Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ètò Kan Lórí Tẹlifíṣọ̀n Mú Kí Obìnrin Kan Yin Ọlọ́run Lógo

Ètò Kan Lórí Tẹlifíṣọ̀n Mú Kí Obìnrin Kan Yin Ọlọ́run Lógo

Àwọn Olùpòkìkí Ìjọba Ròyìn

Ètò Kan Lórí Tẹlifíṣọ̀n Mú Kí Obìnrin Kan Yin Ọlọ́run Lógo

ÀPỌ́SÍTÉLÌ Pọ́ọ̀lù sọ pé “àwọn kan ń wàásù Kristi ní tìtorí ìlara àti ìbánidíje, ṣùgbọ́n àwọn mìíràn pẹ̀lú ní tìtorí ìfẹ́ rere.” (Fílípì 1:15) Nígbà míì, àwọn tí wọ́n fẹ́ láti ba àwọn èèyàn Jèhófà lórúkọ jẹ́ máa ń ṣe àwọn nǹkan tó ń mú káwọn olóòótọ́ ọkàn nífẹ̀ẹ́ sí òtítọ́.

Ní oṣù November 1998, wọ́n ṣe ètò kan lórí tẹlifíṣọ̀n orílẹ̀-èdè Faransé, ètò náà fi àwòrán Bẹ́tẹ́lì hàn, ìyẹn ẹ̀ka iléeṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà nílùú Louviers, ní orílẹ̀-èdè Faransé. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé oríṣiríṣi nǹkan làwọn èèyàn sọ nípa ètò náà, ó so èso rere láwọn ọ̀nà kan tá ò tiẹ̀ rò tẹ́lẹ̀.

Lára àwọn tó wo ètò náà ni Anna-Paula tó ń gbé ní ọgọ́ta kìlómítà sí Bẹ́tẹ́lì. Anna-Paula àti ọkọ rẹ̀ ti kọ ara wọn sílẹ̀. Ó ní ọmọ méjì, ó sì ń wáṣẹ́. Nítorí náà, láàárọ̀ ọjọ́ kejì, ó tẹ Bẹ́tẹ́lì láago láti béèrè bóyá wọ́n lè gba òun ṣíṣẹ́ níbẹ̀. Ó ní: “Ohun tí mo rí lórí ètò tí wọ́n ṣe nínú tẹlifíṣọ̀n jẹ́ kí n gbà pé ibì kan tó dáa ni àti pé iṣẹ́ tí wọ́n ń ṣe níbẹ̀ ń ṣèèyàn láǹfààní.” Ẹnu yà á gan-an nígbà tó gbọ́ pé ńṣe ni gbogbo àwọn òjíṣẹ́ tó ń sìn ní Bẹ́tẹ́lì yọ̀ǹda àkókò wọn lọ́fẹ̀ẹ́! Lẹ́yìn tí wọ́n bá a jíròrò ráńpẹ́ nípa ìgbòkègbodò àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ó gbà pé kí Ẹlẹ́rìí kan wá sọ́dọ̀ òun.

Nígbà tí Léna, òjíṣẹ́ alákòókò kíkún kan láti ìjọ àdúgbò ibẹ̀ lọ sọ́dọ̀ rẹ̀, wọ́n jọ sọ̀rọ̀ gan-an, Anna-Paula sì tẹ́wọ́ gba ìwé Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun. a Kó tó di ìgbà tí Léna máa lọ sọ́dọ̀ rẹ̀ lẹ́ẹ̀kejì, Anna-Paula ti ka ìwé náà látòkèdélẹ̀, ó sì ní ọ̀pọ̀ ìbéèrè tó fẹ́ béèrè. Kíá ló gbà pé kí wọ́n wá máa bá òun ṣèkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Anna-Paula sọ pé: “Àǹfààní lèyí jẹ́ fún mi láti mọ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Mi ò tíì gbé Bíbélì dání rí láyé mi.”

 Anna-Paula ṣèbẹ̀wò sí Bẹ́tẹ́lì ní oṣù January, ní ọ̀sẹ̀ tó tẹ̀ lé e, ó lọ sí ìpàdé Kristẹni fúngbà àkọ́kọ́. Láìpẹ́ lẹ́yìn náà, ó bẹ̀rẹ̀ sí í bá àwọn ọmọ rẹ̀ ṣèkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ó sì ń wàásù fáwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀. Ó ní: “Mi ò lè pa ohun tí mò ń kọ́ mọ́ra láìsọ fáwọn èèyàn. Mo fẹ́ máa sọ ọ̀rọ̀ òtítọ́ Bíbélì fáwọn èèyàn kí n sì máa tù wọ́n nínú.” Lẹ́yìn tí Anna-Paula ti sapá gidigidi láti yanjú àwọn ìṣòro kan tó ní, ó bẹ̀rẹ̀ sí í lọ sípàdé déédéé. Ó tẹ̀ síwájú kíákíá, ó sì ṣe ìrìbọmi ní May 5, 2002.

Kì í ṣe ìyẹn nìkan o, nítorí tí Anna-Paula jẹ́ àpẹẹrẹ rere tó sì ń fi ìtara wàásù, ìyá rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, kò sì pẹ́ tó fi ṣèrìbọmi. Anna-Paula sọ pé: “Ayọ̀ mi pọ̀ jọjọ. Ojoojúmọ́ ni mò ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà fún jíjẹ́ tó jẹ́ kí n mọ òun kí n sì máa jọ́sìn òun, mo sì tún ń dúpẹ́ fún àwọn ìbùkún ti mo rí gbà lọ́wọ́ Jèhófà.”

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la tẹ̀ ẹ́ jáde.

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8]

Òkè: Anna-Paula rèé

Ìsàlẹ̀: Ẹnu àbáwọlé ẹ̀ka iléeṣẹ́ tó wà ní orílẹ̀-èdè Faransé