Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

“Kí Ni Ẹ̀mi Yóò San Padà Fún Jèhófà?”

“Kí Ni Ẹ̀mi Yóò San Padà Fún Jèhófà?”

Ìtàn Ìgbésí Ayé

“Kí Ni Ẹ̀mi Yóò San Padà Fún Jèhófà?”

GẸ́GẸ́ BÍ MARIA KERASINIS ṢE SỌ Ọ́

Nígbà tí mo wà lọ́mọ ọdún méjìdínlógún, mo dẹni àríbanújẹ́ fáwọn òbí mi, ìdílé mi ta mí nù, mo dẹni táwọn ará abúlé wa fi ń ṣe yẹ̀yẹ́. Wọ́n pàrọwà fún mi, wọ́n kógun tì mí, wọ́n tún halẹ̀ mọ́ mi kí n sáà lè ba ìwà títọ́ mi sí Ọlọ́run jẹ́, àmọ́ pàbó ni gbogbo rẹ̀ já sí. Mo mọ̀ dájú pé, bí mo bá fi ìṣòtítọ́ rọ̀ mọ́ òtítọ́ Bíbélì, màá jàǹfààní nípa tẹ̀mí. Nígbà tí mo wo àádọ́ta ọdún tí mo ti fi sin Jèhófà, mo lè sọ bíi ti onísáàmù náà tó sọ pé: “Kí ni èmi yóò san padà fún Jèhófà nítorí gbogbo àǹfààní tí mo rí gbà láti ọ̀dọ̀ rẹ̀?”—Sáàmù 116:12.

NÍ ỌDÚN 1930, wọ́n bí mi sí abúlé Aggelokastro tó wà ní nǹkan bí ogún kìlómítà sí èbúté Kẹnkíríà ní apá ìlà oòrùn Ilẹ̀ Tóóró Kọ́ríńtì. Kẹnkíríà yìí ní ìlú tí wọ́n ti fìdí ọ̀kan lára ìjọ Kristẹni tòótọ́ múlẹ̀ ní ọ̀rúndún kìíní.—Ìṣe 18:18; Róòmù 16:1.

Ìdílé wa tòrò. Bàbá mi ni baálẹ̀ abúlé wa, àwọn ará abúlé sì bọ̀wọ̀ fún un. Èmi ni ọmọ kẹta nínú ọmọ márùn-ún táwọn òbí mi bí. Inú ẹ̀sìn Ìjọ Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì Ilẹ̀ Gíríìsì làwọn òbí mi ti tọ́ wa dàgbà. Gbogbo ọjọ́ Sunday ni mo máa ń lọ gba ara Olúwa. Mo máa ń ṣe ìjẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ níwájú àwọn ère ìjọsìn, mo máa ń tan àbẹ́là nílé ìsìn tó wà lábúlé, gbogbo ààwẹ̀ ni mo sì máa ń gbà. Lọ́pọ̀ ìgbà, mo máa ń ronú àtidi ajẹ́jẹ̀ẹ́ ànìkàngbé. Àmọ́ láìpẹ́, mo dẹni àkọ́kọ́ nínú ìdílé wa tó ṣe ohun tó ba àwọn òbí mi nínú jẹ́.

Òtítọ́ Bíbélì Dùn Mọ́ Mi

Nígbà tí mo wà ní nǹkan bí ọmọ ọdún méjìdínlógún, mo gbọ́ pé Katina, arábìnrin ọkọ ẹ̀gbọ́n mi tó ń gbé ní abúlé tí kò fi bẹ́ẹ̀ jìnnà sọ́dọ̀ wa, ń ka ìwé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà àti pé kò lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì mọ́. Ìròyìn yìí ò múnú mi dún rárá, nítorí náà mo pinnu pé màá ràn án lọ́wọ́ kó lè padà sí ọ̀nà tí mo rò pé ó tọ́ nígbà yẹn. Nípa bẹ́ẹ̀, nígbà tí Katina wá kí wa, mo sọ fún un pé ká jọ jáde kí ń lè mú un ya ilé àlùfáà wa. Nígbà tí alúfàá náà fi máa bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ̀, ńṣe ló kàn ń rọ̀jò ọ̀rọ̀ ìṣáátá sórí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ó sọ pé aládàámọ̀ ni wọ́n, pé wọ́n ti ṣi Katina lọ́nà. Ọjọ́ mẹ́ta la jọ fi sọ̀rọ̀ lálaalẹ́. Katina lo àlàyé tó ti múra sílẹ̀ dáadáa látinú Bíbélì láti fi jẹ́ kó mọ̀ pé irọ́ ni gbogbo ẹ̀sùn tó fi kan àwọn Ẹlẹ́rìí. Níkẹyìn, alúfàá náà sọ fún un pé ó jẹ́ arẹwà ọmọbìnrin tó ní làákàyè, nítorí náà kó kọ́kọ́ jayé orí rẹ̀ nísinsìnyí tó ṣì lè ṣe bẹ́ẹ̀, lẹ́yìn náà ó lè wá máa sin Ọlọ́run nígbà tó bá darúgbó.

Mi ò sọ nǹkan kan fáwọn òbí mi nípa ọ̀rọ̀ tá a jọ sọ yìí, àmọ́ ní Sunday tó tẹ̀ lé e, mi ò lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì. Kíá ni àlùfáà náà wá sí ṣọ́ọ̀bù wa lọ́sàn-án ọjọ́ náà. Mo wá àwáwí kan ṣe pé, ńṣe ni mo dúró sí ṣọ́ọ̀bù láti ran bàbá mi lọ́wọ́.

Àlùfáà náà bi mí pé: “Ṣé ìdí tó ò fi wá sí ṣọ́ọ̀ṣì nìyẹn lóòótọ́, àbí ọmọbìnrin yẹn ti yí ọ lórí?”

Mo sọ fún un ní tààràtà pé: “Ohun táwọn èèyàn yẹn gbà gbọ́ dáa ju tiwa lọ.”

Bí àlùfáà náà ṣe wo bàbá mi lójú, ó ní: “Ọ̀gbẹ́ni Economos, lé ìbátan rẹ yìí jáde kúró nílé rẹ kíá; nítorí ewu ńlá ló jẹ́ fún ìdílé rẹ.”

Ìdílé Mi Kẹ̀yìn sí Mi

Èyí jẹ́ ní ìparí àwọn ọdún 1940 nígbà tí ogun abẹ́lé ilẹ̀ Gíríìkì gbóná janjan. Ẹ̀rù ba bàbá mi pé káwọn adàlúrú máà gbé mi sá lọ, nítorí náà, ó ṣètò pé kí n kúrò lábúlé náà, kí n lọ máa gbé lọ́dọ̀ ẹ̀gbọ́n mi ní abúlé tí Katina wà. Ní oṣù méjì tí mo lò níbẹ̀, mo kẹ́kọ̀ọ́ nípa ohun tí Bíbélì sọ lórí àwọn ọ̀ràn mélòó kan. Ìjákulẹ̀ ló jẹ́ fún mi nígbà tí mo rí i pé ọ̀pọ̀ lára ẹ̀kọ́ ìsìn Ìjọ Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì ni kò bá Ìwé Mímọ́ mu. Mo rí i nínú ẹ̀kọ́ mi pé Ọlọ́run kò fọwọ́ sí ìjọsìn tí à ń tipa ère ṣe àti pé àwọn Kristẹni kọ́ ló bẹ̀rẹ̀ onírúurú àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ ti ẹ̀sìn, irú bíi jíjúbà àgbélébùú, mo tún rí i nínú ẹ̀kọ́ mi pé a ní láti máa jọ́sìn Ọlọ́run “ní ẹ̀mí àti òtítọ́” kí inú rẹ̀ lè dùn sí wa. (Jòhánù 4:23; Ẹ́kísódù 20:4, 5) Ju gbogbo rẹ̀ lọ, mo rí i nínú ẹ̀kọ́ mi pé ìlérí ìyè àìnípẹ̀kun lórí ilẹ̀ ayé wà nínú Bíbélì! Irú òtítọ́ ṣíṣeyebíye látinú Bíbélì bẹ́ẹ̀ wà lára àǹfààní tí mo kọ́kọ́ rí lọ́dọ̀ Jèhófà.

Láàárín àkókò yẹn, ẹ̀gbọ́n mi àti ọkọ rẹ̀ ṣàkíyèsí pé n kì í sàmì àgbélébùú kí n tó jẹun, n kì í sì í gbàdúrà níwájú àwọn ère. Lálẹ́ ọjọ́ kan, àwọn méjèèjì lù mí. Lọ́jọ́ kejì mo bá kúrò nílé wọn, mo lọ sílé àbúrò màmá mi obìnrin. Ọkọ ẹ̀gbọ́n mi sọ ohun tó ṣẹlẹ̀ fún bàbá mi. Láìpẹ́ lẹ́yìn náà, bàbá mi dé tóun ti omijé lójú, ó gbìyànjú láti yí ọkàn mi padà. Ọkọ ẹ̀gbọ́n mi kúnlẹ̀ síwájú mi pé kí n dárí ji òun, mo sì dárí jì í. Láti yanjú ọ̀ràn náà, wọ́n ní kí n padà máa lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì, àmọ́ mo kọ̀ jálẹ̀.

Nígbà tí mo padà sí abúlé bàbá mi, wọ́n tún bẹ̀rẹ̀ sí í fúngun mọ́ mi. Kò sọ́nà tí mo lè gbà máa bá Katina sọ̀rọ̀ mọ́, mi ò sì ní ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ kankan lọ́wọ́, Bíbélì pàápàá, mi ò ní. Ìdùnnú ńlá ló jẹ́ fún mi nígbà tí ọmọbìnrin ẹ̀gbọ́n bàbá mi gbìyànjú láti ràn mí lọ́wọ́. Nígbà tó lọ sí Kọ́ríńtì, ó rí ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ó sì bá mi gba ìwé “Jẹki Ọlọrun Jẹ Olõtọ” bọ̀ àti ẹ̀dá kan Ìwé Mímọ́ Kristẹni lédè Gíríìkì, tí mo bẹ̀rẹ̀ sí í kà ní bòókẹ́lẹ́.

Nǹkan Yí Padà Lójijì

Odindi ọdún mẹ́ta ni mo fi kojú àtakò lílekoko. Mi ò rí Ẹlẹ́rìí kankan, mi ò sì rí ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ kankan gbà. Àmọ́ mi ò mọ̀ pé àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ pàtàkì kan ń bọ̀ wá ṣẹlẹ̀ nígbèésí ayé mi.

Bàbá mi ní kí n wá lọ máa gbé lọ́dọ̀ arákùnrin màmá mi tó wà ní Tẹsalóníkà. Kí n tó lọ sí Tẹsalóníkà, mo lọ sí ṣọ́ọ̀bù obìnrin kan tó ń ránṣọ ní Kọ́ríńtì, láti lọ rán ẹ̀wù àwọ̀lékè kan. Ìyàlẹ́nu gbáà ló jẹ́ fún mi nígbà tí mo rí i pé ibẹ̀ ni Katina ti ń ṣíṣẹ! Inú àwa méjèèjì dùn gan-an láti bára pàdé lẹ́yìn ọjọ́ pípẹ́. Nígbà tí àwa méjèèjì kúrò ní ṣọ́ọ̀bù náà, tá à ń lọ, a bá ọ̀dọ́kùnrin tó fani mọ́ra kan pàdé, ó ń gun kẹ̀kẹ́ bọ̀ láti ibi iṣẹ́, ó ń lọ sílé. Charalambos lorúkọ rẹ̀. Lẹ́yìn tá a ti jọ mọra, a pinnu pé a óò fẹ́ra wa. Ní àkókó yìí, ìyẹn ní January 9, 1952, ni mo ṣe ìrìbọmi láti fi hàn pé mo ti ya ara mi sí mímọ́ fún Jèhófà.

Charalambos ti ṣèrìbọmi ṣáájú ìgbà yẹn. Àwọn ará ilé rẹ̀ ṣe àtakò gidigidi sí òun náà pẹ̀lú. Charalambos ní ìtara gan-an. Ó sìn gẹ́gẹ́ bí olùrànlọ́wọ́ ìránṣẹ́ ìjọ, ó sì ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Láìpẹ́ àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀ ọkùnrin tẹ́wọ́ gba òtítọ́, lónìí ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn ará ilé wọn ló ń sin Jèhófà.

Bàbá mi fẹ́ràn Charalambos gan-an, nítorí náà ó gbà pé ká fẹ́ra wa, àmọ́ màmá mi ò tètè gbà. Láìfi gbogbo èyí pè, èmi àti Charalambos ṣègbéyàwó ní March 29, 1952. Ẹ̀gbọ́n mi àgbà tó jẹ́ ọkùnrin àti ọkàn nínú àwọn ọmọ ẹ̀gbọ́n bàbá mi nìkan ló wá síbi ìgbéyàwó náà. Mi ò mọ̀ nígbà yẹn pé ìbùkún aláìlẹ́gbẹ́, àní ẹ̀bùn kan látọ̀dọ̀ Jèhófà, ni Charalambos yóò jẹ́ fún mi! Nítorí pé ńṣe la jọ máa ń lọ káàkiri, ó ṣeé ṣe fún mi láti gbé ìgbésí ayé tó dá lórí iṣẹ́ ìsìn Jèhófà.

A Ń Fún Àwọn Arákùnrin Wa Lókun

Ní 1953, èmi àti Charalambos ṣí lọ sí ìlú Áténì. Nítorí pé Charalambos fẹ́ ṣe púpọ̀ sí i nínú iṣẹ́ ìwàásù, ó fi okòwò tí ìdílé rẹ̀ ń ṣe sílẹ̀, ó wá bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe iṣẹ́ àbọ̀ọ̀ṣẹ́. A jọ máa ń ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ Kristẹni lọ́sàn-án, a sì ní ọ̀pọ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tá à ń ṣe.

Nítorí tí ìjọba ti fòfin de iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa, a ní láti wá ọgbọ́n ta sí bí a óò ṣe máa wàásù. Bí àpẹẹrẹ, a máa ń fi ẹ̀dà Ilé Ìṣọ́ sí ojú fèrèsé ilé ìtajà kékeré tó wà láàárín ìlú Áténì níbi tí ọkọ mi ti ń ṣe iṣẹ́ àbọ̀ọ̀ṣẹ́. Ọ̀gá ọlọ́pàá kan sọ fún wa pé ìjọba ti fòfin de ìwé ìròyìn náà. Àmọ́, ó béèrè bóyá òun lè mú ẹ̀dà kan lọ kí òun lè ṣe ìwádìí ní ọ́fíìsì tó ń bójú tó ọ̀ràn ààbò. Wọ́n sọ fún un níbẹ̀ pé ìwé ìròyìn náà bófin mu, ó sì padà wá sọ fún wa. Gbàrà tí àwọn arákùnrin yòókù tó ní ilé ìtajà kékeré gbọ́, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í fi ẹ̀dà Ilé Ìṣọ́ sí ojú fèrèsé tiwọn pẹ̀lú. Ọkùnrin kan tó gba Ilé Ìṣọ́ látinú ilé ìtajà wa kékeré náà di Ẹlẹ́rìí, ó ń sìn gẹ́gẹ́ bí alàgbà ní báyìí.

Inú wa dùn pé àbúrò mi ọkùnrin tó kéré jù lọ kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́. Ó wá sí ìlú Áténì láti kẹ́kọ̀ọ́ ní kọ́lẹ́ẹ̀jì àwọn tí ń wakọ̀ òkun oníṣòwò, a sì mú un dání lọ sí àpéjọ àgbègbè. Inú igbó la ti máa ń ṣèpàdé àgbègbè ní bòókẹ́lẹ́. Ohun tó gbọ́ dùn mọ́ ọn nínú, àmọ́ kò pẹ́ tó fi bẹ̀rẹ̀ sí í rìnrìn àjò. Nínú ìrìn àjò rẹ̀ kan, ó gúnlẹ̀ sí èbúté kan ní Ajẹntínà. Níbẹ̀ ni míṣọ́nnárì kan tí wọ ọkọ̀ òkun láti wàásù, àbúrò mi ní kó fún òun ní àwọn ìwé ìròyìn wa. Inú wa dùn jọjọ nígbà tá a rí lẹ́tà rẹ̀ gbà tó sọ pé: “Mo ti rí òtítọ́. Ẹ jọ̀wọ́, ẹ ṣètò kí wọ́n lè máa fi ìwé ìròyìn ránṣẹ́ sí mi déédéé.” Lónìí, òun àti ìdílé rẹ̀ ń fi ìṣòtítọ́ sin Jèhófà.

Ní 1958, wọ́n yan ọkọ mi sí iṣẹ́ alábòójútó àyíká. Níwọ̀n bí ìjọba ti fòfin de iṣẹ́ wa, tí ipò nǹkan sì le koko gan-an, àwọn alábòójútó àyíká kì í sábà mú ìyàwó wọn dání lọ ṣe ìbẹ̀wò. Ní October 1959, a béèrè lọ́wọ́ àwọn arákùnrin tó ń ṣàbójútó ní ẹ̀ka ọ́fíìsì bóyá mo lè máa tẹ̀ lé ọkọ mi nínú iṣẹ́ náà. Wọ́n gbà pé kí n máa tẹ̀ lé e. Àwọn ìjọ tó wà láàárín gbùngbùn orílẹ̀-èdè Gíríìsì àti àríwá Gíríìsì là ń bẹ̀ wò tí a sì ń fún lókun nípa tẹ̀mí.

Ìrìn àjò wọ̀nyẹn ò rọrùn rárá. Ojú ọ̀nà tí wọ́n yọ́ ọ̀dà sí kò pọ̀ láyé ìgbà yẹn. Níwọ̀n bí a ò ti ní mọ́tò, ọkọ̀ èrò tàbí ọkọ̀ akẹ́rù kékeré, tí wọ́n máa fi ń kó adìyẹ àti ẹrù ọjà la máa ń wọ̀. A máa ń wọ bàtà òjò kí a lè gba àwọn ojú ọ̀nà ẹlẹ́rẹ̀ kọjá. Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé abúlé kọ̀ọ̀kan ló ní àwọn ẹ̀ṣọ́ tirẹ̀, òru la máa wọnú ìlú kí wọ́n má báa máa béèrè ọ̀rọ̀ lọ́wọ́ wa.

Àwọn ará mọrírì ìbẹ̀wò wọ̀nyẹn gan-an. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ lára wọn á ti ṣíṣẹ́ àṣelàágùn nínú oko, síbẹ̀ wọ́n máa ń sapá gidigidi láti wá sípàdé tá à ń ṣe lálẹ́ ní ilé ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. Àwọn ará lẹ́mìí àlejò ṣíṣe gan-an, nǹkan tó bá dáa jù lọ ni wọ́n fi ń ṣàlejò, bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọn ò fi bẹ́ẹ̀ ní nǹkan. Nígbà míì, ńṣe làwa àti gbogbo ìdílé wọn á jọ sun yàrá kan náà. Nǹkan míì tó ṣàǹfààní fún wa gan-an ni ìgbàgbọ́, ìfaradà àti ìtara tí àwọn ará ní.

A Mú Iṣẹ́ Ìsìn Wa Gbòòrò Sí I

Nígbà tá a lọ sí ẹ̀ka ọ́fíìsì tó wà nílùú Áténì lóṣù February 1961, wọ́n bi wá léèrè bóyá a fẹ́ sìn ní Bẹ́tẹ́lì. A fi ọ̀rọ̀ Aísáyà fèsì, èyí tó sọ pé: “Èmi nìyí! Rán mi.” (Aísáyà 6:8) Lẹ́yìn oṣù méjì sígbà yẹn, a rí lẹ́tà kan gbà tí wọ́n fi sọ fún wa pé ká tètè máa bọ̀ ní Bẹ́tẹ́lì. Bó ṣe di pé a bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìsìn wa ní Bẹ́tẹ́lì ní May 27, 1961, nìyẹn.

A gbádùn iṣẹ́ tuntun tí wọ́n yàn fún wa gan-an, ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni ibẹ̀ sì ti mọ́ wa lára. Ọkọ mi ṣiṣẹ́ ní ẹ̀ka tó ń bójú tó Iṣẹ́ Ìsìn àti ti Ìforúkọsílẹ̀ fún ìwé ìròyìn, lẹ́yìn náà, ó sìn gẹ́gẹ́ bí ọkàn lára Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka fúngbà díẹ̀. Onírúurú ibi ni mo ti ṣiṣẹ́ ní Bẹ́tẹ́lì. Àwa méjìdínlógún la jẹ́ ara ìdílé Bẹ́tẹ́lì nígbà náà, àmọ́ fún nǹkan bí ọdún márùn ún, àwa tá a wá níbẹ̀ tó nǹkan bí ogójì èèyàn nítorí Ilé Ẹ̀kọ́ Àwọn Alàgbà àti Ìránṣẹ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ tí wọ́n ń ṣe ní Bẹ́tẹ́lì nígbà náà. Láàárọ̀, màá fọ abọ́, màá ṣèrànlọ́wọ́ fún arákùnrin tó máa ń se oúnjẹ, màá tẹ́ bẹ́ẹ̀dì méjìlá, màá sì tún orí tábìlì ìjẹun ṣe fún oúnjẹ ọ̀sán. Tó bá di ọ̀sán, màá lọ aṣọ, màá sì tún mú kí ilé ìtura àtàwọn yàrá wà ní mímọ́ tónítóní. Mo máa ń ṣiṣẹ́ ní ilé ìfọṣọ lẹ́ẹ̀kan lọ́sẹ̀. Iṣẹ́ pọ̀ tí mo máa ń ṣe, àmọ́ inú mi dún pé mo lè ṣèrànwọ́.

Ọwọ́ wa máa ń di gan-an nínú iṣẹ́ Bẹ́tẹ́lì àti nínú iṣẹ́ ìsìn pápá. Lọ́pọ̀ ìgbà, a máa ń ní tó ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì méje tá à ń ṣe. Ní òpin ọ̀sẹ̀, mo máa ń tẹ̀ lé Charalambos tó bá fẹ́ lọ sọ àsọyé ní onírúurú ìjọ. A kì í ya ara wa sílẹ̀.

A bá tọkọtaya kan ṣèkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Tọkọtaya náà ti jinlẹ̀ nínú Ìjọ Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì Ilẹ̀ Gíríìsì, ọ̀rẹ́ àlùfáà tó ń darí ẹgbẹ́ tí Ṣọ́ọ̀ṣì yàn láti máa mú àwọn aládàámọ̀ sì ni wọ́n. Yàrá kan wà nílé wọn tó jẹ́ pé ère ìjọsìn ló kúnnú rẹ̀, tí tùràrí sì ń jó níbẹ̀ láìdáwọ́dúró, tí orin ìsìn Byzantium sì máa ń dún nínú yàrá náà látàárọ̀ ṣúlẹ̀. Fún àwọn àkókò kan, a máa ń lọ sọ́dọ̀ wọn lọ́jọ́ Thursday láti bá wọn ṣèkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, àlùfáà ọ̀rẹ́ wọn sì máa ń wá sọ́dọ̀ wọn lọ́jọ́ Friday. Lọ́jọ́ kan, wọ́n ní ká rí i pé a wá sí ilé àwọn o, nítorí pé àwọn ní nǹkan kan tí wọ́n fẹ́ fi hàn wá. Yàrá yẹn ni wọ́n kọ́kọ́ fi hàn wá. Wọ́n ti kó gbogbo ère ìjọsìn wọ̀nyẹn dànù, wọ́n sì ti tún yàrá náà ṣe. Tọkọtaya náà tẹ̀ síwájú kíákíá, wọ́n sì ṣe ìrìbọmi. Àpapọ̀ iye àwọn tá a bá ṣèkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tí wọ́n ti ya ìgbésí ayé wọn sí mímọ́ fún Jèhófà tí wọ́n sì ti ṣe ìrìbọmi jẹ́ àádọ́ta.

Àǹfààní àkànṣe kan tí mo gbádùn gan-an ni ti ìfararora tí mo ní pẹ̀lú àwọn arákùnrin tó jẹ́ ẹni àmì òróró. Ìbẹ̀wò àwọn tí wọ́n jẹ́ ara Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso, irú bíi Arákùnrin Knorr, Arákùnrin Franz àti Arákùnrin Henschel jẹ́ ìṣírí ńláǹlà fún mi. Ó ti lé ní ogójì ọdún tí mo ti fi sìn ní Bẹ́tẹ́lì, síbẹ̀ mo ṣì ka iṣẹ́ ìsìn yìí sí nǹkan iyì àti àǹfààní ńláǹlà kan.

Àìsàn àti Àdánù

Ní 1982, àrùn Ọdẹ Orí Abọ́jọ́-ogbó-rìn bẹ̀rẹ̀ sí í yọ ọkọ mi lẹ́nu. Nígbà tó máa fi di ọdún 1990, àìsàn ọ̀hún tí wá le sí i, ó wá di pé ká máa ṣètọ́jú rẹ̀ ní gbogbo ìgbà. Láàárín ọdún mẹ́jọ tí ọkọ mi lò kẹ́yìn láyé, a kò lè jáde kúrò ní Bẹ́tẹ́lì rárá. Ọ̀pọ̀ àwọn ará wa ọ̀wọ́n tó wà ní Bẹ́tẹ́lì, títí kan àwọn arákùnrin tó ń ṣe àbójútó ṣètò láti máa ràn wá lọ́wọ́. Àmọ́, pẹ̀lú gbogbo ìrànlọ́wọ́ wọn náà, mo ṣì máa ń lo ọ̀pọ̀ wákàtí tọ̀sán tòru láti ṣètọ́jú rẹ̀. Kì í rọrùn rárá nígbà míì, ọ̀pọ̀ ìgbà ni n kì í lè sùn lóru.

Ní July 1998, ọkọ mi ọ̀wọ́n ṣaláìsí. Òótọ́ ni pé àárò rẹ̀ sọ mí gan-an, àmọ́ mímọ̀ pé ó wà lábẹ́ ààbò Ọlọ́run máa ń tù mí nínú, mo sì mọ̀ pé Jèhófà yóò rántí rẹ̀ nígbà tó bá fẹ́ jí ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn mìíràn dìde.— Jòhánù 5:28, 29.

Mo Mọrírì Oore Tí Jèhófà Ṣe fún Mi

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọkọ mi ò sí mọ́, mi ò dá wà ní èmi nìkan. Mo ṣì ní àǹfààní láti máa sìn ní Bẹ́tẹ́lì àti pé ìfẹ́ àti àbójútó tí gbogbo ìdílé Bẹ́tẹ́lì ń fún mi máa ń mú inú mi dùn. Àwọn arákùnrin àti arábìnrin nípa tẹ̀mí jákèjádò ilẹ̀ Gíríìsì jẹ́ ara ìdílé mi pẹ̀lú. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé mo ti lé lẹ́ni àádọ́rin ọdún báyìí, mo ṣì máa ń ṣe iṣẹ́ nílé ìdáná àti nílé oúnjẹ látàárọ̀ ṣúlẹ̀ bíi táwọn yòókù.

Ní 1999, ohun tí mo ti ń wọ̀nà fún tipẹ́ ṣeé ṣe, mo ṣèbẹ̀wò sí orí iléeṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà nílùú New York. Ìbẹ̀wò náà dùn mọ́ mi gan-an. Ìbẹ̀wò tó ń gbéni ró ni, mi ò sì lè gbàgbé rẹ̀ láé.

Nígbà tí mo padà wẹ̀yìn wò, mo gbà ní ti tòótọ́ pé ọ̀nà tó dára jù lọ ni mo gbà lo ìgbésí ayé mi. Iṣẹ́ tó dáa jù lọ téèyàn lè ṣe ni láti máa sin Jèhófà gẹ́gẹ́ bí òjíṣẹ́ alákòókò kíkún. Mo lè fọwọ́ sọ̀yà pé ìyà nǹkan kan ò jẹ mí rí. Tìfẹ́tìfẹ́ ni Jèhófà fi bójú tó èmi àti ọkọ mi nípa tẹ̀mí àti nípa tara. Ìrírí tèmi fúnra mi ti jẹ́ kí n mọ ìdí tí onísáàmù náà fi béèrè pé: “Kí ni èmi yóò san padà fún Jèhófà nítorí gbogbo àǹfààní tí mo rí gbà láti ọ̀dọ̀ rẹ̀?”—Sáàmù 116:12.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]

Èmi àti Charalambos kì í ya ara wa sílẹ̀

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 27]

Ọkọ mi rèé ní ọ́fíìsì rẹ̀ ní ẹ̀ka iléeṣẹ́

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 28]

Àǹfààní ńlá ni mo ka iṣẹ́ ìsìn Bẹ́tẹ́lì sí