Ìkùdu Tí Kò Lè Gba Omi Dúró
Ìkùdu Tí Kò Lè Gba Omi Dúró
LÁYÉ ìgbà tí wọ́n ń kọ Bíbélì, àwọn èèyàn máa ń gbẹ́ ìkùdu sínú ilẹ̀, kí wọ́n lè máa pọn omi sínú rẹ̀. Ní Ilẹ̀ Ìlérí, ìkùdu nìkan lohun táwọn èèyàn máa ń tọ́jú omi sí láwọn àkókò kan.
Nígbà tí wòlíì Jeremáyà ń ṣe àkọsílẹ̀ ohun tí Ọlọ́run sọ, ó tọ́ka sí ìkùdu lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ, ó ní: “Ohun búburú méjì ni àwọn ènìyàn mi ṣe: Wọ́n ti fi èmi pàápàá, orísun omi ààyè sílẹ̀, láti gbẹ́ àwọn ìkùdu fún ara wọn, àwọn ìkùdu fífọ́, tí kò lè gba omi dúró.”—Jeremáyà 2:13.
Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kọ Jèhófà, Ọlọ́run wọn tí í ṣe “orísun omi ààyè” sílẹ̀, wọ́n wá lọ bá àwọn orílẹ̀-èdè kèfèrí wọnú àjọṣe, wọ́n tún ń jọ́sìn òrìṣà tó jẹ́ pé kò lè ta pútú. Níbàámu pẹ̀lú àpèjúwe Jeremáyà, ńṣe ni irú àwọn ohun tí wọ́n gbẹ́kẹ̀ lé wọ̀nyí dà bí ìkùdu tó ń jò, ohun tí kò ní agbára kankan láti dáàbò boni tàbí láti gbani là.—Diutarónómì 28:20.
Lónìí, ǹjẹ́ ẹ̀kọ́ kankan wà tá a lè rí kọ́ nínú ìtàn tá a fi ṣe àpẹẹrẹ yìí? Gẹ́gẹ́ bó ṣe rí nígbà ayé Jeremáyà, Jèhófà, Ọlọ́run ayérayé nìkan ní Orísun omi ààyè. (Sáàmù 36:9; Ìṣípayá 4:11) Ọ̀dọ̀ rẹ̀ nìkan ṣoṣo ni aráyé ti lè rí ìyè àìnípẹ̀kun gbà, nípasẹ̀ Jésù Kristi, Ọmọ rẹ̀. (Jòhánù 4:14; 17:3) Síbẹ̀, bíi tàwọn èèyàn ìgbà ayé Jeremáyà, ogunlọ́gọ̀ èèyàn lóde òní ti kọ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tí ń bẹ nínú Bíbélì sílẹ̀, tí wọn tiẹ̀ ń ṣáátá ọ̀rọ̀ rẹ̀. Dípò ìyẹn, ohun tí wọ́n gbẹ́kẹ̀ lé ni ètò ìṣèlú tí wọ́n rò pé á yanjú ìṣòro àwọn lójú ẹsẹ̀ àti ìrònú asán táwọn èèyàn gbé kalẹ̀, èròǹgbà àti ìmọ̀ orí tó ń tàbùkù sí Ọlọ́run. (1 Kọ́ríńtì 3:18-20; Kólósè 2:8) Kò ṣòro láti mọ èyí tó yẹ ká yàn. Èwo ni wàá gbẹ́kẹ̀ lé? Ṣé Jèhófà, tí í ṣe “orísun omi ààyè” ni tàbí “ìkùdu tí kò lè gba omi dúró”?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 32]
Ère abo òrìṣà tá a fi amọ̀ ṣe tí wọ́n rí ní ibojì ọmọ Ísírẹ́lì kan
[Credit Line]
Fọ́tò tá a yà nípasẹ̀ ìyọ̀ǹda British Museum