Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ran Àwọn Ẹlòmíràn Lọ́wọ́ Láti Tẹ́wọ́ Gba Ìhìn Ìjọba Náà

Ran Àwọn Ẹlòmíràn Lọ́wọ́ Láti Tẹ́wọ́ Gba Ìhìn Ìjọba Náà

Ran Àwọn Ẹlòmíràn Lọ́wọ́ Láti Tẹ́wọ́ Gba Ìhìn Ìjọba Náà

“Ágírípà wí fún Pọ́ọ̀lù pé: ‘Ní àkókò kúkúrú, ìwọ yóò yí mi lérò padà di Kristẹni.’”—ÌṢE 26:28.

1, 2. Kí nìdí tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fi fara hàn níwájú Gómìnà Fẹ́sítọ́ọ̀sì àti Ọba Hẹ́rọ́dù Àgírípà Kejì?

 ỌBA Hẹ́rọ́dù Àgírípà Kejì àti Bẹ̀níìsì àbúrò rẹ̀ obìnrin wá sí ọ̀dọ̀ Pọ́kíọ́sì Fẹ́sítọ́ọ̀sì tó jẹ́ gómìnà Róòmù ní Kesaréà lọ́dún 58 Sànmánì Tiwa. Nítorí pé Gómìnà Fẹ́sítọ́ọ̀sì pè wọ́n ni wọ́n ṣe wá láti Jerúsálẹ́mù. Ní ọjọ́ kejì, “pẹ̀lú ọ̀pọ̀ àṣehàn aláfẹfẹyẹ̀yẹ̀,” wọ́n “wọnú gbọ̀ngàn àwùjọ lọ, pa pọ̀ pẹ̀lú àwọn ọ̀gágun àti àwọn ọkùnrin jàǹkàn-jàǹkàn ní ìlú ńlá náà.” Fẹ́sítọ́ọ̀sì wá sọ pé kí wọ́n mú Kristẹni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù wá síwájú wọn. Kí ló dé tí ọmọlẹ́yìn Jésù Kristi yìí wá dẹni tó dúró níwájú ìjókòó ìdájọ́ Gómìnà Fẹ́sítọ́ọ̀sì?—Ìṣe 25:13-23.

2 Ohun tí Fẹ́sítọ́ọ̀sì sọ fún àwọn àlejò rẹ̀ fún wa ní ìdáhùn sí ìbéèrè yẹn. Ó ní: “Ágírípà Ọba àti gbogbo ẹ̀yin ọkùnrin tí ẹ wà níhìn-ín pẹ̀lú wa, ẹ ń wo ọkùnrin yìí nípa ẹni tí gbogbo ògìdìgbó àwọn Júù lápapọ̀ ti mú ọ̀ràn rẹ̀ wá sí ọ̀dọ̀ mi ní Jerúsálẹ́mù àti níhìn-ín, tí wọ́n ń kígbe pé kò yẹ láti wà láàyè mọ́. Ṣùgbọ́n mo róye pé kò ṣe nǹkan kan tí ó yẹ fún ikú. Nítorí náà, nígbà tí ọkùnrin yìí fúnra rẹ̀ ké gbàjarè sí Ẹni Ọlọ́lá náà, mo pinnu láti fi í ránṣẹ́. Ṣùgbọ́n nípa rẹ̀ èmi kò ní ohunkóhun pàtó láti kọ sí Olúwa mi. Nítorí náà, mo mú un wá síwájú yín, àti ní pàtàkì síwájú rẹ, Ágírípà Ọba, kí èmi lè rí nǹkan kọ, lẹ́yìn tí àyẹ̀wò ìdájọ́ bá ti ṣẹlẹ̀. Nítorí pé lójú tèmi, ó dà bí ẹni pé kò lọ́gbọ́n nínú láti fi ẹlẹ́wọ̀n kan ránṣẹ́, kí n má sì tọ́ka sí àwọn ẹ̀sùn lòdì sí i.”—Ìṣe 25:24-27.

3. Kí nìdí táwọn aṣáájú ìsìn fi fẹ̀sùn èké kan Pọ́ọ̀lù?

3 Àwọn ọ̀rọ̀ tí Fẹ́sítọ́ọ̀sì sọ fi hàn pé ẹ̀sùn èké ni wọ́n fi kan Pọ́ọ̀lù pé ó ṣọ̀tẹ̀ sí ìjọba—ìyẹn sì jẹ́ ẹ̀sùn tí wọ́n máa ń tìtorí ẹ̀ dájọ́ ikú fúnni. (Ìṣe 25:11) Àmọ́, Pọ́ọ̀lù kò dẹ́ṣẹ̀ kankan. Àwọn òjòwú aṣáájú ìsìn ní Jerúsálẹ́mù ló fi ẹ̀sùn náà kàn án. Wọ́n tako iṣẹ́ tí Pọ́ọ̀lù ń ṣe gẹ́gẹ́ bí olùpòkìkí Ìjọba náà, inú sì ń bí wọ́n pé ó ń ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ láti di ọmọlẹ́yìn Jésù Kristi. Àwọn ẹ̀ṣọ́ tó dì ìhámọ́ra mú Pọ́ọ̀lù láti Jerúsálẹ́mù wá sí Kesaréà tó ní ibùdókọ̀ òkun, níbi tó ti ké gbàjarè sí Késárì. Àtibẹ̀ ni wọ́n ti máa mú un lọ sí Róòmù.

4. Gbólóhùn tó ṣeni ní kàyéfì wo ló ti ẹnu Àgírípà Ọba jáde?

4 Fojú inú wo Pọ́ọ̀lù ní ààfin gómìnà, níwájú àwùjọ kan tí aláṣẹ tó ń ṣàkóso apá pàtàkì kan lára Ilẹ̀ Ọba Róòmù wà. Àgírípà Ọba yíjú sí Pọ́ọ̀lù, ó sì sọ fún un pé: “A gbà ọ́ láyè láti sọ̀rọ̀.” Bí Pọ́ọ̀lù ṣe ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ, ohun àrà ọ̀tọ̀ kan ṣẹlẹ̀. Ohun tí Pọ́ọ̀lù ń sọ bẹ̀rẹ̀ sí nípa lórí ọba náà. Àgírípà Ọba tiẹ̀ sọ pé: “Ní àkókò kúkúrú, ìwọ yóò yí mi lérò padà di Kristẹni.”—Ìṣe 26:1-28.

5. Kí ló mú kí ọ̀rọ̀ tí Pọ́ọ̀lù sọ fún Àgírípà gbéṣẹ́ tó bẹ́ẹ̀?

5 Ìwọ rò ó wò ná! Bí Pọ́ọ̀lù ṣe gbèjà ara rẹ̀ lọ́nà tó jáfáfá ni agbára wíwọnilọ́kàn tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ní fi nípa lórí aláṣẹ kan. (Hébérù 4:12) Kí ló fà á gan-an tí ìgbèjà Pọ́ọ̀lù fi gbéṣẹ́ tó bẹ́ẹ̀? Ẹ̀kọ́ wo la sì lè kọ́ lára Pọ́ọ̀lù tó lè ràn wá lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ sísọni di ọmọ ẹ̀yìn? Tá a bá ṣàyẹ̀wò ìgbèjà rẹ̀ yìí dáadáa, a óò rí i pé ohun méjì ló hàn kedere níbẹ̀: (1) Ọ̀nà tí Pọ́ọ̀lù gbà gbé ọ̀rọ̀ rẹ̀ kalẹ̀ fi hàn pé ó mọ bí a ti ń yíni lérò padà. (2) Ó lo ìmọ̀ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tó ní lọ́nà tó jáfáfá, kódà ó lò ó bí oníṣẹ́ ọnà kan ṣe máa ń lo irin iṣẹ́ rẹ̀ lọ́nà tó jáfáfá.

Lo Ọgbọ́n Ìyíniléròpadà

6, 7. (a) Gẹ́gẹ́ bá a ṣe lò ó nínú Bíbélì, kí ni “ìyíniléròpadà” túmọ̀ sí? (b) Ipa wo ni ìyíniléròpadà kó nínú ríran àwọn èèyàn lọ́wọ́ láti tẹ́wọ́ gba ẹ̀kọ́ Bíbélì?

6 Léraléra ni ọ̀rọ̀ Gíríìkì tí wọ́n lò fún ìyíniléròpadà fara hàn nígbà tí wọ́n ń sọ̀rọ̀ nípa ìwàásù Pọ́ọ̀lù nínú ìwé Ìṣe. Kí ni ìyíniléròpadà ní í ṣe pẹ̀lú iṣẹ́ sísọni di ọmọ ẹ̀yìn?

7 Ìwé atúmọ̀ èdè náà, Expository Dictionary of New Testament Words láti ọwọ́ Vine sọ pé, nínú èdè ìpilẹ̀ṣẹ̀ tá a lo nínú Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì, “yí lérò padà” túmọ̀ sí “mímú kí o gba nǹkan gbọ́” tàbí “mímú ki ẹnì kan yí ọkàn rẹ̀ padà nítorí pé ọ̀rọ̀ tó gbọ́ dára.” Ṣíṣàyẹ̀wò ohun tí kúlẹ̀kúlẹ̀ ọ̀rọ̀ náà túmọ̀ sí túbọ̀ là wa lóye nípa rẹ̀. Ó ní í ṣe pẹ̀lú ìgbẹ́kẹ̀lé. Nítorí náà, tó o bá yí ẹnì kan lérò padà débi tó fi tẹ́wọ́ gba ẹ̀kọ́ Bíbélì kan, o ti jẹ́ kó ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú ohun tó o sọ nìyẹn, ìyẹn á sì jẹ́ kó gbà gbọ́ pé òótọ́ ni ẹ̀kọ́ tó o fi ń kọ́ òun. Ó hàn gbangba pé, wíwulẹ̀ sọ ohun tí Bíbélì wí fún ẹnì kan kí onítọ̀hún lè gbà á gbọ́, kó sì ṣiṣẹ́ lé e lórí nìkan kò tó. Ó tún gbọ́dọ̀ dá ẹni tó ń fetí sí ọ̀rọ̀ rẹ̀ lójú pé ohun tó o sọ jẹ́ òtítọ́, onítọ̀hún ì bàá jẹ́ ọmọdé, ì báà jẹ́ aládùúgbò, òṣìṣẹ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ, ẹni tẹ́ ẹ jọ ń lọ sílé ìwé kan náà, tàbí ìbátan rẹ.—2 Tímótì 3:14, 15.

8. Kí la lè ṣe láti mú kí òtítọ́ inú Ìwé Mímọ́ dá ẹnì kan lójú?

8 Báwo lo ṣe lè mú un dá ẹnì kan lójú pé ohun tó ń wàásù rẹ̀ látinú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run jẹ́ òtítọ́? Pọ́ọ̀lù yí àwọn tó bá sọ̀rọ̀ lọ́kàn padà nípa ṣíṣe àlàyé lọ́nà tó bọ́gbọ́n mu, nípa pípèsè ẹ̀rí tó yè kooro àti nípa fífi taratara rọni. a Nítorí náà, dípò wíwulẹ̀ máa sọ pé ohun kan jẹ́ òtítọ́, o ní láti fi ẹ̀rí tó yé àwọn olùgbọ́ rẹ ti ọ̀rọ̀ rẹ lẹ́yìn. Báwo la ṣe lè ṣe èyí? Rí i dájú pé inú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ló ti mú gbogbo ohun tó o ń sọ jáde kì í ṣe pé ò ń sọ èrò ti ara rẹ. Tún fi àwọn ẹ̀rí mìíràn ti ọ̀rọ̀ àtọkànwá tó o mú jáde láti inú Ìwé Mímọ́ lẹ́yìn. (Òwe 16:23) Bí àpẹẹrẹ, tó o bá sọ pé àwọn onígbọràn èèyàn yóò gbádùn ìyè nínú Párádísè orí ilẹ̀ ayé, fi ẹsẹ Ìwé Mímọ́ ti ohun tó o sọ yẹn lẹ́yìn, irú bíi Lúùkù 23:43 tàbí Aísáyà 65:21-25. Báwo lo ṣe lè fi ẹ̀rí mìíràn ti kókó tó o mú jáde látinú Ìwé Mímọ́ yìí lẹ́yìn? Ó lè mú àpẹẹrẹ jáde látinú ìrírí tí olùgbọ́ rẹ̀ fúnra rẹ̀ ti ní. O lè rán an létí ìgbádùn fàlàlà téèyàn ń rí látinú ẹwà wíwọ̀ oòrùn, òórùn dídùn tó ń jáde lára òdòdó kan, adùn èso kan, tàbí béèyàn ṣe máa ń gbádùn wíwo ìyá ẹyẹ kan tó ń fún àwọn ọmọ rẹ̀ lóúnjẹ. Ràn án lọ́wọ́ láti rí i pé irú ìgbádùn bẹ́ẹ̀ jẹ́ ẹ̀rí tó fi hàn pé Ẹlẹ́dàá wa fẹ́ ká gbádùn ìwàláàyè lórí ilẹ̀ ayé.—Oníwàásù 3:11, 12.

9. Báwo la ṣe lè fòye báni lò nínú iṣẹ́ ìwàásù wa?

9 Nígbà tó o bá ń gbìyànjú láti yí ẹnì kan lérò padà kó lè tẹ́wọ́ gba àwọn ẹ̀kọ́ Bíbélì bíi mélòó kan, ó gbọ́dọ̀ ṣọ́ra kí ìtara rẹ̀ má sọ ẹ́ di ẹni tó ń sọ ohun tí kò mọ́gbọ́n dání, táwọn olùgbọ́ rẹ kò sí ní tipa bẹ́ẹ̀ fọkàn sí ohun tó o ń sọ. Ìwé Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run fúnni ní ìkìlọ̀ yìí pé: “Bí a bá sọ ọ̀rọ̀ jáde lẹ́nu ṣàkó, tí a là á mọ́lẹ̀ pé irọ́ gbuu ni nǹkan tí ẹnì kan gbà gbọ́ tọkàntọkàn, kì í sábàá bọ́ síbi tó dáa lára àwọn èèyàn, kódà bí a tilẹ̀ fi àìmọye ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tí ì lẹ́yìn. Bí àpẹẹrẹ, bí a bá kàn bẹnu àtẹ́ lu àwọn àjọ̀dún kan tó lókìkí, tá a sọ pé ọdún abọ̀rìṣà ni, ìyẹn ò ní kí àwọn kan tìtorí ìyẹn ṣíwọ́ ṣíṣe ọdún náà. Àmọ́ fífòyebánilò ni yóò jẹ́ ká túbọ̀ kẹ́sẹ járí.” Kí nìdí tó fi yẹ ká sa gbogbo ipá wa láti fòye báni lò? Ìwé náà sọ pé: “Àmọ́ sísọ̀rọ̀ lọ́nà tí ń múni ronú jinlẹ̀ máa ń jẹ́ kí ìfọ̀rọ̀wérọ̀ ṣeé ṣe, ó ń jẹ́ káwọn èèyàn lè ronú lé e lórí, á sì jẹ́ kó ṣeé ṣe láti tún rí wọ́n bá sọ̀rọ̀ lọ́jọ́ míì. Ó lè mú kí wọ́n yí èrò wọn padà pátápátá.”—Kólósè 4:6.

Ìyíniléròpadà Tó Ń Sún Ọkàn Ṣiṣẹ́

10. Ọ̀nà wo ni Pọ́ọ̀lù gbà bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ tó fi gbèjà ara rẹ̀ níwájú Àgírípà?

10 Ẹ jẹ́ ká wá fara balẹ̀ wo àwọn ọ̀rọ̀ tí Pọ́ọ̀lù fi gbèjà ara rẹ̀ nínú ìwé Ìṣe orí 26. Kíyè sí ọ̀nà tó gbà bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ̀. Nígbà tí Pọ́ọ̀lù fẹ́ dẹ́nu lé kókó tó sọ̀rọ̀ lé lórí, ó kọ́kọ́ wá ìdí tó bófin mu kan láti gbóríyìn fún Àgírípà, bó tilẹ̀ jẹ́ pé àjọse àárín ọba náà àti àbúrò rẹ̀ Bẹ̀níìsì lákòókò yẹn jẹ́ èyí tó ń dójú tini. Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Nípa gbogbo ohun tí àwọn Júù fẹ̀sùn rẹ̀ kàn mí, Ágírípà Ọba, mo ka ara mi sí aláyọ̀ pé iwájú rẹ ni èmi yóò ti gbèjà ara mi lónìí yìí, ní pàtàkì, níwọ̀n bí ìwọ ti jẹ́ ògbógi nínú gbogbo àṣà àti àríyànjiyàn láàárín àwọn Júù. Nítorí náà, mo bẹ̀ ọ́ láti fi sùúrù gbọ́ ọ̀rọ̀ mi.”—Ìṣe 26:2, 3.

11. Báwo ni ọ̀rọ̀ tí Pọ́ọ̀lù sọ fún Àgírípà ṣe fi ọ̀wọ̀ hàn, kí sì ni àǹfààní tó tibẹ̀ jáde?

11 Ǹjẹ́ o kíyè sí i pé Pọ́ọ̀lù kò fojú kéré ipò gíga tí Àgírípà wà tó fi pè é ní Ọba, ìyẹn orúkọ oyè rẹ̀? Èyí fi ọ̀wọ̀ hàn, bí Pọ́ọ̀lù sì ṣe fi ọgbọ́n sọ àwọn ọ̀rọ̀ rẹ̀ fi hàn pé ó bọ̀wọ̀ fún Àgírípà. (1 Pétérù 2:17) Àpọ́sítélì náà mọ̀ pé Àgírípà jẹ́ ògbógi nínú àwọn àṣà àti òfin tó díjú nípa àwọn Júù tó jẹ́ ọmọ abẹ́ rẹ̀, ó sì sọ pé inú òun dùn pé òun lè gbèjà ara òun níwájú irú aláṣẹ tí òye rẹ̀ jinlẹ̀ tó bẹ́ẹ̀. Pọ́ọ̀lù tó jẹ́ Kristẹni kò ṣe bí ẹni pé òun ní ìmọ̀ ju Àgírípà tí kì í ṣe Kristẹni. (Fílípì 2:3) Kàkà bẹ́ẹ̀, Pọ́ọ̀lù bẹ ọba náà pé kó fi sùúrù gbọ́ ọ̀rọ̀ òun. Pọ́ọ̀lù tipa bẹ́ẹ̀ wá ọ̀nà tí Àgírípà àtàwọn mìíràn tó ń fetí sí ọ̀rọ̀ rẹ̀ yóò fi túbọ̀ fẹ́ láti fara mọ́ ohun tó fẹ́ sọ. Ó ń fi ìpìlẹ̀ lélẹ̀, ó wá ibi tí èdè wọn ti yéra tí yóò gbé ọ̀rọ̀ rẹ̀ kà.

12. Báwo la ṣe lè fa àwọn olùgbọ́ wa lọ́kàn mọ́ra nínú iṣẹ́ pípolongo Ìjọba náà?

12 Gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ tí Pọ́ọ̀lù bá Àgírípà sọ ṣe rí, ẹ jẹ́ kí ọ̀rọ̀ tiwa náà máa fa àwọn olùgbọ́ wa lọ́kàn mọ́ra látìbẹ̀rẹ̀ dópin nígbà tá a bá ń wàásù Ìjọba náà. A lè ṣe èyí nípá fífi ọ̀wọ̀ tó ga hàn fún ẹni tá a ń wàásù fún àti nípa níní ìfẹ́ tó jinlẹ̀ sí irú èèyàn tí onítọ̀hún jẹ́ àti ohun tó jẹ́ èrò rẹ̀.—1 Kọ́ríńtì 9:20-23.

Lo Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Lọ́nà Tó Gbéṣẹ́

13. Báwo lo ṣe lè ṣe bíi ti Pọ́ọ̀lù láti sún àwọn olùgbọ́ rẹ ṣiṣẹ́ lórí ọ̀rọ̀ rẹ?

13 Pọ́ọ̀lù fẹ́ sún àwọn olùgbọ́ rẹ̀ láti ṣiṣẹ́ lórí ìhìn rere náà. (1 Tẹsalóníkà 1:5-7) Láti ṣe èyí, ó sọ ọ̀rọ̀ tó wọ̀ ọkàn ìṣàpẹẹrẹ wọn, ìyẹn ọkàn tó máa ń súnni ṣe nǹkan. Bá a ṣe ń gbé ọ̀nà tí Pọ́ọ̀lù gbà gbèjà ara rẹ̀ níwájú Àgírípà yẹ̀ wò, ṣàkíyèsí ọ̀nà tí Pọ́ọ̀lù gbà ‘fi ọwọ́ títọ̀nà mú ọrọ̀ Ọlọ́run’ nípa títọ́ka sí àwọn nǹkan tí Mósè àtàwọn wòlíì sọ.—2 Tímótì 2:15.

14. Ṣàlàyé ọ̀nà tí Pọ́ọ̀lù gbà lo ìyíniléròpadà nígbà tó wà níwájú Àgírípà.

14 Pọ́ọ̀lù mọ̀ pé Júù aláfẹnujẹ́ ni Àgírípà. Kí Pọ́ọ̀lù má bàa sọ kọjá ohun tí Àgírípà mọ̀ nípa ìsìn àwọn Júù, ó rí i dájú pé bí òun ṣe ń wàásù, òun “kò sọ nǹkan kan àyàfi àwọn ohun tí àwọn Wòlíì àti Mósè sọ pé yóò ṣẹlẹ̀” nípa ikú àti àjíǹde Mèsáyà. (Ìṣe 26:22, 23) Nígbà tí Pọ́ọ̀lù darí ọ̀rọ̀ sí Àgírípà fúnra rẹ̀, ó béèrè pé: “Àgírípà Ọba, ìwọ ha gba àwọn Wòlíì gbọ́ bí?” Àgírípà ò lè fèsì ọ̀rọ̀ náà. Tó bá sọ pé òun kò gba àwọn wòlíì gbọ́, yóò pàdánù ipò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹni tó gba ìsìn àwọn Júù gbọ́. Tó bá sì sọ pé òun gbà ọ̀rọ̀ Pọ́ọ̀lù gbọ́, a jẹ́ pé ó fara mọ́ ohun tí àpọ́sítélì náà wí lójú gbogbo èèyàn nìyẹn, ìyẹn sì lè jẹ́ kí wọ́n pè é ní Kristẹni. Pọ́ọ̀lù wá fọgbọ́n dáhùn ìbéèrè tí òun fúnra rẹ̀ béèrè, ó ní: “Mo mọ̀ pé o gbà gbọ́.” Kí ni ọkàn Àgírípà wá sún un láti fi fèsì ọ̀rọ̀ náà? Ó dáhùn pé: “Ní àkókò kúkúrú, ìwọ yóò yí mi lérò padà di Kristẹni.” (Ìṣe 26:27, 28) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Àgírípà kò di Kristẹni, ó dájú pé ọ̀rọ̀ tí Pọ́ọ̀lù sọ wọ̀ ọ́ lọ́kàn dé ààyè kan.—Hébérù 4:12.

15. Báwo ló ṣe ṣeé ṣe fún Pọ́ọ̀lù láti fìdí ìjọ kan múlẹ̀ sí Tẹsalóníkà?

15 Ǹjẹ́ o kíyè sí i pé Pọ́ọ̀lù lo ìpolongo àti ìyíniléròpadà nínú ọ̀nà tó gbà wàásù ìhìn rere náà? Nítorí ọ̀nà tí Pọ́ọ̀lù gbà ‘fi ọwọ́ títọ̀nà mú ọ̀rọ̀ Ọlọ́run,’ yìí, àwọn kan lára àwọn tó wà níbẹ̀ kò wulẹ̀ gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀ nìkan, ṣùgbọ́n wọ́n tún di onígbàgbọ́ pẹ̀lú. Bí ọ̀ràn náà ṣe rí ní Tẹsalóníkà nìyẹn, níbi tí Pọ́ọ̀lù ti wá àwọn Júù àtàwọn Kèfèrí tó jẹ́ olùbẹ̀rù Ọlọ́run rí nínú sínágọ́gù. Ìtàn tó wà nínú Ìṣe 17:2-4 sọ pé: “Gẹ́gẹ́ bí àṣà Pọ́ọ̀lù, ó wọlé lọ bá wọn, fún sábáàtì mẹ́ta ni ó sì fi bá wọn fèrò-wérò láti inú Ìwé Mímọ́, ó ń ṣàlàyé, ó sì ń fi ẹ̀rí ìdánilójú hàn nípasẹ̀ àwọn ìtọ́ka pé ó pọndandan kí Kristi jìyà, kí ó sì dìde kúrò nínú òkú . . . Gẹ́gẹ́ bí ìyọrísí èyí, àwọn kan lára wọ́n di onígbàgbọ́.” Pọ́ọ̀lù mọ bá a ṣe ń yíni lérò padà. Ó fèrò wérò, ó ṣàlàyé, ó sì fi ẹ̀rí Ìwé Mímọ́ tí ì lẹ́yìn pé Jésù ni Mèsáyà tá a ti ṣèlérí rẹ̀ tipẹ́. Kí ni àbájáde rẹ̀? Ó fìdí ìjọ kan tó jẹ́ ti àwọn onígbàgbọ́ múlẹ̀ síbẹ̀.

16. Báwo lo ṣe lè túbọ̀ rí ìgbádùn kíkọyọyọ nínú pípolongo Ìjọba náà?

16 Ǹjẹ́ o lè túbọ̀ jáfáfá sí i nínú ọgbọ́n ìyíniléròpadà nígbà tó o bá ń ṣàlàyé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run? Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, ọkàn rẹ a balẹ̀ pé o ṣe ohun tó dáa, inú rẹ̀ yóò sì máa dùn nínú iṣẹ́ ìwàásù àti iṣẹ́ kíkọ́ àwọn èèyàn nípa Ìjọba Ọlọ́run. Bí ọ̀ràn náà ṣe rí gan-an nìyẹn lára àwọn akéde ìhìn rere náà tó ti fi àwọn àbá náà sílò pé ká túbọ̀ máa lo Bíbélì nínú iṣẹ́ ìwàásù náà.

17. Sọ ìrírí kan tí ìwọ fúnra rẹ̀ ní tàbí kó o sọ èyí tó wà nínú ìpínrọ̀ yìí láti fi hàn pé lílo Bíbélì nínú ìṣẹ́ òjíṣẹ́ wa ń ṣàǹfààní tó pọ̀.

17 Bí àpẹẹrẹ, ọ̀kan lára àwọn alábòójútó arìnrìn-àjò ti àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà kọ̀wé pé: “Ọ̀pọ̀ àwọn arákùnrin àti arábìnrin ló ń mú Bíbélì sọ́wọ́ báyìí nígbà tí wọ́n bá ń jẹ́rìí láti ilé dé ilé. Èyí ti ran àwọn akéde náà lọ́wọ́ láti ka ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan fún ọ̀pọ̀ lára àwọn èèyàn tí wọ́n ń bá pàdé. Ó ti ran onílé àti akéde lọ́wọ́ láti mọ̀ pé Bíbélì ṣe pàtàkì nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa, kì í ṣe pé a kàn fẹ́ fi ìwé ìròyìn àtàwọn ìwé ńlá lọni nìkan.” Àmọ́ ṣá o, ọ̀rọ̀ nípa bóyá a jẹ́ káwọn èèyàn rí Bíbélì wa nígbà tá a bá ń wàásù tàbí a ò jẹ́ kí wọ́n rí i sinmi lórí onírúurú nǹkan, títí kan àṣà àdúgbò pàápàá. Síbẹ̀síbẹ̀, ó yẹ ká fẹ́ láti jẹ́ ọ̀jáfáfá nínú lílo Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run láti yí àwọn ẹlòmíràn lérò padà kí wọ́n lè tẹ́wọ́ gba ìhìn Ìjọba náà.

Ojú Tí Ọlọ́run Fi Ń Wo Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Náà Ni Kó O Máa Fi Wò Ó

18, 19. (a) Ojú wo ni Ọlọ́run fi ń wo iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa, kí sì nìdí tó fi yẹ kí àwa náà máa fi irú ojú bẹ́ẹ̀ wò ó? (b) Kí ni yóò ràn wá lọ́wọ́ láti ṣe ìpadàbẹ̀wò tó kẹ́sẹ járí? (Wo àpótí tí à pe àkọlé rẹ̀ ní “Bí A Ṣe Lè Kẹ́sẹ Járí Nínú Ṣíṣe Ìpadàbẹ̀wò,” ni ojú ìwé 16.)

18 Ọ̀nà mìíràn láti mú kí ọ̀rọ̀ wa wọ àwọn olùgbọ́ wa lọ́kàn ni pé ká máa fi ojú tí Ọlọ́run fi ń wo iṣẹ́ òjíṣẹ́ náà wò ó, ká sì ní sùúrù. Ìfẹ́ Ọlọ́run ni pé kí gbogbo onírúurú ènìyàn “wá sí ìmọ̀ pípéye nípa òtítọ́.” (1 Tímótì 2:3, 4) Àbí kì í ṣe ohun táwa náà fẹ́ nìyẹn? Jèhófà tún ń mú sùúrù, sùúrù rẹ̀ si ti fún ọ̀pọ̀ èèyàn láǹfààní láti ronú pìwà dà. (2 Pétérù 3:9) Nítorí náà, nígbà tá a bá rí ẹnì kan tó fẹ́ gbọ́ ìhìn Ìjọba náà, ó lè pọn dandan pé ká lọ sọ́dọ̀ rẹ̀ léraléra kí ìfẹ́ tí onítọ̀hún fi hàn yẹn má bàa kú. Ó gba àkókò àti sùúrù kí èso òtítọ́ tó lè dàgbà. (1 Kọ́ríńtì 3:6) Àpótí tó wà pẹ̀lú àpilẹ̀kọ yìí, tá a pe àkọlé rẹ̀ ní “Bí A Ṣe Lè Kẹ́sẹ Járí Nínú Ṣíṣe Ìpadàbẹ̀wò” fúnni láwọn àbá tá a lè tẹ̀ lé kí irú ìfẹ́ táwọn èèyàn fi hàn bẹ́ẹ̀ má bàa kú. Rántí pé ìgbà gbogbo ni ìgbésí ayé àwọn èèyàn, ìṣòro wọn àti ipò wọn ń yí padà. Ó lè gba pé ká lọ lọ́pọ̀ ìgbà ká tó lè bá wọn nílé, àmọ́ àǹfààní ibẹ̀ tó bẹ́ẹ̀, ó jù bẹ́ẹ̀ lọ. A fẹ́ fún wọn láǹfààní láti gbọ́ ìhìn Ọlọ́run tó ń fúnni ní ìgbàlà. Nítorí náà, gbàdúrà pé kí Jèhófà Ọlọ́run fún ọ ní ọgbọ́n láti túbọ̀ jáfáfá sí i nínú yíyí àwọn èèyàn lérò padà nígbà tá a bá ń ràn wọ̀n lọ́wọ́ láti tẹ́wọ́ gba ìhìn Ìjọba náà.

19 Kí ni nǹkan mìíràn tó yẹ kí àwa tá a jẹ́ Kristẹni òṣìṣẹ́ ṣe ní gbára tá a bá ti rí ẹnì kan tó fẹ́ gbọ́ ohun púpọ̀ sí i nípa ìhìn Ìjọba náà? Àpilẹ̀kọ tó kàn yóò sọ ohun tó yẹ ní ṣíṣe.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Láti rí ìsọfúnni síwájú sí i lórí ìyíniléròpadà, wo ẹ̀kọ́ 48 àti 49 nínú ìwé Jàǹfààní Nínú Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run, èyí tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tẹ̀ jáde.

Ǹjẹ́ O Rántí?

• Kí ló mú kí ìgbèjà Pọ́ọ̀lù níwájú Àgírípà Ọba gbéṣẹ́?

• Báwo ni ìhìn tá ń jẹ́ ṣe lè fa àwọn èèyàn lọ́kàn mọ́ra?

• Kí ni yóò ràn wá lọ́wọ́ láti lo Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lọ́nà tó jáfáfá sí i láti mú kí ọ̀rọ wa wọ àwọn èèyàn lọ́kàn?

• Báwo la ṣe lè fi irú ojú tí Ọlọ́run fi ń wo ìhìn rere náà wò ó?

[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]

[Àpótí/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]

Bí A Ṣe Lè Kẹ́sẹ Járí Nínú Ṣíṣe Ìpadàbẹ̀wò

• Fi ìfẹ́ tòótọ́ hàn sí àwọn èèyàn.

• Yan kókó ẹ̀kọ́ Bíbélì kan tó fani mọ́ra láti jíròrò.

• Fi ìpìlẹ̀ lélẹ̀ fún ìbẹ̀wò kọ̀ọ̀kan tí yóò tẹ̀ lé e.

• Máa ronú nípa ẹni náà lẹ́yìn tó o bá ti kúrò níbẹ̀.

• Tètè padà lọ, yálà láàárín ọjọ́ kan sí méjì, kó o lè ṣiṣẹ́ lórí ìfẹ́ tí onítọ̀hún fi hàn.

• Má ṣe gbàgbé pé bó o ṣe máa bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ló yẹ kó jẹ ọ́ lógún jù lọ.

• Gbàdúrà pé kí Jèhófà mú kí ìfẹ́ náà máa pọ̀ sí i.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]

Pọ́ọ̀lù lo ìyíniléròpadà nígbà tó wà níwájú Gómìnà Fẹ́sítọ́ọ̀sì àti Àgírípà Ọba