Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ní Ẹ̀mí Fífúnni Ní Nǹkan

Ní Ẹ̀mí Fífúnni Ní Nǹkan

Ní Ẹ̀mí Fífúnni Ní Nǹkan

KÒ SÍ ẹni tá a bí pẹ̀lú ẹ̀mí fífúnni ní nǹkan. Gbogbo ohun tó wà lọ́kàn ọmọdé jòjòló kò jú bí yóò ṣe rí gbogbo ohun tó bá fẹ́, kódà kò sóhun tó kàn án nípa ire ẹni tó ń tọ́jú ẹ̀. Àmọ́ ṣá o, bọ́jọ́ ti ń gorí ọjọ́, ọmọ náà á wá mọ̀ pé ẹni kan kì í jẹ kílẹ̀ fẹ̀. Ó yẹ kó máa gba tẹlòmíràn rò, kó kọ́ bá a ṣe ń fúnni ní nǹkan àti bá a ṣe ń ṣàjọpín nǹkan, kì í ṣe kó sáà máa gbà nìkan. Ó yẹ kó ní ẹ̀mí fífúnni ní nǹkan.

Kì í ṣe gbogbo àwọn tó ń fúnni ní nǹkan ló lẹ́mìí ọ̀làwọ́, kódà kì í ṣe gbogbo àwọn tó ń fúnni ní nǹkan lọ́pọ̀ yanturu pàápàá ló jẹ́ ọ̀làwọ́. Àwọn kan lè ṣètọrẹ àánú nítorí ire tara wọn. Àwọn mìíràn sì máa ń ṣe é nítorí kí wọ́n lè di ẹni tí ayé ń kan sáárá sí. Àmọ́ ṣá o, báwọn Kristẹni tòótọ́ ṣe ń fúnni ní nǹkan yàtọ̀ pátápátá. Nígbà náà, ọ̀nà wo ní Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run gba wá níyànjú pé ká máa gbà fúnni ní nǹkan? Àyẹ̀wò ṣókí nípa bí àwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní ṣe fúnni ní nǹkan yóò dáhùn ìbéèrè yẹn.

Àwọn Àpẹẹrẹ Ọ̀nà Tí Kristẹni Gba Ń Fúnni Ní Nǹkan

Gẹ́gẹ́ bá a ṣe ṣàpèjúwe rẹ̀ nínú Bíbélì, kìkì àwọn tó nílò nǹkan gan-an ni àwọn Kristẹni máa ń ṣe “àjọpín àwọn nǹkan pẹ̀lú.” (Hébérù 13:16; Róòmù 15:26) A ò sì retí kí wọ́n ṣe é tipátipá. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Kí olúkúlùkù ṣe gan-an gẹ́gẹ́ bí ó ti pinnu nínú ọkàn-àyà rẹ̀, kì í ṣe pẹ̀lú ìlọ́tìkọ̀ tàbí lábẹ́ àfipáṣe, nítorí Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ olùfúnni ọlọ́yàyà.” (2 Kọ́ríńtì 9:7) A kò tún gbọ́dọ̀ fúnni ní nǹkan lọ́nà ṣekárími. Ohun tí Ananíà àti Sáfírà ṣe nìyẹn, wọ́n sì ko àgbákò.—Ìṣe 5:1-10.

Ohun kan ṣẹlẹ̀ tó sọ ọ́ di dandan láti fúnni ní nǹkan, ìyẹn nígbà táwọn Júù àtàwọn aláwọ̀ṣe láti ibi tó jìnnà pé jọ sí Jerúsálẹ́mù láti ṣe àjọyọ̀ Pẹ́ńtíkọ́sì ní ọdún 33 Sànmánì Tiwa. Ibẹ̀ ní àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù ti “kún fún ẹ̀mí mímọ́, [tí] wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí fi onírúurú ahọ́n àjèjì sọ̀rọ̀.” Ogunlọ́gọ̀ àwọn èèyàn tó wà níbẹ̀ ló gbọ́ ọ̀rọ̀ tó ń tani jí tí Pétérù sọ nípa Jésù Kristi. Nígbà tó yá, àwọn èèyàn rí i bí Pétérù àti Jòhánù ṣe mú ọkùnrin arọ kan lára dá lẹ́nu ọ̀nà tẹ́ńpìlì, wọ́n sì gbọ́ lẹ́ẹ̀kan sí i nígbà tí Pétérù tún sọ̀rọ̀ nípa Jésù àti ìdí tí wọ́n fi ní láti ronú pìwà dà. Ẹgbẹẹgbẹ̀rún èèyàn ló ronú pìwà dà tí wọ́n sì ṣe batisí gẹ́gẹ́ bí ọmọ ẹ̀yìn Jésù.—Ìṣe orí kejì àti ìkẹta.

Àwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ yí padà yìí fẹ́ láti dúró sí Jerúsálẹ́mù kí wọ́n lè gbà ìtọ́ni sí i lọ́dọ̀ àwọn àpọ́sítélì Jésù. Ṣùgbọ́n báwo ni àwọn àpọ́sítélì ṣe máa bójú tó gbogbo àwọn àlejò yìí? Àkọsílẹ̀ Bíbélì sọ fun wa pé: “Gbogbo àwọn tí ó ní pápá tàbí ilé a tà wọ́n, wọn a sì mú iye owó àwọn ohun tí wọ́n tà wá, wọn a sì fi wọ́n lélẹ̀ lẹ́bàá ẹsẹ̀ àwọn àpọ́sítélì. Ẹ̀wẹ̀, wọn a pín nǹkan fún olúkúlùkù, gan-an gẹ́gẹ́ bí àìní rẹ̀ bá ṣe rí.” (Ìṣe 4:33-35) Ka sòótọ́, ìjọ Jerúsálẹ́mù tá a ṣẹ̀ṣẹ̀ dá sílẹ̀ ní ẹ̀mí fífúnni ní nǹkan!

Nígbà tó yá àwọn ìjọ mìíràn náà fi ẹ̀mí fífúnni ní nǹkan hàn. Bí àpẹẹrẹ, báwọn Kristẹni tó wà ní Makedóníà kò tiẹ̀ lọ́rọ̀, wọ́n ṣe ré kọjá ohun tá a retí pé kí wọ́n ṣe nígbà tí wọ́n ṣètọrẹ fáwọn arákùnrin tó jẹ́ aláìní tó wà ní Jùdíà. (Róòmù 15:26; 2 Kọ́ríńtì 8:1-7) Ìjọ tó wà ní Fílípì ṣe gudugudu méje láti ṣètìlẹyìn fún iṣẹ́ òjíṣẹ́ Pọ́ọ̀lù. (Fílípì 4:15, 16) Ojoojúmọ́ ni ìjọ tó wà ní Jerúsálẹ́mù máa ń pín oúnjẹ fáwọn opó tó jẹ́ tálákà, àwọn àpọ́sítélì sì yan àwọn ọkùnrin méje tó tóótun láti rí sí i pé kò sí opó kankan tó yẹ kó rí nǹkan gba tá a gbójú fò dá.—Ìṣe 6:1-6.

Kódà ojú ẹsẹ̀ làwọn ìjọ́ Kristẹni ìjímìjí bẹ̀rẹ̀ sí í kó nǹkan jọ de ìgbà tí nǹkan máa le. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí wòlíì Ágábù sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa ìyàn ńlá kan, àwọn ọmọ ẹ̀yìn tó wà nínú ìjọ Áńtíókù ti Síríà “pinnu, ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn gẹ́gẹ́ bí agbára olúkúlùkù ti lè gbé e, láti fi ìpèsè a-dín-ìṣòro-kù ránṣẹ́ sí àwọn ará tí ń gbé ní Jùdíà.” (Ìṣe 11:28, 29) Ẹ ò ri pé ẹ̀mí tó dára ni wọ́n fi hàn yẹn ni ti pé wọ́n múra sílẹ̀ de ìgbà táwọn mìíràn máa nílò nǹkan!

Kí ló sún àwọn Kristẹni àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ tí wọ́n fi lawọ́ tí wọ́n sì nífẹ̀ẹ́ bẹ́ẹ̀? Báwo tiẹ̀ lẹnì kan ṣe lè ní ẹ̀mí fífúnni ní nǹkan? À lè rí ohun púpọ̀ kọ́ tá a bá gbé àpẹẹrẹ Ọba Dáfídì yẹ wò.

Dáfídì Fi Ẹ̀mí Ọ̀làwọ́ Ṣètìlẹyìn fún Ìjọsìn Tòótọ́

Fún ohun tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta ọdún ni àpótí májẹ̀mú tí í ṣe àpótí mímọ́ tó ṣojú fún Jèhófà kò fi sí ní ibì kan pàtó. Wọ́n gbé e pa mọ́ sínú àgọ́ tàbí sínú àgọ́ ìjọsìn tí wọ́n ń gbé láti ibì kan sí ibòmíràn nígbà táwọn ọmọ Ísírẹ́lì ń rìn kiri láginjù àti nígbà tí wọ́n dé Ilẹ̀ Ìlérí níkẹyìn. Ohun tó wu Ọba Dáfídì jù lọ ni pé kó gbé àpótí májẹ̀mú náà kúrò níbi tí wọ́n gbé e pa mọ́ sí, kó sì kọ́ ilé tó bójú mu fún Jèhófà, ìyẹn ilé tí wọ́n máa gbé àpótí májẹ̀mú mímọ́ náà sí. Nígbà tí Dáfídì ń bá wòlíì Nátánì sọ̀rọ̀, ó sọ pé: “Kíyè sí i, èmi ń gbé inú ilé kédárì, ṣùgbọ́n àpótí májẹ̀mú Jèhófà wà lábẹ́ àwọn aṣọ àgọ́.”—1 Kíróníkà 17:1.

Àmọ́ ṣá o, jagunjagun ni Dáfídì. Ìdí nìyẹn tí Jèhófà fi pàṣẹ pé Sólómọ́nì ọmọ rẹ̀ tí yóò fi àlàáfíà ṣàkóso ni yóò kọ́ tẹ́ńpìlì tí wọn yóò gbé àpótí májẹ̀mú náà sí. (1 Kíróníkà 22:7-10) Bó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, ìyẹn ò paná ẹ̀mí fífúnni tí Dáfídì ní. Ó ṣètò ìgbìmọ̀ amúṣẹ́ṣe kan, ó sì pèsè àwọn ohun èlò tí wọ́n máa lò láti fi kọ́ tẹ́ńpìlì náà. Nígbà tó yá, ó sọ fún Sólómọ́nì pé: “Mo ti pèsè ọ̀kẹ́ márùn-ún tálẹ́ńtì wúrà sílẹ̀ fún ilé Jèhófà àti àádọ́ta ọ̀kẹ́ tálẹ́ńtì fàdákà, àti bàbà àti irin láìsí ọ̀nà tí a fi lè wọ̀n wọ́n nítorí tí wọ́n wá pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ ní ìwọ̀n; mo sì ti pèsè àwọn ẹ̀là gẹdú àti òkúta sílẹ̀.” (1 Kíróníkà 22:14) Nígbà tí ìyẹn ò tún tẹ́ ẹ lọ́rùn, Dáfídì mú wúrà àti fàdákà tí iye rẹ̀ lé ní bílíọ̀nù kan owó dọ́là lónìí [$1,200,000,000] láti inú ohun ìní ti ara rẹ̀ láti fi ṣètìlẹyìn. Ìyẹn nìkan kọ́ o, àwọn ọmọ ọba náà ṣètìlẹyìn lọ́pọ̀ yanturu. (1 Kíróníkà 29:3-9) Dájúdájú, Dáfídì fi ẹ̀mí ọ̀làwọ́ hàn, àní ẹ̀mí fífúnni ní nǹkan!

Kí ló sún Dáfídì láti fúnni lọ́pọ̀ yanturu tó bẹ́ẹ̀? Ó mọ̀ pé gbogbo ohun tí òun ní àti gbogbo àṣeyọrí òun kò ṣàdédé wá, ṣùgbọ́n ó rí bẹ́ẹ̀ nítorí pé Jèhófà ló bù kún òun. Ó jẹ́wọ́ èyí nínú àdúrà rẹ̀ pé: “Jèhófà Ọlọ́run wa, gbogbo ọ̀pọ̀ yanturu yìí tí a ti pèsè sílẹ̀ láti fi kọ́ ilé fún orúkọ mímọ́ rẹ, ọwọ́ rẹ ni ó ti wá, tìrẹ sì ni gbogbo rẹ̀ jẹ́. Mo sì mọ̀ dáadáa, ìwọ Ọlọ́run mi, pé ìwọ jẹ́ olùṣàyẹ̀wò ọkàn-àyà, àti pé ìwà òtítọ́ ni ìwọ ní ìdùnnú sí. Èmi, ní tèmi, ti fínnú-fíndọ̀ fún ọ ní gbogbo nǹkan wọ̀nyí nínú ìdúróṣánṣán ọkàn-àyà mi, nísinsìnyí mo ti gbádùn rírí àwọn ènìyàn rẹ tí ó wà ní àrọ́wọ́tó níhìn-ín tí wọ́n ń ṣe àwọn ìtọrẹ àfínnúfíndọ̀ṣe fún ọ.” (1 Kíróníkà 29:16, 17) Dáfídì mọyì àjọṣe àárín òun àti Jèhófà. Ó mọ ìdí tó fi ṣe pàtàkì láti “fi ọkàn-àyà pípé pérépéré àti ọkàn tí ó kún fún inú dídùn” sin Ọlọ́run, inú rẹ̀ sì máa ń dùn láti ṣe bẹ́ẹ̀. (1 Kíróníkà 28:9) Irú ànímọ́ yìí náà ló sún àwọn Kristẹni àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ láti ní ẹ̀mí fífúnni ní nǹkan.

Jèhófà Jẹ́ Olùfúnni Tí Kò Lẹ́gbẹ́

Jèhófà ni àpẹẹrẹ tó dára jù lọ tó bá di ká fúnni ní nǹkan. Ó nífẹ̀ẹ́, ó sì bìkítà gan-an débi pé ‘ó ń mú kí oòrùn rẹ̀ ràn sórí àwọn ènìyàn burúkú àti rere, ó sì ń mú kí òjò rọ̀ sórí àwọn olódodo àti aláìṣòdodo.’ (Mátíù 5:45) Gbogbo ọmọ ènìyàn ló fún “ní ìyè àti èémí àti ohun gbogbo.” (Ìṣe 17:25) Àní ọmọ ẹ̀yìn Jésù náà Jákọ́bù sọ pé: “Gbogbo ẹ̀bùn rere àti gbogbo ọrẹ pípé jẹ́ láti òkè, nítorí a máa sọ̀ kalẹ̀ wá láti ọ̀dọ̀ Baba àwọn ìmọ́lẹ̀ àtọ̀runwá.”—Jákọ́bù 1:17.

Ẹ̀bùn tó tíì ga jù lọ tí Jèhófà fún wa ni fífi tó fi “Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo fúnni, kí olúkúlùkù ẹni tí ó bá ń lo ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀ má bàa pa run, ṣùgbọ́n kí ó lè ní ìyè àìnípẹ̀kun.” (Jòhánù 3:16) Kò sẹ́ni tó lè sọ pé irú ẹ̀bùn bẹ́ẹ̀ tọ́ sóun, “nítorí gbogbo ènìyàn [ló] ti ṣẹ̀, wọ́n sì ti kùnà láti kúnjú ìwọ̀n ògo Ọlọ́run.” (Róòmù 3:23, 24; 1 Jòhánù 4:9, 10) Ẹbọ ìràpadà Kristi ni ìpìlẹ̀ àti ọ̀nà láti rí “inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run títayọ ré kọjá,” gbà ìyẹn, “ẹ̀bùn ọ̀fẹ́ Rẹ̀ aláìṣeé-ṣàpèjúwe.” (2 Kọ́ríńtì 9:14, 15) Nítorí pé Pọ́ọ̀lù mọyì ẹ̀bùn Ọlọ́run, ó fi jíjẹ́rìí “kúnnákúnná sí ìhìn rere nípa inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run” ṣe iṣẹ́ to yàn láàyò. (Ìṣe 20:24) Ó mọ̀ dáadáa pé ìfẹ́ Ọlọ́run ni pé “kí a gba gbogbo onírúurú ènìyàn là, kí wọ́n sì wá sí ìmọ̀ pípéye nípa òtítọ́.”—1 Tímótì 2:4.

Lónìí, à ń ṣe èyí nípa iṣẹ́ ìwàásù àti kíkọ́ni tó ti gbilẹ̀ dé igba ó lé mẹ́rìnlélọ́gbọ̀n [234] ilẹ̀ yíká ayé nísinsìnyí. Jésù sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa ìmúgbòòrò yìí nígbà tó sọ pé: “A ó sì wàásù ìhìn rere ìjọba yìí ní gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé, láti ṣe ẹ̀rí fún gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè; nígbà náà ni òpin yóò sì dé.” (Mátíù 24:14) Bẹ́ẹ̀ ni o, “a ní láti kọ́kọ́ wàásù ìhìn rere náà ní gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè.” (Máàkù 13:10) Lọ́dún tó kọjá, àwọn olùpòkìkí ìhìn rere tó lé ní mílíọ̀nù mẹ́fà lo ohun tó lé ní bílíọ̀nù kan wákàtí [1,202,381,302] nínú ìṣẹ́ yìí, wọ́n sì darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tó lé ní mílíọ̀nù márùn [5,300,000]. Ìtọ́ni yìí ṣe pàtàkì gan-an nítorí pé ìwàláàyè àwọn èèyàn wà nínú ewu.—Róòmù 10:13-15; 1 Kọ́ríńtì 1:21.

Láti ran àwọn tí ebi òtítọ́ Bíbélì ń pa lọ́wọ́, ọ̀kẹ́ àìmọye àwọn ìwé là ń tẹ̀ jáde lọ́dọọdún, ara wọn ni Bíbélì, àwọn ìwé ńlá àti ìwé pẹlẹbẹ. Láfikún sí ìyẹn, iye tó lé ní bílíọ̀nù kan ẹ̀dà ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí! là ń tẹ̀ jáde. Báwọn èèyàn ṣe ń ṣe ohun tí ìhìn rere náà sọ fún wọ́n, ọ̀pọ̀ Gbọ̀ngàn Ìjọba àti Gbọ̀ngàn Àpéjọ ti àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà là túbọ̀ ń kọ́ sí i, à sì ń lò wọ́n gẹ́gẹ́ bí ibùdó tá a ti ń gba ìtọ́ni Bíbélì. Lọdọọdún là ń ṣètò àpèjọ àyíká, àpèjọ àkànṣe, títí kan àpèjọ agbègbè. Ìdánilẹ́kọ̀ọ́ fún àwọn míṣọ́nnárì, àwọn alábòójútó arìnrìn-àjò, àwọn alàgbà, àtàwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ náà kò dúró. A dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà fún pípèsè àwọn nǹkan wọ̀nyí nípasẹ̀ “ẹrú olóòótọ́ àti olóye.” (Mátíù 24:45-47) Ó dájú pé kò sí ohun mìíràn tá a lè ṣe, àfi ká máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Rẹ̀!

Fífi Ìmoore Hàn sí Jèhófà

Gbogbo owó tá a ń ná sórí àwọn nǹkan wọ̀nyí jẹ́ nípasẹ̀ ọrẹ àtinúwá, gẹ́gẹ́ bó ṣe rí nígbà tí wọ́n ń kọ́ tẹ́ńpìlì àti nígbà tí wọ́n ń pèsè ohun táwọn ará inú ìjọ Kristẹni àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ nílò. Àmọ́ ṣá o, kò yẹ ká gbàgbé pé kò sẹ́ni tó lè sọ Jèhófà dọlọ́rọ̀ nítorí pé Òun ló ni ohun gbogbo. (1 Kíróníkà 29:14; Hágáì 2:8) Nígbà náà, tá a bá ṣe ìtọrẹ, ó fì hàn pé a nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, a sì fẹ́ kí ìjọsìn tòótọ́ máa tẹ̀ síwájú. Pọ́ọ̀lù sọ pé fífi irú ìwà ọ̀làwọ́ bẹ́ẹ̀ hàn “ń mú ìfọpẹ́hàn wá fún Ọlọ́run.” (2 Kọ́ríńtì 9:8-13) Jèhófà fẹ́ ká máa fúnni lọ́nà yẹn nítorí tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, ó fi hàn pé a lẹ́mìí tó dáa àti pé ọ̀kan wa mọ́ sí òun. Jèhófà yóò bù kún àwọn tó bá lawọ́ tó sì gbẹ́kẹ̀ lé e, wọn yóò sì lọ́rọ̀ nípa tẹ̀mí. (Diutarónómì 11:13-15; Òwe 3:9, 10; 11:25) Jésù mú un dá wá lójú pé ayọ̀ ló máa ń gbẹ̀yìn fífúnni ní nǹkan nígbà tó sọ pé: “Ayọ̀ púpọ̀ wà nínú fífúnni ju èyí tí ó wà nínú rírígbà lọ.”—Ìṣe 20:35.

Àwọn Kristẹni tó lẹ́mìí fífúnni ní nǹkan kì í dúró dìgbà táwọn èèyàn bá nílò rẹ̀ kí wọ́n tó fúnni. Kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n máa ń wá ọ̀nà láti ṣe “ohun rere sí gbogbo ènìyàn, ṣùgbọ́n ní pàtàkì sí àwọn tí ó bá [wọn] tan nínú ìgbàgbọ́.” (Gálátíà 6:10) Nígbà tí Pọ́ọ̀lù ń gbani níyànjú láti ní ìwà ọ̀làwọ́ tínú Ọlọ́run dùn sí, ó kọ̀wé pé: “Ẹ má gbàgbé rere ṣíṣe àti ṣíṣe àjọpín àwọn nǹkan pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn, nítorí irú àwọn ẹbọ bẹ́ẹ̀ ni inú Ọlọ́run dùn sí jọjọ.” (Hébérù 13:16) Lílo àwọn ohun tá a ni, bí àkókò wa, okun wa àti owó wa láti fi ṣèrànwọ́ fáwọn mìíràn àti láti mú kí ìjọsìn tòótọ́ tẹ̀ síwájú máa ń dùn mọ́ Jèhófà Ọlọ́run nínú jọjọ. Ká sòótọ́, ó fẹ́ràn ẹ̀mí fífúnni ní nǹkan.

[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 28, 29]

Àwọn Ọ̀nà Táwọn Kan Yàn Láti Gbà Fúnni Ní Nǹkan

ÌTỌRẸ FÚN IṢẸ́ YÍKÁ AYÉ

Ọ̀pọ̀ ń ya iye kan sọ́tọ̀ tàbí kí wọ́n ṣètò iye owó kan tí wọ́n ń fi sínú àwọn àpótí ọrẹ tá a kọ “Contributions for the Worldwide Work [Ọrẹ fún Iṣẹ́ Yíká Ayé]Mátíù 24:14,” sí lára.

Oṣooṣù làwọn ìjọ máa ń fi owó wọ̀nyí ránṣẹ́ sí ẹ̀ka ọ́fíìsì àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ní orílẹ̀-èdè kọ̀ọ̀kan. O tún lè fi ọrẹ owó tó o fínnúfíndọ̀ ṣe ránṣẹ́ ní tààràtà sí Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania, c/o Office of the Secretary and Treasurer, 25 Columbia Heights, Brooklyn, New York 11201-2483, tàbí sí ẹ̀ka iléeṣẹ́ tí ń bójú tó orílẹ̀-èdè rẹ. Kí ẹ kọ orúkọ “Watch Tower” sórí ṣẹ́ẹ̀kì tàbí sọ̀wédowó èyíkéyìí tí ẹ bá fẹ́ fi ránṣẹ́, kí ó lè ṣeé ṣe fún wa láti rí owó náà gbà. O tún lè fi ohun ọ̀ṣọ́ ṣíṣeyebíye tàbí ohun àlùmọ́ọ́nì mìíràn ṣètọrẹ. Kí lẹ́tà ṣókí tó fi hàn pé irú ohun bẹ́ẹ̀ jẹ́ ẹ̀bùn bá àwọn ọrẹ wọ̀nyí rìn.

ÈTÒ ỌRẸ TÓ ṢEÉ GBÀ PADÀ

A lè fi owó ṣe ìtọrẹ lábẹ́ ìṣètò àkànṣe kan nínú èyí tí a óò dá owó náà padà fún ẹni tó fi tọrẹ, bó bá ṣẹlẹ̀ pé onítọ̀hún béèrè rẹ̀. Fún àfikún àlàyé, jọ̀wọ́ kàn sí Ọ́fíìsì Akọ̀wé àti Akápò ní àdírẹ́sì tá a kọ sókè yìí.

ÌFÚNNI TÍ A WÉWÈÉ

Ní àfikún sí ẹ̀bùn owó ní tààràtà àti ọrẹ tó ṣeé gbà padà, àwọn ọ̀nà mìíràn wà tá a lè gbà ṣètọrẹ fún àǹfààní iṣẹ́ Ìjọba náà kárí ayé. Lára wọn ni:

Owó Ìbánigbófò: A lè kọ orúkọ Watch Tower Society gẹ́gẹ́ bí olùjàǹfààní ètò ìbánigbófò ẹ̀mí tàbí olùjàǹfààní owó ìfẹ̀yìntì lẹ́nu iṣẹ́.

Àkáǹtì Owó ní Báńkì: A lè fi àkáǹtì owó ní báńkì, ìwé ẹ̀rí owó ìdókòwò, tàbí àkáǹtì owó ìfẹ̀yìntì lẹ́nu iṣẹ́ sí ìkáwọ́ Watch Tower Society, tàbí ká mú kó ṣeé san fún Society bí ẹni tó ni ín bá kú, ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ohun tí báńkì àdúgbò bá béèrè.

Ìwé Ẹ̀tọ́ Lórí Owó Ìdókòwò àti Ẹ̀yáwó: A lè fi ìwé ẹ̀tọ́ lórí owó ìdókòwò àti ẹ̀yáwó ta Watch Tower Society lọ́rẹ gẹ́gẹ́ bí ẹ̀bùn.

Dúkìá Ilé Tàbí Ilẹ̀: A lè fi dúkìá ilé tàbí ilẹ̀ tó ṣeé tà tọrẹ, yálà nípa fífi ṣe ẹ̀bùn, tàbí tó bá jẹ́ ilé gbígbé nípa pípa á mọ́ gẹ́gẹ́ bí ohun ìní tí olùtọrẹ náà ṣì lè máa lò nígbà ayé rẹ̀. Kàn sí ẹ̀ka iléeṣẹ́ tó wà lórílẹ̀-èdè rẹ kó o tó fi ìwé àṣẹ sọ dúkìá ilé tàbí ilẹ̀ èyíkéyìí di èyí tó o fi tọrẹ.

Ìwé Ìhágún àti Ohun Ìní Tí A Fi Síkàáwọ́ Onígbọ̀wọ́: A lè fi dúkìá tàbí owó sílẹ̀ bí ogún fún Watch Tower Society nípasẹ̀ ìwé ìhágún tá a ṣe lábẹ́ òfin, tàbí ká kọ orúkọ Watch Tower Society gẹ́gẹ́ bí olùjàǹfààní ohun ìní tá a fi síkàáwọ́ onígbọ̀wọ́. Àwọn ohun ìní tá a fi síkàáwọ́ onígbọ̀wọ́, tó jẹ́ pé ètò ìsìn kan ń jàǹfààní nínú rẹ̀ lè pèsè àwọn àǹfààní mélòó kan nínú ọ̀ràn owó orí.

Gẹ́gẹ́ bí ohun tí ọ̀rọ̀ náà, “ìfúnni tí a wéwèé” túmọ̀ sí, irú àwọn ọrẹ báwọ̀nyí ń béèrè fún àwọn ìwéwèé lọ́dọ̀ ẹni tó ń ṣètọrẹ. Láti ṣèrànwọ́ fáwọn èèyàn tó ń fẹ́ láti ṣe ìtìlẹyìn fún iṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà kárí ayé nípa oríṣiríṣi ìfúnni tá a wéwèé, Society ti ṣe ìwé pẹlẹbẹ kan lédè Gẹ̀ẹ́sì àti Spanish, tá a pe àkọlé rẹ̀ ní Charitable Planning to Benefit Kingdom Service Worldwide. A kọ ìwé pẹlẹbẹ náà láti dáhùn ọ̀pọ̀ ìbéèrè tá a ti rí gbà lórí ẹ̀bùn, ìwé ìhágún, àti ohun ìní tá a fi síkàáwọ́ onígbọ̀wọ́. Ó tún ní àfikún ìsọfúnni tó wúlò fún ìwéwèé ilé tàbí ilẹ̀, okòwò, àti owó orí nínú. Ó ń jẹ́ káwọn èèyàn mọ onírúurú ọ̀nà tí wọ́n lè gbà fúnni ní ẹ̀bùn nísinsìnyí tàbí bí wọ́n ṣe lè fi ẹ̀bùn sílẹ̀ nígbà tí wọ́n bá kú. Lẹ́yìn tí ọ̀pọ̀ ti ka ìwé pẹlẹbẹ náà, tí wọ́n sì ti fọ̀rọ̀ wérọ̀ pẹ̀lú àwọn lọ́yà wọn àti ẹ̀ka Charitable Planning Office, ó ti ṣeé ṣe fún ọ̀pọ̀ èèyàn láti ṣètìlẹ́yìn fún àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà kárí ayé, kí wọ́n sì tún rí àwọn àjẹmọ́nú gbà látinú owó orí tí wọ́n san. A lè rí ìwé yìí gbà nípa bíbéèrè fún ẹ̀dà kan ní tààràtà láti ẹ̀ka Charitable Planning Office.

Tó o bá nífẹ̀ẹ́ sí ìsọfúnni síwájú sí i, ó lè kàn sí ẹ̀ka Charitable Planning Office, yálà nípa kíkọ̀wé sí àdírẹ́sì tá a kọ sísàlẹ̀ yìí tàbí kó o pè wọ́n lórí ẹ̀rọ tẹlifóònù, tàbí kó o kàn sí ẹ̀ka iléeṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí ń bójú tó orílẹ̀-èdè rẹ.

Charitable Planning Office

Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania

100 Watchtower Drive,

Patterson, New York 12563-9204

Telephone: (845) 306-0707.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]

Kí ló sún àwọn Kristẹni àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ láti lẹ́mìí ọ̀làwọ́?