Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìdí Tí Ọ̀pọ̀ Èèyàn Fi Ń Lọ Sí Ṣọ́ọ̀ṣì

Ìdí Tí Ọ̀pọ̀ Èèyàn Fi Ń Lọ Sí Ṣọ́ọ̀ṣì

Ìdí Tí Ọ̀pọ̀ Èèyàn Fi Ń Lọ Sí Ṣọ́ọ̀ṣì

“IYE àwọn onísìn Presbyterian tó wà ní ilẹ̀ olómìnira Kòríà báyìí ti fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ìlọ́po mẹ́rin ti orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà.” Ìyàlẹ́nu lohun tí ìwé ìròyìn Newsweek sọ yìí lè jẹ́ fún ọ̀pọ̀ àwọn tó kà á, nítorí pé ojú tí ọ̀pọ̀ èèyàn fi ń wo ilẹ̀ Kòríà ni pé àwọn ẹlẹ́sìn Confucius tàbí ti Búdà ló pọ̀ jù níbẹ̀. Lónìí, ẹni tó bá lọ sí orílẹ̀-èdè yẹn á rí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ṣọ́ọ̀ṣì “àwọn Kristẹni,” wọ́n máa ń ní àgbélébùú tá a fi iná pupa ṣe. Lọ́jọọjọ́ Sunday, ẹ óò rí àwọn èèyàn ní méjì-méjì tàbí mẹ́ta-mẹ́ta, tí wọ́n á gbé Bíbélì dání, tí wọ́n á máa lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì. Gẹ́gẹ́ bí ìwádìí kan tá a gbé jáde lọ́dún 1998 ṣe fi hàn, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ìpín ọgbọ́n nínú ọgọ́rùn ún lára àwọn ọmọ ilẹ̀ Kòríà tó ń ṣe ẹ̀sìn Kátólíìkì tàbí ti Pùròtẹ́sítáǹtì, iye yìí sì ju tàwọn tó pe ara wọn ní ẹlẹ́sìn Búdà lọ.

Láyé ìsinsìnyí, kò wọ́pọ̀ láti rí àwọn èèyàn tí wọ́n ń lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì déédéé tí iye wọn pọ̀ tó báyìí. Síbẹ̀, ilẹ̀ Kòríà nìkan kọ́ niye àwọn tó ń lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì ti pọ̀ bẹ́ẹ̀, ó tún rí bẹ́ẹ̀ láwọn orílẹ̀-èdè míì ní Éṣíà pẹ̀lú, títí kan àwọn orílẹ̀-èdè tó wà ní Áfíríkà àti ní Látìn Amẹ́ríkà. Kí nìdí tí àwọn tó pọ̀ tó báyìí ṣì fi ń sọ pé àwọn gba Ọlọ́run gbọ́ nígbà tó jẹ́ pé ibi gbogbo làwọn èèyàn ò ti ka ìsìn sí? Kí nìdí tí ọ̀pọ̀ èèyàn fi ń lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì?

Ìwádìí kan tí a ṣe lọ́dọ̀ àwọn aráàlú fi hàn pé ó lé ní ìdajì lára àwọn tó ń lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì nílẹ̀ Kòríà tó ń wá báwọn yóò ṣe ní ìbàlẹ̀ ọkàn; nǹkan bí ìdá mẹ́ta lára wọn ló ń retí pé àwọn á rí ìyè àìnípẹ̀kun gbà lẹ́yìn ikú; ìdá kan nínú mẹ́wàá lára wọn sì ń wá ilera, ọlà àti àṣeyọrí.

Ọ̀pọ̀ èèyàn lórílẹ̀-èdè Ṣáínà ló ń rọ́ lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì, tí wọ́n sì ń retí pé táwọn bá ń lọ ṣọ́ọ̀ṣì, àwọn á lè padà sí ipò tẹ̀mí tí àwọn wà tẹ́lẹ̀ kí ìjọba oníṣòwò bòńbàtà tó rọ́pò ìjọba àjùmọ̀ní ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀. Lọ́dọọdún, ọ̀kẹ́ àìmọye ẹ̀dà Bíbélì ni wọ́n ń tẹ̀ jáde ní Ṣáínà, ó sì jọ pé irú ìtara kan náà táwọn èèyàn fi ń ka ìwé kékeré pupa tí Mao ṣe ni wọ́n fi ń kà á.

Ìlérí ayọ̀ nínú ayé tí ń bọ̀ lọ́jọ́ iwájú kò tẹ́ àwọn kan tó ń ṣe ẹ̀sìn Kátólíìkì ní orílẹ̀-èdè Brazil lọ́rùn, pàápàá àwọn tí kò tíì pẹ́ tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ ẹ̀sìn náà, wọ́n fẹ́ kí ìlérí yẹn ṣẹ nínú ayé ìsinsìnyí. Ìwé ìròyìn Tudo sọ pé: “Bó bá jẹ́ pé ẹ̀kọ́ ìsìn tó dá lórí ìjìjàgbara ló ń mú káwọn èèyàn máa lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì láwọn ọdún 1970, ẹ̀kọ́ ìsìn tó dá lórí ọ̀nà àtilà lohun tó ń mú káwọn èèyàn máa lọ lóde òní.” Nínú ìwádìí kan tí wọ́n ṣe ní ilẹ̀ Gẹ́ẹ̀sì, wọ́n ní káwọn tó ń lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì sọ ohun kan tí wọ́n fẹ́ràn nípa ṣọ́ọ̀ṣì wọn. Ìbákẹ́gbẹ́pọ̀ lohun ti púpọ̀ nínú wọn dárúkọ.

Gbogbo èyí fi hàn pé bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ èèyàn ṣì gba Ọlọ́run gbọ́, ohun tó ń bọ̀ lọ́jọ́ iwájú tàbí Ọlọ́run fúnra rẹ̀ kọ́ lohun tó jẹ púpọ̀ lára wọn lógún, bí kò ṣe ohun tọ́wọ́ wọ́n lè tẹ̀ nísinsìnyí. Kí lo rò pé ó yẹ kó jẹ́ ìdí tá a fi gba Ọlọ́run gbọ́? Kí ni Bíbélì tiẹ̀ sọ nípa ọ̀ràn náà? Wàá rí ìdáhùn nínú àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé e.