Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
Ṣé gbólóhùn Sítéfánù tó wà nínú Ìṣe 7:59 fi hàn pé Jésù ló yẹ ká máa gbàdúrà sí ni?
Ìṣe 7:59 sọ pé: “Wọ́n sì ń bá a lọ ní sísọ òkúta lu Sítéfánù bí ó ti ń ké gbàjarè, tí ó sì wí pé: ‘Jésù Olúwa, gba ẹ̀mí mi.’” Gbólóhùn yìí ti fa ìbéèrè lọ́kàn àwọn kan, nítorí pé Jèhófà ni Bíbélì pè ní “Olùgbọ́ àdúrà.” (Sáàmù 65:2) Ṣé Jésù ni Sítéfánù gbàdúrà sí lóòótọ́ ? Tó bá jẹ́ pé òun ni, ṣé èyí wá túmọ̀ sí pé Jésù kò yàtọ̀ sí Jèhófà?
Ohun tí Bíbélì King James sọ ni pé, Sítéfánù “ń ké pe Ọlọ́run.” Abájọ tí ọ̀pọ̀ fi fara mọ́ ọ̀rọ̀ tí Matthew Henry tó máa ń ṣàlàyé Bíbélì sọ. Ó ní: “Kristi ni Sítéfánù ń gbàdúrà sí nínú ẹsẹ yìí, òun làwa náà sì ní láti máa gbàdúrà sí.” Àmọ́, èrò yẹn ò tọ̀nà. Kí nìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀?
Òótọ́ pọ́ńbélé ni ìwé kan tó ń jẹ́ Barnes’ Notes on the New Testament tó ṣàlàyé Bíbélì sọ, ó ní: “Kì í ṣe ọ̀rọ̀ náà Ọlọ́run ní wọ́n lò ní ẹsẹ yìí nínú Bíbélì ìpilẹ̀ṣẹ̀, torí náà kì í ṣòun ló yẹ kí wọ́n lò nínú ìtumọ̀ yìí. A ò rí i nínú Bíbélì ìgbà láéláé kankan tí wọ́n fọwọ́ kọ.” Báwo wá ni ọ̀rọ̀ náà “Ọlọ́run” ṣe dénú ẹsẹ yìí? Akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Abiel Abbot Livermore, sọ pé “àpẹẹrẹ kan lèyí jẹ́ tó ń fi hàn pé àwọn atúmọ̀ èdè ti jẹ́ kí ohun táwọn ìsìn kan gbà gbọ́ nípa lórí wọn.” Ìdí rèé tí ọ̀pọ̀ Bíbélì tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ń túmọ̀ lóde òní fi yọ ọ̀rọ̀ náà “Ọlọ́run” tí kò sí níbẹ̀ tẹ́lẹ̀ kúrò nínú ẹsẹ náà.
Síbẹ̀, ohun tó wà nínú ọ̀pọ̀ Bíbélì ni pé Jésù ni Sítéfánù “gbàdúrà” sí. Ohun tó sì wà nínú àlàyé ìsàlẹ̀ Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun lédè Gẹ̀ẹ́sì tó ní atọ́ka nínú ni pé ọ̀rọ̀ náà, “ké gbàjarè” tún lè túmọ̀ sí “rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí” tàbí “gbàdúrà sí.” Ṣé ìyẹn wá fi hàn pé Jésù ni Ọlọ́run Olódùmarè ni? Rárá o. Ìwé atúmọ̀ èdè tó ń jẹ́ Vine’s Expository Dictionary of Old and New Testament Words ṣàlàyé pé, lórí kókó tá à ń sọ̀rọ̀ lé yìí, ohun tí ọ̀rọ̀ Gíríìkì náà e·pi·ka·leʹo, túmọ̀ sí ni: “Láti ké sí, láti rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí, tàbí . . . ké gbàjarè sí ẹnì kan tó wà nípò gíga.” Ọ̀rọ̀ kan náà yìí ni Pọ́ọ̀lù lò nígbà tó sọ pé: “Mo ké gbàjarè sí Késárì!” (Ìṣe 25:11) Abájọ tí Bíbélì The New English Bible fi túmọ̀ ẹsẹ náà lọ́nà tó dára, ó ní Sítéfánù “ké sí” Jésù.
Kí nìdí tí Sítéfánù fi rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí Jésù? Ìṣe 7:55, 56 sọ pé, “bí [Sítéfánù] ti kún fún ẹ̀mí mímọ́, ó tẹjú mọ́ ọ̀run, ó sì tajú kán rí ògo Ọlọ́run àti Jésù tí ó dúró ní ọwọ́ ọ̀tún Ọlọ́run.” Ká ní kì í ṣe pé Sítéfánù rí ìran yìí ni, Jèhófà ni ì bá rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí. Àmọ́ rírí tí Sítéfánù rí Jésù tó ti jíǹde nínú ìran ló mú kó darí ẹ̀bẹ̀ rẹ̀ sí Jésù ní tààràtà, pé: “Jésù Olúwa, gba ẹ̀mí mi.” Sítéfánù mọ̀ pé Ọlọ́run ti fún Jésù láṣẹ láti jí òkú dìde. (Jòhánù 5:27-29) Ìdí nìyẹn tó fi bẹ Jésù pé kó gba ẹ̀mí òun tàbí kó fi ẹ̀mí òun pa mọ́ títí ọjọ́ tí yóò fi jí òun sí ìyè àìleèkú ní ọ̀run.
Ṣé gbólóhùn ṣókí tí Sítéfánù sọ yìí wá jẹ́ àpẹẹrẹ fún wa pé Jésù ni ká máa gbàdúrà sí ni? Rárá o. Ìdí kan ni pé, Sítéfánù fi hàn gbangba pé Jésù yàtọ̀ sí Jèhófà nítorí pé àkọsílẹ̀ náà sọ pé ó rí Jésù “tí ó dúró ní ọwọ́ ọ̀tún Ọlọ́run.” Yàtọ̀ síyẹn, irú àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ bẹ́ẹ̀ ṣọ̀wọ́n. Ẹlòmíràn tó tún sọ irú gbólóhùn bẹ́ẹ̀ sí Jésù ni àpọ́sítélì Jòhánù, òun náà bá Jésù sọ̀rọ̀ ní tààràtà nígbà tó rí i nínú ìran.—Ìṣípayá 22:16, 20.
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jèhófà Ọlọ́run làwọn Kristẹni ń darí gbogbo àdúrà wọn sí lónìí, àwọn náà ní ìgbàgbọ́ tí kò mì pé Jésù ni “àjíǹde àti ìyè.” (Jòhánù 11:25) Bí ìgbàgbọ́ tí Sítéfánù ní nínú Jésù pé ó lè jí àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ dìde ṣe ràn án lọ́wọ́, bẹ́ẹ̀ náà ni ìgbàgbọ́ yìí lè ran àwa náà lọ́wọ́ kó sì mú ẹsẹ̀ wa dúró nígbà ìdánwò.