Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Ọ̀nà wo ni Ìsíkíẹ́lì gbà di “aláìlèsọ̀rọ̀,” tàbí ẹni tó “yadi,” lákòókò tí wọ́n gbógun ti Jerúsálẹ́mù tí wọ́n sì pa á run?

Láìwulẹ̀ déènà pẹnu, ó jẹ́ nítorí pé kò ní ohunkóhun tó tún fẹ́ fi kún àsọtẹ́lẹ̀ Jèhófà tó ti sọ.

“Ọjọ́ karùn-ún oṣù, èyíinì ni, ní ọdún karùn-ún ìgbèkùn Jèhóákínì Ọba,” ìyẹn 613 ṣááju Sànmánì Tiwa ni wòlíì Ìsíkíẹ́lì bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí olóòótọ́ olùṣọ́ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó wà nígbèkùn ní Bábílónì. (Ìsíkíẹ́lì 1:2, 3) Ní ọjọ́ kẹwàá oṣù òṣùpá kẹwàá, ọdún 609 ṣááju Sànmánì Tiwa, Ọlọ́run fi hàn án pé àwọn ará Bábílónì ti gbógun ti Jerúsálẹ́mù. (Ìsíkíẹ́lì 24:1, 2) Kí ni ìgbóguntì yẹn yóò yọrí sí? Ṣé Jerúsálẹ́mù àtàwọn olùgbé rẹ̀ aláìṣòótọ́ yóò rí ọ̀nà àbáyọ? Ìsíkíẹ́lì tó jẹ́ olùṣọ́ ti kéde ègbé tó dájú látọ̀dọ̀ Jèhófà lé wọn lórí, kò sì tún sídìí kankan fún Ìsíkíẹ́lì mọ́ láti fi ohunkóhun kún un bíi pé ó fẹ́ mú kí iṣẹ́ tó ti jẹ́ fún wọn tẹ́lẹ̀ túbọ̀ dá wọn lójú. Ìsíkíẹ́lì di aláìlèsọ̀rọ̀ ní ti pé kò sọ nǹkan kan síwájú sí i mọ́ nípa ìgbóguntì Jerúsálẹ́mù.—Ìsíkíẹ́lì 24:25-27.

Ní nǹkan bí oṣù mẹ́fà lẹ́yìn ìparun Jerúsálẹ́mù lọ́dún 607 ṣááju Sànmánì Tiwa, olùsálà kan wá ròyìn fún Ìsíkíẹ́lì ní Bábílónì pé ìlú mímọ́ náà ti di ahoro. Ní alẹ́, Jèhófà “ṣí ẹnu [Ìsíkíẹ́lì] . . . kò sì jẹ́ aláìlèsọ̀rọ̀ mọ́” kí olùsálà náà tó dé ní òwúrọ̀ ọjọ́ kejì. (Ìsíkíẹ́lì 33:22) Bí Ìsíkíẹ́lì ò ṣe yadi mọ́ nìyẹn.

Ṣé Ìsíkíẹ́lì yadi ní ti gidi lákòókò náà ni? Ó dájú pé kò yadi ní ti gidi nítorí pé lẹ́yìn tá a tiẹ̀ sọ pé ó “yadi” yìí, ó ṣì kéde àwọn àsọtẹ́lẹ̀ sórí àwọn orílẹ̀-èdè àyíká ibẹ̀ tó ń yọ̀ nítorí ègbé tó dé bá Jerúsálẹ́mù. (Ìsíkíẹ́lì orí kẹẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n sí ìkejìlélọ́gbọ̀n) Jèhófà ti sọ fún Ìsíkíẹ́lì nígbà tó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ wòlíì àti iṣẹ́ olùṣọ́, pé: “Ahọ́n rẹ pàápàá ni èmi yóò mú kí ó lẹ̀ mọ́ àjà ẹnu rẹ, dájúdájú, ìwọ yóò sì yadi, ìwọ kì yóò sì jẹ́ ọkùnrin tí ń fi ìbáwí tọ́ni sọ́nà fún wọn, nítorí wọ́n jẹ́ ọlọ̀tẹ̀ ilé. Nígbà tí mo bá sì bá ọ sọ̀rọ̀, èmi yóò la ẹnu rẹ.” (Ìsíkíẹ́lì 3:26, 27) Nígbà tí Jèhófà ò sì rán iṣẹ́ kankan sí Ísírẹ́lì, Ìsíkíẹ́lì yóò ní láti pa ẹnu rẹ̀ mọ́ nípa orílẹ̀-èdè yẹn. Ohun tí Jèhófà bá fẹ́ kí Ìsíkíẹ́lì sọ ló gbọ́dọ̀ sọ, ìgbà tí Jèhófà bá sì fẹ́ kí ó sọ ọ́ ló gbọ́dọ̀ sọ ọ́. Yíyadi tí Ìsíkíẹ́lì yadi túmọ̀ sí pé kò sọ ohun tó jẹ́ àsọtẹ́lẹ̀ mọ́ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.

Ẹgbẹ́ olùṣọ́ òde òní, ìyẹn àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró, ti ń kìlọ̀ tipẹ́ nípa ègbé tí ń bọ̀ wá sórí àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì, tí wọ́n dà bí Jerúsálẹ́mù ìgbàanì. Nígbà tí “ìpọ́njú ńlá” náà bá bẹ̀rẹ̀, tó sì sọ “Bábílónì Ńlá,” ilẹ̀ ọba ìsìn èké àgbáyé dahoro, kò tún ní sídìí fún àwọn ẹni àmì òróró tó jẹ́ ẹgbẹ́ Ìsíkíẹ́lì láti sọ ohunkóhun mọ́ nípa ìparun àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì tó jẹ́ apá tó ṣe pàtàkì jù lọ nínú ilẹ̀ ọba yẹn.—Mátíù 24:21; Ìṣípayá 17:1, 2, 5.

Bẹ́ẹ̀ ni o, ọjọ́ ń bọ̀ tí àwọn ẹni àmì òróró àtàwọn alábàákẹ́gbẹ́ wọn yóò yadi, tí wọ́n kò tún ní ní ohunkóhun láti sọ fáwọn oníṣọ́ọ̀ṣì mọ́. Ìyẹn yóò jẹ́ ìgbà tí “ìwo mẹ́wàá” àti “ẹranko ẹhànnà” náà bá sọ Bábílónì Ńlá dahoro àti ìhòòhò. (Ìṣípayá 17:16) Àmọ́ ṣá, èyí ò túmọ̀ sí pé àwọn Kristẹni yóò di aláìlèsọ̀rọ̀ ní ti gidi. Wọn yóò máa yin Jèhófà, wọn yóò sì máa sọ̀rọ̀ rẹ̀ lójoojúmọ́ “jálẹ̀ gbogbo ìran tí ń bọ̀,” àní bí wọ́n ti ń ṣe nísinsìnyí.—Sáàmù 45:17; 145:2.