Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

‘Ẹ Máa Kún Fún Ọpẹ́’

‘Ẹ Máa Kún Fún Ọpẹ́’

‘Ẹ Máa Kún Fún Ọpẹ́’

“Ẹ jẹ́ kí àlàáfíà Kristi máa ṣàkóso nínú ọkàn-àyà yín . . . Ẹ sì fi ara yín hàn ní ẹni tí ó kún fún ọpẹ́.”—KÓLÓSÈ 3:15.

1. Ìyàtọ̀ wo la kíyè sí láàárín ìjọ Kristẹni àti ayé tó wà lábẹ́ àkóso Sátánì?

 ÀWỌN Ẹlẹ́rìí Jèhófà jákèjádò ayé, tó wà nínú 94,600 ìjọ lẹ́mìí ìmọrírì gan-an. Gbogbo ìpàdé la máa ń fàdúrà bẹ̀rẹ̀ tá a sì ń fàdúrà parí rẹ̀. A ò sì lè ṣe ká má fọpẹ́ fún Jèhófà nínú àdúrà wọ̀nyí. Nígbà tá a bá ń ṣe ìjọsìn àti ìpàdé aláyọ̀ pa pọ̀, a máa ń gbọ́ ọ̀rọ̀ bíi “ẹ ṣé o,” “òo, a dúpẹ́,” tàbí irú àwọn gbólóhùn bẹ́ẹ̀ lẹ́nu tọmọdé tàgbà, lẹ́nu ẹni tó ṣẹ̀ṣẹ̀ di Ẹlẹ́rìí àti ẹni tó ti di Ẹlẹ́rìí tipẹ́tipẹ́. (Sáàmù 133:1) Èyí mà yàtọ̀ pátápátá o sí ẹ̀mí ìmọtara-ẹni-nìkan tó wọ́pọ̀ láàárín ọ̀pọ̀ ‘àwọn tí kò mọ Jèhófà tí wọn kò sì ṣègbọràn sí ìhìn rere’! (2 Tẹsalóníkà 1:8) Ayé ẹlẹ́mìí abaraámóorejẹ là ń gbé. Kò sì yani lẹ́nu pé ó rí bẹ́ẹ̀ tá a bá ti rántí pé Sátánì Èṣù ni ọlọ́run ayé yìí. Òun ni olórí ẹlẹ́mìí ìmọtara-ẹni-nìkan, tí ìgbéraga àti ẹ̀mí ọ̀tẹ̀ rẹ̀ gbilẹ̀ láàárín ọmọ aráyé!—Jòhánù 8:44; 2 Kọ́ríńtì 4:4; 1 Jòhánù 5:19.

2. Ìkìlọ̀ wo ló yẹ ká kọbi ara sí, àwọn ìbéèrè wo la ó sì gbé yẹ̀ wò?

2 Nígbà tó sì jẹ́ pé àárín ayé Sátánì là ń gbé, a gbọ́dọ̀ ṣọ́ra kí ẹ̀mí ayé yẹn má bàa ràn wá. Ní ọ̀rúndún kìíní, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù rán àwọn Kristẹni tó wà ní Éfésù létí pé: “Ẹ ti rìn ní àkókò kan rí ní ìbámu pẹ̀lú ètò àwọn nǹkan ti ayé yìí, ní ìbámu pẹ̀lú olùṣàkóso ọlá àṣẹ afẹ́fẹ́, ẹ̀mí tí ń ṣiṣẹ́ nísinsìnyí nínú àwọn ọmọ àìgbọ́ràn. Bẹ́ẹ̀ ni, ní àkókò kan, gbogbo wa hùwà láàárín wọn ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ìfẹ́-ọkàn ti ẹran ara wa, ní ṣíṣe àwọn ohun tí ẹran ara fẹ́ àti ti àwọn ìrònú, a sì jẹ́ ọmọ ìrunú lọ́nà ti ẹ̀dá àní bí àwọn yòókù.” (Éfésù 2:2, 3) Irú ohun kan náà ló ń ṣẹlẹ̀ sí ọ̀pọ̀ èèyàn lónìí. Àmọ́, báwo la ṣe lè jẹ́ ẹni tó mọ ọpẹ́ dá? Ìrànlọ́wọ́ wo ni Jèhófà pèsè fún wa nípa rẹ̀? Àwọn ọ̀nà tó hàn gbangba wo la lè gbá fi hàn pé a lẹ́mìí ìmoore ní tòótọ́?

Àwọn Ìdí Tó Fi Yẹ Ká Máa Kún fún Ọpẹ́

3. Àwọn ohun wo ló yẹ ká torí ẹ̀ máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà?

3 Jèhófà Ọlọ́run, Ẹlẹ́dàá wa, Ẹni tó fún wa ní ìyè ni ọpẹ́ wa yẹ, pàápàá bí a bá tiẹ̀ ronú nípa díẹ̀ lára ọ̀pọ̀ jaburata ẹ̀bùn tó ti fún wa. (Jákọ́bù 1:17) Ojoojúmọ́ là ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà pé ó dá ẹ̀mí wa sí. (Sáàmù 36:9) À ń rí ẹ̀rí rẹpẹtẹ yí wa ká tó ń fi iṣẹ́ ọwọ́ Jèhófà hàn, irú bí oòrùn, òṣùpá, àtàwọn ìràwọ̀. Bí ilẹ̀ ayé wa ṣe kún fún àwọn èròjà agbẹ́mìíró, bí onírúurú afẹ́fẹ́ àyíká wa ṣe wà níwọ̀n tó yẹ gẹ́lẹ́, àti bí ìyípo-yípo omi, afẹ́fẹ́ àtàwọn nǹkan bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ ṣe ń ṣiṣẹ́ lọ́nà ìyanu jẹ́ ẹ̀rí pé Bàbá wa ọ̀run onífẹ̀ẹ́ lọpẹ́ wa yẹ. Kódà Dáfídì Ọba kọ ọ́ lórin pé: “Ọ̀pọ̀ nǹkan ni ìwọ fúnra rẹ ti ṣe, ìwọ Jèhófà Ọlọ́run mi, àní àwọn iṣẹ́ àgbàyanu rẹ àti ìrònú rẹ sí wa; kò sí ẹnì kankan tí a lè fi ọ́ wé. Ká ní mo fẹ́ máa wí, kí n sì máa sọ nípa wọn ni, wọ́n pọ̀ níye ju èyí tí mo lè máa ròyìn lẹ́sẹẹsẹ.”—Sáàmù 40:5.

4. Kí nìdí tó fi yẹ ká máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà fún ìfararora aláyọ̀ tá à ń gbádùn nínú àwọn ìjọ wa?

4 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwa ìránṣẹ́ Jèhófà kò tíì máa gbé nínú Párádísè tá a lè fojú rí, à ń jẹ̀gbádùn wíwà tá a wà nínú párádísè tẹ̀mí. Nínú àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba wa tá a ti ń jọ́sìn àti nínú àwọn àpéjọ àgbègbè, ti àyíká àti ti àkànṣe wa, a máa ń rí bí ẹ̀mí Ọlọ́run ṣe ń bá àwọn ará wa ṣiṣẹ́ pọ̀. Àní bí àwọn Ẹlẹ́rìí kan bá tiẹ̀ ń wàásù fáwọn èèyàn tí kò fi bẹ́ẹ̀ fara mọ́ ẹ̀sìn láti kékeré wọn wá, àwọn Ẹlẹ́rìí yìí máa ń tọ́ka sí ohun tí Pọ́ọ̀lù ṣàpèjúwe nínú ìwé tó kọ sí àwọn ará Gálátíà. Wọ́n yóò kọ́kọ́ tọ́ka sí “àwọn iṣẹ́ ti ara,” wọ́n á wá ní káwọn tí wọ́n ń bá sọ̀rọ̀ sọ ohun táwọn náà ti kíyè sí. (Gálátíà 5:19-23) Kíá lọ̀pọ̀ jù lọ wọn máa ń sọ pé irú ìwà bẹ́ẹ̀ ló gbòde kan lónìí. Tí wọ́n bá sì ti fi àlàyé èso ẹ̀mí Ọlọ́run hàn wọ́n, tí wọ́n sì mú wọn lọ sí Gbọ̀ngàn Ìjọba tó sún mọ́ wọn kí wọ́n lọ fojú ara wọn rí ẹ̀rí rẹ̀, kíá ni ọ̀pọ̀ wọn máa ń gbà pé: “Ọlọ́run wà láàárín yín ní ti tòótọ́.” (1 Kọ́ríńtì 14:25) Bẹ́ẹ̀, kì í ṣe kìkì Gbọ̀ngàn Ìjọba tó sún mọ́ wọn nìkan ni irú nǹkan bẹ́ẹ̀ wà o. Ibikíbi yòówù kó o lọ láyé yìí, tó o bá bá èyíkéyìí nínú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó lé ní mílíọ̀nù mẹ́fà pàdé, ẹ̀mí ìdùnnú àti ayọ̀ kan náà lo máa rí pé wọ́n ní. Ní tòótọ́, ìfararora tó ń gbéni ró yìí jẹ́ ìdí kan tó fi yẹ ká máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà, ẹni tó ń fún wa ní ẹ̀mí rẹ̀ tó mú kí èyí lè ṣeé ṣe.—Sefanáyà 3:9; Éfésù 3:20, 21.

5, 6. Báwo la ṣe lè fi hàn pé a mọrírì ẹ̀bùn gíga jù lọ tí Ọlọ́run fún wa, ìyẹn ìràpadà?

5 Ẹ̀bùn tó ga jù lọ, tó sì pé jù lọ tí Jèhófà fi jíǹkí wa ni Jésù Ọmọ rẹ̀, ipasẹ̀ ẹni tí ìràpadà wa fi ṣeé ṣe. Àpọ́sítélì Jòhánù kọ ọ́ pé: “Bí ó bá jẹ́ pé báyìí ni Ọlọ́run ṣe nífẹ̀ẹ́ wa, nígbà náà àwa fúnra wa wà lábẹ́ iṣẹ́ àìgbọ́dọ̀máṣe láti nífẹ̀ẹ́ ara wa lẹ́nì kìíní-kejì.” (1 Jòhánù 4:11) Bẹ́ẹ̀ ni o, nínífẹ̀ẹ́ Jèhófà kí á sì máa fọpẹ́ fún un nìkan kọ́ lọ̀nà tà a ó gbà fi hàn pé a mọrírì ìràpadà wa, a tún ní láti máa lo ìgbésí ayé wa lọ́nà tó fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ ọmọnìkejì wa.—Mátíù 22:37-39.

6 Tá a bá wo bí Jèhófà ṣe bá Ísírẹ́lì ìgbàanì lò, a óò rí ẹ̀kọ́ púpọ̀ kọ́ nípa ọ̀nà tí a lè gbà fi ẹ̀mí ìmoore hàn. Jèhófà lo Òfin tó ti ẹnu Mósè sọ fún orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì láti fi kọ́ àwọn èèyàn náà ní ẹ̀kọ́ púpọ̀. Àwa pẹ̀lú lè tipa “kókó ìmọ̀ àti ti òtítọ́ inú Òfin” kọ́ ẹ̀kọ́ púpọ̀ tí yóò ràn wá lọ́wọ́ láti lè ṣe gẹ́gẹ́ bí ìmọ̀ràn Pọ́ọ̀lù pé: “Ẹ . . . fi ara yín hàn ní ẹni tí ó kún fún ọpẹ́.”—Róòmù 2:20; Kólósè 3:15.

Ẹ̀kọ́ Mẹ́ta Látinú Òfin Mósè

7. Báwo ni ètò sísan ìdámẹ́wàá ṣe fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì láǹfààní láti fi hàn pé àwọn mọrírì oore Jèhófà?

7 Nínú Òfin Mósè, Jèhófà pèsè ọ̀nà mẹ́ta táwọn ọmọ Ísírẹ́lì lè gbà fi hàn pé àwọn mọrírì oore Ọlọ́run látọkànwá. Àkọ́kọ́ ni, sísan ìdámẹ́wàá. Òfin sọ pé kí ìdámẹ́wàá ilẹ̀ náà, àti “ìdá mẹ́wàá ọ̀wọ́ ẹran àti agbo ẹran” di “ohun mímọ́ lójú Jèhófà.” (Léfítíkù 27:30-32) Nígbà tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pa òfin yìí mọ́, Jèhófà bù kún wọn jìgbìnnì. Ó ní: “‘Ẹ mú gbogbo ìdá mẹ́wàá wá sínú ilé ìtọ́jú nǹkan pa mọ́, kí oúnjẹ bàa lè wà nínú ilé mi; kí ẹ sì jọ̀wọ́, dán mi wò nínú ọ̀ràn yìí,’ ni Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun wí, ‘bóyá èmi kì yóò ṣí ibodè ibú omi ọ̀run fún yín, kí èmi sì tú ìbùkún dà sórí yín ní ti tòótọ́ títí kì yóò fi sí àìní mọ́.’”—Málákì 3:10.

8. Kí ni ọrẹ àtinúwá fi yàtọ̀ sí ìdámẹ́wàá?

8 Ìkejì, láfikún sí ìdámẹ́wàá tó di dandan fún wọn láti máa san, Jèhófà ṣètò pé kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa mú ọrẹ àtinúwá wá. Ó ní kí Mósè sọ fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé: “Nígbà tí ẹ bá dé ilẹ̀ náà tí èmi yóò mú yín lọ, kí ó ṣẹlẹ̀ pẹ̀lú pé nígbà tí ẹ bá jẹ èyíkéyìí nínú oúnjẹ ilẹ̀ náà, kí ẹ mú ọrẹ wá fún Jèhófà.” Wọn yóò máa mú lára “àkọ́so ẹ̀wẹ́ ọkà” wọn “gẹ́gẹ́ bí àwọn àkàrà onírìísí òrùka” wá fún Jèhófà “gẹ́gẹ́ bí ọrẹ” ní gbogbo ìran-ìran wọn. Ṣàkíyèsí pé a ò dá iye àkọ́so kan pàtó lé wọn láti mú wá. (Númérì 15:18-21) Ṣùgbọ́n bí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì bá fẹ̀mí ọpẹ́ mú ọrẹ wọn wá, a mú un dá wọn lójú pé Jèhófà yóò bù kún wọn. Bákan náà la rí irú ìṣètò yìí nínú ohun tí wọ́n ń ṣe ní tẹ́ńpìlì tí Ìsíkíẹ́lì rí lójú ìran. A kà á pé: “Àkọ́kọ́ nínú gbogbo àkọ́pọ́n èso ohun gbogbo àti gbogbo ọrẹ ohun gbogbo tí ó wá láti inú gbogbo ọrẹ yín—ti àwọn àlùfáà ni yóò jẹ́; àkọ́so ẹ̀wẹ́ ọkà yín ni kí ẹ sì fi fún àlùfáà, láti mú kí ìbùkún wà lórí ilé rẹ.”—Ìsíkíẹ́lì 44:30.

9. Ẹ̀kọ́ wo ni Jèhófà tipa ètò pípèéṣẹ́ kọ́ni?

9 Ìkẹta, Jèhófà ṣe ètò pípèéṣẹ́. Ọlọ́run fún wọn ní ìtọ́ni pé: “Nígbà tí ẹ bá sì kórè ilẹ̀ yín, ìwọ kò gbọ́dọ̀ kárúgbìn eteetí pápá rẹ pátápátá, ìwọ kò sì gbọ́dọ̀ pèéṣẹ́ ìkórè rẹ. Pẹ̀lúpẹ̀lù, ìwọ kò gbọ́dọ̀ kó àṣẹ́kùsílẹ̀ inú ọgbà àjàrà rẹ, ìwọ kò sì gbọ́dọ̀ ṣa àwọn èso àjàrà tí ó fọ́n ká nínú ọgbà àjàrà rẹ. Kí o fi wọ́n sílẹ̀ fún ẹni tí ìṣẹ́ ń ṣẹ́ àti àtìpó. Èmi ni Jèhófà Ọlọ́run yín.” (Léfítíkù 19:9, 10) Lẹ́ẹ̀kan sí i, a kò dá ìwọ̀n kan pàtó lé wọn pé kí wọ́n máa fi sílẹ̀. Olúkúlùkù ọmọ Ísírẹ́lì ni yóò pinnu bí ìwọ̀n tí òun yóò fi sílẹ̀ fáwọn aláìní ṣe máa pọ̀ tó. Ọlọ́gbọ́n Ọba Sólómọ́nì ṣàlàyé tó bá a mú gẹ́lẹ́, ó ní: “Ẹni tí ń fi ojú rere hàn sí ẹni rírẹlẹ̀, Jèhófà ni ó ń wín, òun yóò sì san ìlòsíni rẹ̀ padà fún un.” (Òwe 19:17) Jèhófà wá tipa báyìí kọ́ wọn pé kí wọ́n máa ní ojú àánú àti ẹ̀mí ìgbatẹnirò fáwọn aláìní.

10. Nígbà tí àwọn èèyàn Ísírẹ́lì hùwà abaraámóorejẹ kí ló yọrí sí fún wọn?

10 Jèhófà bù kún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nígbà tí wọ́n ṣègbọràn, tí wọ́n san ìdámẹ́wàá, tí wọ́n mú ọrẹ àtinúwá wá, tí wọ́n sì pèsè nǹkan fáwọn tálákà. Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì hùwà abaraámóorejẹ, wọn ò rójú rere Jèhófà rárá. Ìyọnu ńlá tipa bẹ́ẹ̀ dé bá wọn, wọ́n sì dèrò ìgbèkùn lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn. (2 Kíróníkà 36:17-21) Ẹ̀kọ́ wo lèyí kọ́ wa?

Ọ̀nà Tá A Lè Gbà Fọpẹ́ Wa Hàn

11. Ọ̀nà pàtàkì wo la lè gbà fọpẹ́ wa hàn fún Jèhófà?

11 Ọ̀nà pàtàkì tí àwa náà lè gbà máa yin Jèhófà ká sì máa fọpẹ́ wa hàn wé mọ́ mímú “ọrẹ” wá bákan náà. Lóòótọ́ àwa Kristẹni kò sí lábẹ́ Òfin Mósè tó sọ ọ́ di dandan pé kéèyàn máa fi ẹranko tàbí irúgbìn rúbọ. (Kólósè 2:14) Síbẹ̀síbẹ̀, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù rọ àwọn Kristẹni tó jẹ́ Hébérù pé: “Ẹ jẹ́ kí a máa rú ẹbọ ìyìn sí Ọlọ́run nígbà gbogbo, èyíinì ni, èso ètè tí ń ṣe ìpolongo ní gbangba sí orúkọ rẹ̀.” (Hébérù 13:15) Bí a bá ń lo òye wa, agbára wa àti ohun ìní wa láti fi rú ẹbọ ìyìn sí Jèhófà, yálà nínú iṣẹ́ ìwàásù wa tàbí nínú “àpéjọpọ̀ ọ̀pọ̀ ènìyàn” tàwa Kristẹni, à ń fọpẹ́ fún Jèhófà Ọlọ́run, Baba wa ọ̀run onífẹ̀ẹ́ látọkànwá nìyẹn. (Sáàmù 26:12) Tá a bá fẹ́ ṣe bẹ́ẹ̀, kí la lè rí kọ́ látinú ọ̀nà tá a ní káwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa gbà fọpẹ́ fún Jèhófà?

12. Ní ti ọ̀ràn ojúṣe àwa Kristẹni, ẹ̀kọ́ wo la rí kọ́ nínú ètò ìdámẹ́wàá?

12 Lákọ̀ọ́kọ́, a ti rí i pé ọ̀ranyàn ni ìdámẹ́wàá sísan jẹ́ fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì, kò ṣeé yẹ̀ sílẹ̀; ojúṣe tí kálukú wọn gbọ́dọ̀ máa ṣe ni. Ní tàwa Kristẹni, ojúṣe tiwa ni pé ká máa kópa nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa ká sì máa wá sí àwọn ìpàdé Kristẹni. Gbogbo èyí jẹ́ ọ̀ranyàn, kò ṣeé yẹ̀ sílẹ̀. Jésù sọ ọ́ ní pàtó nínú àsọtẹ́lẹ̀ ńlá tí ó sọ nípa àkókò òpin, ó ní: “A ó sì wàásù ìhìn rere ìjọba yìí ní gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé, láti ṣe ẹ̀rí fún gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè; nígbà náà ni òpin yóò sì dé.” (Mátíù 24:14; 28:19, 20) Ní ti lílọ sí àwọn ìpàdé Kristẹni, Ọlọ́run mí sí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kí ó kọ̀wé pé: “Ẹ . . . jẹ́ kí a gba ti ara wa rò lẹ́nì kìíní-kejì láti ru ara wa sókè sí ìfẹ́ àti sí àwọn iṣẹ́ àtàtà, kí a má máa kọ ìpéjọpọ̀ ara wa sílẹ̀, bí àwọn kan ti ní àṣà náà, ṣùgbọ́n kí a máa fún ara wa ní ìṣírí lẹ́nì kìíní-kejì, pàápàá jù lọ bí ẹ ti rí i pé ọjọ́ náà ń sún mọ́lé.” (Hébérù 10:24, 25) À ń fọpẹ́ wa hàn fún Jèhófà nígbà tá a bá fi ayọ̀ tẹ́wọ́ gba ojúṣe wa láti máa wàásù àti láti máa kọ́ni, ká sì máa pé jọ pọ̀ déédéé pẹ̀lú àwọn ará wa nínú àwọn ìpàdé ìjọ, kí á máa ka ṣíṣe bẹ́ẹ̀ sí àǹfààní tá a fi dá wa lọ́lá.

13. Ẹ̀kọ́ wo la rí kọ́ látinú ètò ọrẹ àtinúwá àti pípèéṣẹ́?

13 Bákan náà, a tún lè jàǹfààní nínú àgbéyẹ̀wò àwọn ètò méjì mìíràn tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa ń tipa rẹ̀ fi ẹ̀mí ìmoore wọn hàn, ìyẹn ètò ọrẹ àtinúwá àti pípèéṣẹ́. Ètò méjèèjì yìí yàtọ̀ sí ti ìdámẹ́wàá, nítorí pé, ní ti ìdámẹ́wàá ó jẹ́ ọ̀ranyàn fúnni láti ṣe àwọn nǹkan pàtó kan, àmọ́ ní ti ọrẹ àtinúwá àti pípèéṣẹ́, a kò díwọ̀n iye pàtó téèyàn ní láti ṣe. Kàkà bẹ́ẹ̀, ètò méjèèjì yìí fún ìránṣẹ́ Jèhófà láyè láti ṣe gẹ́gẹ́ bí ẹ̀mí ìmoore rẹ̀ látọkànwá ṣe sún un láti ṣe tó. Lọ́nà kan náà, a lè mọ̀ pé ojúṣe pàtàkì ló jẹ́ fún olúkúlùkù ìránṣẹ́ Jèhófà láti máa kópa nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ àti láti máa lọ sí àwọn ìpàdé Kristẹni, àmọ́ ǹjẹ́ gbogbo ọkàn wa la fi ń ṣe é àti pé ṣé à ń fínnú fíndọ̀ ṣe é? Ǹjẹ́ a máa ń kà á sí àǹfààní láti fi ẹ̀mí ìmoore àtọkànwá hàn fún gbogbo ohun tí Jèhófà ti ṣe fún wa? Ǹjẹ́ à ń kópa nínú nǹkan méjèèjì yìí fàlàlà, gẹ́gẹ́ bí ipò kálukú wa ṣe yọ̀ǹda tó? Tàbí ṣé ẹ̀mí pé a kò ríbi yẹ̀ wọ́n sí la fi ń ṣe wọ́n? Àmọ́ ṣá o, kálukú wa ló máa fúnra rẹ̀ dáhùn ìbéèrè wọ̀nyí. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ ọ́ lọ́nà yìí pé: “Kí olúkúlùkù máa wádìí ohun tí iṣẹ́ tirẹ̀ jẹ́, nígbà náà ni yóò ní ìdí fún ayọ̀ ńláǹlà ní ti ara rẹ̀ nìkan, kì í sì í ṣe ní ìfiwéra pẹ̀lú ẹlòmíràn.”—Gálátíà 6:4.

14. Kí ni Jèhófà ń retí pé ká máa ṣe nínú iṣẹ́ ìsìn wa sóun?

14 Jèhófà Ọlọ́run mọ ipò tó yí kálukú wa ká dáadáa. Ó mọ ibi tí agbára wá mọ. Ó mọrírì ẹbọ táwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ bá fínnú fíndọ̀ rú, ì báà pọ̀, ì báà má pọ̀. Kò retí pé kí gbogbo wa máa ṣe ìwọ̀n kan náà, torí ó mọ̀ pé ìka ò dọ́gba. Nígbà tí Pọ́ọ̀lù ń sọ̀rọ̀ nípa fífi ohun ìní ṣe ìtọrẹ, ó sọ fún àwọn Kristẹni tó wà ní Kọ́ríńtì pé: “Bí ìmúratán bá kọ́kọ́ wà, ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà ní pàtàkì ní ìbámu pẹ̀lú ohun tí ènìyàn ní, kì í ṣe ní ìbámu pẹ̀lú ohun tí ènìyàn kò ní.” (2 Kọ́ríńtì 8:12) A lè lo ìlànà yìí kan náà gẹ́lẹ́ nínú iṣẹ́ ìsìn wa sí Ọlọ́run. Kì í ṣe ìwọ̀n tá à ń ṣe nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa ló ń pinnu bí Jèhófà ṣe máa tẹ́wọ́ gbà á, bí kò ṣe ẹ̀mí tá a fi ń ṣe é, ìyẹn tayọ̀tayọ̀ àti tinútinú.—Sáàmù 100:1-5; Kólósè 3:23.

Ní Ẹ̀mí Aṣáájú Ọ̀nà

15, 16. (a) Ìsopọ̀ wo ló wà láàárín iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà àti ẹ̀mí ìmoore? (b) Báwo ni àwọn tí kò lè ṣe aṣáájú ọ̀nà ṣe lè fi ẹ̀mí aṣáájú ọ̀nà hàn?

15 Ọ̀nà kan tó lérè tá a lè gbà fi han Jèhófà pé a moore ni pé ká wọ iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún. Ọ̀pọ̀ nínú àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà tó ti ya ara wọn sí mímọ́ ni ìfẹ́ tí wọ́n fẹ́ Jèhófà àti ìmọrírì wọn fún inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí rẹ̀ mú kí wọ́n ṣe ìyípadà tó ga nínú ìgbésí ayé wọn kí wọ́n lè túbọ̀ ráyè sin Jèhófà sí i. Ó ṣeé ṣe fáwọn kan láti ṣe aṣáájú ọ̀nà déédéé, tí wọ́n ń lo àádọ́rin wákàtí lóṣooṣù láti fi máa wàásù ìhìn rere àti láti kọ́ àwọn èèyàn ní òtítọ́. Àwọn mìíràn tó jẹ́ pé wọn ò fi bẹ́ẹ̀ ráyè nítorí bí ipò wọn ṣe rí, máa ń wá àyè láti lo àádọ́ta wákàtí lóṣù lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù gẹ́gẹ́ bí olùrànlọ́wọ́ aṣáájú ọ̀nà.

16 Ọ̀pọ̀ àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà tí wọn ò wá lè ṣe aṣáájú ọ̀nà déédéé tàbí olùrànlọ́wọ́ aṣáájú ọ̀nà ńkọ́? Wọ́n lè fẹ̀mí ìmoore hàn bí wọ́n bá dẹni tó lẹ́mìí aṣáájú ọ̀nà. Báwo ni wọn yóò ṣe ṣe èyí? Ńṣe ni kí wọ́n máa fún àwọn tó bá lè ṣe aṣáájú ọ̀nà ní ìṣírí, kí wọ́n gbin ẹ̀mí àtiṣe iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún sínú àwọn ọmọ wọn, kí wọ́n sì máa kópa déédéé nínú iṣẹ́ ìwàásù bí ipò wọn bá ṣe gbà. Bí ìmọrírì fún ohun tí Jèhófà ti ṣe fún wa, èyí tó ń ṣe lọ́wọ́lọ́wọ́, àtèyí tí yóò ṣe fún wa bá ṣe jinlẹ̀ tó lọ́kàn wa, bẹ́ẹ̀ náà ni ohun tá a máa ṣe nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa yóò ṣe pọ̀ tó.

Lílo ‘Àwọn Ohun Ìní Wa Tí Ó Níye Lórí’ Lọ́nà Tó Fi Hàn Pé A Lẹ́mìí Ìmoore

17, 18. (a) Báwo la ṣe lè lo ‘àwọn ohun ìní wa tí ó níye lórí’ lọ́nà tó fi hàn pé a lẹ́mìí ìmoore? (b) Kí ni Jésù sọ nípa ọrẹ opó kan, kí sì nìdí tó fi sọ bẹ́ẹ̀?

17 Òwe 3:9 sọ pé: “Fi àwọn ohun ìní rẹ tí ó níye lórí bọlá fún Jèhófà àti àkọ́so gbogbo èso rẹ.” A kò tún béèrè pé kí àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà máa san ìdámẹ́wàá mọ́. Kàkà bẹ́ẹ̀, ìwé tí Pọ́ọ̀lù kọ sí ìjọ Kọ́ríńtì ni pé: “Kí olúkúlùkù ṣe gan-an gẹ́gẹ́ bí ó ti pinnu nínú ọkàn-àyà rẹ̀, kì í ṣe pẹ̀lú ìlọ́tìkọ̀ tàbí lábẹ́ àfipáṣe, nítorí Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ olùfúnni ọlọ́yàyà.” (2 Kọ́ríńtì 9:7) Fífi ọrẹ ṣètìlẹyìn fún iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba Ọlọ́run tó ń lọ kárí ayé tún fi hàn pé a lẹ́mìí ìmoore. Ìmọrírì àtọkànwá ń sún wa láti máa ṣe èyí déédéé, bóyá nípa yíya àwọn nǹkan kan sọ́tọ̀ lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ tá a ó máa fi sílẹ̀, gẹ́gẹ́ bí àwọn Kristẹni ìjímìjí ti ṣe.—1 Kọ́ríńtì 16:1, 2.

18 Kì í ṣe iye tá a fi sílẹ̀ gan-an ló ń fi bí ìmọrírì wa sí Jèhófà ṣe tó hàn. Kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ̀mí tá a fi mú un wá ló ń fi í hàn. Ohun tí Jésù sọ nìyẹn nígbà tó ń wo àwọn èèyàn tí wọ́n ń fi ọrẹ wọn sínú àwọn àpótí ọrẹ nínú tẹ́ńpìlì. Nígbà tí Jésù rí i tí opó aláìní kan fi “ẹyọ owó kéékèèké méjì tí ìníyelórí wọn kéré gan-an” síbẹ̀, ó ní: “Lótìítọ́ ni mo sọ fún yín, Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé opó yìí jẹ́ òtòṣì, ó sọ sínú rẹ̀ ju gbogbo wọn lọ. Nítorí gbogbo àwọn wọ̀nyí sọ ẹ̀bùn sílẹ̀ láti inú àṣẹ́kùsílẹ̀ wọn, ṣùgbọ́n obìnrin yìí láti inú àìní rẹ̀, ó sọ gbogbo àlùmọ́ọ́nì ìgbésí ayé tí ó ní sínú rẹ̀.”—Lúùkù 21:1-4.

19. Kí nìdí tí ó fi dára pé ká tún ṣàyẹ̀wò àwọn ọ̀nà tá à ń gbà fẹ̀mí ìmoore hàn?

19 Ǹjẹ́ kí àyẹ̀wò wa yìí nípa bí a ṣe lè fi hàn pé a lẹ́mìí ìmoore sún wa láti tún ṣàyẹ̀wò àwọn ọ̀nà tá à ń gbà fi ẹ̀mí ìmọrírì wa hàn. Ǹjẹ́ ó ṣeé ṣe ká fi kún ẹbọ ìyìn wa sí Jèhófà, bákan náà ká tún fi kún ìwọ̀n ohun ìní wa tá a fi ń ṣe ìtìlẹyìn fún iṣẹ́ ìwàásù kárí ayé? Ìwọ̀n yòówù kí á fi kún un tó, kí ó dá wa lójú pé inú Baba wa ọ̀run onífẹ̀ẹ́, tó jẹ́ ọ̀làwọ́, yóò dùn gan-an pé à ń fi hàn pé a lẹ́mìí ìmoore.

Ǹjẹ́ O Rántí?

• Àwọn ìdí wo ló fi yẹ ká máa fọpẹ́ fún Jèhófà?

• Àwọn ẹ̀kọ́ wo la rí kọ́ látinú sísan ìdámẹ́wàá, ọrẹ àtinúwá àti pípèéṣẹ́?

• Báwo la ṣe lè dẹni tó ní ẹ̀mí aṣáájú ọ̀nà?

• Báwo la ṣe lè lo ‘àwọn ohun ìní wa tí ó níye lórí’ láti fi dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà?

[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]

“Gbogbo ẹ̀bùn rere àti gbogbo ọrẹ pípé jẹ́ láti òkè”

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]

Ẹ̀kọ́ mẹ́ta wo la fi hàn níhìn-ín pé a lè rí kọ́ látinú Òfin Mósè?

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]

Àwọn ohun wo la lè fi rúbọ?