Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwọn Wo Ló Wà Nínú Ìdílé Tá A Ti Bí Jésù?

Àwọn Wo Ló Wà Nínú Ìdílé Tá A Ti Bí Jésù?

Àwọn Wo Ló Wà Nínú Ìdílé Tá A Ti Bí Jésù?

NÍ IBI púpọ̀ lágbàáyé, tó bá ti di ìgbà December, a sábà máa ń rí àwọn àwòrán tó fi ìgbà tí Jésù wà lọ́mọ ọwọ́ hàn, tí Màríà ìyá rẹ̀ àti Jósẹ́fù alágbàtọ́ rẹ̀ ń tọ́jú rẹ̀. Àwọn àwòrán yìí tiẹ̀ lè fa àwọn tí kì í ṣe Kristẹni pàápàá mọ́ra. Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé Jésù lẹni tí wọ́n ń torí rẹ̀ ya àwòrán wọ̀nyí, kí ni Ìwé Mímọ́ jẹ́ ká mọ̀ nípa ìdílé tá a ti bí Jésù?

Ilé rere ni Jésù ti wá. Wúńdíá kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Màríà ló bí i, bí Jésù sì ṣe di ara ìdílé kan lórí ilẹ̀ ayé nìyẹn. Gẹ́gẹ́ bí Bíbélì ṣe sọ, Ọlọ́run tipasẹ̀ ẹ̀mí mímọ́ fi ìwàláàyè rẹ̀ lọ́run sínú ilé ọlẹ̀ Màríà. (Lúùkù 1:30-35) Ṣáájú kí Màríà tó lóyún Jésù lọ́nà ìyanu, òun àti ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Jósẹ́fù ti ń fẹ́ra wọn sọ́nà, Jósẹ́fù sì wá tipa báyìí di alágbàtọ́ Jésù.

Lẹ́yìn tí Màríà bí Jésù, ó wá bí àwọn ọmọ mìíràn lọ́kùnrin lóbìnrin fún Jósẹ́fù. Ìbéèrè tí àwọn ará Násárétì bi Jésù lẹ́yìn náà fi èyí hàn, wọ́n ní: “Èyí ha kọ́ ni ọmọkùnrin káfíńtà náà? Kì í ha ṣe ìyá rẹ̀ ni a ń pè ní Màríà, àti àwọn arákùnrin rẹ̀ Jákọ́bù àti Jósẹ́fù àti Símónì àti Júdásì? Àti àwọn arábìnrin rẹ̀, gbogbo wọn kò ha wà pẹ̀lú wa?” (Mátíù 1:25; 13:55, 56; Máàkù 6:3) Látinú ìbéèrè yìí, a lè wá sọ nígbà náà pé bàbá rẹ̀ àti ìyá rẹ̀, àbúrò rẹ̀ ọkùnrin mẹ́rin àti ó kéré tán àbúrò rẹ̀ obìnrin méjì ló wà nínú ìdílé tá a ti bí Jésù.

Àmọ́ lónìí, àwọn kan ò gbà gbọ́ pé Jósẹ́fù òun Màríà ló bí àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin Jésù, ìyẹn àwọn àbúrò rẹ̀. Kí nìdí tí wọ́n ò fi gbà gbọ́? Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ náà New Catholic Encyclopedia sọ pé: “Láti ìpilẹ̀ṣẹ̀ ni Ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì ti fi ń kọ́ni pé wúńdíá ni Màríà títí dọjọ́ ikú rẹ̀. Nítorí èyí, ó dájú pé Màríà kò tún bímọ mìíràn mọ́ lẹ́yìn Jésù.” Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ yìí kan náà tún sọ pé ọ̀rọ̀ náà “arákùnrin” àti “arábìnrin” tí wọ́n lò nínú Ìwé Mímọ́ yìí lè tọ́ka sí “ẹni kan tàbí àwọn kan tí wọ́n jọ wà nínú ẹ̀sìn kan náà tàbí tí wọ́n jọ ní àjọṣe kan náà” tàbí ìbátan ẹni, bóyá ọmọ ẹ̀gbọ́n tàbí ọmọ àbúrò bàbá òun ìyá ẹni.

Ṣé bí ọ̀rọ̀ náà ṣe rí nìyẹn? Àwọn ẹlẹ́kọ̀ọ́ ìsìn Kátólíìkì kan kò fara mọ́ ẹ̀kọ́ tó ti wà tipẹ́ yìí pàápàá. Ẹ̀kọ́ tí wọ́n fara mọ́ ni èyí tó sọ pé Jésù ní àwọn àbúrò ọkùnrin àtàwọn àbúrò obìnrin tó jẹ́ ọmọ ìyá rẹ̀. John P. Meier tó jẹ́ ààrẹ àjọ Catholic Bible Association of America tẹ́lẹ̀ rí kọ̀wé pé: “Tí a kò bá lo [èdè Gíríìkì náà tá a túmọ̀ sí “arákùnrin”] nínú Májẹ̀mú Tuntun lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ tàbí lọ́nà àfiwé láti fi sọ bí ẹnì kan ṣe bá àwọn kan tan, yálà nípa tara tàbí lábẹ́ òfin, kìkì ohun tó máa ń túmọ̀ sí ni ọmọ bàbá àti ìyá kan náà tàbí àwọn tó jọ jẹ́ ọmọ ìyá tàbí ọmọ bàbá.” a Bẹ́ẹ̀ ni o, Ìwé Mímọ́ fi hàn pé Jésù ní àwọn àbúrò ọkùnrin àtàwọn àbúrò obìnrin tí Màríà bí fún Jósẹ́fù.

Ìwé Ìhìn Rere mẹ́nu kan àwọn ìbátan Jésù mìíràn, àmọ́ ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa òbí àtàwọn àbúrò Jésù, ká sì wá wo ẹ̀kọ́ tá a lè kọ́ lára wọn.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a “Ojú Tí Onírúurú Ẹ̀sìn Fi Ń Wo Àwọn Arákùnrin àti Arábìnrin Jésù,” látọwọ́ J. P. Meier, The Catholic Biblical Quarterly, January 1992, ojú ìwé 21.