Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ǹjẹ́ A Rí Ẹni Tó Ṣeé Fọkàn Tán?

Ǹjẹ́ A Rí Ẹni Tó Ṣeé Fọkàn Tán?

Ǹjẹ́ A Rí Ẹni Tó Ṣeé Fọkàn Tán?

LẸ́YÌN tí Ògiri Berlin wó lulẹ̀ lọ́dún 1989 ni àwọn àṣírí bíi mélòó kan tó bò dáadáa tẹ́lẹ̀ wá tú síta. Bí àpẹẹrẹ, Lydia a wá rí i pé àjọ Stasi, tàbí Àjọ Aláàbò ilẹ̀ Jámánì ti kọ oríṣiríṣi nǹkan nípa àwọn ohun tí òun ṣe níkọ̀kọ̀ lákòókò tí Ẹgbẹ́ Àjùmọ̀ní ń ṣàkóso ní Ìlà Oòrùn Jámánì. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ya Lydia lẹ́nu láti gbọ́ nípa ohun tí wọ́n kọ yìí, ohun tó wá yà á lẹ́nu jù lọ ni pé ọkọ rẹ̀ gan-an ló fún àjọ Stasi ní àwọn ìsọfúnni náà. Ẹni tó yẹ kó fọkàn tán ti dà á.

Ìwé ìròyìn The Times ti London ròyìn pé, àgbàlagbà kan tó jẹ́ ọmọlúwàbí ni Robert, kò kóyán dókítà tó ń tọ́jú rẹ̀ kéré rárá, “ó bọ̀wọ̀ fún un gidigidi, ó gba tiẹ̀, ó sì fọkàn tán an.” Wọ́n sọ pé dókítà náà jẹ́ “onínúure àti ẹni tó lẹ́mìí ìbánikẹ́dùn.” Àmọ́ Robert wá kú lójijì. Ṣe àrùn ọkàn ló pa á ni àbí àrùn ẹ̀gbà? Rárá o, àwọn àrùn yìí kọ́. Ìwádìí tí àwọn aláṣẹ ṣe fi hàn pé dókítà náà wá bá Robert nílé, ó sì gún un ní abẹ́rẹ́ ikú láìjẹ́ kí Robert àti ìdílé rẹ̀ mọ̀ nípa èyí. Ó hàn gbangba pé ẹni tí Robert fọkàn tán ló ṣekú pa á.

Àwọn tí Lydia àti Robert fọkàn tán ló dà wọ́n, àbájáde rẹ̀ sì burú jáì. Ohun tó ń tibẹ̀ jáde lè má burú tó ìyẹn nínú àwọn ọ̀ràn mìíràn. Síbẹ̀síbẹ̀, kí ẹni tá a fọkàn tán dani kì í ṣe ohun tójú ò rírí. Ìròyìn tí àjọ ìṣèwádìí kan tó ń jẹ́ Allensbacher Jahrbuch der Demoskopie 1998-2002, nílẹ̀ Jámánì, gbé jáde fi hàn nínú ìwádìí kan pé ìpín mẹ́rìndínláàádọ́rùn-ún nínú ìpín ọgọ́rùn-ún àwọn tí wọ́n fọ̀rọ̀ wá lẹ́nu wò ló sọ pé ẹni táwọn fọkàn tán ti já àwọn kulẹ̀ rí. Ó ṣeé ṣe kí ìwọ náà ti ní irú ìrírí yẹn rí. Nítorí náà, kò yẹ kó yà wá lẹ́nu pé ìwé ìròyìn Switzerland tó ń jẹ́ Neue Zürcher Zeitung, ròyìn lọ́dún 2002 pé, “ó ti pẹ́ gan-an tí ìfọkàntánni ti di ohun àtijọ́ ní àwọn orílẹ̀-èdè oníléeṣẹ́ ńláńlá ní Ìwọ̀ Oòrùn ayé.”

Kì Í Dé Lójijì, Àmọ́ Ó Lè Pòórá Lójijì

Kí ló túmọ̀ sí láti fọkàn tánni? Láti fọkàn tán àwọn ẹlòmíràn túmọ̀ sí pé kó o gbà gbọ́ pé wọ́n jẹ́ aláìlábòsí àti olóòótọ́, àti pé wọn ò lè mọ̀ọ́mọ̀ ṣe ohunkóhun tó lè pa ọ́ lára. Kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀ la máa ń fọkàn tánni, kì í dé lójijì, àmọ́ ó lè pòórá lójú ẹsẹ̀. Níwọ̀n bí ọ̀pọ̀ èèyàn ṣe rí i pé a ti já àwọn kulẹ̀, ǹjẹ́ ó yẹ kó yà wá lẹ́nu pé àwọn èèyàn kì í fẹ́ fọkàn tán àwọn ẹlòmíràn mọ́? Ìwádìí kan tí wọ́n gbé jáde nílẹ̀ Jámánì lọ́dún 2002 fi hàn pé, “àwọn ọ̀dọ́ tó fọkàn tán àwọn ẹlòmíràn kò tó ẹyọ kan nínú mẹ́ta.”

A lè bi ara wa pé: ‘Ǹjẹ́ a rí ẹni tó tiẹ̀ ṣeé fọkàn tán? Ǹjẹ́ ó tiẹ̀ tọ́ láti fọkàn tán ẹni kan nígbà tá ò mọ̀ bóyá ó lè já wa kulẹ̀?’

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a A ti yí orúkọ wọn padà.

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 3]

Ìwádìí kan fi hàn pé ìpín mẹ́rìndínláàádọ́rùn-ún nínú ìpín ọgọ́rùn-ún àwọn tí wọ́n fọ̀rọ̀ wá lẹ́nu wò ló sọ pé ẹni táwọn fọkàn tán ti já àwọn kulẹ̀ rí