Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ohun Tó Yẹ Kó Jẹ́ Ìdí Tá A Fi Gba Ọlọ́run Gbọ́

Ohun Tó Yẹ Kó Jẹ́ Ìdí Tá A Fi Gba Ọlọ́run Gbọ́

Ohun Tó Yẹ Kó Jẹ́ Ìdí Tá A Fi Gba Ọlọ́run Gbọ́

ÌWÉ ilẹ̀ Kòríà náà 31 Reasons Why Young People Leave the Church (Ìdí Mọ́kànlélọ́gbọ̀n Táwọn Ọ̀dọ́ Kì í Fi Í Lọ sí Ṣọ́ọ̀ṣì Mọ́) sọ pé ọ̀pọ̀ ni kò lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì mọ́ nítorí pé wọn kò rí ìdáhùn tó tẹ́ wọn lọ́rùn sáwọn ìbéèrè wọn. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n máa ń béèrè ìbéèrè bíi, ‘Kí nìdí táwọn èèyàn tó gba Ọlọ́run gbọ́ fi ń jìyà?’ àti ‘Èé ṣe tá a fi ní láti fara mọ́ gbogbo ohun tí wọ́n ń kọ́ni ní ṣọ́ọ̀ṣì nígbà tó jẹ́ pé ọ̀pọ̀ lára àwọn ẹ̀kọ́ náà ni kì í yéni, tó sì tún ta ko ara wọn?’

Ọ̀pọ̀ èèyàn ló gbà pé kò sí ìdáhùn nínú Bíbélì nítorí pé ìdáhùn tí àwọn àlùfáà ṣọ́ọ̀ṣì wọn fún wọn kò dùn mọ́ wọn rárá. Nígbà tí àlùfáà kan bá gbé àlàyé rẹ̀ karí èrò tara rẹ̀, àṣìlóye lohun tó sábà máa ń yọrí sí, kódà ó máa ń mú káwọn èèyàn kọ Ọlọ́run àti Bíbélì sílẹ̀.

Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Abel, ẹni tí wọ́n bí sínú ẹ̀sìn Luther ní Gúúsù Áfíríkà nìyẹn. Ó sọ pé: “Wọ́n ń kọ́ni ní ṣọ́ọ̀ṣì pé Ọlọ́run ló ‘ń mú’ gbogbo àwọn tó ti kú lọ. Àmọ́, mi ò mọ̀dí tí Ọlọ́run onífẹ̀ẹ́ fi ‘ń gba’ àwọn òbí mọ́ àwọn ọmọ wọn lọ́wọ́. Ní abúlé Áfíríkà tí mo ti dàgbà, ó dìgbà tọ́mọ adìyẹ kan bá dàgbà dáadáa ká tó pa ìyá rẹ̀ jẹ. Tá a bá ti rí i pé màlúù kan ti lóyún, ńṣe la máa dúró títí dìgbà tí màlúù náà á fi bímọ, tí á sì já ọmọ rẹ̀ lẹ́nu ọmú, ká tó pa á. Nítorí náà, mi ò mọ̀dí tí Ọlọ́run onífẹ̀ẹ́ kò fi ní irú ojú àánú bẹ́ẹ̀ fọ́mọ èèyàn.”

Ọmọ ilẹ̀ Kánádà kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Aram ní irú iyèméjì yìí. Ó ní: “Ọmọ ọdún mẹ́tàlá ni mí nígbà tí bàbá mi ṣaláìsí. Gbajúmọ̀ àlùfáà kan ló sọ̀rọ̀ ìsìnkú náà. Nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀, ó sọ pé ńṣe ni Ọlọ́run fẹ́ kí bàbá mi kú kó lè sún mọ́ Ọlọ́run sí i lọ́run. Ó sọ pé ‘Ọlọ́run máa ń mú àwọn ẹni rere lọ sọ́run nítorí Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ àwọn olódodo.’ Mi ò mọ̀dí tó fi jẹ́ pé tara rẹ̀ nìkan ni Ọlọ́run mọ̀.”

Ní àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀, Abel àti Aram rí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, wọ́n kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́dọ̀ wọn, nígbẹ̀yìngbẹ́yín wọ́n rí ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè wọn. Wọ́n wá dẹni tó nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run, wọ́n sì wá ní ìgbàgbọ́ tó lágbára nínú rẹ̀. Níkẹyìn, wọ́n ya ara wọn sí mímọ́ fún Jèhófà, wọ́n sì di ìránṣẹ́ tó dúró ṣinṣin sí Ọlọ́run.

Ìmọ̀ Pípéye Ṣe Pàtàkì Ká Tó Lè Gba Ọlọ́run Gbọ́

Kí la lè rí kọ́ látinú àwọn ìrírí wọ̀nyí? Ohun tí wọ́n kọ́ wa ni pé ká tó lè gba Ọlọ́run gbọ́, ó ṣe pàtàkì ká ní ìmọ̀ pípéye látinú Bíbélì. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ fáwọn Kristẹni tó wà nílùú Fílípì ìgbàanì pé: “Èyí . . . ni ohun tí mo ń bá a lọ ní gbígbàdúrà, pé kí ìfẹ́ yín lè túbọ̀ máa pọ̀ gidigidi síwájú àti síwájú pẹ̀lú ìmọ̀ pípéye àti ìfòyemọ̀ kíkún.” (Fílípì 1:9) Pọ́ọ̀lù jẹ́ ká mọ̀ níbi yìí pé láìsí ìmọ̀ pípéye nípa Ọlọ́run àti òye ohun tí ìfẹ́ rẹ̀ jẹ́, a kò lè nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run àtàwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wa.

Èyí bọ́gbọ́n mu nítorí pé ká tó lè sọ pé a gbẹ́kẹ̀ lé ẹnì kan, a ní láti kọ́kọ́ mọ onítọ̀hún, bá a bá sì ṣe mọ ẹni náà dáadáa sí la ṣe máa gbẹ́kẹ̀ lé e tó. Bákan náà, ó ṣe pàtàkì kó o ní ìmọ̀ pípéye nípa Ọlọ́run kí ọkàn rẹ tó lè sún ọ láti gbà á gbọ́. Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Ìgbàgbọ́ ni ìfojúsọ́nà tí ó dáni lójú nípa àwọn ohun tí a ń retí, ìfihàn gbangba-gbàǹgbà àwọn ohun gidi bí a kò tilẹ̀ rí wọn.” (Hébérù 11:1) Tẹ́nì kan bá lóun gba Ọlọ́run gbọ́ àmọ́ tí kò ní ìmọ̀ pípéye látinú Bíbélì, ńṣe ló dà bí ìgbà táwọn ọmọdé bá fi iyanrìn kọ́lé sójú ọ̀gbàrá, tó jẹ́ pé tá a bá fẹsẹ̀ tẹ̀ ẹ́, kíá ló máa tú ká.

Tó o bá kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ láti rí ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè bí èyí tó rú Abel àti Aram lójú fúngbà pípẹ́, irú bíi, Kí nìdí téèyàn fi ń kú? Bíbélì ṣàlàyé pé, “ẹ̀ṣẹ̀ . . . tipasẹ̀ ènìyàn kan wọ ayé àti ikú nípasẹ̀ ẹ̀ṣẹ̀, ikú sì tipa báyìí tàn dé ọ̀dọ̀ gbogbo ènìyàn nítorí pé gbogbo wọn ti dẹ́ṣẹ̀.” (Róòmù 5:12) Ẹ̀ṣẹ̀ Ádámù ló mú káwọn èèyàn máa darúgbó kí wọ́n sì máa kú, kì í ṣe nítorí pé Ọlọ́run ń mú wọn lọ. (Jẹ́nẹ́sísì 2:16, 17; 3:6, 17-19) Láfikún sí i, Bíbélì jẹ́ ká mọ ìrètí tó ṣe é gbára lé tí Jèhófà Ọlọ́run fún wa. Jèhófà típasẹ̀ Jésù Kristi Ọmọ rẹ̀ pèsè ìrètí àjíǹde fún aráyé ẹlẹ́ṣẹ̀.—Jòhánù 5:28, 29; Ìṣe 24:15.

Láti lè mú ká lóye òtítọ́ nípa àjíǹde, àwọn àpẹẹrẹ mélòó kan wà nínú Bíbélì nípa àwọn ẹni tí Jésù jí dìde. (Lúùkù 7:11-17; 8:40-56; Jòhánù 11:17-45) Nígbà tó o bá ń ka ìtàn wọ̀nyí nínú Bíbélì, kíyè sí bí ayọ̀ àwọn ọ̀rẹ́ àti mọ̀lẹ́bí àwọn èèyàn tí Jésù jí dìde ṣe pọ̀ tó. Sì tún kíyè sí bí ọkàn wọn ṣe sún wọn láti yin Ọlọ́run lógo àti láti gba Jésù gbọ́.

Ìmọ̀ pípéye nípa Ọlọ́run àtàwọn ohun tó fẹ́ ṣe lè ní ipa kan náà lórí àwọn èèyàn lóde òní. Nígbà kan rí, àwọn ìbéèrè pàtàkì tí ọ̀pọ̀ èèyàn kò rí ìdáhùn tó tẹ́ wọn lọ́rùn sí, mú kí wọ́n má mọ ọ̀nà tó tọ́, kí wọn dẹni tí a di ẹrù pa, àní ó tiẹ̀ mú wọn kọsẹ̀ pàápàá. Àmọ́, nígbà tí wọ́n kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, wọ́n rí ìdáhùn sáwọn ìbéèrè náà, èyí sì yí ìgbésí ayé wọn padà pátápátá.

Ìfẹ́ fún Ọlọ́run Lohun Pàtàkì Tó Yẹ Kó Mú Wa Máa Sìn Ín

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìmọ̀ pípéye ṣe pàtàkì láti lè ní ìgbàgbọ́ nínú Ọlọ́run, ohun tá a nílò ju ìyẹn lọ ká tó lè dẹni tó ń ṣègbọràn sí Ọlọ́run ká sì máa sìn ín. Nígbà tẹ́nì kan béèrè òfin tó tóbi jù nínú òfin Ọlọ́run lọ́wọ́ Jésù, ó dáhùn pé: “Kí ìwọ sì nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run rẹ pẹ̀lú gbogbo ọkàn-àyà rẹ àti pẹ̀lú gbogbo ọkàn rẹ àti pẹ̀lú gbogbo èrò-inú rẹ àti pẹ̀lú gbogbo okun rẹ.” (Máàkù 12:30) Bí ẹnì kan bá nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run bí Jésù ṣe ní ká nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, ònítọ̀hún á ṣe tán láti máa ṣègbọràn sí Ọlọ́run àti láti máa sìn ín. Ṣé ìwọ ń ṣe bẹ́ẹ̀?

Ohun tí Rachel tó ti sìn gẹ́gẹ́ bí míṣọ́nnárì ní Kòríà fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún sọ pé ó jẹ́ ìdí tóun fi gba Ọlọ́run gbọ́ rèé, ó ní: “Mo máa ń ronú nípa ẹ̀mí ọ̀làwọ́ tí Jèhófà ní sí àwọn nǹkan tó dá, ẹ̀mí ìdáríjini tó ní sáwọn èèyàn rẹ̀ àti jíjẹ́ tó ń jẹ́ ká mọ ohun tó fẹ́ ká ṣe láti lè ṣe ara wa láǹfààní. Gbogbo nǹkan wọ̀nyí ló ń mú kí ìfẹ́ tí mo ní sí Ọlọ́run túbọ̀ jinlẹ̀ sí i. Ìfẹ́ yìí sì ń mú kí n fẹ́ láti sìn ín.”

Ọdún méjìdínláàádọ́ta ni Martha, opó kan tó ń gbé lórílẹ̀-èdè Jámánì ti fi sin Jèhófà. Ó sọ pé: “Kí nìdí tí mo fi ń sin Jèhófà? Ìdí ni pé mo nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. Alaalẹ́ ni mo máa ń gbàdúrà sí Jèhófà, tí mo máa ń dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀ gan-an fún gbogbo ẹ̀bùn rẹ̀, àgàgà ẹ̀bùn ẹbọ ìràpadà.”

Bẹ́ẹ̀ ni, ìfẹ́ tá a ní sí Ọlọ́run ló ń mú ká fẹ́ láti máa sìn ín látọkànwá. Àmọ́, báwo la ṣe lè ní irú ìfẹ́ yìí? Ohun tó lágbára jù lọ tó lè mú ká nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run ni pé ká mọyì ìfẹ́ tó ní sí wa. Ẹ wo ìránnilétí tó ń múnú ẹni dún yìí látinú Bíbélì, tó sọ pé: “Ẹni tí kò bá nífẹ̀ẹ́ kò tíì mọ Ọlọ́run, nítorí Ọlọ́run jẹ́ ìfẹ́. Nípa èyí ni a fi ìfẹ́ Ọlọ́run hàn kedere nínú ọ̀ràn tiwa, nítorí Ọlọ́run rán Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo jáde sínú ayé kí a lè jèrè ìyè nípasẹ̀ rẹ̀. Ìfẹ́ náà jẹ́ lọ́nà yìí, kì í ṣe pé àwa ti nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run, bí kò ṣe pé òun nífẹ̀ẹ́ wa, ó sì rán Ọmọ rẹ̀ jáde gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ìpẹ̀tù fún àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa.”—1 Jòhánù 4:8-10.

Ǹjẹ́ o mọ bí ìfẹ́ yìí ṣe jinlẹ̀ tó? Fojú inú wò ó pé odò ńlá kan ń gbé ọ lọ, ọkùnrin kan sì wá fẹ̀mí ara rẹ̀ wewu láti gbé ọ jáde. Ṣé wàá gbàgbé ọkùnrin yìí, àbí wàá máa dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀? Ǹjẹ́ o ò ní ṣetán láti ṣe gbogbo ohun tó o bá lè ṣe fún un? Ìfẹ́ tí Ọlọ́run ní sí wa tí ó fi fi Jésù Kristi, Ọmọ rẹ̀ ṣe ẹbọ ìràpadà ju ìyẹn lọ fíìfíì. (Jòhánù 3:16; Róòmù 8:38, 39) Bí ìfẹ́ tí Ọlọ́run ní sí ọ bá wọ̀ ọ́ lọ́kàn, ọkàn rẹ yóò sún ọ láti nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ àti láti sìn ín tinútinú.

Ọ̀pọ̀ Ìbùkún Nísinsìnyí àti Lọ́jọ́ Iwájú

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìfẹ́ tá a ní sí Ọlọ́run ló yẹ kó jẹ́ olórí ìdí tá a fi ń ṣe ìfẹ́ rẹ̀, ó dùn mọ́ni láti mọ̀ pé Ọlọ́run máa ń san èrè fáwọn tó ń sìn ín. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Láìsí ìgbàgbọ́ kò ṣeé ṣe láti wù ú dáadáa, nítorí ẹni tí ó bá ń tọ Ọlọ́run wá gbọ́dọ̀ gbà gbọ́ pé ó ń bẹ àti pé òun ni olùsẹ̀san fún àwọn tí ń fi taratara wá a.”—Hébérù 11:6.

Ọlọ́run máa ń bùkún àwọn tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ tí wọ́n sì ń ṣègbọràn sí i. Ọ̀pọ̀ ni ara wọn máa ń le dáadáa nítorí pé wọ́n ń tẹ̀ lé àwọn ìlànà Bíbélì. (Òwe 23:20, 21; 2 Kọ́ríńtì 7:1) Ní ti àwọn tí wọ́n ń fi ìlànà Bíbélì sílò nípa jíjẹ́ aláìlábòsí àti òṣìṣẹ́kára, àwọn tó gbà wọ́n síṣẹ́ máa ń fọkàn tán wọn, nítorí náà ohun tí wọ́n á fi gbọ́ bùkátà ara wọn kì í wọ́n wọn. (Kólósè 3:23) Nítorí pé Jèhófà ni àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run gbẹ́kẹ̀ lé, ọkàn wọn máa ń balẹ̀ àní bí wọ́n tiẹ̀ wà nínú ipò tó le koko pàápàá. (Òwe 28:25; Fílípì 4:6, 7) Lékè gbogbo rẹ̀, wọ́n ń fi ìdánilójú wọ̀nà fún ìyè àìnípẹ̀kun nínú Párádísè ilẹ̀ ayé tó ń bọ̀.—Sáàmù 37:11, 29.

Kí lohun táwọn tó ń rí irú ìbùkún wọ̀nyí gbà lọ́dọ̀ Jèhófà rò nípa Jèhófà? Jacqueline, Kristẹni kan ní Kánádà fi hàn pé òun mọrírì àwọn ohun tí Ọlọ́run ti ṣe, ó ní: “Gbogbo ìgbà ló ń fún wa ní irú àwọn ẹ̀bùn ńláǹlà bí èyí, ó sì tún fún wa nírètí tó dájú, ìyẹn ìyè àìnípẹ̀kun.” Abel, ẹni tó sọ̀rọ̀ níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí sọ bí ọ̀ràn náà ṣe rí lára òun, ó ní: “Ọ̀rọ̀ pé àwọn èèyàn yóò gbé títí láé nínú Párádísè lórí ilẹ̀ ayé jẹ́ nǹkan tuntun sí mi, mo sì ń wọ̀nà fún un. Àmọ́ ṣá o, ká tiẹ̀ sọ pé Ọlọ́run ò ṣèlérí Párádísè, màá ṣì máa sin Ọlọ́run láti fi hàn pé mo nífẹ̀ẹ́ rẹ̀.”

Ìwọ Náà Lè Ní Ìgbàgbọ́ Tòótọ́

Bíbélì sọ pé: “Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun ń fi òdodo ṣe ìdájọ́; ó ń ṣàyẹ̀wò kíndìnrín àti ọkàn-àyà.” (Jeremáyà 11:20) Bẹ́ẹ̀ ni, Jèhófà ń yẹ ohun tó fara pamọ́ sínú ọkàn wa lọ́hùn ún wò. Ó yẹ kí olúkúlùkù wa yẹ ara rẹ̀ wò láti lè mọ ohun tó mú kóun gba Ọlọ́run gbọ́. Ó lè jẹ́ pé ìgbàgbọ́ tí kò tọ̀nà àti èrò òdì ló mú ká máa hùwà tí kò tọ́ tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀. Ṣùgbọ́n, ìmọ̀ pípéye nípa Bíbélì yóò mú ká ní àjọṣe tó dára pẹ̀lú Jèhófà Ọlọ́run, Ẹlẹ́dàá wa.—1 Tímótì 2:3, 4.

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń tipa ẹ̀kọ́ Bíbélì tí wọ́n ń kọ́ àwọn èèyàn lọ́fẹ̀ẹ́ ràn wọ́n lọ́wọ́ láti ní ìmọ̀ pípéye nípa Ọlọ́run. (Mátíù 28:20) Ọ̀pọ̀ èèyàn tó tẹ́wọ́ gba ìrànlọ́wọ́ yìí ti dẹni tó nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run, wọ́n sì ti wá ní ojúlówó ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀. Ẹ̀kọ́ tí wọ́n ń kọ́ nínú Bíbélì ti mú kí wọ́n ní “ọgbọ́n tí ó gbéṣẹ́ àti agbára láti ronú,” èyí sì ti ràn wọ́n lọ́wọ́ láti máa “rìn nínú ààbò” ní àwọn àkókò tó léwu yìí. (Òwe 3:21-23) Ju gbogbo rẹ̀ lọ, wọ́n ní ìrètí ọjọ́ iwájú ‘tó dájú, tó sì fìdí múlẹ̀ gbọin-in.’ (Hébérù 6:19) Ìwọ náà lè ní ìgbàgbọ́ tòótọ́ kó o sì rí àwọn ìbùkún wọ̀nyí gbà.

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 6]

Àwọn Ìbéèrè Apinnilẹ́mìí Tó Ń Fẹ́ Ìdáhùn

“Nígbà tí mo ń gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ ní ọsibítù gẹ́gẹ́ bí àkẹ́kọ̀ọ́ ìṣègùn, mo rí àwọn èèyàn rere tí wọ́n ń jẹ̀rora nítorí àìsàn àti àjálù. Tó bá jẹ́ pé lóòótọ́ ni Ọlọ́run wà, kí nìdí táwọn nǹkan wọ̀nyí fi ń ṣẹlẹ̀? Ṣé ọ̀nà àtirí ìbàlẹ̀ ọkàn nìkan ni ìsìn wulẹ̀ wà fún ni?”—Onísìn Presbyterian tẹ́lẹ̀ rí kan ní ilẹ̀ Kòríà.

“Mo sábà máa ń ṣe kàyéfì bóyá ọ̀run àpáàdì ni bàbá mi tó jẹ́ ọlọ́tí lọ tàbí ọ̀run rere. Ẹ̀rù àwọn òkú àti ọ̀run àpáàdì máa ń bà mí. Mi ò mọ̀dí tí Ọlọ́run onífẹ̀ẹ́ á fi ní kẹ́nì kan lọ máa jìyà ayérayé ní ọ̀run àpáàdì.”—Onísìn Kátólíìkì tẹ́lẹ̀ rí kan ní orílẹ̀-èdè Brazil.

“Kí ló ń bọ̀ wá ṣẹlẹ̀ sí ilẹ̀ ayé yìí àti aráyé lọ́jọ́ iwájú? Ọ̀nà wo ní aráyé lè gbà wà láàyè títí láé? Báwo lọwọ́ aráyé yóò ṣe tẹ àlàáfíà tòótọ́?”—Onísìn Kátólíìkì tẹ́lẹ̀ rí kan ní orílẹ̀-èdè Jámánì.

“Ẹ̀kọ́ àtúnwáyé ò tiẹ̀ bọ́gbọ́n mu lójú tèmi. Àwọn ẹranko kì í jọ́sìn, nítorí náà ká ní o tún ayé wá gẹ́gẹ́ bí ẹrankó kí o lè jìyà àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ, báwo ni wàá ṣe ṣàtúnṣe àwọn ohun tó o ti ṣe sẹ́yìn kí o wá tẹ̀ síwájú láti ibẹ̀ lọ?”—Onísìn Híńdù tẹ́lẹ̀ rí kan ní Gúúsù Áfíríkà.

“Ìsìn Confucius ni wọ́n bí mi sí, mo sì máa ń bá wọn ṣe ayẹyẹ tá a fi ń ṣàdúrà pé kí Ọlọ́run fọ̀run kẹ́ àwọn baba ńlá wa. Bá a bá jọ ń tẹ́ tábílì ìrúbọ tá a sì ń forí balẹ̀, mo máa ń ṣe kàyéfì pé ṣé lóòótọ́ làwọn baba ńlá máa ń wá jẹ oúnjẹ tá a gbé kalẹ̀ fún wọn, tí wọ́n sì ń rí wa bá a ṣe ń forí balẹ̀ fún wọn.”—Onísìn Confucius tẹ́lẹ̀ rí kan ní ilẹ̀ Kòríà.

Gbogbo àwọn èèyàn yìí ló rí ìdáhùn sí ìbéèrè wọn nígbà táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.