Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìfẹ́ Tí Wọ́n Ní Sí Ọlọ́run Ló Mú Kí Wọ́n Wà Níṣọ̀kan

Ìfẹ́ Tí Wọ́n Ní Sí Ọlọ́run Ló Mú Kí Wọ́n Wà Níṣọ̀kan

Ìfẹ́ Tí Wọ́n Ní Sí Ọlọ́run Ló Mú Kí Wọ́n Wà Níṣọ̀kan

NÍGBÀ tí wọ́n dá ìjọ Kristẹni sílẹ̀ ní ọ̀rúndún kìíní, wọ́n mọ àwọn ohun pàtàkì kan mọ ìjọ náà. Lára àwọn ohun náà ni ìṣọ̀kan tó wà láàárín wọn bó tilẹ̀ jẹ́ pé ibi ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni wọ́n ti wá. Àwọn orílẹ̀-èdè tó wà ní Éṣíà, Yúróòpù àti Áfíríkà làwọn olùjọsìn Ọlọ́run tòótọ́ wọ̀nyẹn ti wá. Onírúurú èèyàn sì ni wọ́n. Lára wọn la ti rí àlùfáà, ọmọ ogun, ẹrú, olùwá-ibi-ìsádi, oníṣòwò, oníṣẹ́ ọwọ́ àti amọṣẹ́dunjú. Júù làwọn kan, Kèfèrí sì làwọn míì. Tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀, ọ̀pọ̀ lára wọn ló jẹ́ panṣágà, abẹ́yà-kan-náà-lò-pọ̀, ọ̀mùtípara, olè tàbí alọ́nilọ́wọ́gbà. Àmọ́ nígbà tí wọ́n di Kristẹni, wọ́n kiwọ́ ìwàkiwà bọlẹ̀ wọ́n sì wá wà níṣọ̀kan nínú ìgbàgbọ́.

Kí ló mú kí ìjọ Kristẹni ọ̀rúndún kìíní lè so onírúurú àwọn èèyàn wọ̀nyí pọ̀? Kí nìdí tí kò fi sí gbọ́nmisi-omi-ò-tó láàárín wọn tí wọn kì í sì í bá àwọn tí kì í ṣe Kristẹni fa wàhálà? Kí ló dé tí wọn kì í bá àwọn ará ìlú lọ́wọ́ sí ọ̀tẹ̀ àti ìjà? Kí nìdí tí ìjọ Kristẹni ọ̀rúndún kìíní fi yàtọ̀ gan-an sí àwọn ìsìn ńlá-ńlá lóde òní?

Kí Ló Mú Káwọn Kristẹni Ọ̀rúndún Kìíní Wà Níṣọ̀kan?

Ìfẹ́ táwọn onígbàgbọ́ ọ̀rúndún kìíní ní sí Ọlọ́run lohun tó ṣe kókó jù lọ tó mú kí wọ́n wà níṣọ̀kan. Àwọn Kristẹni wọ̀nyẹn mọ̀ pé ohun tó jẹ́ ojúṣe wọn jù lọ ni kí wọ́n fi gbogbo ọkàn wọn àti gbogbo èrò inú wọn nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, tí í ṣe Ọlọ́run tòótọ́. Bí àpẹẹrẹ, áńgẹ́lì kan sọ fún àpọ́sítélì Pétérù pé kó lọ bẹ ẹnì kan tí kì í ṣe Júù wò. Bẹ́ẹ̀ Pétérù ò jẹ́ lọ sọ́dọ̀ irú ẹni bẹ́ẹ̀ ká ní kì í ṣe pé wọ́n ní kó lọ. Àmọ́ ìfẹ́ tó ní sí Jèhófà ló jẹ́ kó ṣe ohun tí wọ́n ní kó ṣe yìí. Pétérù àtàwọn Kristẹni tó kù ní ọ̀rúndún kìíní ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Ọlọ́run. Ohun tó sì mú kí wọ́n ní irú àjọṣe bẹ́ẹ̀ ni ìmọ̀ pípéye tí wọ́n ní nípa irú ẹni tí Ọlọ́run jẹ́, wọ́n mọ àwọn ohun tó fẹ́ àtàwọn ohun tí kò fẹ́. Nígbà tó yá, gbogbo àwọn olùjọsìn náà wá mọ̀ pé ohun tí Jèhófà fẹ́ ni pé káwọn “ṣọ̀kan rẹ́gírẹ́gí nínú èrò inú kan náà àti nínú ìlà ìrònú kan náà.”—1 Kọ́ríńtì 1:10; Mátíù 22:37; Ìṣe 10:1-35.

Ohun mìíràn tó mú kí wọ́n wà níṣọ̀kan ni ìgbàgbọ́ tí wọ́n ní nínú Jésù Kristi. Wọ́n fẹ́ láti máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù lójú méjèèjì. Jésù pàṣẹ fún wọn pé: “Ẹ nífẹ̀ẹ́ ara yín lẹ́nì kìíní-kejì; gan-an gẹ́gẹ́ bí mo ti nífẹ̀ẹ́ yín. . . . Nípa èyí ni gbogbo ènìyàn yóò fi mọ̀ pé ọmọ ẹ̀yìn mi ni yín, bí ẹ bá ní ìfẹ́ láàárín ara yín.” (Jòhánù 13:34, 35) Kì í ṣe ìfẹ́ tí kò dénú ló sọ pé kí wọ́n ní síra wọn o, ojúlówó ìfẹ́ ni. Tí wọ́n bá ní irú ìfẹ́ yìí, kí ló máa jẹ́ àbájáde rẹ̀? Jésù gbàdúrà nípa àwọn tó gbà á gbọ́ pé: “[Mo] ṣe ìbéèrè . . . [pé] kí gbogbo wọn lè jẹ́ ọ̀kan, gan-an gẹ́gẹ́ bí ìwọ, Baba, ti wà ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú mi, tí èmi sì wà ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú rẹ, kí àwọn náà lè wà ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú wa.”—Jòhánù 17:20, 21; 1 Pétérù 2:21.

Jèhófà tú ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ tàbí ipá ìṣiṣẹ́ rẹ̀ sórí àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ olóòótọ́ wọ̀nyẹn. Ẹ̀mí yìí jẹ́ kí ìṣọ̀kan wà láàárín wọn. Ó jẹ́ kí wọ́n lóye àwọn ẹ̀kọ́ inú Bíbélì. Gbogbo ìjọ ló sì fara mọ́ òye yẹn. Ohun kan náà ni gbogbo àwọn olùjọsìn Jèhófà wọ̀nyẹn wàásù rẹ̀, ìyẹn ìsọdimímọ́ orúkọ Jèhófà nípasẹ̀ Ìjọba Ọlọ́run tí Mèsáyà yóò ṣàkóso rẹ̀. Ọ̀run ni Ìjọba yìí yóò wà, yóò sì ṣàkóso gbogbo aráyé. Àwọn Kristẹni ìjímìjí mọ̀ pé àwọn “kì í ṣe apá kan ayé yìí.” Ìdí nìyẹn tí wọn kì í lọ́wọ́ nínú ọ̀tẹ̀ tí wọn kì í sì í dá sọ́ràn ogun. Bí wàhálà ò ṣe ní í sí láàárín wọn àtàwọn ẹlòmíràn ni wọ́n máa ń wá.—Jòhánù 14:26; 18:36; Mátíù 6:9, 10; Ìṣe 2:1-4; Róòmù 12:17-21.

Gbogbo àwọn onígbàgbọ́ náà ló ṣe ojúṣe wọn láti jẹ́ kí ìṣọ̀kan tó wà láàárín wọn máa lágbára sí i. Báwo ni wọ́n ṣe ṣe é? Wọ́n máa ń jẹ́ kí ìwà wọn bá ohun tí Bíbélì sọ mu. Èyí sì bá ohun tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ sáwọn Kristẹni mu, pé: “Ẹ bọ́ ògbólógbòó àkópọ̀ ìwà sílẹ̀, èyí tí ó bá ipa ọ̀nà ìwà yín àtijọ́ ṣe déédéé,” kí ẹ sì “gbé àkópọ̀ ìwà tuntun wọ̀.”—Éfésù 4:22-32.

Wọn Ò Jẹ́ Kí Ìṣọ̀kan Tó Wà Láàárín Wọn Bà Jẹ́

Ká sòótọ́, aláìpé làwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní, àwọn nǹkan kan sì ṣẹlẹ̀ tó fẹ́ ba ìṣọ̀kan wọn jẹ́. Bí àpẹẹrẹ, Ìṣe 6:1-6 sọ pé awuyewuye kan wáyé láàárín àwọn Júù tó jẹ́ Kristẹni, ìyẹn láàárín àwọn tó ń sọ èdè Gíríìkì lára wọn àtàwọn tó ń sọ èdè Hébérù. Àwọn tó ń sọ èdè Gíríìkì rò pé àwọn tó ń sọ èdè Hébérù ń fi àwọn nǹkan kan du àwọn. Nígbà táwọn àpọ́sítélì gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí, kíá ni wọ́n mójú tó o láìsí ojúsàájú. Lẹ́yìn ìyẹn, awuyewuye míì tún wáyé lórí ọ̀ràn ẹ̀kọ́ ìsìn. Wọ́n ń ṣàríyànjiyàn nípa ohun tí àwọn Kristẹni tí kì í ṣe Júù gbọ́dọ̀ máa ṣe. Ni wọ́n bá yẹ ohun tí Bíbélì wí wò, wọ́n sì fẹnu ọ̀rọ̀ náà jóná síbì kan. Gbogbo ìjọ ló fara mọ́ ibi tí wọ́n fẹnu ọ̀rọ̀ náà jóná sí.—Ìṣe 15:1-29.

Àwọn àpẹẹrẹ tá a gbé yẹ̀ wò yìí fi hàn pé àìgbọ́ra-ẹni-yé kò mú kí ìyapa wà láàárín onírúurú ẹ̀yà tó wà nínú ìjọ Kristẹni ọ̀rúndún kìíní, bẹ́ẹ̀ ni kò mú kí wọ́n máa fi ẹ̀kọ́ tó yàtọ̀ síra kọ́ni. Kí nìdí tó fi rí bẹ́ẹ̀? Ìdí ni pé àwọn ohun tó so wọ́n pọ̀ lágbára tó láti jẹ́ kí wọ́n wà níṣọ̀kan kí àlàáfíà sì wà láàárín wọn. Àwọn ohun náà ni: Ìfẹ́ tí wọ́n ní sí Jèhófà, ìgbàgbọ́ tí wọ́n ní nínú Jésù Kristi, ojúlówó ìfẹ́ tí wọ́n ní síra wọn, bí wọ́n ṣe máa ń fara mọ́ ìtọ́sọ́nà ẹ̀mí mímọ, ẹ̀kọ́ Bíbélì kan náà tí wọ́n fi ń kọ́ni, àti bí wọ́n ṣe múra tán láti kiwọ́ ìwàkiwà bọlẹ̀.

Ìṣọ̀kan Wà Nínú Ìjọsìn Lóde Òní

Ǹjẹ́ a lè mú kí ìṣọ̀kan wà bẹ́ẹ̀ lóde òní? Ǹjẹ́ àwọn ohun tó mú kí ìṣọ̀kan wà láàárín àwọn Kristẹni ìjímìjí lè mú kí ìṣọ̀kan wà láàárín àwọn tó wà nínú ìsìn kan náà lónìí? Ṣé ó sì lè mú kí àlàáfíà wà láàárín wọn àti gbogbo èèyàn káàkiri ayé? Bẹ́ẹ̀ ni! Ìṣọ̀kan wà láàárín àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kárí ayé. Orílẹ̀-èdè àti erékùṣù tí wọ́n wà lé ni igbà ó lé ọgbọ̀n [230]. Kẹ́ ẹ sì wá wò ó o, àwọn ohun tó mú káwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní wà níṣọ̀kan ló mú káwọn náà wà níṣọ̀kan.

Èyí tó ṣe pàtàkì jù lọ lára àwọn ohun tó mú káwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà wà níṣọ̀kan ni ìfọkànsìn wọn sí Jèhófà Ọlọ́run. Èyí túmọ̀ sí pé wọ́n ń sapá gidigidi láti jẹ́ olóòótọ́ sí i ní ipòkípò tí wọ́n bá wà. Bákan náà, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní ìgbàgbọ́ nínú Jésù Kristi, wọ́n sì gba àwọn ohun tó fi kọ́ni gbọ́. Àwọn Kristẹni wọ̀nyí nífẹ̀ẹ́ ara wọn dénú. Ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run kan náà sì ni wọ́n ń wàásù rẹ̀ ní gbogbo ibi tí wọ́n ti ń wàásù. Inú wọn máa ń dùn láti sọ̀rọ̀ nípa Ìjọba yìí fáwọn èèyàn tó wá látinú gbogbo ìsìn, gbogbo ẹ̀yà, gbogbo orílẹ̀-èdè àti látinú onírúurú àwùjọ. Láfikún sí i, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kì í dá sí àwọn ohun tó jẹ́ ti ayé yìí, ì báà jẹ́ nínú ìṣèlú, nínú àṣà ìbílẹ̀, láwùjọ tàbí nínú ọrọ̀ ajé. Ìdí nìyẹn táwọn nǹkan tó máa ń pín aráyé níyà yìí kì í pín àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà níyà. Gbogbo Ẹlẹ́rìí ló ń ṣe ojúṣe wọn láti jẹ́ kí ìṣọ̀kan wà láàárín wọn nípa híhu ìwà tó bá ìlànà Bíbélì mu.

Ìṣọ̀kan Tó Wà Láàárín Wọn Ń Fa Àwọn Míì Mọ́ra

Ìṣọ̀kan tó wà láàárín àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà sábà máa ń wú àwọn tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà lórí. Bí àpẹẹrẹ, Ilse a jẹ́ obìnrin ajẹ́jẹ̀ẹ́ ìnìkàngbé nínú ìsìn Kátólíìkì tẹ́lẹ̀. Ilé àwọn ajẹ́jẹ̀ẹ́ ìnìkàngbé ní orílẹ̀-èdè Jámánì ló sì ń gbé nígbà yẹn. Kí ló wù ú lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà? Ilse sọ pé: “Nínú àwọn èèyàn tí mo ti ń rí láyé mi, àwọn ni wọ́n ṣèèyàn jù. Wọn kì í lọ sógun, wọn kì í sì í pa ẹnikẹ́ni lára. Bí wọ́n ṣe máa ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ kí wọ́n lè wà láàyè títí láé nínú Párádísè lábẹ́ Ìjọba Ọlọ́run ló jẹ wọ́n lógún.”

Ẹlòmíràn ni Günther tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ọmọ ogun ilẹ̀ Jámánì. Ilẹ̀ Faransé sì ni wọ́n gbé e lọ nígbà Ogun Àgbáyé Kejì. Lọ́jọ́ kan, àlùfáà Pùròtẹ́sítáǹtì kan lọ ṣèsìn fáwọn sójà tó wà nínú ẹgbẹ́ ọmọ ogun tí Günther wà. Àlùfáà náà gbàdúrà pé kí Ọlọ́run ràn wọ́n lọ́wọ́, kó dáàbò rẹ̀ bò wọ́n kó sì jẹ́ kí wọ́n ṣẹ́gun. Nígbà tí wọ́n gbàdúrà tán, Günther lọ sídìí iṣẹ́ olùṣọ́ tí wọ́n yàn fún un. Bó ṣe ń fi awò-awọ̀nàjíjìn rẹ̀ wo òréré, bẹ́ẹ̀ ló rí àwọn ọmọ ogun ọ̀tá. Ó rí i tí àlùfáà kan ń ṣèsìn fáwọn náà. Nígbà tó ṣe, Günther sọ pé: “Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ńṣe ni àlùfáà yẹn ń gbàdúrà fáwọn náà pé kí Ọlọ́run ràn wọ́n lọ́wọ́, kó dáàbò rẹ̀ bò wọ́n kó sì jẹ́ kí wọ́n ṣẹ́gun. Ó yà mí lẹ́nu pé àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì ń ti àwọn ọmọ ogun tó ń bára wọn jà lẹ́yìn.” Àwọn ohun tí Günther rí yìí kò kúrò lọ́kàn rẹ̀. Ìyẹn ló fi jẹ́ pé nígbà tó pàdé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, tó sì rí i pé wọn kì í lọ́wọ́ sógun, òun náà di Ẹlẹ́rìí Jèhófà.

Ìsìn kan tí wọ́n ń ṣe ní apá Ìlà Oòrùn ayé ni Feema àti Ashok ń ṣe. Wọ́n ní ojúbọ kan nínú ilé wọn. Àmọ́ nígbà tí àìsàn líle koko kọ lu ìdílé wọn, wọ́n tún ìsìn wọn yẹ̀ wò. Nígbà tí wọ́n wá bá àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fọ̀rọ̀ jomitoro ọ̀rọ̀, àwọn ẹ̀kọ́ inú Bíbélì wú wọn lórí, bẹ́ẹ̀ náà ni ìfẹ́ tó wà láàárín àwọn Ẹlẹ́rìí wú wọn lórí pẹ̀lú. Ní báyìí, ńṣe ni Ashok àti Feema ń fi ìtara kéde Ìjọba Jèhófà.

Ilse, Günther, Ashok, àti Feema ti wà níṣọ̀kan pẹ̀lú ọ̀kẹ́ àìmọye àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí ẹgbẹ́ ará wọn wà jákèjádò ayé. Wọ́n gba ohun tí Bíbélì ṣèlérí rẹ̀ gbọ́. Ìlérí náà ni pé àwọn ohun tó mú kí wọ́n wà níṣọ̀kan nínú ìjọsìn wọn nísinsìnyí yóò mú kí gbogbo èèyàn tó bá ṣègbọràn wà níṣọ̀kan láìpẹ́. Nígbà náà, kò ní sí ìwà ìkà mọ́, ìyapa á lọ àlọ rámirámi, ìsìn ò sì ní máa fa ìpínyà mọ́. Gbogbo ayé á wá wà níṣọ̀kan nínú ìjọsìn Jèhófà, Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo náà.—Ìṣípayá 21:4, 5.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a A ti yí àwọn orúkọ kan padà nínú àpilẹ̀kọ yìí.

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 4, 5]

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé onírúurú ibi làwọn Kristẹni ìjímìjí ti wá, tó sì jẹ́ pé onírúurú ìwà ni wọ́n ń hù tẹ́lẹ̀, síbẹ̀ wọ́n wà níṣọ̀kan