Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Wọ́n Wà Ojú Ọ̀nà Híhá Náà

Wọ́n Wà Ojú Ọ̀nà Híhá Náà

Wọ́n Wà Ojú Ọ̀nà Híhá Náà

NÍ NǸKAN bí àádọ́tadínlẹ́gbẹ̀ta [550] ọdún sẹ́yìn, àwùjọ kéékèèké kan tí wọ́n pe ara wọn ní Kristẹni, tí wọ́n ń gbé ní ìlú Prague, Chelčice, Vilémov, Klatovy àtàwọn ìlú mìíràn tó pa pọ̀ di ibi tá à ń pè ní orílẹ̀-èdè Olómìnira ti Czech lónìí, fi ilé wọn sílẹ̀. Wọ́n lọ ń gbé ní abúlé kan tó ń jẹ́ Kunwald, ní àfonífojì kan níhà àríwá ìlà oòrùn Bohemia. Wọ́n kọ́ àwọn ilé kó-kò-kó, wọ́n ń dáko, wọ́n ń ka Bíbélì wọn, wọ́n sì ń pe ara wọn ní Àwọn Ará Tó Wà Níṣọ̀kan, tàbí Unitas Fratrum lédè Látìn.

Onírúurú èèyàn làwọn tó ṣí lọ sí àfonífojì yìí. Lára wọn, a rí kò-là-kò-ṣagbe, ọ̀tọ̀kùlú, ọmọ ilé ẹ̀kọ́ yunifásítì, ọlọ́lá àti tálákà, ọkùnrin àti obìnrin, opó àti aláìníbaba, tó sì jẹ́ pé ohun kan náà ló sún wọn wá síbẹ̀. Nínú àkọsílẹ̀ wọn, wọ́n sọ pé: “Ọlọ́run Tìkára Rẹ̀ là ń gbàdúrà sí, tá a sì ń bẹ̀ ẹ́ pé kí Ó jẹ́ ká mọ ohun tó jẹ́ ojúlówó ìfẹ́ Rẹ̀ nínú ohun gbogbo. A fẹ́ máa tọ àwọn ọ̀nà Rẹ̀.” Ní tòótọ́ Àwọn Ará Tó Wà Níṣọ̀kan yìí, tàbí àwọn Ará Nílẹ̀ Czech, gẹ́gẹ́ bá a tún ṣe ń pe àwọn onígbàgbọ́ yìí lẹ́yìn náà, wá ‘ojú ọ̀nà híhá tí ó lọ sínú ìyè.’ (Mátíù 7:13, 14) Òtítọ́ inú Bíbélì wo ni wọ́n wá kàn? Báwo ni ìgbàgbọ́ wọn ṣe yàtọ̀ sí ohun táwọn èèyàn gbà gbọ́ láyé ìgbà tiwọn, ẹ̀kọ́ wo la sì lè rí kọ́ lára wọn?

Má Hùwà Ipá—Má Ṣe Juwọ́ Sílẹ̀

Inú onírúurú ẹgbẹ́ ẹ̀sìn làwọn tó para pọ̀ di Àwọn Ará Tó Wà Níṣọ̀kan ti jáde wá láàárín ọ̀rúndún kẹẹ̀ẹ́dógún. Ọ̀kan lára ẹgbẹ́ yẹn ni ti Àwọn Ọmọlẹ́yìn

Waldo, èyí tó ti wà láti ọ̀rúndún kejìlá. Inú ẹ̀sìn Kátólíìkì, tí í ṣe ẹ̀sìn ilẹ̀ Àárín Gbùngbùn Yúróòpù ni Àwọn Ọmọlẹ́yìn Waldo ti ya kúrò. Àmọ́ nígbà tó yá, wọ́n tún padà ń tẹ̀ lé àwọn kan lára ẹ̀kọ́ ẹ̀sìn Kátólíìkì. Ẹgbẹ́ mìíràn tó tún gbajúmọ̀ ni ti Àwọn Ọmọlẹ́yìn Jan Hus. Ẹ̀sìn yìí ni ọ̀pọ̀ jù lọ ní ilẹ̀ Czech ń ṣe, àmọ́ ìṣọ̀kan ò sí láàárín wọn rárá. Apá kan ń jà lórí ọ̀ràn ire aráàlú, nígbà tí apá mìíràn ń lo ẹ̀sìn láti fi gbé ìṣèlú lárugẹ. Àwọn ẹlẹ́kọ̀ọ́ ìjọba ẹgbẹ̀rún ọdún ti Kristi àtàwọn akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ nínú Bíbélì lórílẹ̀-èdè yẹn àti nílẹ̀ òkèèrè tún nípa lórí ẹgbẹ́ Àwọn Ará yìí pẹ̀lú.

Peter Chelčický ará ilẹ̀ Czech (tó gbé ayé ní nǹkan bí ọdún 1390 sí 1460), tó jẹ́ akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ nínú Bíbélì àti alátùn-únṣe, mọ̀ nípa ẹ̀kọ́ Àwọn Ọmọlẹ́yìn Waldo àti Àwọn Ọmọlẹ́yìn Jan Hus dáadáa. Chelčický yìí kò fara mọ́ Àwọn Ọmọlẹ́yìn Jan Hus nítorí ìwà jàgídíjàgan tó ti wọ inú ẹgbẹ́ wọn, bẹ́ẹ̀ ni kò sì fojúure wo Àwọn Ọmọlẹ́yìn Waldo nítorí pé wọ́n gbàgbàkugbà mọ́ ẹ̀kọ́ wọn. Ó bẹnu àtẹ́ lu ogun jíjà, pé kò bá ìwà Kristẹni mu. Èrò tirẹ̀ ni pé bí iná ń jó tí ìjì ń jà “òfin Kristi” ló yẹ kí Kristẹni tẹ̀ lé. (Gálátíà 6:2; Mátíù 22:37-39) Lọ́dún 1440, Chelčický kọ ohun tó ń kọ́ni sínú ìwé kan tó ń jẹ́ Net of the Faith (Ohun Tí Ìgbàgbọ́ Wé Mọ́).

Ẹ̀kọ́ ọ̀mọ̀wé Chelčický gba Gregory ti ìlú Prague lọ́kàn débi pé ó kúrò nínú ẹgbẹ́ Àwọn Ọmọlẹ́yìn Jan Hus. Ó ṣẹlẹ̀ pé àkókò kan náà ni Chelčický àti Gregory yìí jọ gbé láyé, bó tilẹ̀ jẹ́ pé Gregory kéré sí i lọ́jọ́ orí. Lọ́dún 1458, Gregory rọ àwùjọ kéékèèké lára àwọn Ọmọlẹ́yìn Jan Hus ní onírúurú ibi ní ilẹ̀ Czechia pé kí kálukú wọn fi ibi tí wọ́n ń gbé sílẹ̀. Àwọn wọ̀nyí wà lára àwọn tó tẹ̀ lé e lọ sí abúlé Kunwald láti lọ tẹ ibì kan dó láti máa bá ẹ̀sìn wọn lọ. Nígbà tó yá, àwọn kan lára Àwọn Ọmọlẹ́yìn Waldo ní ilẹ̀ Czech àti ilẹ̀ Jámánì ṣí wá bá wọn níbẹ̀.

Ohun Tó Ṣẹlẹ̀ sí Wọn

Láàárín ọdún 1464 sí 1467, àwọn olórí ẹ̀sìn tuntun tó ń gbèrú yìí ṣe ọ̀pọ̀ ìpàdé ẹgbẹ́ ní ẹkùn Kunwald, wọ́n sì fẹnu kò lórí ọ̀pọ̀ ìlànà tí wọn yóò máa tẹ̀ lé nínú ìsìn tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ dá sílẹ̀ yìí. Gbogbo ìpinnu tí wọ́n fẹnu kò lé lórí ni wọ́n fara balẹ̀ kọ sínú ọ̀wọ́ àwọn ìwé kan tí a wá mọ̀ sí Acta Unitatis Fratrum (Ìṣe Àwọn Ará Tó Wà Níṣọ̀kan), àwọn ìwé yẹn ṣì wà títí dòní. Àwọn ìwé Ìṣe yìí jẹ́ ká mọ ohun tó ṣẹlẹ̀ sí wọn láyé ìgbà náà, ìyẹn sì mú ká mọ̀ dáadáa nípa ohun tí ẹgbẹ́ Àwọn Ará yìí gbà gbọ́. Ohun tó wà nínú ìwé wọ̀nyẹn ni àwọn lẹ́tà tí wọ́n kọ, ìwé àsọyé wọn àti ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé nípa awuyewuye wọn pàápàá.

Ní ti ìgbàgbọ́ ẹgbẹ́ Àwọn Ará náà, ìwé Ìṣe yìí sọ pé: “A pinnu láti gbé ètò ìṣàkóso wa karí kìkì ohun tá a bá kà tá a sì ṣàṣàrò lé lórí nínú Bíbélì àti nínú àpẹẹrẹ Olúwa wa àtàwọn àpọ́sítélì rẹ̀ mímọ́, láti máa lo ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ àti ìpamọ́ra, láti nífẹ̀ẹ́ ọ̀tá wa, ká máa ṣe wọ́n lóore, ká máa wá ire wọn, ká sì máa gbàdúrà fún wọn.” Àwọn ìwé yìí sì fi hàn pé ẹgbẹ́ Àwọn Ará yìí tiẹ̀ ń wàásù níbẹ̀rẹ̀. Wọ́n máa ń rìnrìn àjò lọ káàkiri ní méjì-méjì, àwọn obìnrin wọn sì ń ṣe dáadáa nínú iṣẹ́ míṣọ́nnárì létílé. Ẹgbẹ́ Àwọn Ará yìí kì í tẹ́wọ́ gba ipò òṣèlú, wọn kì í ṣe ìbúra, wọn kì í sì í lọ́wọ́ sí ọ̀ràn ológun tàbí kí wọ́n gbé ohun ìjà ogun.

Ìyapa Dé

Àmọ́ lẹ́yìn ọ̀pọ̀ ọdún, Àwọn Ará Tó Wà Níṣọ̀kan yìí, kò jẹ́ kí orúkọ rò àwọn mọ́. Awuyewuye nípa ọ̀nà tó yẹ kí wọ́n máa gbà fi ohun tí wọ́n gbà gbọ́ sílò dá ìyapa sílẹ̀ láàárín wọn. Lọ́dún 1494, ẹgbẹ́ Àwọn Ará yìí pín sí ọ̀nà méjì, ìyẹn Ẹgbẹ́ Ńlá àti Ẹgbẹ́ Kékeré. Nígbà tí Ẹgbẹ́ Ńlá ń bomi la ohun tó jẹ́ ìgbàgbọ́ wọn ìpilẹ̀ṣẹ̀, Ẹgbẹ́ Kékeré ń wàásù pé kí ẹgbẹ́ Àwọn Ará kọ̀ jálẹ̀ láti lọ́wọ́ sí ọ̀ràn ìṣèlú àti ọ̀ràn ayé.—Wo àpótí náà “Kí Ló Wá Ṣẹlẹ̀ sí Ẹgbẹ́ Ńlá?”

Bí àpẹẹrẹ, ọ̀kan lára ọmọ Ẹgbẹ́ Kékeré kọ̀wé pé: “Àwọn tó ń rìn ní ọ̀nà méjì kì í sábà lè dúró ti Ọlọ́run, nítorí pé ekukáká ni wọ́n fi máa ń fẹ́ láti ṣègbọràn kí wọ́n sì tẹrí ba fún Ọlọ́run, àyàfi tó bá jẹ́ nínú àwọn nǹkan kéékèèké, àmọ́ tó bá ti dórí àwọn ọ̀ràn pàtàkì-pàtàkì, ìfẹ́ inú wọn ni wọ́n máa ń ṣe. . . . Ní ti àwọn tọ́kàn wọn dúró ṣinṣin, tí ẹ̀rí ọkàn wọn sì ń ṣiṣẹ́ dáadáa, ńṣe ni wọ́n ń tẹ̀ lé Kristi Olúwa lójoojúmọ́ tàwọn ti àgbélébùú wọn, ara irú àwọn bẹ́ẹ̀ làwa sì ń fẹ́ wà.”

Àwọn ọmọ Ẹgbẹ́ Kékeré ka ẹ̀mí mímọ́ sí ipá ìṣiṣẹ́ Ọlọ́run, “ìka” ọwọ́ rẹ̀. Òye wọn nípa ìràpadà ni pé, ńṣe ni Jésù, ọkùnrin pípé nì, fi ìwàláàyè rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ènìyàn san ohun tí Ádámù ẹlẹ́ṣẹ̀ gbé sọnù. Wọn kì í júbà Màríà, ìyá Jésù. Wọ́n padà sí ẹ̀kọ́ tó sọ pé gbogbo onígbàgbọ́ lápapọ̀ jẹ́ ẹgbẹ́ àlùfáà láìsí pé ká ṣẹ̀ṣẹ̀ máa jẹ́ ẹ̀jẹ́ ìnìkàngbé. Wọ́n ń gba àwọn ará ìjọ níyànjú pé gbogbo wọn ni kí ó máa wàásù fáwọn èèyàn, wọ́n sì ń yọ àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ tí kò ronú pìwà dà lẹ́gbẹ́. Wọn kò fàyè gba kíkópa nínú iṣẹ́ ológun tàbí ọ̀ràn ìṣèlú rárá. (Wo àpótí “Ohun Táwọn Ará Tó Jẹ́ Ẹgbẹ́ Kékeré Gbà Gbọ́.”) Nítorí pé Ẹgbẹ́ Kékeré kò yà kúrò nínú àwọn ìpinnu tó wà nínú ìwé Ìṣe wọn, wọ́n gbà pé àwọn ni ojúlówó ẹgbẹ́ tó ń tọpasẹ̀ Àwọn Ará Tó Wà Níṣọ̀kan.

Wọ́n Sojú Abẹ Níkòó, Inúnibíni Bá Wọn

Ẹgbẹ́ Kékeré máa ń ṣe lámèyítọ́ àwọn ẹ̀sìn yòókù títí kan Ẹgbẹ́ Ńlá, wọ́n sì ń ṣe é láìfi bò. Wọ́n kọ̀wé nípa irú àwọn ẹ̀sìn wọ̀nyẹn pé: “Ẹ̀ ń kọ́ni pé kí wọ́n máa ṣèrìbọmi fáwọn ọmọdé tí kò tíì dẹni tó ní ìgbàgbọ́, ẹ tipa bẹ́ẹ̀ ń tẹ̀ lé ohun tí bíṣọ́ọ̀bù kan tó ń jẹ́ Dionysius dá sílẹ̀, ẹni táwọn aláìgbọ́n kan ń tì nítìkutì tóun náà wá ń ránnu mọ́ ṣíṣe ìrìbọmi fáwọn ọmọ ọwọ́ . . . Ohun kan náà yìí ló fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé gbogbo àwọn olùkọ́ni àtàwọn dókítà, Luther, Melanchthon, Bucerus, Korvín, Jiles̆, Bullinger, . . . [àti] Ẹgbẹ́ Ńlá gbà gbọ́, tí gbogbo wọ́n sùn tí wọ́n kọrí síbì kan náà.”

Abájọ tí wọ́n fi ń ṣe inúnibíni sí Ẹgbẹ́ Kékeré. Lọ́dún 1524, wọ́n na Jan Kalenec tó jẹ́ ọ̀kan lára aṣáájú ẹgbẹ́ yìí, wọ́n fi bílálà oníkókó nà án ní ànàṣeléṣe. Lẹ́yìn náà, wọ́n dáná sun àwọn mẹ́ta lára ọmọ Ẹgbẹ́ Kékeré lórí òpó. Ó jọ pé nǹkan bí ọdún 1550 ni Ẹgbẹ́ Kékeré yìí wọlẹ̀ lẹ́yìn ikú aṣáájú wọn tó gbẹ̀yìn.

Síbẹ̀síbẹ̀, àwọn onígbàgbọ́ tí ń bẹ nínú Ẹgbẹ́ Kékeré ti ṣe ohun tórúkọ ẹgbẹ́ náà ò fi lè pa rẹ́ láé nínú ìtàn àwọn ẹ̀sìn ilẹ̀ Yúróòpù láyé ìgbà tí ọ̀làjú ṣẹ̀ṣẹ̀ ń bọ̀. Lóòótọ́, nítorí pé “ìmọ̀ tòótọ́” kò tíì di púpọ̀ láyé ìgbà Ẹgbẹ́ Kékeré, kò ṣeé ṣe fún wọn láti borí òkùnkùn tẹ̀mí tó ti bolẹ̀ tipẹ́tipẹ́ ṣáájú ìgbà náà. (Dáníẹ́lì 12:4) Síbẹ̀, bí wọ́n ṣe fi gbogbo ọkàn wá ojú ọ̀nà híhá náà, tí wọ́n sì làkàkà láti máa tọ́ ọ́ láìfi inúnibíni pè jẹ́ ẹ̀kọ́ fáwọn Kristẹni òde òní.

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 13]

Nínú ọgọ́ta ìwé tí wọ́n ṣe ní ilẹ̀ Bohemian (ìyẹn orílẹ̀-èdè Czech) láàárín ọdún 1500 sí 1510, wọ́n sọ pé àádọ́ta nínú rẹ̀ jẹ́ látọwọ́ àwọn ọmọ ẹgbẹ́ Àwọn Ará Tó Wà Níṣọ̀kan

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 11]

Kí Ló Wá Ṣẹlẹ̀ sí Ẹgbẹ́ Ńlá?

Kí ló wá ṣẹlẹ̀ sí Ẹgbẹ́ Ńlá? Lẹ́yìn tí Ẹgbẹ́ Kékeré wọlẹ̀ tá ò gbúròó wọn mọ́, Ẹgbẹ́ Ńlá ń bá a lọ gẹ́gẹ́ bí ètò ẹ̀sìn kan, táwọn èèyàn ṣì mọ̀ gẹ́gẹ́ bí Àwọn Ará Tó Wà Níṣọ̀kan. Nígbà tó ṣe, ẹgbẹ́ yìí ṣe àwọn ìyípadà kan nínú ohun tí wọ́n gbà gbọ́ nípilẹ̀ṣẹ̀. Lápá ìparí ọ̀rúndún kẹrìndínlógún, Àwọn Ará Tó Wà Níṣọ̀kan wọ àdéhùn àjọṣepọ̀ pẹ̀lú Ẹgbẹ́ Ajẹméjèèjì ti Ilẹ̀ Czech, a tí ìṣe wọ́n jọ tàwọn Ọmọlẹ́yìn Luther. Àmọ́ ṣá, ẹgbẹ́ Àwọn Ará yìí ṣì ń bá ìgbòkègbodò wọn lọ, wọ́n ń túmọ̀ Bíbélì àtàwọn ìwé ìsìn mìíràn wọ́n sì ń tẹ̀ wọ́n jáde. Ó yẹ fún àfiyèsí pé nínú àwọn ìwé tí wọ́n kọ́kọ́ ṣe jáde, lẹ́tà mẹ́rin tó dúró fún orúkọ Ọlọ́run lédè Hébérù, ìyẹn Jèhófà, sábà máa ń hàn lójú ewé ìṣáájú tí ọ̀rọ̀ òǹṣèwé wà.

Lọ́dún 1620, ìjọ Kátólíìkì jẹ gàba lórí ìjọba ilẹ̀ Czech. Nítorí náà, ọ̀pọ̀ lára àwọn Ẹgbẹ́ Ńlá kúrò lórílẹ̀-èdè náà, wọ́n ń bá ìgbòkègbodò wọn lọ nílẹ̀ òkèèrè. Nílẹ̀ òkèèrè yìí, wọ́n mọ̀ wọ́n sí Ẹ̀sìn Moravia (nítorí pé ara ilẹ̀ Czech ni Moravia jẹ́). Ẹ̀sìn Moravia yìí ṣì wà dónìí.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Ọ̀rọ̀ yìí wá látinú ọ̀rọ̀ èdè Látìn náà utraque, tó túmọ̀ sí “méjèèjì.” Ní ìyàtọ̀ sí ìṣe àwọn àlùfáà ìjọ Kátólíìkì tí wọn kì í fún àwọn ọmọ ìjọ ní wáìnì mu tí wọ́n bá ń gba Ara Olúwa, Ẹgbẹ́ Ajẹméjèèjì (tó jẹ́ àpapọ̀ onírúurú ẹ̀ya Ọmọlẹ́yìn John Hus) máa ń fún àwọn ọmọ ìjọ tiwọn ní búrẹ́dì àti wáìnì.

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 12]

Ohun Táwọn Ará Tó Jẹ́ Ẹgbẹ́ Kékeré Gbà Gbọ́

Àwọn ọ̀rọ̀ tá a fà yọ sísàlẹ̀ yìí, látinú ìwé Acta Unitatis Fratrum (Ìṣe Àwọn Ará Tó Wà Níṣọ̀kan), fi ohun tí Ẹgbẹ́ Kékeré gbà gbọ́ hàn. Gbólóhùn táwọn olórí Ẹgbẹ́ Kékeré kọ yìí, Ẹgbẹ́ Ńlá ni wọ́n darí wọn sí ní pàtàkì.

Mẹ́talọ́kan: “Bí ẹ bá yẹ Bíbélì wò látòkèdélẹ̀, ẹ ò ní rí ibì kankan tó wà pé Ọlọ́run pín sí irú Mẹ́talọ́kan kan, ẹni mẹ́tà tó lórúkọ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, bí àwọn èèyàn kan ṣe fòye ara wọn gbé e kalẹ̀.”

Ẹ̀mí mímọ́: “Ẹ̀mí mímọ́ jẹ́ ìka Ọlọ́run àti ẹ̀bùn Ọlọ́run, tàbí olùtùnú, tàbí Agbára Ọlọ́run, tí Bàbá máa ń fún àwọn onígbàgbọ́ lọ́lá Kristi. A kò rí i nínú Ìwé Mímọ́ pé ká máa pe ẹ̀mí mímọ́ ní Ọlọ́run tàbí Ẹni gidi kan; bẹ́ẹ̀ ni kò sì sí nínú ẹ̀kọ́ àwọn àpọ́sítélì.”

Ẹgbẹ́ Àlùfáà: “Wọ́n fi àṣìṣe fún yín ní òye “àlùfáà”; tẹ́ ẹ bá ti yọwọ́ fífá tẹ́ ẹ̀ ń fárí kodoro àti òróró ìwọ́ra yín, kò sí ohun mìíràn tẹ́ ẹ fi ju èyíkéyìí nínú àwọn ọmọ ìjọ lọ. Pétérù Mímọ́ sọ pé kí gbogbo Kristẹni jẹ́ àlùfáà, ó ní: Ẹ̀yin ni ẹgbẹ́ àlùfáà mímọ́ tó ń rú ẹbọ nípa tẹ̀mí. (1 Pétérù 2)”

Ìrìbọmi: “Kristi Olúwa sọ fún àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ pé: Ẹ lọ sínú gbogbo ayé, kí ẹ wàásù Ìhìn Rere fún gbogbo ìṣẹ̀dá, fún àwọn tí ó bá gbà gbọ́. (Máàkù, orí 16) Ìgbà tí wọ́n bá ṣe gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ yìí; tí wọ́n sì ṣe ìrìbọmi, ni wọn yóò tó rí ìgbàlà. Ẹ̀yin wá ń kọ́ni pé kí wọ́n máa ṣe ìrìbọmi fáwọn ọmọdé tí kò tíì dẹni tó ní ìgbàgbọ́.”

Àìdá-sí-ọ̀ràn-ogun: “Ohun táwọn arákùnrin yín ìjímìjí kà sí àìdáa àti ohun àìmọ́, láti máa wọṣẹ́ ológun láti pànìyàn tàbí láti fi ohun ìjà dìhámọ́ra ká sì máa rìn kiri lójú pópó, gbogbo ìyẹn ni ẹ̀yin kà sí ohun tó dára . . . Nítorí náà, àwa kà á sí pé ńṣe ni òye ẹ̀yin àtàwọn olùkọ́ yín kò kún tó nípa ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ tó sọ pé: Ó tipa báyìí fọ́ agbára ọfà, apata àti idà àti ogun jíjà túútúú. (Sáàmù 75) Àti pé: Wọn kì yóò ṣe ìpalára tàbí kí wọ́n fa ìparun ní gbogbo òkè mímọ́ mi, nítorí ilẹ̀ ayé tó jẹ́ ti Olúwa yóò kún fún ìmọ̀ Ọlọ́run, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. (Aísáyà, orí 11).”

Iṣẹ́ Ìwàásù: “A mọ̀ dájú pé, ní ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀, àwọn èèyàn tó tipasẹ̀ àwọn obìnrin dẹni tó ronú pìwà dà pọ̀ ju àpapọ̀ iye àwọn tí àwọn àlùfáà àtàwọn bíṣọ́ọ̀bù mú ronú pìwà dà lọ. Àmọ́ ní báyìí, àwọn àlùfáà lọ ń fẹ̀ kalẹ̀ sí àyè wọn àti sí ilé àwọn àlùfáà. Àṣìṣe gbáà lẹ̀ ń ṣe! Ẹ lọ sínú gbogbo ayé. Ẹ wàásù . . . fún gbogbo ìṣẹ̀dá.”

[Àwọn àwòrán ilẹ̀ tó wà ní ojú ìwé 10]

(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)

ILẸ̀ JÁMÁNÌ

ILẸ̀ POLAND

ILẸ̀ OLÓMÌNIRA TI CZECH

BOHEMIA

Odò Elbe

PRAGUE

Odò Vitava

Ìlú Klatovy

Ìlú Chelčice

Abúlé Kunwald

Ìlú Vilémov

MORAVIA

Odò Danube

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10, 11]

Apá òsì: Peter Chelčický rèé; ìsàlẹ̀: ojú ewé kan látinú ìwé “Net of the Faith” (Ohun Tí Ìgbàgbọ́ Wé Mọ́)

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 11]

Gregory ti ìlú Prague

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 13]

Gbogbo àwòrán: S laskavým svolením knihovny Národního muzea v Praze, C̆esko