Shield Toutjian, Gene Orrell, àti John Booth wà lára àwọn ẹni ọ̀wọ́n wọ̀nyí.

Ní 1931, kò sí ẹnikẹ́ni nínú àwùjọ wa tó lè lọ sí àpéjọ tó wáyé ní Columbus, Ohio, níbi táwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ti gbà láti jẹ́ orúkọ náà Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Àmọ́ àwọn ẹgbẹ́, bá a ṣe máa ń pe àwọn ìjọ nígbà náà, àtàwọn àwùjọ tó wà ní àdádó tí ẹnikẹ́ni lára wọn ò lọ sí àpéjọ náà pàdé pọ̀ níbì kan nítòsí ní oṣù August káwọn náà lè tẹ́wọ́ gba ìpinnu táwọn ará ṣe láti tẹ́wọ́ gba orúkọ náà. Àwùjọ wa kékeré tó wà ní La Grande náà ṣe bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú. Nígbà tó wá di ọdún 1933, a bẹ̀rẹ̀ sí ṣe ìpolongo láti pín àwọn ìwé pẹlẹbẹ náà, The Crisis, káàkiri, mo wá há ọ̀nà kan tá a lè gbà báni jíròrò Bíbélì sórí, ìgbà àkọ́kọ́ sì nìyẹn tí mo dá nìkan jẹ́rìí láti ilé dé ilé.

Wọ́n ṣe àtakò sí iṣẹ́ wa gan-an láwọn ọdún 1930. Ohun tá a sì ṣe láti kojú àtakò náà ni pé a pín àwọn ẹgbẹ́ náà sí ohun tá a pè ní ẹ̀ka, èyí tó máa ń ṣe àwọn àpéjọ kéékèèké, tó sì máa ń kópa nínú iṣẹ́ ìwàásù tá a mọ̀ sí ìpolongo tá à ń ṣe ní ẹ̀ka kọ̀ọ̀kan lẹ́ẹ̀kan tàbí ẹ̀ẹ̀méjì lọ́dún. Àwọn ọ̀nà tá a máa gbà wàásù àti bá a ṣe máa bá àwọn ọlọ́pàá tó bá fẹ́ dí wa lọ́wọ́ lò tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ ni wọ́n máa ń kọ́ wa láwọn àpéjọ wọ̀nyí. Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé gbogbo ìgbà ni wọ́n máa ń mú àwa Ẹlẹ́rìí lọ síwájú àwọn ọlọ́pàá tó ń dájọ́ tàbí kí wọ́n mú wa lọ sílé ẹjọ́, ńṣe la máa ń ṣe àṣefihàn àwọn ohun tó yẹ ní ṣíṣe nípa títẹ̀lé ohun tá a kọ sínú bébà kan tó ní àwọn ìtọ́ni nínú, èyí tá a ń pè ní Order of Trial. Èyí sì mú wa gbára dì gan-an láti kojú àwọn àtakò náà.

Bí Mo Ṣe Tẹ̀ Síwájú Nínú Otítọ́ Bíbélì Láti Kékeré

Bí mo ṣe ń dàgbà ni mo túbọ̀ ń mọyì àwọn òtítọ́ Bíbélì àti ìrètí tá a gbé karí Bíbélì pé àwọn èèyàn yóò wà láàyè títí láé lórí ilẹ̀ ayé lábẹ́ Ìjọba Ọlọ́run ti ọ̀run. Ní àkókò yẹn, a kò fi bẹ́ẹ̀ ka ìrìbọmi sí ohun tó pọn dandan fáwọn tí kò ní ìrètí bíbá Kristi jọba lókè ọ̀run. (Ìṣípayá 5:10; 14:1, 3) Síbẹ̀, wọ́n sọ fún mi pé tí mo bá ti pinnu lọ́kàn mi pé mo fẹ́ ṣe ìfẹ́ Jèhófà, ohun tó bọ́gbọ́n mu ju ni pé kí n ṣe ìrìbọmi. Mo wá ṣe ìrìbọmi ní August 1933.

Nígbà tí mo wà lọ́mọ ọdún méjìlá, olùkọ́ mi rí i pé mo mọ ọ̀rọ̀ sọ dáadáa, ìdí nìyẹn tó fi ní kí Màmá ṣètò àfikún ẹ̀kọ́ fún mi. Màmá rí i pé èyí á ràn mi lọ́wọ́ láti túbọ̀ sin Jèhófà. Bó ṣe bẹ̀rẹ̀ sí bá ẹni tó ń kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́ náà fọṣọ nìyẹn fún odindi ọdún kan gbáko kó lè fi owó tó ń gbà níbẹ̀ san owó ẹ̀kọ́ tí mò ń kọ́. Ìdálẹ́kọ̀ọ́ náà ran mi lọ́wọ́ gan-an nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ mi. Nígbà tí mo wà lọ́mọ ọdún mẹ́rìnlá, ibà aromọléegun ṣe mi, èyí tó mú ki n fi ilé ìwé sílẹ̀ fún ohun tó lé ní ọdún kan.

Ní 1939, òjíṣẹ́ alákòókò kíkún kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Warren Henschel wá sí àgbègbè wa. a Ẹ̀gbọ́n gidi ló jẹ́ fún mi nípa tẹ̀mí, ó máa ń mú mi jáde òde ẹ̀rí fún ọ̀pọ̀ ọjọ́. Kò pẹ́ tó fi ràn mí lọ́wọ́ láti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìsìn aṣáájú ọ̀nà tá a máa ń ṣe lákòókò ìsinmi, èyí tá a lè pè ní iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún onígbà díẹ̀. Ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn yẹn gan-an ni wọ́n sọ àwùjọ wa di ẹgbẹ́. Wọ́n fi Warren ṣe ìránṣẹ́ ẹgbẹ́, wọ́n sì yàn mí gẹ́gẹ́ bí olùdarí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́. Ìgbà tí Warren lọ sìn ní Bẹ́tẹ́lì, ìyẹn orílé iṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ní Brooklyn, New York, ni mo di ìránṣẹ́ ẹgbẹ́.

Mo Bẹ̀rẹ̀ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Alákòókò Kíkún

Ẹrù iṣẹ́ púpọ̀ sí i tó já lé mi léjìká gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ ẹgbẹ́ ló túbọ̀ fún ìpinnu mi lókun láti wọnú iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún, èyí tí mo bẹ̀rẹ̀ lọ́mọ ọdún mẹ́tàdínlógún lẹ́yìn tí mo parí ọdún mẹ́ta tí mo lò nílé ẹ̀kọ́ gíga. Ìsìn ti Bàbá yàtọ̀ sí tiwa, àmọ́ ó jẹ́ ẹni tó ń gbọ́ bùkátà ìdílé rẹ̀ dáadáa, kò sì gba gbẹ̀rẹ́. Ó fẹ́ kí n lọ sí kọ́lẹ́ẹ̀jì. Àmọ́, ó sọ pé, ohun tó bá wù mi ni mo lè ṣe tí mi ò bá ti retí pé kóun máa fún mi lówó oúnjẹ àti owó ilé. Bí mo ṣe bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà nìyẹn ní September 1, 1940.

Nígbà tí mo fẹ́ kúrò nílé, màmá mi ní kí n ka ìwé Òwe 3:5, 6, tó kà pé: “Fi gbogbo ọkàn-àyà rẹ gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, má sì gbára lé òye tìrẹ. Ṣàkíyèsí rẹ̀ ní gbogbo ọ̀nà rẹ, òun fúnra rẹ̀ yóò sì mú àwọn ipa ọ̀nà rẹ tọ́.” Ní tòótọ́, fífi gbogbo ìgbésí ayé mi gbára lé Jèhófà ti ràn mí lọ́wọ́ gan-an.

Láìpẹ́, mo dara pọ̀ mọ́ Joe àti Margaret Hart nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ náà ní apá àríwá gbùngbùn ìpínlẹ̀ Washington ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà. Ìpínlẹ̀ náà ní oríṣiríṣi nǹkan nínú—ó ní àwọn oko màlúù, oko àgùntàn, àti agbègbè àdágbé táwọn ará Íńdíà wà, títí kan àwọn ìlú kéékèèké àti àwọn abúlé. Ní ìgbà ìrúwé ọdún 1941, wọ́n yàn mí gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ ẹgbẹ́ nínú ìjọ tó wà ní Wenatchee, Washington.

Ní àpéjọ kan tá a ṣe ní Walla Walla, Washington, mo wà lára àwọn tó ń bójú tó èrò níbẹ̀, tí mò ń kí àwọn èèyàn tó ń dé sí gbọ̀ngàn àpéjọ náà káàbọ̀. Mo wá kíyè sí arákùnrin ọ̀dọ́ kan tó ń sa gbogbo ipá rẹ̀ láti mú kí ẹ̀rọ gbohùngbohùn tá a fẹ́ lò lè ṣiṣẹ́ àmọ́ ẹ̀rọ náà kò ṣiṣẹ́. Mo wá dábàá pé kó lọ máa ṣe iṣẹ́ tí wọ́n yàn fún mi kí èmi náà sì bá a ṣe tirẹ̀. Nígbà tí ìránṣẹ́ tó ń bójú tó agbègbè yẹn, Albert Hoffman, padà dé tó rí i pé mo ti fi iṣẹ́ tá a yàn fún mi sílẹ̀, ẹ̀rín músẹ́ ló fi ṣàlàyé ìjẹ́pàtàkì kéèyàn dúró sídìí iṣẹ́ tá a bá yàn fún un, àyàfi tá a bá sọ pé kó kúrò níbẹ̀. Mi ò gbàgbé ìmọ̀ràn tó fún mi yẹn látìgbà náà.

Ní August 1941, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà wéwèé láti ṣe àpéjọ ńlá kan ní St. Louis, Missouri. Tọkọtaya Harts fi nǹkan bo ẹ̀yìn ọkọ̀ akẹ́rù wọn, wọ́n si kó bẹ́ǹṣì síbẹ̀. Ẹ̀yìn ọkọ̀ yẹn ni àwa aṣáájú ọ̀nà mẹ́sàn-án jókòó sí tá a fi rin ìrìn àjò egbèjìlá [2,400] kìlómítà dé St. Louis. A lò tó ọ̀sẹ̀ kan lọ́nà nígbà tá à ń lọ, a tún lò tó ọ̀sẹ̀ kan nígbà tá à ń bọ̀. Ní àpéjọ náà, àwọn ọlọ́pàá fojú bù ú pé àwọn èrò tó wà níbẹ̀ á pọ̀ tó ẹgbẹ̀rún márùndínlọ́gọ́fà [115,000]. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ṣeé ṣe kí àwa tó wà níbẹ̀ má pọ̀ tó ìyẹn, ó dájú pé a pọ̀ jù nǹkan bí ẹgbẹ̀rún márùndínláàádọ́rin [65,000] àwọn Ẹlẹ́rìí tó wà ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà lákòókò yẹn. Àpéjọ náà gbéni ró gan-an nípa tẹ̀mí.

Mo Bẹ̀rẹ̀ Iṣẹ́ Ìsìn ní Bẹ́tẹ́lì Tó Wà ní Brooklyn

Lẹ́yìn tí mo padà sí Wenatchee, mo gba lẹ́tà kan tó sọ pé kí n wá sìn ní Bẹ́tẹ́lì tó wà ní Brooklyn. Bí mo ṣe ń dé síbẹ̀ ní October 27, 1947 ni wọ́n mú mi lọ sí ọ́fíìsì Nathan H. Knorr, tó jẹ́ alábòójútó ibi ìtẹ̀wé. Ó fara balẹ̀ ṣàlàyé bí Bẹ́tẹ́lì ṣe rí fún mi, ó sì tẹnu mọ́ ọn pé rírọ̀ mọ́ Jèhófà ni ohun tó lè mú kéèyàn ṣàṣeyọrí níbẹ̀. Ẹ̀yìn ìyẹn ni wọ́n mú mi lọ sí Ẹ̀ka Ìkówèéránṣẹ́, wọ́n sì ní kí n máa di àwọn páálí tí wọ́n kó àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ sí, tí wọ́n fẹ́ kó ránṣẹ́.

January 8, 1942 ni Joseph Rutherford, tó ń mú ipò iwájú láàárín àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà kárí ayé, kú. Ọjọ́ márùn-ún lẹ́yìn ìyẹn ni àwọn tó jẹ́ olùdarí fún Society yan Arákùnrin Knorr láti gbapò rẹ̀. Nígbà tí W. E. Van Amburgh, tó ti jẹ́ akọ̀wé àti akápò fún Society láti ọjọ́ pípẹ́, kéde èyí fún ìdílé Bẹ́tẹ́lì, ó sọ pé: “Mo rántí ìgbà tí C. T. Russell kú [ní 1916] tí J. F. Rutherford sì gba ipò rẹ̀. Olúwa ń bá a lọ láti darí iṣẹ́ rẹ̀ àti láti mú kí iṣẹ́ Rẹ̀ tẹ̀ síwájú. Nísinsìnyí, ó dá mi lójú pé iṣẹ́ náà yóò máa tẹ̀ síwájú pẹ̀lú Nathan H. Knorr gẹ́gẹ́ bí ààrẹ, nítorí pé iṣẹ́ Olúwa ni, kì í ṣe tèèyàn.”

Ní February 1942, wọ́n kéde pé “Ẹ̀kọ́ Tó Túbọ̀ Gbé Pẹ́ẹ́lí sí I nípa Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Ọlọ́run” yóò bẹ̀rẹ̀. Wọ́n ṣètò rẹ̀ láti dá àwọn tó wà ní Bẹ́tẹ́lì lẹ́kọ̀ọ́ kí wọ́n lè túbọ̀ mọ bá a ṣe ń ṣe ìwádìí lórí àwọn kókó tó wà nínú Bíbélì, kí wọ́n lè ṣe àkójọpọ̀ ọ̀rọ̀ wọn dáadáa, kí wọ́n sì sọ ọ́ lọ́nà tó gbéṣẹ́. Ẹ̀kọ́ tí mo gbà tẹ́lẹ̀ lórí sísọ̀rọ̀ ní gbangba ràn mí lọ́wọ́ láti tètè tẹ̀ síwájú nínú ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà.

Kò pẹ́ kò jìnnà tí wọ́n ní kí n lọ ṣiṣẹ́ ní Ẹ̀ka Iṣẹ́ Ìsìn, èyí tó ń bójú tó iṣẹ́ òjíṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí tó wà ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà. Nígbà tí ọdún yẹn ń lọ sópin, a pinnu láti tún ìtòlẹ́sẹẹsẹ kan ṣe fún àwọn tó jẹ́ ìránṣẹ́ láti máa bẹ àwọn ẹgbẹ́ tó jẹ ti àwa Ẹlẹ́rìí wò. Bí àkókò ti ń lọ, àwọn ìránṣẹ́ arìnrìn-àjò wọ̀nyí, tí à ń pè ní àwọn ìránṣẹ́ fún àwọn arákùnrin, wá di ẹni tí a ń pè ní àwọn alábòójútó àyíká. Ní ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn ọdún 1942, wọ́n ṣètò ìdánilẹ́kọ̀ọ́ kan ní Bẹ́tẹ́lì láti kọ́ àwọn arákùnrin fún irú iṣẹ́ òjíṣẹ́ yìí, mo sì láǹfààní láti jẹ́ ọ̀kan lára àwọn tó gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ náà. Mo rántí dáadáa pé Arákùnrin Knorr, tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn tó ń dáni lẹ́kọ̀ọ́ náà, tẹnu mọ́ kókó yìí fún wa pé: “Má gbìyànjú láti múnú èèyàn dùn. Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, o ò ní múnú ẹnikẹ́ni dùn. Ìwọ ṣáà múnú Jèhófà dùn, wàá sì múnú gbogbo àwọn tó nífẹ̀ẹ́ Jèhófà dùn pẹ̀lú.”

October 1942 ni iṣẹ́ arìnrìn-àjò náà bẹ̀rẹ̀. Díẹ̀ lára àwa tó wà ní Bẹ́tẹ́lì kópa nínú rẹ̀ láwọn òpin ọ̀sẹ̀ bíi mélòó kan, tá a ń bẹ àwọn ìjọ tó wà ní nǹkan bí irínwó kìlómítà sí New York City wò. A gbé ìgbòkègbodò báwọn ará ìjọ náà ṣe ń wàásù tó àti bí wọ́n ṣe ń wá sípàdé tó yẹ̀ wò, a bá àwọn tó ń mójú tó ẹrú iṣẹ́ nínú ìjọ náà ṣèpàdé, a sọ àsọyé kan tàbí méjì, a sì bá àwọn Ẹlẹ́rìí tó wà nínú ìjọ náà jáde òde ẹ̀rí.

Ní 1944, mo wà lára àwọn tá a rán jáde láti Ẹ̀ka Iṣẹ́ Ìsìn pé ká lọ ṣe iṣẹ́ arìnrìn-àjò fún oṣù mẹ́fà, mo sìn ní ìpínlẹ̀ Delaware, Maryland, Pennsylvania, àti Virginia. Lẹ́yìn ìyẹn ni mo tún bẹ àwọn ìjọ wò ní Connecticut, Massachusetts, àti Erékùṣù Rhode fún oṣù bíi mélòó kan. Nígbà tí mo padà dé sí Bẹ́tẹ́lì, mo ṣiṣẹ́ fúngbà díẹ̀ ní ọ́fíìsì Arákùnrin Knorr àti ti akọ̀wé rẹ̀, Milton Henschel, ibẹ̀ ni mo ti wá mọ̀ dáadáa nípa bí a ṣe ń ṣe iṣẹ́ wa kárí ayé. Mo tún ṣiṣẹ́ fúngbà díẹ̀ ní Ọ́fíìsì Akápò lábẹ́ àbójútó W. E. Van Amburgh àti igbákejì rẹ̀, Grant Suiter. Nígbà tó di ọdún 1946, wọ́n wá fi mi ṣe alábòójútó àwọn ọ́fíìsì bíi mélòó kan ní Bẹ́tẹ́lì.

Àwọn Ìyípadà Ńlá Nínú Ìgbésí Ayé Mi

Ìgbà tí mo bẹ ìjọ kan wò lọ́dún 1945 ni mo mọ Julia Charnauskas ní ìlú Providence, Erékùṣù Rhode. Nígbà tó fi máa di àárín ọdún 1947, a ti ń ronú nípa ìgbéyàwó. Mo fẹ́ràn iṣẹ́ ìsìn Bẹ́tẹ́lì gan-an, àmọ́ kò tíì sí àǹfààní láti mú aya ẹni wá láti sìn níbẹ̀ lákòókò yẹn. Nítorí ìdí èyí, nígbà tó di January 1948, mo fi Bẹ́tẹ́lì sílẹ̀, èmi àti Julia (Julie) sì ṣe ìgbéyàwó. Mo rí iṣẹ́ àbọ̀ọ̀ṣẹ́ kan gbà ní ilé ìtajà ńlá kan ní ìlú Providence, àwa méjèèjì sì bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìsìn aṣáájú ọ̀nà wa níbẹ̀.

September 1949 ni wọ́n pè mí láti wá ṣe iṣẹ́ àyíká ní ìwọ̀ oòrùn àríwá Wisconsin. Nǹkan àjèjì ló jẹ́ fún èmi àti Julie láti máa wàásù ní àwọn ìlú kéékèèké àti láwọn eréko tó wà ní àgbègbè tí ibi tí wọ́n ti ń fún wàrà pọ̀ sí. Ìgbà òtútù yẹn gùn, ó sì tutù gan-an pẹ̀lú ọ̀pọ̀ ìrì dídì. A ò ní ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́. Àmọ́, a kì í ṣe ká má rí ẹni gbé wa lọ sí ìjọ tó bá kàn láti bẹ̀ wò.

Kété lẹ́yìn tí mo bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ àyíká náà la ṣe àpéjọ àyíká. Mo rántí bí mo ṣe ń tọpinpin gbogbo ohun tó ń lọ níbẹ̀ kí gbogbo nǹkan lè lọ létòlétò, èyí sì kó jìnnìjìnnì bá àwọn kan. Alábòójútó àgbègbè wa, Nicholas Kovalak, wá ṣàlàyé fún mi lọ́nà pẹ̀lẹ́tù pé àwọn arákùnrin tó wà lágbègbè náà mọ bí wọ́n ṣe ń bójú tó àwọn nǹkan wọ̀nyẹn lọ́nà tiwọn, àti pé mi ò ní láti máa tọpinpin tó báyẹn. Ìmọ̀ràn yẹn ti ran mí lọ́wọ́ gan-an nínú bí mo ṣe ń bójú tó àwọn iṣẹ́ tá a bá yàn fún mi láti ìgbà yẹn.

Ní 1950, mo gba iṣẹ́ onígbà kúkúrú kan, ìyẹn iṣẹ́ wíwá ilé fún àwọn tí wọ́n wá sí àpéjọ àkọ́kọ́ lára ọ̀pọ̀ àpéjọ tá a ṣe ní Pápá Ìṣeré Yankee ní New York City. Àpéjọ náà lárinrin láti ìbẹ̀rẹ̀ dé òpin, pẹ̀lú àwọn tó wá sí àpéjọ náà láti orílẹ̀-èdè mẹ́tàdínláàádọ́rin tí iye àwọn tó wà níbẹ̀ ní ọjọ́ tí èrò pọ̀ jù lọ sì jẹ́ 123,707! Lẹ́yìn àpéjọ náà, èmi àti Julie padà sẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ arìnrìn-àjò wa. A ní ayọ̀ tó ga nínú iṣẹ́ àyíká náà. Àmọ́, a rí i pé ó yẹ ká ṣe púpọ̀ sí i nínú iṣẹ́ alákòókò kíkún. Nítorí náà, ọdọọdún la máa ń gba fọ́ọ̀mù Bẹ́tẹ́lì àti ti iṣẹ́ ìsìn míṣọ́nnárì. Inú wa dùn gan-an nígbà tí wọ́n pè wá pé ká wá sí kíláàsì ogún ti ilé ẹ̀kọ́ Watchtower Bible School of Gilead, níbi tá a ti gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ fún iṣẹ́ míṣọ́nnárì.

Iṣẹ́ Ìsìn Nílẹ̀ Òkèèrè

Nígbà tá a kẹ́kọ̀ọ́ yege ní 1953, wọ́n yàn wá sí ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, níbi tí mo ti sìn nínú iṣẹ́ àbójútó àgbègbè ní gúúsù ilẹ̀ England. Lẹ́yìn tá a lo ohun tí kò pé ọdún kan nínú ìgbòkègbodò tí èmi àti Julie gbádùn gan-an yìí, ó yà wá lẹ́nu púpọ̀ nígbà tá a tún gba lẹ́tà pé ká kọrí sí Denmark. Wọ́n ń wá alábòójútó mìíràn tó máa bójú tó ẹ̀ka ilé iṣẹ́ tó wà ní Denmark. Níwọ̀n bí mo ti wà nítòsí, tí mo sì ti gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ lórí irú nǹkan bẹ́ẹ̀ ní Brooklyn tẹ́lẹ̀, wọ́n ní kí n lọ ṣèrànwọ́. A wọ ọkọ̀ ojú omi lọ sí Netherlands, a sì tibẹ̀ wọ ọkọ̀ ojú irin kan lọ sí Copenhagen, Denmark. A débẹ̀ ní August 9, 1954.

Ọ̀kan lára àwọn ìṣòro tá a ní ni pé, díẹ̀ lára àwọn tó mú ipò iwájú níbẹ̀ kùnà láti tẹ́wọ́ gba ìtọ́ni tó ń wá láti orílé iṣẹ́ ní Brooklyn. Àti pé mẹ́ta lára àwọn mẹ́rin tó ń bá wa túmọ̀ àwọn ìtẹ̀jáde wa sí èdè Danish fi Bẹ́tẹ́lì sílẹ̀, wọn kò sì dara pọ̀ mọ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà mọ́ nígbà tó yá. Àmọ́ Jèhófà gbọ́ àdúrà wa. Àwọn aṣáájú ọ̀nà méjì, ìyẹn Jørgen àti Anna Larsen, tí wọ́n ti ṣe iṣẹ́ títúmọ̀ ìwé fúngbà díẹ̀ tẹ́lẹ̀ yọ̀ǹda ara wọn láti wá ṣe iṣẹ́ náà ní àkókò kíkún. Bá a ṣe ń bá títúmọ̀ àwọn ìwé ìròyìn wa sí èdè Danish lọ nìyẹn láìpàdánù ẹ̀dà kankan. Jørgen àti Anna Larsen ṣì wà ní Bẹ́tẹ́lì ní Denmark di bá a ti ń sọ̀rọ̀ yìí, kódà Jørgen ni akóṣẹ́jọ fún Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka báyìí.

Ohun tó ń fún wa níṣìírí jù lọ láwọn ọdún wọ̀nyẹn ni bí Arákùnrin Knorr ṣe máa ń ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ wa déédéé. Kì í kánjú, ńṣe ló máa ń jókòó tá a máa bá ẹnì kọ̀ọ̀kan wa sọ̀rọ̀, tá a máa sọ àwọn ìrírí tó ń jẹ́ ká túbọ̀ lóye bá a ṣe máa borí àwọn ìṣòro tó lè dìde. Nígbà kan tó bẹ̀ wá wò lọ́dún 1955, ohun tá a jọ fẹnu kò sí ni pé ká kọ́ ẹ̀ka tuntun kan tó ní àwọn ilé ìtẹ̀wé nínú ká lè máa tẹ ìwé ìròyìn jáde fún Denmark. A rí ilẹ̀ kan rà sí ìgbèríko kan ní apá àríwá Copenhagen, a sì kó lọ sí ilé tuntun tá a ṣẹ̀ṣẹ̀ kọ́ yìí ní ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn ọdún 1957. Harry Johnson, tí òun àti Karin, ìyàwó rẹ̀, ṣẹ̀ṣẹ̀ dé sí Denmark lẹ́yìn tí wọ́n kẹ́kọ̀ọ́ yege ní kíláàsì kẹrìndínlọ́gbọ̀n ti Gílíádì, ṣèrànwọ́ láti gbé ẹ̀rọ ìtẹ̀wé náà sí àyè rẹ̀ àti láti rí i pé ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́.

A ṣe ètò tó túbọ̀ sunwọ̀n sí i láti máa ṣe àpéjọ ńlá ní Denmark, ìrírí tí mo sì ti ní nígbà tí mo ń ṣiṣẹ́ láwọn àpéjọ ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ṣèrànwọ́ gan-an. Ó lé ní ọgbọ̀n orílẹ̀-èdè táwọn èèyàn ti wá sí àpéjọ àgbáyé tá a ṣe ní Copenhagen lọ́dún 1961. Àwọn tó wà níbẹ̀ lọ́jọ́ tí èrò pọ̀ jù lọ jẹ́ 33,513. Ní 1969, a ṣe àpéjọ kan tó jẹ́ èyí tó tóbi jù lọ nínú gbogbo àwọn àpéjọ tá a ṣe ní Scandinavia, àwọn tó sì wà níbẹ̀ lọ́jọ́ térò pọ̀ jù lọ jẹ́ 42,073!

Ọdún 1963 ni wọ́n pè mí sí kíláàsì kejìdínlógójì ti Gílíádì. Èyí jẹ́ àkànṣe ìdánilẹ́kọ̀ọ́ olóṣù mẹ́wàá tá a ṣètò fún kìkì àwọn tó wà ní ẹ̀ka ilé iṣẹ́. Inú mi dùn láti wà pẹ̀lú ìdílé Bẹ́tẹ́lì ti Brooklyn lẹ́ẹ̀kan sí i, àti láti jàǹfààní látinú ìrírí àwọn tó ti wà lẹ́nu iṣẹ́ fún ọ̀pọ̀ ọdún tí wọ́n ń bójú tó gbogbo bí nǹkan ṣe ń lọ ní orílé iṣẹ́.

Lẹ́yìn ìdánilẹ́kọ̀ọ́ yìí, mo padà sí Denmark láti máa bá bíbójútó àwọn ẹrù iṣẹ́ lọ níbẹ̀. Yàtọ̀ síyẹn, mo tún láǹfààní láti sìn gẹ́gẹ́ bí alábòójútó ìpínlẹ̀ ńlá, tí mo ń bẹ àwọn ẹ̀ka ilé iṣẹ́ tó wà ní ìwọ̀ oòrùn àti àríwá ilẹ̀ Yúróòpù wò láti fún àwọn tó ń ṣiṣẹ́ níbẹ̀ níṣìírí àti láti ràn wọ́n lọ́wọ́ kí wọ́n lè máa ṣe iṣẹ́ tá a gbé lé wọn lọ́wọ́ lọ́nà tó yẹ. Ẹnu àìpẹ́ yìí ni mo ṣe iṣẹ́ tá à ń wí yìí ní Ìwọ̀ Oòrùn Áfíríkà àti láwọn ilẹ̀ Caribbean.

Ní òpin àwọn ọdún 1970, àwọn arákùnrin ní Denmark bẹ̀rẹ̀ sí wá ibi kan tí wọ́n lè kọ́ ilé iṣẹ́ tó tóbi sí nítorí iṣẹ́ ìtumọ̀ àti iṣẹ́ ìwé títẹ̀ tó túbọ̀ gbòòrò sí i. Wọ́n rí ilẹ̀ kan rà sí nǹkan bí ọgọ́ta kìlómítà sí ìwọ̀ oòrùn Copenhagen. Èmi àtàwọn kan la jọ wéwèé bá a ṣe fẹ́ kí ilé tuntun yìí rí, èmi àti Julie sì retí pé àwa àtàwọn ìdílé Bẹ́tẹ́lì tó wà níbẹ̀ la jọ máa gbé inú ilé tuntun náà. Àmọ́, ibi tá a fojú sí ọ̀nà ò gbabẹ̀.

A Padà sí Brooklyn

Ní November 1980, wọ́n pe èmi àti Julie pé ká wá sìn ní Bẹ́tẹ́lì tó wà ní Brooklyn, a sì dé síbẹ̀ ní ìbẹ̀rẹ̀ January 1981. A ti ń sún mọ́ ẹni ọgọ́ta ọdún nígbà yẹn, lẹ́yìn tá a sì ti fi èyí tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ìdajì ìgbésí ayé wa gbé lọ́dọ̀ àwọn arákùnrin àti arábìnrin wa ọ̀wọ́n tó wà ní Denmark, kò rọrùn fún wa láti padà sí orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà. Síbẹ̀, a ò bẹ̀rẹ̀ sí ronú nípa ibi tó wù wá láti wà àmọ́ a gbìyànjú láti gbájú mọ́ iṣẹ́ tá a yàn fún wa àti ìṣòro èyíkéyìí tó bá dìde níbẹ̀.

A dé sí Brooklyn a sì fi ibẹ̀ ṣe ibùjókòó. Wọ́n yàn Julie sí ọ́fíìsì tá a ti ń ṣírò owó, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí i ṣe iṣẹ́ tó dà bí èyí tó ṣe ni Denmark. Wọ́n yàn mí sí Ẹ̀ka Ìwé Kíkọ kí n lè ṣèrànwọ́ níbi ètò tá à ń ṣe láti mú àwọn ìwé wa jáde. Ìbẹ̀rẹ̀ àwọn ọdún 1980 jẹ́ àkókò tí nǹkan yí padà gan-an nínú bá a ṣe ń ṣe àwọn iṣẹ́ wa ní Brooklyn, ìgbà yẹn la fi lílo ẹ̀rọ ìtẹ̀wé àti fífi lẹ́ẹ̀dì tẹ̀wé sílẹ̀ tá a bẹ̀rẹ̀ sí í lo kọ̀ǹpútà àti ẹ̀rọ ìtẹ̀wé alátẹ̀yípo. Mi ò mọ ohunkóhun nípa kọ̀ǹpútà, ṣùgbọ́n mo mọ̀ ìlànà bá a ṣe ń ṣe ètò àwọn nǹkan àti bá a ṣe ń bá àwọn èèyàn ṣiṣẹ́ pọ̀.

Kété lẹ́yìn ìyẹn la rí i pé ó di dandan fún wa láti jẹ́ kí Ẹ̀ka Àwòrán Yíyà túbọ̀ dára sí i, nítorí pé a fẹ́ bẹ̀rẹ̀ sí tẹ àwọn ìwé wa ní aláwọ̀ mèremère ká sì máa lo oríṣiríṣi àwọ̀ fún àwọn àwòrán tá a bá fi ṣàpèjúwe nǹkan àti àwọn fọ́tò tá a bá yà. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé èmi kì í ṣe ayàwòrán, síbẹ̀ mo lè ṣèrànwọ́ láti jẹ́ kí nǹkan lọ létòlétò. Nítorí ìdí èyí, mo láǹfààní láti jẹ́ alábòójútó ẹ̀ka yẹn fún odindi ọdún mẹ́sàn-án gbáko.

Nígbà tó di ọdún 1992, wọ́n yàn mi láti ṣèrànwọ́ fún Ìgbìmọ̀ Ìṣèwéjáde ti Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso, wọ́n sì gbé mi lọ sí Ọ́fíìsì Akápò. Ibí yìí ni mo ti wá bẹ̀rẹ̀ sí ṣiṣẹ́ tó ní í ṣe pẹ̀lú ètò ìnáwó àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà.

Sísìn Láti Ìgbà Èwe Mi Wá

Jèhófà ti kọ́ mi láti ìgbà èwe mi wá àti ní àádọ́rin ọdún tí mo ti fi ṣe iṣẹ́ ìsìn àtọkànwá fún un. Ó ti mú sùúrù pẹ̀lú mi ó sì kọ́ mi nípasẹ̀ Bíbélì, Ọ̀rọ̀ rẹ̀, àti àwọn arákùnrin tó wúlò gan-an nínú ètò àjọ rẹ̀ tó ga lọ́lá. Mo ti gbádùn ohun tó lé ní ọdún mẹ́tàlélọ́gọ́ta nínú iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún, èyí tó sì lé ní ọdún márùndínlọ́gọ́ta níbẹ̀ ni mo gbádùn pẹ̀lú Julie aya mi ọ̀wọ́n. Láìsí àní-àní, mo rí i pé Jèhófà bù kún mi gan-an ni.

Nígbà yẹn lọ́hùn-ún, lọ́dún 1940 tí mo fẹ́ kúrò nílé láti wọnú iṣẹ́ ìsìn aṣáájú ọ̀nà, bàbá mi fi mi ṣe yẹ̀yẹ́ nítorí ìpinnu tí mo ṣe, ó sì sọ pé: “Ọmọ, nígbà tó o bá fi ilé sílẹ̀ láti lọ ṣe ohun tó o sọ yìí, má retí pé wàá tún sáré wálé wá bá mi fún ìrànlọ́wọ́ kankan o.” Láti àwọn ọdún wọ̀nyí wá, mi ò ṣe ohun tó jọ bẹ́ẹ̀. Jèhófà ti pèsè àwọn ohun tí mo nílò lọ́pọ̀ yanturu, ọ̀pọ̀ ìgbà lèyí sì jẹ́ nípasẹ̀ àwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ mi. Nígbà tó yá, bàbá mi náà wá mọrírì iṣẹ́ wa gan-an, ó tiẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ Bíbélì fúngbà díẹ̀ kó tó kú ní 1972. Màmá, tó ní ìrètí gbígbé ní òkè ọ̀run, sin Jèhófà tọkàntọkàn títí di ìgbà ikú rẹ̀ ní 1985, ní ẹni ọdún méjìlélọ́gọ́rùn-ún [102].

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ìṣòro máa ń yọjú nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún, síbẹ̀ èmi àti Julie ò ronú pé a fẹ́ fi iṣẹ́ wa sílẹ̀ rí. Jèhófà sì mú ẹsẹ̀ wa dúró lórí ìpinnu yìí. Kódà nígbà táwọn òbí mi ń darúgbó tí wọ́n sí nílò ìrànwọ́, ẹ̀gbọ́n mi obìnrin tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Victoria Marlin ló gba iṣẹ́ náà ṣe tó sì bójú tó wọn. A mọrírì ìrànwọ́ tó ṣe yìí gan-an ni, èyí tó mú kó ṣeé ṣe fún wa láti máa bá iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún wa lọ.

Julie dúró tì mí gbágbáágbá nínú gbogbo iṣẹ́ tí wọ́n yàn fún wa, ó ka èyí sí ara ìyàsímímọ́ rẹ̀ sí Jèhófà. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé mo ti di ẹni ọgọ́rin ọdún báyìí, tí àwọn àìlera kan sì ń bá mi fínra, síbẹ̀ mo rí i pé Jèhófà ti bù kún mi gan-an ni. Mo rí ìṣírí tó pọ̀ gbà látọ̀dọ̀ onísáàmù tó jẹ́ pé lẹ́yìn tó polongo pé Ọlọ́run ti kọ́ òun láti ìgbà èwe òun wá, ó tún bẹ̀bẹ̀ pé, ‘Àní títí di ọjọ́ ogbó àti orí ewú, Ọlọ́run, má fi mí sílẹ̀, títí èmi yóò fi lè sọ nípa apá rẹ fún ìran tó ń bọ̀.’—Sáàmù 71:17, 18.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Warren ni ẹ̀gbọ́n Milton Henschel, tó sìn gẹ́gẹ́ bi ọkàn lára Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso ti àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà fún ọ̀pọ̀ ọdún.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 20]

Èmi àti Màmá rèé lọ́dún 1940, nígbà tí mo bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 21]

Èmi àti Joe òun Margaret Hart, tá a jọ ṣe iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]

Ọjọ́ ìgbéyàwó wa ní January 1948

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]

Ní 1953, èmi àtàwọn tá a jọ wà ni kíláàsì kan náà ní ilé ẹ̀kọ́ Gílíádì. Láti apá òsì sí apá ọ̀tún: Don àti Virginia Ward, Geertruida Stegenga, Julie, àti èmi

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]

Èmi àti Frederick W. Franz àti Nathan H. Knorr ní Copenhagen, Denmark, 1961

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]

Èmi àti Julie rèé lónìí