Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

“Gbára Dì Fún Iṣẹ́ Rere Gbogbo”

“Gbára Dì Fún Iṣẹ́ Rere Gbogbo”

“Gbára Dì Fún Iṣẹ́ Rere Gbogbo”

“MÁA bá a lọ ní rírán wọn létí láti wà ní ìtẹríba àti láti jẹ́ onígbọràn sí àwọn ìjọba àti àwọn aláṣẹ gẹ́gẹ́ bí olùṣàkóso, láti gbára dì fún iṣẹ́ rere gbogbo.” (Títù 3:1) Iṣẹ́ rere wo ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ní lọ́kàn nígbà tó kọ ọ̀rọ̀ yẹn sí àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ̀? Ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì jinlẹ̀ kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ F. Scott tọ́ka sí irú iṣẹ́ rere kan, ó ní: “Kì í ṣe pé kí àwọn Kristẹni kàn máa ṣègbọràn sí àwọn aláṣẹ nìkan ni, wọ́n tún gbọ́dọ̀ ṣe tán láti máa ṣe iṣẹ́ rere èyíkéyìí. . . . Nígbàkigbà tó bá pọn dandan, ó yẹ káwọn Kristẹni wà lára àwọn tí yóò mú ipò iwájú nínú ṣíṣe ohun tó máa ṣe aráàlú láǹfààní. Jàǹbá iná, àjàkálẹ̀ àrùn, àjálù lóríṣiríṣi kò ní yéé wáyé, tí gbogbo ẹni rere nílùú yóò fẹ́ láti máa ṣèrànlọ́wọ́ fún ọmọnìkejì wọn.”

Àwọn Kristẹni máa ń bá àwọn aráàlú kópa nínú àwọn iṣẹ́ kan tí wọ́n bá ń ṣe níwọ̀n bí iṣẹ́ ọ̀hún kò bá ti lòdì sófin Ọlọ́run. (Ìṣe 5:29) Bí àpẹẹrẹ, ẹ̀ka ọ́fíìsì àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà nílùú Ebina ní orílẹ̀-èdè Japan máa ń kóra jọ lọ́dọọdún láti gba ẹ̀kọ́ lórí ohun téèyàn lè ṣe nígbà jàǹbá iná, gẹ́gẹ́ bí ìtọ́ni tí ẹ̀ka iléeṣẹ́ panápaná ti àdúgbò náà fún wọn. Ní irú àkókò báyìí, gbogbo ìdílé Bẹ́tẹ́lì pátá ni yóò kóra jọ láti gbọ́ ìtọ́ni tí aṣojú kan láti ẹ̀ka iléeṣẹ́ panápaná ti àdúgbò náà yóò fún wọn.

Láfikún sí èyí, ó ti lé lọ́dún mẹ́wàá tí ẹ̀ka ọ́fíìsì àwọn Ẹlẹ́rìí ní Japan ti máa ń bá àwọn aláṣẹ àdúgbò fọwọ́ sowọ́ pọ̀ níbi ètò ìlàlóye kan tí àwọn aláṣẹ náà ń ṣe láti fi kọ́ àwọn èèyàn lóhun tí wọ́n lè ṣe láti dènà jàǹbá iná. Níbi ètò ìlàlóye yìí, àwọn iléeṣẹ́ tó wà nílùú yẹn máa ń ṣàṣefihàn béèyàn ṣe lè gbára dì fún iná pípa. Àìmọye ìgbà ni wọ́n ti gbóríyìn fún ẹ̀ka ọ́fíìsì àwọn Ẹlẹ́rìí fún ìmọ̀ wọn àti ìfọwọ́sowọ́pọ̀ àwọn òṣìṣẹ́ wọn. Ní 2001, wọ́n gba ẹ̀bùn ipò kìíní níbi ètò ìlàlóye náà. Wọ́n ṣe tán láti ṣe iṣẹ́ rere tó lè gbẹ̀mí àwọn èèyàn là bí jàǹbá iná bá wáyé.

Iṣẹ́ Tó Ń Ṣeni Láǹfààní

Ṣùgbọ́n, iṣẹ́ ìgbẹ̀mílà kan tún wà tó ju ìyẹn lọ tó jẹ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lógún. Wọ́n ń lọ sọ́dọ̀ àwọn aládùúgbò wọn déédéé láti sọ ìhín rere Ìjọba Ọlọ́run fún wọn. (Mátíù 24:14) Àwọn Ẹlẹ́rìí máa ń gba àwọn èèyàn níyànjú pé kí wọ́n kọ́ àwọn ìlànà Bíbélì kí wọ́n sì máa fi ohun tí wọ́n kọ́ ṣèwà hù nígbèésí ayé wọn, kí ìgbésí ayé wọn lè túbọ̀ dára sí i, kí wọ́n sì lè máa retí ìyè àìnípẹ̀kun nínú ayé kan tí àlàáfíà àti ààbò yóò wà.

Àwọn kan lè má mọyì iṣẹ́ táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ṣe yìí, wọ́n lè kà wọ́n sí ayọnilẹ́nu èèyàn. Àmọ́, èrò Jean Crepeau tó jẹ́ adájọ́ ní Ilé Ẹjọ́ Gíga kan nílùú Quebec ní Kánádà, yàtọ̀ sí ìyẹn. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà níbẹ̀ kò fara mọ́ òfin tí wọ́n ṣe nílùú Blainville, ní Quebec pé kí wọ́n kọ́kọ́ gbàwé àṣẹ kí wọ́n tó lè máa wàásù láti ilé dé ilé. Nínú ẹjọ́ tí adájọ́ tó ń jẹ́ Crepeau dá, ó ní: “Ìbẹ̀wò àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà jẹ́ iṣẹ́ tí àwọn Kristẹni fi ń ṣe aráàlú láǹfààní . . . ìwé pàtàkì làwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà sì máa ń fún aráàlú tó bá nífẹ̀ẹ́ sí ọ̀rọ̀ wọn, ìwé náà máa ń dá lórí ọ̀ràn tó jẹ mọ́ ìsìn, Bíbélì, oògùn, ọtí àmujù, ẹ̀kọ́ fáwọn ọ̀dọ́, ìṣòro ìgbéyàwó àti ìkọ̀sílẹ̀.” Lára ohun tí adájọ́ náà sọ nínú ìdájọ́ rẹ̀ ni pé: “Ohun tí ilé ẹjọ́ yìí parí èrò sí ni pé ọ̀rọ̀ àrífín, àìfinipeni, èébú àti ìbanilórúkọjẹ́ ni yóò jẹ́ tá a bá ń fi àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà wé àwọn tó ń kiri ọjà káàkiri.”

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń wá ire àwọn aráàlú ibi tí wọ́n ń gbé nípa ríràn wọ́n lọ́wọ́ láti borí àwọn ìṣòro ìgbésí ayé wọn àti láti mọ ohun rere tó ń bọ̀ lọ́jọ́ iwájú. Bíbélì ló ń ràn wọ́n lọ́wọ́ láti ṣe iṣẹ́ yìí. “Gbogbo Ìwé Mímọ́ ni Ọlọ́run mí sí, ó sì ṣàǹfààní fún kíkọ́ni, fún fífi ìbáwí tọ́ni sọ́nà, fún mímú àwọn nǹkan tọ́, fún bíbániwí nínú òdodo, kí ènìyàn Ọlọ́run lè pegedé ní kíkún, tí a mú gbára dì pátápátá fún iṣẹ́ rere gbogbo.”—2 Tímótì 3:16, 17.

Ṣé wàá fẹ́ mọ bí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe ń “gbára dì fún iṣẹ́ rere gbogbo”? A rọ̀ ọ́ pé kó o gbà wọ́n láyè kí wọ́n ràn ọ́ lọ́wọ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ sí i nípa Bíbélì, kó o sì tipa báyìí jàǹfààní tó wà nínú iṣẹ́ tí wọ́n ń ṣe fún aráàlú ní àdúgbò rẹ àti káàkiri ayé.

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 30, 31]

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń bá àwọn aláṣẹ fọwọ́ sowọ́ pọ̀

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 31]

Àwọn èèyàn mọ̀ pé àwọn Ẹlẹ́rìí máa ń ṣèrànlọ́wọ́ fún ọmọnìkejì wọn