Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ayé Kan Láìsí Ìwà Ọ̀daràn Ti Sún Mọ́lé

Ayé Kan Láìsí Ìwà Ọ̀daràn Ti Sún Mọ́lé

Ayé Kan Láìsí Ìwà Ọ̀daràn Ti Sún Mọ́lé

TÓ O bá lè ṣe é, fojú inú wo ayé kan láìsí àwọn ọ̀daràn! A kò ní nílò ọlọ́pàá àti ọ̀gbà ẹ̀wọ̀n mọ́, bẹ́ẹ̀ ni kò ní sí ètò ìdájọ́ tó ń náni lówó tí kì í sì í yéni bọ̀rọ̀, èyí tí wọ́n gbé kalẹ̀ nítorí ìwà ọ̀daràn. Yóò jẹ́ ayé kan tí olúkúlùkù yóò ti bọ̀wọ̀ fún ìwàláàyè àti ohun ìní àwọn ẹlòmíràn. Ǹjẹ́ eléyìí ò dà bí àlá tí kò lè ṣẹ? O lè rò bẹ́ẹ̀, ṣùgbọ́n ìyípadà àgbàyanu tó máa mú nǹkan sunwọ̀n sí i yìí ni ohun tí Bíbélì ṣèlérí. Kí ló dé tó ò ṣàyẹ̀wò ohun tí Ìwé Mímọ́ sọ tẹ́lẹ̀ nípa ìwà ọ̀daràn àtàwọn ìwà láabi mìíràn lórí ilẹ̀ ayé?

Nínu ìwé Sáàmù, a kà pé: “Má ṣe gbaná jẹ nítorí àwọn aṣebi. Má ṣe ìlara àwọn tí ń ṣe àìṣòdodo. Nítorí pé bí koríko ni wọn yóò rọ pẹ̀lú ìyára kánkán, àti bí àṣẹ̀ṣẹ̀yọ koríko tútù ni wọn yóò rẹ̀ dànù. Ṣùgbọ́n àwọn ọlọ́kàn tútù ni yóò ni ilẹ̀ ayé, ní tòótọ́, wọn yóò sì rí inú dídùn kíkọyọyọ nínú ọ̀pọ̀ yanturu àlàáfíà.” (Sáàmù 37:1, 2, 11) Ká sòótọ́, kò sẹ́ni tó lè dí Ọlọ́run lọ́wọ́ pé kó máà mú ìlérí yìí àtàwọn ìlérí rẹ̀ mìíràn tó fini lọ́kàn balẹ̀ ṣẹ.

Ọlọ́run yóò lo Ìjọba rẹ̀ láti mú àwọn ìbùkún wọ̀nyí wá. Nínú Àdúrà Olúwa, Jésù Kristi kọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ láti máa gbàdúrà pé kí Ìjọba yìí dé àti pé kí ìfẹ́ Ọlọ́run ṣẹ “gẹ́gẹ́ bí ti ọ̀run, lórí ilẹ̀ ayé pẹ̀lú.” (Mátíù 6:9, 10) Láìpẹ́, lábẹ́ Ìjọba yẹn, kò sẹ́ni tí ipò òṣì, ìnilára tàbí ìmọtara-ẹni-nìkan yóò sún láti hu ìwà ọ̀daràn. Dípò ìyẹn, ohun tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ ni pé: “Ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ ọkà yóò wá wà lórí ilẹ̀; àkúnwọ́sílẹ̀ yóò wà ní orí àwọn òkè ńlá.” (Sáàmù 72:16) Láìṣe àní-àní, Jèhófà Ọlọ́run yóò pèsè àwọn ohun rere lọ́pọ̀ yanturu fún gbogbo ẹni tí ń gbé orí ilẹ̀ ayé. Ní pàtàkì, ìfẹ́ fún Ọlọ́run àti fún aládùúgbò ẹni ni yóò máa sún àwùjọ ẹ̀dá èèyàn ṣe nǹkan, àní ìwà ọ̀daràn kì yóò tún yọ ayé lẹ́nu mọ́ láéláé.