Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Ojú wo ló yẹ kí Kristẹni fi wo lílo òkúta ọ̀ṣọ́ tó ní í ṣe pẹ̀lú ọjọ́ ìbí?

Nínú àwọn àṣà ìbílẹ̀ kan, òkúta ọ̀ṣọ́ tó ní í ṣe pẹ̀lú ọjọ́ ìbí ni wọ́n so pọ̀ mọ́ oṣù tí wọ́n bí ẹnì kan. Bóyá Kristẹni kan yóò lo òrùka tó ní òkúta ọ̀ṣọ́ pàtó kan tàbí kò ní í lò ó, jẹ́ ọ̀ràn tí olúkúlùkù yóò pinnu fúnra rẹ̀. (Gálátíà 6:5) Láti ṣe ìpinnu yẹn, àwọn kókó pàtàkì wà tó yẹ fún àgbéyẹ̀wò.

Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ náà, Encyclopædia Britannica sọ nípa òkúta ọjọ́ ìbí pé ó jẹ́ “òkúta ọ̀ṣọ́ tó ní í ṣe pẹ̀lú ọjọ́ tí wọ́n bí ẹnì kan, èyí tí ọ̀pọ̀ èèyàn rò pé tẹ́nì kan bá lò ó, á jẹ́ kí onítọ̀hún ṣoríire.” Ìwé yìí fi kún un pé: “Tipẹ́tipẹ́ làwọn awòràwọ̀ ti gbà pé àwọn òkúta ọ̀ṣọ́ kan ní àwọn agbára àràmàǹdà.”

Pàápàá, láyé ọjọ́hun ọ̀pọ̀ ló gbà gbọ́ pé òkúta ọjọ́ ìbí máa ń gbé oríire ko ẹni tó bá lò ó. Ṣé Kristẹni tòótọ́ gba èyí gbọ́? Rárá o, nítorí wọ́n mọ̀ pé inú Jèhófà kò dùn sí ẹni tó bá kọ̀ òun sílẹ̀, tó wá gbẹ́kẹ̀ lé “ọlọ́run Oríire.”—Aísáyà 65:11.

Ní Sànmánì Ìgbà Ọ̀làjú, àwọn tó máa ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ oríire ti yan òkúta ọ̀ṣọ́ kan fún oṣù kọ̀ọ̀kan tó wà nínú ọdún. Wọ́n rọ àwọn èèyàn láti máa lo òkúta ọ̀ṣọ́ tó bá oṣù tí wọ́n bí wọn mu, bóyá kó lè dáàbò bò wọ́n kúrò nínú ewu. Ṣùgbọ́n kò bá Ìwé Mímọ́ mu pé kí Kristẹni máa tẹ̀lé ohun táwọn alásọtẹ́lẹ̀ ìṣẹ̀lẹ̀ bá sọ nítorí Bíbélì dẹ́bi fún irú àwọn èèyàn bẹ́ẹ̀.—Diutarónómì 18:9-12.

Bákan náà, kì í ṣe ohun tó bójú mu fún Kristẹni láti gbà pé òrùka kan ṣe pàtàkì nítorí pé ó ní òkúta ọ̀ṣọ́ tó ní í ṣe pẹ̀lú ọjọ́ ìbí lára. Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà kì í ṣe ọjọ́ ìbí. Ohun tó sì fa èyí ni pé irú àwọn ayẹyẹ bẹ́ẹ̀ máa ń pàfiyèsí sára ẹni tó ń ṣe ọjọ́ ìbí àti pé, àwọn àkọsílẹ̀ ọjọ́ ìbí tá a rí nínú Bíbélì jẹ́ tàwọn alákòóso tí kò sin Ọlọ́run.—Jẹ́nẹ́sísì 40:20; Mátíù 14:6-10.

Àwọn èèyàn kan rò pé lílo òrùka tó ní òkúta ọ̀ṣọ́ tó ní í ṣe pẹ̀lú ọjọ́ ìbí máa ń ní ipa tó dára lórí àkópọ̀ ìwà ẹni tó lò ó. Àmọ́ ṣá o, àwọn Kristẹni tòótọ́ kò gba èyí gbọ́, nítorí wọ́n mọ̀ pé kìkì lábẹ́ ìdarí ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run àti nípa fífi àwọn ìlànà inú Ìwé Mímọ́ sílò ni ẹnì kan fi lè ní “àkópọ̀ ìwà tuntun.”—Éfésù 4:22-24.

Ohun kan tó ṣe kókó ni ohun tó sún ẹnì kan lo òrùka kan. Nígbà tá a bá fẹ́ pinnu bóyá kí á lo òrùka tó ní òkúta ọjọ́ ìbí tàbí kí á má lò ó, Kristẹni kan lè bi ara rẹ̀ pé, ‘Bó tilẹ̀ jẹ́ pé òrùka kan ní ohun tí wọ́n ń pè ní òkúta ọjọ́ ìbí, ṣé nítorí pé òkúta ọ̀ṣọ́ yìí kàn wù mí ni mo ṣe fẹ́ lo òrùka náà? Àbí ìgbàgbọ́ nínú ohun asán táwọn kan ní lórí irú òkúta ọ̀ṣọ́ bẹ́ẹ̀ ló ti nípa lórí mi?’

Kristẹni kan gbọ́dọ̀ ṣàyẹ̀wò ọkàn rẹ̀ láti mọ ohun tó máa ń sún òun ṣe nǹkan. “Ju gbogbo ohun mìíràn tí a ní láti ṣọ́, fi ìṣọ́ ṣọ́ ọkàn-àyà rẹ,” ni ohun tí Ìwé Mímọ́ sọ nítorí, “láti inú rẹ̀ ni àwọn orísun ìyè ti wá.” (Òwe 4:23) Nígbà tí Kristẹni kan bá fẹ́ pinnu bóyá kí òun lo òrùka ọ̀ṣọ́ tó ní í ṣe pẹ̀lú ọjọ́ ìbí tàbí kí òun má lò ó, yóò dára kó ṣàyẹ̀wò ohun tó ń mú kí òun ṣe nǹkan àti ipa tó ṣeé ṣe kí ohun tóun ṣe yẹn ní lórí òun alára àti lórí àwọn ẹlòmíràn.—Róòmù 14:13.