Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

“Ẹ Wo Bí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Ṣe Lágbára Tó!”

“Ẹ Wo Bí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Ṣe Lágbára Tó!”

“Ẹ Wo Bí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Ṣe Lágbára Tó!”

“Ọ̀RỌ̀ Ọlọ́run yè, ó sì ń sa agbára.” (Hébérù 4:12) Láti lè jẹ́rìí sí agbára Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tí èèyàn ò lè dí lọ́wọ́, 2003 Calendar of Jehovah’s Witnesses gbé ìtàn ìgbésí ayé àwọn èèyàn jáde kárí ayé. Lábẹ́ àkòrí náà “Nígbà Kan Rí àti Nísinsìnyí,” kàlẹ́ńdà náà fi hàn bí iṣẹ́ ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ láti túbọ̀ mú kí ìwà wọn dára sí i, kí wọ́n kọ ìgbésí ayé játijàti sílẹ̀ àti láti mú kí ìgbésí ayé ìdílé wọn dára sí i, tó sì tún mú kí àjọṣe tó wà láàárín àwọn àti Ọlọ́run túbọ̀ dán mọ́rán.

A ti rí lẹ́tà ìdúpẹ́ bíi mélòó kan gbà nípa kàlẹ́ńdà 2003 náà. Díẹ̀ lára àwọn ohun tí wọ́n sọ rèé:

“Kàlẹ́ńdà yìí jẹ́ ẹ̀rí láti jẹ́ káwọn Kristẹni tòótọ́ mọ̀ pé àwọn kan wà tó ń ja fitafita bíi tiwọn nítorí ìgbàgbọ́. Ní báyìí, àwọn Kristẹni tòótọ́ lè wo àwọn àwòrán náà, kí wọ́n sì rántí àwọn ìyípadà táwọn náà ti ṣe.”—Steven, United States.

“Mo dìídì kọ ìwé yìí láti jẹ́ kẹ́ ẹ mọ bí kàlẹ́ńdà 2003 yìí ṣe wọ̀ mí lọ́kàn tó. Kò sí kàlẹ́ńdà tó tíì nípa lórí mi tó èyí rí. Ìtàn ìgbésí ayé àwọn èèyàn yìí yóò di ọ̀kan lára ohun tí máa fi sínú àpò òde ẹ̀rí mi láti jẹ́ káwọn èèyàn rí àwọn ẹ̀rí tó ṣeé fojú rí, tó sì mórí ẹni yá gágá nípa agbára tí Bíbélì lè ní lórí ẹnì kọ̀ọ̀kan.”—Marc, Belgium.

“Orí mi wú gan-an nígbà tí mo rí kàlẹ́ńdà yìí. Ó wọ̀ mí lára gan-an nígbà tí mo kà á tí mo sì rí bí Jèhófà ṣe yí ìgbésí ayé àwọn èèyàn padà. Ìyẹn ti wá fún mí ní ìṣírí ńláǹlà láti máa ṣe àwọn ìyípadà kan nínú ìgbésí ayé mi. Ní báyìí, mo ti wá rí i pé mo wà láàárín ẹgbẹ́ àwọn ará kárí ayé ju ti ìgbàkigbà rí lọ.”—Mary, United States.

“Àánú ṣe Jésù gan-an nígbà tó rí ìṣòro tẹ̀mí táwọn èèyàn ní. Ẹ ṣeun púpọ̀ fún bí ẹ ṣe fara wé àpẹẹrẹ Kristi nípa gbígbé ìtàn ìgbésí ayé àwọn èèyàn jáde nínú kàlẹ́ńdà 2003. Kò tíì sí ìgbà kan rí nínú ìgbésí ayé mi tí kàlẹ́ńdà wú mi lórí débi tí mo fi sunkún.”—Cassandra, United States.

“Nígbà tí mo wà lọ́mọ ọdún mọ́kànlá, mo bẹ̀rẹ̀ sí mu sìgá; nígbà tó yá, mò ń lo oògùn olóró. Ọ̀pọ̀ ìgbà ni mo máa ń ronú láti gbẹ̀mí ara mi. Nígbà tí mo mọ Jèhófà, a ràn mí lọ́wọ́ láti pà gbogbo ìwà yẹn tì. Kàlẹ́ńdà yìí ṣe pàtàkì sí mí gan-an ni. Àpẹẹrẹ àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin mi kárí ayé ti fún mi lókun. Ní báyìí, mo ti wá mọ̀ pé kì í ṣe èmi nìkan ló ń ja ìjà yìí, àti pé ohun tó ṣe pàtàkì jù ni kéèyàn nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, kó sì sìn ín tọkàntọkàn.”—Margaret, Poland.

“Áà, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run mà lágbára gan-an o! Nígbà tí mo gba kàlẹ́ńdà 2003, mo gbìyànjú láti má ṣe sunkún. Àwọn ìrírí àtàwọn àwòrán wọ̀nyẹn ń fún ìgbàgbọ́ lókun gan-an ni.”—Darlene, United States.

“Ìgbésí ayé tí àwọn kan lára àwọn èèyàn yìí gbé tẹ́lẹ̀ jọ ìgbésí ayé témi náà gbé tẹ́lẹ̀. Jèhófà ti fún mi lókun láti borí àwọn ìwà burúkú tó dà bí èyí tí kò ṣeé borí. Ẹ ṣeun púpọ̀ fún ìtàn ìgbésí ayé àwọn èèyàn yìí.”—William, United States.