Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

A Rọ Àwọn Tó Kẹ́kọ̀ọ́ Yege Ní Gílíádì Láti Máa Sọ̀rọ̀ “Àwọn Ohun Ọlá Ńlá”

A Rọ Àwọn Tó Kẹ́kọ̀ọ́ Yege Ní Gílíádì Láti Máa Sọ̀rọ̀ “Àwọn Ohun Ọlá Ńlá”

A Rọ Àwọn Tó Kẹ́kọ̀ọ́ Yege Ní Gílíádì Láti Máa Sọ̀rọ̀ “Àwọn Ohun Ọlá Ńlá”

Ọ̀PỌ̀ èèyàn tí iye wọn jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́fà, ó lé ẹgbàata àti márùnlélọ́gbọ̀n [6,635] tó wá láti orílẹ̀-èdè méjìléláàádọ́ta ló pésẹ̀ síbi ayẹyẹ ìkẹ́kọ̀ọ́yege kíláàsì karùndínlọ́gọ́fà [115] ti ilé ẹ̀kọ́ Watchtower Bible School of Gilead ní September 13, 2003.

Wọ́n gbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ inú Bíbélì ta a fi gba àwọn akẹ́kọ̀ọ́ méjìdínláàádọ́ta náà níyànjú pé kí wọ́n máa lọ sọ “àwọn ohun ọlá ńlá Ọlọ́run” fún àwọn èèyàn ní ilẹ̀ mẹ́tàdínlógún. (Ìṣe 2:11) Ibẹ̀ ni àwọn akẹ́kọ̀ọ́yege náà yóò ti máa bá ìṣẹ́ míṣọ́nnárì wọn lọ.

Nínú ọ̀rọ̀ tí Stephen Lett, tó jẹ́ ọ̀kan lára Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso ti Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, tó tún jẹ́ alága ayẹyẹ ìkẹ́kọ̀ọ́yege náà kọ́kọ́ sọ, ó rán àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà létí pé: “Nígbà tí ẹ bá dé ibi iṣẹ́ tí wọ́n yàn fún yín, ibikíbi tí ẹ bá lọ tàbí ipòkípò tí ẹ bá bá ara yín, àwọn tó wà lẹ́yìn yín pọ̀ ju àwọn tó lòdì sí yin lọ.” Arákùnrin Lett fi ọ̀rọ̀ tó wà nínú Àwọn Ọba kejì orí kẹfà rán àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà létí pé kí wọ́n gbára lé Jèhófà Ọlọ́run àti ẹgbàágbèje àwọn áńgẹ́lì bí wọ́n ṣe ń sọ “àwọn ohun ọlá ńlá Ọlọ́run” di mímọ̀. (2 Àwọn Ọba 6:15, 16) Àwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní dojú kọ àtakò àti ìdágunlá lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù àti iṣẹ́ ìkọ́ni wọn, àwọn Kristẹni tó jẹ́ míṣọ́nnárì lónìí náà ń dojú kọ ohun kan náà. Àmọ́, wọ́n lè gbára lé ìtìlẹyìn tó ń wá látọ̀dọ̀ Ọlọ́run àti èyí tó ń wá látọ̀dọ̀ ètò àjọ Jèhófà lórí ilẹ̀ ayé.—Sáàmù 34:7; Mátíù 24:45.

Ẹ Máa Sọ̀rọ̀ “Àwọn Ohun Ọlá Ńlá Ọlọ́run”

Kété lẹ́yìn tí alága sọ̀rọ̀ ìkínikáàbọ̀ tán ni Harold Corkern, tó jẹ́ ọ̀kan lára Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka ti orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà sọ̀rọ̀ lórí ẹṣin ọ̀rọ̀ náà tó sọ pé: “Lílé Ohun Tí Ọwọ́ Lè Tẹ̀, Ló Ń Mú Ayọ̀ àti Àṣeyọrí Wá Nínú Iṣẹ́ Ìsìn.” Arákùnrin Corkern fi hàn pé bí ọwọ́ wa kò bá tẹ àwọn ohun tá à ń fẹ́, ó lè yọrí sí ìjákulẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìwé Òwe 13:12 ṣe sọ. Ṣùgbọ́n ìjákulẹ̀ ló máa ń sábà jẹ́ bí ọwọ́ wà kò bá tẹ àwọn ohun ńlá tá à ń retí. Ohun táwọn tó ti kẹ́kọ̀ọ́ yege náà ń retí lọ́dọ̀ ara wọn àti lọ́dọ̀ àwọn ẹlòmíràn gbọ́dọ̀ wà ní ìwọ̀ntúnwọ̀nsì kó sì mọ́gbọ́n dání. Bí wọ́n ṣe ń làkàkà láti ràn àwọn mìíràn lọ́wọ́ láti mọ̀ nípa “àwọn ohun ọlá ńlá Ọlọ́run,” wọ́n gbọ́dọ̀ mọ̀ pé ó ṣeé ṣe kí àwọn ṣàṣìṣe, ṣùgbọ́n kò yẹ́ kí èyí mú wọn banú jẹ́ kọjá bó ṣe yẹ. Arákùnrin Corkern rọ àwọn míṣọ́nnárì tuntun náà láti gbára lé Jèhófà, ẹni tó jẹ “olùsẹ̀san fún àwọn tí ń fi taratara wá a.”—Hébérù 11:6.

Ẹni tí ọ̀rọ̀ kàn lórí ìtòlẹ́sẹẹsẹ ni Daniel Sydlik, tó jẹ́ ọ̀kàn lára Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso, ó sọ̀rọ̀ lórí kókó náà tó sọ pé: “Kí Ni Ìrètí Kristẹni Túmọ̀ Sí?” Ó sọ pé: “Ànímọ́ dáradára tó yẹ kí Kristẹni kan ní ni ìrètí jẹ́. Ó jẹ́ ìlànà fún ohun tó tọ́, ó sì ń mú kí àjọṣe tó wà láàárín Ọlọ́run àti ẹnì kan dára sí i. Kò ṣeé ṣe fún ẹni tí kì í ṣe Kristẹni láti ní ìrètí bíi tàwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà.” Arákùnrin Sydlik ṣàlàyé nípa oríṣiríṣi ìrètí tí Kristẹni ní tó lè ran ẹnì kan lọ́wọ́ láti ní ìrètí pé ọ̀la á dárá nígbà tá a bá dojú kọ àwọn ìṣòro nínú ìgbésí ayé. “Bá a bá nírètí, yóò jẹ́ ká máa fi ààpọ́n àti ẹ̀mí ìjagunmólú kojú àwọn ìṣòrò ojoojúmọ́.” Ìrètí tí Kristẹni kan ní ló ń ràn án lọ́wọ́ láti máa wo Jèhófà gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run tí kì í ṣe nǹkan láìnídìí, òun ló sì ń jẹ́ kó máa fi ìdùnnú sìn ín.—Róòmù 12:12.

Wallace Liverance tó ń fi orúkọ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ sílẹ̀ ní Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì rọ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ láti “Máa Rìn Nípa Ẹ̀mí.” (Gálátíà 5:16) Ó ṣàlàyé nípa bí Bárúkù tó jẹ́ akọ̀wé Jeremáyà ṣe dẹni tó fẹ́rẹ̀ẹ́ sú lọ kúrò nínú rírìn nípa tẹ̀mí. Nígbà kan, àárẹ̀ tẹ̀mí mú Bárúkù, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í lé àwọn ohun ńlá fún ara rẹ̀. (Jeremáyà 45:3, 5) Arákùnrin Liverance wá sọ pé àwọn kan kò tẹ̀lé Jésù mọ́, wọ́n sì ti tipa bẹ́ẹ̀ kọ òtítọ́ tẹ̀mí sílẹ̀, bẹ́ẹ̀ sì rèé òtítọ́ tẹ̀mí yẹn la nílò ká tó lè rí ìgbàlà. Ìyẹn jẹ́ nítorí pé wọn kò lóye ohun tí Jésù ń kọ́ wọn nígbà yẹn, àti pé wọ́n rí ìjákulẹ̀ nítorí pé wọn kò rí àwọn nǹkan tara tí wọ́n ń fẹ́ lákòókò yẹn. (Jòhánù 6:26, 27, 51, 66) Kí làwọn míṣọ́nnárì tó jẹ́ pé iṣẹ́ wọn ni láti máa darí àwọn èèyàn sọ́dọ̀ Ẹlẹ́dàá àtàwọn ohun tó fẹ́ ṣe lè rí kọ́ nínú àwọn ìtàn yìí? A gba àwọn akẹ́kọ̀ọ́ níyànjú láti yàgò fún lílé ipò kiri, wíwá iyì lọ́dọ̀ èèyàn tàbí lílo iṣẹ́ tí Ọlọ́run yàn fún wọn láti máa wá èrè ti ara wọn.

Mark Noumair tó jẹ́ olùkọ́ nílé ẹ̀kọ́ Gílíádì béèrè pé: “Ṣé Ẹni Tó Ń Fúnni Lo Fẹ́ Jẹ́ Ni Àbí Ẹni Tó Ń Gba Tọwọ́ Ẹni?” Ó gbé ọ̀rọ̀ rẹ̀ karí ìwé Àwọn Onídàájọ́ 5:2, níbi tí à ti gbóríyìn fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nítorí bí wọ́n ṣe yọ̀ǹda ara wọn tọkàntọkàn láti sìn nínú ẹ̀gbẹ́ ọmọ ogun Bárákì. A gbóríyìn fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Gílíádì nítorí ẹ̀mí tí wọ́n fi hàn lórí bí wọ́n ṣe jẹ́ ìpè tí Bárákì Ńlá náà, Jésù Kristi pè wọ́n láti túbọ̀ kópa nínú ogun tẹ̀mí. Ó yẹ kí àwọn ọmọ ogun Kristi fẹ́ láti rí ojú rere ẹni tó pè wọ́n. Arákùnrin Noumair rán àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà létí pé: “Gbàrà tá a bá ti bẹ̀rẹ̀ sí ronú lórí títẹ́ ara wa lọ́rùn ni a ti ṣíwọ́ bíbá ọ̀tà náà jà. . . . Ìṣẹ́ ìsìn míṣọ́nnárì kì í sì ṣe ọ̀rọ̀ nípa ara rẹ. Ọ̀rọ̀ nípa Jèhófà, ipò ọba aláṣẹ rẹ̀, àti bí ìfẹ́ rẹ̀ yóò ṣe ṣẹ ni. A kò sìn gẹ́gẹ́ bíi míṣọ́nnárì nítorí pé a fẹ́ kí Jèhófà múnú wà dùn, ṣùgbọ́n à ń sìn ín nítorí pé a nífẹ̀ẹ́ rẹ̀.”—2 Tímótì 2:4.

Bowen tí òun náà jẹ́ olùkọ́ ní ilé ẹ̀kọ́ Gílíádì ló bójú tó apá tó kàn tó sọ pé: “Sọ Wọ́n Di Mímọ́ Nípasẹ̀ Òtítọ́.” (Jòhánù 17:17) Ó sọ pé àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tó wà ní kíláàsì karùndínlọ́gọ́fà jẹ́ òjíṣẹ́ tí a ti sọ dí mímọ́ fún Ọlọ́run. Nígbà tí wọ́n wà nílé ẹ̀kọ́, wọ́n kópa nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ pápá, wọ́n ń wá àwọn olóòótọ́ ọ̀kan tó nífẹ̀ẹ́ òtítọ́. Gẹ́gẹ́ bíi Jésù àtàwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ìjímìjí ti ṣe, àwọn akẹ́kọ̀ọ́ wọ̀nyí náà kò sọ̀rọ̀ látinú “agbára ìsúnniṣe ti ara” wọn. (Jòhánù 12:49, 50) Wọ́n ń fi ìtara sọ ọ̀rọ̀ tí ó ní ìmísí, tó ń gbà ẹ̀mí là, tó sì tún jẹ́ ọ̀rọ̀ òtítọ́ náà. Àṣefihàn àwọn ìrírí táwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà ní àtèyí tí wọ́n fẹnu sọ fi agbára tí Bíbélì ní lórí àwọn tí wọ́n bá sọ̀rọ̀ hàn.

Ìmọ̀ràn Àti Ìrírí Máa Ń Gbéni Ró

Anthony Pérez àti Anthony Griffin tí wọ́n ń sìn ní Ẹ̀ka Iṣẹ́ Ìsìn tó wà ní ẹ̀ka ti orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà fọ̀rọ̀ wá ọ̀rọ̀ wò lẹ́nu àwọn mẹ́ńbà Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka tó wá láti àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn kárí ayé. Àwọn ọkùnrin wọ̀nyí ṣàlàyé àwọn ìṣòro táwọn míṣọ́nnárì tuntun máa ń kojú, wọ́n sì fún wọn ní àwọn ìmọ̀ràn tó máa wúlò látinú ìrírí ti ara wọn. Díẹ̀ lára àwọn ìṣòro ọ̀hún ni àṣà ìbílẹ̀ tó yàtọ̀, àwọn ibi tí ooru tí máa ń mú jálẹ̀ ọdún, oríṣiríṣi ìsìn àti ọ̀rọ̀ òṣèlú tó yàtọ̀ sí èyí táwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà ti mọ̀ tẹ́lẹ̀. Kí ló lè ran àwọn míṣọ́nnárì tuntun wọ̀nyí lọ́wọ́ láti mú ara wọ́n bá àyíká tuntun tí wọ́n wà mu? Ìfẹ́ fún Jèhófà, ìfẹ́ fún àwọn èèyàn, ṣíṣàì bojú wẹ̀yìn àti ríronú jinlẹ̀ kí wọ́n to ṣe ohunkóhun ni yóò ṣèrànwọ́. Ọ̀kan lára Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka sọ pé: “Àwọn èèyàn tó wà ní ibi tí wọ́n yàn wá sí ti ń gbé ibẹ̀ fún àìmọye ọdún ká tó débẹ̀. Ó dájú pé àwa náà lè gbé ibẹ̀, kí ibẹ̀ sì mọ́ wa lára. Àpẹẹrẹ àwọn èèyàn yẹn la máa ń wò nígbàkigbà tá a bá ti ní ìṣòro èyíkéyìí. Bí ẹ bá ń gbàdúrà déédéé, tí ẹ sì gbára lé ẹ̀mí Jèhófà, ẹ óò rí pé òtítọ́ ni ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ pé, ‘Mo wà pẹ̀lú yín.’”—Mátíù 28:20.

Samuel Herd tó jẹ́ ọ̀kan lára Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso wá sọ ọ̀rọ̀ kan tó fakíki nínú ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà, ẹṣin ọ̀rọ̀ rẹ̀ ni, “Máa Báa Lọ Láti Sọ̀rọ̀ Nípa Àwọn Ohun Ọlá Ńlá Ọlọ́run.” Títú tí a tú ẹ̀mí mímọ́ jáde ní ọjọ́ Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Tiwa ló fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù lágbára láti sọ̀rọ̀ nípa “àwọn ohun ọlá ńlá Ọlọ́run.” Kí ló lè ran àwọn míṣọ́nnárì tuntun ti òde òní wọ̀nyí lọ́wọ́ láti máa fi irú ìtara kan náà sọ̀rọ̀ nípa Ìjọba Ọlọ́run? Ẹ̀mí mímọ́ kan náà yìí ni. Arákùnrin Herd fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́yege náà nímọ̀ràn pé kí wọ́n jẹ́ “kí iná ẹ̀mí máa jó” nínú wọn, kí inú wọn máa dùn sí iṣẹ́ tí a yàn fún wọn, kí wọ́n má ṣe gbàgbé ìdálẹ́kọ̀ọ́ tí a ti fún wọn yìí láé. (Róòmù 12:11) Arákùnrin Herd sọ pé “Bíbélì ni ohun ọlá ńlá Ọlọ́run. Ẹ kò sí gbọ́dọ̀ fojú kéré bó ṣe wúlò tó. Ọ̀rọ̀ inú rẹ̀ yè. Ó sì máa ń sojú abẹ níkòó. Ẹ máa lò ó láti mú nǹkan tọ́ nínú ìgbésí ayé yín. Ẹ jẹ́ kó yí ọ̀nà tí ẹ gbà ń ronú padà. Ẹ máa darí agbára ìrònú yín nípa kíkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Mímọ́, kíkà á, àti nípa ṣíṣe àṣàrò lórí rẹ̀ . . . Ẹ jẹ́ kó wà lórí ẹ̀mí yín, kẹ́ ẹ sì pinnu pé ẹ ó máa lo ìdálẹ́kọ̀ọ́ tá a fún yin ní ilé ẹ̀kọ́ Gílíádì láti máa sọ̀rọ̀ nípa ‘àwọn ohun ọlá ńlá Ọlọ́run.’”

Lẹ́yìn tí wọ́n ka ìwé ìkíni tí wọ́n rí gbà láti orígun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ayé tán, tí wọ́n sì fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ní ìwé ẹ̀rí dípúlọ́mà wọn, akẹ́kọ̀ọ́ kan wá ka lẹ́tà ìdúpẹ́ tí kíláàsì náà kọ láti fi hàn pé àwọn mọrírì ìdálẹ́kọ̀ọ́ tí wọ́n rí gbà. Arákùnrin Lett wá mú ayẹyẹ aláyọ̀ náà wá sópin nípa títọ́ka sí 2 Kíróníkà 32:7 àti Diutarónómì 20:1, 4. Ó so ọ̀rọ̀ àsọparí rẹ̀ mọ́ ọ̀rọ̀ tó kọ́kọ́ sọ, ó ní: “Ẹ̀yin akẹ́kọ̀ọ́yege ọ̀wọ́n, ẹ máa rántí pé Jèhófà ń báa yin lọ bí ẹ ṣe ń lọ, àní bí ẹ ṣe ń yan lọ sójú ogun tẹ̀mí ní ibi iṣẹ́ tí a yàn fún. Ẹ má ṣe gbàgbé láé pé àwọn tó wà lẹ́yìn yín pọ̀ ju àwọn tó lódì sí yín lọ.”

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 25]

ÌSỌFÚNNI ONÍṢIRÒ NÍPA KÍLÁÀSÌ

Iye orílẹ̀-èdè tá a ṣojú fún: 7

Iye orílẹ̀-èdè tá a yàn wọ́n sí: 17

Iye àwọn akẹ́kọ̀ọ́: 48

Ìpíndọ́gba ọjọ́ orí: 33.7

Ìpíndọ́gba ọdún tí wọ́n ti lò nínú òtítọ́: 17.8

Ìpíndọ́gba ọdún tí wọ́n ti lò nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún: 13.5

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]

Kíláàsì Karùndínlọ́gọ́fà Tó Kẹ́kọ̀ọ́ Yege Nílé Ẹ̀kọ́ Watchtower Bible School of Gilead

Nínú ìlà àwọn orúkọ tí ń bẹ nísàlẹ̀ yìí, nọ́ńbà kọ̀ọ̀kan jẹ́ láti iwájú lọ sẹ́yìn, a sì to orúkọ láti ọwọ́ òsì sí ọwọ́ ọ̀tún lórí ìlà kọ̀ọ̀kan.

(1) Brown, T.; Goller, C.; Hoffman, A.; Bruzzese, J.; Trahan, S. (2) Smart, N.; Cashman, F.; Garcia, K.; Lojan, M.; Seyfert, S.; Gray, K. (3) Beckett, M.; Nichols, S.; Smith, K.; Gugliara, A.; Rappenecker, A. (4) Gray, S.; Vacek, K.; Fleming, M.; Bethel, L.; Hermansson, T.; Hermansson, P. (5) Rappenecker, G.; Lojan, D.; Dickey, S.; Kim, C.; Trahan, A.; Washington, A.; Smart, S. (6) Goller, L.; Burghoffer, T.; Gugliara, D.; Nichols, R.; Washington, S.; Kim, J. (7) Beckett, M.; Dickey, J.; Smith, R.; Garcia, R.; Hoffman, A.; Seyfert, R.; Brown, H. (8) Fleming, S.; Bruzzese, P.; Burghoffer, W.; Bethel, T.; Cashman, J.; Vacek, K.